“Ìwọ Ha Fẹ́ràn Mi Bí?”
Bí a bá fẹ́ fi ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run hàn, a níláti ní òye bí Òun ti dá àfihàn ìfẹ́ wa mọ̀.
Nínú òwe ọmọ onínàákúnàá, arákùnrin rẹ̀ àgbà kọ́kọ́ tiraka láti ṣe àjọyọ̀ nígbàtí àbúrò rẹ̀ ọkùnrin náà padà sílé lẹ́hìn àkokò kan ti àwọn àṣàyàn aìtọ́ àti “[ìfi]ṣòfò ohun ìní rẹ̀ pẹ̀lú ìgbé ayé aláriwo.” Ìgbéraga àti ìṣòdodo-araẹni ti arákùnrin àgbà náà fà á sẹ́hìn kúrò ní ṣíṣe ìgbàmọ́ra ayọ̀ ti ìpadàbọ̀ onirònúpìwàdà arákùnrin rẹ̀. Àwa bákannáà le jẹ́ kí àwọn ànfààní fò wá kọjá láì jẹ́ kí àwọn olólùfẹ́ wa mọ̀, nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ àti àwọn iṣe wa, nípa ìfẹ́ òdodo wa fún wọn.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àpẹrẹ tó lágbára ló wà nínú àwọn ìwé mímọ́ nípa ìfẹ́ òdodo tí a pín tí a sì gbà: Nàómì àti Rúùtù, Ámọ́nì àti Ọba Lámónì, ọmọ onínàákúnàá àti baba rẹ̀, Olùgbàlà àti àwọn ọmọ ẹ́hìn Rẹ̀.
Nígbàtí ìfẹ́ bá jẹ́ fífúnni lọ́fẹ̀ẹ́ àti gbígbà lódodo, àyípo oníwàrere kan nṣẹlẹ̀ pẹ̀lú àlékún ìfẹ́ láàrin ẹni tó nfúnni àti ẹni tó ngbà.
Ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́ pípé, àìlópin, pípẹ́ títí, àti “dídùn jùlọ.” Ó nkún ọkàn pẹ̀lú “ayọ̀ nlá gidigidi.” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nígbà míràn ó lè ṣòro fún wa láti dá ìfẹ́ Ọlọ́run mọ̀ nínú ayé wa. Ṣùgbọ́n, Baba wa Ọ̀run olùfẹ́ni pípé ní ìfẹ́ inú jíjinlẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ fún wa láti ní ìrírí ìfẹ́ Rẹ̀ tí Ó “bá [wa] sọ̀rọ̀ ní ìbámu sí … òye [wa].” Òun yíò fi ìfẹ́ Rẹ̀ fún wa hàn ní àwọn ọ̀nà tí àwa, bí ẹnìkọ̀ọ̀kan, lè dá mọ̀. A lè ní ìrírí ìfẹ́ Ọlọ́run fún wa nígbàtí a bá kíyèsí àwọn ẹwà inú adánidá, tàbí gba àwọn ìdáhùn sí àwọn àdúrà, tàbí kí àwọn èrò inú wá sí iyè wa ní àkokò gan an tí a nílò, tàbi ki a ní ìrírí àwọn àkókò ayọ̀ dídùn. Ìfarahàn títóbi jùlọ ti ìfẹ́ Baba Ọ̀run fún wa, tí ó ní ìfaramọ́ pẹ̀lú iyè inú àti ọkàn, ni nígbàtí Ó fi ààyè gba Ọmọ Rẹ̀ Ọ̀wọ́n láti fi ara Rẹ̀ sílẹ̀ bíi ètùtù kan.
Bíi arákùnrin àgbà ti ọmọ onínàákunàá, ìdojúkọ wa máa nsaabà dá lórí ara wa. A máa nṣe àníyàn tó bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú wíwá ẹ̀rí ìfẹ́ Ọlọ́run fún wa, a sì máa nkáarẹ̀ nígbàtí a kò bá rí i. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ rírẹwà tó jọra ni pé bí a bá ti fi ojú sí fífi ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run hàn sí, bẹ́ẹ̀ ni yíó rọrùn fún wa sí láti dá ìfẹ́ Rẹ̀ fún wa mọ̀. Bóyá èyí ni ìdí tí Olùgbàlà fi dáhùn si ìbéèrè náà “Èwo ni ó jẹ́ òfin títóbi?” pẹ̀lú ìpè tó rọrùn tó sì ṣe pàtàkì yí: “Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ̀, àti gbogbo ọkàn rẹ̀, àti gbogbo inú rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ.”
Nígbà míràn bí a ti nfi ìfẹ́ wa hàn sí àwọn tí a mú bíi ọ̀wọ́n jùlọ kìí ṣe bí àwọn ṣe dá ìfẹ́ mọ̀. Èyí le fa ìkáarẹ̀ fún olùfúnni àti ẹni tí ó ngbà. Ó le ṣèrànwọ́ láti béèrè lọ́wọ́ àwọn tí a fẹ́ràn bi wọ́n ti dá ìfẹ́ tí a fihàn mọ̀ sí. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, bí a bá fẹ́ fi ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run hàn, a níláti ní òye bí Òun ti dá ìfẹ́ wa mọ̀. Pẹ̀lú orí ire, Òun ti la oríṣiríṣi àwọn ọ̀nà sílẹ̀ kedere nínú àwọn ìwé mímọ́ ti a fi le ṣe àfihàn ìfẹ̀ wa fún Un.
Ìwọ Ha Fẹ́ Mi Ju Àwọn Wọ̀nyí Lọ Bí?
Nínú pàṣípààrọ̀ ìkọ́ni láàrin Pétérù àti Olúwa tó jínde ni ibi Òkun Tíbéríásì, a kọ́ ẹ̀kọ́ nípa àwọn ọ̀nà tí a fi lè ṣe àfihàn ìfẹ́ wa fún Olúwa.
“Jésù wí fún Símónì Pétérù pé, Símónì, ọmọ Jónà, ìwọ fẹ́ mi ju àwọn wọ̀nyí lọ bí? Ó wí fún un pé, Bẹ́ẹ̀ni, Olúwa, ìwọ mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.”
Kókó ìbéèrè nínú ìwádìí yìí láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni pé “Ìwọ ha fẹ́ràn mi púpọ̀ ju àwọn ìwọ̀nyí lọ bí?” A nfi ìfẹ́ wa sí Olúwa hàn nígbàtí a bá fi Òun sí òkè “àwọn wọ̀nyí,” àti pé “àwọn wọ̀nyí” lè jẹ́ ẹnikẹ́ni, èyíkéyìí iṣẹ́ ṣíṣe, tàbí ohunkóhun tí ó bá gba ààyè Rẹ̀ kúrò ní jíjẹ́ ipá pàtàkì jùlọ nínú ayé wa.
Kò lè sí ànító àkókò láé nínú ọjọ́ kan, ọ̀sẹ̀ kan, oṣù kan, tàbí ọdún kan láti ṣe gbogbo ohun tí a fẹ́ tàbí nílò láti ṣeyọrí. Apákan ìdánwò ayé ikú ni láti lo ohun èlò iyebíye ti àkókò fún ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ fún ire ayérayé wa àti láti jẹ́kí àwọn ohun wọnnì tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì ó kọjá lọ.
Ààrẹ Russell M. Nelson wí pé: “Ìbéèrè fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa … jẹ́ ọ̀kannáà. … Njẹ o nfẹ́ láti jẹ́kí Ọlọ́run jẹ́ ipa pàtàkì jùlọ nínú ayé rẹ bí? Njẹ́ ìwọ ó fi ààyè gba àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀, òfin Rẹ̀, àti àwọn májẹ̀mú Rẹ̀ láti ní ipá lórí ohun tí ìwọ ó ṣe ní ojojúmọ́? Njẹ́ ìwọ ó fi ààyè gba ohùn Rẹ̀ láti wà ní ipò ìṣíwájú sí èyíkéyìí míràn? Njẹ́ o nfẹ́ láti jẹ́ kí ohunkóhun tí Ó bá nílò kí o ṣe jẹ́ ìṣíwájú lórí gbogbo àwọn ìlépa míràn? Njẹ́ o nfẹ́ láti jẹ́ kí ìfẹ́ inu tìrẹ ó jẹ́ gbígbémì nínú Tirẹ̀?” A nṣe àfihàn jíjẹ́ ọmọẹ̀hìn àti ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run nígbàtí a bá fi Òun sí òkè pátápátá ohun tí a fẹ́.
Ẹ Bọ́ àwọn Àgùtàn Mi
Nínú ẹsẹ tó kàn ti ìbáraẹni-sọ̀rọ̀ yí kannáà láàrin Pétérù àti Olùgbàlà, a kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ọ̀nà míràn tí Olúwa fi ndá àfihàn ìfẹ́ wa mọ̀: “[Olúwa] tún wí fún un ní ìgbà kejì pé, Símónì, ọmọ Jónásì, ìwọ ha fẹ́ràn mi bí? Ó wí fún un pé, Bẹ́ẹ̀ni, Olúwa; ìwọ mọ̀ pé èmi fẹ́ràn rẹ. Ó wí fún un pé, Bọ́ àwọn àgùtàn mi.”
A nfi ìfẹ́ wa fún Baba Ọ̀run hàn nígbàtí a bá nsìn, fetísílẹ̀ sí, fẹ́ràn, gbé sókè, tàbí ṣe iṣẹ́ ìrànṣẹ́ sí àwọn ọmọ Rẹ̀. Iṣẹ́ ìsìn náà lè jẹ́ rírọrùn bíi rírí àwọn ẹlòmíràn ní tòótọ́ láìsí ìdájọ́. Nínú ìpín 76 ti Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú, a ní ìtọ́wò ìwà àwọn ẹni tí yíò jogún ògo sẹ̀lẹ́stíà: “Wọ́n nrí bí a ti rí wọn, wọ́n sì nmọ̀ bí a ti mọ̀ wọ́n.” Wọ́n nrí àwọn ẹlòmíràn bí Ọlọ́run ti nrí wọn, Òun sì nrí wọn bí wọ́n ti lè dà, pẹ̀lú agbára àtọ̀runwá ológo.
Lẹ́hìn pípadà sílé láti ibi iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi, mo tẹ́wọ́gba iṣẹ́ ìtọ́jú koríko ti àwọn arákùnrin mi àti èmi bẹ̀rẹ̀ bíi ọ̀dọ́. Bákannáà ọwọ́ mi dí pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ yunifásítì mi. Ní ọ̀sẹ̀ kan nígbà ìrúwé, ọ̀pọ̀ òjò àti àwọn ìdánwò àṣekágbá tó nbọ̀ mú mi ní ìrẹ̀wẹ̀sì àti ìfàsẹ́hìn níbi iṣẹ́ inú ọgbà.
Ní ààrin ọ̀sẹ̀ ojú ọ̀run ṣe kedere, mo sì gbèrò láti ṣe àlébá lórí iṣẹ́ inú ọgbà lẹ́hìn àwọn ètò ẹ̀kọ́. Ṣùgbọ́n nígbàtí mo délé, ọkọ̀ aroko àti àwọn irinṣẹ́ mi ti lọ. Ní fífẹ́ mọ̀, mo ṣe àbẹ̀wò sí àwọn ọgbà ti a ti ṣètò; ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ti jẹ́ títọ́jú tán pẹ̀lú ẹwà. Ní ibi ọgbà tó kẹ́hìn lórí ètò, mo rí arákùnrin àbúrò mi to nrìn lẹ́hìn ẹ̀rọ ìroko. Ó rí mi, ó rẹ́rìín, ó sì juwọ́. Ní bíborí pẹ̀lú ìmoore, mo gbà á mọ́ra mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Ìṣẹ́ ìsìn rẹ̀ tó nítumọ̀ fi okun to jinlẹ̀ fún ìfẹ́ àti ìṣòtítọ́ mi fún un. Sísin ara wa jẹ́ ọ̀nà kan tí kò ṣeé ṣì mọ̀ tí a fi nṣe àfihàn ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀.
Jẹ́wọ́ Ọwọ́ Rẹ̀ nínú Ohun Gbogbo
A nṣe àfihàn ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run bákannáà nípa níní ọkàn ìmoore. Olúwa wí pé, “Nínú ohunkóhun kọ́ ni ènìyàn ti ṣẹ Ọlọ́run, … bíkòṣe àwọn wọnnì tí wọn kò jẹ́wọ́ agbára rẹ̀ nínú ohun gbogbo.” A nfi ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run hàn nípa jíjẹ́wọ́ Rẹ̀ bíi orísun ohun rere gbogbo nínú ayé wa.
Ní àwọn ọjọ́ ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ti ṣíṣe ìgbékalẹ̀ ilé iṣẹ́ kan, ẹnìkejì mi ní ìdí iṣẹ́ àti èmi yíó gbàdúrà pẹ̀lú ìtara ṣaájú àwọn ìpáde pàtàkì, ní bíbéèrè fún ìrànlọ́wọ́ Baba Ọ̀run. Ní àkokò lẹ́hìn àkokò, Ọlọ́run dáhùn àwọn àdúrà wa, àwọn ìpàdé wa sì lọ dáradára. Lẹ́hìn ìpàdé kan, ẹnìkejì mi ní ìdí iṣẹ́ tọ́ka síi pé a máa nyára láti béèrè fún ìrànlọ́wọ́ ṣùgbọ́n a nlọ́ra láti ṣe ọpẹ́. Láti ìgbà náà lọ, a sọ ọ́ di ìwà láti ṣe àwọn àdúrà òdodo ti imoore, ni dídá ọwọ́ Olúwa mọ̀ nínú àwọn àṣeyọrí wa. A nfi ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run hàn pẹ̀lú “ìṣesí ìmoore.”
Bí Ẹ Bá Fẹ́ràn Mi, Ẹ Pa àwọn Òfin Mi Mọ́
Ọ̀nà míràn tí a fi nfi ìfẹ́ wa fún Baba Ọ̀run àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀ hàn ni láti yàn láti gbọ́ràn si Wọn. Olùgbàlà wí pé, “Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn mi, ẹ pa àwọn òfin mi mọ́.” Irú ìgbọràn yìí kò fọ́jú tàbí kí ó ṣe dandan ṣùgbọ́n ó jẹ́ àfihàn òdodo àti ìfẹ́ àtinúwá. Baba ní Ọ̀run fẹ́ kí àwa fẹ́ láti jẹ́ olùgbọ́ràn. Arábìnrin Tamara W. Runia pe èyí ní “ìgbọràn ìfẹ́ni.” Ó wí pé, “Àní bíótilẹ̀jẹ́pé a kò ní ìgbọràn pípé síbẹ̀, a ngbìyànjú ìgbọràn ìfẹ́ni nísisìnyí, ní yíyàn láti dúró, lẹ́ẹ̀kansi àti lẹ́ẹ̀kansi, nítorí a fẹ́ràn Rẹ̀.”
Baba Ọ̀run fún wa ní agbára òmìnira láti mísí wa láti fẹ́ láti yan Òun. Iṣẹ́ àti ògo Rẹ̀ kìí ṣe láti mú ìyè ayérayé wa ṣẹ nìkan ṣùgbọ́n ó ní ìrètí nínú bákannáà pé ìfẹ́ inú wa títóbi jùlọ ni láti padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, Òun kò ní fi ipá mú wa láti gbọ́ràn. Nínú orin isìn “Mọ Èyí, Pé Gbogbo Ẹ̀mí Ni Ó ní Òmìnira,” a nkọ́rin pé:
Bíi olùdarí ẹkùn iṣẹ́ ìránṣẹ́, ìyàwó mi, Christina, àti èmi jẹ́ mímísí nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere tí wọ́n yàn láti jẹ́ olùgbọ́ràn, kìí ṣe nítorípé ó jẹ́ òdiwọ̀n fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ nìkan ṣùgbọ́n nítorípé wọ́n fẹ́ láti fi ìfẹ́ wọn fún Olúwa hàn nípa fífi ìrẹ̀lẹ̀ yàn láti ṣe ojú Rẹ̀.
Alàgbà Dale G. Renlund wí pé: “Ìlépa Baba wa Ọ̀run nínú ṣíṣe òbí kìí ṣe láti mú àwọn ọmọ Rẹ̀ ṣe ohun tó tọ́; ó jẹ́ láti mú àwọn ọmọ Rẹ̀ yàn láti ṣe ohun tó tọ́ ati nígbẹ̀hìn kí wọn ó dà bíi Rẹ̀. Bí Ó bá kàn fẹ́ pé kí a jẹ́ olùgbọ́ràn, Òun ó lo àwọn èrè àti ìjìyà ojú ẹsẹ̀ láti darí àwọn ìhùwàsí wa.” A nfi ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run hàn nígbàtí a bá yàn láti gbọ́ràn sí I.
Baba wa Ọ̀run àti Olùgbàlà wa ndá àwọn àfihàn ìfẹ́ wa fún Wọn mọ̀ nígbàtí a bá fi Wọ́n ṣe àkọ́kọ́ nínú ayé wa, ti a sin ara wa, jẹ́wọ́ gbogbo àwọn ìbùkún láti ọ̀dọ̀ Wọn pẹ̀lú ìmoore, tí a sì yàn láti gbọ́ràn àti láti tẹ̀lé Wọn.
Mo jẹ́rìí pé ẹnìkọ̀ọ̀kan wa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run ní tòótọ́ Òun sì fẹ́ràn wa ní pípé. Mo jẹ́rìí pé Ó npòngbẹ fún wa láti ni ìrírí ìfẹ́ Rẹ̀ ní àwọn ọ̀nà tí a dámọ̀ tí ó sì yé wa. Àwọn ọ̀rọ̀ jíjọra rírẹwà ni pé a ó ní ìrírí ìfẹ́ Rẹ̀ fún wa àní jinlẹ̀ síi bí a ti nfi ìfẹ́ wa fún Un hàn. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.