Kí Ẹni Gbogbo Lè Di Gbígbéga
Bí a ti nfojú sí ara Jésù Krístì, tí a nkọ́ni ní ẹ̀kọ́ Rẹ̀, tí a sì nkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú aápọn, a npe Ẹ̀mí Mímọ́ láti mú ìgbàgbọ́ wa jinlẹ̀ síi nínú Jésù Krístì kí ó sì ràn wá lọ́wọ́ láti dà bíi Rẹ̀ síi.
Ìtàn kan ni a sọ nípa ọ̀dọ́ akẹ́kọ̀ọ́ unifásítì kan ẹnití ó tiraka pẹ̀lú kíláàsì líle kan, nítorìnáà ó gba olùkọ́ kan láti ràn án lọ́wọ́. Ní ìsúnmọ́ ìparí ẹ̀kọ́ kíkọ́, ọ̀jọ̀gbọ́n náà kéde pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lè mú ẹ̀là bébà kan wá sí ibi ìdánwò ìkẹhìn lórí èyítí wọ́n le fi ohunkóhun tí wọ́n bá fẹ́ lé. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan múrasílẹ̀ nípa ṣíṣe àkọsílẹ̀ kínkiní pẹ̀lú ìwífúnni láti inú àwọn ìdánilẹkọ̀ọ́ àti àwọn ìwé, tí ó ṣeé kà nípa lílo jígí imútóbi nìkan. Ṣùgbọ́n ọ̀dọ́mọkùnrin náà dé sí ibi ìdánwò ìkẹhìn náà pẹ̀lú bébà funfun lásán àti àjèjì kan. Nígbàtí ọ̀jọ̀gbọ́n náà bi í léèrè, ọ̀dọ́mọkùnrin náà dáhùn pé, “O sọ pé mo lè mú ẹ̀là bébà kan wá pẹ̀lú ohunkóhun lórí rẹ̀.” Lẹ́hìnnáà ó fi bébà náà sí orí ilẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ tábílì rẹ̀ ó sì wí pé, “Èmi fẹ́ kí olùkọ́ mi wá dúró sí orí ẹ̀là bébà mi.”
Ẹ̀mí Mímọ́
Àwa bí ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, tí a jẹ́ alábùkún fún pẹ̀lú ojúgbà ti ọmọ Àjọ Ọlọ́run Olórí, a lè ní ìrànlọ́wọ́ ti Olùkọ́ni pípé. Ẹ̀mí Mímọ́ mọ ohun gbogbo, ó njẹ́rìí nípa òtítọ́, yíò sì “mú ohun gbogbo wá sí ìránti [wa].” Ààrẹ Russell M. Nelson ti sọ̀rọ̀ léraléra nípa pàtàkì gbígbọ́ ohùn Olúwa. Ó kọ́ wa bí a ṣe lè pe ìtọ́ni Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú wa lemọ́lemọ́ láti mú agbára ti ẹ̀mí wa pọ̀ síi lati gba ìfihàn.
Lónìí mo pè yín láti ṣe àṣàrò ipa ti Ẹmí Mímọ́, ní pàtó bí ó ti ní í ṣe sí kíkọ́ ẹ̀kọ́ àti kíkọ́ni ní ìhìnrere nínú ilé àti ní ilé ìjọsìn. Ẹmí Mímọ́ ni a nfúnni nípa àdúrà ìgbàgbọ́ àti bí a ti ntiraka láti gbé ìgbé ayé yíyẹ fún ẹ̀bùn iyebíye yí. Ìwé ìléwọ́ onímìísí ti Ìjọ Kíkọ́ni ni Ọ̀nà ti Olùgbàlà ṣe àfihàn àfikún àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ tí Olúwa ti gbékalẹ̀ ti´ yíò ṣèrànwọ́ láti pe ipá ti Ẹmí Mímọ́.
Ẹ Pè Ẹ̀kọ́ Kíkọ́ Pẹ̀lú Aápọn
Ọ̀kan nínú àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ wọ̀nyí ni láti pe ẹ̀kọ́ kíkọ́ pẹ̀lú aápọn. Ní ìgbà àtijọ́, a lè ti ronú nípa ìkọ́ni bíi ààyè kan fún òbí tàbí olùkọ́ láti pe Ẹ̀mí sínú ìmúrasílẹ̀ tiwọn àti lẹ́hìnnáà kí wọn ó ṣe àbápín ohun tí wọ́n ti kọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ tàbí àwọn ará kíláàsì, tí ó ti jẹ́ ipa wọn láti fetísílẹ̀. Ṣùgbọ́n àní dídára síi jẹ́ ìgbàtí àwa, bíi akẹ́kọ̀ọ́, bákannáà bá wá pẹ̀lú ìmúrasílẹ̀ àti ìgbàtí àwọn olùkọ́ bá dá àwọn ìrírí kíkọ́ ẹ̀kọ́ tó ṣìkẹ́ ìfihàn ti araẹni tààrà sí ọkàn àti inú wa sílẹ̀. Nígbànáà, bi a ti nfún wa ní àwọn ànfààní láti ṣe àbápín ohun tí a nkọ́ nípasẹ̀ àṣàrò wa àti láti ọ̀dọ̀ Ẹmí Mímọ́, a nran ara wa lọ́wọ́ láti jẹ́ kíkọ́ àti gbígbéga. Bí a ti nṣe àmúlò àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ ìhìnrere, Ẹ̀mí lẹ́ẹ̀kansíi njẹ́ ẹ̀rí nípa jíjẹ́ òtítọ́ wọn.
Bíi nínú ohun gbogbo, Jésù Krístì ni àpẹrẹ pípé náà. Ó ti pè ẹnìkọ̀ọ̀kan wa láti jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ alaápọn àti láti wà ni àmójútó àwọn ẹ̀rí ti arawa. Ó pè àwọn ọmọẹ̀hìn rẹ̀ láti múrasílẹ̀ láti kọ́ ẹ̀kọ́, láti pín ohun tí wọn nkọ́, àti láti ṣe ìṣe nínú ìgbàgbọ́. Ó gbàdúrà fún wọn, ó rí agbára àtọ̀runwá wọn, ó fetísílẹ̀ sí wọn, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ̀ pé a fẹ́ràn a sì nílò wọn.
Àwa bíi olùkọ́, a le fojúsí orí ìtẹ̀síwájú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ síi, sórí bíbá àwọn àìní wọn pàdé, àti sórí ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe ìmúdàgbà àwọn ìwà ti ẹ̀mí nípa jíjẹ́ ọmọẹ̀hìn ní gbogbo ọjọ́ ayé. Bíi akẹ́kọ̀ọ́, nígbàtí a bá lo agbára òmìnira wa nínú ètò ikẹ́kọ̀ọ́ náà, a nṣe àpẹrẹ sí Ẹmí Mímọ́ pé a ṣetán láti jẹ́ kíkọ́ láti ọwọ́ Rẹ̀.
Mo fi ìmoore hàn fún olùkọ́ kan tí ó pè mí láti jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ dídára síi. Nígbàtí mo bẹ̀rẹ̀ kọ́lẹ́ẹ̀jì, mo ṣèèṣì ronú nípa ilé ìwé bíi ohun kan tí a níláti forítì kí a lè fi ààyè gbà wá láti ṣe àwọn eré ìdárayá. Ní ọjọ́ kan, lẹ́hìn kíka béba kan tí mo ti kọ, ọ̀jọ̀gbọ́n mi sọ fún mi pé òun rò pé mo jẹ́ onírònú afọ́rọ̀síwẹ́wẹ́ tó ni ẹ̀bùn Èmi kò tilẹ̀ mọ ohun tí èyí túmọ̀ sí. Ó wí pé pẹ̀lú aápọn fífojúsí díẹ̀ síi mo le jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ dáradára kan. Irònú náà kò wá sí ọkàn mi rí. Ìfẹ́ràn, ìgbani-níyànjú, àti àwọn ìpè rẹ̀ yí ipa ọnà ètò ẹkọ́ mi padà ó sì bùkún ayé mi lọ́pọ̀lọpọ̀.
Kọ́ni ni Ẹ̀kọ́ náà
Ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ míràn tí ó ní í ṣe sí pípe Ẹmí Mímọ́ ni láti kọ́ni ni ẹ̀kọ́ òtítọ́. Èyí túmọ̀ sí pé ṣiṣe àṣàrò àti kíkọ́ni ní ìhìnrere wa jẹ́ fìfi ìdí múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti pé a kò bù mọ́ tàbí ta gbìrò lórí ohun tí Olúwa kò tíì fihàn. Dípò bẹ́ẹ̀, a nfojúsí orí àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ pàtàkì àti ti ayérayé, èyítí ó fààyè gba Ẹ̀mí láti jẹ́rìí nípa òtítọ́. Lẹ́ẹ̀kansíi, a ntẹ̀lé àpẹrẹ Olùgbàlà. Ó wí pé, “Ẹ̀kọ́ mi kìí ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ti ẹni náà tí ó rán mi.”
Ẹ̀kọ́ òtítọ́ ni a nrí nínú àwọn ìwé mímọ́ àti nínú àwọn ìkọ́ni ti àwọn wòlíì òde òní. Ìgbani-níyànjú ti Olúwa láti ṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́ bíi ẹnìkọ̀ọ̀kan àti bíi ẹbí àti láti máa wà ní ilé ìjọsìn ní ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan láti ṣe àṣàrò ìhìnrere Rẹ̀ npèsè àwòṣe tó lápẹrẹ láti kọ́ ẹ̀kọ́ Rẹ̀ àti láti gbọ́ ohùn Rẹ̀. A nwá inú àwọn ìwé mímọ́ láti ní òye àlàyé náà, àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ni, àti àmúlò àwọn òtítọ́ wọ̀nyí nínú ayé wa. Ó ti jẹ́ ìbùkún tó láti ní àwọn ìwé mímọ́ ní orí ìka ọwọ́ wa. Ẹ fi ojú inú wo Ádámù àti Éfà, Ábínádì, tàbí Ọ̀gá Olùkọ́ni pàápàá, Jésù Krístì, ní ṣíṣe àbẹ̀wò sí ilé tàbí àwọn kíláàsì wa láti kọ́ wa. Wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀ nígbàtí a bá ṣe àpèjẹ lóri ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Pẹ̀lú aápọn léraléra, a lè kọ́ láti ní òye àti ìfẹ́ àwọn ìwé mímọ́ kí a sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé wọ́n ní àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbèèrè ti ọkàn.
Ìgbà kan wà ṣaájú ìgbéyàwó wa nígbàtí ìyàwó mi Kristi, ntiraka láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Baba Ọ̀run àti láti ní òye ètò Rẹ̀ fún un. Bí ó ti gbàdúrà fún ìtọ́ni, ìtẹ̀mọ́ra kan wá pé kí ó lọ sí ibi ìdánilẹ́kọ̀ọ́, nítorínáà ó pinnu láti forúkọsílẹ̀ nínú kíláàsì Májẹ̀mú Titun kan. Ọ̀nà tí olùkọ́ ibi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ fi kọ́ni láti inú àwọn ìwé mímọ́, àní ọ̀nà tí ó fi mú wọn, fi hàn bí ó ti fẹ̀ràn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó. Bí ó ti nwà níbẹ̀, Ẹmí Mímọ́ sọ fún un kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pé ohun kan wà nínú àwọn ìwé mímọ́ tí ó nílò. Ìfẹ́ olùkọ́ rẹ̀ fún àwọn ìwe mímọ́ àti àwọn ìṣíléti ti Ẹmí Mímọ́ fún un ní ìfẹ́ inú láti bẹ̀rẹ̀ àṣàrò ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gidigidi—èyítí ó di ìrìnàjò ọjọ́ ayé ti ìjìnlẹ̀ ìyípadà ọkàn àti iṣẹ́ ìsìn yíyàsí mímọ́.
Fojúsí orí Jésù Krístì
Ní ìparí, bí Kíkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà ti dábàá, ìkọ́ni àti ẹ̀kọ́ kíkọ́ wa níláti fi ìgbà gbogbo fi ojú sí ara Krístì. A lè sọ̀rọ̀ léraléra síi àti pẹ̀lú ọ̀wọ̀ síi nípa Rẹ̀ kí a sì wá àwọn ànfààní síi áti sọ ẹ̀rí, ìmoore, àti ìfẹ́ wa fún Un. Bí ó ti wù kí ó rí, bí a ti nrántí Rẹ̀, a lè ní “Ẹ̀mí rẹ̀ láti wà pẹ̀lú [wa].”
Ọ̀nà kan láti fi Jésù Krístì sí ààrin gbùngbùn ìkọ́ni wa ni láti tẹnumọ́ọ pé Òun ni àpẹrẹ pípé, àmì àti ọ̀rọ̀ sísọ ti gbogbo ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ ìhìnrere. Àní nígbàtí Òun kò jẹ́ títọ́kasí tààrà nínú àkọsílẹ̀ ti ìwé mímọ́ kan, síbẹ̀ a lè tọ́ka sí I bíi àpẹrẹ ti ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ tí a nkọ́ni. A kàn lè béèrè pé, “njẹ́ o lè ronú àkókò kan nígbàtí Jésù Krístì ṣe àpẹrẹ ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ yìí?”
A lè fojú sí ara Rẹ̀ bákannáà nípa kíkọ́ nípa àwọn àpèjá, àwọn ipa, àti àwọn ìhùwàsí Rẹ̀, ní wíwá láti kọ́ ẹ̀kọ́ kìí ṣe nípa ohun tí Ó ti ṣe nìkan ṣùgbọ́n láti ní òye dídára síi nípa ẹni tí Ó jẹ́. Fún àpẹrẹ, nígbàtí a bá nṣe àṣàrò ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ ti ìrònúpìwàdà, ó ṣe pàtàkì láti ní òye bí a ṣe nronúpìwàdà. Ṣùgbọ́n bákannáà ó ṣe pàtàkì láti rántí ohun tí Jésù Krístì ti ṣe láti mú kí ìrònúpìwàdà ṣeéṣe àti láti ní òye ohun tí ìrònúpìwàdà kọ́ wa nípa Rẹ̀, nípa àdánidá àti àwọn ìhùwàsí Rẹ̀ tòótọ́. Kínni ohun tí ànfààní wa láti ronúpìwàdà sọ nípa ìfẹ́, sùúrù, àti àánú Rẹ̀, ìgbàgbọ́ Rẹ̀ nínú agbára àtọ̀runwá wa, ìfẹ́ Rẹ̀ láti ṣ̣e ètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, àti ayọ̀ tí Ó nrí nínú dídáríjì? Àti pé níní òye àwọn àpèjá Rẹ̀—bí irú Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run, Olùràpadà, àti Oníwòsàn—nràn wá lọ́wọ́ láti ríi pé ìrònúpìwàdà jẹ́ ìfipè Rẹ̀ láti wẹ̀ wá nù, yí wa padà, àti láti wò wá sàn. Fífi ojú sí ohun ti Ó ti ṣe fún wa àti ohun tí ó sọ nípa ẹni tí Ó jẹ́ lè ràn wá lọ́wọ́ ní “ìgbàgbọ́ sí ìrònúpìwàdà.”
Nígbà míràn a lè má tètè rí àwọn ìhùwàsí ti Olùgbàlà ní fífarahàn nínú àkọsílẹ̀ ti ìwé mímọ́. Fún àpẹrẹ, nígbàtí a bá nkà nípa Néfì tó nkan ọkọ̀ ojú omi, a lè fojúsí ara Néfì nìkan. Ṣùgbọ́n fífojú sí ara Olùgbàlà le ràn wá lọ́wọ́ láti ríi pé àkọsílẹ̀ yìí kò jẹ́ pípamọ́ láti kọ́ wa nípa títóbi Néfì ṣùgbọ́n láti fi títóbi Ọlọ́run hàn sí wa—pé Ó fún wa ní okun láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́ àti láti gbà wá ní àwọn àkókò àìní.
Bákannáà a le fojú sí ipa pàtàkì ti Jésù Krístì nínú ètò ìdùnnú pípé ti Baba Ọ̀run. Ó le yí ipa ọ̀nà ti ìgbé ayé wa padà láti rí àwọn ipò wa nípasẹ̀ awò-ojú ètò ayérayé ti Ọlọ́run dípò rírí ètò náà nípasẹ̀ awò-ojú àwọn ipò wa tó jẹ́ ti ara. Ìhìnrere kìí ṣe ìtòlẹ́sẹ̀ẹ̀sẹ ti àwọn ìbéèrè, ó jẹ́ ìròhìn ayọ̀ pé Jésù Krístì borí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú Ó jẹ́ nípa gbígbà nínú oore ọ̀fẹ́ ìyanu Rẹ̀ nípasẹ̀ pípa àwọn májẹ̀mú wa pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́ ni a fi lè gbé pẹ̀lú ayọ̀ nísisìyí kí a sì múrasílẹ̀ fún ìgbé ayé pẹ̀lú Baba ní Ọ̀run nínú àwọn ayérayé. Bí a ti nkọ́ láti rí Baba Ọ̀run àti Olùgbàlà nínú àwọn ìwé mímọ́, a ó mọ̀ Wọ́n dáradára síi a ó sì rí ìfẹ́ àti ipa Wọn léraléra síi àti ní lílágbára síi nínú ayé tiwa.
Èmi ó máa fi ìgbà gbogbo rántí Ẹ̀mí tí mo ní ìmọ̀lára bí ọ̀dọ́ nígbàtí olùkọ́ wa kọ́ni nípa àwọn ọjọ́ tó kẹ́hìn nínú ayé Olùgbàlà. Ó rànwá lọ́wọ́ láti rí pàtàkì àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ nínú yàrá òkè, Gẹ́tsémánè, Gólgótà, àti ibojì òfìfo náà Ó pín ìjìnlẹ̀ ìmoore rẹ̀ fún Olùgbàlà àti ìgbọ́ná ìfẹ́ inú rẹ̀ láti tẹ̀lé E. Ìkọ́ni Rẹ̀ jẹ́ ìfipè kan fún Ẹ̀mí Mímọ́ láti jẹ́rìí nípa Jésù Krístì. Àti pé Ẹ̀mí ti mo mọ̀lára nínú kíláàsì náà mú ìgbàgbọ́ mi jinlẹ̀ ó sì fi kún ìfẹ́ àti ìmoore mi fún Olùgbàlà. Ipá ti olùkọ́ náà ti wà pẹ̀lú mi ní gbogbo ayé mi. Bí a ti sọ nípa olùkọ́ ìhìnrere míràn, “A lè jẹ́ kí ọwọ́ wa móoru nípa iná ìgbàgbọ́ rẹ̀.”
Íparí
Nínú ilé àti ní àwọn ìpàdé ilé ìjọsìn wa, bí a ti nfojú sí ara Jésù Krístì, nkọ́ni ní ẹ̀kọ́ Rẹ̀, tí a sì nkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú aápọn, a npe Ẹ̀mí Mímọ́ láti mú ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì jinlẹ̀ síi kí ó sì ràn wá lọ́wọ́ láti dà bíi Òun síi, èyítí ó jẹ́ èròngbà gbogbo ìkọ́ni àti ìkẹ́kọ̀ọ́ ìhìnrere.
Mo dúpẹ́ fún àwọn olùkọ́ nínú ayé mi, láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí dídára àti àwọn aṣaájú ìbílẹ̀ àti àwọn olùkọ́ dé ọ̀dọ̀ àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí a ti pè láti kọ́ni àti láti jẹ́rìí láti orí pẹpẹ yìí, tí wọ́n ràn wá lọ́wọ́ láti mọ̀ àti láti tẹ̀lé Jésù Krístì. Mo sì dúpẹ́ fún Ẹ̀mí Mímọ́, Olùkọ́ni pípé, Nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ ni mo ti mọ̀ pé Baba Ọ̀run fẹ́ràn wa Ó sì ní ètò pípé kan fún wa, pé Jésù ni Kristì náà, Olùgbàlà àti Olùràpadà aráyé, àti pé ìhìnrere àti Ìjọ Rẹ̀ ni a ti múpadàbọ̀sípò. Mo fi pẹ̀lú ìdúpẹ́ jẹ́rìí nípa àwọn ohun wọ̀nyí ní orúkọ̀ Jésù Krístì, Àmín.