Lọ kí o sì Ṣe Bákannáà
Èmi yíò fẹ́ láti ṣàfihàn àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere tí wọ́n pè sí àwọn iṣẹ́-ìsìn ìyànsílẹ̀. Wọ́n jẹ́ àpẹrẹ fún wa.
Nígbàtí Olùgbàlà nrìnrìnàjò kiri Bethsaida, àwọn ènìyàn kan mú afọ́jú kan wá sọ́dọ̀ Rẹ̀. Bóyá wọ́n nretí láti rí iṣẹ́ ìyanu kan. Olùgbàlà “mú afọ́jú náà lọ́wọ́, ó sì mú un jáde kúrò ní ìlú” láti mú u láradá ní ìkọ̀kọ̀. Ní ìbẹ̀rẹ̀, ìwòsàn dàbí ẹnipé kò múnádóko. Ọkùnrin náà “gbójú sókè, ó sì wípé, mo rí àwọn ọkùnrin bíi igi, tí wọ́n nrìn.” Jésù, pẹ̀lú ìyọ́nú, “tún gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ojú [ọkùnrin] náà, ó sì mú kí ó gbójú sókè.” Pẹ̀lú àfikún ìfọwọ́kan ọwọ́ Olùgbàlà yẹn, afọ́jú náà “ríran … kedere.”
Èyí jẹ́ àpẹrẹ kan ṣoṣo ti bí ìgbé ayé Olùgbàlà ṣe jẹ́ àpèjúwe àwọn ìṣẹ ìrẹ̀lẹ̀ iṣẹ́ ìsìn. Ó rán wa létí pé Òun “kò wá kí a lè ṣeránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe láti ṣe ìránṣẹ́ fúnni” ó sì pè wá láti tẹ̀lé àpẹrẹ Rẹ̀ nípa ṣíṣe àfikún iṣẹ́, fífún àwọn tí ó béèrè lọ́wọ́ wa, àti fífẹ́ràn ọmọlàkejì wa. Nígbàtí a bèèrè, “Tani ọmọlàkejì mi?” Krístì ṣàbápín àkàwé ará Samáríà rere, pẹ̀lú àṣẹ pé “Lọ, kí o sì ṣe bákannáà.”
Àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn jẹ́ àpẹrẹ òde òní ti ará Samáríà rere tí Krístì pè wá láti dà. Èmi yíò fẹ́ láti ṣàfihàn àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere tí wọ́n pè sí àwọn iṣẹ́-ìsìn ìyànsílẹ̀. Wọ́n jẹ́ àpẹrẹ fún wa ti bí iṣẹ́ ìsìn (1) ṣe nṣí ọkàn sílẹ̀ sí ìhìnrere Jésù Krístì, (2) ṣe njẹ́ kí gbogbo wa ṣe ìránṣẹ́ láìka ipò wa sí, àti (3) bí ó ṣe nmú agbára Krístì wá sí ìgbésí ayé wa.
Lákọ̀ọ́kọ́, Iṣẹ́ ìsìn Nṣí Ọkàn sílẹ̀ sí Ìhìnrere Jésù Krístì.
Ní nkan bí ọdún kọkanlelaadọwa Ṣaájú Ìbí Krístì, Ámọ́nì fi ara rẹ̀ hàn Ọba Lámónì nípa sísọ pé, “Mo fẹ́ láti máa gbé àárín àwọn ènìyàn yìí fún ìgbà díẹ̀; … èmi [yíò sì] jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ.” Nítorí iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí ọba, Ámọ́nì ní a fún ní ànfààní láti “sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìgboyà, … ó sì sọ fún [Ọba Lámónì] … nípa agbára” tí ó fi ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Ní ìṣepadà, ọba ṣèlérí pé “ohunkóhun tí [Amọ́nì] bá fẹ́ … [ọba yíò] fi í fún.” Ìbéèrè Ámọ́nì kan ṣoṣo ni kí ọba fetísí ìhìnrere Jésù Krístì. Iṣẹ́ ìsìn Ámónì yọrí sí “ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọkàn [tí a mú] wá sí ìrònúpìwàdà.”
Ní ọjọ́ wa, iṣẹ́ ìsìn ntẹ̀síwájú láti darí àwọn ẹlòmíràn sí ìhìnrere. Arábìnrin Bevan nsìn bíi ìránṣẹ́ ìhìnrere tí nkọ́ni nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í nírìírí àwọn ọ̀ràn ìlera, tí ó nílò rẹ̀ láti padà sílé fún ìtọ́jú. Dípò kí wọ́n dá a sílẹ̀, ó ṣeé ṣe fún un láti máa sìn bíi ìránṣẹ́ ìhìnrere oníṣẹ́ ìsìn láti ilé.
Nígbàtí wọ́n nṣèbẹ̀wò sí ọgbà ìtura kan, Arábìnrin Bevan àti ọ̀rẹ́ kan gba ìṣílétí láti bá ìyá kan tí ó ní àwọn ọ̀dọ́mọdé mẹ́rin sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n nwọ́n ṣiyèméjì àti pé àwọn ẹ̀bí náà wakọ́ lọ. Lọ́jọ́ kejì, wọ́n padà sí ọgbà ìtura, wọ́n ngbàdúrà pé kí ẹbí yìí wà níbẹ̀. Lọ́nà ìyanu, ìyá náà jókòó síbi kan náà gan-an bíi ti ọjọ́ tó ṣáájú. Lọ́tẹ̀ yìí, Arábìnrin Bevan àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ tọ ìyá náà lọ, wọ́n mọ̀ ọ́n, wọ́n sì ṣàwárí pé ó nílò ìrànlọ́wọ́ ìgbà díẹ̀. Wọ́n pèsè ìrànlọ́wọ́, wọ́n sì pè é láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìhìnrere.
Nítorí iṣẹ́ ìsìn náà àti ìfipè, ìyá náà àti ọmọ rẹ̀ àgbà ṣèrìbọmi, ẹni tí ó dàgbà jùlọ tẹ̀lé e ní ọdún kan lẹ́hìnnáà. Wọ́n jẹ́ àwọn ọmọ ìjọ tó nṣe déédé lónìí. Arábìnrin Bevan mọ̀ pé ìrírí yìí jẹ́ ìmísí àtọ̀runwá àti pé ó “jẹ́rìí sí [i] pé [ó] wà gan-an níbití Ọlọ́run nílò [rẹ̀] láti wà.”
Bíi ti Ámọ́nì àti Arábìnrin Bevan, bí a ṣe nsin àwọn ẹlòmíràn, a “nfi àpẹrẹ rere hàn wọ́n” àti pé wọ́n fẹ́ mọ “ìdí ìrètí tí ó wà nínú [wa].”
Jésù pè wá láti “Lọ, kí a sì ṣe bákannáà.”
Ìkejì, Iṣẹ́ ìsìn Ngbà Gbogbo Wa Láyè Láti Ṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Láìka Ipò Wa Sí.
Ààrẹ Russell M. Nelson ti pe “gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin tó yẹ, tó sì lágbára láti múra sílẹ̀ fún àti láti sìn ní míṣọ̀n kan” àti fún gbogbo ọ̀dọ́ arábìnrin tó bá lágbára láti “gbàdúrà láti mọ̀ bí Olúwa bá fẹ́ kí [òun] sìn ní míṣọ̀n kan.” Ó ṣèlérí pé “ìpinnu yín láti sìn ní míṣọ̀n kan, bóyá ẹnití ó nyíni lọ́kàn padà tàbí iṣẹ́́ ìránṣẹ́ ìsìn kan, yíò bùkún ẹ̀yin àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn míràn.” Àwọn iṣẹ́́ ìránṣẹ́ ìsìn ti yí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà ìleṣe. Nísisìyí gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin tí wọ́n fẹ́ láti sìn fún ìgbà kíkún fún Olúwa lè ṣe bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú àwọn ìyàtọ̀ díẹ̀.
Alàgbà Holgado jẹ́ àpẹrẹ ti lílè sìn láìbìkítà àwọn ipò ti araẹni. Wọ́n bí i pẹ̀lú àrùn apilẹ̀ àbùdá tó ṣọ̀wọ́n, èyí tí kò jẹ́ kí ó ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́bí ìránṣẹ́ ìhìnrere kíkọ́ni. Alàgbà Holgado ni a pè bíi ìrànṣẹ́ ìhìnrere oníṣẹ́ ìsìn ó sì yọ̀ọ̀da ara rẹ̀ nínú ilé ìṣúra àwọn bíṣọ́ọ̀pù, níbi tí ó ti ran ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti rí ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n nílò. Ó kó ẹrù sínú àwọn selifu, kó àwọn ewébẹ̀ sínú àpò, ó sì nfọ́ àwọn àpótí páálí.
Bí Alàgbà Holgado ṣe sọ̀rọ̀ nínú ìpàdé oùnjẹ Olúwa lẹ́hìn iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, ó wí pé “Ọlọ́run nílò àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere oníṣẹ́ ìsìn. Ó nílò àwọn ènìyàn láti fẹ́ràn àti láti sin àwọn míràn. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí nkó bébà ìgbọ̀nsẹ̀ jọ, kó bórókólì sínú àpò, kan ohun ọ̀ṣọ́ ilé, wọ́n sì dára sí àwọn ènìyàn.”
Ẹ kò nílò láti ní iṣẹ́ ìsìn ìyànsílẹ̀ tàbí wọ táàgì orúkọ láti ṣe rere. Gbogbo ìṣe ti iṣẹ́ ìsìn jẹ dídámọ̀ nípasẹ̀ Olùgbàlà. Gbogbo wá lè ṣẹ̀rànwọ́ fún àwọn míràn láti wá sọ́dọ̀ Krístì nípa sísìn pẹ̀lú ìṣeun-ìfẹ́. Gbogbo wa lè ṣe ìṣẹ́ ìrànṣẹ́ ní orúkọ Krístì sí ọ̀kan náà nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́ kí a sì gbé bíi àpẹrẹ ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì. Iṣẹ́ ìsìn máa ngbàwá láyè láti fi ara wa hàn bíi ẹbọ ààyè tí Ọlọ́run tẹ́wọ́gbà.
Jésù pè wá láti “Lọ, kí a sì ṣe bákannáà.”
Ìkẹta, Iṣẹ́ ìsìn Nmú Agbára Krístì Wá sínú Ayé Wa.
Ọ̀dọ́mọkùnrin ìránṣẹ́ ìhìnrere kan tó ṣípò padà láti ibi ìyànsíṣẹ̀ kíkọ́ni lọ sí ìyànsíṣẹ̀ iṣẹ́ ìsìn tiraka pẹ̀lú àwọn ìpèníjà ti araẹni tí ó mú kó nílò agbára ìwòsàn Kristi. Iṣẹ́ ìsìn mímọ́ mú agbára náà wá sínú ayé rẹ̀. Ó wípé, “Mo nímọ̀lára pé nígbàtí mo ntiraka, mo lè nmọ̀lára pé Krístì ngbé mi sókè. Nkan pàtàkì kan wà nípa lílè ríi pé Ó nbùkún àwọn ènìyàn nípasẹ̀ ilé ìkó-oúnjẹ sí kan, nínú tẹ́mpìlì, àti nípasẹ̀ ìhìnrere Rẹ̀.”
Alàgbà yìí bẹ̀rẹ̀ sí í nímọ̀lára ayọ̀ jíjinlẹ̀, ìtara rẹ̀ titun sì bù kún òun àti gbogbo ẹbí rẹ̀. Ẹ̀mí wọ inú ilé wọn lọ́pọ̀lọpọ̀ síi, wọ́n lọ sí tẹ́mpìlì papọ̀ déédéé síi, Krístì sì di àfojúsí títóbi nínú ẹbí wọn. Ìránṣẹ́ ìhìnrere yí gbàgbọ́ pé Krístì gba ayé rẹ̀ là ó sì bùkún àwọn ẹbí rẹ̀ nípasẹ̀ iṣẹ́ ìsìn.
Ààrẹ Nelson ti kọ́ni pé, “Ìfẹ́ láti sìn àti láti fún àwọn ẹlòmíràn lókun dúró gẹ́gẹ́bí àmì ìmúratán ẹni láti rí ìwòsàn” nípasẹ̀ agbára ìràpadà ti Olùgbàlà.
Jésù pè wá láti “lọ, kí a sì ṣe bákannáà.”
Àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere oníṣẹ́-ìsìn jẹ́ àpẹrẹ àwọn ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì tí a yà sí mímọ́
Nígbàtí ẹ̀yin tàbí ọmọ ẹbí kan bá jẹ́ bíbùkún pẹ̀lú ìpè kan bíi ìránṣẹ́ ìhìnrere oníṣẹ́-ìsìn, ìyẹn jẹ àkokò kan láti ṣayẹyẹ. Ẹbí yín nísisìyí yíò ní aṣojú Olúwa Jésù Krístì kan tí a yàsọ́tọ̀ tí ngbé inú ilé yín. Ìyẹn yíò yí gbogbo yín padà sí rere. Kò yẹ kí ìjákulẹ̀ wà ní èyííkèyí ìpè láti sìn. A nkọrin, “Èmi yíò lọ sí ibití o fẹ́ kí nlọ” àti pé “Èmi yíò jẹ́ ohun tí o fẹ́ kí njẹ́.” Nihin ni ànfààní láti fihàn pé ohun tí a sọ dáwa lójú gidi!
Sí gbogbo ẹ̀yin tí ẹ nsìn, àti ní pàtàkì sí àwọn ọ̀dọ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere oníṣẹ́-ìsìn tí ó lé ní ẹ̀gbẹ̀rún mẹ́rin, a fẹ́ràn yín! Bí àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere kíkọ́ni bá jẹ́ ẹnu Olúwa, a jẹ́ wípé ọwọ́ Olúwa ni ẹ̀yin jẹ́, ẹ kì í sì í ṣe ìránṣẹ́ ìhìnrere onípò kejì. Olukúlùkù wa jẹ́ pàtàkì sí kíkójọ Ísráẹ́lì. Ààrẹ Nelson kọ́ni pé: “ìgbàkúgbà tí a bá ṣe ohun kan tí ó nran ẹnìkan lọ́wọ́ … tí a dá tí a sì pa àwọn májẹ̀mú wa pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́, à nṣèrànwọ́ láti kó Ísráẹ́lì jọ.”
Ẹ̀ nkó Ísráẹ́lì jọ lójoojúmọ́ ní ọ̀nà púpọ̀, iṣẹ́ ìsìn yín sì nyí ìgbésí ayé padà. Nígbàgbogbo ẹ kò mọ ẹni tí ó lè jẹ ànfààní iṣẹ́ ìsìn yín, ṣùgbọ́n Ọlọ́run mọ̀. Ẹ máa rántí nígbàgbogbo pé “níwọ̀n bí ẹ̀yin [bá sin] ọ̀kan nínú àwọn tí ó kéré jùlọ nínú ìwọ̀nyí, … ẹ [nsìn Ín].” A ngbọ́ àwọn ohun yín bí ẹ ṣe nyọ̀ọ̀da ní àwọn ibi ìpè Ìjọ; a nrí àwọn ẹ̀rín músẹ́ yín bí ẹ ṣe nṣèrànwọ́ ní àwọn àjọ agbègbè; a sì nímọ̀lára ìmọ́lẹ̀ yín bí ẹ ṣe nsìn ní tẹ́mpìlì. Ẹ nbọ́ àwọn tí ebi npa, wọ àwọn tí ó wà níhòhò ní aṣọ, ẹ sì nfún ẹnití òngbẹ ngbẹ ní ohun mímu.
Gbogbo wa ní láti lọ kí a sì ṣe bákannáà.
Iṣẹ́ ìsìn Jẹ́ Ẹjẹ̀-ìyè àwọn Ọmọẹ̀hìn Krístì.
Iṣẹ́ ìsìn lágbára láti ṣí ọkàn sí ìhìnrere àti láti gba gbogbo wa láàyè láti fi gbogbo ẹ̀mí wa fún Krístì. Ó nyí ọkàn wa padà láti dàbí Rẹ̀ síi, àti nínú ọ̀nà náà, a ngbé àwọn ẹlòmíràn ga. Ààrẹ Nelson nígbà kan béèrè pé, “Nínú ayé yìí tí ìbàjẹ́ ti ẹ̀mí ti kọlu, njẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan … lè ṣe ìyàtọ̀?” Ó dáhùn, “Bẹ́ẹ̀ni! … ‘Àwọn ènìyàn májẹ̀mú ti Olúwa, … tí ó di ìhámọ́ra … pẹ̀lú agbára Ọlọ́run nínú ògo nlá’ … lè gbé ìgbé ayé gbogbo ẹ̀dá ènìyàn ga.” Nípasẹ̀ iṣẹ̀-ìsìn a nyí àwọn ọkàn pada—àti àgbáyé.
Krístì “lọ kiri ní ṣíṣe ore.” Ó ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn aláìsàn, fi ìríran fún àwọn afọ́jú, bẹ àwọn tí a tẹ̀ mọ́lẹ̀ wò. Ó se oúnjẹ, ṣèrànwọ́ níbi àsè ìgbéyàwó, ó sì bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ebi npa. Bí a ti nsìn ní orúkọ Krístì sí ẹnìkan náà, a túbọ̀ di mímọ́ tí a sì yẹ fún ẹ̀bùn ìyè ayérayé. Jésù Krístì wà láàyè. Òun ni Olùgbàlà èmi àti ẹ̀yin. Òun ni Olùràpadà wa. Òun ni àpẹrẹ nlá wa ti iṣẹ́ ìránṣẹ́ ṣíṣe Mo pe olúkúlùkù wa láti lọ kí a sì ṣe bákannáà. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.