Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Rírántí Àgùntàn
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwàá 2025


12:14

Rírántí Àgùntàn

Ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ ti kíkà àti àwọn iṣẹ́ ṣíṣe ìṣirò. Ó jẹ́ ọ̀nà Olúwa.

Jésù ni Olùṣọ́-àgùtàn Rere. Olúkúlukú agbo ni ó ṣe iyebíye sí I. Ó ṣe àwòkọ́ṣe ṣíṣe olùṣọ́ àgùtàn ó sì kọ́ wa nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe àwọn ànímọ́ olùṣọ́ àgùntàn rere, títí kan mímọ àwọn àgùntàn rẹ nípa orúkọ, fífẹ́ràn wọn, rírí àwọn tí wọ́n sọnù, bíbọ́, àti, níkẹhìn, dídarí wọn padà sílé lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó nretí pé kí a ṣe bákannáà gẹ́gẹ́bí àwọn olùṣọ́-àgùntàn rẹ̀ tí ó wà lábẹ́ rẹ̀.

A lè kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ọ̀nà Olúwa láti ọ̀dọ̀ wòlíì ìgbàanì—àti olùṣọ́-àgùtàn àkànṣe—Mórónì. Ó gbé ní ìgbà ìṣòro tó le gan-an, kò ní àǹfààní fóònù àgbéká, àwọn kọ̀ǹpútà, àti íntánẹ́ẹ̀tì. Ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe fún un láti ṣàkóko àwọn àgùntàn náà. Báwo ni èyí ṣe ṣeéṣe? A ní ṣókí sínú ìlànà rẹ̀ ní Mórónì 6. Níbẹ̀ a kà pé àwọn ọmọ ìjọ “ni a kà mọ́ àwọn ènìyàn ìjọ ti Kristi; a sì gba àwọn orúkọ wọn, kí a lè rántí wọn kí a sì tọ́ wọn dàgbà nípa ọ̀rọ̀ rere Ọlọ́run, láti pa wọ́n mọ́ ní ọ̀nà títọ́. … Ìjọ náà máa npàdé pọ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, láti gbààwẹ̀ àti láti gbàdúrà, àti láti bá ara wọn sọ̀rọ̀ nípa ire ọkàn wọn” (Mórónì 6:4–5; afikún ìtẹnumọ́).

Fún Mórónì, gbogbo rẹ̀ jẹ́ nípa àwọn ènìyàn—àwọn orúkọ! Ó ṣe ìṣe ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ ti kíkà àti ṣíṣe ìṣirò kí gbogbo ènìyàn ba lè jẹ́ rírántí. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tiraka tàbí tí ó rìn kiri ni a ṣe àkíyèsí, tí ngba àwọn ènìyàn mímọ́ láàyè láti jíròrò ire wọn nínú àwọn ìgbìmọ̀. Gẹ́gẹ́bí olùṣọ́-àgùtàn tí ó fi àwọn mọ́kàndínlọ́gọ́run (àìléwu àti ààbò sílẹ̀, ó dá mi lójú) tí ó sì tẹ̀lé èyítí ó sọnù (wo Luku 15:4–7), a ti sọ fún wa pẹ̀lú láti ní ìfura àwọn agbo-ẹran wa bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́—láti ṣe àkíyèsí àti láti rántí kí a sì ṣe bákannáà.

Gẹ́gẹ́bí aṣáájú míṣọ́n kan ní Íńdíà, mo rántí bíbéèrè lọ́wọ́ ọ̀dọ́ ààrẹ ẹ̀ka kan nípa díẹ̀ lára àwọn àfojúsùn rẹ̀ fún ọdún tí nbọ̀ pé: “Àwọn ọkùnrin mélo ni ìwọ yóò múra sílẹ̀ láti gba Oyè Àlùfáà Mẹlikisédékì?” Ìdáhùn rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni “Méje!”

Ó yàmílẹ́nu láti ibití ó wà nínú étérì tí ó ti wá nọ́mbà kan pàtó náà! Ṣáájú kí ntó dáhùn, ó pèsè ẹ̀là ìwé kan pẹ̀lú àwọn nọ́mbà kínní sí méje tí a kọ sílẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́. Àwọn ìlà márun àkọ́kọ́ ní orúkọ lára ​​wọn—àwọn ènìyàn gidi tí òun àti ìyèjú àwọn alàgbà rẹ̀ yíò pè tí wọ́n ó sì gbà wọ́n níyànjú láti ní ìbùkún oyè àlùfáà nínú ìgbésí ayé wọn. Nítorí bẹ́ẹ̀, Mo ní láti bèèrè àwọn ìlà ṣíṣòfo kẹfà àti kéje. “Áà, Ààrẹ,” ni ó sọ, ní mímì orí rẹ̀ pẹ̀lú ìbákẹ́dùn, “Dájúdájú a ó ṣe ìrìbọmi ó kéré tán àwọn ọkùnrin méjì ní ọdún kínní tí wọ́n lè ní oyè àlùfáà ní òpin ọdún.” Aṣaájú dídára jùlọ yi ní ímọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ ti kíkà àti ṣíṣe ìṣirò.

Krístì ti ṣe Ìjọ Rẹ̀ ní ọ̀nà tí ó yẹ kí ó ṣòro láti gbàgbé ẹ̀mí kan, nítorí ọ̀kọ̀ọkan jẹ́ olùfẹ́ sí I. Olúkúlukú ènìyàn ní ẹ̀ka rẹ̀, láìka ọjọ́-orí tàbí akọ tàbí abo sí, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìrijú—àwọn olùṣọ́-àgùtàn—tí a fún ní iṣẹ́ ṣíṣe pẹ̀lú láti tọ́jú wọn, pẹ̀lú rírántí. Ọ̀dọ́kùnrin kan, fún àpẹẹrẹ, ti yàn fún ìwà-ìrọ̀rùn ara rẹ̀ bíṣọ́ọ̀prìkì kan tó nsìn ín, àwọn ìránṣẹ́ arákùnrin, àwọn agbaninímọ̀ràn ọ̀dọ́, àwọn olùkọ́ sẹmínárì, àwọn ààrẹ àjọ ìyèjù, àti nígbànáà àwọn kan—tí wọ́n nsìn gẹ́gẹ́bí àwọ̀n ààbò, múra ṣinṣin lábẹ́ ọ̀dọ́ náà láti dìímú bí ó bá ṣubú. Àní bí a bá tilẹ́ mú àwọ̀n kanṣoṣo dúró dáradára, ọ̀dọ́kùnrin náà yíò wà ní ààbò, ní àkíyèsí, yíò sì jẹ́ rírántí. Àti pé síbẹ̀síbẹ̀, nígbàkugbà a nrí àwọ̀n ní ibì kan. Àwọn ènìyàn máa nrìn kiri nígbà kọ̀ọ̀kan sínú ìkùukùu—kò sì sí ẹni tó nṣàkíyèsí. Báwo ni a ṣe lè jẹ́ àwọn olùṣọ́ àgùtàn tí ó dára jùlọ? A lè kọ́ láti kà àti láti ṣe ìṣirò.

Ìjọ npèsè wa pẹ̀lú àwọn ìròhìn àti àwọn ohun-èlò láti ṣe ìyẹn—láti rántí. Ìjábọ̀ ti ìdámẹ́rin ọdún jẹ́ àpẹrẹ àkọ́kọ́. Ó gbà wá láàyè láti kà àti láti ṣe ìṣirò fún ọmọ ìjọ kọ̀ọ̀kan ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà àti láti ṣe àkíyèsí àwọn tí a pàdánù tàbí nílò ìrànlọ́wọ́ wa àti ìfẹ́ wa. Ìṣe ti àkójọ ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò nṣe ìdánimọ̀ àwọn tí ó nílo ìfojúsí wa báyi, gẹ́gẹ́bí ìwé ìkaniyẹ tẹ́mpìlì ti ṣè jẹ́ ìjabọ̀ ipò àti àwọn míran. Àwọn ohun-èlò kíkà àti ṣíṣírò wọ̀nyi fojú wa sí àwọn ènìyàn lórí. Tani ó nílò ìpè kan, ìlọsíwájú oyè àlùfáà kan, tàbí ìrànlọ́wọ́ Láti mú orúkọ ẹbí kan lọ sí tẹ́mpìlì? Tani a lè ṣe ìrànlọ́wọ́ mímúrasílẹ̀ fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìgbà-kíkún? Tani ẹ pàdánù ní oṣù yi? Àwọn ohun-èlò wọ̀nyí ràn wa lọ́wọ́ láti rántí àwọn ènìyàn.

Mo mọ ìdílé kan láti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà tó gba iṣẹ́ àyànfúnni ní Áfríkà. Ní ọjọ́ Ìsinmi àkọ́kọ́ wọn gan-an, wọ́n rìnwọ ẹ̀ka Ìjọ kanṣoṣo ní orílẹ̀-èdè náà, níbití wọ́n ti kí wọn pẹ̀lú orí-yíyá. Ní òpin òwúrọ̀ náà, a ti pe ìyàwó ọkùnrin náà gẹ́gẹ́bí ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ àti òun gẹ́gẹ́bí olùdarí àwọn Ọ̀dọ́mọkùnrin! Ó béèrè lọ́wọ́ ààrẹ ẹ̀ka tí ó ti rẹ̀ pé àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mélo ló wà níbẹ̀. Olóòótọ́ yi, aṣáájú-ìran àkọ́kọ́ tọ́ka sí ẹ̀hìn gbàgede oúnjẹ́ Olúwa ó sì sọ pé, “Àwọn méjèèjì tí ó wà lọ́hun un nì.” Ọkùnrin náà ṣiyèméjì lọ́nà tí ó yẹ, nítorí náà ó mú ìwé àkọsílẹ̀ ẹ̀ka kan lọ sí ilé, ní kíákíá o kíyèsí pé dájúdájú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ogún ló wà nínú ìtòsílẹ̀ náà. Ó padà sọ́dọ̀ ààrẹ ẹ̀ka náà ó sì bèèrè fún àwọn ọ̀dọ́ àgbà alágbára, elédèméjì láti sìn gẹ́gẹ́bí olùdámọ̀ràn rẹ̀ nígbànáà ó sì jóko pẹ̀lú wọn àti àwọn ọmọdékùnrin méjì láti ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn orúkọ náà.

Lẹ́hìnnáà àwọn ọ̀dọ́ tí ó ní ìtara wọ̀nyí lọ sí ṣiṣẹ́. Ní àwọn oṣù díẹ̀ síi, wọ́n rí gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí a ṣe àkójọ. Ní orúkọ sí orúkọ, àwọn ojúgbà wọn kí àwọn àgùntàn tó sọnù wọ̀nyí káàbọ̀ padà wọ́n sì bọ́ wọn nípa ti ẹ̀mí àti nípa ti ara! Láarín ọdún kan, ní ọjọ́ Ìsinmi èyíkéyi, àpapọ̀ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mọ́kànlélógún ló wà ní ìjoòkó. Ọpẹ́ oore fún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí wọ́n kà tí wọ́n sì ṣe ìṣirò.

Ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n kan, gẹ́gẹ́bí ọ̀dọ́ akẹ́kọ gboyè, ṣí lọ pẹ̀lú ẹbí rẹ̀ sí ìlú nlá kan ní Amẹ́ríkà láti máa bá ẹ̀kọ́ rẹ̀ lọ. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n pè e láti daríṣe àkóso lórí ìyèjú àwọn alàgbà. Nípa Àìbàlẹ̀ ọkàn díẹ̀ ti ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú ààrẹ èèkàn, ó pinnu láti lọ pẹ̀lú ìmúrasílẹ̀. Ó sọ fún ààrẹ èèkàn pé òun ní ìlépa mẹ́ta fún ọdún tí nbọ̀: (1) ìpín àadọ́run iṣẹ́-ìránṣẹ́, (2) ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹ̀kọ́ ìhìnrere kan lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, àti (3) ìṣe-ṣíṣe tí a ṣètò-dáradára ní ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan lóṣù.

Ní rírẹ́rin músẹ́ sí ọ̀rẹ́ mi, ààrẹ èèkàn ọlọgbọ́n yi bèèrè, “Ṣé o lè dárúkọ ọmọ ẹgbẹ́ iyejú àìwá-déédé tí o lè ràn lọ́wọ́ láti lọ sí tẹ́mpìlì pẹ̀lú ẹbí rẹ̀ ní ọdún yi?” Èyí mú ọ̀rẹ́ mi ní ìyàlẹ́nu. Ó ronú dáradára ó sì dá orúkọ kan. “Kọ èyíinì sílẹ̀,” ni ààrẹ èèkàn náà darí. Lẹ́hìnnáà olùdarí tí ó ní ìrírí yi bèèrè ìbéèrè kannáà nígbà mẹ́ta síi—ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà si parí. Ọ̀dọ́mọkùnrin yi jáde kúrò níbi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà lẹ́hìn tí ó ti kọ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ tí ó tóbi jùlọ lórí jíjẹ́ aṣaájú àti ṣíṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́. Ó lọ sínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn ètò, àwọn ẹ̀kọ́, àti àwọn ìṣe ṣíṣe. Ó jáde pẹ̀lú àwọn orúkọ! Àwọn orúkọ mẹ́rin wọ̀nyí lẹ́hìnnáà di kókó i`fojúsí ti iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ti ìyèjú rẹ̀.

Gẹ́gẹ́bí aṣáájú míṣọ́n, mo ṣe ìbẹ̀wò sí ọ̀kan lára ​​àwọn ẹ̀ka mi ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ìsinmi kan. Mo kíyèsí pé ààrẹ ẹ̀ka náà nmú káàdì bébà kan jáde nínú àpò rẹ̀ ó sì nkọ̀wé sórí rẹ̀. Mo pinnu láti bií léèrè nípa èyí lẹ́hìn àdúrà ìparí. Nígbàtí ìpàdé parí àti aíwájú kí ntó lè béèrè nípa káàdì náà, aṣáájú ẹ̀ká míṣọ́n náà sá lọ síbi pẹpẹ, níbi tí wọ́n ti fún un ní ìwé náà. Mo yára tẹ̀lé aṣáájú oníyáàrí yìí lọ sí ìpàdé dídarí àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ẹ̀ka rẹ̀ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀, ó mú ìwé náà jáde nínú àpò rẹ̀. Ó kún fún orúkọ àwọn ọmọ ìjọ tí ó pàdánù wíwá sí i`pàdé oúnjẹ Olúwa. Láarín ìṣẹ́jú díẹ̀, ọmọ ìgbìmọ̀ kọ̀ọ̀kan ti yan orúkọ kan tàbí méjì, ní ìpinnu láti ṣe ìbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn lọ́jọ́ náà gan-an láti ri dájú pé ara wọn dá àti láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a ṣèdárò àìwá wọn. Báyi èyí jẹ́ kíkà àti ṣíṣe ìṣirò.

Mo rántí ẹ̀kùn kan, ọ̀pọ̀ wákàtí nípasẹ̀ ọkọ̀ òfúrufú láti tẹ́mpìlì tí ó súnmọ́ jùlọ, níbití àbójútó ìwé ìkaniyẹ tẹ́mpìlì lọ́wọ́lọ́wọ́ ti jẹ́ ààyò gígá, bíótilẹ̀jẹ́pé ó lè má ṣeé lò rárá. Ní ọjọ́ Ìsinmi àkọ́kọ́ ti oṣù kọ̀ọ̀kan, àwọn aṣaájú nlo ohun-èlò kíkà wọn làti ṣe ìṣirò fún àwọn ọmọ ìjọ tí ó ti ní ẹ̀bùn tẹ́mpìlì. Tí wọn bá ri pé ìwé ìkaniyẹ tẹ́mpìlì kan yíò tó parí láìpẹ́, akọ̀wé aláṣẹ yíò ṣètò ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ìsọdọ̀tun. Àwọn ènìyàn tí ó ní ìwé ìkaniyẹ tẹ́mpìlì tí ó ti parí ni a dámọ̀ràn lé lórí, lẹ́hìnnáà wá ọ̀na àbájáde láti ràn wọ́n lọ́wọ́ ní pípadà sí ipa ọ̀nà májẹ̀mú. Mo bèèrè mélo nínú àwọn tí ó gba ẹ̀bùn tẹ́mpìlì ní ó ní ìwé ìkaniyẹ tẹ́mpìlì lọ́wọ́lọ́wọ́. Ìdáhùn sí jẹ́ ìyànilẹ́nu ìpín 98.6 nínú ọgọ́run. Nígbàtí a bèèrè nípa àwọn mẹ́fà tí ìwe ìkaniyẹ tẹ́mpìlì wọn ti parí, àwọn aṣaájú ní ànfààní láti ṣe ìdánimọ̀ wọn nípa orúkọ wọ́n sì ṣe àpèjúwe fún mi àwọn ìgbìyànjú tí wọ́n nṣe láti gbà wọ́n padà!

Ní ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, ẹbí mi padà sí ìlú Amẹ́ríkà. Inú wa dùn láti lọ sí Ìjọ níbí lẹ́hìn ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26) nínú ibi kékeré, kọ̀ọ̀kan tí a yà sọ́tọ̀. Wọ́n pè mí gẹ́gẹ́bí ìránṣẹ́ ìhìnrere wọ́ọ̀dù kan. A ní aṣaájú míṣọ́n wọ́ọ̀dù nlá ó sì nṣe àwọn nkàn alárinrin àti tí wọ́n sì nkọ́ àwọn ènìyàn ìyanu. Mo bèèrè láti wà ní ìpàdé ìgbìmọ̀ wọ́ọ̀dù láti ṣe àkíyèsí àti láti gba ìrànlọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ tí à nṣiṣẹ́ pẹ̀lú. Ó yà mí lẹ́nu nígbàtí gbogbo ohun tí wọ́n sọ jẹ́ ìṣe ṣíṣe wọ́ọ̀dù tí nbọ̀. Mo dé ọ̀dọ̀ olùdarí míṣọ́n wọ́ọ̀dù lẹ́hìnáà àti gbìrò pé òun kò ní àyè láti padà kí òun sì jíhìn lórí àwọn ènìyàn wa. Ìdáhùn rẹ̀? “Áà, Èmi kò ráyéláti jíhìn rárá.”

Mo ṣe ìyàtọ̀ sí ìpàdé ìgbìmọ̀ ẹ̀ka kan ní Lahore, Pakistan, Mo ṣe ìyàtọ̀ sí ìpàdé ìgbìmọ̀ ẹ̀ka kan ní. Ẹgbẹ́ kékeré yi jókòó yí tábìlì kékeré kan papọ̀, gbogbo nkan tí wọ́n sì nsọ jẹ́ nípa àwọn ènìyàn. Àwọn orúkọ. Aṣáájú kọ̀ọ̀kan ròhìn iṣẹ́ ìríjú wọn àti àwọn olúkúlùkù àti àwọn ẹbí tí wọ́n ní àníyàn nípa wọn. Gbogbo wọn ní áǹfààní láti fi èrò wọn kún ọ̀nà tó dára jùlọ tí wọ́n fi lè bùkún àwọn tí wọ́n nsọ̀rọ̀ lé. Wọn ṣe àwọn ètò wọn sì fúnni ní ìyànsíṣẹ̀. Ẹ ò ri pé ẹ̀kọ́ àtàtà ní èyí nínú kíka àti ṣíṣe ìṣirò nípa orúkọ láti ìran àkọ́kọ́ àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin wa.

Nínú Ìjọ ti Jésù Krístì, a ti fún wa ní ìtọ́ni láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì àtijọ́ àti àwọn wòlíì ìsisìyí—àti nípa àwòṣe tí Olùgbàlà wa fi lélẹ̀—bí a ṣe lè ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́. A ngba àwọn orúkọ, a nrántí, a sì ngbani nímọ̀ràn lórí ire àwọn ẹ̀mí. Àwọn aṣaájú tí ó ṣe èyí kì yíò parí àwọn nkàn àgbéṣe ní ìpàdé ìgbìmọ̀ wọn! Ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ ti kíkà àti àwọn iṣẹ́ ṣíṣe ìṣirò. Ó jẹ́ ọ̀nà Olúwa. A lè ṣé dídàra jùlọ. Sí Ọlọ́run, ẹnití ó dá àgbáyé tí ó sì nṣe àkóso gbogbo rẹ̀, iṣẹ́ yi—iṣẹ́ àti ògo Rẹ̀ jẹ́ ti—ara ẹni gan-an. Bẹ́ẹ̀ sì ni ó yẹ kí ó rí fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, gẹ́gẹ́ bí ohun èlò ní ọwọ́ Rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ ti ìgbàlà àti ìgbéga. Àwọn iṣẹ́ ìyanu ní ìgbésí ayé awọn ènìyàn gidi yíò jẹ́ àyọrísí. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.