Bá Ọlọ́run Làjà
Ẹ bá Ọlọ́run làjà, nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì, ndarí sí ìgbàgbọ́ àìyẹsẹ̀.
Bí mo ti nṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́, mo rí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó gba ìfojúsí mi lódodo, kókó nítorí wọ́n ní ìtumọ̀ pàtàkì bí àbájádeàwọn ìrírí tí mo ní ní ìgbà ayé mi. Mo lo iṣẹ́ ṣíṣe mi bí oníṣirò ìwaàdí. Pẹ̀lú agbétẹ́lẹ̀ náà, ọ̀rọ̀ náà bálàjà ti gba ìfojúsí mi bí mo ti nka àwọn ìwé mímọ́. Iṣẹ́ mi ni láti ṣe lílàjà oye ìròhìn pẹ̀lú áwọn àkọsílẹ̀ ìnàwó nípa lílo ṣíṣírò, ṣe àyẹ̀wò, àti àwọn iṣẹ́ ìtọsẹ̀. Ní ọ̀rọ̀ míràn, ìlépa mi ni láti fi ìròhìn ìṣúná-owó sí ìbámu pẹ̀lú àwọn ìwé ìṣúná-owó abẹ́lẹ̀ láti mu ìṣegẹ́gẹ́ àti agbára òfin dájú. Mo nṣe ìtiraka aápọn láti yanjú àwọn àṣìṣe, ó sì wọ́pọ̀ láti ya àkokò pàtàkì sọ́tọ̀ sí yíyànjú àní àṣìṣe kekeré jùlọ.
Àpóstélì Páùlù bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú àwọn ará Kọ́ríntì láti “bá Ọlọ́run Làjà.” Láti bá Ọlọ́run Làjà túmọ̀sí láti mú padà sí ìbárẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run tàbí láti mú ìbáṣepọ̀ kan pẹ̀lú Ọlọ́run tí ó ti bàjẹ́ tàbí já nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ìṣe wa padàbọ̀sípò. Ká fi sí ìrọrùn, lílàjà pẹ̀lú Ọlọ́run túmọ̀ sí fífi ìfẹ́ àti ìṣe wa sí ìbámu pẹ̀lú ifẹ́ Ọlọrun tàbí, bí a ṣe kọ́ nípasẹ̀ wòlíì wa ọ̀wọ́n, Ààrẹ Russell M. Nelson, jíjẹ́ kí Ọlọ́run borí nínú ayé wa.
Bí a ti kọ́ni nínú àwọn ìwé mímọ́, a ní òmìnira láti ṣe ìṣe fún arawa, “láti yan ikú ayé àìlópin tàbí ọ̀nà ìyè ayérayé.” Ṣùgbọ́n bí a kò bá ní aápọn, o`mìnira láti ṣe ìṣe yí fún ara wa lè darí sí àdánù ìbámu pẹ̀lú Ọlọ́run.
Wòlíì Jákọ́bù kọ́ni pé nígbàtí a bá rí ara wa ní àìwà-ní-ìbárẹ́ tàbí àìsí-ní-ìbámu pẹ̀lú Ọlọ́run, ọ̀nà kanṣoṣo tí a fi lè ṣe àṣeyege ìbálàjà ni láti “bá [Ọlọ́run] làjà nípasẹ̀ ètùtù ti Krístì.” A gbọ́dọ̀ damọ̀ pé bíbálàjà dá lé orí àánú, ó túmọ̀sí pé ìṣe oore ti ètùtù Jésù Krístì nmú bíbálàjà ṣeéṣe.
Bí ẹ ti njíròrò ìgbé ayé ara yín, ẹ ronú nípa àkokò kan nígbàtí ẹ ti ní ìmọ̀lára jíjìnnà kúrò lọ́dọ̀ Baba Ọ̀run nítorí ẹ ti rìn kúrò ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Fún àpẹrẹ, bóyá ẹ di dídínkù ní aápọn nínú àdúrà yín sí I tàbí ní pípa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́. Gẹ́gẹ́bí a ti yàn mú ara wa jìnnà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ yàn láti mú ìtiraka láti làjà dìde. Nolúwa tẹnumọ́ ojúṣe wa nígbàtí Ó wípé: “Sún mọ́ mi Èmi yíò sì sún mọ́ Ọ; wá mi pẹ̀lú aápọn ìwọ yíó sì rí mi; bèèrè, àti pé ìwọ yíò rí gbà; kànkù, a ó sì ṣí fún ọ.”
Báwo ni Olùgbàlà ṣe nràn wá lọ́wọ́ láti múpadàbọ̀sípò àti láti làjà ìbáṣepọ̀ pàtàkì yí? Fún mi, mo ní ìlọsíwájú púpọ̀ nínú ìrìnàjò mi láti bá Ọlọ́run Làjà nígbàtí mo tẹ̀lé àmọ̀ràn tí a kọ́ni nípasẹ̀ Ààrẹ Nelson tí mò sì nronúpìwàdà lójojúmọ́. Èrèdí náà jẹ́ pé ìbálàjà fi ìmúpadàpọ̀sípò nípa ìbáṣepọ̀ jíjá hàn, nípàtàkì ní àárín Ọlọ́run àti ti-ènìyàn, nípa mímú ìdènà ti ẹ̀ṣẹ̀ kúrò.
Ọ̀kan lára àwọn ìbálàjà nlá tí a kà nínú àwọn ìwé mímọ́ ni ìyẹn ti Énọ́sì. Ohunkan nínú ayé rẹ̀ kò sí ní ìbámu pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó fi àpẹrẹ gbígbáralé Ètùtù Jésù Krístì láti bá Ọlọ́run làjà. Ó ṣe àlàyé ìfẹ́-inú rẹ̀ láti ronúpìwàdà, ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀, ìkọjúsí rẹ̀, àti ìpinnu rẹ̀. Ìbálàjà rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run ni a fi ẹsẹ rẹ̀ múlẹ̀ nígbàtí ohùn kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, o´ wípe, “Énọ́sì, a dári àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ´, a ó sì bùkún ọ.” Énọ́sì da ipa tí ìrònúpìwàdà àti ìbálàjà ní lórí rẹ̀ mọ̀, nígbàtí ó wípé, “Èmi, Énọ́sì sì mọ̀ wípé Ọlọ́run kò lè purọ́; nítorí-èyí a ti gbá ẹ̀bi mi lọ.”
Bíbálàjà nmú kìí ṣe ìrànlọ́wọ́ wá látinú ìmọ̀lára ẹ̀bi nìkan ṣùgbọ́n bákannáà àláfíà ní àárín arawa àti pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ó nwo àwọn ìbáṣepọ̀ sàn, mú ọkàn rọ̀, àti fi okun fún jíjẹ́ ọmọẹ̀hìn wa, mímú ìgbẹ́kẹ̀lé níwájú Ọlọ́run pọ̀ si. Ohun tí ó nmú ìrètí àti ìgbẹ́kẹ̀lé nlá wá fún mi ni èso míràn ti bíbálàjà tí a ṣe àpèjúwe nípasẹ̀ Énọ́sì nígbàtí ó wípé, “Àti lẹ́hìn tí èmi, Énọ́sì, ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ìgbàgbọ́ mi bẹ̀rẹ̀ síí fi ẹsẹ̀múlẹ̀ nínú Olúwa.”
Nígbàtí mo jẹ́ ọmọdékùnrin, baba ìyá mi ní ọgbà ṣẹ́rrì nlá kan. Mo ní ànfàní láti ṣiṣẹ́ nínú ọgbà náà, púpọ̀ jùlọ ní àkokò ẹ̀rùn nígbà ìkórè ti àwọn ṣẹ́rrì. Gẹ́gẹ́bí ọ̀dọ́mọdékùnrin gan, mo rí pé ìnọ̀gà lílọ́wọ́sí mi ni fífúnni ní garawa nígbànáà kan kí a sì na igi sókè láti mú àwọn ṣẹ́rrì.
Kíkórè ti àwọn ṣẹ́rrì yípadà gidigidi nígbàtí Baba ìyá mi ra ẹ̀rọ kan tí à npè ní gbígbọ̀ ṣẹ́rrì. Ẹ̀rọ yí ìtì igi mú ó sì ngbọ̀ ọ́n, ó nmú kí àwọn ṣẹ́rrì náà jábọ́ kúrò lára igi sínú àwọ̀n tí a nlò láti gba àwọn ṣẹ́rrì nàa. Mo ṣe àkíyèsí pé nígbàtí ẹnití ó ngbọ̀n ọ́n bá bẹ̀rẹ̀ láti gbọ̀n igi náà, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ gbogbo àwọn ṣẹ́rrì náà ó jábọ́ kúrò lára igi ní àárín ìṣẹ́jú-akàn. Bákannáà mo ṣe àkíyèsí pé ko pọndandan bí a bá gbọn igi náà fún ìṣẹ́jú-akàn mẹ́wàá tàbí iṣẹ́jú kan kíkún, àwọn ṣẹ́rrì kan kò ní jábọ́. Wọ́n wà láìmira lóòótọ́.
Gbígbọn àwọn ṣẹ́rrì jáde lára igi ṣeéṣe nítorí ti ìdásílẹ̀ ti ẹmú. Hómónù yí nfa ẹ̀là ti ihò ní àárín ẹ̀ká ṣẹ́rrì náà àti igi láti di àìlágbára. Nítorínáà, ẹ̀ká igi ti ṣẹ́rrì pípọ́n máà njá kúrò ní ìrọ̀rùn kúrò lára igi nítorí ti ìsopọ̀ àìlágbára.
Nínú ìwé mímọ́, a kọ́ pé Ẹ̀ká Jéssè ni àfiwé fún Mèssíàh, Jésù Krístì, tí a sọtẹ́lẹ̀ láti wá látinú ìran ti Jéssè, baba Ọba Dáfídì. Gẹ́gẹ́bí ẹ̀mú ṣe nsọ ìsopọ̀ ẹ̀ká ṣẹ́rrì pípọ́n di àìlágbára, àìgbọ́ràn, iyèméjì, àti ẹ̀rù lè sọ ìsopọ̀ wa sí Ẹ̀ká Jéssè, tàbí Jésù Krístì di àìlágbára, ní fífi ààyè gbà wá láti di gbígbọ̀n ní ìrọ̀rùn kí a sì di yíyà kúrò ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Gẹ́gẹ́bí onígbàgbọ́ bí a ti lè jẹ́, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ní ìlòdì sí sísọ ìsopọ̀ wa sí Jésù Krístì di àìlágbára.
Nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú, àní àwọn onígbàgbọ́ ni a fún ní ìkìlọ̀: “Ṣùgbọ́n ìṣeéṣe wà pé ènìyàn lè ṣubú látinú oore ọ̀fẹ́ kí a sì kúrò ní ọ`dọ̀ Ọlọ́run alààyè .” Olúwa tẹ̀síwájú, “Bẹ́ẹ̀ni, … àní ẹ jẹ́ kí àwọn tí a yàsímímọ́ náà kíyèsára bákannáà.” Láti yẹra ní ṣíṣubú, Olúwa dámọ̀ràn, “Nítorínáà ẹ jẹ́ kí ìjọ kíyèsára kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbàgbogbo, kí wọ́n má baà bọ́ sínú ìdánwò.”
Ẹnìkan lè mú ipò jíjẹ́ gbígbọ̀n ní ìrọ̀rùn bá ohun tí ìwé mímọ́ ṣe àpèjúwe bíi pọ́n fún ìparun dọ́gba pẹ̀lú àbájáde tó nbọ̀ fún àwọn ìṣe. Gbólóhùn náà bákannáà ni a lè lò ní gbangbà síi láti fi ipò ìjẹra, ìbàjẹ́, tàbí dínkù tí ó nmú ìmọ̀ sínú ohunkan sí ìwólulẹ̀ tàbí ìdibàjẹ́ hàn.
Kíni pípọ́n yí rọ́pò? Ṣé ó túmọ̀ sí pé a lè nawọ́ dé àmì kan níbití a kò ti ní lè ṣe ìyípadà? Rárá, mo rò pé ó túmọ̀ sí pé a lè nawọ́ dé àmì kan ní àkokò níbití a kò ti ní ìfẹ́ láti yípadà. Ẹ̀rọ̀ sí dída pípọ́n fún ìparun ni láti ṣe àwọn ohun tí yíò fi okun fún ìsopọ̀ wa sí Jésù Krístì. Bí a ti dárúkọ, ìrònúpìwàdà darí Énọ́sì sí àmì ìgbàgbọ́ fífẹsẹ̀múlẹ̀. Okun wà nínú ìrònúpìwàdà—déédé, kánkán, àti ìrònúpìwàdà lémọ́lemọ́. Bí Ààrẹ Nelson ti kọ́ wa: “Kò sí ohunkóhun tó ntúnisílẹ̀ si, níyì si, tàbí ṣe pàtàkì sí ìlọsíwájú ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ju ìdojúkọ lórí ìrònúpìwàdà ojojúmọ́ wa, ti ṣe déédé sí.”
Ní àfikún sí ìrònúpìwàdà, wòlíì Jákọ́bù kọ́ni pé níní ìfura ọwọ́ Ọlọ́run nínú ayé wa, wíwá àti gbígba ìfihàn, àti fífetísílẹ̀ sí Ọlọ́run nígbàtí Ó bá nsọ̀rọ̀ gbogbo láti ràn wá lọ́wọ́ láti máṣe yẹsẹ̀. Jákọ́bù bákannáà kọ́ni, “Nítorí-èyí, àwa ṣe àwárí àwọn wòlíì, àwa sì ní ìfihàn tí ó pọ̀, àti ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀; nígbàtí àwa sì ti gba àwọn ẹ̀rí wọ̀nyí, a rí ìrètí gbà, ìgbàgbọ́ sì wà láìmì.” Ẹ fetísílẹ̀ sí kí ẹ sì ṣe ìṣe lórí àwọn ọ̀rọ̀ àti ìfipè ti àwọn wòlíì àti àpóstélì tí ó lè kún inú wa pẹ̀lú ìrètí, ìgbẹ́kẹ̀lé, àti okun, ní ìyọrísí kí ìgbàgbọ́ wa di àìyẹsẹ̀.
Mo ti kọ́ pé ìfẹ́-inú láti bá Ọlọ́run làjà gbọ́dọ̀ jẹ́ bíbárìn nípa ìfẹ́-inú láti ronúpìwàdà. Ríronúpìwàdà àti níní ìrírí àwọn ìbùkún Ètùtù Jésù Krístì ndarí sí ìgbàgbọ́ àìyẹsẹ̀. Ìgbàgbọ́ àìlèmì ndarí sí ìfẹ́-inú láti bá Ọlọ́run làjà nígbàgbogbo. Èyí ni ìyíká kan, tàbí àwòṣe, àtúnwí.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, mo pè yín láti bá Ọlọ́run làjà nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé dídá àti pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ nmú ìsopọ̀ wa sí Olùgbàlà le, nípa èyí kí a yẹrẹ fún dídi pípọ́n fún ìparun. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé bíbá Ọlọ́run làjà yí, nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì, ndarí sí ìgbàgbọ́ àìlèmì.
Mo pé Baba Ọ̀run fẹ́ràn ẹ̀yin àti èmí, Ó rán Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, láti jẹ́ Olùgbàlà, Olùràpadà, àti Olùlàjà nlá wa. Mo jẹ́rìí nípa Jésù Krístì mo sì ṣe bẹ́ẹ̀ ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.