Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Fífún Ara Wa Niyari
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwàá 2025


11:52

Fífún Ara Wa Niyari

Olúwa nìkan ni ó mọ àwọn ìdiwọ̀n àti agbára olúkúlùkù wa ní kíkún, àti nítorí ìyẹn, Òun nìkan ni ó lẹtọ ní kíkún láti ṣèdájọ́ iṣẹ́ wa.

Láìpẹ́ mo kà nípa ìrírí kan tí o kàn mí lára jinlẹ̀. Ó wáyé ní Ipa-ọ̀nà Olórí àti Asíwájú Pápá Orílẹ̀-èdè Ilẹ̀ Àmẹ́ríkà—ìdíje fún àwọn àgbàlagbà.

Ọ̀kan nínú àwọn olùkópa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ 1,500-mítà náà jẹ́ Orville Rogers ẹni ọgọ́ọ̀rún ọdún. Ònkọ̀wé kọ:

“Nígbàtí ìbọn olùbẹ̀rẹ̀ dún, àwọn aṣáré náà gbéra, pẹ̀lú Orville tí ó nfarabalẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ sí ààyè tí ó kẹ́hìn, níbití òhun nìkan wà fún gbogbo eré-ìje náà, tí ó nlọ láìyára. [Nígbàtí] olùsáré tí ó kẹ́hìn lẹ́hìn tí Orville parí, Orville tún ní ipele méjì àti ìdajì láti lọ. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àwọn olùwòra jókòó láìparuwo nwòó láìyára ṣe ọ̀nà rẹ̀ ní àyíká ipa-ọ̀nà—pátápátá, ní ìdákẹ́jẹ́, ati ni aibalẹ nikan.

“[Ṣùgbọ́n] nígbàtí ó bẹ̀rẹ̀ ipele rẹ̀ ìkẹhìn, ogunlọ́gọ̀ dìde sí ẹsẹ̀ wọn, wọ́n nyọ̀, wọ́n sì npàtẹ́wọ́. Nígbàtí ó fi máa gúnlẹ̀ nílẹ̀, àwọn ènìyàn ti nké ramúramù. Pẹ̀lú ìyànjú ìwúrí ti ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùwòran, Orville pe àwọn ìfipamọ́ agbára rẹ̀ tí ó kẹ́hìn. Ogunlọ́gọ̀ tú jáde pẹ̀lú ìdùnnú bí ó ti rékọjá ìlà ìparí àti pé àwọn olùdíje akẹgbẹ́ rẹ̀ gbàá mọ́ra. Orville fi ìrẹ̀lẹ̀ àti ìmoore juwọ́ sí ogunlọ́gọ̀ náà ó sì rìn kúrò ní ipa-ọ̀nà náà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ titun.”

Èyí jẹ́ eré ìje karun Orville, àti nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ míràn, ó ti tún gba ààyè tó kẹ́hìn. Àwọn díẹ̀ kan lè ti ní ìdánwò láti ṣèdájọ́ Orville, ní rírò pé kò tilẹ̀ yẹ kí ó díje pàápàá ní ọjọ́ orí rẹ̀—pé kò wà ní ipa-ọ̀nà náà nítorí ó jẹ́ kí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ rẹ̀ pẹ́ púpọ̀ fún gbogbo ènìyàn tí ó kù.

Ṣùgbọ́n bíótilẹ̀jẹ́pé ó nparí kẹ́hìn nígbàgbogbo, Orville gba àwọn ìwé-ìrántí àgbáyé marun ní ọjọ́ náà. Kò sẹ́nìkan tí ó nwo eré-ìje rẹ̀ tí yíò gbàgbọ́ pé ó ṣeéṣe, ṣùgbọ́n àwọn olùwòran tàbí àwọn olùdíje akẹgbẹ́ rẹ̀ kìí ṣe àwọn Onídàájọ́. Orville kò rú èyíkéyìí àwọn òfin, àwọn olóyè kò dín èyíkéyìí àwọn ìdiwọ̀n kù. Ó sì sáré ìje kannáà ó sì mú àwọn ìbèrè kannáà bí gbogbo àwọn olùdíje míràn. Ṣùgbọ́n ìwọ̀n ìṣòro rẹ̀—nínú ọ̀ràn yí ọjọ́-orí rẹ̀ àti agbára ti ara tí ó lópin—jẹ́ sísọ di mímọ́ nípa gbígbé e sí ìpín ọjọ́-orí ọgọ́ọ̀run ó lé. Àti nínú ìpín náà, ó gba àwọn ìwé-ìrántí àgbáyé marun.

Gẹ́gẹ́bí ó ṣe gba Orville ní ìgboyà nlá láti tẹ̀ síwájú ní ipa ọ̀nà náà nígbà kọ̀ọ̀kan, ó tún gba ìgboyà nlá fún àwọn kan lára àwọn arábìnrin wa àti àwọn arákùnrin wa láti tẹ̀ síwájú nínú pápá ìgbé ayé lójoojúmọ́, ní mímọ̀ pé a lè dá wọn lẹ́jọ́ lọ́nà tí kò tọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n nṣe ohun tí ó dára jùlọ tí wọ́n lè ṣe ní ìdojúkọ àwọn ìdààmú láti tẹ̀lé Olùgbàlà àti láti bọlá fún àwọn májẹ̀mú wọn pẹ̀lú Rẹ̀.

Ibi yòówù ká máa gbé nínú ayé, láìka ọjọ́ orí wa sí, ó jẹ́ ìpìlẹ̀ ìnílò ẹ̀dá fún gbogbo wa láti nímọ̀lára èro orí wíwà pẹ̀lú, láti nímọ̀lára pé a jẹ́ fífẹ́ àti nínílò àti pé ìgbésí ayé wa ní èrèdí àti ìtumọ̀, láìka àwọn ipò tàbí ààlà wa sí.

Ní ipele tí ó kẹ́hìn ti eré-ìje náà, ogunlọ́gọ̀ náà fún Orville niyari, ní fífún un ní agbára láti tẹ̀síwájú. Kò ṣe pàtàkì pé ó parí kẹ́hìn. Fún àwọn olùkópa àti ogunlọ́gọ̀ èrò, èyí jẹ́ díẹ̀ si ju ìdíje lọ. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà, èyí jẹ́ àpẹrẹ rírẹwà ti ìfẹ́ Olùgbàlà ní ìṣe. Nígbàtí Orville parí, gbogbo wọn yọ̀ papọ̀.

Gẹ́gẹ́bí Olórí Aṣíwájú, àwọn ìpéjọ àti àwọn ẹbí le jẹ́ ibi tí a ti nkó ara wa jọ tí a ti nṣe ìyárí arawa—àwọn àwùjọ májẹ̀mú tó njẹ́ fífún lókun nípasẹ̀ ìfẹ́ Krístì fún ara wa—ríràn arawa lọ́wọ́ láti borí ìpèníjà èyíkéyìí tí a bá dojú kọ, fífún ara wa ní okun àti ìyànjú láìṣèdájọ́ ara wa. A nílò ara wa. Agbára àtọ̀runwá nwa látara ìṣọ̀kan, èyí sì nídì tí ète Sátánì fi jẹ́ láti yàwá.

Láìyọsíre, fún díẹ̀ nínú wa, lílọ sílé ìjọsìn lè le nígbà míràn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èrèdí. Ó lè jẹ́ ẹnìkan tó ntiraka pẹ̀lú àwọn ìbèèrè ìgbàgbọ́ tàbí ẹníkan tí ó ní àníyàn ìbákẹ́gbẹ́ tàbí ìrẹ̀wẹ̀sì. Ó lè jẹ́ ẹnìkan láti orílẹ̀-èdè míràn tàbí ẹ̀yà tàbí ẹnìkan tí ó ní onírúurú ìrírí ìgbésí ayé tàbí ọ̀nà tí a nrí àwọn nkan tí ó lè dàbíi pé wọn kò wà sí mímọ náà. Ó tilẹ̀ lè jẹ́ àìlèsùn àti àwọn òbí tí wọ́n ti nínà ti ẹ̀dùn ti àwọn ọmọdé àti àwọn ọ̀dọ́mọdé tàbí ẹnìkan tí kò tíì ṣègbéyàwó nínú ìjọ tó kún fún tọkọtaya àti àwọn ẹbí. Ó lè jẹ́ ẹnìkan tí ó ní ìgboyà láti padà lẹ́hìn ọ̀pọ̀ ọdún tí kò fi bẹ́ẹ̀ sí tàbí ẹnìkan tí ó nímọ̀lára ìdààmú pé wọn kì í díwọ̀n àti pé wọn kò lè wà pẹ̀lú.

Ààrẹ Russell M. Nelson ti wípé: “Bí tọkọtaya kan nínú wọ́ọ̀dù yín bá kọra wọn sílẹ̀, tàbí tí ọ̀dọ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere kan tètè padà sílé, tàbí ọ̀dọ́langba kan ṣiyèméjì ẹ̀rí rẹ̀, wọn kò nílò ìdájọ́ yín. Wọ́n nílò láti ní ìrírí ìfẹ́ àìlábàwọ́n ti Jésù Krístì tó hàn nínú àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe yín.”

Ìrírí wa nínú ilé ìjọsìn ní láti pèsè àwọn àsopọ̀ pàtàkì pẹ̀lú Olúwa àti pẹ̀lú ara wa tí a nílò púpọ̀ fún àlàáfíà ti ẹ̀mí àti ti ẹ̀dùn ọkàn. Ìwà nínú àwọn májẹ̀mú tí a ṣe pẹ̀lú Ọlọ́run, bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìrìbọmi, jẹ́ ojúṣe wa láti fẹ́ràn àti láti ṣàbojútó ara wa gẹ́gẹ́bí àwọn ọmọ ẹbí Ọlọ́run, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Krístì, kìí ṣe láti ṣàyẹ̀wò àtòkọ nìkan nínú àwọn nkan láti ṣe.

Ìfẹ́ àti àbójútó bíi ti Krístì ga ó sì jẹ́ mímọ́ jùlọ. Ìfẹ́ àìlábàwọ́n ti Krístì jẹ́ ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́. Gẹ́gẹ́bí Ààrẹ Nelson ti kọ́ni, “Ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ sún wa ‘láti ru ẹrù ara wa’ [Mosiah 18:8] dípò gbígbé àwọn àjàgà orí ara wa.”

Olùgbàlà wípé, “Nipa èyí ni gbogbo ènìyàn yíò mọ̀ pé ẹ jẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn mi bí ẹ bá ní ìfẹ́ sí ara yín.” Ààrẹ Nelson sì ṣe àfikún pé: “Ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ ni kókó ìwà ti àtẹ̀lé tòótọ́ Jésù Krístì.” Ọ̀rọ̀ Olùgbàlà hàn kedere pé: Àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ tòótọ́ ngbéga, nkọ́, ngbésókè, ngbàní níyànjú, nyílọ́kànpadà, wọ́n sì nmísíni. … ”Bí a ṣe nsọ́rọ́ sí àti nípa àwọn míràn … ṣe pàtàkì gan.”

Ìkọ́ni Olùgbàlà lórí èyí rọrùn púpọ̀. Ó ti wà ní àkópọ̀ nínú Òfin Wúrà: Ṣe sí àwọn ẹlòmíràn bí ìwọ ṣe fẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn ṣe sí ọ. Fi ara rẹ sí ipò ẹni náà kí o sì máa ṣe sí wọn bí ìwọ yíò ṣe fẹ́ kí a ṣe sí ọ bí o bá wà nínú ipò wọn.

Bí Kristi ṣe nhùwà sí àwọn ẹlòmíràn lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ ju àwọn ẹbí àti ìjọ wa lọ. Ó pẹ̀lú àwọn arábìnrin àti arákùnrin wa tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́sìn míràn tàbí tí wọn kò ní ẹ̀sìn rárá. Ó pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin láti orílẹ̀-èdè míràn àtàwọn àṣà bákanáà. Gbogbo wa jẹ́ ara ẹbí Ọlọ́run, Ó sì fẹ́ràn gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀. Ó nfẹ́ kí àwọn ọmọ Rẹ̀ fẹ́ràn Rẹ̀ àti ara wọn.

Ìgbé-ayé Olùgbàlà jẹ́ àpẹrẹ onífẹ̀ẹ́, kíkójọ, àti gbígbéga àní àwọn tí àwùjọ ti dálẹ́jọ́ bíi ìsánsá àti aláìmọ́. Tirẹ̀ ni àpẹrẹ tí a paláṣe fún wa láti tẹ̀lé. A wà nihin láti mú ìwà bíi Krístì dàgbàsókè àti níkẹhìn kí á dàbí Olùgbàlà. Tirẹ̀ kìí ṣe ìhìnrere àwọn àtòkọ; ó jẹ́ ìhìnrere dídà—dídà bíi Ó ṣe rí àti fífẹ́ràn bíi Rẹ̀. Ó fẹ́ kí á di ènìyàn Síónì.

Nígbàtí mo ti lé lẹ́ni ogún ọdún, mo la àkókò ìrẹ̀wẹ̀sì tó jinlẹ̀ kọjá, nígbà náà, ó dà bí ẹni pé òtítọ́ náà pé Ọlọ́run wà lọ lójijì. Èmi ò lè ṣàlàyé ní kíkún ìmọ̀lára náà ju láti sọ pé mo nímọ̀lára sísọnù pátápátá. Láti ìgbà tí mo ti jẹ́ ọmọdé, mo ti mọ̀ nígbà gbogbo pé Baba mi Ọ̀run wà níbẹ̀ àti pé mo lè bá a sọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n lákòókò náà, mi ò mọ̀ mọ́ bóyá Ọlọ́run wà. Èmi ò ní irú ìrírí náà rí nílé ayé mi, ó sì rí bí ẹnipé gbogbo ìpìlẹ̀ mi nṣubú.

Nítorí èyí, ó ṣòro fún mi láti lọ sí ilé ìjọsìn. Mo lọ, ṣùgbọ́n ó jẹ́ lápá kan nítorí pé ẹ̀rù nbà mí pé kí wọ́n má pè mí ní “aíṣèdéédé” tàbí “aláìlóòótọ́,” ẹ̀rù sì nbà mí láti di iṣẹ́ tí a yàn fún ẹnìkan. Ohun tí mo nílò gan-an láàárín àkokò náà ni pé kí nní ojúlówó ìfẹ́, òye, àti ìtìlẹ́hìn látọ̀dọ̀ àwọn tó yí mi ká, kì í ṣe ìdájọ́.

Díẹ̀ nínú àwọn àronúsí tí mo bẹ̀rù pé àwọn ènìyàn yíò ṣe nípa mi, èmi fúnrami ti ṣe sí àwọn míràn nígbàtí wọ́n kò lọ sí ilé ìjọsìn déédé. Ìrírí araẹni onírora náà kọ́ mi ní àwọn ẹ̀kọ́ ṣíṣeyebíye kan nípa ìdí tí a ti paláṣẹ láti máṣe da ara yín lẹ́jọ́ lọ́nà àìṣòdodo.

Njẹ́ àwọn kan wà laarin wa tí ó njìyà ní ìpalọ́lọ́, tí ó bẹ̀rù fún àwọn míràn láti mọ àwọn ìjàkadì fífarapamọ́ wọn nítorí wọn kò mọ ohun tí ìṣesí yíò jẹ́?

Olúwa nìkanló mọ ipele ìnira gan tí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa fi sáré ìje ìgbé ayé wa—àwọn ẹrù ìnira, ìpèníjà, àti àwọn ìdènà tí a ndojúkọ tí a kìí sábà rí pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Òun nìkan ni ó lóye ní kíkún àwọn ọgbẹ́ ìyípadà-ayé àti ìbàlọ́kànjẹ́ tí díẹ̀ nínú wa lè ti ní ìrírí ní ìṣaájú tí ó ṣì nkàn wá lọ́wọ́lọ́wọ́.

Nígbàgbogbo, àwa pàápàá nṣèdájọ́ arawa ní líle, rírò pé ó yẹ kí a wá ṣíwájú síi ní ipa-ọ̀nà. Olúwa nìkan ni ó mọ àwọn ìdiwọ̀n àti agbára olúkúlùkù wa ní kíkún, àti nítorí èyí, Òun nìkan ni ó lẹtọ ní kíkún láti ṣèdájọ́ iṣẹ́ wa.

Ẹ̀yin arábìnrin àti arákùnrin, ẹ jẹ́ kí a dà bí àwọn olùwòran wọnnì nínú ìtàn náà kí a sì mú ara wa yọ̀ nínú ìrìn àjò ọmọ ẹ̀hìn wa láìka ipò wa sí! Ìyẹn kò nílò wa láti rú àwọn òfin tàbí dín àwọn ìṣedédé kù. Ní tòótọ́, ó jẹ́ òfin nlá kejì—láti fẹ́ràn ọmọlàkejì wa gẹ́gẹ́bí ara wa. Àti bí Olùgbàlà ti wípé, “Níwọ̀n bí ẹyin bá ti ṣé sí ọ̀kan tó kéré jù lára wọ̀nyí … , ẹyin ti ṣe é sí mi,” fún rere tàbí búburú. Ó sì tún ti sọ fún wa pé, “Bí ẹ̀yin kìí bá ṣe ọ̀kan, ẹ kìí ṣe tèmi.”

Àwọn àkokò yíò wá nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìgbé ayé wa nígbàtí a yíò jẹ́ ẹni tí ó nílò ìrànlọ́wọ́ àti ìyànjú. Jẹ́ kí a faramọ báyìí láti ṣe ìyẹn nígbàgbogbo fún ara wa. Bí a ṣe nṣe bẹ́ẹ̀, a máa mú ìṣọ̀kan títóbi pọ̀ síi, a ó sì dẹrọ àyè kan fún Olùgbàlà láti ṣe iṣẹ́ mímọ́ Rẹ̀ ti ìwòsàn àti yíyí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa padà.

Sí àwọn tí ó lè lérò pé ẹ ti lọ sẹ́hìn nínú eré-ìje ìgbésí ayé yí, ìrìn-àjò ayé ikú yí, jọ̀wọ́ tẹ̀síwájú. Olùgbàlà nìkan ni ó lè dájọ́ ní kíkún ibi tí ó yẹ kí ó wà ní ààyè yí, Ó sì ní àànù àti òdodo. Òun ni Onídajọ́ Nlá ti eré-ìje ti ìyè, àti ẹni náà tí ó lóye ní kíkún ipele ìṣòro pẹ̀lú èyítí ẹ nsáré tàbí nrìn tàbí nyípadà. Yíò ṣàkọọ́lẹ̀ ìdiwọ̀n yín, agbára yín, ìrírí ìgbésí ayé yín, àti àwọn ẹrù ìkọ̀kọ̀ tí o rù, àti àwọn ìfẹ́-inú ọkàn yín. lè gba ìwé ìrántí alápẹrẹ nítòótọ́ bákanáà. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ máṣe sọ ìrètí nù. Ẹ jọ̀wọ́ tẹsiwaju! Ẹ jọ̀wọ́ dúró! Ẹ pẹ̀lú! Olúwa nílò yín, àti pé a nílò yín!

Níbikíbi tí ó bá ngbé nínú ayé, bí ó ti wù kí ó jìnà tó, jọ̀wọ́ rántí nígbàgbogbo pé Baba yín tó nbẹ ní Ọ̀run àti Olùgbàlà yín mọ̀ yín pátápátá Ó sì fẹ́ràn yín ní pípé. Ẹ̀yin jẹ́ gbígbàgbé sí Wọn. Wọ́n fẹ́ mú yín délé.

Ẹ gbójú yín sí Olùgbàlà. Òun ni ọ̀pá irin yín. Máṣe fi Í sílẹ̀. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Ó wà láàyè àti pé ẹ gbẹ́kẹ̀lé E. Mo tún jẹ́ ẹ̀rí pé Ó nfún yín niyari lọ.

Njẹ́ kí gbogbo wa tẹ̀lé àpẹrẹ Olùgbàlà àti kí á sì fún arawa niyari ni àdúrà mi ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Jeffrey C. Strong, ìkọ̀wé araẹni; tí a lò nípa àṣẹ.

  2. Ọ̀kan lára àwọn ààyò àjọ ààrẹ wa ti jẹ́ fún àwọn arábìnrin wa láti nímọ̀lára èro orí wíwà pẹ̀lú ní ilé ìjọsìn, àti ní pàtàkì nínú Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́. Mo ti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìgbà láti ka àwọn lẹ́tà àti láti gbọ́ àwọn ìrírí tí ó ti fa ìbànújẹ́ fún mi gidigidi.

  3. Wo 1 Kọ́ríntì 12:26.

  4. Wo Henry B. Eyring, “Ọkàn Wa Ní Ìrẹ́pọ̀ Bí Ọ̀kan,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2008, 68–71; wo bákannáà Ulisses Soares, “Ọ̀kan nínú Krístì,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2018, 37–39; “Ọ̀kan nínú Krístì” (fídíò), Ibi-Ìkàwé Ìhìnrere.

  5. Wo 3 Néfì 11:29.

  6. Russell M. Nelson, “A Nílò Àwọn Olùlàjà,” Làìhónà, Oṣù karun 2023, 100. Nínú ọ̀rọ̀ kannáà, ó wí pé “àríyànjiyàn máa nlé Ẹ̀mí lọ—ní gbogbo ìgbà” (ojú ewé 100). Èmi yíò ṣàfikún pé àwọn ìrònú onidajọ nípa àwọn míràn lè lé Ẹ̀mí lọ pẹ̀lú. Nígbàti a bá wo àwọn míràn pẹ̀lú èrò olóminú, ìyẹn jẹ́ ẹ̀rí ìgbéraga, àti pé Ààrẹ Henry B. Eyring ti wípé “ìgbéraga ni ọ̀tá nla ìṣọ̀kan” (“Àwọn Ọkàn Wa Sopọ̀ bí Ọ̀kan,” 70).

  7. Wo J. Anette Dennis, ní “Wá gbé àyè Rẹ bí Àwọn Obìnrin Májẹ̀mú” (àdírẹ́ẹ̀sì tí a fifúnni ní Apejọ Àwọn Obìnrin Yunifásítì Brigham Young, Oṣù karun 1, 2024), Ibi-ìkàwé Ìhìnrere; bákannáà wo Mòsíàh 18:8–10.

  8. Wo 1 Kọ́ríntì 12:14–26.

  9. Wo Mórónì 7:47.

  10. Wo Russell M. Nelson, “A Nílò Àwọn Onílàjà,” 101; àfikún àtẹnumọ́.

  11. Jòhánnù 13:35; àfikún àtẹnumọ́.

  12. Wo Russell M. Nelson, “A Nílò Àwọn Onílàjà,” 100, 99.

  13. Wo Máttéù 7:12.

  14. Bí a ṣe ntẹ̀lé Olùgbàlà tí a sì nfẹ́ láti dàbí Rẹ̀, a ó gbìyànjú láti rí gbogbo ènìyàn ní ọ̀nà tí Ó fi nwo wọn, àti bí a ṣe nbá a lọ láti gbàdúrà fún ẹ̀bùn ìfẹ́, ìmọ̀lára òtítọ́ inú ti ìfẹ́ àti ìtọ́jú lè dàgbà nínú ọkàn wa níkẹhìn. A yíò ṣèdàgbàsókè ìfẹ́ inú láti “kọ, gbéga, gbàníyànjú, yílọ́kànpadà, àti mísí” àti àwọn míràn, kìí ṣe látinú ojúṣe ṣùgbọ́n nítorí a ndà bí Olùgbàlà wa díẹ̀díẹ̀ (Russell M. Nelson, “A Nílò àwọn Onílàjà,” 100). Iṣẹ́ ìránṣẹ́ bíi ti Krístì fún àwọn ẹlòmíràn yíò di irú ẹni tí a jẹ́, kìí ṣe ohun tí a nṣe.

  15. Wo Mòsíàh 23:15.

  16. Wo, fún àpẹẹrẹ, Máttéù 9:10–13; Mákù 1:40–42; Lúkù 8:43–48; 14:13–14; Jòhánnù 4:7–26; 5:2–9; 8:3–11.

  17. Wo 3 Néfì 27:27; bákannáà wo Robert C. Gay, “Gbígbé Orúkọ Jésù Krístì Lé Arawa,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2018, 97–100.

  18. “Ojútùú àìyẹ̀ kanṣoṣo sí àwọn ìyàtọ̀ tí ó pín wa ní kí gbogbo wa láti tẹ̀lé àwọn ìkọ́ni Olùgbàlà wa àti láti di pàápàá bí Òun ti jẹ́” (Dallin H. Oaks, in Joel Randall, “Títẹ̀lé Krístì ‘Ìfarajì Títẹ̀síwájú àti Ọ̀nà Ìgbé-ayé,’ Ààrẹ Oaks nkọ́ àwọn Ènìyàn Mímọ́ European láti Belgium,” Àwọn Ìròhìn Ìjọ, Oṣù kéje 14, 2025).

  19. Dallin H. Oaks, “Ìpèníjà láti Di Ẹni,” Làìhónà, Oṣù Kínní 2001, 40-43.

  20. Wo Jòhánnù 13:34.

  21. “Ìpè clarion sí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ti Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ni láti làkàkà láti jẹ́ ènìyàn Síónì tí wọ́n ní ọkàn kan àti inú kan tí wọ́n sì ngbé nínú òdodo” (Quentin L. Cook, “Ọkàn NSopọ̀ Ní Ìṣọ̀kan àti Òdodo,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2020, 21).

  22. Wo J. Anette Dennis, “Ìdí tí Mo Fi Yàn láti Dúró” (àdírẹ́sì tí a fúnni ní Ìpàdé Àpapọ̀ Àwọn Obìnrin ti Yunifásítì Brigham Young, Oṣù karun 2, 2024), Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.

  23. Wo Ìtumọ̀ Joseph Smith Máttéù 7:1, 2 (ní Máttéù 7:1, footnote a); Álmà 41:14.

  24. Wo J. Anette Dennis, “Àjàgà Rẹ̀ Rọrùn Ẹrù Rẹ̀ sì Fúyẹ́,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2022, 80–81.

  25. Wo Álmà 7:11–12.

  26. Wo Máttéù 22:36–40.

  27. Máttéù 25:40.

  28. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 38:27.

  29. Wo Orin Dáfídì 145: 8–9; Éfésù 2: 4–5.

  30. Wo Tamara W. Runia, “Ìrònúpìwàdà Rẹ Kò Di Ẹrù Fún Jésù Krístì; Ó Mú Ayọ̀ Rẹ̀ Tàn,” Lìàhónà, Oṣù Karun 2025, 91.

  31. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 137:9.

  32. Wo Rómù 8:38–39.

  33. Wo Patrick Kearon, “Èrò-Inú Ọlọ́run Ni láti Mú Yín Wá Sílé,” Làìhónà, Oṣù Karun 2024, 87–89.

  34. Wo Jóhánnù 1, ìpín àkòrí àti ẹsẹ 1; 1 Néfì 11:24–25.

  35. Wo Jeffrey R. Holland, “Ní Ọ̀la Olúwa Yóò Ṣe Àwọn Ìyanu Láarín Yín,” LàìhónàOṣù karun 2016, 127.