Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ẹ Kọjúsí Ọlọ́run kí ẹ sì Yè
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwàá 2025


14:13

Ẹ Kojúsí Ọlọ́run kí ẹ sì Yè

Ó jẹ́ nípa kíkọjúsí Ọlọ́run nìkan ni olúkúlùkù, ẹbí, àní orílẹ̀-èdè fi lè gbilẹ̀.

Ní Oṣù Kẹfà ọdún yí, ìjàmbá búburú kan ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Lesotho ní Gúsù Áfríkà. Ọkọ̀ èrò kékeré tí ó gbé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ọgún ti Ẹ̀ka Ìjọ Maputsoe àti àwọn méje lára aṣaájú wọn nlọ sí olú ìlú, Maseru, fún àkójọpọ̀ àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin láti ẹ̀kùn wọn. Bí wọn ṣe nrin ìrìnàjò ní òpópónà ìlà-méjì ní òwúrọ̀ wákàtí Ọjọ́ Kọkànlélógún Oṣù Kẹfà, ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́ kan tí ó nbọ̀ ní òdì kejì, ní ìgbìyànjú láti sọdá ọkọ̀ míràn, wá sínú ìlà tí ọkọ̀ akérò náà wà. Kò sí ààyè rárá tàbí àkokò láti yẹra fún ìforí-gbárí, àti pé ní ìṣẹ́ju-akàn àwọn ọkọ̀ náà gbá ara wọn, yí kúrò lórí ọ̀nà, wọ́n sì gbiná.

Nínú gbogbo rẹ̀, ènìyàn máàrúndínlógún kú nínú ìjàmbá náà, tí àwọn ọ̀dọ́mọbìrin mẹ́fà wà nínú rẹ̀, àwọn aṣaájú Ọ̀dọ́mọbìnrin méjì, àti ààrẹ ẹ̀ka Maputsoe àti ìyàwó rẹ̀. Àwọn yíyè, ọmọ ẹbí, àti ọ̀rẹ́ ti fi sàkání ti àwọn ẹ̀dùn ọkàn hàn, tí ó ní àwọn àkokò irinú, ìrẹ̀wẹ̀sì, àní àti ẹbi nínú. Pẹ̀lú àwọn ìmọ̀lára wọ̀nyí àti àìdáhùn àwọn ìbèèrè, wọ́n ti tu ara wọn nínú wọ́n sì yípadà sí Ọlọ́run nínú orin mímọ́, ìwé mímọ́, àti àdúrà, níbití wọ́n ti rí ìtùnú. Ẹni ọdún–mẹ́tàdínlógún yíyè Setso’ana Selebeli jẹ́ ẹ̀rí, “Jésù Krístì fẹ́ràn wa ó sì wà pẹ̀lú wa, àní bíótilẹ̀jẹ́pé a ní ìpalára ọkàn.”

Àwọn ọmọ ìjọ ní Lesotho

Ọ̀dọ́mọbìnrin kan àti aṣaájú kan tí wọ́n wà ní ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú ara jíjó ṣe àṣàrò Ìwé ti Mọ́mọ́nì papọ̀. Ọ̀kan wípé, “Láìpẹ́, a ti nkàwé nínú Mórónì, Mórónì sì wí ohun tí mo ti nní ìmọ̀lára rẹ̀ ní gẹ́gẹ́. … Nígbàtí ó sọ̀rọ̀, ó dàbí ó nwípé, ‘O níláti kọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nítorí a kọ wọ́n fún o láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti la èyí kọjá.’”

Ìsìnkú ní Lesotho

Níbi ìsìn ìsìnkú àpapọ̀ àwọn tó ṣègbé, Àádọ́rin Agbègbè Alàgbà Siyabonga Mkhize dámọ̀ràn, “Gbogbo wa níláti yípadà sí Olúwa ní àkokò yí kí a sì ní kí Ó tu ọkàn wa nínú … láti dẹ ìrora tí à nní ìmọ̀lára rẹ̀ lára.” Ààrẹ àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin láti òdìkejì ẹ̀ka Leribe, Mampho Makura, rọni, “Ẹ yípadà sí Olúwa, kí ẹ sì wá okun láti tẹ́wọ́gba ìfẹ́ Rẹ̀. Jésù Krístì ni ‘olùdásílẹ̀ àti aláṣetán ìgbàgbọ́ wa’ [Hébérù 12:2]. Ẹ máṣe gbojú kúrò ṣùgbọ́n ẹ kọ́júsí I.”

Ẹ Wò Ó. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe ìró-dídún àmọ̀ràn ti Álmà sí ọmọ rẹ̀ Hẹ́lámánì: “Ẹ ri pé ẹ wo Ọlọ́run kí ẹ sì Yè.” Álmà sọ̀ nípa i`rírí Léhì a`ti a`wọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú Làìhónà bí irú kan: “Ó rọrùn láti fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ Krístì, èyítí yíò tọ́ka ọ̀nà tí ó gún sí àlãfíà pípé ayérayé sí ọ, bí o ṣe rí fún àwọn bàbá wa láti fetísílẹ̀ sí atọ́nisọ́nà yìi, èyítí yíò tọ́ka ọ̀nà tí ó gún sí ilẹ̀ ìlérí náà sí wọn.” Álmà wípé, “Bí wọ́n yíò bá wòó wọ́n lè yè. … Àti pé bí àwa … bá wòó àwa le yè títíláé.”

Ní ọ̀ràn míràn, Álmà sọ nípa ẹjo idẹ tí a gbé sókè láti ọwọ́ Mósè nígbàtí a pọ́n àwọn Ísráẹ́lì àtijọ́ lójú nípasẹ̀ ejò amúbíiná. Olúwa wí fún Mósè láti rọ èrè ejò kan kí ó sì fií sórí ọ̀págun kan, pẹ̀lú ìlérí “pé olúkúlùkù ẹni tí ejò bá bùṣán, nígbàtí ó bá wòó, yíò yè.” Álmà ṣe àlàyé pé èrè idẹ náà ni irú tàbí àmì Krístì tí a ó gbé sókè lórí àgbélèbú. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ kọjúsi wọ́n sì yè, ṣùgbọ́n àwọn míràn, ní àwọn ọ̀rọ̀ Álmà, “ti ṣe ọkàn wọn lè” tí wọn kò lè kọjúsíi jẹ́jẹ́ kí wọ́n yè.

Álmà bèèrè:

“Bí ẹ̀yin bá lè rí ìwòsàn nípa fífi ojú nyín wò ṣá kí ẹ̀yin lè rí ìwòsàn, njẹ́ ẹ̀yin kò ní wõ ní kíákíá, tàbí ó tẹ́ẹ nyín lọ́rùn láti sé ọkàn nyín le nínú àìgbàgbọ́, kí ẹ sì ya ọ̀lẹ, kí ẹ sì má lè fi ojú nyín wòó, tí ẹ̀yin ó sì parun?”

“ … Nígbànáà ẹ gbé ojú yín ká kí ẹ sì bẹ̀rẹ̀sí gbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run, pé ó nbọ̀wá láti ra àwọn ènìyàn rẹ padà, àti pé yíò jìyà yíò sì kú láti ṣe ètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn; àti pé yíò tún jínde kúrò nínú ipò òkú, èyítí yíò mú àjĩnde náà ṣẹ, pé gbogbo ènìyàn yíò dúró níwájú rẹ̀, láti jẹ́ dídá lẹ́jọ́ ní ọjọ́ ìkẹhìn àti ti ìdájọ́, ní ìbámu sí àwọn iṣẹ́ wọn.”

Bẹ́ẹ̀ni, àmọ̀ràn náà “ẹ kọjúsí Ọlọ́run kí ẹ sì yè” ní ìtumọ̀ fún wa kìí ṣe ní ayé àìlópin nìkàn, ṣùgbọ́n bákannáà ó nmú gbogbo ìyàtọ̀ wá nínú ìhùwàsí àti ìwà ìgbé ayé ikú wa. Ẹ rántí àwọn ọ̀rọ̀ ti ọ̀dọ́ Arábìnrin Selebeli ní Lesotho tí a ti dárúkọ̀ tẹ́lẹ̀—“Jésù Krístì fẹ́ràn wa ó sì wà pẹ̀lú wa, àní bíótilẹ̀jẹ́pé ọkàn wa ní ìpalára.”

Ó wà nínú àdánidá ayé ìṣubú—níbití èṣù ti njà ràin àti níbití gbogbo ènìyàn ti jẹ́ àìpé—pé àwọn ìjákulẹ̀ àti ṣíṣẹni, ìjìyà àti ìkorò, àdánù àti òfò, inúnibíni àti àìní-ìdáláre yíò wà. Ó jẹ́ nípa kíkọjúsí Ọlọ́run nìkan ni olúkúlùkù, ẹbí, àní orílẹ̀-èdè fi lè gbilẹ̀. Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni, ”Nítorípé Olùgbàlà, nípasẹ̀ Ètùtù àìlópin Rẹ̀, ra ẹnìkọ̀ọ̀kan wa padà kúrò nínú àìlera, àṣìṣe, àti ẹ̀ṣẹ̀, àti nítorípé Ó ní ìrírí gbogbo ìrora, ìdàmú, àti ẹrù tí ẹ ti ní rí [wo Álmà 7:11–13], nígbànáà bí ẹ ṣe nronúpìwàdà ní tòótọ́ tí ẹ sì nwá ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀, ẹ lè dìde kọjá ewu ayé yí nísisìyí.”

Kò sí ìlérí tí a sọ léraléra síi nígbàkugbà nínú ìwé mímọ́ Ìwé ti Mọ́mọ́nì ju èyí: “Níwọ̀n bí ẹ̀yin bá pa àwọn òfin mi mọ́ ẹ̀yin yíò ṣe rere ní ilẹ̀ náà; ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ̀yin kò bá pa àwọn òfin mi mọ́ a ó gé yín kúrò níwájú mi.” Ìgbé ìrírí àwọn ènìyàn Ìwé ti Mọ́mọ́nì ní àwọn sẹ̀ntúrì ṣe àpèjúwe òtítọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. “Ṣe rere” túmọ̀ sí gbígbádùn ìtọ́sọ́nà àti àwọn ìbùkún tọ̀run nínú ayé wa. “Ṣe rere” túmọ̀ sí ṣíṣe àṣeyege àwọn ipele ti wíwà-dáadáa ọrọ̀-ajé tí ó nmú wọn lè ṣe ìgbeyàwó, tọ́ ẹbí, àti láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àìní àwọn ẹlòmíràn. “Ṣíṣe rere” pẹ̀lú okun láti dìde kọjá ìnira àti àdánwò. Nípasẹ̀ Olúwa, “gbogbo ohun [n] ṣiṣẹ́ papọ̀ fún ire [wọn],” tú wọn ṣe, àti láti mú ìbáṣepọ̀ wọn pẹ̀lú Rẹ̀ jìnlẹ̀ síi.

Álmà ṣe àlàyé pé wíwo Ọlọ́run ni láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, kígbe sí I lemọ́lemọ́ fún àtìlẹhìn Rẹ̀, dàmọ̀ràn pẹ̀lú Rẹ̀ nínú gbogbo ìṣe yín, àti jíjẹ́ kí ọkàn yín kún fún ọpẹ́ sí I ní ọ̀sán àti òru. Àwọn òfin Ọlọ́run àti àmọ̀ràn ni a rí nínú àwọn ìwé mímọ́ àti ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀. Àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ àti èrò tí a gbé jáde nínú “Ẹbí Náà: Ìkéde Kan Sí Àgbáyé” ní kókó àpẹrẹ kan. Òmíràn ni ìtọ́sọ́nà tí a rí nínú àkópọ̀ ìwé náà Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́. Àkórí àwọn Ọ̀dọ́mọkùnrin àti Ọ̀dọ́mọbìnrin fún ọdún yí “Wo Ọ̀dọ̀ Krístì,” tí a mú látinúìdarí ìtuninínú Olúwa sí Joseph Smith àti Oliver Cowdery: “Wo ọ̀dọ̀ mi ní gbogbo èrò; dmáṣe ṣiyèméjì, máṣe bẹ̀rù.” Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ sọ̀rọ̀ sí onírurú púpọ̀ jùlọ àwọn òfin Ọlọ́run kánmọ́kánmọ́ àti òṣùwọ̀n àti ìkọ́ni bí a ó ṣe wo Olúwa ní ṣíṣe àwọn ìpinnu rere. Ó jẹ́ ìtọ́sọ́nà kìí ṣe fún àwọn ọ̀dọ̀ nìkan ṣùgbọ́n fún gbogbo wa.

Gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ pàtàkì kan, Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ ní ìtọ́sọ́nà pàtàkì nínú orí tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Ara Yín jẹ́ Mímọ́.” Ó kọ́ni, “Ẹ tọ́jú ara yín—àti ara àwọn ẹlòmíràn—pẹ̀lú ọ̀wọ̀. Bí ẹ ti nṣe àwọn ìpinnu nípa aṣọ, ẹ̀yà-irun, àti ìrísí, ẹ bèèrè lọ́wọ́ ara yín, ‘Njẹ́ èmi nbu-ọlá fún ara mi bí ẹ̀bùn mímọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run?’”

Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ ní títẹ̀síwájú sọ pé, “Ẹ pa ìbaralòpọ̀ àti ìmọ̀lára bíbáralòpọ̀ ní mímọ́. A kò gbọdọ̀ mú kí ó jẹ́ ẹ̀kọ́ àpárá tàbí ìdánilárayá. Ní òde ìgbeyàwó ní àárín ọkùnrin àti obìnrin kan, ó jẹ́ àṣìṣe láti fọwọ́kan ibi-ìkọ̀kọ̀, apákan mímọ́ ti ara ẹlòmíràn àní bí ó bá wọṣọ. Nínú àwọn yíyàn yín nípa ohun tí ẹ̀ nṣe, wò, ka, fetísílẹ̀ sí ronú nípa, lẹ̀, tàbí tẹ̀kọ, ẹ yẹra fún ohunkóhun tí ó nmọ̀ọ́mọ̀ mú ìdìde àwọn ẹ̀dùn-ọkàn àdánù nínú àwọn ẹlòmíràn tàbí ara yín wá.”

Èyí múni rántí ìkìlọ̀ àìpẹ́ ti Ààrẹ Nelson:

“Àwọn ohun díẹ̀ ni yío mú ayé yín díjú kíákíá síi ju rírú òfin àtọ̀runwá [ti ìparaẹnimọ́]. Fún àwọn tí wọ́n ti dá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, àgbèrè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó yá jùlọ láti sọ ẹ̀rí yín nù.

Agbára láti dá ẹ̀mí jẹ́ ànfààní kan ti jíjẹ́ ọlọ́run tí Baba Ọ̀run fi ààyè gba àwọn ọmọ ayé ikú Rẹ̀ láti lò. Báyi, Ọlọ́run ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ìtọ́ni kedere fún lílò agbára, ààyè àtọ̀runwá yi. Ìfarakanra wà fún ọkùnrin kan àti obìnrin kan nìkan tí wọ́n ti ṣègbeyàwó pẹ̀lú ara wọn.

Púpọ̀ nínú àwọn aráyé kò gbà èyí gbọ́, ṣùgbọ́n èrò orí ti ìta gbangba kìí ṣe alágbàwí ti òtítọ́. Olúwa ti kéde pé kò sí ẹni àìmọ́ kan tí yío dé ìjọba sẹ̀lẹ́stíà. … Bí ẹ bá sì ti jẹ́ aláìmọ́, mo bẹ̀bẹ̀ sí yín pé kí ẹ ronúpìwàdà, Ẹ wá sọ́dọ̀ Krístì kí ẹ sì gba ìlérí ìdáríjì Rẹ̀ tán pátápátá bí ẹ ti nronúpìwàdà nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín ní kíkún [Wo Ísáíàh 1:16–18; Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 58:42–43].”

Ẹ rántí pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì ṣe ìlérí, ìdàkejì ìṣe rere kìí ṣe òṣì—ó jẹ́ gígéni kúrò ní ọ̀dọ̀ Olúwa. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ tọ́ka sí ipa ti Ẹ̀mí Mímọ́ nínú ayé ẹnìkan. Gbogbo ènìyàn ni a bí pẹ̀lú Ìmọ́lẹ̀ Krístì bí wọ́n ṣe wá sínú ayé. Ní àfikún, àwọn ìṣe láti ṣe ìrìbọmi àti láti gba ẹ̀bùn àti àfikún ìmọ́lẹ̀ ti Ẹ̀mí Mímọ́. Ó nmú ìmísí àti ìtọ́sọ́nà wá, ó ntúnṣe ó sì nmú àwọn ẹ̀bùn àbínibí àti okun gbòòrò si, ó nṣèrànwọ́ láti yẹra fún ipa ibi, àwọn ìpinnu tí kò dára, àti òpin kíkú.

Bíiti yín, mo mọ àwọn kan tí wọ́n ti gbádùn ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ rí ṣùgbọ́n nípa ìjákulẹ̀ láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ tí wọ́n ti sọ ìbùkún náà nù. Ọ̀kan ní pàtàkì nwá sí ọkàn tí jíjẹ́ ọmọ Ìjọ rẹ̀ ti di gbígbà nítorí ìrèkọjá. Ó wí pé ìfèsì òun tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ ni láti ní ìmọ̀ bíbínú. Ó ròó pé òun di dídálẹ́jọ́ nípasẹ̀ àwọn aṣaájú tí kò pé. Ó mọ̀ pé ìwà òun ti jẹ́ àṣìṣe, ṣùgbọ́n ó ṣe àwáwí rẹ̀ nípa nínawọ́ sí àwọn àṣìṣe àti ìjákulẹ̀ àwọn ẹlòmíràn. Lẹ́hìn ìgbà díẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ìtura nínú ìgbé ayé níta Ìjọ láìsí ojúṣe ti ìpè àti ìgbèrò ti lílọ sí àwọn ìsìn ìjọ́sìn àti ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn.

Èyí tẹ̀síwájú fún ìgbà díẹ̀, ṣùgbọ́n ó bẹ̀rẹ̀ sí nní ìmọ̀ara àìsí ti Ẹ̀mí Mímọ́ gidi síi—wíwà Ọlọ́run—nínú ayé rẹ̀. Nípa ìrírí, ó mọ ohun tí ó dàbí láti ní, ọjọ́ sí ọjọ́, ìtùra, ìtọ́sọ́nà, àti ìgbẹ́kẹ̀lé tí a bí nípa Ẹ̀mí, tí òun sì ti pàdánù rẹ̀. Ní òpin, ó ṣe ohun tí ó nílò láti ronúpìwàdà ó sì yege lẹ́ẹ̀kansíi fún ìrìbọmi ti omi àti ti Ẹ̀mí.

Ó dàbí kò sí òpin sí oríṣiríṣi àwọn orísun ọ̀nà tí àwọn ènìyàn nwò fún ìtumọ̀, ìdùnnú, àti ìrànlọ́wọ́. Púpọ̀jù ni wọ́n “nwo kọjá àmì.” Ṣùgbọ́n a kò nílò láti jẹ́ “èwe mọ́, tí à nfi gbogbo afẹ́fẹ́ ẹ̀kọ́ tì síwá tì sẹ́hìn [tàbí ọ̀ṣọ́].” Ní kíkọjúsí Ọlọ́run, a lè rí àláfíà nínú ìṣòro àti pé ìgbàgbọ́ wa lè tẹ̀síwájú láti dàgbà àní ní àwọn ìgbà iyèméjì àti ìpènijà ti ẹ̀mí. A lè gba okun ní ojú àtakò àti ìpatì. A lè bá èrò làjà pẹ̀lú òdodo lọ́wọ́lọ́wọ́. Nítòótọ́ kò sí ọ̀nà míràn ju ohun tí Ọlọ́run Fúnrarẹ̀ ti yàn, “Ẹ kọjú sí mi, kí a sì gbà yín là, gbogbo òpin ayé: nítorí èmi ni Ọlọ́run, kò sí ẹlòmíràn.”

Kíkọjú sí Ọlọ́run túmọ̀ sí pé Òun kìí ṣe ọ̀kan lára ààyò wa lásán; ó túmọ̀ sí, sísànju pé Ó jẹ́ ààyò wa kan gígajùlọ. Mo rántí lẹ́ẹ̀kansi pé ìjàmbá olóró náà ní Lesotho ní Oṣù Kẹfà tó kọjá. Láti ibùsùn ilé ìwòsàn rẹ̀, ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin náà tí ó yè, tí kò gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run ṣíwájú dídárapọ̀mọ́ Ìjọ, wí pé èrèdí òun nísisìyí ni láti ṣe àwárí ìdí tí a fi dá ẹ̀mí rẹ̀ sí. “Sísin Ọlọ́run lemọ́lemọ́ ni bí èmi ó ṣe wá sí ìdáhùn kan,” ni ó sọ. “Mo máa nròó pé mo fẹ́ràn Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nísisìyí lódodo, lódodo, lódodo mo fẹ́ràn Rẹ̀. Nísisìyí Òun ni [àkọ́kọ́] ààyò nínú ayé mi.”

Mo jẹ́ ẹ̀rí ti Baba, Ọmọ, àti Ẹ̀mí Mímọ́ tí wọ́n wà nínú ìrẹ́pọ̀ pípé ti ọ̀rọ̀, èrò, èrèdí, àti pé ìṣe, jẹ́ Ọlọ́run kan, sí ẹnití a lè wò fún gbogbo àwọn ohun rere. Mo jẹ́ ẹ̀rí Ètùtù Jésù Krístì, níbití agbára sí ìmúṣẹ ìlérí ìyanilẹ́nu ti nwá: “Ẹ wò mi, kí ẹ sì forítì títí dé òpin, ẹ̀yin ó sì yè; nítorí fún ẹnikẹ́ni tí ó bá forítì títí dé òpin ni èmi ó fún ní ìyè ayérayé.” Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Wo Ryan Jensen, “Àwọn Yíyè nínú Ìjàmbá Ọkọ̀ Èrò ní Lesotho Pín Ọ̀fọ—àti Ìgbàgbọ́—ní Kùtùkùtù Àjálù,” Ìròhìn Ìjọ, Ọjọ́ Kejìdínlógún Oṣù Kéje, 2025, thechurchnews.com; Ryan Jensen, “‘Ọlọ́run Ṣì Jẹ́ Ọlọ́run’—Rírántí Àwọn Ayé Tó Sọnù nínú Ìjàmbá Ọkọ̀ Èrò ní Lesotho,” Ìròhìn Ìjọ, Ọjọ́ Kọkàndínlógún Oṣù Kéje, 2025, thechurchnews.com.

  2. Álmà 37:47.

  3. Álmà 37:44.

  4. Álmà 7:7; àfikùn àtẹnumọ́.

  5. Wo Númérì 21:5–6.

  6. Númérì 21:8.

  7. Wo Álmà 33:19.

  8. Alma 33:20

  9. Álmà 33:21–22. Ọmọ-ọmọ Álmà, Néfì, ní jíjẹ́ ẹ̀rí àkọsílẹ̀ Olùgbàlà, fikun, “Gbogbo àwọn tí yíò sì gbe ójú sókè wo ejò náà ni yíò yè, bẹ́ẹ̀ni gbogbo àwọn tí yíò gbe ójú sókè wo Ọmọ Ọlọ́run náà pẹ̀lú ìgbàgbọ́, tí nwọ́n ní ẹ̀mí ìròbìnújẹ́, lè yè, àní sí ayé nnì èyítí í ṣe ayérayé” (Hẹ́lámánì 8:15).

  10. Russell M. Nelson, “Ẹ Ṣẹ́gun Ayé kí ẹ sì Wá Ìsinmi,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2022, 96.

  11. 2 Nefi 1:20.

  12. Àwọn Ará Rómù 8:28.

  13. A lè rí àwọn èsò wíwo Ọlọ́run àti níní Ẹ̀mí Rẹ̀ láti wà pẹ̀lú wa ní àyíká wa. Fún àpẹrẹ, ìwadi ti ri pé “ìdàgbàsókè ti ẹ̀mí rọ̀ mọ́ ààbò ní ìlòdì sí ìrẹ̀wẹ̀sì àti ìlòkulò ohun mímú àti pẹ̀lú gbígbékalẹ̀ ọ̀dọ́ àgbà sókè fún àwọn ìbáṣepọ̀ lílera, iṣẹ́ tó lérèdí síi, àti agbára-inú títóbi ẹ̀dùn-ọkàn” (Àwọn Agbára Cornelia, “Aṣaájú Ti-ẹ̀mí nínú Ọgbà Ilé-ìwé,” The Atlantic, May 18, 2025, theatlantic.com).

    Àwọn ipele dídánìkanwà líle, ìpatì ẹ̀dùn-ọkàn, àti àníyàn nínú ìkànìyàn gbogbogbò ní ìlòdì sí ìgbésí-ayé lílera gbòòrò, okun ti ara àti ti ọpọlọ, ipele gígajù ti ẹ̀kọ́, àti ìwo-ìtà dídára tí ó dálé ìgbàgbọ́ ní àárín àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ikẹhìn. Kìí ṣe pé àwa, bí ènìyàn, kò ní ìrírí àwọn ìpènijà wíwọ́pọ̀ tí ó wà nínú ayé rí. Sànjù bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ pé ní wíwo Jésù Krístì, a lè borí.

  14. Wo Álmà 37:35–37.

  15. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 68:4.

  16. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 6:36.

  17. Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́: Atọ́nà kan fún Ṣíṣe àwọn Yíyàn (2022), 11.

  18. Russell M. Nelson, “Ẹ Ronú Sẹ̀lẹ́stíà!,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2023, 118; àtẹnumọ́ ní àtilẹ̀bá.

  19. Wo Jòhánnù 1:9; Mórónì 7:16; Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 84:45–46; 93:2.

  20. Jákọ́bù 4:14.

  21. Éfésù 4:14.

  22. Isaiah 45:22.

  23. Mapule Joyce Takane, ní Jensen, “Àwọn Yíyè ti Ìjàmbá Olóró Ọkọ̀ Èrò ní Lesotho Pín Ọ̀fọ̀—àti Ìgbàgbọ́—ní Kùtùkùtù Àjálù,” thechurchnews.com.

  24. Wo 1 Jòhánnù 5:7; 3 Néfì 11:36; Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 20:28; Atọ́nà sí àwọn Ìwé Mímọ́, “Ọlọ́run, Ọlọ́run Olórí,” Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.

  25. 3 Néfì 15:9.