Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àwọn Ni Onídàájọ́ Ara Wọn
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwàá 2025


14:25

Àwọn Ni Onídàájọ́ Ara Wọn

(Álmà 41:7)

Bí a bá lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, a ti dá a sì ti pa àwọn májẹ̀mú mọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, a sì ti ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, nígbànáà ìtẹ́ ìdájọ́ yíó dùnmọ́ni.

Ìwé ti Mọ́mọ́nì parí pẹ̀lú àwọn ìfipè onimìísí láti ọ̀dọ̀ Mórónì láti “wá sí ọ̀dọ̀ Krístì,” “di pípé nínú Rẹ̀,” “sẹ́ [ara wa] ní ti gbogbo àìwàbí Ọlọ́run,” kí a sì “fẹ́ràn Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ipá, inú àti agbára [wa].” Pẹ̀lú ìwuní, gbólóhùn tó kẹ́hìn ìkọ́ni rẹ̀ fojúsọ́nà fún Àjínde àti Ídájọ́ Ìkẹhìn.

Ó wípé, “Èmi yíò lọ sinmi ní párádísè Ọlọ́run láìpẹ́ yìí, títí tí ẹ̀mí àti ara mi yíò tún dàpọ̀, tí á ó sì mú mi jáde pẹ̀lú ayọ̀ ìṣẹ́gun nínú òfúrufú, láti pàdé yín níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ aláyọ̀ ti Jèhófàh nlá, Onídàjọ́ Ayérayé tí ààye àti òkú.”

Mo ní ìyàlẹ́nu nipasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí Mórónì lò “aláyọ̀” láti júwe Ídájọ́ Ìkẹhìn náà. Àwọn wòlíì míràn nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ṣe àpèjúwe ìdájọ́ náà bíi “ọjọ́ ológo” àti ọ̀kan tí a níláti “fojú sọ́nà [sí] pẹ̀lú ojú ti ìgbàgbọ́.” Síbẹ̀ nígbà púpọ̀ tí a bá nfojúsọ́nà fún ọjọ́ ìdájọ́, àwọn àpèjúwe míràn bíi ti wòlíì nwá sọ́kàn, bí irú “ìtìjú àti ẹ̀bi búburú,” ìbẹ̀rù àti ẹlẹ́rù,” àti “òṣì àìlópin.”

Mo gbàgbọ́ pé àwọn ìyàtọ̀ kedere nínú èdè yí ntọ́ka sí pé ẹ̀kọ́ Krístì mú kí ó ṣeéṣe fún Mórónì àti àwọn wòlíì míràn láti fojúsọ́nà sí ọjọ́ nlá náà pẹ̀lú ìtara àti ìfojúsọ́nà tó nírètí, dípò ẹ̀rù tí wọ́n kìlọ̀ nípa rẹ̀ fún àwọn tí kò múrasílẹ̀ ní ti ẹ̀mí. Kínni Mórónì ní òye rẹ̀ tí ìwọ àti èmi nílò láti kọ́?

Mo gbàdúrà fún àtìlẹ́hìn Ẹ̀mí Mímọ́ bí a ti ngbèro ètò ìdùnnú àti àánú ti Baba Ọ̀run, ipa ètùtù Olùgbàlà nínú ètò ti Baba, àti bí a ó ṣe “jíhìn fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ [tiwa] ní ọjọ́ ìdájọ́.”

Ètò Ìdùnnú ti Baba

Kókó àwọn èrèdí ètò Baba ni láti pèsè àwọn ọmọ ẹ̀mí Rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ànfààní láti gba àgọ́ ara, mọ “rere yàtọ̀ sí ibi” nípasẹ̀ ìrírí ayé ikú, dàgbà ní ti ẹ̀mí, kí wọn ó sì tẹ̀síwájú ní ti ayérayé.

Ohun ti Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú tọ́ka sí bíi “ìhùwàsí agbára láti yàn” jẹ́ pàtàkì nínú ètò Ọlọ́run láti yege àìkú àti ìyè ayérayé ti àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Rẹ̀. Ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ pàtàkì yìí ni a júwe bákannáà nínú àwọn ìwé mímọ́ bíi agbára láti yàn àti ominira láti yàn àti láti ṣe ìṣe.

Gbólóhùn ọ̀rọ̀ “ìhùwàsí agbára láti yàn” jẹ́ ìkọ́ni. Àwọn àpẹrẹ fún ọ̀rọ̀ náà “ìhùwàsí” ní “rere,” “òtítọ́,” àti “ìwà rere” nínú. Àwọn àpẹrẹ fún ọ̀rọ̀ náà “agbára láti yàn” ní “ìgbésẹ̀,” “ìṣe ṣíṣe,” àti “iṣẹ́” nínú. Nítorínáà, a lè ní òye “ìhùwàsí agbára láti yàn” bíi okun àti ànfààní láti yàn àti láti ṣe ìṣe fún ara wa ní àwọn ọ̀nà tí ó dára, jẹ́ òtítọ́, ìwàrere, àti tòótọ́.

Àwọn ìṣẹ̀dá Ọlọ́run ní méjèjì “àwọn ohun láti ṣe àti àwọn ohun láti ṣe ìṣe lé lórí nínú.” Àti pé ìhùwàsí agbára láti yàn ni “agbára ìṣe òmìnira” tí a ṣe àwòṣe rẹ̀ láti ọ̀run wá tí nró àwa bíi ọmọ Ọlọ́run lágbára láti dàbí aṣojú láti ṣe àti tí kìí ṣe ohun kan lásán láti ṣe ìṣe lé lórí.

Ilẹ̀ ayé ni a dá bíi ibìkan níbití àwọn ọmọ Baba Ọ̀run ti lè jẹ́ dídánwò láti ríi bóyá wọn yíó “ṣe ohun gbogbo èyíkéyìí tí Olúwa Ọlọ́run wọn yíó pàṣẹ fún wọn.” Èrèdí pàtàkì kan fún Ìṣẹ̀dá àti fún wíwà láyé ikú wani láti pèsè ànfààní fún wa lati ṣe ìṣe kí a sì di ohun tí Olúwa pè wá láti dà.

Olúwa kọ́ Énọ́kù pé:

“Kíyèsí àwọn arákùnrin rẹ̀ wọ̀nyí; wọ́n jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ tèmi, èmi sì fi ìmọ̀ tiwọn fún wọn, ní ọjọ́ tí èmi dá wọn; àti nínú Ọgbà Èdẹ́nì, ni èmi ti fún ènìyàn ní agbára láti yàn rẹ̀;

“Àti fún àwọn arákùnrin rẹ ni èmi ti wí, àti bákannáà mo fún wọn ní òfin, pé kí wọn kí ó fẹ́ràn ara wọn, àti pé kí wọn kí ó yan èmi, Baba wọn.”

Ìpìlẹ̀ àwọn èrèdí fún lílo agbára láti yàn jẹ́ láti fẹ́ràn ara wa àti láti yan Ọlọ́run. Àwọn èrèdí méjèèjì wọ̀nyí sì báramu déédé pẹ̀lú àwọn òfin nlá àkọ́kọ́ àti ìkejì, láti fẹ́ràn Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn, àyà, àti inú wa, àti láti fẹ́ ọmọnìkejì wa bí ara wa.

Ẹ gbèrò pé a pàṣẹ fún wa ni—kìí ṣe ọ̀rọ̀ ìyànjú tàbí ìmọ̀ràn lásán, ṣùgbọ́n pàṣẹ—láti lo agbára láti yàn wa láti fẹ́ràn ara wa àti láti yan Ọlọ́run. Njẹ́ kí ndábàá pé nínú àwọn ìwé mímọ́, ọ̀rọ̀ àtúnṣe náà “ìhùwàsí” kìí ṣe ọ̀rọ̀ ìjúwe lásán ṣùgbọ́n bóyá bákannáà ìdarí àtọ̀runwá kan nípa bí agbára láti yàn wa ṣe níláti jẹ́ lílò.

Orin isìn kan tó gbajúmọ̀ ni a fún ni àkòrí “Yàn Èyí Tó Tọ́” fún ìdí kan. A kò bùkún wa pẹ̀lú ìhùwàsí agbára láti yàn láti ṣe ohunkóhun tó wù wá nígbàtí a fẹ́. Dípò bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ètò ti Baba, a gba ìhùwàsí agbára láti yàn láti wá láti ṣe ìṣe ní ìbárẹ́ pẹ̀lu òtítọ́ ayérayé. Bíi “aṣojú sí [ara wa],” a níláti fi pẹ̀lú ìtara kópa nínú àwọn iṣẹ́ rere, kí a “ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun láti inú ìfẹ́ ara [wa], kí a sì mú òdodo púpọ̀ wá sí ìmúṣẹ.”

Ṣíṣe pàtàkì ayérayé ti ìhùwàsí agbára láti yàn ni a fi àmí sí nínú àkọsilẹ̀ ìwé mímọ́ ti ìgbìmọ̀ ṣaájú-ayé-ikú. Lúsíférì ṣọ̀tẹ̀ sí ètò Baba fún àwọn ọmọ Rẹ̀ ó sì wá láti pa agbára ìṣe òmìnira run. Ní pàtàkì, ìjà ti èṣù náà kọjúsí orí ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ ìhùwàsí agbára láti yàn tààrà.

Ọlọ́run ṣàlàyé pé, “Nítorínáà, nítorípé … Sátánì ṣọ̀tẹ̀ sí mi, tí ó sì lépa láti pa òmìnira ènìyàn run, … èmi mú kí a lé e sọ̀kalẹ̀.”

Ète ìmọtaraẹni nìkan ti ọ̀tá ni láti gba agbára kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ọlọ́run láti di “aṣojú fún ara wọn”, tí wọ́n le ṣe nínú ìṣòdodo. Èrò inú rẹ̀ ni láti ṣe àwọn ọmọ Baba Ọ̀run bíi àwọn nkan tí a lè ṣe ìṣe lé lórí nìkan.

Ṣíṣe àti Dídàbí

Ààrẹ Dallin H. Oaks ti tẹnumọ́ọ pé ìhìnrere Jésù Krístì npè wá láti mọ ohun kan àti láti dà bíi ohun kan nípasẹ̀ lílo ìhùwàsí agbára láti yàn pẹ̀lú ìṣòdodo. Ó wí pé:

“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Bíbélì àti àwọn ìwé mímọ́ òde òní sọ̀rọ̀ nípa ìdájọ́ ìkẹhìn kan, níbití gbogbo ènìyàn yíó ti jẹ́ fífún ní èrè gẹ́gẹ́bí àwọn ìṣe tàbí àwọn iṣẹ́ tàbí àwọn ìfẹ́ inú ọkàn wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ìwé mímọ́ míràn mú èyí gbòòrò nípa títọ́ka sí ìdálẹ́jọ́ wa nípa ipò tí a bá ti ṣe yọrí.

“Wòlíì Néfì ṣe àpèjúwe Ìdájọ́ Ìkẹhìn bíi ohun tí a bá ti dà: ‘Àti pé bí àwọn iṣẹ́ wọn bá jẹ́ ti ẹ̀gbin àwọn gbọ́dọ̀ fi dandan jẹ́ ẹlẹ́gbin; bí wọ́n bá sì jẹ́ ẹlẹ́gbin ó gbọdọ̀ di dandan pé wọn kò ní lè gbé nínú ìjọba Ọlọ́run’ [1 Néfì 15:33; àfikún àtẹnumọ́]. Mórónì kéde pé, ‘Ẹni náà tí ó bá jẹ́ ẹlẹ́gbin yíó jẹ́ ẹlẹ́gbin síbẹ̀; àti ẹni náà tí ó bá jẹ́ olódodo yíó jẹ́ olódodo síbẹ̀’ [Mọ́mọ́nì 9:14; àfikún àtẹnumọ́].”

Ààrẹ Oaks tẹ̀síwájú pé: “Láti inú irú àwọn ìkọ́ni bẹ́ẹ̀ a parí pé Ìdájọ́ Ìkẹhìn kìí wulẹ̀ ṣe àyẹ̀wò ti àròpọ̀ àwọn ìṣe rere àti búburú nìkan—ó jẹ́ ohun tí a ti ṣe. Ó jẹ́ jíjẹ́wọ́ àyọrísí ìkẹhìn ti àwọn ìṣe àti àwọn èrò wa—ohun tí a ti .”

Ètùtù Olùgbàlà Náà.

Àwọn iṣẹ́ wa àti àwọn ìfẹ́ inú wa nìkan kò gbà wá kò sì lè gbà wá là. “Lẹ́hìn gbogbo ohun tí a lè ṣe,” a làjà pẹ̀lú Ọlọ́run nìkan nípasẹ̀ àánú àti oore ọ̀fẹ́ tí ó wà nípasẹ̀ ètùtù ẹbọ ọrẹ àìlópin àti ti ayérayé Olùgbàlà.

Álmà wí pé, “Ẹ bẹ̀rẹ̀sí gbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run, pé yíó wá láti ra àwọn ènìyàn rẹ padà, àti pé yíò jìyà yíò sì kú láti ṣe ètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn; àti pé yíò tún jínde kúrò nínú ipò òkú, èyítí yíò mú àjínde náà ṣẹ, pé gbogbo ènìyàn yíò dúró níwájú rẹ̀, láti jẹ́ dídá lẹ́jọ́ ní ọjọ́ ìkẹhìn àti ti ìdájọ́, ní ìbámu sí àwọn iṣẹ́ wọn.”

“Àwa gbàgbọ́ pé nípasẹ̀ Ètùtù Krístì, gbogbo ènìyàn lè jẹ́ gbígbàlà, nípa ìgbọràn sí àwọn òfin àti ìlànà Ìhìnrere.” Ó ti yẹ kí a ní ìmoore tó pé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti ìwà búburú wa kì yíó dúró bíi ẹ̀rí ní ìtakò sí wa bí a bá jẹ́ “àtúnbí” ní tòótọ́, ẹ lo ìgbàgbọ́ nínú Olùràpadà, ẹ ronúpìwàdà pẹ̀lú “ọkàn ìṣòtítọ́” àti “èrò inú tòótọ́,” kí ẹ sì “forítì títí dé òpin.”

Ìbẹ̀rù ti Ọlọ́run

Púpọ̀ nínú wa le ní ìrètí pé ìfarahàn wa níwájú ìtẹ́ ti Onídàájọ́ Ayérayé yíó jọra sí ìtẹ̀síwájú nínú ilé ẹjọ́ ti ayé yìí. Onídàájọ́ kan yíó ṣe àkóso. Ẹ̀rí yíó jẹ́ gbígbé kalẹ̀. Ìpinnu kan yíò jẹ́ ṣíṣe. Ó sì ṣeéṣe kí á wà nínú àìdánilójú àti ẹ̀rù títí tí a ó fi mọ àyọrísí ìgbẹ̀hìn. Ṣùgbọ́n irú ìjúwe bẹ́ẹ̀ kò péye tó.

Ohun tó yàtọ̀ ṣùgbọ́n tó ní í ṣe sí àwọn ẹ̀rù tí a sáábà máa nní ìrírí rẹ̀ ni ohun tí àwọn ìwé mímọ́ ṣe àpèjúwe rẹ̀ bíi “ìbẹ̀rù Ọlọ́run” tàbí “ìbẹ̀rù Olúwa.” Láìjọ ìbẹ̀rù ti ayé tí í máa nfa ìjayà àti àníyàn, ìbẹ̀rù Ọlọ́run npe àláfíà, ìdánilójú, àti ìgbẹ́kẹ̀lé wá sínu ayé wa.

Ìbẹ̀rù òdodo kún fún ìjìnlẹ̀ ìmọ̀lára ti ìbọ̀wọ̀ àti ìtẹríba fún Olúwa Jésù Krístì, ìgbọràn sí àwọn òfin Rẹ̀, àti ìfojúsọ́nà fún Ìdájọ́ Ìkẹhìn àti òdodo ni ọwọ́ Rẹ̀. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run ndàgbà láti inú níní òye pípé nípa adánidá àtọ̀runwa àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ Olùràpadà, ṣíṣetán láti fi ìfẹ́ wa sílẹ̀ fùn ìfẹ́ Rẹ̀, àti ìmọ̀ pé olukúlùkù ọkùnrin àti obìnrin yíò jíhìn fún ìfẹ́ inú, àwọn èrò, àwọn ọ̀rọ̀, àti àwọn ìṣe rẹ̀ nínú ara ní Ọjọ́ Ìdájọ́ náà.

Ìbẹ̀rù Olúwa kìí ṣe gbígbọ̀n pẹ̀lú ìlọ́ra nípa wíwá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ láti jẹ́ dídálẹ́jọ́. Dípo bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ìrètí jíjẹ́wọ́ nígbẹ̀hìn funra ara wa nípa àwọn nkan bí wọ́n ṣe wà ní tòótọ́ àti bí wọ́n ó ṣe rí ní tòótọ́.

Olukúlùkù ènìyàn tí wọ́n ti wà rí, ti wọ́n wà nísisìyí, àti ti wọ́n sì máa wà lórí ilẹ̀ ayé ni “a ó mú wá dúró níwájú itẹ Ọlọ́run, láti jẹ́ dídá lẹ́jọ́ nípasẹ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ wọn [lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin] bóyá wọ́n jẹ́ rere tàbí wọ́n jẹ́ ibi.”

Bí àwọn ìfẹ́ inú wa bá jẹ́ fún ìṣòdodo ti àwọn iṣẹ́ wa sì jẹ́ rere—tí ó túmọ̀ sí pé a ti lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, a ti dá a sì ti pa àwọn májẹ̀mú mọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, a sì ti ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa—nígbànáà ìtẹ́ ìdájọ́ yíó dùnmọ́ni. Bí Énósì ti kéde, a ó “dúró níwájú [Olùràpadà]; nígbànáà ni [àwa] yíò rí ojú rẹ̀ pẹ̀lú ìgbádùn.” Àti ní ọjọ́ ìkẹhìn a ó “jẹ́ fífún ní èrè sínú ìṣòdodo.”

Ní ìdàkejí, bí àwọn ìfẹ́ inú wa bá ti jẹ́ fún ibi tí àwọn iṣẹ́ wa sì jẹ́ búburú, nígbànáà ìtẹ́ ìdájọ́ yíó jẹ́ ohun tó mú ìbẹ̀rù wá. Àwa yíó ní “ìmọ̀ pípé kan,” ìrántí dídán,” kan àti “èrò orí jíjí pépé ti ẹ̀bi [wa] gan-an.” “Àwa kí yíò le wo òkè sí Ọlọ́run; awa yíò sì kún fún ayọ̀ tí a bá le pàṣẹ fún àwọn àpáta àti àwọn òkè pé kí wọ́n wó lù wá láti fi wá pamọ́ kúrò ní iwájú rẹ̀.” Àti ní ọjọ́ ìkẹhìn àwa yíó “ní èrè [wa] fún ibi.”

Níkẹhìn, nígbànáà, àwa ni onídàájọ́ ara wa. Ẹnikẹ́ni kì yíò nílò láti sọ ibití àwa ó lọ fún wa. Ní ọ̀dọ̀ Olúwa, àwa ó jẹ́wọ́ ohun tí a yàn láti jẹ́ ní ayé ikú a ó sì mọ̀ fún ara wa ibi ti a níláti wà ni ayérayé.

Ìlérí àti Ẹrí

Níní òye pé Ìdájọ́ Ìkẹhìn le jẹ́ dídùnmọ́ni kìí ṣe ìbùkún tí a pamọ́ fún Mórónì nìkan.

Álmà ṣe àpèjúwe àwọn ìbùkún tí a ṣ̣e ìlérí tó wà fún olukúlùkù àwọn olùfọkànsìn ọmọ-ẹ̀hìn Olùgbàlà. Ó wí pé:

“Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ ìmúpadàbọ̀sípò jẹ́ láti mú ibi padà lẹ́ẹ̀kansíi fún ibi, tàbí ti ara fún ti ara, tàbí ti èṣù fún ẹni ti èṣù—rere fún èyítí í ṣe rere; òdodo fún èyítí í ṣe òdodo; ohun tó tọ́ fún èyítí ó tọ́, àánú fún èyítí í ṣe àánú.

“… Ṣe èyítí ó tọ́, ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o sì máa ṣe rere títí lọ; bí ìwọ bá sì ṣe gbogbo nkan wọ̀nyí ìgbànnáà ni ìwọ yíò gba èrè rẹ; bẹ́ẹ̀ni, àánú yíó jẹ́ mímú-padàbọ̀-sípò fún ọ lẹ́ẹ̀kansíi; àìṣègbè yíó jẹ́ mímú-padàbọ̀-sípò fún ọ lẹ́ẹ̀kansíi; ìdájọ́ òdodo yíó jẹ́ mímú-padàbọ̀-sípò fún ọ lẹ́ẹ̀kansíi; ìwọ yíò sì rí ìṣe rere ní sísan fún ọ lẹ́ẹ̀kansíi.”

Mo fi tayọ̀tayọ̀ jẹ́ri pé Jésù Krístì ni alààyè Olùgbàlà wa. Ìlérí Álmà jẹ́ òtítọ́ ó sì wà fún ìwọ àti èmi—lónìí, lọ́la, àti ní gbogbo ayérayé. Mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ mímọ́ ti Olúwa Jésù Krístì, àmín.