Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Orúkọ Náà nípa Eyítí a Pè Yín
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwàá 2025


11:1

Orúkọ Náà nípa Eyítí a Pè Yín

Kíni ó túmọ̀ sí láti jẹ́ pípè pẹ̀lú orúkọ Krístì?

Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni pé bí Olúwa bá nbá wa sọ̀rọ̀ tààrà, ohun àkọ́kọ́ tí Òun yíò mú kí ó dá wa lójú ni ìdánimọ̀ tòótọ́ wa: ọmọ Ọlọ́run ni àwa, ọmọ májẹ̀mú, àti ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì. Orúko míràn yíò já wa kulẹ̀ nígbẹ̀hìn.

Mo kọ́ èyí fún ara mi nígbàtí ọmọkùnrin mi tó dàgbà jùlọ gba fóònù alagbeka rẹ̀ àkọ́kọ́. Pẹ̀lú ìnúdídùn nlá, ó bẹ̀rẹ̀síí tẹ àwọn orúkọ ẹbí rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ sínú àwọn olùbásọ̀rọ̀ rẹ̀. Ní ọjọ́ kan, mo sàkíyèsí pé ìyá rẹ̀ npèé. Lórí ìbòjú orúkọ “Ìyá” hàn. Ìyẹn jẹ́ yíyàn tí ó bọ́gbọ́n mu tí ó sì lọ́lá—àti pé, èmi yíò gba, àmì ọ̀wọ̀ fún òbí tí ó dára jùlọ nínú ilé wa. Nípa àdánidá, Mo ní ìyàlẹ́nu. Orúkọ wo ni ó ti fún mi?

Mo yí orúkọ àwọn olùbásọ̀rọ̀ rẹ̀ kiri, ní èrò pé bí Wendi bá jẹ́ “Ìyá,” Mo gbọdọ̀ jẹ́ “Baba.” Kò sí níbẹ̀. Mo wá “Baba.” Kò sí nkankan síbẹ̀. Ìyàlẹ́nu mi yípadà sí àníyàn ránpẹ́. “Àbí ó pé mì ní ‘Corey’?” Rárá. Nínú ìtiraka kan tí ó kẹ́hìn, mo rò pé, “Agbábọ́ọ̀lù ni wá—bóyá ó pè mí ní ‘Pelé.’” Ìrònú onífẹ̀ẹ́. Níkẹhìn, mo pe nọ́mbà rẹ̀ fúnra mi, àwọn ọ̀rọ̀ méjì sì jáde sórí àwo rẹ̀: “Kìí ṣe Ìyá”!

Arákùnrin àti arábìnrin, orúkọ wo ni a fi npé yín?

Jésù pe àwọn ọmọlẹ́hìn Rẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ orúkọ: Ọmọẹ̀hìn. Ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Ọmọ Wòlíì. Àgùntàn. Ọ̀rẹ́. Ìmọ́lẹ̀ Ayé. Ènìyàn Mímọ́. Ọ̀kọ̀ọ̀kan gbé jíjẹ́pàtàkì ayérayé ó sì tẹnu mọ́ ìbáṣepọ̀ ti ara ẹni pẹ̀lú Olùgbàlà.

Ṣùgbọ́n nínú àwọn orúkọ wọ̀nyí, ìkan ga ju àwọn yòókù lọ—orúkọ Krístì. Nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, Ọba Bẹ́njámínì kọ́ni pẹ̀lú agbára pé:

“Kò sí orúkọ míràn tí a fún ni nípasẹ̀ èyítí ìgbàlà yíò wá; nítorínáà, èmi ìbá fẹ́ kí ẹ́ gbé orúkọ Krístì lé ara yín. …

“Yíò sì ṣe, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe eleyĩ ni a ó bá ní ọwọ́ ọ̀tun Ọlọ́run, nítorítí òun yíò mọ orúkọ nã tí à fi npè é; nítorítí a ó fi orúkọ Krístì pè é.”

Àwọn tí wọ́n gbé orúkọ Krístì lé ara wọn di ọmọẹ̀hìn àti àwọn ẹlẹ́rìí Rẹ̀. Nínú ìwé Ìṣe Àwọn Àpóstélì, a kà pé lẹ́hìn Àjínde Jésù Krístì, a pàṣẹ fún àwọn ẹlẹ́rìí tí Ọlọ́run yàn láti wàásù àti láti jẹ́rìí pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gba Jésù gbọ́, ṣe ìrìbọmi, tí ó sì gba Ẹ̀mí Mímọ́ yíò gba ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀. Àwọn tí wọ́n gba àwọn ìlànà mímọ́ wọ̀nyí péjọ pọ̀ pẹ̀lú Ìjọ, di ọmọẹ̀hìn, a sì pè wọ́n ní Kristẹni. Ìwé ti Mọ́mọ́nì pẹ̀lú ṣàpèjúwe àwọn onígbàgbọ́ ti Krístì bíi Kristẹni àti àwọn tí wọ́n dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run “àwọn ọmọ Krístì, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀.”

Kíni ó túmọ̀ sí láti jẹ́ pípè pẹ̀lú orúkọ Krístì? Ó túmọ̀ sí dídá àti pípa àwọn májẹ̀mú mọ́, rírántí Rẹ̀ nígbàgbogbo, pípa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, àti jíjẹ́ “mímúra tán … láti dúró gẹ́gẹ́bí ẹlẹ́rìí fún Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà àti nínú ohun gbogbo.” Ó túmọ̀ sí dídúró pẹ̀lú àwọn wòlíì àti àwọn àpọ́sítélì bí wọ́n ti ngbé ọ̀rọ̀ Krístì kiri—jákèjádò àgbáyé—pẹ̀lú ẹ̀kọ́, májẹ̀mú, àti àwọn ìlànà rẹ̀. Ó tún túmọ̀ sí sísìn àwọn ẹlòmíràn láti mú ìjìyà fúyẹ́, àti láti jẹ́ ìmọ́lẹ̀, àti láti mú ìrètí nínú Krístì wá fún gbogbo ènìyàn. Dájúdájú, èyí jẹ́ ìlànà ìgbé ayé pípẹ́. Wòlíì Joseph Smith kọ́ni pé “èyí jẹ́ ibùdókọ̀ kan tí ẹnikẹ́ni kò tíì dé sí ní àkokò kan.”

Nítorí ìrìn àjò jíjẹ́ ọmọlẹ̀hìn ngba àkokò àti ìgbìyànjú tí a mú dàgbà ní “ìlà lórí ìlà, ìlànà lórí ìlànà,” ó rọrùn láti di ẹni tí a mú nínú àwọn orúkọ oyè tí ayé. Ìwọ̀nyí nìkan ní iye fún ìgbà díẹ̀ àti pé wọn kì yíò tó láyè ara wọn. Ìràpadà àti àwọn ohun ayérayé nìkan “nwọlé nínú àti nípasẹ̀ Mèsáíàh Mímọ́.” Nítorínáà, títẹ̀lé ìmọ̀ràn àsọtẹ́lẹ̀ láti fi jíjẹ́ ọmọẹ̀hìn ṣe ààyò jẹ́ méjèèjì bíbọ́sí àkokò àti ti ọgbọ́n, pàápàá jùlọ lákòókò tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohùn àti ipa tí ndíje. Èyí wà nínú ọkàn ìmọ̀ràn Ọba Bẹ́njámínì nígbàtí ó sọ pé, “Mo fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó rántí láti pa orúkọ [Krístì] mọ́ nínú ọkàn yín nígbà gbogbo, … kí ẹ gbọ́ kí ẹ sì mọ ohun tí a ó fi pè yín, àti pẹ̀lú, orúkọ tí òun yíò fi pè yín.”

Martin Gassner

Mo ti rí èyí nínú ẹbí mi. Baba-nla Baba mi Martin Gassner ni a yípadà láéláé nítorí ààrẹ ẹ̀ka tí ó nírẹ̀lẹ̀ dáhùn ipè Olùgbàlà. Ní Germany ní 1909, àwọn àkokò le, àti pé owó há gidigidi. Martin ṣiṣẹ́ bí ajórinmọ́rin ní ilé-iṣẹ́ kan tó nṣe páìpù. Nípa gbígbà tirẹ̀, ọjọ́ ìsanwó parí sórí mímu, sìgá, àti ríra ohun mímu kiri ní ilé-ọtí. Níkẹhìn ìyàwó rẹ̀ kìlọ̀ fún un pé tí kò bá yípadà, òun yíò lọ kúrò.

Lọ́jọ́ kan, alábàáṣiṣẹ́ Martin pàdé rẹ̀ lójú ọ̀nà ilé-ọtí pẹ̀lú bébà dídí lọ́wọ́ rẹ̀. Òun ti ri ní àdúgbò ó sì sọ fún Martin ó ní ìmọ̀lára ohun tí ó yàtọ̀ lẹ́hìn tí ó ka ìwé pẹlẹbẹ náà tí àkọlé rẹ̀ Jẹ́ wissen Sie von den Mormonen?, tàbí Kíni O Mọ̀ Nípa àwọn Mọ́mọ́nì? Ó dá mi lójú pé orúkọ àkọ́lé náà ti yípadà.

Sítámpù Àdírẹ́sì kan tí a tẹ̀ sẹ́hìn rẹ̀ hàn tó láti mọ ibi tí ilé ìjọsìn wà. Ó jìnnà níwọ̀nba, ṣùgbọ́n ohun tí wọ́n kà wú wọn lórí, wọ́n sì pinnu láti wọ ọkọ̀ ojú irin lọ́jọ́ Ìsinmi náà láti ṣèwádìí. Nígbàtí wọ́n débẹ̀, wọ́n ri pé kì í ṣe ilé ìjọsìn tí wọ́n nírètí ni àdírẹ́sì náà, ṣùgbọ́n ilé ìsìnkú ni. Martin ṣiyèméjì—nítorí lóòótọ́, ilé ìjọsìn kan ní ilé ìsìnkú kan dún díẹ̀ púpọ̀ bíi àdéhùn ìṣòwò.

Ṣùgbọ́n ní òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì, nínú gbọ̀ngàn tí wọ́n nyàlò, wọ́n rí àwùjọ kékeré ti àwọn Ènìyàn Mímọ́. Ọkùnrin kan pè wọ́n láti wá sí ìpàdé ìjẹ́rìí. Ẹ̀mí fọwọ́ tọ́ Martin ó sì wú u lórí gan-an nípasẹ̀ àwọn ìjẹ́rìí rírọrùn, tí ó gbóná janjan débi pé ó jẹ́rìí tirẹ̀. Àti pé ó wà níbẹ̀, ní ààyè tí kò ṣeéṣe jùlọ, pé ó sọ pé ó ti mọ̀ pé ó gbọ́dọ̀ jẹ́ òtítọ́.

Lẹhìnnáà, ọkùnrin náà fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́bí ààrẹ ẹ̀ka náà, ó sì béèrè bóyá wọ́n yíò padà wá. Martin ṣàlàyé pé ó ngbé jìnà púpọ̀ àti pé kò lè ní faradà láti rin ìrìn-àjò bẹ́ẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ààrẹ ẹ̀ka náà kàn sọ pé, “Tẹ̀lé mi.”

Wọn rìn bíi búlọ́kì díẹ̀ lọ sí ilé-iṣẹ́ níbi tí ọ̀rẹ́ ààrẹ ẹ̀ka náà ti nṣiṣẹ́ Lẹ́hìn ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kúkúrú kan, wọ́n fún Martin àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní iṣẹ́. Lẹ́hìnnáà, ààrẹ ẹ̀ka mú wọn lọ sí ilé kan ó sì wá ilé fún àwọn ẹbí wọn.

Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ laarin wákàtí méjì. Ẹbí Martin kó lọ ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀le. Oṣù mẹ́fà lẹ́hìnwá, wọ́n ṣèrìbọmi. Ọkùnrin náà tí a ti mọ̀ sí ọ̀mùtípara tí kò nírètí nígbà kan di ẹni tí a mọ̀ dípò rẹ̀ gẹ́gẹ́bí ìránṣẹ́ ìhìnrere onítara ti ìgbàgbọ́ titun rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn ìlú náà fi bẹ̀rẹ̀ sí pè é ní bóyá kìí ṣe pẹ̀lú ìfẹ́ni “àlùfáà náà.”

Ní ti ààrẹ ẹ̀ka, mi ò lè sọ orúkọ rẹ̀ fún yín—ìdánimọ̀ rẹ̀ ti sọnù fún àkokò. Ṣùgbọ́n mo pè é ní ọmọẹ̀hìn, ikọ̀, Kristẹni, ará Samáríà rere, àti ọ̀rẹ́. Ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́fà (116) lẹ́hìnwá ni ipa rẹ̀ ṣì wà, mo sì dúró lé èjìká jíjẹ́ ọmọẹ̀hìn rẹ̀.

Gassners ní tẹ́mpìlì

“Ọ̀rọ̀ kan wà tí à nsọ pé ka àwọn irúgbìn nínú ápù kan, ṣùgbọ́n ẹ kò lè ka àwọn èso ti ó wá láti inú irúgbìn kan.” Irúgbìn tí ààrẹ ẹ̀ka gbìn ti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso jáde. Kékeré ni òun ìbá fi mọ̀ pé ní ọdún méjìdinlàádọ́ta (48) lẹ́hìnwá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìran ẹbí Martin ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìkelè náà ni a ó fi èdìdi dì ní Tẹ́mpìlì Bern Switzerland.

Bóyá àwọn ìwàásù tí ó tóbi jùlọ ni àwọn tí a kò gbọ́ rí ṣùgbọ́n àwọn tí a nrí nínú ìdákẹ́jẹ́ẹ́, àwọn ìṣe aláìnírònú àti ìṣe tí a ṣàkíyèsí nínú ìgbésí ayé àwọn ènìyàn gbáàtúù tí wọ́n ngbìyànjú láti dà bí Jésù, tí wọ́n nlọ kiri ní ṣíṣe ohun rere. Ohun tí ààrẹ ẹ̀ka olóore yí ṣe kì í ṣe ọ̀kan lára àtòkọ àyẹ̀wò. Ó kàn ngbé ìhìnrere náà gẹ́gẹ́bí a ti ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú ìwé Álmà: “Wọn kò lé ẹnikẹ́ni lọ … tí ebi npa, tàbí àwọn tí òùngbẹ ngbẹ, tàbí àwọn tó nṣàìsàn, … wọ́n jẹ́ olómìnira sí gbogbo ènìyàn, àti àgbà àti ọ̀dọ́, … àti akọ àti abo.” Àti pé, kókó kan tí a kò gbọ́dọ̀ fojú fo, wọn kò lé èyíkéyìí lọ “yálà kúrò nínú ìjọ tàbí nínú ìjọ.”

Àwọn tí wọ́n gba orúkọ Kristi lé ara wọn mọ̀, bí Joseph Smith ti sọ, “Ọkùnrin kan tí ó kún fún ìfẹ́ Ọlọ́run, kò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú bíbùkún ẹbí rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ó gbòòrò káàkiri gbogbo ayé, ó nṣàníyàn láti bùkún gbogbo ìran ènìyàn.”

Bí Jésù ṣe gbé ìgbé ayé rẹ̀ nìyí. Kódà, ó ṣe púpọ̀ débi pé àwọn ọmọẹ̀hìn rẹ̀ kò lè kọ gbogbo rẹ̀ sílẹ̀. Àpọ́sítélì Jòhánnù kọsílẹ̀: “Ọ̀pọ̀ nkan míràn tún wà tí Jésù ṣe, èyí tí, bí a bá kọ̀ wọ́n ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, mo rò pé ayé pàápàá kò lè gba àwọn ìwé tí ó yẹ kí a kọ wọ́n sí.”

Ẹ jẹ́ ká tiraka láti tẹ̀lé àpẹrẹ Krístì, ní ṣíṣe ohun rere àti sísọni di ọmọlẹ̀hìn ní ààyò ìgbésí ayé pípẹ́ wa nítorínáà gbogbo ìgbà tí a bá nbá àwọn ẹlòmíràn lò, kí wọ́n lè ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run àti agbára ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ti Ẹ̀mí Mímọ́. Nígbànáà a lè dara pọ̀ mọ́ baba-nlá baba mi àti mílíọ̀nù ọ̀kẹ́ àwọn ọkùnrin àti obìnrin míràn tí wọ́n ti polongo, gẹ́gẹ́bí ọmọẹ̀hìn Andrew pé, “A ti rí Mèsáíàh náà.”

Ní ìparí, ìdánimọ̀ wa kò ní àsọyé nípasẹ̀ àgbáyé. Ṣùgbọ́n jíjẹ́ ọmọẹ̀hìn wa ní àsọyé nípasẹ̀ àwọn ìlànà tí a gbà, àwọn májẹ̀mú tí a pa mọ́, àti ìfẹ́ tí a fihàn sí Ọlọ́run àti ọmọnìkejì nípa ṣíṣe rere nírọ̀rùn. Gẹ́gẹ́bí Ààrẹ Nelson ti kọ́ni, àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run nítòótọ́, ọmọ májẹ̀mú, ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì.

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Jésù Krístì wà láàyè àti pé ó ti rà wá padà. Òun ni Ẹni náà tó wípé, “Mo ti pè yín nípasẹ̀ … orúkọ; ẹ̀yin jẹ́ tèmi.” Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.