Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwàá 2025 Abala Òwúrọ̀ Sátidé Abala Òwúrọ̀ SátidéAbala òwúrọ̀ Sátidé ti Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Ìkarùndinlọ́gọ́ọ̀wá Ìlàjì-ọlọ́dọdún ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn tí a ṣe ní Ọjọ́ ìkẹ́rin sí ikarun Oṣù Kẹwa, 2025. Dallin H. OaksỌ̀rọ̀-ìṣíwájúÀàrẹ Oaks ṣe àfihàn ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò yí, èyí tí ó nṣẹlẹ̀ láìpẹ́ lẹ́hìn kíkọjá lọ Ààrẹ Russell M. Nelson tí ó sì jẹ́ àìwọ́pọ̀ ṣùgbọ́n tí yíò tẹ̀síwájú bí a ti ṣètò. Henry B. EyringÌmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, Àádọ́rin Agbègbè, àti Olóyè GbogbogbòAlàgbà Eyring gbé àwọn Aláṣẹ Gbogbogbo, Àádọ́rin Agbègbè, àti Olóye Gbogbogbò ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn kalẹ̀ fún ìbò ìmúdúró. Gary E. StevensonAlábùkún-fún ni àwọn OnílàjàAlàgbà Stevenson kọ́ wa láti tẹ̀lé ìkìlọ̀ Olùgbàlà láti jẹ́ onílàjà—nínú ọkàn wa, ní ilé, àti ní àwọn ìletò wa. Tracy Y. BrowningYí Ọkàn Rẹ sí Jésù Krístì: Ẹ̀bùn Mímọ́ ti Orin Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀Arábìnrin Browning kọ́ni pé orin lè jẹ́rìí nípa Olùgbàlà kí ó sì kọ́ni ní àwọn òtítọ́ ìhìnrere pàtàkì tó le dúró pẹ̀lú wa fún gbogbo ọjọ́ ayé. Ronald M. BarcellosOlúwa Nwo ỌkànAlàgbà Barcellos pè wá láti fi ọkàn wa fún Olúwa nípa fífi arajì sí mímọ̀ọ́mọ̀ tẹ̀lé E si. Brik V. EyreMọ Ẹnití Ìwọ Jẹ́ Lóotọ́Alàgbà Eyre pín àwọn ọ̀nà méjì láti ní òye ohun tí ó túmọ̀ sí láti jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. Kelly R. JohnsonBá Ọlọ́run LàjàAlàgbà Johnson pè wá láti bá Ọlọ́run làjà nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì. Dieter F. UchtdorfṢe Ipa Tìrẹ Pẹ̀lú Gbogbo Ọkàn RẹAlàgbà Uchtdorf kọ́ni pé a níláti ṣiṣẹ́ láti ṣe ìmúdàgbà àwọn ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ti fún wa kí wọn lè bùkún wa àti àwọn ẹlòmíràn. Abala Ọ̀sán Sátidé Abala Ọ̀sán SátidéAbala Ọ̀sán Sátidé ti Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Ìkarùndinlọ́gọ́ọ̀wá Ìlàjì-ọlọ́dọdún ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn tí a ṣe ní Ọjọ́ ìkẹ́rin sí ikarun Oṣù Kẹwa, 2025. Ronald A. RasbandÌkede Ẹbí Náà—Àwọn Ọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́runAlàgbà Rasband pín àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ látinú ìkéde lórí ẹbí náà ó sì kọ́ni pé ìwé yí ní ìbẹ̀rẹ̀ àtọ̀runwá a sì níláti tọjú rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ tí a nfifún àwọn ọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Chad H WebbKí Ẹni Gbogbo Lè Di GbígbégaArákùnrin Webb kọ́ni bí a ti lè pe Ẹ̀mí Mímọ́ láti kọ́ wa ní àwọn òtítọ́ ìhìnrere. Jeremy R. JaggiÀwọn Ọkàn tó Nírẹ̀lẹ̀ Kúnlẹ̀ Níbi PẹpẹAlàgbà Jaggi kọ́ni pé a ó jẹ́ alábùkún fún bi a ti npa àwọn májẹ̀mú mọ́ tí a dá pẹ̀lú Ọlọ́run ní ibi àwọn pẹpẹ mímọ́. Kevin G. BrownẸ̀bun Ayérayé ti Ẹ̀ríAlàgbà Brown ṣàbápín àwọn òtítọ́ mẹ́ta tí ó sọ àwọn ẹ̀rí wa tí ó sì gbà wá níyànjú láti yàn làti gbàgbọ́ Gerrit W. GongKò Sí Ẹni Tí Ó Ndánìkan JokoAlàgbà Gong kọ́ni pé Olúwa npe gbogbo wa láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ àti láti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú ara wa nínú Ìjọ Rẹ̀. Michael CzieslaÌrọ̀rùn nínú KrístìAlàgbà Cziesla kọ́ni pé fífi ẹ̀kọ́ Kristi sílò ní ọ̀nà tí ó rọrùn yíò mú ayọ̀ wá, fún wa ní ìtọ́sọ́nà nínú àwọn ìpè wa, dáhùn àwọn ìbéèrè dídíjú jùlọ ní ìgbésí ayé, àti láti pèsè agbára. Quentin L. CookOlúwa Nyára Kánkán Ṣiṣẹ́ Rẹ̀Alàgbà Cook kọ́ni pé bí Olúwa ṣe nyára kánkán ṣiṣẹ́ Rẹ̀, a`wọn ọmọ Ìjọ ní ojúṣe kan láti tẹ́wọ́gbà kí wọ́n sì gba a`àwọn ọmọ ìjọ titun a`ti pípadàbọ̀ mọ́ra. Ó fi ìmọ́ràn fún àwọn ọmọ ìjọ titun àti pípadà bọ̀ Abala Ìrọ̀lẹ́ Sátidé Abala Ìrọ̀lẹ́ SátidéAbala Ọ̀sán Sátidé ti Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Ìkarùndinlọ́gọ́ọ̀wá Ìlàjì-ọlọ́dọdún ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn tí a ṣe ní Ọjọ́ ìkẹ́rin sí ikarun Oṣù Kẹwa, 2025. Patrick KearonJésù Krístì àti Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀tun YínAlàgbà Kearon jẹ́rìí sí i pé Jésù Krístì fún wa ní àwọn ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun—gẹ́gẹ́bí a ṣe nílò rẹ̀—nígbàtí ẹ̀ṣẹ̀, àìlera, tàbí ìjákulẹ̀ bá di ẹrù wọ̀ wá lọ́rùn. J. Anette DennisFífún Ara Wa NiyariArábìnrin Dennis nkọ́ni pé a ní ojúṣe májẹ̀mú láti fẹ́ràn arawa kí a sì tiraka fún ìṣọ̀kan. Steven C. Barlow“Ìwọ Ha Fẹ́ràn Mi Bí?”Alàgbà Barlow ṣe apèjúwe àwọn ọ̀nà tí a fi lè ṣe àfihàn ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run, èyítì ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti dá ìfẹ́ Rẹ̀ fún wa mọ̀. William K. JacksonRírántí ÀgùntànAlàgbà Jackson kọ́ni pé ó yẹ kí a dojúkọ sí ṣíṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú iṣẹ́ ìsìn wa nínú Ìjọ, ní títẹ̀lé àwọn ìlànà ti kíkà àti ìṣirò. Neil L. AndersenÈtùtù Ifẹ́ Jésù KrístìAlàgba Andersen kọ́ni nípa agbára Jésù Krístì láti mú ìdáríjì wá fún a`wọn tí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ a`ti ìwòsàn fún a`wọn tí wọ́n ti ní ìpalára nípa ẹ̀ṣẹ̀ ti àwọn ẹlòmíràn. Abala Òwúrọ̀ Ọjọ́-ìsinmi Abala Òwúrọ̀ Ọjọ́-ìsinmiAbala Òwúrọ̀ Ọjọ́-ìsinmi ti Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Ìkarùndinlọ́gọ́ọ̀wá Ìlàjì-ọlọ́dọdún ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn tí a ṣe ní Ọjọ́ ìkẹ́rin sí ikarun Oṣù Kẹwa, 2025. Jeffrey R. HollandÀti Nísisìyí Mo RíranÀàrẹ Holland kọ́ni pé gẹ́gẹ́bí Olúwa ti wo ọkùnrin afọ́jú kan sàn pẹ̀lú àdàpọ̀ amọ̀, Ó máa nfi ìgbà púpọ̀ lo àwọn ohun ìrẹ̀lẹ̀ tàbí tí kò wọ́pọ̀ láti bùkún àti láti kọ́ wa. James E. EvansonLọ kí o sì Ṣe BákannáàAlàgbà Evanson ṣàfihàn àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere oníṣẹ́ ìsìn ó sì kọ́ni bí iṣẹ́ ìsìn wọn ṣe nṣèrànwọ́ láti mú àwọn ènìyàn wá sọ́dọ̀ Krístì tí ó sì nfi àpẹrẹ lélẹ̀ fún wa. Ulisses SoaresṢe Lọ́ọ̀ṣọ́ pẹ̀lú Ìwà-rere ti Ìwọ̀ntún-wọ̀nsìAlàgbà Soares kọ́ni pé ìwọ̀ntún-wọ̀nsì nmú ìbámu àti okun wá fún àwọn ìhùwá bíiti Krístì. Ó npè wá láti tẹ̀lé àpẹrẹ Olùgbàlà kí a sì mú ìwà rere yí jẹ́ ara ti ìwà wa Peter M. JohnsonAgbára Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ sí Ẹni NáàAlàgbà Johnson kọ́ni pé nígbàtí a bá ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní àwọn ọ̀nà tí ó dárí sí ilé Olúwa, a nran ara wa lọ́wọ́ láti di ọmọ-ẹ̀hìn olùfọkànsìn ti Jesu Kristi. D. Todd ChristoffersonẸ Kọjúsí Ọlọ́run kí ẹ sì YèAlàgbà Christofferson kọ́ni pé wíwo Ọlọ́run nmú àwọn ìbùkún, pẹ̀lú ìṣerere àti ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ wá. Andrea Muñoz SpannausÀwọn Wòlíì Ọlọ́runArábìnrin Spannaus kọ́ni bí ìgbà èwe ṣe lè jèrè ẹ̀rí tiwọn nípa àwọn wòlíì Ọlọ́run alààyè. Henry B. EyringDídánwò àti Fífúnlókun nínú KrístìAlàgbà Eyring kọ́ni pé àwọn ìpèníjà wa le fún wa lókun bí a bá gbáralé Olùgbàlà tí a sì yípadà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Abala Ọ̀sán Ọjọ́-ìsinmi Abala Ọ̀sán Ọjọ́-ìsinmiAbala Ọ̀sán Ọjọ́-ìsinmi ti Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Ìkarùndinlọ́gọ́ọ̀wá Ìlàjì-ọlọ́dọdún ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn tí a ṣe ní Ọjọ́ ìkẹ́rin sí ikarun Oṣù Kẹwa, 2025. David A. BednarÀwọn Ni Onídàájọ́ Ara WọnAlàgbà Bednar ṣe àlàyé bí Ọjọ́ Ìdájọ́ ṣe lè jẹ́ ọjọ́ dídùnmọ́ni, ológo, sànju ọ̀kan tí a bẹ̀rù tàbí dídẹ́rùbà. B. Corey CuvelierOrúkọ Náà nípa Eyítí a Pè YínAlàgbà Cuvelier ṣàbápín ohun tí ó túmọ̀ sí láti gbé orúkọ Krístì lé arawa Matthew S. HollandẸ Máṣe Kọ̀ Àánú Ara Yín Sílẹ̀Alàgbà Holland kọ́ wa láti tẹ̀lé àpẹrẹ Jonah kí a sì pe ìyanu ìmísí àánú Krístì wá sínú ayé wa. Carlos A. GodoyÀwọn Ojú Ẹ̀rín àti Àwọn Ọkàn ÌmooreAlàgbà Godoy kọ́ni bí àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní Áfríkà ṣe ngbé pẹ̀lú ayọ̀ àti ìmoore láìka àwọn ìpèníjà sí nípa ìdojúkọ sí Olùgbàlà. Dale G. RenlundGbígba Orúkọ Jésù Krístì SóríAlàgbà Relund kọ́ni pé nígbàtí a bá gba orúkọ Krístì sórí arawa, a lè dà bíi Tirẹ̀. John D. AmosÌjúwe Ìròhìn RereAlàgbà Amos kọ́ni pé a lè rí ìdùnnú bía bá ṣe púpọ̀ ohun tí ó npe Jésù Krístì wá sínú ayé wa. Ozani FariasÌwé ti Mọ́mọ́nì—Ìṣúra Àìlódíwọ̀n Lórí Ìrìn Àjò WaAlàgbà Farias fúnni ní àbá mẹ́ta fún mímú ìyípadà wa sí Jésù Krístì jinlẹ̀ nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Dallin H. OaksẸbí Náà-Oókan Ìhìnrere Jésù KrístìÀàrẹ Oaks ṣe àlàyé ìdí tí ẹbí fi ṣe pàtàkì nínú ìhìnrere Jésù Krístì ó sì ṣe àpèjúwe àwọn ohun tí a lè ṣe láti fún àwọn ẹbí wa lókun.