Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ẹ Máṣe Kọ̀ Àánú Ara Yín Sílẹ̀
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwàá 2025


10:43

Ẹ Máṣe Kọ̀ Àánú Ara Yín Sílẹ̀

Ẹ ní ààyè kíákíá sí ìrànlọ́wọ́ àti ìwòsàn tọ̀run bíótilẹ̀jẹ́pé ẹ ní àwọn àlébù ènìyàn.

Olùkọ́ni-ilé-ẹ̀kọ́ kọ́ni nígbàkànrí pé erinmi kan—àní bí ó tilẹ̀ tóbi—kò lè gbé ẹnìkan mì nítorí àwọn erinmi ní ọ̀fun kékeré. Ọmọdébìnrin kan kọ̀jálẹ̀, “Ṣùgbọ́n Jonah ni a gbé mi nípasẹ̀ erinmi kan.” Olùkọ́ni náà fèsì, “Ìyẹn kò ṣeéṣe.” Ní àìgbàgbọ́, ọmọdébìnrin náà wípé, “Ó dára, nígbàtí mo bá dé ọ̀run, èmi yíò bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” Olùkọ́ni náà yínmú, “Bí Jonah bá jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò sì lọ sí ọ̀run nkọ́?” Ọmọdébìnrin náà dáhùn, “Nígbànáà ẹ lè bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀.”

A rẹrin, ṣùgbọ́n a kò níláti sọ agbára tí ìtàn Jonah fún gbogbo “onírẹ̀lẹ̀ olùwákiri ìdùnnú,” nípàtàkì àwọn tí wọ́n nlàkàkà nù.

Ọlọ́run pàṣẹ fún Jonah láti “lọ sí Nineveh” láti kéde ìrònúpìwàdà. Ṣùgbọ́n Nineveh ọ̀tá burúkú ti Ísráẹ́lì àtijọ́—nítorínáà Jonah lọ sí ọ̀nà míràn kíákíá, nípa ọkọ̀ ojù-omi, lọ sí Tarshish. Bí ó ti nlọ kúrò nínú ìpè rẹ̀, ìjì líle abọkọ̀-ojù-omi jẹ́ kan bẹ̀rẹ. Ó dájú pé àìgbọ́ran rẹ̀ ni ìdí náà, Jonah yọ̀ọ̀da láti di jíjù sọnù. Èyí mú òkun rírú náà rọlẹ̀, èyítí ó gba àwọn ẹlẹgbẹ́-ọkọ̀-ojú-omi là.

Pẹ̀lú ìyànu, Jonah yọ nínú ikú nígbàtí “ẹjà nlá” tí Olúwa “ti múrasílẹ̀” gbe mì. Ṣùgbọ́n ó kérora nínú òkùnkùn àìgbàgbọ́ náà àti ibi rírà fún ọjọ́ mẹ́ta títí tí ó fi jẹ́ títu jáde sórí ilẹ̀ gbígbẹ. Lẹ́hìnnáà ó tẹ́wọ́gba ìpè rẹ̀ lọ sí Nineveh. Síbẹ̀, nígbàtí ìlú náà ronúpìwàdà tí a sì dá wọn sí kúrò lọ́wọ́ ìparun, Jonah ní ìkùnsínú sí àánú tí a fihàn àwọn ọ̀tà. Ọlọ́run kọ́ Jonah pẹ̀lú sùúrù pé Òun fẹ́ràn àti pé òun nwá láti gba gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ là.

Ní kíkọsẹ̀ ju ìgbà kan lọ nínú ojúṣe rẹ̀, Jonah pèsè ẹ̀rí gbangba kan pé nínú ayé ikú, “Gbogbo ènìyàn ti Ṣubú.” À kìí sábá sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀rí ti Ìṣubú. Ṣùgbọ́n níní òye ti ẹ̀kọ́ àti ẹ̀rí ti ẹ̀mí nípa ìdí tí gbogbo ẹnìkọ̀ọ̀kan wa fi nlàkàkà pẹ̀lú ìhùwàsí, ti ara, àti ti ipò àwọn ìpènijà jẹ́ ìbùkún títóbi. Ní ìhín lórí ilẹ̀ ayé, koríko burúkú ndàgbà, àní àwọn egungun alágbára nkán, àti pé gbogbo ènìyàn “ti kùnà ògo Ọlọ́run.” Ṣùgbọ́n ipò ara yí—àbájáde àwọn yíyàn tí a ṣe nípasẹ̀ Ádámù àti Éfà—ṣe pàtàkì sí èrèdí gan tí a fi wà: “kí [a] lè ní ayọ̀”! Gẹ́gẹ́bí àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ti kọ́ ẹ̀kọ́, nípa dídán ìkorò wò àti níní ìmọ̀lára ìrora ìṣubú ayé nìkan ni a fi lè àní ní i, kí a tó sọpé gbígbádùn, ìdùnnú òtítọ́ níkàn

Ẹ̀rí kan nípa Ìṣubú fi àyè gba ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ìwà àìnáání nínú ojúṣe ìgbé ayé, èyítí ó pè nígbàgbogbo fún aápọn, ìwà rere, àti ìjíhìn. Ṣùgbọ́n ó níláti mú àwọn ìjákulẹ̀ wa rọlẹ̀ nígbàtí àwọn ohun kò bá lọ déédé tàbí tí a rí kíkùnà ìwà nínú ọmọ ẹbí kan, ọ̀rẹ́, tàbí aṣaàjú. Nígbàkugbà àwọn ohun bí èyí nmú wa yíràá nínú àtakò ìjà tàbí ikorira tí ó nmú ìgbàgbọ́ wa kúrò. Ṣu`gbọ́n ẹ̀rí dídúró ṣinṣin ti Ìṣubú lè ràn wá lọ́wọ́ láti dàbíi Ọlọ́run síi bí a ṣe júwe nípasẹ̀ Jonah, pé ó jẹ́, “aláàánú, lọ́ra sí ìbínú, àti inúrere nlá” sí gbogbo ènìyàn—pẹ̀lú arawa—nínú ipò àìyẹsẹ̀ àìpé wa.

Àní títóbiju fífi àyọrísí ti Ìṣubú hàn, ìtàn alágbára Jonah darí wa lọ sọ́dọ̀ Rẹ̀ ẹnití ó lè gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn àyọrísí wọnnì. Ẹbọ-ọrẹ araẹni ti Jonah láti gbá àwọn ẹlẹgbẹ́ ọkọ̀-ojú omi là jẹ́ bíiti Krístì lódodo. Àti pé ẹ̀ẹ̀mẹ́ta nígbàtí a bèèrè lọ́wọ́ Jésù fún àmì ìyanu kan nípa àtọ̀runwá Rẹ̀, Ó wípé “kò sí àmì tí a ó fúnni … ṣùgbọ́n àmì [Jonah] nìkan ni a ó fúnni,” ní kíkíyèsi pé bí Jonah ṣe wà “nínú ikùn erinmi náà fún ọjọ́ mẹ́ta àti òru mẹ́ta; bẹ́ẹ̀ náà ni Ọmọ ènìyàn yíò ṣe wà ní ọjọ́ mẹ́ta àti òru mẹ́ta ní oókan ilẹ̀ ayé.” Gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ ikú ti ìrúbọ Olùgbàlà àti Àjíìnde ológo, Jonah lè ní àṣìṣe. Ṣùgbọ́n bákannáà èyí jẹ́ ohun tí ó mú ẹ̀rí rẹ̀ ti araẹni nípa àti ìfarajì sí Jésù Krístì, fúnni nínú ikùn ti erinmi, jẹ́ pàtàkì àti oníìmísí.

Ìgbe Jonah ni ti ọkùnrin rere kan nínú aáwọ̀, ọ̀kan tí ó jẹ́ nípa ṣíṣe rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀. Fún ènìyàn mímọ́, nígbàtí àjálù bá wá nípa ìhùwà àbámọ̀ kan, àsọyé tàbí, ìpinnu, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èròngbà rere míràn gan àti ìtara ìtiraka òdodo, nípàtàkì ó lè di rírún kí ó sì fi ẹnìkan sílẹ̀ ní níní ìmọ̀lára ìkọ̀sílẹ̀. Ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó fàá tàbí oye àjálù tí a kojú, ìlẹ̀ gbígbẹ wà nígbàgbogbo fún ìrètí, ìwòsàn, àti ìdùnnú. Ẹ Fetísílẹ̀ sí Jonah:

“Èmi kígbè nítorí ìpọ́njú mi sí Olúwa … ; látinú ipò òkú ni mo kígbe. …

“Nítorítí ìwọ ti sọ mi sínú ibú, ní àárín òkun; …

“[Àti pé] mo wípé, A tà mí nù kúrò níwájú rẹ̀; ṣùgbọ́n èmi ó tún máa wo ìhà tẹ́mpìlì mímọ́ rẹ̀.

“Omi yí mi káàkiri, àní títí dé ọkàn: ibú yí mi káàkiri, a fi koríkò odò wé orí mi.

“Èmi sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ àwọn òkè nlá; … ṣùgbọ́n ìwọ ti mú ẹ̀mí mi wá sókè látinú ibú wá. …

“Nígbàtí ó rẹ ọkàn mi … èmi rántí Olúwa: àdúrà mi sì wá … sínú tẹ́mpìlì mímọ́ rẹ̀.

“Àwọn tí nkíyèsí èké lásán kọ àánú ara wọn sílẹ̀.

“Ṣùgbọ́n èmì ó fi ohun ìdúpẹ́ rúbọ̀ sí ọ èmi ó san ẹ̀jẹ́ tí mo ti jẹ́. Ti Olúwa ni ìgbàlà.”

Bíótilẹ̀jẹ́pé ó ti jẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ́ ọdún sẹ́hìn, mo lè wí fún yín déédé nibití mo joko sí, àti déédé ohun tí mo ní ìmọ̀lára, nígbàtí, mo wà nínú ibú ipò-òkú, èmi ṣe àwárí ìwé mímọ́ yí. Fún ẹnikẹ́ni ní òní tí ó bá ní ìmọ̀lára bí mo ti ṣe nígbànáà—tí a tì yín sọnù, sínú ibú omi, pẹ̀lú koríkò òkun tí a wé mọ́ orí yín tí òkè òkun nṣẹ́ yí yín káàkiri—ẹ̀bẹ̀ mi, ti a mísíni nípasẹ̀ Jonah, ni pé Ẹ máṣe kọ àánú tì yín sílẹ̀. Ẹ ní ààyè kíákíá sí ìrànlọ́wọ́ àti ìwòsàn tọ̀run bíótilẹ̀jẹ́pé ẹ ní àwọn àlébù ènìyàn. Àánú ìmísí ìyanu yí nwá láti inú àti nípasẹ̀ Jésù Krístì. Nítorí Ó mọ̀ ó sì ní ìfẹ́ yín ní pípé, Ó nfi i fún yín bíi ìtumọ̀ “arayín,” tí ó bá yín mu ní pípé, tí a ṣe láti ràn ìkọ̀ọ̀kan yín lọ́wọ́ nínú àwọn ìjẹ̀rora kí ó sì wo àwọn ìrora yín ní pàtó sàn. Nítorínáà, nítorí tọ̀run àti ti yín, ẹ máṣe kọ ẹ̀hìn yín padà lórí ìyẹn. Ẹ tẹ́wọ́gbà á. Ẹ bẹ̀rẹ̀ nípa kíkọ̀ láti fetísílẹ̀ sí “Àwọn ẹ̀tàn irọ́” ti ọ̀tà tí yíò dán an yín wò ní rírò pé ìrànlọ́wọ́ náà ni à nrí nínú sísọdá kúrò nínú àwọn ojúṣe ti ẹ̀mí yín. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹ tẹ̀lé ìdarí náà nípa Jonah olùronúpìwàdà. Ẹ kígbe sí Ọlọ́run. Ẹ yípadà sí tẹ́mpìlì. Ẹ rọ̀mọ́ àwọn májẹ̀mú yín. Ẹ sin Olúwa, Ìjọ Rẹ̀, àti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú ẹbọ ọrẹ àti dídúpẹ́.

Ṣíṣe àwọn ohun wọ̀nyí nmú ìran pàtàkì ti májẹ̀mú ìfẹ́ Ọlọ́run wá fún yín—ohun tí Bíbélì Hébérù pè ní hesed. Ẹ yíò rí ẹ ó sì ní ìmọ̀lára agbára ìṣòdodo Ọlọ́run, àìlágara, àìṣàárẹ̀, àti “ìrọ́nú àánú” tí ó lè mú yín “lágbára… sí … ìtúsílẹ̀” látinú ẹ̀ṣẹ̀ eyikeyi tàbí ìfàsẹ́hìn eyikeyi. Ìrora kùtùkùtù àti líle lè mú ìkuùkù bá ìran náà ní àkọ́kọ́. Ṣùgbọ́n bí ẹ ti ntẹ̀síwájú láti “sàn èyítí [ẹ] ti jẹ́ ẹ̀jẹ́,” irú ìràn bẹ́ẹ̀ yíò tan ìmọ́lẹ̀ dídán yíò sì dán síi nínú ọkàn yín Àti pé pẹ̀lú ìràn náà ẹ kò ní rí ìrètí àti ìwòsàn nìkàn ṣùgbọ́n, pẹ̀lú ìyanilẹ́nu, ẹ ó rí ayọ̀, àní ní àárín ìkorò yín. Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ wa dáadáa pé: “Nígbàtí ìfojúsí ti ìgbésí ayé wa bá wà lórí ètò ìgbàlà Ọlọ́run … àti Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ, a lè ní ìmọ̀lára ayọ̀ láìkà ohun tó nṣẹlẹ̀ sí—tàbí tí kò ṣẹlẹ̀—nínú ìgbésí ayé wa. Ayọ̀ nwá láti ọ̀dọ̀ àti nítorí Rẹ̀.”

Bóyá a ndojúkọ àjálù jíjìnlẹ̀ kan, bíiti Jonah, tàbí àwọn ìpènijà ojoojúmọ́ ti ayé àìpé wa, ìfipè náà ni ọ̀kannáà: Ẹ máṣe kọ àánú tiyín sílẹ̀. Ẹ wo àmì ti Jonah, Krístì alààyè, Ẹnití ó dìde kúrò nínú ibojì Rẹ̀ ọjọ́ mẹ́ta ní ṣíṣẹ́gun gbogbo rẹ̀fún yín. Ẹ yípadà sí I. Ẹ gbàgbọ́ nínú Rẹ̀. Ẹ Sìn In. Ẹ rẹrin músẹ́. Nítori nínú Rẹ̀, àti Tirẹ̀ nìkan, ni à nrí ìwòsàn ìdùnnú kíkún látinú Ìṣubú tí gbogbo wa nfi kánmọ́kánmọ́ nílò gan tí a sì nwá pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé òtítọ́ ni. Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Álmà 27:18. Ẹsẹ méjìdínláàdọ́ta péré ní àpapọ̀, ìwé ti Jonah ni a fúnpọ̀, ewì ọ̀wọ̀wọ́ ti oríṣiríṣi àwọn òtítọ́ àti ẹ̀kọ́ ti ẹ̀mí. Wo Ellis T. Rasmussen, Àsọyé Ènìyàn Mímọ́ Kan lórí Májẹ̀mú Láéláé (1993), 653–57; D. Kelly Ogden àti Andrew C. Skinner, Ẹsẹ sí Ẹsẹ: Májẹ̀mú Láéláé, vol. 2, 1 Kings Nípasẹ̀ Málákì (2013), 133–38. Ogden àti Skinner kíyèsi pé nítorí agbára àwọn ìkọ́ni ìrònúpìwàdà nínú Ìwé Jonah, ó jẹ́ “kíkà nínú àwọn sínágọ́gù ní ọjọ́ mímọ́jùlọ ti ọdún fún àwọn ènìyàn Júù—Ọjọ́ Ètùtù, tàbí Yom Kippur—bákannáà èyí tí ó dálé orí ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì.”

  2. Wo Ogden àti Skinner, Ẹsẹ sí Ẹsẹ: Májẹ̀mú láéláé, 134.

  3. Wo Jonah 1–4.

  4. Álmà 34:32.

  5. Rómù 3:23.

  6. Wo 2 Nefi 2:17–25.

  7. Jonah 4:2.

  8. Wo Lúkù 11:29–30; bákannáà wo Matteu 12:39–41; 16:1–4.

  9. Jonah 2 jẹ́ ẹ̀rí àtẹ̀hìnwá àti ìwé-orin ti àwọn ọpẹ́, ọ̀pọ̀ ti èyí tí ó ṣe àpèjúwe àdúrà Jonah látinú ikùn erinmi.

  10. Ní ọ̀nà yí, Jonah yàtọ̀ sí ẹnìkan bí Jóbù, ẹnití ó farahàn ní dídàbí aláìmọ̀kan pẹ̀lú ọ̀wọ̀ sí ìjìyà tí ó wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Méjèjì ni àwọn ìtàn ìgbàgbọ́ àti lílókun ní ojú àjálù, ṣùgbọ́n ti Jonah lè wà ní ìbámu jùlọ fún àwọn wọnnì tí wọ́n rò pé ìṣe ti ara wọn ni orísun ìrora àti ìjákulẹ̀.

  11. Ó dájú fún Joseph Smith nígbàtí ìrọ́nú àtọkànwá àti ìmoore fún olóore rẹ̀ Martin Harris darí rẹ̀ láti pín ojú-ewé 116 iyebíye ìyírọ̀padà Iwé ti Mọ́mọ́nì tí ó sọnù nígbànáà, which caused Joseph to wail, “Gbogbo rẹ̀ ti sọnù” (wo Àwọn Ènìyàn Mímọ́: Ìtàn Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, vol. 1, Òṣùwọ̀n Òtítọ́, 1815–1846 [2018], 43–53)

  12. Jonah 2:2–9; àfikún àtẹnumọ́.

  13. 1 Néfì 1:20; wo Russell M. Nelson, “Májẹ̀mú Àìlópin Náà,” Làìhónà, Oṣù Kẹwa. 2022, 6, 10. Ojúlówó ọ̀rọ̀ Hébérù fún àánú nínú Jonah 2 ni hesed, eyí tí Ààrẹ Nelson ṣe àlàyé pé ó jẹ́ “irú ìfẹ́ àti àánú pàtàkì” fún àwọn ẹni tí wọ́n dá májẹ̀mú—àánú tí ó ṣe àlàyé pé ó jẹ́ ìṣòdodo, àìlágara, àti àìṣàárẹ̀.

  14. Russell M. Nelson, “Ayọ̀ àti Ìtúsílẹ̀ Ti Ẹ̀mí,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá 2016, 82.