Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Alábùkún-fún ni àwọn Onílàjà
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwàá 2025


13:16

Alábùkún-fún ni àwọn Onílàjà

Lílàjà ṣì nbẹ̀rẹ̀ ní ibi tó jẹ́ kókó jùlọ—inú ọkàn wa. Lẹ́hìnnáà nínú ilé àti ẹbí wa.

Ẹ káàbọ̀ sí ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò. Bí ìmoore wa ti tó láti kórajọ.

Bí a ti ngbèrò àwọn ìtẹ̀síwájú ìpàdé àpapọ̀ wọ̀nyí, a ní ìfura déédé nípa àwọn ọ̀sẹ̀ tí ó ti darí sí i. A damọ̀ pé ọkàn wa nṣọ̀fọ̀ àdánù, àti pé àwọn kàn ní ìmọ̀lára àìnírètí tí ó nwá nípa ìjà tàbí àjálù káàkiri àgbáyé. Àní àwọn ẹ̀nìyàn olùfọkànsìn kórajọ̀ níní àwọn ibi mímọ́—pẹ̀lú ìlé-ìjọsìn yíyàsímímọ́ wa ní Michigan—ti sọ ìgbé ayé wọn tàbí àwọn olúlùfẹ́ nù. Èmi sọ̀rọ̀ látinú ọkàn mi, ní ìdámọ̀ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára ọkàn yín ngbé ẹ̀rù nípa ohun tí ẹ̀yin, ẹbí yín, àti ayé wa ti làkọjá látigbà ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò tó kọjá.

Kapernáúmù ní Gálílì

Ròó pẹ̀lú mi pé ẹ jẹ́ ọ̀dọ́mọdé ọ̀dọ́ kan ní Kapernáúmù, nítòsí Òkun Gálílì, ní àkokò iṣẹ́ ìránṣẹ́ Jésù Krístì. Ọ̀rọ̀ tànká nípa rábbí kan—olùkọ́ni kan—ẹnití ọ̀rọ̀ rẹ̀ nfá ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn súnmọ́. Awọ̀n aladugbo ṣètò láti rin ìrìnàjò lọ sí orí òkè ní àìbojúwò òkun láti gbọ́ Ọ.

Ẹ darapọ̀ mọ́ àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n nrìn ní ọ̀nà eruku ti Gálílì. Ní dídé, ọ̀pọ̀ èrò kórajọ láti gbọ́ Jésù yí ní yíyà yín lẹ́nu. Àwọn kan sọ̀rọ̀ jẹ́jẹ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, “Mèssíàh.”

Ẹ fetísílẹ̀. Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ fọwọ́kàn ọkàn yín. Ní ìrìn gigùn lọ sílé, ẹ yàn dídákẹ́ lórí ìbárasọ̀rọ̀.

Ẹ̀ njíròrò àwọn ohun ìyanu—àwọn ohun tó tayọ àní kọjá òfin Mósè. Ó sọ̀rọ̀ nípa yíyí ẹ̀rẹ̀kẹ́ míràn àti fífẹ́ràn àwọn ọ̀tá wa. Ó ṣe ìlérí, “Alábùkúnfún ni àwọn onílàjà: nítorí ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè wọ́n.”

Nínú ìṣòdodo yín, bí ẹ ṣe nní ìmọ̀lára ìwọ̀n ti àwọn ọjọ́ líle—àìdánilójú àti ẹ̀rù—àlàáfíà ndàbí ó jìnnà.

Ìgbésẹ̀ yín nyára, ẹ dé ìlé ní àìní èémí. Ẹbí yín kórajọ́, baba yín bèèrè, “Sọ fún wa ohun tí o gbọ́ tí o sì mọ̀lára.”

Ẹ̀ nṣe àbápín pé Ó pè yín láti jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín tàn níwájú àwọn ẹlòmíràn, láti wá òdodo àní nígbàtí a njẹ́ ṣíṣe inínubíni sí. Ohùn yín ndún bí ẹ ti ntunsọ: “Alábùnkúnfún ni àwọn onílàjà nítorí ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè wọ́n.”

Ẹ bèèrè, “Ṣe èmi lè di onílàjà ní òtítọ́ nígbàtí ayé wà ní ìrúkèrúdò, nígbàtí ọkàn mi kún pẹ̀lú ẹ̀rù, àti nígbàtí àlàáfíà dàbí ó jìnnà gidi gan?”

Baba yín wò ìyá yín ó sì dáhùn jẹ́jẹ́, “Bẹ́ẹ̀ni. A bẹ̀rẹ̀ ní ibi tó jẹ́ kókó jùlọ—inú ọkàn wa. Lẹ́hìnnáà nínú ilé àti ẹbí wa. Bí a ṣe ngbáradì nibẹ̀, lílàjà lè tànká sí àwọn òpópónà àti ìletò wa.”

Ṣísí Iwájú Ẹgbẹ̀rún Méjì ọdún

Ṣísí Iwájú Ẹgbẹ̀rún Méjì ọdún. Kò sí ìnílò láti ròó—èyí jẹ́ ìṣòdodo wa. Bíotilẹ̀jẹ́pé àwọn ìtẹ̀mọ́ra ti ìmọ̀lára nípa àwọn ìran tó ndìde ní òní yàtọ̀ sí àwọn ọ̀dọ́ ènìyàn ní Gálílì—tọ̀túntòsìn, ìkẹ́ẹ̀kọ́, gbígbẹ̀san, ìrunú ọ̀nà, ìbínú, àti àkópọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ ìròhìn àwùjọ—méjèèjì àwọn ìran ndojúkọ àwọn ọ̀làjú ti ìjà àti ẹ̀dọ̀fú.

Pẹ̀lú ìmoore, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin wa bákannáà fà súnmọ́ Ìwàásù wọn lórí Òkè ní àkokò—ti sẹ́minárì, Àwọn ìpàdé àpapọ̀ Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, àti Wá, Tẹ̀lẹ́ Mi Ní ìhín wọ́n gba àwọn ìfipè ìforítì kannáà láti ọ̀dọ̀ Olúwa: láti jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wọn tàn níwájú àwọn ẹlòmíràn, láti wá òdodo àní nígbàtí a bá jẹ́ ṣíṣe inúnibíni si, àti láti fẹ́ràn àwọn ọ̀tá wọn.

Bákannáà wọ́n gba àwọn ọ̀rọ̀ ìgbàni-níyànjú láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì alààyè ti Ìmúpadàsípò: “A Nílò àwọn Onílàjà.” Má faramọ́ láì di aláìfaramọ́. Rọ́pò ìjà àti ìgbéraga pẹ̀lú ìdáríjì àti ìfẹ́. Kíkọ àwọn afárá bíbáré àti níní òye, kìí ṣe àwọn ògiri ẹ̀tanú tàbí yíyàsọ́tọ̀. Àti pé ìlérí kannáà: “Alábùkúnfún ni àwọn onílàjà: nítorí ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè wọ́n.”

Ọkàn àwọn ìràn tí ó ndìde ní òní kún fún ẹ̀rí kan nípa Jésù Krístì àti ìrètí fún ọjọ́ ọ̀la. Síbẹ̀ wọ́n bèèrè pẹ̀lú, “Ṣe èmi lè di onílàjà ní òtítọ́ nígbàtí ayé wà ní ìrúkèrúdò, nígbàtí ọkàn mi kún pẹ̀lú ẹ̀rù, àti tí àlàáfíà dàbí ó jìnnà gidi gan?”

Èsì àtúnsọ náà lẹ́ẹ̀kansi ni bẹ́ẹ̀ni! A ó di àwọn ọ̀rọ̀ Olùgbàlà tí ó jẹ́ ìtumọ̀ otítọ́ gan mú nígbàtí Ó sọ pé: “Àláfíà ni mo fi sílẹ̀ fún yín, àláfíà mi ni mo fún yín. … Ẹ máṣe jẹ́ kí ọkàn yín kí ó dàrú, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí ó wárìrì.”

Lílàjà ṣì nbẹ̀rẹ̀ ní ibi tó jẹ́ kókó jùlọ—inú ọkàn wa. Lẹ́hìnnáà nínú ilé àti ẹbí wa. Bí a ṣe ngbáradì nibẹ̀, lílàjà lè tànká sí àwọn òpópónà àti ìletò wa.”

Ẹ jẹ́ kí á gbèrò àwọn ibi mẹ́tà wọ̀nyí síwájú síi níbití àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn òde-òní tí nmú àlááfíà wá.

Lílàjà nínú ọkàn wa

Àkọ́kọ́ wà nínú ọkàn wa. Ohun èlò rírí kan nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ Krístì ṣe àpèjúwe bí àwọn ọmọ ṣe nfà súnmọ́ Ọ. Nihin ni olobó kan. Wíwo inú ọkàn ọmọ kan onílàjà mímọ́ àti aláìmọ̀kan lè jẹ́ ìmísí fún ọkàn wa. Ní ìhín ni bí oríṣiríṣi àwọn ọmọ ọjọ́ orí Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti dáhùn “Kíni ó dàbí láti jẹ́ onílàjà?”

Mo pín àwọn èsì wọn tààrà láti ọkàn wọn! Lúkù wípé, “Ẹ ran àwọn ẹlòmírán lọ́wọ́ nígbàgbogbo.” Grace pín bí ó ti ṣe pàtàkì tó láti foríjì ara wa, àní nígbàtí kò dàbí ó dára. Anna wípé, “mo rí ẹnìkan tí kò ní ẹnìkankan láti bá ṣeré, nítorínáà mo lọ láti ba ṣeré.” Lindy ronú pé láti jẹ́ onílàjà ni láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. “Nígbànáà ẹ gbé e síwájú. Yíò sì tẹ̀síwájú ní lílọ àti lílọ si.” Liam wípéd, “Ẹ máṣe kanra sí áwọn ènìyàn, àní bí wọ́n tilẹ̀ kanra mọ́ yín.” London kígbe, “Bí ẹnìkan bá pẹ̀gàn yín tàbí kanra sí yín, ẹ ó wípé, ‘Jọ̀wọ́ dúró.’” Trevor ṣe àkíyèsí, “Bí kò bá sí dónọtù tó kù tí gbogbo yín sì fẹ́ ẹ, ẹ pin.”

Ìfèsì àwọn ọmọ wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀rí sí mi pé gbogbo wa ni a bí pẹ̀lú àwọn ìrò àtọ̀runwá síwájú inúrere àti àánú. Ìhìnrere Jésù Krístì nṣìkẹ́ ó sì nso ète àtọ̀runwá wọ̀nyí pọ̀, pẹ̀lú onílàjà, sínú ọkàn wa, ní bíbùkún wa nínú ayé yí àti tí ó nbọ̀.

Lílàjà ní Ilé

Ìkejì, gbígbé lílàjà ga nínú ilé wa nípa lílo àwòṣe Ọlọ́run sí ipa àwọn ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú ara wa: ìyílọ́kànpadà, mú sùúrù, ìwà-pẹ̀lẹ́, inúrere, ìwà-tútù, àti ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn.

Ní ìhín ni ìtàn ìmísí tí ó ṣe àpèjúwe bí ẹbí kan ṣe mú lílàjà jẹ́ ọ̀ràn ẹbí kan, ní fífi àwọn ìpílẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ wọ̀nyí sínú ìṣe.

Àwọn ọmọdé nínú ẹbí yí làkàkà nínú ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àgbàlàgbà kan ẹnití ìrísí rẹ̀ máa nkanra nígbàkugbà, rírẹlẹ̀, àti ránpẹ́. Àwọn ọmọdé náà, ní ìpalàra àti ìjákulẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ronú bí ọ̀nàkanṣoṣo náà síwájú bá jẹ́ láti tún ẹ̀mí ìwà ìkanra kannáà ṣe

Ní ìrọ̀lẹ́ kan ẹbí náà kórajọ yíka tábìlì oúnjẹ́ alẹ́ wọ́n nsọ̀rọ̀ gbàngba nípa irunú àti ohun tí ó nfà. Nígbànáà èrò kan jáde—kìí ṣe ìyanjú kan ṣùgbọ́n àyẹ̀wò kan.

Dípò fífèsì pẹ̀lú dídákẹ́ tàbí sísanpadà, àwọn ọmọ náà yíò ṣe ohunkan àìròtẹ́lẹ̀: wọn yíò fèsì pẹ̀lú inúrere. Kìí ṣe ìdẹ́kun ọ̀wọ̀ lásán ṣùgbọ́n mímọ̀ọ̀mọ́, ìtújáde àwọn ọ̀rọ̀ rere àti iṣe ọlọ́gbọ́n àtọkànwá, bíótiwù kí a ṣe sí wọ́n ní àbábọ̀. Gbogbo wọn faramọ láti gbìyànjú rẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, lẹ́hìn èyí tí wọ́n padà-pẹ́jọ tí wọ́n sì ròó.

Bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn kan lọ́ra ní àkọ́kọ́, wọn farajì láti ṣètò pẹ̀lú ọkàn òtítọ́.

Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ tẹ̀le kìí ṣe ohunkóhun tí ó dínkù ní lílápẹrẹ.

Ìbáraṣe àìdára bẹ̀rẹsí rẹlẹ̀. Ẹ̀rín músẹ́ nrọ́pò ìbojújẹ́. Àgbàlagbà náà, tí ó ti jìnnà tí ó sì nira, bẹ̀rẹ̀ sí nyípadà. Àwọn ọmọ náà, tí a ró lágbára nípa yíyàn wọn láti darí pẹ̀lú ìfẹ́, rí ayọ̀ nínú ìyípadà wọn. Yíyípadà náà jẹ́ ìjìnlẹ̀ gidi tí wọn kò nílò ìṣètò ìpàdé tó tẹ̀lè e. Inúrere ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ jẹ́jẹ́.

Ní àkokò, wọ́n ti dá ìsopọ̀ òtitọ́ ìbáṣọ̀rẹ́ sílẹ̀, ní gbígbé gbogbo ènìyàn ga. Láti jẹ́ onílàjà, à ndáríji àwọn ẹlòmíràn a sì nmọ̀ọ́mọ́ gbé àwọn ẹlòmíràn ga dípò fífà wọ́n sílẹ̀.

Lílàjà nínú àwọn Ìletò Wa

Ìkẹ́ta, lílàjà nínú àwọn ìletò wa. Nínú ìdàmú àwọn ọdún Ogun Àgbáyé Kejì Alàgbà John A. Widstoe kọ́ni pé: “Ọ̀nà kanṣoṣo láti kọ́ ìlètò alálàáfíà ni láti gbé àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ́ olólùfẹ́ àti olùṣe alàáfíà ga. Olúkúlùkù ẹnìkọ̀ọ̀kan, nípa ẹ̀kọ́ ti Krístì náà … ndi àlááfíà ti [gbogbo] ayé mú ní ọwọ́ rẹ̀.”

Ìtàn tí ó tẹ̀le ṣe ìjúwe ti ìlànà náà dáradára.

Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn, àwọn ọkùnrin méjì—Ìmámù Mùsùlùmí kan àti Olùṣọ́-àgùtàn Krìstẹ́nì kan láti Nigeria—dúró ní ẹ̀gbẹ̀ẹ́gbẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti ìpinyà ẹ̀sìn onírora. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ti jìyà jíjinlẹ̀ gan. Àti pé síbẹ̀, nípasẹ̀ agbára ìwòsàn ìdáríjì, wọ́n yàn láti rin ipa-ọ̀nà kan papọ̀.

Olùṣọ́-àgùtàn James Wuye àti Ìmámù Muhammad Ashafa

Ìmámù Muhammad Ashafa àti Olùṣọ́-àgùtàn James Wuye di ọ̀rẹ́ àti àìdàbí olùbáṣepọ̀ nínú àlàáfíà. Lápapọ̀, wọ́n gbé gbàgede fún ìlàjà onírúurú ẹ̀sìn kalẹ̀. Nísisìyí wọ́n nkọ́ ara wọn láti rọ́pò ikorira pẹ̀lú ìrètí. Bí àwọn tí a yàn ní ìgbà mejì fún Ìfúnni lọ́wọ́ Oye Àlàáfíà, láìpẹ́ wọ́n di olùgbà idanilẹkọ ti Oye Àlàáfíà Commonwealth.

Àwọn ọ̀tá tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ nísisìyí nrin ìrìnàjò lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ní títúnṣe ohun tó ti bàjẹ́, àwọn ẹlẹ́rìí alààyè pé ìfipè Olùgbàlà láti jẹ́ onílàjà kò ṣeéṣe nìkan—ó jẹ́ alágbára.

Nígbàtí a bá wá láti mọ ògo Ọlọ́run, nígbànáà a “kò ní ní ọkàn láti pa ara wa lára, ṣùgbọ́n láti gbé ní àlàáfíà.” Nínú àwọn ìjọ wa àti ní ìletò wa, a lè yàn láti rí ara wa bí àwọn ọmọ Ọlọ́run.

Ètò Kan Fún Onílàjà Ọ̀sẹ̀ Kan

Ní àkópọ̀, mo fi ìfipè kan fúnni. Lílàjà bèèrè fún ìṣe—kíni ohun tí èyí lè jẹ́, fún ẹnìkọ̀ọ̀kan lára wa, bíbẹ̀rẹ̀ ní ọ̀la? Njẹ́ ẹ yíò gbèrò ètò kan, ìgbésẹ̀ mẹ́ta onílàjà ọ̀sẹ̀-kan?

  1. Àyíká ilé kan tí kò ní ìjà: Nígbàtí ìjà bá bẹ̀rẹ̀, ẹ dáwọ́dúró kí ẹ sì ṣe àtúnbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe rere.

  2. Ṣíṣe Àtúnṣe Díjítà: Ṣíwájú lílẹ̀, dídáhùn, tàbí sísọ̀rọ̀ lórí ayélujára, bèèrè, “Ṣé èyí yíò ṣe àtúnṣe?” Bíbẹ́ẹ̀kọ́, dúró. Máṣe fi ránṣẹ́. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣàbápín inúrere Gbé àlàáfíà jáde ní ipò ikorira.

  3. Ẹ ṣe àtúnṣe kí ẹ sì ṣe àtún-dàpọ̀: Ọmọ ẹbí kọ̀ọ̀kan lè wá ìbáṣepọ̀ bíbàjẹ́ jáde ní èrò láti bẹ̀bẹ̀, ṣe iṣẹ́ ìrànṣẹ́, ṣe àtúnṣe, kí ẹ sì ṣe àtún dàpọ̀.

Íparí

Ó ti jẹ́ bíi oṣù díẹ̀ látigbà tí mo ti ní ìmọ̀lára ìwọ̀lọ́kàn àìlèsẹ́ kan sí ọ̀rọ̀ yí: “Alábùkún-fún ni àwọn Onílàjà.” Ní ìparí, njẹ́ kí npín àwọn ìwọ̀lọ́kàn tí ó ti tẹ̀ mọ́ ọkàn mi ní àkokò díẹ̀.

Lílàjà ni ìhùwàsí bíiti Krístì. Àwọn onílàjà nígbàmíràn ni a kàsí aláìmọ̀ àti aláìlera—ní gbogbo ọ̀nà. Síbẹ̀, láti jẹ́ onílájà kìí ṣe láti jẹ́ aláìlera ṣùgbọ́n láti lágbára ni ọ̀nà kan tí ayé lè mátilẹ̀ mọ̀. Lílàjà bèèrè fún ìgboyà àti ṣíṣe ìbámu ṣùgbọ́n kò bèèrè fún ìrúbọ ìkóraẹni-níjánu. Lílàjà ni láti darí pẹ̀lú ọkàn ṣíṣí, kìí ṣe pípa ọkàn mọ́. Ó jẹ́ láti dé ọ̀dọ̀ ara wa pẹ̀lú nínawọ́ jáde, kìí ṣe dídi ọwọ́. Lílàjà kìí ṣe ohun titun kan, tí kò sí nínú ìròhìn. A kọ́ni nípasẹ̀ Jésù Krístì Fúnrarẹ, méjèèjì sí àwọn wọnnì nínú Bíbélì àti sí Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Lílàjà ni a ti kọ́ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ àwọn wòlíì òde-òní láti àwọn ọjọ́ ìṣíwájú ti Ìmúpadàbọ̀sípò àní di òní.

À nmú ojúṣe àtọ̀runwá ṣẹ bí àwọn ọmọ olùfẹ́ni Baba Ọ̀run bí a ti ntiraka láti di onílàjà. Mo jẹ́ ẹ̀rí nípa Jésù Krístì, ẹnití ó jẹ́ Aládé Àlááfíà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè, ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.