Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Gbígba Orúkọ Jésù Krístì Sórí
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwàá 2025


13:22

Gbígba Orúkọ Jésù Krístì Sórí

Bí a bá nṣe ndi-ọ̀kannáà pẹ̀lú tí a sì nrántí Jésù Krístì, bẹ́ẹ̀náà ni a ó fẹ́ láti dà bíi Rẹ̀ síi.

Ní 2018, ní Unifásítì ti Utah, ipò-ọ̀jọ̀gbọ́n pàtàkì kan ni a dá sílẹ̀ tí a pè ní “Dókítà. Russell M. Nelson àti Dantzel W. Nelson Alága ti Ààrẹ Iṣẹ́-abẹ Ọkàn-àyà”—kádíò, túmọ̀sí ọkàn, àti pé tòrásíkì, túmọ̀sí àyà. Ó bu-ọlá fún iṣẹ́ pàtàkì Ààrẹ Nelson bí oníṣẹ́-abẹ ọkàn àti àtìlẹhìn tí ó gbà láti ọwọ́ olóògbé aya rẹ̀, Dantzel. Ipò-ọ̀jọ̀gbọ́n yí ni a nsànwó fún nípa owó kan tí a ṣe láti pẹ́ títí di ọjọ́ iwájú. Olúkúlùkù tí a yàn fún irú ipò-ọ̀jọ̀gbọ́n ọlọ́lá yí gba ììdánimọ̀, àtìlẹhìn owo-oṣù, àti owo ìwáàdí.

Dókíta. Selzmanpẹ̀lú Ààrẹ Nelson

Oníṣẹ́-abẹ àkọ́kọ́ tí a yàn láti di ipò-ọ̀jọ̀gbọ́n náà mú ni Dókítà. Craig H. Selzman, akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ oníṣẹ́-abẹ ọkàn tí kìí ṣe ọmọ Ìjọ wa. Ní ibi ayẹyẹ láti fúnni ní ipò-ọ̀jọ̀gbọ́n yí fún Dókítà. Selzman, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àlejò pàtàkì wà ní ijoko, pẹ̀lú Ààrẹ Nelson àti aya rẹ̀, Arábìnrin Wendy W. Nelson. Nínú ìpàdé náà, Ààrẹ Nelson sọ̀rọ̀ ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì nípa jíjẹ́ olùlànà iṣẹ́ abẹ rẹ̀.

Nígbàtí Dókítà. Selzman pín ohun tí ó túmọ̀ sí fun láti jẹ́ yíyàn sí ipò-ọ̀jọ̀gbọ́n yí. Ó gbé iyẹn yẹ̀wò ní ọjọ́ mẹ́rin ṣíwájú, lẹ́hìn pípẹ́ ọjọ́ nínú yàrá iṣẹ́-abẹ, ó ri pé ọ̀kàn lára àwọn aláìsàn rẹ̀ nílò láti padà síbi iṣẹ́-abẹ. Ó ti rẹ̀ẹ́ ó sì ní ìjákulẹ̀, ní mímọ̀ pé òun yíò ní láti lo alẹ́ míràn nínú ilé-ìwòsàn.

Dókíta. Selzman pẹ̀lú Arábìnrin àti Ààrẹ Nelson

Ní ìrọ̀lẹ́ yí, Dókítà. Selzman ní ìbánisọ̀rọ̀ ìgbé ayé-yíyípadà kan pẹ̀lú ararẹ̀. Ní àkokò náà, ó ronú, “ní Ọjọ́-ẹtì, a o yàn mí sí ipò-ọ̀jọ̀gbọ́n bí àtẹ̀lé Dókítà. Nelson Òun ni a ti mọ̀ bí ẹnìkan tí ó npa àwọn ẹ̀dùn-ọkàn rẹ̀ mọ́ ní dídẹ́kun nígbàgbogbo, ó hùwàsí gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ọ̀wọ̀, kò sì, kò sì sọ àìbínú rẹ̀ nù rí. Nísisìyí tí a ó so orúkọ mi pọ̀ mọ́ tirẹ̀, èmi nílò láti gbìyànjú láti dàbíi tirẹ̀ síi.” Dókíta. Selzman jẹ́ oníṣẹ́-abẹ yíyẹ gan tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n àní ó fẹ́ láti di dídára si.

Ní àtẹ̀hìnwá, àwọn ẹgbẹ́ oníṣẹ́-abẹ rẹ̀ lè ti ní ìfura ti rírẹni àti ìjákulẹ̀ rẹ̀ nítorí ó lè ti jẹ́ kí ó hàn nínú ìwà àti irú ohùn rẹ̀. Ṣùgbọ́n nínú yàrá iṣẹ́-abẹ ní alẹ́ náà, Dókítà. Selzman ṣe ìtiraka ìmọ̀-sínú láti tinilẹ́hìn nípàtàkì àti níní òye àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀. Ó ní ìmọ̀lára pé ó jẹ́ ìyàtọ̀ kan ó sì pinnu láti tẹ̀síwájú ní gbígbìyànjú láti dàbíi ti Dókítà. Nelson

Dókíta. Selzman ní wíwọ píìnì RMN

Ọdún marun lẹ́hìnnáà, Ààrẹ Nelson dá ìwé ìmòye rẹ̀ sí Unifásitì ti Utah. Àwọn ọlọ́lá láti Unifásítì wá láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ààrẹ Nelson fúnrawọn. Ní ìgbà ìṣẹ̀lẹ̀ yí, Dókítà. Selzman sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kansi. Ní títọ́ka sí àkékúrú orúkọ Ààrẹ Nelson, RMN, ó wípé, “Ìyèkoro ‘RMN’ kan wà nísisìyí tí ó la ẹ̀ka Iṣẹ́-abẹ Ọ̀kan-Ọ̀fun ní Unifásítì ti Utah jálẹ̀.”

Nínú ipò ìjákulẹ̀, Dókítà. Selzman ṣe àlàyé: “Èmi nṣe ohun tí a nkọ́ àwọn akọ́ṣẹ́ wa láti ṣe nísisìyí—fojúsí, ṣe é tán, kí wọ́n si ṣe dídárajùlọ tí ó lè ṣe. Ìyèkoro yí ngbé nínú wa ní ojojúmọ́. À nfi píìnì làpẹ́lì fún gbogbo ọmọ ẹ̀ka àti ọ̀kọ̀ọ̀kan akọ́ṣẹ́ titun. Ní ìsàlẹ̀ píìnì náà ni àwọn lẹ́tà ‘RMN.’ Ìyèkoro RMN ni ìpìlẹ̀ sí idanilẹkọ wa; à nkọ́ ọ sí gbogbo ènìyàn.” Dókíta. Selzman ṣe àtúnṣe ìmọ̀ọ́mọ̀ ìsíwájú ìhùwa àti ìnọ̀gàsí rẹ̀ nítorí a ti sò orúkọ rẹ̀ mọ́ ti Ààrẹ Nelson.

Ìṣẹ̀lẹ̀ ìtẹ̀lé-ẹsẹẹsẹ yí tí ó pẹ̀lú Dókítà. Selzman mú kí nbi ara mi léèrè, “Báwo ni mo ti ṣe yípadà látigbà tí mo ti so orúkọ̀ mi pọ̀ pẹ̀lú orúkọ Jésù Krístì? Ṣe mo ti gba ìyèkoro bíiti Krístì bi àbájáde kan. Ṣe mo ti fi tinútinú gbìyànjú láti dà bíi Tirẹ̀ síi?”

Nínú ìrírí Dókíta. Selzman, a lè rí ó kéréjù àwọn ìjọra marun sí ètò náà nípasẹ̀ èyí tí a ngbé orúkọ Jésù Krístì lé orí arawa. Àní bíotilẹ̀jẹ́pé ètò náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìrìbọmi, kò tíì pé tán títí tí a ó fi di mímọ́ àti àìléèrí síi ti a ó sì dà bíi Tirẹ̀ síi.

Ìjọra àkọ́kọ́ ni dída-ọ̀kannáà. Yíyàn Dókíta. Selzman sí ipò-ọ̀jọ̀gbọ́n ti Nelson so orúkọ rẹ̀ mọ́ ti Ààrẹ Nelson, àti pé Dókítà. Selzman bẹ̀rẹ̀ láti di-ọ̀kannáà pẹ̀lú Ààrẹ Nelson. Nígbàtí a bá gbé orúkọ Jésù Krístì lé orí arawa, à nso orúkọ wa pẹ̀lú Tirẹ̀. À ndi-ọ̀kannáà pẹ̀lú Rẹ̀. À nfi inúdídùn dí mímọ̀ bí Krìstẹ́nì. A jẹ́wọ́ Olùgbàlà àti pé a fi àìtọ̀rọ̀-àforíjì dìde dúró láti jẹ́ kíká bíi Tirẹ̀.

Tímọ́tímọ́ ní ìbámu sí dídà-ọ̀kànnáà ni ìjọra míràn—ìrántí. Nígbàtí Dókítà. Selzman bá lọ sí ófísì rẹ̀, ojú rẹ̀ yíò fà sí ohun-àmì-ẹ̀yẹ tí ó gbà nígbàtí a yàn án sí ipò-ọ̀jọ̀gbọ́n ti Nelson. Ohun-àmì-ẹ̀yẹ yí nrán an létí lójojúmọ́ nípa ìyèkoro RMN. Fún wa, ṣíṣe àbápín oúnjẹ Olúwa ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ nràn wá lọ́wọ́ láti rántí Jésù Krístì ní gbogbo ọ̀sẹ̀ náà. Bí a ṣe nṣe àbápín oúnjẹ Olúwa, à nṣe é ní ìrántí oye tí Ó sàn láti rà wá padà. À ndá májẹ̀mú ọ̀tun láti rántí Rẹ̀, da títóbijùlọ Rẹ̀ mọ̀, àti láti mọyì ìnúrere Rẹ̀. A jẹ́wọ́ léraléra pé nínú àti nípasẹ̀ oore ọ̀fẹ́ Rẹ̀ nìkan ni a fi ní ìgbàlà kúrò nínú ikú ti ara àti ti-ẹ̀mí.

Ìrántí túmọ̀sí pé àntẹ̀lé àmọ̀ràn tí a fúnni nípasẹ̀ wòlíì Álmà Ìwé ti Mọ́mọ́nì. À “njẹ́ kí gbogbo ìṣe [wa] jẹ́ ti Olúwa, ibikíbi tí [a bá sì lọ, kí a] jẹ́ kí ó wà nínú Olúwa; … [kí a] jẹ́ kí gbogbo èrò [wa] kọ́júsí Olúwa; … [kí a sì] jẹ́ kí ìfẹ́ ọkàn [wa] dúró lé Olúwa títí láé.” Àní nígbàtí ọwọ́ wa bá kún pẹ̀lú àwọn ọ̀ràn míràn, kí a dúró ní rírántí Rẹ̀, gẹ́gẹ́bí a ṣe nrántí orúkọ ti ara wa, ní ìkàsí ohun èyíówù kí a kọjúsí.

Dídàgbà-kọjá rírántí ohun tí Olùgbàlà ti ṣe fún wa ni ìkẹ́ta ìjọra: fífarawé. Dókíta. Selzman bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àfarawé Ààrẹ Nelson àti àwọn ìyèkoro RMN. Mo gbàgbọ́ pé àwọn ìyèkoro Ààrẹ Nelson kàn jẹ́ ìfihàn ti ipò-ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ ìgbé ayé-pípẹ́. Fún wa, bí a bá nṣe ndi-ọ̀kannáà pẹ̀lú tí a sì nrántí Jésù Krístì, bẹ́ẹ̀náà ni a ó fẹ́ láti dà bíi Rẹ̀ síi. Gẹ́gẹ́bí ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀, à nyípadà sí dídárasi nígbàtí a bá kojúsí I, jú bẹ́ẹ̀ nígbàtí a bá kojúsí arawa lọ. A ntiraka láti dà bíi Tirẹ̀ àti láti wá láti di alábùkúnfún pẹ̀lú àwọn íhùwàsí Rẹ̀. À ngbàdúrà taratara kí a lè kún fún ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́, ìfẹ́ mímọ́ ti Krístì.

Bí Ààrẹ Nelson ti kọ́ni ní Oṣù Kẹ́rin: “Bí ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ ṣe ndi ara ìwà-ẹ̀dá wa, a ó sọ agbára-ìrọ́lù láti rẹ àwọn ẹlòmíràn sílẹ̀ nù. A ó dáwọ́dúró ní dídájọ́ àwọn ẹlòmíràn. A ó ní ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ fún àwọn wọnnì láti gbogbo ilẹ̀ ayé. Ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ sí gbogbo ènìyàn … ṣe pàtàkì sí ìlọsíwájú wa. Ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ ni ìpìnlẹ̀ ìwà tọ̀run.” Ní ẹ̀gbẹ́ ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́, à nwá, “láti múdàgbà, … o, kí a sì mú gbòòrò” àwọn ẹ̀bùn ti ẹ̀mí míràn láti ọ̀dọ̀ Olùgbàlà, pẹ̀lú ìwà rere, ìwà títọ́, sùúrù, ìrẹ̀lẹ̀, àti aápọn.

Fífarawé Jésù Krístì ndarí sí ìbámu kẹrin: ìbáramu pẹ̀lú àwọn èrèdí Rẹ̀. A darapọ̀ mọ́ Ọ nínú iṣẹ́ Rẹ̀. Gẹ́gẹ́bí oníṣẹ́-abẹ, Dókítà. Nelson ni a mọ̀ bí olùkọ́ni, olùwòsàn, àti olùwáàdí kan. Píìnì lápẹ̀ tí a nlò ní abala Dókítà. Selzman tẹnumọ pé àwọn ìṣe wọ̀nyí, ní fífi àwọn ọ̀rọ̀ náà Kọ́ni, Wọ̀sàn, àti Wárí hàn. Fún wa, ara gbígbé orúkọ Jésù Krístì lé orí arawa pẹ̀lú fífi tìfẹ́tìfẹ́, ìmọ̀ọ́mọ́, àti ìyárí fi àwọn ìlépa wa wà ní ìbámu pẹ̀lú Tirẹ̀. A darapọ̀ mọ́ Ọ nínú iṣẹ́ Rẹ̀ nígbàtí a bá “fẹ́ràn, pín, tí a sì pè.” A darapọ̀ mọ́ Ọ nínú iṣẹ́ Rẹ̀ nígbàtí a bá ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ẹnití a ti palára, fọ́nká, tàbí tẹ̀pa nípasẹ̀ àwọn ìrírí ilẹ̀ ayé wọn.

À ngbé orúkọ Jésù Krístì lé orí arawa ní kíkún nípasẹ̀ dídí-ọ̀kannáà, ìràntí, ìfarawé, àti ìbáramu. Ṣíṣe mẹ́rin wọ̀nyí ndarí wa sí ìjọra karun: ìfúnni-lágbára. À nní ààyè sí agbára Ọlọ́run àti àwọn ìbùkún nínú ayé wa. Ipò-ọ̀jọ̀gbọ́n Nelson pèsè ìdánimọ̀ àti àtìlẹhìn owó fún Dókítà. Selzman tí ó nlò láti yí ọ̀làjú nínú abala rẹ̀ padà. Ó lo èyí “ẹ̀bùn ti agbára” láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Ní irú ọ̀nà kannáà, nígbàtí a ba gbé orúkọ Jésù Krístì lé orí arawa, Baba wa Ọ̀run nbùkún wa pẹ̀lú agbára Rẹ̀ láti ṣèrànwọ́ láti mú iṣẹ́́ ìránṣẹ́ wa ṣẹ nínú ayé ikú.

Bí a ṣe ndá àwọn àfikún májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, à ngbé orúkọ Jésù Krístì lé orí arawa síi ní kíkún. Ní àbábọ̀, Ọlọ́run nbùkún wa pẹ̀lú agbára Rẹ̀. Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni: “Ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó ndá àwọn májẹ̀mú nínú àwo ìrìbọmi àti nínú àwọn tẹ́mpìlì—tí ó sì npa wọn mọ́—ní ààyè púpọ̀ sí agbára Jésù Krístì. “Èrè fún pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ni agbára àtọ̀runwá … agbára tí ó nfún wa lokun láti kojú àwọn ìpèníjà, ìdánwò, àti ìrora-ọkàn wa dáadáa.”

À ndi títẹ́wọ́gba níti ẹ̀mí síi . A nní ìgboyà síi láti dojúkọ àwọn ìpò tí ó dàbí kò ṣeéṣe. À nní okun nínú ìpinnu wa síi láti tẹ̀lé Jésù Krístì. À nronúpìwàdà síi kánmọ́kánmọ́ kí a sì padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nígbàtí a bá dẹ́ṣẹ́. À ndi dídára síi ní pípín ìhìnrere Rẹ̀ pẹ̀lú agbára àti àṣẹ Rẹ̀. À nran àwọn wọnnì nínú àìní lọ́wọ́ nígbàtí a bá dínkù ní ṣíṣèdájọ́ , ní dídínkù gan ní dídájọ́. À ndi ìwẹ̀nùmọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa mú. À nní àlàáfíà púpọ̀, a sì nní ọ̀yàyà síi nítorí a lè yayọ̀ nígbàgbogbo. Ògo Rẹ̀ yíò yí wa ká, àti pé àwọn ángẹ́lì Rẹ̀ yíò gba ìṣọ́ lórí wa.

Olùgbàlà pè wá, “Ẹ wá sọ́dọ̀ Baba ní orúkọ mi, ní àkokò tótọ́ kí ẹ sì gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀.” Mo rọ̀ yín láti ṣe èyí. Ẹ wá sọ́dọ̀ Baba wa Ọ̀run. Gbígba orúkọ Jésù Krístì sórí arayín. Ẹ di-ọ̀kannáà pẹ̀lú Rẹ̀. Ẹ rántí Rẹ̀ nígbàgbogbo Ẹ tiraka láti dàbíi Tirẹ̀. A darapọ̀ mọ́ Ọ nínú iṣẹ́ Rẹ̀. Ẹ gba agbára Rẹ̀ àti àwọn ìbùkún nínú ayé yín. Ẹ gbẹ́ orúkọ Rẹ̀ sínú ọkàn yín, tìfẹ́tìfẹ́ àti ní mímọ̀ọ́mọ̀. Èyí fún yín ní “dídúró” níwájú Ọlọ́run ó sì nmú yín yege fún ìgbẹnusọ ti Olùgbàlà ní ìtìlẹhìn yín. Ìwọ yíò di ajogún gbígbéga kan nínú ìjọba Baba wa ní Ọ̀run, ajogún-papọ̀ pẹ̀lú Àkọ́bí Rẹ̀, Àyànfẹ́ Olùgbàlà àti Olùrápadà wa.

Ó wà láàyè. Mo mọ̀ ọ́ dájúdájú. Ó fẹ́ràn yín. Ó fi ayé Rẹ̀ fún yín. Ó nbẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú yín láti wá sọ́dọ̀ Baba nípasẹ̀ Rẹ̀. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Owó náà ni a kà sí ẹ̀bùn kan.

  2. Àṣeyọrí kan tó gboríyìn ni iṣẹ́ ìdàgbàsókè àkọ́kọ́ ti ẹ̀rọ̀ wíwo ọkàn-ọ̀fún tí à nlò fún iṣẹ́-abẹ ṣíṣí ọkàn ti Ààrẹ Nelsòn.

  3. Ààrẹ Nelson ròhìn pé nínú ìkọ́ṣẹ́ ti iṣẹ́-abẹ rẹ̀, oníṣẹ́-abẹ kan nínú yàrá iṣẹ́-abẹ runú ó sì ju ọ̀bẹ iṣẹ́-abẹ kan tí ó bàlé apá Ààrẹ Nelson. Ààrẹ Nelson wípé: “Ìrírí yí fi ìtẹ̀mọ́ra pípẹ́ sí mi lára. Ní wákàtí náà gan, mo ṣe ìlérí fúnra mi pé ohunkóhun tí ó bá ṣẹlẹ̀ nínú yàrá iṣẹ́ abẹ mi èmì kò ní sọ àkóso ẹ̀dùn ọkàn mi nù láé . Bákannáà mo ṣèlérí ní ọjọ́ náà láti máṣe ju ohun kankan sọnù nínú ìbínú láé—bóyá ó jẹ́ ọ̀bẹ iṣẹ́ abẹ tàbí àwọn ọ̀rọ̀” (“A Nílò Àwọn Onílàjà,” Làìhónà, Oṣù Karun 2023, 98).

  4. Ìdáwó náà pẹ̀lú ó ju ẹgbẹ̀rún méje ìròhìn iṣẹ́-abẹ, ní ẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ìwé ìwáàdí àti àwọn ìkọ̀wé ti ọ̀jọ̀gbọ́n tí wọ́n kójọ papọ̀ ní igbà iṣẹ́ ìṣègùn àrà-ọ̀tọ̀ ti Ààrẹ Nelson.

  5. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn bá Ààrẹ Nelson sọ̀rọ̀, pẹ̀lú Ààrẹ Unifásìtì ti Utah, Ààrẹ Taylor R. Randall, ẹnití ó tọ́ka sí Ààrẹ Nelson bí ẹni tó tayọ jùlọ bí akẹkọ tẹ́lẹ̀rí Unifásítì ti Utah.

  6. Ọ̀rọ̀ náà ìyèkoro ṣe àpèjúwe “ìwà títayọ, ìtara, ìwà ẹ̀dá, tàbí ìtọ́nisọ́nà àwọn ìgbàgbọ́ ti ẹnìkan, ẹgbẹ́, tàbí ilé-ẹ̀kọ́” (Merriam-Webster.com Ìtumọ̀, “ìyèkoro”).

  7. Ní 2018, aya mi, Ruth, àti èmi lè lọ síbi ayẹyẹ nínú èyí tí a ti yan Dókítà. Selzman ni a yàn sí ipò ọ̀jọ́gbọ́n ti Nelson. Ní 2023, mo lè lọ sí ìṣẹ̀lẹ̀ gbangba níbití Ààrẹ Nelson ti dáwó sí àwọn ìwé ọ̀jọ̀gbọ́n sí Unifásítì ti Utah.

  8. Wo Mórónì 7:48.

  9. Ọ̀rọ̀ Hébérù náà ni a ṣe ìyírọ̀pada bí “mú” nínú gbólóhùn “gbé orúkọ Krístì sórí” túmọ̀sí “gbé sókè” tàbí “gbé,” bí ọ̀kan yíò ṣe gbé àsíá tí ó nmúni di ọ̀kannáà pẹ̀lú olúkúlùkù tàbí ẹgbẹ́ (wo James Strong, Ìgbòòrò Àkótán Ìtọ́ka Pàtàkì Alágbára ti Bíbélì [2010], abala ìtumọ̀ Hébérù, ojú-ewé 80, nọ́mbà 5375).

  10. Wo 2 Néfì 10:24; Mórónì 10:32-33; Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 76:69.

  11. Álmà 37:36.

  12. Dókíta. Selzman ti ṣe àyọsọ bí wíwípé: “Nígbàkugbà tí ẹ bá bẹ̀rẹ̀ sísọ̀rọ̀ nípa ìtọ́jú ìlera pẹ̀lú [Ààrẹ Nelson], ó máa nní ṣíṣẹ́jú kékeré nínú ojú rẹ̀. … Ó yanilẹ́nu láti rí bí ó ṣe [nní] okun sí ní sísọ̀rọ̀ nípa gbogbo àwọn nkan yẹn” (nínú Sydney Walker, “Bí Ààrẹ Nelson ṣe di ọmọ ọdún ọgọ́ọ̀rún, Ẹbí àti akẹ́gbẹ́ rẹ̀ ronú lórí Ìgbé-ayé Rẹ̀ àti Ohun-ìní ,” Àwọn Ìròhìn Ìjọ, Oṣù Kẹsan, Ọjọ́ Keje, 2024, thechurchnews.com). Èmi ti ri níti ara pé “ìtọ́jú ìlera nṣẹ́jú” nínú ojú Ààrẹ Russell M. Nelson, ṣùgbọ́n kìí ṣe ohun tí a lè fiwé ìtàná tí ó nní nígbàti ó bá nsọ̀rọ̀ Jésù Krístì.

  13. Wo Mórónì 7:47–48.

  14. Russell M. Nelson, “Ìgbẹ́kẹ̀lé ní Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run,” Làìhónà, Oṣù Karun 2025, 128.

  15. Wo 1 àwọn Kọ́ríntì 11:11; Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 132:19–20

  16. Russell M. Nelson, “Ìkópa Àwọn Arábìnrín nínú Ìkójọ Ísráẹ́lì,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2018, 69.

  17. Wo Wàásù Ìhìnrere Mi: Atọ́nà Kan Sí Pípín Ìhìnrere Jésù Krístì (2023), 123–38.

  18. Wo Mósè 1:39. Àkórí Iyejú Oyè Àlùfáà Árọ́nì bẹ̀rẹ̀, “Èmi jẹ́ àyànfẹ́ ọmọ Ọlọ́run, Ó sì ní iṣẹ́ kan fún mi láti ṣe” (Ibi-ìkàwé Ìhìnrere). Àkórí Àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin kà pé: “Gẹ́gẹ́bí ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì, mo ntiraka láti dà bíi Rẹ̀. Mò nwá láti ṣe ìṣe lórí ìfihàn araẹni àti láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn ní orúkọ mímọ́ Rẹ̀” (Ibi-ìkàwé Ìhìnrere).

  19. Wo Dieter F. Uchtdorf, “Iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere: Pípín Ohun Tí Ó Wà Nínú Ọkàn Yín,” Làìhónà, Oṣù Karun 2019, 16–18; Gary E. Stevenson, “Fẹ́ràn, Pín, Pè,” Làìhónà, Oṣù 2022, 84–87.

  20. Ní kùtùkùtù nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ayé ikú Rẹ̀, Olùgbàlà ṣe àlàyé èrèdí Rẹ̀ fún wa nípa ṣíṣe àyọsọ látinú Ísáíàh, “Ẹ̀mí Olúwa nbẹ lára mi, nítorí ó ti fi àmì òróró yàn mi láti wàásù ìhìnrere sí àwọn òtòṣì, ó ti rán mi láti wò àwọn ọkàn oníròbìnújẹ́ sàn, láti wàásù ìdásílẹ̀ fún àwọn tó wà nígbèkùn, àti ìríran fún àwọn afọ́jú, láti sọ àwọn tí a pa lára di òmìnira” (Lúkù 4:18).

  21. Àní àwọn àdúra wa sí Baba wa Ọ̀run yíò yípadà. Bí a ti sọ nínú ìwọlé Ìtumọ̀ Bíbélì “Àdúrà”: “A kọ́ àwọn Krìstẹ́nì láti gbàdúrà ní orúkọ Krístì. A gbàdúrà ní orúkọ Krístì nígbàtí iyè-inú wa bá jẹ́ iyè inú Krístì—nígbàtí ọ̀rọ̀ Rẹ̀ bá ngbé inú wa. Nígbànáà a bèèrè fún àwọn ohun tí ó ṣeéṣe fún Ọlọ́run láti fúnni. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà dúró ní àìdáhùn sí nítorí wọn kò sí nínú orúkọ Krístì rárá; wọ́n kò ṣojú iyè-inú Rẹ̀ ní ọ̀nà kankan ṣùgbọ́n rú jáde látinú ìmọtaraẹni-nìkàn ti ọkàn ẹ̀nìyàn.”

  22. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 109:26.

  23. Russell M. Nelson, “Ẹ Ṣẹ́gun Ayé Kí Ẹ Rí Ìsinmi,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2022; àfikún àtẹnumọ́.

  24. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 109:21–22. Gbólóhùn náà “nígbàtí àwọn ènìyàn mi bá rékọjá, eyikeyi lára wọn” lo ọ̀rọ̀ náà “nígbàtí,” kìí ṣe “bí.” Èyí dá àbá pé Olu dá á mọ́ pé gbogbo wa yíò ní ìrékọja, ṣe àwọn àṣìṣe, kí a sì dẹ́ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n ètò náà ni kí a “ronúpìwàdà kánmọ́kánmọ́” kí a jẹ́ “mímúpadàbọ̀sípò sí àwọn ìbùkún” a ti gba ìlérí.

  25. Wo Jòhánnù 16:33; Mòsíàh 4:11; 18:26; Álmà 36:2, 28–29; Ẹtérì 7:27; Mórónì 9:25,

  26. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 109:22.

  27. Ẹkọ àti Àwọn Májẹmú 93:19.

  28. Mọ́mọ́nì ṣe àpèjúwe ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ̀ nígbàtí Krístì kò lọ́wọ́ sí ìgbé ayé wọn mọ́. Àwọn ènìyàn rẹ̀, “jẹ́ onínú-dídùn ní ìgbàkan rí, wọ́n sì ní Krístì gẹ́gẹ́bí olùṣọ́-àgùtàn wọn; bẹ́ẹ̀ni, Ọlọ́run tí í ṣe Baba ní ó sì ndari wọn. Ṣugbọn nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, Sátánì ní ó ndari wọn kakiri, àní gẹgẹbi iyangbo tí di gbigba kiri níwájú afẹ́fẹ́, tabi bí ọkọ̀ omi tí di bíbì síwá-sẹ́hin nínú ìru omi, èyítí kò ní igbokun ọkọ̀, tabi ìdákọ̀ró, tabi ohunkóhun tí a ó fí tù ú; àti pẹ̀lú gẹ́gẹ́bí ó ti rí, bẹ́ẹ̀ ni wọn rí” (Mọ́mọ́nì 5:17–18). Pẹ̀lú Olùgbàlà nínú ayé wa, a di alábùkúnfún pẹ̀lú agbára, ìdúró-ṣinṣin, a`ti ìdarí.

  29. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 109:24.

  30. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 45:3–5.

  31. Wo Àwọn Rómù 8:17.