Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, Àádọ́rin Agbègbè, àti Olóyè Gbogbogbò
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwàá 2025


3:26

Ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, Àádọ́rin Agbègbè, àti Olóyè Gbogbogbò

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, èmi yíò gbé àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, àwọn Àádọ́rin Agbègbè, àti àwọn Olóyè Gbogbogbò Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn fún ìbò ìmúdúró yín.

Ẹ jọ́wọ́ ẹ fi àtìlẹhìn yín hàn bí ẹ ti nṣe. Bí a bá rí àwọn wọ̀nni tí wọń tako eyikeyi nínú àwọn àbá, a bèèrè pé kí ẹ kàn sí ààrẹ èèkàn yín.

A dalaba pé kí a ṣe ìmúdúró Dallin Harris Oaks Bí Ààrẹ Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.

Àwọn to bá faramọ, jọ̀wọ́ ṣàpẹrẹ.

Alátakò kankan tó bá wa lè fihàn.

A dalaba kí a ṣe imúdúró àwọn wọ̀nyí bí ọmọ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá: Dallin H. Oaks, Jeffrey R. Holland, Henry B. Eyring, Dieter F. Uchtdorf, David A. Bednar, Quentin L. Cook, D. Todd Christofferson, Neil L. Andersen, Ronald A. Rasband, Gary E. Stevenson, Dale G. Renlund, Gerrit W. Gong, Ulisses Soares, àti Patrick Kearon.

Àwọn tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.

Alátakò kankan lè ṣe àmì bẹ́ẹ̀.

A dalaba kí a ṣe ìmúdúró àwọn ọmọ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá bí àwọn wòlíì, aríran, àti olùfihàn.

Gbogbo ẹni tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.

Ìlòdì, tí ẹnìkankan bá wá, nípa irú àmì kannáà.

A ṣe àkíyèsí pé àwọn Àádọ́rin Agbègbè titun méjì ni a múdúró nínú àwọn ìpàdé àpapọ̀ olórí gbogbogbò a sì ti kéde rẹ̀ sí orí ibi ayélujára Ìjọ. A pè yín láti ṣe ìmúdúró àwọn arákùnrin wọ̀nyí nínú yíyàn síṣẹ́ wọn titun.

Àwọn tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.

Àwọn alátakò, nípa irú àmì kannáà.

A dalaba pé kí a ṣè ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, Àádọ́rin Agbègbè, àti àwọn Olóyè Gbogbogbò bí a ṣe gbé wọn kalẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

Àwọn wọnnì tó bá faramọ lè fihàn.

Àwọn wọnnì tó bá tàkòó, tí ẹnikẹ́ni bá wà, lè fihàn.

A dúpẹ́ lọ́wọ́ yín, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, fún ìbò ìmúdúró yín ní ìtìlẹhìn àwọn olórí Ìjọ.

Àwọn Ìyípadà sí Àwọn Àádọ́rin Agbègbè

Àwọn Àádọ́rin Agbègbè wọ̀nyí ni a ṣe ìmúdúró fún nínú abala àwọn olórí kan tí a ṣe bí ara ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò:

Bhanu K. Hiranandani àti Fernando Vivas.