Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ṣe Lọ́ọ̀ṣọ́ pẹ̀lú Ìwà-rere ti Ìwọ̀ntún-wọ̀nsì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwàá 2025


15:8

Ṣe Lọ́ọ̀ṣọ́ pẹ̀lú Ìwà-rere ti Ìwọ̀ntún-wọ̀nsì

Mo nawọ́ ìfipè àtinúwá mi sí gbogbo wa láti ṣe iyè-inú àti ọkàn wa pẹ̀lú ìwà rere ìwọ̀ntún-wọ̀nsì bíiti Krístì

Ní Oṣù Karun 2021, nígbàtí à nṣe íbẹ́wò iṣẹ́ àtúnṣe ti Tẹ́mpìlì Salt Lake, ìtiraka àwọn olùlànà ya Ààrẹ Russell M. Nelson lẹ́nu, pẹ̀lù ohun-èlò ìwọ̀nba àti ìgbàgbọ́ àìyẹsẹ̀, tí wọ́n kọ́ ilé mímọ́ náà, iṣẹ́-àṣetán rírí àti ti ẹ̀mí, èyítí ó ti dúró fún ìgbà pípẹ́. Ṣùgbọ́n, ó ṣe àkíyèsí àbájáde àgbàrá bákannáà, èyítí ó ti fa àlafo pípẹ́ nínú òkúta ìpìlẹ̀ àtètèkọ́ṣe tẹ́mpìlì àti àìdúró-gbọingbọin nínú àwọn ohun ìkọ́lé, àwọn àmì tí ó hàn kedere nípa ìnílò fún ọ̀nà ìfúnlókun.

Ààrẹ Nelson ní òde Tẹ́mpìlì Salt Lake

Àyànfẹ́ wòlíì wa nígbànáà kọ́ wa pé gẹ́gẹ́bí ó ti ṣeéṣe tó láti ṣe àmúlò kókó àwọn òdiwọn láti fún ìpìlẹ tẹ́mpìlì lókun ní èrò fún un láti kojú àwọn ipa àdánidá, bákannáà a nílò láti ṣe àwọn òdiwọn àrà-ọ̀tọ̀—bóyá àwọn òdiwọ̀n tí a kò ṣe tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ rí—láti fún ìpìlẹ̀ ti ẹ̀mí wa nínú Jésù Krístì lókun. Ó fi wá sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìbèèrè jíjinlẹ̀ fún ìfiyèsí araẹni: “Bí ìpìlẹ̀ yín ṣe dúró gbọingbọin? Àti pé kíni àwọn ìfúnlókun sí ẹ̀rí yín àti níní òye ìhìnrere tí ẹ nílò?”

Ìhìnrere Jésù Krístì npèsè wa pẹ̀lú ìmísí àtọ̀runwá àti àbájáde ìtumọ̀ láti dẹ́kun àgbàrá ti-ẹ̀mí nínú ọkàn wa, ní fifi agbára fún ìpìlẹ̀ wa lókun àti ríràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún àwọn àlàfo nínú ìgbàgbọ́ wa àti àìdúró ṣinṣin nínú méjèjì ẹ̀rí àti níní òye wa nípa àwọn òtítọ́ mímọ́ ti ìhìnrere. Ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ kan pàtàkì ní pàtò fún ṣíṣe àṣeyege èrèdí yí ni a rí nínú ìpín kejìlá ti Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú, ìfihàn kan tí a fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí Joseph Knight, ọkùnrin olódodo kan tí ó fi tinútinú wá láti ní òye ìfẹ́ Olúwa, kìí ṣe fún ìyípadà òde lásán, ṣùgbọ́n láti dúró láìyẹsẹ̀ nínú ipò-ọmọẹ̀hìn rẹ̀—“ní ìdúró ṣinṣin bí àwọn òpó ti ọ̀run.” Olúwa kéde pé:

“Kíyèsíi, èmi nbá ọ sọ̀rọ̀, àti bákannáà sí gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ láti mú iṣẹ́ yìí jáde wá àti láti ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀;

“Àti pé ẹnìkẹ́ni kò lè ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ yìí bí kò ṣe pé ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ kí ó sì kún fún ìfẹ́, pẹ̀lú níní ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́, pẹ̀lú wíwà ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì nínú ohun gbogbo, èyíkéyìí tí a lè fi sí abẹ́ ìtọ́jú rẹ̀.”

Ìtọ́sọ́nà Olùgbàlà, tí a kọsílẹ̀ nínú ìfihàn mímọ́ yí, rán wa létí pé ìwọ̀ntún-wọ̀nsì ni pàtàkì ìfúnlókun fún ìpìlẹ̀ dídúró ṣinṣin nínú Jésù Krístì. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìwàrere tí a kò lè sọnù, kìí ṣe fún àwọn tí a ti pè láti sìn nìkan ṣùgbọ́n fún gbogbo àwọn ẹni tí wọ́n ti dá májẹ̀mú mímọ́ pẹ̀lú Olúwa tí wọ́n sì tẹ́wọ́gbà láti tẹ̀lé E lóòtítọ́. Ìwọ̀ntún-wọ̀nsì nṣe ìbámu ó sì nfún àwọn ìwà bíiti Krístì míràn tí a dárúkọ nínú ìfihàn yí lókun: ìrẹ̀lẹ̀, ìgbàgbọ́, ìrètí, ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́, àti ìfẹ́ mímọ́ tí ó nṣàn láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Síwájú síi, ṣíṣe ìmúdàgbà ìwọ̀ntún-wọ̀nsì ni ọ̀nà tó nítumọ̀ láti dá ààbò bo ẹ̀mí wa ní ìlòdì sí ẹ̀tàn síbẹ̀ tí ó nfa àgbàrá nípa àwọn ipa ti-ayé ti ó lè mú àìlera bá ìpìlẹ̀ wa nínú Jésù Krístì.

Ní àárín àwọn ìwà tí ó nṣe ọ̀ṣọ́ Ọmọẹ̀hìn òtítọ́ ti Krístì, ìwọ̀ntún-wọ̀nsì hàn kedere bí ìfiyèsí ti Olùgbàlà Fúnrarẹ̀, èso iyebíye kan fún Ẹ̀mí, wà fún gbogbo àwọn ẹni tí wọ́n bá fi arawọn sílẹ̀ fún ipa àtọ̀runwá. Ìwà rere ni ó nmú ìrẹ́pọ̀ wá sí ọkàn, tí ó ntún ifẹ́-inú àti ẹ̀dún-ọkàn ṣe pẹ̀lú ọgbọ́n áti ìrọlẹ̀. Nínú àwọn ìwé mímọ́, ìwọ̀ntún-wọ̀nsì ni a gbékalẹ̀ bí ara pátákì ti ìlọsíwájú ìrìn-àjò ti-ẹ̀mí wa, tí ó ndarí wa lọ síwájú sùúrù, ìwà-bí-Ọlọ́run, àti àánú, nígbàtí ó nsọ àwọn ìmọ̀làra wa, ọ̀rọ̀ wa, àti iṣe wa di ọ̀tun.

Àwọn ọmọẹ̀hìn Krístì tí wọ́n tiraka láti ṣe ìmúdàgbà ìwà bíiti Krístì yí ó di onírẹ̀lẹ̀ àti kíkún fún ìfẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀. Okun títòrò ndìde nínú wọn, wọ́n sì ndi dídára sí ní ìlèṣe láti dá ìbínú dúró, ṣìkẹ́ sùúrù, àti láti hùwàsí àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú ìfaradà, ìtẹríba, àti ọ̀wọ̀ àní nígbàtí àwọn ìjì ọ̀tá bá nfẹ́ lílelíle. Wọ́n ntiraka láti máṣe ṣe ìṣe pẹ̀lú agbára ìrọ́lù ṣùgbọ́n yàn láti ṣe ìṣe pẹ̀lú ọgbọ́n, tí a tọ́sọ́nà nípa ìwà-pẹ̀lẹ́ àti ipa jẹ́jẹ́ ti Ẹ̀mí Mímọ́. Ní ọ̀nà yí, wọ́n lè dínkù ní níní ìpalára sí àgbàrá ti-ẹ̀mí nítorí, bí Àpóstélì Páùlù ṣe kóni, wọ́n mọ̀ pé wọ́n lè ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ Krístì, ẹni tí ó nfún wọn lókun àní nínú ojú àdánwò tí ó lè mi ẹ̀rí wọn nípa Rẹ̀.

Nínú ìwàásù rẹ̀ sí Titus, Páùlù fi àmọ̀ràn mímọ́ fúnni nípa ìmúyẹ àwọn tí wọ́n ní ìfẹ́-inú láti ṣojú Olùgbàlà kí wọ́n sì ṣe ìfẹ́ Rẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìfọkànsìn. Ó wí pé wọ́n níláti jẹ́ aláájò, fi ara balẹ̀, olóòótọ́, àti mímọ́—àwọn ìwà tí ó fi ipa ìwọ̀ntún-wọ̀nsì hàn kedere.

Bíotilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, Páùlù kìlọ̀ pé wọ́n kò níláti jẹ́ “aṣe-tinú-ẹni, onínú-fùfù, … [àti] aluni.” Irú àwọn ìhùwà bẹ́ẹ̀ lòdì sí inú Olùgbàlà ó sì ndènà ìdàgbà òtítọ́ ti-ẹ̀mí. Nínú àkóónú ti ìwé mímọ́, “kìí ṣe aṣe-tinú-ẹni” ni ẹnìkan tí ó kọ̀ láti ṣe ìṣe pẹ́lú ìyangàn àti ìgbéraga; “kìí ṣe onínú-fùfù” ni ẹnìkan tí ó nyẹra fún rírọ̀ àdánidá láti di aláìní-sùúrù àti mímú-bínú; àti “kìí ṣe aluni” tọ́ka sí ẹnìkan tí ó kọ jíjà, ìrunú, àti ìwà sísọ̀rọ̀ líle, níti ara, àti ẹ̀dùn-ọkàn. Bí a ṣe ntiraka láti yí ìwà wa padà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìrẹ̀lẹ̀, a lè ní ìdákọ̀ró dídúró ṣinṣin sí àpáta gbọingbọin oore ọ̀fẹ́ Rẹ̀ kí a sì di ohun èló mímọ́ áti títúnṣe ní ọwọ́ mímọ́ Rẹ̀.

Hannah àti Samuel

Ní fífiyesí ìlò láti mú ìwà rere ìwọ̀ntún-wọ̀nsì dàgbà, a rán mi létí àwọn ọ̀rọ̀ Hánnà, ìyá wòlíì Sámúẹ́lì—obìnrin kan onígbàgbọ́ alámì ẹnití, àní lẹ́hìn àwọn àdánwò nlá, fi orin ìmoore fún Olúwa. Ó wípé, “Máṣe halẹ̀; má jẹ́ kí ìgbéraga kí ó ti ẹnu yín jáde: nítorípé Ọlọ́run olùmọ̀ ni Olúwa, láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá ni àti ìwọ̀n ìwà.” Orin rẹ̀ ni ó ju àdúrà kan lọ—ó jẹ́ pípe-araẹni láti ṣe ìṣe pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀, ìkóraẹni-níjánu, àti ìwọ̀nba. Hánnà rán wa léti pé òtítọ́ okun ti-ẹ̀mí kìí ṣe ìfihàn àdẹ̀hìnbọ̀ agbára-ìrọ́lù tàbí àwọn ọ̀rọ̀ ìréra ṣùgbọ́n nínú ìwọ̀ntún-wọ̀nsì, àwọn ìwà elérò wà ní ìbámu pẹ̀lú ọgbọ́n Olúwa.

Nígbàkugbà, ayé ngbé ìwa tí a bí pẹ̀lú rírunú, ìyangàn, àìní-sùúrù, àti àpọ̀jù ga, nígbàkugba ní dídá irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ láre nípa àwọn ìtẹ̀mọ́ra ìgbé ayé ojojúmọ́ àti ìtẹ̀sí síwájú ipá àti òkìkí. Nígbàtí a bá yí ìwò wá kúrò nínú ìwà rere ti ìwọ̀ntún-wọ̀nsì tí a sì pa ipa jẹ́jẹ́ àti ti ìwọ̀nba Ẹ̀mí Mímọ́ ti ní ọ̀nà ti ṣíṣe àti sísọ̀rọ̀ wa, à nfi ìrọ̀rùn ṣubú sínú pàkúté ọ̀tá, èyítí ó ndarí wa sí àìlèyẹ̀ láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ kí a sì gba àwọn ìwà tí a ó kábámọ́ jínlẹ̀jinlẹ̀ mọ́ra, bóyá nínú ìbákẹ́gbẹ́ wa, ẹbí, tàbí àní àwọn ìbáṣepọ̀ ti ìjọ. Ìhìnrere Jésù Krístì npè wá láti lo ìwà rere yí nípàtàkì ní àkokò ìpènijà, nítorí ó jẹ́ déédé lórí àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí pé ìwà òtítọ́ ti ẹnìkọ̀ọ̀kan ni a fihàn. Gẹ́gẹ́bí Martin Luther King Jr. ti sọ nígbàkan, “Ìwọn gígajùlọ ti ẹ̀nìyàn kìí ṣe ibití ó dúró sí ní àkokò ìtunú àti ìtura, ṣùgbọ́n ibití ó dúró sí ní àwọn àkokò ìpènijà àti àríyànjiyàn.”

Gẹ́gẹ́bí àwọn ènìyàn májẹ̀mú, a pè wá láti gbé pẹ̀lú fífi ọkàn wa múlẹ̀ gbọingbọin nínú àwọn ìlérí mímọ́ tí a ti ṣe sí Olúwa, ní títẹ̀lé àwòṣe tí Ó ti gbékalẹ̀ pẹ̀lẹ́pẹ́lẹ́ nípasẹ̀ àpẹrẹ Rẹ̀ pípé. Ní àbàbọ́, Ó ti ṣe ìlérí pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, pé èyí ni ẹ̀kọ́ mi, àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́lé sórí èyí kọ́lé sórí àpáta mi, àwọn ẹnu-ọ̀nà ọ̀run àpáàdì kì yíò sì lè borí wọn.”

Olùgbàlà

Ẹ Máṣe Jẹ́ Kí Ọkàn Yín Dàmú, láti ọwọ́ Howard Lyon, nípasẹ̀ Havenlight

Iṣẹ́ ìrànṣẹ́ Olùgbàlà lórí ilẹ̀ ayé ni a fàmì sí nípa ìwà rere ìwọ̀ntún-wọ̀nsì ní gbogbo ìrísí ìwà Rẹ̀. Nípasẹ̀ àpẹrẹ pípé Rẹ̀, Ó kọ́ wa láti “ní sùúrù nínú ìpọ́njú, ẹ máṣe kẹ́gàn àwọn tí wọ́n nkẹ́gàn yín.” Bí ó ti kọ́ni pé a kò níláti júwọ́lẹ̀ fún ìbínú nítorí àwọn asọ̀ àti ìjà, Ó kéde pé: “Ẹ gbọ́dọ̀ ronúpìwàdà, kí ẹ sì dàbí ọmọ kékeré.” Bákannáà ó kọ́ni pé gbogbo ẹni tí ó ní ìfẹ́-inú láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú èrèdí kíkún ti ọkàn gbọ́dọ̀ ṣe ìbálàjà pẹ̀lú àwọn wọnnì pẹ̀lú ẹnití wọ́n nbínú sí tàbí pẹ̀lú àwọn wọnnì tí wọ́n ní ohunkan ní ìlòdì sí wọn. Pẹ̀lú ìwà ìwọ̀ntún-wọ̀nsì àti ọkàn àánú, Ó mu dá wa lójú pé nígbàtí wọ́n bá ṣe hùwàsí sí wa pẹ̀lú ìwà líle, àìní-inúrere, àìní-ọ̀wọ̀, tàbí àìkàsí, inúrere Rẹ̀ kò ní fi wa sílẹ̀, àti pé májẹ̀mú àlàáfíà Rẹ̀ kò ní kúrò nínú ayé wa.

Ní ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, aya mi àti èmi ní ànfààní mímọ́ ti pípàdé pẹ̀lú àwọn ọmọ ìjọ olóòótọ́ ti Ìjọ ní Ìlú Mexico. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára wọn, bóyá níti ara tàbí nípasẹ̀ àwọn olólùfẹ́ wọn, ti farada àwọn àdánwò àìlèjúwe, pẹ̀lú ìjínigbé, ìpànìyàn, àti àwọn àjálù ìròbìnújẹ́ ọkàn míràn.

Bí a ṣe nwo ojú àwọn Ènìyàn Mímọ́ wọnnì, a kò rí ìbínú, irunú, tàbí ìfẹ́-inú fún ẹ̀san. Dípò bẹ́ẹ̀, a rí ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́jẹ́. Àwọn ìwò wọn, bíótilẹ̀jẹ́pé wọ́n ní àmì ìkorò, tàn ìpòngbẹ òdodo fún ìwòsàn àti ìtùnú. Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní ìròbìnújẹ́ ọkàn nípa ìjìyà, àwọn Ènìyàn Mímọ́ wọ̀nyí tẹ̀ síwájú pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, ní yíyàn láti máṣe jẹ́ kí àwọn ìpọ́njú wọn di àlàfo nínú ìgbàgbọ́ wọn tàbí fa àìdúró ṣinṣin nínú ẹ̀rí wọn nípa ìhìnrere.

Ní ìparí ìkórajọ mímọ́ náà, a kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn. Gbogbo ìbọnilọ́wọ́, gbogbo ìdìmọ́ra, di ẹ̀rí jẹ́jẹ́ pé pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olúwa, a lè yàn láti fèsì pẹ̀lú ìwọ̀ntún-wọ̀nsì sí àwọn ìjákulẹ̀ àti ìpènijà ayé. Dídákẹ́ jẹ́jẹ́ wọn àti àpẹrẹ àìlèrò dúró bí ìfipè rírọ́ kan láti rìn ní ipa-ọ̀nà Olùgbàlà pẹ̀lú ìwọ̀ntún-wọ̀nsì nínú ohun gbogbo. A ní ìmọ̀lára bí ẹnipé a wà ní àárín àwọn àngẹ́lì.

Jésù Krístì, títóbiju gbogbo ènìyàn lọ, jìyà fún wa títí tí Ó fi ṣẹ̀jẹ̀ ní gbogbo ihò ara, síbẹ̀ Òun kò fi ayè gba ìbínú rárá láti rú ọkàn Rẹ̀, tàbí kí ó jẹ́ kì ìrunú, bíbínú, tàbí àwọn ọ̀rọ̀ àìmọ́ jáde ní ẹnu Rẹ̀, àní ní àárín irú ìpọ́njú bẹ́ẹ̀. Pẹ̀lú ìwọ̀ntún-wọ̀nsì pípé àti ìwàtútú àìláfiwé, Òun kò ronú nípa Ararẹ̀ ṣùgbọ́n nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ Ọlọ́run—tó ti kọjá lọ, tó wà lọ́wọ́lọ́wọ́, àti tí ó nbọ̀ lọ́jọ́ iwájú. Àpóstélì Pétérù jẹ́ ẹ̀rí ọlọ́lá ti ìwà Krístì nígbàtí ó kéde: “Ẹni, nígbàtí a kẹ́gàn rẹ̀, tí kò sì padà kẹ́gàn; nígbàtí ó jìyà, tí kò sì kìlọ̀; ṣùgbọ́n ó fi ọ̀ràn rẹ̀ lé ẹnití nṣe ìdájọ́ òdodo lọ́wọ́.” Àní ninú ìrora títóbijùlọ Rẹ̀, Olùgbàlà ṣe àpèjúwe ìwọ̀ntún-wọ̀nsì átọ́runwá àti pípé. Ó kéde pé, “Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, ògo ni fún Baba, àti pé èmi kópa mo sì ṣe àṣepari àwọn ìmúrasílẹ̀ mi fún àwọn ọmọ ènìyàn.”

Ẹ̀yin àyànfẹ́ arákùnrin àti arábìnrin mi, mo nawọ́ ìpè àtinúwá kan sí gbogbo wa láti ṣe iyè-inú àti ọkàn wá lọ́ọ̀ṣọ́ pẹ̀lú ìwàrere ìwọ̀ntún-wọ̀nsì bíiti Krístì bí ìfèsí mímọ́ sí ìpè wòlíì ti Ààrẹ wa ọ̀wọ́n Russell M. Nelson. Bí a ṣe ntiraka pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti aápọn láti wé ìwọ̀ntún-wọ̀nsì sínú àwọn ìṣe àti ọ̀rọ̀ wa, mo jẹ́ ẹ̀rí pé a ó fi okún fún a ó sì ṣe ìdákọ̀ró àwọn ìgbé ayé wa ní mímúdúró lórí ìpìlẹ̀ dídájú ti Olùràpadà wa.

Mo fi pẹ̀lú ọ̀wọ̀ jẹ́ ẹ̀rí mi pé ìlépa lemọ́lemọ́ ti ìwọ̀ntún-wọ̀nsì nsọ ẹ̀mí wa di mímọ́ ó sì nya ọkàn wa sí mímọ́ níwájú Olùgbàlà, ní fifi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fà wá súnmọ́ Ọ ó sì nmúra wa sílẹ̀, pẹ̀lú ìrètí àti àlàáfíà, fún ọjọ́ ológo náà nígbàtí àwà yíò pàdé Rẹ̀ ní Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Rẹ̀. Mo pín àwọn ọ̀rọ̀ mímọ́ wọ̀nyí ní orúkọ Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, àmín.