Àwọn Ọkàn tó Nírẹ̀lẹ̀ Kúnlẹ̀ Níbi Pẹpẹ
Bí a ti ndá tí a sì nbu ọlá fún àwọn májẹ̀mú wa, a nso ara wa mọ́ Olùgbàlà, ní jíjèrè ààyè títóbijù sí àánú, ààbo, ìyàsímímọ́, ìwòsàn, àti ìsinmi Rẹ̀.
Ẹ ṣeun, ẹ̀yin akọrin, fún ẹ̀rí nípasẹ̀ orin isìn titun náà.
Orin isìn titun ti oúnjẹ Olúwa “Oúnjẹ Ìyè, Omi Alààyè” kún ọkàn mi. Ìlà kan nínú orin isìn náà wí pé, “Nísisìyí mo wá síwájú pẹpẹ náà, ní fífi ọkàn ìrora mi sílẹ̀ fún Un.”
Òye mi ní ti àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí jinlẹ̀ bí kété lẹ́hìn tí ẹbí mi fi Newbury Park, California, sílẹ̀ láti sìn ní ẹkùn iṣẹ́ ìránṣẹ́ Utah Ogden ní 2015. Mo gba ìpè kan láti rìn yíká Ibùdó àwọn Ológun Òfurufú ti Hill ní ẹ̀bá Layton, Utah. Èmi kò tíì dé ibùdó àwọn ológun kankan rí, tàbi kí èmi ti pàdé oníwàásù ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ogun tàbi àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n nṣiṣẹ́ láti pèsè àìléwu àti ààbò fún orílẹ̀-èdè wọn.
Oníwàásù ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ogun Harp, bíi ti ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn olùyọ́ọ̀da àti ọ̀jọ̀gbọ́n oníwàásù ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ogun míràn tí wọ́n nsìn ní àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n, àwọn ilé ìwòsàn wa, àti ní àgbékalẹ̀ àwọn ológun ní àyíká àgbáyé, jẹ́ ìmísí àti ìgbéga fún mi. Ibití a ti dúró kẹ́hìn ní ibùdó náà ni ibi mímọ́ jùlọ. Mo béèrè lọ́wọ́ oníwàásù ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ogun náà bí ó bá nṣe àwọn ìsìn fún gbogbo ènìyàn tí wọ́n bá fẹ́ láti ṣe jíròrò, gbàdúrà, ronú, àti jọ́sìn. Ó lọ sí ibi ògiri iwájú ilé ijọ́sìn náà, ó sì fa àgbélèbú kan jáde láti ẹhìn àwọn kọ́tìnnì. Ó wí pé òun máa nlo àgbélèbú náà fún àwọn iṣẹ́ ìsìn ti Pùròtẹ́sítántì àti Kátólíìkì. Mo béèrè ohun tí ó nlò fún àwọn arákùnrin àtí arábìnrin wa tí wọ́n jẹ́ Júù, ó sì lọ sí ẹ̀gbẹ́ kejí ògiri iwájú náà, ó sì fa Ìràwọ̀ Dáfídì jáde.
Lẹ́hìnnáà mo béèrè pé, “Kínni ò nṣe fún àwọn iṣẹ́ ìsìn ti Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ikẹhìn?” Ó ti àwọn àpẹrẹ náà kúrò ó sì nawọ́ sí pẹpẹ onígi títóbi kan ní ààrin ibi mímọ́ náà. Ó wí pé àwọn ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn máa npèsè wọn a sì bùkún búrẹ́dì àti omi lórí pẹpẹ náà. Mo bèèrè bí pẹpẹ títóbi, tí ó dàbíi kíkàn náà bá máa njẹ́ gbígbé kúrò ṣaájú àwọn ìjọ́sìn ti àwọn arákùnrin àtí arábìnrin wa tí wọ́n jẹ́ Júù, Mùsùlùmí, Kátólíìkì, tàbí Pùròtẹ́sítántì. Ó wí pé pẹpẹ náà ndúró sí ibẹ̀, nítorí onírurú àwọn ìgbàgbọ́ wọnnì bákannáà nlo pẹpẹ náà ní àwọn ọ̀nà kan.
Ábráhámù kọ́ pẹpẹ kan, ó de Ísáákì, ó sì ṣetán láti fi ọmọkùnrin rẹ̀ kanṣoṣo rúbọ, ṣùgbọ́n a dá ọwọ́ rẹ̀ dúró, ó sì kéde, bí Olúwa ti kéde pé, “Èmi nìyí”! Ìgbà mélòó ni Èmi Ni Nlá náà tàbí ọ̀kan nínú àwọn wòlíì Rẹ̀ ti yọ̀ọ̀da pé, “Èmi nìyí”?
Ní ìgbà Ìwàásù Rẹ̀ ní orí Òkè, Olùgbàlà pè wá láti làjà pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ṣaájú kí a tó lọ sí ibi pẹpẹ. Páùlù kọ́ni pé àwa di “yíyà sí mímọ́” ní ibi pẹpẹ nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì.
Wòlíì Léhì “fi ilé rẹ̀ … àti àwọn ohun iyebíye rẹ̀. … [Nígbànáà] ó kọ́ pẹpẹ kan … ó sì rú ẹbọ-ọrẹ kan … , ó sì fi ọpẹ́ fún Olúwa.”
Bíbélì àti Ìwé Ti Mọ́mọ́nì kọ́ wa láti jọ́sìn Ọmọ Ọlọ́run ni ibi àwọn pẹpẹ. Kíni ìdí?
Àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, kọ́ àwọn pẹpẹ wọ́n sì jọ́sìn níbẹ̀. Lẹ́hìn tí wọ́n di lilé jáde ní Ọgbà Édẹ́nì tí wọ́n sì ti jọ́sìn fún “ọjọ́ púpọ̀,” angẹ́lì kan bẹ̀ wọ́n wò ó sì bèèrè ìbèèrè dídunni kan tí a lè béèrè lọ́wọ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan wa: “Kínni ṣe ti ẹ̀yin fi nrú ẹbọ sí Olúwa?”
Ádámù dáhùn pé, “Èmi kò mọ̀.”
Ìdáhùn angẹ́lì náà sí bí Ádámù ṣe fi ìrẹlẹ̀ gbà jẹ́ yíyanilẹ́nu: “Èyí … jẹ́ àfijọ ìrúbọ ti Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo Baba. … Nítorínáà, ẹ̀yin yíò máa ṣe gbogbo ohun tí ẹ nṣe ni orúkọ Ọmọ, ẹ̀yin ó sì ronúpìwàdà ẹ ó sì képe Ọlọ́run ní orúkọ Ọmọ náà títíláé.”
Tábìlì oúnjẹ Olúwa àti àwọn pẹpẹ tẹ́mpìlì nṣe àpẹrẹ ìrúbọ Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀ àìlópin.
Bí a ti ndá tí a sì nbu ọlá fún àwọn májẹ̀mú wa, tí a ngba àwọn ìlànà oúnjẹ Olúwa ní ilé ìjọsìn àti ẹ̀bùn àti fífi èdìdi dì ni tẹ́mpìlì, a nso ara wa mọ́ Olùgbàlà, ní jíjèrè ààyè títóbijù sí àánú, ààbo, ìyàsímímọ́, ìwòsàn, àti ìsinmi Rẹ̀.
Àánú àti Ààbò Nípasẹ̀ àwọn Májẹ̀mú.
Bí ọ̀dọ́mọkùnrin ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dógún, mo béèrè lọ́wọ́ baba mi bi mo bá le pa ìpàdé oúnjẹ Olúwa jẹ—ní ọjọ́ Ìsinmi kan péré nínú Oṣù Kínní fún eré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá pàtàkì kan ti àwọn ará Amẹ́ríkà. Ó wí pé mo ti dàgbà tó láti ṣe yíyàn náà fún ara mi ó sì sọ fúnmi láti ṣe àgbéyẹ̀wò ẹyọ ìmọ̀ràn kan. Ó wí pé, “Bí o bá yàn láti pa oúnjẹ Olúwa jẹ lẹ́ẹ̀kan, ó rọrùn síi láti yàn láti pa á jẹ lẹ́ẹ̀kansíi.”
Bí Olùgbàlà bá jẹ́ olùmúni-mọra nlá, nígbànáà ọ̀tá jẹ́ olùmúni-pínyà. Òun, Sátánì, ndán wa wò láti pín ara wa níyà kúrò ní àwọn ibi ìjọ́sìn wa yíyà sí mímọ́ àti kúrò níbi ààbò Jésù Krístì. Nígbàtí a bá jọ́sìn Olùgbàlà, a ngba “agbára láti dojúkọ ìṣàn adánidá ti ayé.” Nígbàtí a bá lo àkókò ní sísọ̀rọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀, a ní ìlérí kan láti jẹ́ “gbígbà kúrò lọ́wọ́ Sátánì.” “Nígbànáà, bí a ti npa àwọn májẹ̀mú wa mọ́, Ó nfún wa ní ẹ̀bùn pẹ̀lú agbára … ìfúnnilókun Rẹ̀ .” Áà, mo ti mọyì ìrírí sísọ̀rọ̀ pẹ̀lú Olùgbàlà tó nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú ṣíṣe ni ibi àwọn pẹpẹ mímọ́.
Mímú òye kan dàgbà nípa Ètùtù ayérayé ti Olùgbàlà ní ìlà lé ìlà, ẹsẹ lé ẹsẹ, npèsè àjẹsára ti ẹ̀mí ní ìlòdìsí àwọn àrékérekè ọ̀tá. Ọ̀dọ́ Alàgbà Jaggi ni Mexico, Zuster Jaggi ní Belgium, àti àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere míràn jákèjádò àgbáyé ṣeéṣe púpọ̀ síi láti rí àwọn ọ̀ré wọn tí wọ́n ngba àwọn ìbùkún ìrìbọmi àti ní gbígbà ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ bí àwọn ọ̀rẹ́ wọn bá wà níbi ìpàdé oúnjẹ Olúwa láàrin ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ ti pípàdé.
Ọ̀dọ́ àgbà kan ní Tonga tàbí Samoa ṣeéṣe púpọ̀ síi láti jẹ́ fífi èdìdi dì nínú ilé Olúwa bí wọ́n bá ti múrasílẹ̀ fún tí wọ́n sì gba ẹ̀bùn tẹ́mpìlì wọn ní kété lẹ́hìn ṣíṣetán ní ilé ìwé. Ni ibi gbígba ẹ̀bùn tẹ́mpìlì, àwọn ọmọ ìjọ ni a npè láti gbé ìgbé ayé, gbọ́ràn, àti pa àwọn òfin márun mọ́ èyítí nfùnni ní agbára àti ààbò. Bí a ti ndá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Olúwa, àsanpadà ìbáṣepọ̀ nṣẹlẹ̀. A nṣe àfihàn ìṣòtítọ́ àti ìfẹ́ wa sí I. Okun àti agbára wa ndàgbà pẹ̀lú ọkọ̀ọ̀kan ìlérí tí a ṣe tí a sì pamọ́.
Ìfiyèsí àti Ìyàsímímọ́
Nígbàtí a bá fi ìrẹ̀lẹ̀ àti ṣíṣe àpẹrẹ kúnlẹ̀ níbi àwọn pẹpẹ Olúwa, ó jẹ́ ànfààní fún ríronúsẹ́hìn, “ní yíyẹ̀wò bíi sí ìgbéraga ọkàn [wa], … [ní rírẹ ara wa sílẹ̀] níwájú Ọlọ́run.” Ṣaájú jíjáde pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi bíi ọ̀dọ́, ìyá mi á fi igbà púpọ̀ wí pé, “Rántí ẹnití o jẹ́, àti pé yọjú sími nígbàtí o bá dé ilé.” Ní àwọn òru díẹ̀, mo pa yíyọjusí mi jẹ nítorípé ó ti pẹ́ jù kí ntó dé ilé Mo kábàámọ̀ pípa àwọn àbẹ̀wò pàtàkì wọ̀nyí jẹ pẹ̀lu Ìyá.
Lónìí, mo fojúsọ́nà sí ìsopọ̀ yíyọjúsí pẹ̀lu Baba Ọ̀run. Nínú àwòṣe ìjọ́sìn ti araẹni mi, mo nkúnlẹ̀ nínú àdúrà, ní ẹ̀gbẹ́ ibùsùn mi tàbí kíkorajọ pẹ̀lú ẹbí, mo nrí ara mi ní kíkúnlẹ̀ níbi àwọn pẹpẹ, ní fífiyèsí àti ṣíṣe àyẹ̀wò ayé mi. Mo ronú nípa oúnjẹ Olúwa, àní gbogbo àwọn ẹ̀là búrẹ́dì, jíja àti fífàya fún wa, ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ àpẹrẹ ara jíjá ti Olùgbàlà wa. A rán mi létí ìkọ́ni Ààrẹ Dallin H. Oaks pé “ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀là búrẹ́dì náà jẹ́ àrà ọ̀tọ̀, gẹ́gẹ́bí ẹnìkọ̀ọ̀kan ti nkópa nínú rẹ̀ ṣe jẹ́ àrà ọ̀tọ̀.” Nígbàtí mo bá kúnlẹ̀ nínú àdúrà, mo nronú lórí bí mo ṣe lè fí ìfẹ́ inú mi fún Ọlọ́run.
Alàgbà David A. Bednar kọ́ni pé: “ìlànà oúnjẹ Olúwa jẹ́ ìpé mímọ́ àti léraléra láti ronúpìwàdà nítòótọ́ àti láti jẹ́ sísọ di ọ̀tun nípa ti ẹ̀mí. Ìṣe ti kíkópa nínú oúnjẹ Olúwa, nínú àti ní ti òun nìkan, kò mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kúrò. Ṣùgbọ́n bí a ti nmúra pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn tí a sì nkópa nínú ìlànà mímọ́ yìí pẹ̀lú ìrora ọkàn àti ẹ̀mí ìròbìnújẹ́, nígbànáà ìlérí náà ni pé kí a lè máà fi ìgbà gbogbo ní Ẹ̀mí Olúwa láti wà pẹ̀lú wa. Àti pé nípa agbára ìsọdimímọ́ ti Ẹ̀mí Mímọ́ bíi ojúgbà wa lemọ́lemọ́, a lè fi ìgbà gbogbo di ìmúkúrò àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa mú.”
Nígbàtí Amy àti èmi wo àwọn ìrírí ìgbé ayé wa dáadáa, a ṣe àjọyọ̀ ẹ̀bùn ìfẹ́ pípé àti ìrúbọ ti Jésù Krístì. Bákannáà a ríi bí ìbínú ọ̀run àpáàdì ti jẹ́ títú sílẹ̀. Báwo ni a ṣe lè borí àwọn ìwoni ti ìdájọ́, àníyàn, ìrẹ̀wẹ̀sì, àrùn jẹjẹrẹ, àtọ̀gbẹ, yẹ̀yẹ́ ṣíṣe lórí ayélujára, jíja olè ìdánimọ̀ àwọn oyún sísọnù, àti pípàdánù ọmọ, arákùnrin, àti baba kan? Nítorípé Jésù gbà nínú ago kíkorò ti ìwárìrì, ago ìbínú náà—fún èmi, fún ẹbí mi, fún gbogbo wa!
Gẹ́tsémánè, láti ọwọ́ Adam Abram, láti ipasẹ̀ altusfineart.com © 2025
“Ago kíkorò” náà tí Ó mu nínú Ọgbà Gétsémánì àti ìjìyà Rẹ̀, tí ó jẹ́ “líle síi” lórí àgbélèbú ni Kálfárì, fi ààyè gbà wá láti fi ẹni líle, aláfojúdi, ìkà, oníbìínú, àti ẹni ìwárìrì lélẹ̀ lórí àwọn pẹpẹ Olúwa kí wọn ó sì jẹ́ “yíyà sí mímọ́ nípa gbígbà ti Ẹ̀mí Mímọ́,” nígbà gbogbo.
Arábìnrin Patricia Holland wí pé, “Àdúrà mi jíjinlẹ̀ jùlọ fún yín àti fún ara mi lónìí ni pé a ó le fi sílẹ̀ pátápátá, fi ara wa sílẹ̀ níbi pẹpẹ àwọn ìlérí àti àlàáfíà Ọlọ́run ibikíbi tí ó wù kí a wà àti ohunkóhun tí ó wù kí a ti ṣe.”
Ibi Ìwòsàn àti Ìsinmi Kan.
Nígbàtí a bá wá sí ibi pẹpẹ, kìí ṣe pé a ngba èrè kan; a nkẹ́kọ̀ọ́ nípa Olùfúnni ní Ẹ̀bùn. Nínú ẹ̀kọ́ kíkọ́ àti májẹ̀mú dídè náà ni ìwòsàn ti nwá. Néfì wí pé, “Ó ti fi ìfẹ́ rẹ̀ kún mi, àní sí jíjẹ ẹran ara mi run.” Àti pé olùfẹ́ni Olùgbàlà wa ti pè wípé, “Ẹ̀yin kì yíò ha padà sí ọ̀dọ̀ mi nísisìyí, kí ẹ sì ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì yípadà, kí èmi lè mú yín láradá?”
Nígbàtí àwọn ọmọbìnrin wa méjì tí wọ́n dàgbà jùlọ, Mackenzie àti Emma, wà ní kékeré, ọ̀kan lára àwọn ààyò ìtàn wọn ni Àwọn Króníkà ti Narnia: Kìnnìún, Àjẹ́ àti Ibi ìpa aṣọ mọ́ sí. Gbogbo wa kún fún ìfẹ́ pẹ̀lú kìnnìún náà, Aslan. Ọ̀kan nínú àwọn àṣálẹ́ tí ó jẹ́ mọ́nigbàgbé jùlọ ní kíka ìwé náà ni ìgbà tí kìnnìún nlá náà fi ayé rẹ̀ sílẹ̀ fún Edmund. Mọ́nigbàgbé nítorípé àwọn òbí àti àwọn ọmọbìnrin sun ẹkún bí wọ́n ṣe gba ẹ̀mí kìnnìún náà lórí Tábìlì Òkúta láti ọwọ́ Àjẹ́ náà. Mọ́nigbàgbé nítorípé ìrètí tẹ̀síwájú, láìka ti àjálù náà sí, títí tí ohun nlá kan fi ṣẹlẹ̀. Àwọn igbe ayọ̀ dún nínú yàrá kékeré náà nígbàtí Aslan jẹ́ jíjí dìde tí ó sì wí pé, “Bí [Àjẹ́ náà bá mọ ìtumọ̀ tòótọ́ ti ìrúbọ], … òun yíó [mọ̀] pé [bí] ohun ẹbọ tó ṣetán ẹnití kò dá ẹ̀ṣẹ̀ ìwà ọ̀dàlẹ̀ bá [kú] ní ipò oníkúpani kan, Tabìlì [Òkúta] náà yío là, ikú funrarẹ yíó sì [bẹ̀rẹ̀sí tú].”
Jésù Krístì nwo gbogbo àwọn ọgbẹ́ sàn. Jésù Krístì nmu ṣeéṣe láti wà láàyè lẹ́ẹ̀kansíi.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ níbi ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwàá 2022, Ààrẹ Russell M. Nelson ṣe àpèjúwe ẹgbẹ́ tó nrìn kiri kan tó nla ètò ìṣílé tẹ́mpìlì kọjá. Ọmọdékùnrin kan wà níbẹ̀. Ààrẹ Nelson kọ́ni pé:
Ní ìgbàtí ẹgbẹ́ tó nrìn kiri náà wọ inú yàrá ẹ̀bùn tẹ́mpìlì, ọmọdékùnrin náà na ọwọ́ sí pẹpẹ, níbití àwọn ènìyàn nkúnlẹ̀ láti dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, ó sì wí pé, ‘Áà, èyí dára. Ní ìhín ni ibìkan fún àwọn ènìyàn láti sinmi lórí ìrìnàjò tẹ́mpìlì wọn.’
“… Òun kò jọ pé ó ní èrò ori nípa ìsopọ̀ tààrà láàrìn dídá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run nínú tẹ́mpìlì àti ìlérí yíyanilẹ́nu ti Olùgbàlà:
“Ẹ wa sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tó ńṣiṣẹ́, tí a sì di ẹrù wúwo lé lórí, èmi yíò sì fún yín ní ìsinmi
“Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì máa kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi; … ẹ̀yin ó sì rí ìsinmi fún ọkàn yín
“‘Nítorí àjàgà mi rọrùn, ẹrù mi sì fúyẹ́’ [Máttéù 11:28–30; àfikún àtẹnumọ́].”
“Ọmọ Ènìyàn kò ní ibì kan láti fi orí rẹ̀ lélẹ̀ sí,” síbẹ̀ Ó pe àwọn ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀, ẹ̀yin àti èmi, sí ibi tábìlì oúnjẹ Olúwa láti sinmi pẹ̀lú Rẹ̀ níbẹ̀. Nígbàtí “àwọn ọkàn tó nírẹ̀lẹ̀ bá kúnlẹ̀ níbi àwọn pẹpẹ,” àlàáfíà npọ̀ síi. Ọwọ́ Olùgbàlà wa jẹ́ nínà sóde; tábìlì Rẹ̀ jẹ́ títẹ́. Ẹ wá sin Ọmọ Ọlọ́run ní ibi àwọn pẹpẹ mímọ́ Rẹ̀. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.