Mọ Ẹnití Ìwọ Jẹ́ Lóotọ́
Ibi yòówù kí a wà ní ipa ọ̀nà jíjẹ́ ọmọ ẹ̀hìn wa, ìgbésí ayé wa yóò yípadà bí a bá lóye ẹnití a jẹ́ gan-an dáadáa.
Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn ọmọbìnrin wa ní ìrírí jíjinlẹ̀ lórí iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀. Pẹ̀lú ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀, mo ṣàjọpín apá kan ohun tí ó kọ sí wa lọ́sẹ̀ náà:
“Lána ọmọ ẹgbẹ́ kan ti npadà bọ̀ bèèrè fún wá láti wá ní kíákíá bí ó bá ṣeéṣe. Nígbàtí a débẹ̀, a rí i lórí ilẹ̀, ó nsunkún láìjáfara. Nípasẹ̀ omijé, a rí i pé ó ti pàdánù iṣẹ́ rẹ̀, a fẹ́ lé e kúrò ní ilé rẹ̀, àti lẹ́ẹ̀kansi síi yóò di aláìnílé.”
Ọmọbìnrin wa tẹ̀síwájú pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí àṣàrò àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ mi pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀, ní ìgbìyànjú láti rí ohunkan—ohunkóhun—láti ran lọ́wọ́. Bí mo ti nwá ẹsẹ pípé, mo rò ó pé, ‘Kíni mò nṣe? Èyí kì í ṣe ohun tí Krístì yóò ṣe. Èyí kì í ṣe ìṣòro tí mo lè yanjú, ṣùgbọ́n èyí jẹ́ ọmọbirin gidi ti Ọlọ́run tí ó níló ìrànlọ́wọ́ mi.’ Nítorínáà mo pa àwọn ìwé mímọ́ mi dé, mo kúnlẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, mo sì dì í mú nígbàtí a jọ nsunkún, títí tó fi ṣetán láti dìde kí ó sì dojúkọ ìdánwò yi.”
Lẹ́hìn ìtùnú fún obìnrin yi, ọmọbìnrin wa wá lo àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ láti gba níyànjú àti ràn án lọ́wọ́ láti lóye òtítọ́ ìtóye rẹ̀ àtọ̀runwá àti láti kọ́ ọ ní ọ̀kan lára àwọn òtítọ́ ìpìlẹ̀ pàtàkì jùlọ nínú wíwàláàyè wa—pé àwa jẹ́ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Ọlọ́run olùfẹ́ ọ̀wọ́n, Ọlọ́run tí nní ìyọ́nú pípé fún wa nígbàtí a bá jìyà tó sì múra tán láti ràn wá lọ́wọ́ bí a ṣe nṣe àfẹ̀hìntì.
Ó jẹ́ ìjìnlẹ̀ òye pé kókó ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ tí àwọn míṣọ́nnárì nkọ́ni ni pé Ọlọ́run jẹ́ olùfẹ́ni Baba Ọ̀run. Gbogbo òtítọ́ tí ó tẹ̀le nkọ́lé lórí òye ìpìlẹ̀ ti ẹnití a jẹ́ gan an.
Susan H. Porter, Ààrẹ Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, kọ́ni: “Nigbati o bá mọ̀ tí o sì lóye bí a ṣe nífẹ rẹ pátápátá gẹ́gẹ́bí ọmọ Ọlọ́run, ó nyí ohun gbogbo padà. Ó nyí ọ̀nà tí o lérò nípa ara rẹ padà nígbàtí o bá ṣe àwọn àṣìṣe. Ó nyí bí o ṣe lérò padà nígbàtí àwọn nkan tí ó nira bá ṣẹlẹ̀. Ó nṣe ìyipada ìwòye yín nípa awọn ofin Ọlọrun. Ó nṣe ìyipada ìwòye rẹ sí àwọn ẹlòmíràn àti ti agbára rẹ̀ láti ṣe ìyàtọ̀.”
Ìyípadà yìí jẹ́ àkàwé bí a ṣe nkà nípa ìrírí tí Mósè ní nígbàtí ó nbá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lójú-ko-jú. Nígbà ìbáarasọ̀rọ náà, Ọlọ́run kọ́ Mósè léraléra nípa ogún àtọ̀runwá rẹ̀, ní sísọ pé, “Mósè, … ọmọ mi ni ìwọ.” Ọlọ́run ṣàlàyé pé Mósè wà ní àwòrán Ọmọ bíbí Rẹ̀ Kanṣoṣo. Mósè wá ní òye ẹnití òun jẹ́, pé òun ní iṣẹ́ kan láti ṣe, àti pé òun ní olùfẹ́ni Baba Ọ̀run kan.
Lẹ́hìn ìrírí yi, ọ̀tá náà wá láti dán an wò ó sì bá a sọ̀rọ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé, “Mósè, ọmọ ènìyàn.” Èyí jẹ́ ohun èlò tí ó wọ́pọ̀ àti tí ó léwu nínú ohun ìjà ti ọ̀tá. Níwọ̀n bí Baba wa Ọrun lemọ́lemọ́ ati pẹlu ifẹ nrán wa létí pé a jẹ́ ọmọ Rẹ̀, ọ̀tá yóò gbìyànjú nígbàgbogbo láti fi àmì sí wa lára nípasẹ̀ àwọn àìlera wa. Ṣùgbọ́n Mósè ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé òun jẹ́ ju “ọmọ ènìyàn lọ.” Ó sọ fún Sátánì pé: “Tani ìwọ? Nítorí kíyèsí i, ọmọ Ọlọ́run ni èmi.” Bákannáà, nígbàtí a bá dojúkọ àwọn ìpèníjà ti ikú tàbí nígbàtí a bá nímọ̀lára pé ẹnìkan ngbìyànjú láti fi àwọn àìlera wa sàmì sí wa lára, a ní láti dúró gbọnin gbọnin nínú ìmọ̀ ẹnití a jẹ́ nítòótọ́. A gbọ́dọ̀ wá àfọwọ́sí ní ìnàró, kii ṣe ní ìdùbúlẹ̀. Àti pé bí a ti nṣe é, àwa náà lè fi ìgboyà kéde pé, “Ọmọ Ọlọ́run ni mi.”
Nínú ìfọkànsìn kárí ayé fún àwọn ọ̀dọ́ àgbà, Olùfẹ́ Ààrẹ wa President Russell M. Nelson kọ́ni pé: “Nítorínáà ta ni ìwọ? Lákọ̀ọ́kọ́ àti ṣáajú, ìwọ jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, ọmọ májẹ̀mú, àti ọmọ ẹ̀hìn Jésù Kristi. Bí o ṣe ngba àwọn òtítọ́ wọ̀nyí mọ́ra, Baba wa Ọ̀run yíò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dé ibi àfojúsùn rẹ tí ó ga jùlọ ti gbígbé títí láé ní iwájú Rẹ̀ mímọ́.”
Kìí ṣe àìròtẹ́lẹ̀ pé ó ṣeéṣe ní ẹsẹ ìwé mímọ́ tí a sọ léraléra jùlọ, Ọlọ́run rán wa létí àjọṣe wa pẹ̀lú Rẹ̀. Nínú gbogbo àwọn orúkọ tí a lè dá mọ̀ nípa àdúrà oúnjẹ Olúwa, Ó ti bèèrè pé kí a pè É ní “Ọlọ́run, Baba Ayérayé.”
Bí a ṣe wá mọ ẹnití a jẹ́ nítòótọ́, a ó ní ìgbàgbọ́ púpọ̀ sí pé Baba wa Ọ̀run onífẹ ti pèsè ètò kan fún wa láti padà láti gbé pẹ̀lú Rẹ̀ lẹ́ẹ̀kansíi. Alàgbà Patrick Kearon kọ́ni pé: “Ètò rírẹwà Bàbá wa, àní ètò ‘ọlọ́lá’ Rẹ̀, ni a ṣe láti mú ọ wá sílé, kì í ṣe láti mú ọ jáde. … Ọlọ́run nlépa rẹ láìdábọ̀.” Ronú nípa èyí fún ìṣẹ́jú kan—Baba wa-alágbára, tó jẹ́ onífẹ wà nínu “ìlépa rẹ láìdábọ̀.”
Ibi yòówù kí a wà ní ipa ọ̀nà jíjẹ́ ọmọ ẹ̀hìn wa, ìgbésí ayé wa yóò yípadà bí a bá lóye ẹnití a jẹ́ gan-an dáadáa. Njẹ́ mo lè dába àwọn ọ̀nà méjì tí a lè mú òye yi jinlẹ̀.
Àkọ́kọ́, Àdúrà
Bí Olùgbàlà ti nbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ kíkú, a mú un lọ sínú aginjù láti “wà pẹ̀lú Ọlọ́run.” Bóyá ó yẹ kí a yí èrò inú wa kúrò nínú gbígbàdúrà lásán sí lílo àkókò tí ó pọ̀ tó láti bá a sọ̀rọ̀ níti gidi àti láti “wà pẹ̀lú Ọlọ́run” lójoojúmọ́.
Mo ti rí i pé òṣùwọ̀n àdúrà mi túbọ̀ ndára sí bí mo ṣe nlo ìṣẹ́jú díẹ̀ láti múra sílẹ̀ láti bá Baba mi sọ̀rọ̀. Àwọn ìwé mímọ́ fihàn wá pé èyí jẹ́ àpẹrẹ tí ó ṣiṣẹ́. Bóyá Joseph Smith ni; Néfì, ọmọ Hẹ́lámánì; tàbí Ẹ́nọ́sì, gbogbo wọn ní irú ìrònú àti àfihàn díẹ̀ ṣáájú ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tí a gbàsílẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ẹ́nọ́sì sọ pé ebi npa ọkàn òun bí ọ̀rọ̀ baba òun ti wọnú jinlẹ̀ sínú ọkàn òun. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àpẹrẹ wọ̀nyí kọ́ wa pé a nílò láti múra àkókò wa sílẹ̀ nípa tẹ̀mí lójoojúmọ́ láti “wà pẹ̀lú Ọlọ́run.”
Sí àwọn ará Néfì, Olùgbàlà fúnni ní ìtọ́ni pé, “Nígbàtí ẹ̀yin bá ngbàdúrà, wọ inú kọ́lọ́fín rẹ, nígbàtí ìwọ bá sì ti ilẹ̀kùn rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ.”
Bóyá o wà nínú kọ́lọ́fín tàbí yàrá, ìlànà náà ni láti wá àyè níbití o lè dánìkan wà lati gbàdúrà, láti jẹ́kí ẹ̀mí rẹ dúro jẹ́jẹ́, àti láti ní ìmọ̀lára àwọn ìtúsílẹ̀ ti “ohùn kekere jẹ́jẹ́.” A lè múra sílẹ̀ nípa ríronú lórí àwọn ohun tá a mọrírì àti àwọn ìbéèrè tàbí àwọn àníyàn tí a nífẹ láti mú wá sọ́dọ̀ Baba wa. A gbọ́dọ̀ sapá láti máṣe ní ọ̀nà ìlò àdúrà pàtó ṣùgbọ́n láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Baba wa, sókè bí ó bá ṣeéṣe.
Mo mọ̀ pé nínú ìdàrúdàpọ̀ ìgbésí ayé wa, nígbàtí a bá njìjàkadì pẹ̀lú àwọn ọmọdé tàbí tí a bá nsáré láàárín àwọn ìpàdé, a lè máà ní ìgbádùn àwọn ìyẹ̀wù dídákẹ́jẹ́ẹ́ àti ìmúrasílẹ̀ pẹ̀lú ìrònú—ṣùgbọ́n àwọn àdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́, kíákíá, àti kánjúkánjú lè túbọ̀ nítumọ̀ nígbàtí a bá ti sapá láti “wà pẹ̀lú Ọlọ́run” ṣáájú ọjọ́ náà.
Ó lè jẹ́ pé àwọn kan wà tí wọn kò tíì gbàdúrà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tàbí àwọn miran tí wọn kò tíì rò pé à ngbọ́ àwọn àdúrà wọn. Mo ṣèlérí fún ọ pé Baba rẹ Ọ̀run mọ̀ ọ́, ó nífẹ rẹ, ó sì fẹ́ gbọ́ látọ̀dọ̀ rẹ. Ó fẹ́ láti bá ọ sọ̀rọ̀. Ó fẹ́ kí o rántí ẹnití o jẹ́.
Alàgbà Jeffrey R. Holland kọ́ni láìpẹ́ yí pé: “Bí ó ti wù kí ó maá gbadura tó, gbadura síi. Bi o ti wu ki o le tí o ngbadura, gbàdúrà síi.”
Ní àfikún sí jíjẹ́ kí àwọn àdúrà wa lóòrèkoòrè àti mímúra gidigidi pọ̀ síi, kíkẹ́kọ Ìwé ti Mọ́mọ́nì lójoojúmọ́ àti jíjọ́sìn nínú tẹ́mpìlì yíò ṣèrànwọ́ láti múra àwọn ọkàn wa sílẹ̀ fún ìfihàn. Bí a ṣe ngbìyànjú láti mú ìbánisọ̀rọ̀ wa pọ̀ si pẹ̀lú Baba wa Ọ̀run, Òun yíò bùkún wa láti ní ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ síi pé ọmọ Rẹ̀ ni wá.
Èkejì, Wá Mọ Pé Jésù Ni Kristi náà
Ìfihàn títóbi jùlọ ti ìfẹ́ Baba Ọ̀run fún wa gẹ́gẹ́bí ọmọ Rẹ̀ ni àrídájú pé Ó rán Ọmọ Rẹ̀, Olùgbàlà tiwa fúnra wa, láti ràn wá lọ́wọ́ láti wá sí ilé. Nítorínáà, a ní láti mọ̀ Ọ́n.
Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn, nígbàtí mo nsìn bíi ààrẹ èèkàn, mo fi àbá kan sílẹ̀ fún arákùnrin kan láti sìn bí òṣìṣẹ́ ìlànà nínú tẹ́mpìlì. Lẹ́hìn ṣíṣàlàyé rẹ̀ bí òṣìṣẹ́ ìlànà kan tí yóò jẹ́ àgbàyanu, mo tẹ̀ láìmọ̀ọ́mọ̀ “maṣe fọwọ́ sí,” èyítí ó fi àbá náà sílẹ̀. Lẹ́hìn tí mo ti gbìyànjú láti tún ìhìn iṣẹ́ náà pè láì-ṣàṣeyorí, mo pe ààrẹ tẹ́mpìlì náà mo sì sọ pé, “Mo ti ṣe àṣìṣe nlá kan.” Láìsí iyèméjì, Ààrẹ tẹ́mpìlì rere yi sọ pé, “Ààrẹ Eyre, kò sí ohun kan tí o ṣe tí a kò lè dáríjì tí kò sì ṣeé túnṣe níkẹhìn.” Ó ti jẹ́ òtítọ́ nlá tó. Nítòótọ́, Jésù Kristi jẹ́ “alágbára ńlá láti gbani là.”
Ní 2019 ìyípadá nlá wà nínú àwọn ìbèèrè ìṣèdúró tẹ́mpìlì. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ìbéèrè kan bèèrè bóyá o ní ẹ̀rí ipa tí Jésù Krístì wa bí Olùgbàlà àti Olùràpadà kó. Ó nbèrè báyi tí o bá ní ẹ̀rí ti ipa Rẹ̀ bí Olùgbàlà àti Olùràpadà rẹ. Ètùtù Jésù Krístì kìí ṣe fún àwọn ẹlòmíràn; o ṣiṣẹ fun ìwọ ati fun èmi. Òun ni Olùgbàlà mi. Òun ni Olùgbàlà rẹ. Olúkúlukú. Nípasẹ̀ Rẹ̀ ni ìwọ àti èmi lè padà wà pẹ̀lú Baba.
Nítorínáà, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ẹ jẹ́ kí a wá A. Ẹ jẹ́ kí a kẹ́kọ ìbáṣepọ̀ àtọ̀runwá Rẹ̀ pẹ̀lú Baba àti pẹ̀lú ẹnìkọ̀ọ̀kan wa. Jẹki a ní ìrírí orin ti ìfẹ́ ìràpadà tí ó wá fún olúkúlukú wa nípasẹ̀ Olùràpadà wa bí a ti nronúpìwàdà. Bí a ṣe wá mọ “òun ẹnití ó lágbára láti gbàlà,” àwa yóò wà ní òye pé àwà, gẹ́gẹ́bí ọmọ Ọlọ́run, jẹ́ ayọ̀ Rẹ̀—ìfojúsùn Rẹ̀ tí ó ṣe pàtàkì jùlọ—àti pé ní tòótọ́ ni olúkúlùkù tọ́ sí ìgbàlà.
Mo jẹ́ri pé a ní Bàbá Ọ̀run onífẹ. Bí a ṣe nmọ òtítọ́ ayérayé yi nípasẹ̀ àdúrà tó lágbára, ìfihàn ti araẹni, àti wíwá sọ́dọ̀ Jésù Krístì, a lè polongo nísisìyi àti nígbàgbogbo pé, “Ọmọ Ọlọ́run ni mí.” Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.