Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ọ̀rọ̀-ìṣíwájú
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwàá 2025


3:34

Ọ̀rọ̀-ìṣíwájú

À nlọ síwájú nísisìyí pẹ̀lú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò ìlàjì-ọlọ́dọdún yi, à ntẹ̀síwájú bí a ti ṣètò àti pẹ̀lú àwọn olùsọ̀rọ̀ àti orin tí a yàn láti ọwọ́ Ààrẹ Nelson lẹ́hìn àwọn oṣù ti ìmúrasílẹ̀.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, a pàdé bí a ṣe nṣọ̀fọ̀ ikú àyànfẹ́ Ààrẹ wa Russell M. Nelson. Èmi nbá yín sọ̀rọ̀ bí Ààrẹ Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá, nínú ipò èyí tí a ti ṣe ìmúdúró fún mi ní ìpàdé àpapọ̀ kọ̀ọ̀kan, ní wọ́ọ̀dù, èèkàn, àti ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbó fún ọdún méje àti ààbọ̀ tó kọjá.

À nlọ síwájú nísisìyí pẹ̀lú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò ìlàjì-ọlọ́dọdún yi, à ntẹ̀síwájú bí a ti ṣètò àti pẹ̀lú àwọn olùsọ̀rọ̀ àti orin tí a yàn láti ọwọ́ Ààrẹ Nelson lẹ́hìn àwọn oṣù ti ìmúrasílẹ̀. Àwọn àyọkúrò díẹ̀ péré nìkan ni èyí, àlàyé ọ̀rọ̀ ìṣíwájú mi, àti ọ̀rọ̀ sísọ mi ní ìpò Ààrẹ Nelson nínú abala ìparí ní ọ̀sàn Ọjọ́-ìsinmi.

Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ ní bíi ọdún 75 (máàrúndín ní ọgọ́rin) tí Ààrẹ Ìjọ ti kú ní ọjọ́ díẹ̀ ṣíwájú ìpadé àpapọ̀ gbogbogbò kan. Èyí ti mú kí a ṣètò bí a ti lè ṣe àwọn ìpàdé pàtàkì ti àwọn aṣaájú ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò bákannáà bí àwọn abala gbogbogbò ti ìpàdé àpapọ̀, ní ìgbà kannáà a nṣètò ìsìnkù rẹ̀ ní àìpẹ́ bí ó ti ṣeéṣe tó. Ààrẹ Nelson ní òye iyì ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò láti pèsè ìdarí fún àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní àwọn oṣù tó nbọ̀. A bú-ọlá fún un nípa títẹ̀lé ìṣètò ìpàdé àpapọ̀ náà bí ó ti fàṣẹ si.

Ní ìgbà ìkẹdùn yí, a ti ní ìpàdé kan tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ láti gbé oríyìn fún Ààrẹ Russell M. Nelson ṣíwájú àwọn ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò wa àti nígbànáà a ti ṣètò ìsìnkú rẹ̀ ní àìpẹ́ bí ó ti ṣeéṣe tó lẹ́hìn ìpàdé àpapọ̀. Gbogbo èyí ni a ti ṣe pẹ̀lú àṣẹ ẹbí Ààrẹ Russell M. Nelson àti Iyejú àwọn Méjìlá.

Bí ó ti jẹ́ pé gbogbo àwa tí a ti yàn láti sọ̀rọ̀ nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò yíò fẹ́ láti lo àkokò ti a yàn fún láti ṣe gbígbé oríyìn araẹni kan fún Ààrẹ Nelson, a ti bèèrè pé kí gbogbo olùsọ̀rọ̀ nínú ìpàdé àpapọ̀ wa di irú oríyìn eyikeyi bẹ́ẹ̀ mú sí ìwọ̀n, di àkokò oríyìn títóbí fún ìsìnkú, èyí tí a ti bẹ̀rẹ̀ sí nṣe ètò tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.

Oríyìn tèmi ní ṣókí—tí ó wà ní ìbámu sí ìpàdé àpapọ̀ yí àti sí àwọn oríyìn tí a ti fúnni tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀—ni èyí: Mo ní ìfẹ́ Russell M. Nelson mo sì tí kọ́ ẹ̀kọ́ síi nípa ìhìnrere àti ipò aṣaàjú ìhìnrere láti inú ìbáṣọ̀rẹ́ àti ìbákẹ́gbẹ́ mi ìgbà pípẹ́ pẹ̀lú rẹ̀ ju láti ọ̀dọ̀ eyikeyi aṣaájú míràn tí mo ti mọ̀ níti araẹni lọ. Òun ni àwòṣe wa bí ìrànṣẹ́ kan àti ọmọlẹ́hìn Olúwa Jésù Krístì. Nípa àwọn ohun wọ̀nyí ni mo jẹ́ ẹ̀rí, ni orúkọ Jésù Krístì, àmín.