Ìwé ti Mọ́mọ́nì—Ìṣúra Àìlódíwọ̀n Lórí Ìrìn Àjò Wa
Bí a ṣe nṣàṣàrò lórí àwọn ọ̀rọ̀ Krístì tí a rí nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, ẹ̀mí náà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti lóye àwọn òtítọ́ ayérayé.
Ṣé o lè rántí àkókò kan nígbàtí ẹnìkan fún ọ ní ẹ̀bùn tí ó yí ìgbésí ayé rẹ padà? Oṣù Kẹwàá yi jẹ́ ogójì ọdún láti ìgbà tí mo gba ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀bùn nlá jùlọ ní ìgbésí ayé mi. Nígbàtí mo wà ní ilé ẹ̀kọ́ gíga, mo kíyèsí pé ọ̀kan lára àwọn ọmọ kíláàsì wa ní ìmọ́lẹ̀ tó yàtọ̀ sí púpọ̀ jùlọ àwọn ọ̀dọ́ yokù. Mo gbádùn wíwà ní àyíká rẹ̀. Ní ọjọ́ kan ó sọ fún mi pé ọmọ Ìjọ ti Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ni òun jẹ́. Lẹ́hìnnáà ó fún mi ní ẹ̀bùn kan: ẹ̀dà ti Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ó pè mí kí nka ojú ewé mélo kan kí nsì bá àwọn ọ̀rẹ́ méjì kan pàdé tí wọ́n lè dáhùn àwọn ìbéèrè mi. Àwọ̀n ọ̀rẹ́ náà jẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere.
Nígbàtí mo bá àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere náà pàdé, wọ́n kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ Kristi wọ́n sì pè mí láti tẹ̀lé ìpè wòlíì Mórónì: “Nígbàtí ẹ̀yin yíò gba àwọn nkan wọ̀nyí, èmi yíò gba yín níyànjú pé kí ẹ bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Baba Ayérayé, ní orúkọ Krístì, bí àwọn nkan wọ̀nyí kò bá jẹ́ òtítọ́; àti pé bí ẹ̀yin bá bèèrè pẹ̀lú ọkàn òtítọ́, pẹ̀lú èrò gidi, ní níní ìgbàgbọ́ nínú Krístì, òun yíò fi agbára òtítọ́ rẹ̀ hàn sí yín, nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́” (Mórónì 10:4).
Mo ka àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ojú-ewé Ìwé ti Mọ́mọ́nì mo sì gbàdúrà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò tíì lóye gbogbo ohun tí àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere nkọ́ mi, mo mọ̀ lọ́kàn mi pé ohun tí mò nkà jẹ́ rere ó sì ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Mo gba ìmúdájú ìlérí Moroni: “Àti nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́ ẹ̀yin lè mọ òtítọ́ ohun gbogbo” (Mórónì 10:5).
Lẹ́hìn tí mo ṣèrìbọmi sí Ìjọ ti Jésù Kristi ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn, àwọn ọ̀rẹ́ kan gbìyànjú láti mú dá mi lójú pé mo ti ṣe ìpinnu tí kò tọ́. Ṣùgbọ́n ní gbogbo ìgbà tí mo bá dojúkọ irú àwọn ìyèméjì àti àtakò bẹ́ẹ̀, mo gba ìmúdájú ìsọdọ̀tun nípa kíkẹ́kọ́ àwọn ìwé mímọ́ àti gbígbàdúrà láti dúró ṣinṣin sí àwọn májẹ̀mú tí mo ti dá pẹ̀lú Ọlọ́run. Láti ìgbà náà, Ìwé ti Mọ́mọ́nì ti jẹ́ alábakẹ́gbẹ́ mi ó sì ti di ohun ìṣúra tí kò lódíwọ̀n nínú ìrìnàjò ikú mi.
Ìwé ti Mọ́mọ́nì ju ìwé kan lọ. Ó jẹ́ májẹ̀mú Jésù Krístì miran, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn wòlíì ìgbàanì kọ nípasẹ̀ ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ àti ìfihàn.
Ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣe pàtàkì jùlọ tí a gbàsílẹ̀ nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni iṣẹ́-ìránṣẹ́ ti araẹni tí Olúwa Jésú Krístí láarin àwọn ara Néfì ní kété lẹ́hìn Àjínde Rẹ̀. Ìwé ti Mọ́mọ́nì “ti fi àwọn ẹ̀kọ́ ti ìhìnrere jáde, ó ṣe ìlànà ètò ìgbàlà, ó sì sọ fún àwọn ènìyàn ohun tí wọn gbọdọ ṣe lati jere alaafia ni igbesi-aye yi ati igbala ayeraye ni igbesi-aye ti nbọ” (ọ̀rọ̀ ìsáájú sí Ìwé ti Mọ́mọ́nì).
Àtẹ̀jáde àkọ́kọ́ ti Ìwé ti Mọ́mọ́nì: Májẹ̀mú Miràn ti Jésù Krístì jẹ́ títẹ̀jáde ní ìlú kékeré kan ní ìpínlẹ̀ New York ní Oṣù Kẹta 1830. Wòlíì Joseph Smith jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún (23) nígbàtí ó parí ìtumọ̀ ìwé náà ní 1829. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé kò tíì pé ọjọ́ márùndínlọ́gọ́rin (75) ló túmọ̀ gbogbo ìwé náà, nǹkan bí oṣù méje sì ni iṣẹ́ ìtẹ̀wé náà gbà.
Lónìí, nkan bí Ogójì Ọ́kẹ́ (80,000) àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere alákokò-kíkún ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ju Àádọ́jọ (150) ló nsìn gẹ́gẹ́bí olùyọ̀ǹda araẹni, tí wọ́n nya ìgbésí-ayé wọn sí mímọ́ láti jẹ́ri pé òtítọ́ ni Ìwé ti Mọ́mọ́nì àti pé ó jẹ́ri nípa Jesu Kristi.
Níbi ìdánilẹ́kọ àìpẹ́ jùlọ fún àwọn olùdarí ẹkùn iṣẹ́ ìránṣẹ́ tuntun ní Òkúdù ti ọdún yi, Ààrẹ Russell M. Nelson ṣàjọpín ẹ̀rí rẹ̀ alágbára ti Ìwé ti Mọ́mọ́nì: “Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ … ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó nkọ́ni ní ẹ̀kọ́ Kristi ó sì nṣàlàyé púpọ̀ sí i nípa Ètùtù Olùgbàlà ju bí ìwé míran ti ṣe lọ.”
Èmi yóò fẹ́ láti fúnni ní àwọn ìmọ̀ràn mẹ́ta tí ó lè ṣe ìrànlọ́wọ́ jíjinlẹ̀ fún ìyípadà wa sí Jésù Krístì nípasẹ̀ ìkẹ́kọ ti Ìwé ti Mọ́mọ́nì:
1. Jẹ́ aláápọn kí o sì ṣe déédé nínú ìkẹ́kọ ojoójúmọ́ rẹ
Gẹ́gẹ́bí Álmà àti àwọn ọmọ Mòsíàh, a gbọ́dọ̀ “[wádi] àwọn ìwé mímọ́ tọkàntọkàn, kí [a] lè mọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” kí a sì fún wa lókun nínú òtítọ́ (Álmà 17:2).
Nígbàtí a nsìn gẹ́gẹ́bí olùdarí ẹkùn iṣẹ́ ìránṣẹ́ míṣọ́n ní Ìpínlẹ̀, èmi àti ìyàwó mi gba gbogbo míṣọ́nnárì níyànjú láti kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé ti Mọ́mọ́nì fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú ó kéré tán lójoojúmọ́. Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ yẹn mú kí ìgbàgbọ́ wa pọ̀ sí i ó sì ràn wá lọ́wọ́ láti wá àti retí retí àwọn iṣẹ́ ìyanu.
Ó ṣeéṣe pé lẹ́hìn iṣẹ́ míṣọ̀n a lè má ní iye àkókò kannà tí ó wà fún ìkẹ́kọ ìwé mímọ́ lojoojumọ, ṣugbọn mo ṣèlérí pé tí o bá fi tọkàntọkàn ṣe pàtàkì kíka Ìwé ti Mọ́mọ́nì pẹ̀lú àdúrà lójoojúmọ́, ìwọ yóò rí agbára àti ìgbẹ́kẹ̀lé ti ẹ̀mí nlá sí Olúwa àti àwọn ìlérí Rẹ̀.
2. Jẹ́kí Ẹ̀kọ́ Rẹ ní Ìtumọ̀ Díẹ̀ Si i nípa Àṣàrò lórí àwọn Ọ̀rọ̀ Krístì
Néfì kọ́ni pé, “Ṣàṣàrò lórí àwọn ọ̀rọ̀ Krístì; nítorí kíyèsíi, àwọn ọ̀rọ̀ Krístì yíò sọ ohun gbogbo fún ọ ohun tí ìwọ yíò ṣe” (2 Néfì 32:3).
Láti ṣe àsàrò túmọ̀ sí ju kíkàwé nìkan lọ—ó túmọ̀ sí adùn, àròjinlẹ̀, àti mímú lò. Bí o ṣe nkẹ́kọ Ìwé ti Mọ́mọ́nì, ronú nípa àwọn ọ̀nà láti mú kí ìkẹ́kọ Ìwé Mímọ́ rẹ túbọ̀ ní ìtumọ̀. Fún àpẹrẹ:
-
Lo àwọn ìtìlẹhìn ìkẹ́kọ tí ó wà nínú áàpù Ibi Ìkàwé Ìhìnrere.
-
Ṣe ìdánimọ̀ àwọn òtítọ́ ayérayé tí ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa láti lóye ètò Ọlọ́run tí ó sì darí wa láti ṣe àti pa àwọn májẹ̀mú mọ̀ pẹ̀lú Baba wa Ọ̀run.
-
Ṣe àmì sí àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ pàtàkì kí o sì ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìwúnilórí rẹ láti tọ́jú ohun tí ó ti kọ lákokò ìkẹ́kọ rẹ̀.
Ìwé ti Mọ́mọ́nì ní agbára láti dáhùn àwọn ìbéèrè ti ọkàn wa. Gẹ́gẹ́bí Néfì ti sọ, a gbọ́dọ̀ “fi gbogbo àwọn ìwé mímọ́ wé wa, kí ó lè jẹ́ fún èrè àti kíkọ́ wa” (1 Néfì 19:23).
Bí a ṣe nṣàṣàro lórí àwọn ọ̀rọ̀ Krístì, wọn yíò ṣílẹ̀kùn fún ìfihàn wọn yóò sì fi ohun tí a nílò láti ṣe hàn wá nínú onírúurú ipò ìgbésí ayé wa láti sún mọ́ Ọn.
3. Ṣe ìjẹ́rí rẹ nípa òtítọ́ Ìwé ti Mọ́mọ́nì.
Gẹ́gẹ́bí Léhì ṣe fẹ́ láti ṣàjọpín èso igi ìyè pẹ̀lú ẹbí rẹ̀ (wo 1 Néfì 8:12), nígbàtí a bá jèrè ẹ̀rí Ìwé ti Mọ́mọ́nì, a nṣe ìmúdàgbà ìfẹ́ inú láti ṣàjọpín ayọ̀ tí nwá láti inú mímọ̀ ìhìnrere ti Jésù Krístì.
Ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere wa, Arábìnrin Benson, tó nbá wa lọ sípàdé yì, ṣàjọpín ìfẹ́ rẹ̀ láti ran arákùnrin rẹ̀ ọ̀dọ́ lọ́wọ́. Ní àkókò yẹn, ó nmúrasílẹ̀ láti lọ sí kọ́lẹ́ẹ̀jì ati pé kò ní ìdánilójú sísin iṣẹ́ ìránṣẹ́ kan. Mo ní ìmọ̀lára ìwúrí láti pe Arábìnrin Benson láti ka Ìwé ti Mọ́mọ́nì ní oṣù mẹ́rin àkọ́kọ́ ti iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, ní fífi àmì sí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó fẹ́ràn jù, kí ó sì fi ẹ̀dà náà ránṣẹ́ sí arákùnrin rẹ̀.
Arábìnrin Benson fi ẹ̀dà Ìwé ti Mọ́mọ́nì tí ó ní àmì ránṣẹ́ ó sì ké sí arákùnrin rẹ̀ láti kà nínú rẹ̀ lálẹ́ kọ̀ọ̀kan. Lẹ́hìn náà ó ṣàjọpín pẹ̀lú mi pé: “Ṣáájú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi, arákùnrin mi kò mọ̀ bóyá ó fẹ́ ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ alákokò-kíkún. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, bí àkókò ti nlọ, bí ó ṣe nka Ìwé ti Mọ́mọ́nì, ó rí ayọ̀ púpọ̀ síi nínú ìgbésí ayé rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ronú ṣíṣe ìránṣẹ́.”
Ọ̀sẹ̀ méjì ṣáájú kí Arábìnrin Benson tó parí iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, arákùnrin rẹ̀ gba ìpè sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀. Ó nsìn nísisìyí ní Míṣọ̀n Mexico Tuxtla Gutierrez. Nípasẹ̀ Ìwé ti Mọ́mọ́nì, Alàgbà Benson wá láti rí ìgbésí ayé rẹ̀ pẹ̀lú ìmísí nípa ti ẹ̀mí, èyítí ó mú kí ó sin Olúwa àti láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé àwọn nkan yíò ṣẹ. Ìpinnu yẹn jẹ́ ìyanu—ó ní ipa nípasẹ̀ agbára ti àwọn ọ̀rọ̀ ti Krístì.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, mo gba ẹnìkọ̀ọ̀kan yín níyànjú láti túbọ̀ jinlẹ̀ sí ìkẹ́kọ Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Mo mọ̀ pé bí a ṣe nṣàṣàrò lórí àwọn ọ̀rọ̀ Krístì tí a rí nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, Ẹ̀mí yíò ràn wá lọ́wọ́ láti lóye àwọn òtítọ́ ayérayé, àti láti ṣàjọpín ẹ̀rí wa pẹ̀lú àìlẹ́bi sí àwọn tí Olúwa ti pèsè láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Olúwa sọ pé, “Àwọn àyànfẹ́ mi gbọ́ ohùn mi wọn kò sì ṣe sé ọkàn wọn le” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 29:7). Mo jẹ́ri pé àwọn tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run nínú ìgbàgbọ́ yóò jèrè ẹ̀rí òtítọ́ àti jíjẹ́ àtọ̀runwá ti Ìwé ti Mọ́mọ́nì nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Nípa èyí ni mo jẹ́rí ni orúkọ Jésù Krístì, àmín.