Jésù Krístì àti Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀tun Yín
Gbogbo wa lè ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun nípasẹ̀, àti nítorí Jésù Krístì. Àní ẹ̀yin.
Àìsọtó ìwé-mímọ́ kan: Jésù Lọ Kiri Ní Ṣíṣe Rere
Jésù “lọ ní ṣíṣe rere.” A ka ìròhìn rírọrùn náà nínú ìwé Ìṣe àwọn Àpóstélì. Irú àìsọtó nlà tí èyí jẹ́! Ó dájú pé Jésù lọ ní ṣíṣe rere! Òun gan-an ni kókó—àti orísun—ohun rere! Ó fi gbogbo ìgbésí ayé ikú Rẹ̀ ṣe rere. Ó kún fún “ìyọ́nú àti oore-ọ̀fẹ́, ìjìyà pípẹ́, àti ọ̀pọ̀ oore àti òtítọ́.”
Ìgbìyànjú èyíkéyìí láti ṣàpèjúwe tàbí ṣàkópọ̀ oore àti àánú Rẹ̀ yíò jẹ́ àìsọtó! Ní tòótọ́, gẹ́gẹ́bí Àpóstélì Jòhánnù ti gbìyànjú láti sọ, bí a bá gbìyànjú láti ṣàkọsílẹ̀ gbogbo àpẹrẹ àti ìfihàn oore Olùgbàlà, “àní ayé fúnra rẹ̀ kò lè gba àwọn ìwé tí ó yẹ kí á kọ.”
Jésù Krístì Nfún Olúkúlùkù Wa ní Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀tun Yín
Àwọn àpẹrẹ pàtó díẹ̀ tí a kò yípadà nínú ìwé mímọ́ tí Jésù nlọ ní “ṣíṣe rere” rú ìbẹ̀rú àti ìyàlẹ́nu tí ó jinlẹ̀ sókè, pàápàá nígbàtí a bá ronú gidi ohun tí ó lè dàbí láti wà níbẹ, láti ṣẹlẹ́rìí àwọn iṣẹ́́ ìyanu Rẹ̀, láti gba àwọn ìkọ́ni Rẹ̀, àti láti nírìrí mímúláradá Rẹ̀. Ó nbá àwọn ìbákẹ́gbẹ́ ìsánsá sọ̀rọ̀, Ó fọwọ́ kan àwọn aláìsàn àti aláìmọ́, Ó mú àwọn aláàárẹ̀ lọ́kàn balẹ̀, Ó kọ́ àwọn ènìyàn ní òtítọ́ tó ntúni sílẹ̀, Ó sì pe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sí ìrònúpìwàdà. Sí olúkúlùkù adẹ́tẹ̀, ọkùnrin afọ́jú, àti obìnrin onípanṣágà; sí arọ, adití, àti odi; fún gbogbo ìyá tó nṣọ̀fọ̀, baba tó nṣọ̀fọ̀, àti opó tó nṣọ̀fọ̀; sí àwọn tí a dá lẹ́bi, àwọn tí ojú ntì, àti àwọn tí njìyà; sí òkú nínú ara tàbí òkú nínú ẹ̀mí, ohun tí Ó ṣe ni fífúnni ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun. Bẹ́ẹ̀ ni, àìsọtó tí ó yani lẹ́nu míràn!
Gbogbo ohun tí Ó sọ tí ó sì ṣe pèsè ìbẹ̀rẹ̀ titun fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn wọnnì tí Ó mú láradá, bùkún, tí ó kọ́, tí ó sì gbà lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Kò yà kúrò lọ́dọ̀ wọn, dájúdájú Òun kò sì ní fà sẹ́hìn kúrò lọ́dọ̀ yín. Ẹ fojúinú wo ní àkokò yí ní gbígbọ́ èyíkéyìí nínú àwọn ọ̀rọ̀ fífúnni-níyè láti ọ̀dọ́ Rẹ̀:
“Ọmọ, a dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”
“Ọmọbìnrin, mo wí fún ọ, dìde.”
“Bẹ́ẹ̀ni èmi kò dá ọ lẹ́bi: lọ, kí o má sì ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́.”
“Ọmọbìnrin, tújúká: ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ lára dá; máa lọ ní àlàáfíà”
Àwọn ọ̀rọ̀ Olùgbàlà sí àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan wọ̀nyí jẹ́ kúkúrú, ṣùgbọ́n pẹ̀lú wọn Ó ya àwọn ìjìnlẹ̀ titun títóbi ti ìdáríjì, ìwòsàn, ìmúpadàbọ̀sípò, àlàáfíà, àti ìyè ayérayé. Àti pé ìròhìn ológo náà ni pé, Ó nfi ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun kannáà fún ẹ̀yin àti fún èmi. Gbogbo wa lè ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun nípasẹ̀, àti nítorí Jésù Krístì. Àní ẹ̀yin. Àwọn ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun wà ní ọkàn kan ti ètò Baba Ọ̀run fún àwọn ọmọ Rẹ̀. Èyí ni Ìjọ ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun. Èyí ni Ìjọ ti Jésù Krístì!
Èyí ni Ìjọ ti àwọn Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀tun.
Pẹ̀lú ìrìbọmi nípasẹ̀ omi àti Ẹ̀mí, a “di àtúnbí” a sì lè “rìn nínú ayé titun.” Ìrètí mélòó ni ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun náà mú wá fún ẹni tó ti rìn lábẹ́ ẹrù ìnira ẹ̀ṣẹ̀ tàbí tí wọ́n jìyà ìyọrísí ìgbésí ayé onídààmú àti ìbáṣepọ̀ tí kò dára? Jésù kò nílò ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ Fúnrarẹ̀ tàbí ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun nínú ìgbésí ayé, síbẹ̀ òun fúnra Rẹ̀ ni a ṣe ìrìbọmi fún, tí ó nfi hàn wá nínú ìtura gíga ọ̀nà sí ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun tí Ó ti gbẹ́ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.
Àti pé ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun yín kìí dédé ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan. A ṣọ́ láti rò pé ìrìbọmi wa jẹ́ ọ̀kan pàtó ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun. Kò rí bẹ́ẹ̀. A kò ní ààyè kan nìkan. Àwọn ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun wọ̀nyí lè ṣẹlẹ̀ ní gbogbo ọjọ́! Àti pé dájúdájú ní gbogbo ọ̀sẹ̀ bí a ṣe njẹ àkàrà kékeré kan tí a sì nmu ife omi kékeré kan ní ìrántí ẹ̀bùn Olùgbàlà wa pípe, ẹnití ó kú fún èrèdí tí ó hàn gbangba ti fífún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun bí a ṣe nílò! Jésù fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun bí a ti nílò.
Pẹ̀lú ìfọkànsìn àti ìforítì nínú ìfaramọ́ sí ìyè titun nínú Krístì, a lè di “ẹ̀dá titun,” níbi tí àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ tí ohun gbogbo sì ti di titun. Ìdákẹ́jẹ̀ẹ́ wo ni àǹfààní kejì náà nmú wá fún ọkàn kan tí ó ngbìyànjú láti tẹ̀ síwájú láti yan ìgbàgbọ́ nínú agbára Olùràpadà wa láti wòsàn àti láti múpadà bọ̀ sípò, láìka àwọn ìfàsẹ́hìn pípalẹ̀ ti gbígbé nínú ayé ìṣubú sí? Olùgbàlà kò rẹ̀wẹ̀sì nínú ìfaramọ́ Rẹ̀ láti mú ìfẹ́ Baba ṣẹ àti láti parí iṣẹ́ ètùtù Rẹ̀ àtọ̀runwá, àní nípa ìrora tí ó mú Un wárìrì, láti ṣẹ̀jẹ̀ nínú gbogbo ihò, láti jìyà ara àti ẹ̀mí, kí ó sì gbàdúrà kí a lè mú ife kíkorò náà kúrò. Lẹ́ẹ̀kansi, O nṣàfihàn fún wa kíni ìfaradà òtítọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run dàbí.
Pẹ̀lú gbogbo májẹ̀mú tí a bá dá àti gbogbo ìsapá tí a bá ṣe láti pa á mọ́, a lè gba “ọkàn titun” àti ìwọ̀n ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ti “ẹ̀mí titun.” Díẹ̀díẹ̀, bí a bá ti npe oore rẹ̀ sínú ọkàn wa tí a sì nlé àwọn ohùn ṣíṣẹ́gun araẹni jáde ní orí wa, a ndi ènìyàn Rẹ̀ nítorípé a fi Òun ṣe Ọlọ́run wa nítòótọ́. Jésù fẹ́ láti jẹ́ Ọba wa àti Olùṣọ́ Àgùntàn wa àti Ọmọ aládé Àlàáfíà wa, a sì gbọ́dọ̀ yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ọkàn àti èrò inú tiwa fúnra wa.
Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀tun Ní Bí A Ṣe Fojú Wo Ìrònúpìwàdà
Ìrònúpìwàdà nṣílẹ̀kùn sí àwọn ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun wa, àwọn ìbẹ̀rẹ̀ titun, àti àwọn ààyè kejì. Ààrẹ Nelson wa ọ̀wọ́n ti mú àwọn èrò òdì kúrò nípa ẹ̀bùn àtọ̀runwá ti ìrònúpìwàdà, mo sì rò pé a ti bẹ̀rẹ̀ sí í lóye rẹ̀ níkẹhìn.
Ó dùn mọ́ni gan-an láti gbọ́ tí àwọn ọ̀dọ́ wa nṣàlàyé ohun tí ìrònúpìwàdà túmọ̀ sí fún wọn. Laipẹ mo gbọ́ ọdọmọbinrin kan tó sọ, pẹ̀lú ẹ̀rínmúsẹ́ lójú rẹ̀ pé, “Nígbàtí mo bá ronú nípa ìrònúpìwàdà, mo nnímọ̀lára ayọ̀ àti ìrètí yíyanilẹ́nu. Mo nnímọ̀lára ìfẹ́ àti ayọ̀ Baba mi Ọ̀run àti Olùgbàlà mi. Èmi kò bẹ̀rù láti wá sọ́dọ́ Baba Ọ̀run nínú àdúrà àti láti bèèrè fún ìrànlọ́wọ́ Rẹ pẹ̀lú ohunkohun ti mo n tiraka pẹ̀lú. Mo mọ pé kìí ṣe pé Wọn ngbìyànjú láti ká mi ní ṣíṣe ohun tí kò tọ́. Àwọn apá wọn ṣí gbòòrò. Ìyẹn ni ìrònúpìwàdà sí mi,. Ọ̀dọ́mọbìnrin yìí lóye pé nítorí Jésù Krístì, òun lè ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun!
Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀tun fún Gbogbo Ènìyàn, Ní Gbogbo Ìgbà
Njẹ́ ẹ nílò ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun? Njẹ́ ẹ lè ṣe ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun, àní ẹ̀yin? Ẹ ronú nípa àwọn ènìyàn tí Olùgbàlà ṣe ìránṣẹ́ fún—àwọn ènìyàn tí Ó kọ́, wòsàn, jí dìde, dáríjì, tí Ó sì mú padàbọ̀sípò. Njẹ́ Ó nṣà wọ́n láti inú ẹ̀ka ètò ọrọ̀ ajé tàbí ìpìlẹ̀ kan? Njẹ́ Ó nfi ìyàtọ̀ sí ààrín àwọn olódodo àti ẹlẹ́ṣẹ̀? Njẹ́ Ó nyọ àwọn ènìyàn jáde nítorí pé wọ́n yẹ díẹ̀ síi tàbí a fẹ́ràn wọn díẹ̀ síi? Rárá.
Àwọn kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nlá, wọ́n sì gba agbára Rẹ̀ láti mú láradá—gẹ́gẹ́bí obìnrin tí ó ní ìsun ẹ̀jẹ̀, balógun ọ̀rún ará Rómù tí ìránṣẹ́ rẹ̀ nkú, adẹ́tẹ̀, Jáírù, tàbí Bartíméù afọ́jú. Olúkúlùkù wọ́n fi ìgbàgbọ́ wọn sórí ìlà, nírètí pé oore àti agbára ti Rabbi láti Násárẹ́tì yíò yí ìgbé ayé wọn àti ìrètí wọn padà. Ó sì ṣeé! Ó jẹ́ kí ìwòsàn Rẹ̀ ṣàn.
Ṣùgbọ́n Jésù pẹ̀lú bùkún àwọn tí wọ́n nígbàgbọ́ tó nṣiyèméjì, gẹ́gẹ́bí baba ọmọ tó nṣàìsàn náà tí ó kígbe, bóyá bí ẹ̀yin náà ti ṣe pé, “Olúwa, mo gbàgbọ́, ràn àìgbàgbọ́ mi lọ́wọ́.” Ó sì tú àánú sí àwọn tí kò wá a rárá, gẹ́gẹ́bí obìnrin tí a mú nínú panṣágà, opó Náínì, amukun ọkùnrin ní adágún Bẹ́tẹ́sídà, àti ọkùnrin tí a bí ní afọ́jú. Njẹ́ ẹ ti nímọ̀lára pé Ò nlọ kiri ní ṣíṣe rere nínú ìgbésí ayé yín bí, àní nígbàtí ẹ̀yin kò ì tí wá A tàbí tẹ̀lé E?
Sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ònkàwé inú Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí, àti fún gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ gbọ́ tí wọ́n sì dáhùn, Ó fún wọn ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun kan, bóyá ó jẹ́ ìyè titun ni didáríjì fún ẹ̀ṣẹ̀, tàbí ìyè titun ní mímú láradá kúrò nínú àìsàn, tàbí ìyè titun ní jíjí dìde kúrò nínú òkú.
Kíni eléyìí túmọ̀ sí fún ẹ̀yin àti èmi? Oore Rẹ̀, àánú rẹ̀, ati inú-rere-onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ kò mọ ààlà. Àwọn ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun wà ní ọkàn ti ètò Baba! Ìbẹ̀rẹ̀ titun jẹ́ iṣẹ́́ ìránṣẹ́ ti Ọmọ! Àwọn òwúrọ̀ titun, àwọn ìpín titun, àti àwọn ààyè titun jẹ́ kókó rírọrùn ti ìròhìn ìhìnrere!
Nítorínáà, njé ẹ ti yapa kúrò jù nínú àwọn májẹ̀mú yín láti gba ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun? Rárá. Njẹ́ ẹ ti ṣe èyí tàbí ìyẹn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà láti fúnni ní ààyè míràn? Rárá. Njẹ́ ẹ ti lọ jinnà púpọ̀ látọ̀dọ̀ Krístì fún Un láti ṣèrànwọ́ fún yín láti kọ ìtàn titun láti ibí yí lọ? Rárá. Ọ̀tá náà nìkan ni ó ní ànfààní láti inú èrò pé ẹ ti rì. Ẹ kìí ṣe bẹ́ẹ̀.
Àti pé àwọn ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun jẹ́ díẹ̀ si ju àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn àṣìṣe wa lọ. Nípa oore àti oore-ọ̀fẹ́ Olùgbàlà, a lè ní àwọn ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun tó nmú ìyípadà nínú àwọn ìrònú àtijọ́, ìwà búburú, ìrònú ìríra, ìhùwàsí òdì, ìmọ̀lára àìlágbára, àti ìtẹ̀sí láti dá àwọn ẹlòmíràn lẹ́bi kí a sì yẹra fún ojúṣe ti araẹni. Ẹ lè ṣe ìyípadà àwọn nkan nípa ara yín tí ó ti rìn yín mọ́lẹ̀ fún àwọn ọdùn. Ẹ lè bẹ̀rẹ̀ lẹ́ẹ̀kansi nípasẹ̀ agbára Olórí àwọn ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun. Kò rẹ̀ Ẹ́ rí ní fífi wọ́n fún wa.
Sí àwọn wọnnì tí wọ́n ntiraka pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ kan náà tàbí ìfàsẹ́hìn kan náà léraléra, ẹ̀yin ẹ máa tẹ̀síwájú. Kò fi ìdínà kan sí iwájú yín. Ko fi ààlà sí àwọn ààyè kejì yín. Ẹ tẹ̀ síwájú. Ẹ máa gbìyànjú. Ẹ wá ìrànwọ́ lọ́dọ̀ àwọn tí ó wà ní àyíká yín. Ẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun tí ó wà fún yín ní gbogbo ìgbà tí ó bá yí yín padà sí Baba yín ní òtítọ́ ọkàn. Ẹ jẹ́ kí á fi mímọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀, àwọn àtúnwí àìròtẹ́lẹ̀, àti ìṣọ̀tẹ̀ ìgbéraga sílẹ̀ lẹ́hìn wa níbití wọn wa. Ẹ kò níláti jẹ́ ẹni tí ẹ ti jẹ́ tẹ́lẹ̀. Ẹ gbá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun yín mọ́ra, ààyè kéjì tàbí kẹ́ta tàbí kẹ́rin—tàbí ọgọ́ọ̀rúnẹ̀—, tí a fi rúbọ sí yín nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ètùtù Jésù Krístì.
Ìmoore mi kọjá àpèjúwe lọ fún ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun tí a ti fún mi àti fún àwọn tí a ó ṣì tún fi fúnni.
Íparí
Olùgbàlà wa sọ àìsọtó ìkẹ́hìn láìsí èyí tí kò ní sí ìdí fún ìrètí tàbí yíyọ̀ ní ọjọ́ òní. Lẹhìn ìrora Gẹtisémánì àti ní ìparí àgbélébùú oró, Ó kàn sọ pé, “Ó ti parí.” Àsọtẹ́lẹ̀ Mèsáíàh ti di mímúṣẹ, a sì ti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ àti ìjìyà ẹ̀dá ènìyàn ní kíkún. Ó kéde “ó parí” ẹbọ àìlópin àti ayérayé Rẹ̀. Síbẹ̀ Ètùtù Rẹ̀ kì yíò pé títí tí Òun fúnra rẹ̀ yíò fi ní ìrírí ìgbé ayé titun ní ọjọ́ kẹ́ta, ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun náà bíi ẹni ìṣelógo, ẹ̀dá tí a jí dìde nípasẹ̀ agbára Baba.
Nítorí pé ó máa nṣe àwọn ohun tí ó wu Baba Rẹ̀ nígbà gbogbo, àti nítorí pé Ó “jìyà ìfẹ́ Baba nínú ohun gbogbo,” ìwọ àti èmi lè ní àwọn ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun. Ẹ gba ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun yín, àní lónìí, ní báyìí. Jésù Krístì ni Olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti Aláṣeparí ìgbàgbọ́ wa, tó nkọ àwọn ìpín titun àìníye pẹ̀lú wa. Òun ni Ìbẹ̀rẹ̀ àti Òpin—òpin ti ìtìjú àti ìjìyà wa, àti ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé titun nínú Rẹ̀, jíjẹ́ kí a fi ohun tí ó ti kọjá sẹ́hìn kí a tún bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú òwúrọ̀ titun ní iye ìgbà tí a nílò. Nítòótọ́ “oore àti àànù Rẹ̀ yíò máa tẹ̀lé [wa] ní gbogbo ọjọ́ ayé [wa].” Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.