Ẹ̀bun Ayérayé ti Ẹ̀rí
Gbogbo ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin Ọlọ́run lè ní ìmọ̀ jíjinlẹ̀, fífẹsẹ̀múlẹ̀, àti ìmọ̀ dídánilójú fún ara wọn.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, láìpẹ́ yìí mo ti nronú lórí àwọn òtítọ́ alágbára mẹ́ta láti inú Ìmúpadàbọ̀sípò. Àwọn òtítọ́ wọ̀nyí ti bùkún ìgbésí ayé mi ní kíkún. Lónìí, èmi yíò fẹ́ láti ṣàwárí wọn ní ṣókí àti lẹ́hìnnáà ṣàbápín ọ̀nà kan tí wọ́n ti ṣamọ̀nà mi lórí ìrìn-àjò mi sí ẹ̀rí tí ó dájú ti ìhìnrere Jésù Krístì.
1. Ọlọ́run Jẹ́ Olùfẹ́ni Baba Wa Ọ̀run
Ó jẹ́ olóye ohun gbogbo àti alágbára gbogbo. Nípasẹ̀ Ìmọ́lẹ̀ Krístì àti iṣẹ́-ìránṣẹ́ ti Ẹmí Mímọ́, ipa Rẹ̀ wa níbi gbogbo. Ó wà nínú ìṣẹ̀dá Rẹ̀ láti bùkún wa.
Ó nrí àtijọ́, ìsisìnyí, àti kádàrá ayérayé wa. Kò sí ohun tí ó lè pamọ́ fún Un.
Ìpè Ààrẹ Russell M. Nelson láti “ronú sẹ̀lẹ́stíà” ngbà wá níyànjú láti fara wé ìran àti ìṣẹ̀dá Baba wa Ọ̀run.
Nítorí àwọn ànímọ́ tọ̀run Rẹ̀, Baba wa Ọ̀run fún wa ní gbogbo ẹ̀bùn rere, ọ̀kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ojú ìwòye ayérayé àti ìran Rẹ̀ ní ọkàn.
2. Agbára Òmìnira Jẹ́ Ẹ̀bùn láti Yàn àti láti Ṣe Fúnrawa
Ó tún jẹ́ ojúṣe láti yàn dáradára.
Jésù Krístì san iye tí ó gajù fún ànfààní náà pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ iyebíye Rẹ̀.
Nígbà míràn a lè gbàgbọ́ pé agbára láti yàn túmọ̀ sí ṣíṣe ohunkóhun tí a fẹ́. Ṣùgbọ́n òtítọ́ pé a san ìdíyelé rẹ̀ túmọ̀ sí pé agbára òmìnira jẹ́ ẹ̀bùn mímọ́.
A jẹ́ aṣojú, àti pé àwọn aṣojú ní ojúṣe kan. Ní ọ̀ràn yí, a ní ojúṣe fún àwọn yíyàn tí a ṣe ní dídá lórí ìmọ̀ tí a ní àti àwọn ẹ̀bùn tí a fún wa. A kò lè ṣe yíyàn láì gba ojúṣe fún àwọn àbájáde.
Kínìdí tí a fi ní agbára láti yàn?
Láti yàn rere.
Láti yan Krístì.
3. Ẹ̀rí Wa Wá Nípasẹ̀ Agbára Ẹ̀mí Mímọ́
Ẹlẹ́rìí láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ tóbi jù ojúran. Òun ni ẹlẹ́rìí pàtàkì Baba àti Ọmọ. Ààrẹ Nelson kọ́ni, “Ní àwọn ọjọ́ tí ó nbọ̀, kò ní ṣeéṣe láti yè ní ti-ẹ̀mí láìsí títọ́nisọ́nà, dídarí, titùnínú, àti ti ipa Ẹ̀mí Mímọ́ ní léraléra.”
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ìdí nìyí tí olúkúlùkù wa fi nílò agbára Ẹ̀mí Mímọ́ lónìí.
Ẹ̀rí nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ lè wá ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà. Gẹ́gẹ́bí gílóòbù ìmọ́lẹ̀ nínú yàrá dúdú, ó lè wá ní àràọ̀tọ̀ àti lójijì. Ó lè wá bíi ìlà-oòrùn díẹ̀díẹ̀ àti ní àkokò púpọ̀. Ó lè wá bíi ìtànṣán ìmọ́lẹ̀, ìfihàn lemọ́lemọ́ sí òye mímọ́. Èyíkèyí ọ̀nà, ó nwá nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.
Wíwá Ẹ̀rí ní Jamaica
Mo dàgbà ní ìlú rírẹwà Jamaica; ó jẹ́ ìgbádùn àti ìyanu. Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, nígbàtí mo bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ gíga, àwọn ọmọ kíláàsì àti àwọn ọ̀rẹ́ tí wọn kò lè lóye ìpinnu mi láti jẹ́ ọmọ Ìjọ ti Jésù Krístì. “Báwo ni o ṣe lè darapọ̀ mọ ìjọ náà?” ni wọn yíò bèèrè. “Báwo lo ṣe lè gba ìtàn yẹn gbọ́?”—tó ntọ́ka sí Ìran Àkọ́kọ́. “Báwo lo ṣe lè ka ìwé yẹn?”—nítọ́ka sí Ìwé ti Mọ́mọ́nì.“ “Njẹ́ o gba gbogbo ìyẹn gbọ́ lóòótọ́?” Àti pé “Kínìdí tí o fi nfi ẹ̀mí rẹ ṣòfò?”
Ó jẹ́ ohun ìrora, pàápàá nígbàtí ó wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí mo bìkítà nípa.
Ṣùgbọ́n ohun tí wọn kò mọ̀ ní èyí: Mo ní ìrírí pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́. Bí ẹ̀rí yẹn ti kún ọkàn mi, ó mú ìrora àwọn ọjọ́ di afẹ́fẹ́, àti “fún ìṣẹ́jú kúkúrú kan, ojú ọ̀run [farahàn] níwájú mi.”
Bóyá a ti bèèrè díẹ̀ nínú àwọn ìbèèrè wọ̀nyí. Bóyá, àní ní báyìí ẹ ti wà ní kíkọlù bíi tèmí.
Ẹ̀bùn àti ẹlẹ́rìí ti Ẹ̀mí Mímọ́ wà fún gbogbo ènìyàn.
Jamaica sí mi jẹ́ bí Palmyra ṣe jẹ́ sí Joseph Smith. Ó jẹ́ Igbó Ṣúúrú Mímọ́ mi. Èmi kò mọ ààyè gangan níbití Joseph kúnlẹ̀ láti gbàdúrà ní Igbó Ṣúúrú Mímọ́, ṣùgbọ́n mo mọ̀ ní pàtó ibití mo wà nígbàtí Igbó Ṣúúrú Mímọ́ mi di òtítọ́. Ó ṣẹlẹ̀ ní Ẹ̀kẹ́rin Ọ̀nà Igbó ṣúúrú, Mandeville, Jamaica, nínú balùwẹ̀ mi, ní aago mẹ́fà òwúrọ̀ ní ọjọ́rú kan ọdún mẹ́ta lẹ́hìn ìrìbọmi mi. Ìrírí mímọ́ yìí ṣẹlẹ̀ nítorí pé ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́hìn ni arábìnrin ojíṣẹ́ ìhìnrere kan tí a mí sí pè mí láti ka Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Arábìnrin Audrey Krauss wà ní ìpàdé àpapọ̀ yí lónìí pẹ̀lú ẹbí rẹ̀, èmi sì fẹ́ràn rẹ títí láé.
Ìrírí náà yí mi padà.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ẹ̀rí kan kò jẹ́ fún lílò fún ìgbà díẹ̀. Ẹ̀bùn yí láti ọ̀dọ̀ Baba Ọ̀run ní láti jẹ ayérayé nítorí olùfúnni jẹ́ ayérayé. Ẹ̀rí kò yẹ kí ó ní ọjọ́ ìparí. Kò yẹ kí ó rẹ̀wẹ̀sì tàbí dínkù nítorí ohun kan nínú ìgbésí ayé mi ti yípadà tàbí ohun kan ti yípadà ní àgbáyé. Ó yẹ kí ó túbọ̀ lágbára sí i nítorí, gẹ́gẹ́bí ìránṣẹ́ nínú àkàwé àwọn tálẹ́ntì, ẹ̀rí ara mi jẹ́ ẹ̀bùn tí a lè sọ di púpọ̀—kìí ṣe láti sin.
Wíwẹ̀hìn wo àwọn ọjọ́ ìṣòro dídánwò àti inúnibíni ràn mí lọ́wọ́ láti dé ibi tí mo ti mọ̀ fúnra mi báyìí. Èmi kò gbàgbọ́, ní ìrètí, tàbí ní ìgbẹ́kẹ̀lé nìkan, bíótilẹ̀jẹ́pé ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn pátíkù pàtàkì ti ìgbàgbọ́ lórí ipa ọ̀nà sí ẹlẹ́rìí tó dájú. Mo yìn yín fún ṣíṣe ọ̀nà tiyín nípa bíbèèrè àwọn ìbèèrè, ṣíṣàṣàrò, gbígbàdúrà, gbígbààwẹ̀ àti ìjíròrò. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ máṣe dúró. Ó tọ́ sí gbogbo ìgbìyànjú láti lépa ipa ọ̀nà yí sí ẹ̀rí. Tani tàbí kíni ẹ̀yin yíò gbà láàyè láti mú ìyẹn lọ? “Irú ẹ̀rí nlá wo ni ẹ lè ní ju látọ̀dọ̀ Ọlọ́run?”
Gbogbo ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin Ọlọ́run lè ní ìmọ̀ jíjinlẹ̀, fífẹsẹ̀múlẹ̀, àti ìmọ̀ dídánilójú fún ara wọn. Gẹ́gẹ́bí Joseph Smith, ẹnití ó fìdí ẹ̀rí rẹ̀ múlẹ̀ láìka àtakò sí, a lè sọ pẹ̀lú ìgboyà, “Mo mọ̀, mo sì mọ̀ pé Ọlọ́run mọ̀, èmi kò sì lè sẹ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò le ṣe é.”
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábinrin mi ọ̀wọ́n, ẹ jẹ́ kí irúgbìn ẹ̀rí kéékèèké ṣiṣẹ́ nínú yín títí tí yíò fi dàgbà di ìmọ̀ tí ó dájú tí ó lógo títí ayérayé
Bí ẹ bá ti ṣèrìbọmi tí a sì ti fẹsẹ̀ wọn múlẹ̀ bí ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ṣùgbọ́n tí wọn ntiraka pẹ̀lú, “Èmi kò mọ̀ bóyá mo mọ̀,” jọ̀wọ́ rántí ìlérí yi nínú àdúrà oúnjẹ́ Olúwa: “Kí wọn lè ní Ẹ̀mi rẹ̀ láti wà pẹ̀lú wọn nígbagbogbo.” Nítorí ìlérí yí, olúkúlùkù wa lè lépa ọ̀nà sí ẹ̀rí àti ìmọ̀ tó dáju.
Wà ní Ìkáwọ́ Ẹ̀rí Yín
Bàyíì òtítọ́ títóbi nìyí: Lọ́nà yìówù tí a bá jẹ́ ẹ̀rí—yálà ó dà bíi àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn tàbí ó wá nínú ìran ológo kan—ó ṣì nbèèrè yíyàn kan láti gba ẹ̀bùn ṣíṣeyebíye yí.
Wípé “Mo yàn láti gbàgbọ́” mú kí ó rọrùn láti gba ẹ̀rí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Bí a bá rí i pé ẹ̀rí wa nrẹ̀wẹ̀sì, ẹ rántí pé àwọn yíyàn tí a ṣe ló ndín agbára ẹ̀rí kù. Ṣùgbọ́n ẹ̀rí náà kò tíì lọ síbikíbi. A kàn nílò láti yàn láti tún sopọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.
Yíyàn láti gbàgbọ́ jẹ́ ọ̀nà alágbára láti lo agbára òmìnira.
Èmi kò lè rí ọ̀nà tí ó dára jùlọ láti lo agbára láti yàn mi ju ní dídáàbò bò ẹ̀rí mi lọ.
Ààrẹ Nelson kọ́ni pé: “Mo bẹ̀ yín láti wà ní ìkáwọ́ ẹ̀rí yín. Ṣiṣẹ́ fún un. Gbà á. Ṣe ìtọ́jú fún un. Ṣíkẹ́ rẹ̀ kí ó lè dagbà. Fi òtítọ́ bọ́ ọ.”
Sí mi, àwọn ọ̀rọ̀ náà gba àkóso, iṣẹ́, ìtọ́jú, ní, bojútó, àti bọ́ dún bí aṣojú olùrànlọ́wọ́ tí a fún ní ìríjú fún nkan iyebíye tí ó sì ṣe pàtàkì.
Nínú Ìjọ àkọ́kọ́, Parley P. Pratt ní ìmọ̀lára ìbínú sí Wòlíì Joseph Smith ó sì yàn láti ṣàríwísí òun àti Ìjọ. “Nígbàtí John Taylor, ẹnití Parley kọ́ ní ìhìnrere, wá sí ìlú, Parley mú u lọ sí apákan ó sì kìlọ̀ fún un láti máṣe tẹ̀lé Joseph. John Taylor wí fún Parley láti:
“Ṣaájú kí ó tó kúrò ní Canada, ó jẹ́ ẹ̀rí tí ó lágbára nípa Joseph Smith pé ó jẹ́ wòlíì Ọlọ́run, … o sì sọ pé ó mọ nkan wọ̀nyí nípa ìfihàn àti ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́.”
“… Mo ti wá ní ẹ̀rí kan náà tí ẹ̀ nyọ̀ nínú rẹ̀ nígbà náà. Bí iṣẹ́ náà bá jẹ́ òtítọ́ ní oṣù mẹ́fà sẹ́hìn, ó jẹ́ òtítọ́ lónìí. Bí Joseph Smith bá jẹ́ wòlíì nígbànáà, wòlíì ni báyìí.”
Èmi jẹ́ ẹ̀rí pé Joseph Smith jẹ́ wòlíì Ọlọ́run àti pé ẹ̀wù àsọtẹ́lẹ̀ tí ó gbà ntẹ̀síwájú ní lónìí. Jésù Kristi ló ndarí iṣẹ́ yìí.
Mo pè yín láti ronú nípa ọ̀nà yín sí ẹlẹ́rìí tí ó dájú ti Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀. Ẹ wà ní ìkáwọ́ ẹ̀rí yín; ẹ lo agbára láti yàn yín pẹ̀lú ọgbọ́n kí ẹ sì jẹ́wọ́ olùfúnni àti gbogbo àwọn àbùdá ológo Rẹ̀. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé agbára wà nínú yín. Kò sí ẹni tí ó lè yàn fún yín. Kò sí ẹni tí ò lè gba ẹ̀bùn yí. Ẹ lè yàn láti gbàgbọ́.
Mo ṣèlérí pé bí ẹ ṣe nṣe èyí, ẹ̀rí yín yíò jẹ́ “kanga omi ìyè, tó nrú jáde sí ìyè àìnípẹ̀kun.” Yíò jẹ́ ìdákọ̀ró àti ìwúrí kan, yíò sì gbé yín ró ní àwọn àkokò ìṣòro. Ó máa mú kí ẹ mú ẹ̀bùn ti-ẹ̀mí dàgbà. Yíò ràn yín lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìrànṣẹ́ ara ẹni yín àti iṣẹ́ ìsìn yín. Yíò jẹ́ ohun ìjà sí Sátánì àti àwọn ọ̀tá yín. Ẹ̀rí yín yíò jẹ́ ayọ̀ bí ẹ ṣe rí i tí a ṣe àtúnṣe nínú àwọn ọmọ yín, àwọn ọmọ-ọmọ yín, àti àwọn ọmọ-ọmọ-ọmọ yín àti nínú àwọn wọnnì tí ẹ fẹ́ràn tí ẹ sì nsìn. Yíò jẹ́ alágbára nígbàtí ẹ bá pín in tí ẹ sì lò ó láti jẹ́ ẹ̀rí.
Bí ẹ bá mọ̀, ẹ mọ̀. Mo mọ̀ pé mo mọ̀. A nílò àwọn ẹlẹ́rìí tó dájú ti Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀. Dé ibẹ̀! Wá a! Ní kíákíá ni! Èyí ni iṣẹ́ ìríjú tí ó kẹ́hìn—iṣẹ́ ìríjú ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àkokò.
Jésù Krístì kéde òtítọ́ yìí pé: “Ọ̀run àti ayé yíò kọjá lọ, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yíò kọjá lọ.”
Ẹ̀yin arákunrin àti arábìnrin, ẹ̀rí Jésù Krístì kò túmọ̀ sí láti jẹ́ ẹ̀bùn ìgbà díẹ̀. Kò sí nkankan nípa rẹ̀ tí ó jẹ fún ìgbà díẹ̀—kìí ṣe olùfúnni, kìí ṣe ẹ̀bùn fúnrararẹ̀, kìí ṣe olùfẹ̀bùn náà jíṣẹ́, kìí ṣe ẹnití ẹ̀bùn náà wà nípa. Njẹ́ kí a ṣe àpèjúwe ẹ̀rí yín ní ọ̀nà yí kannáà. Bíótilẹ̀jẹ́ pé “ọ̀run àti ayé yíò kọjá lọ,” ẹ̀rí yín àti ẹlẹ́rìí ìhìnrere Jésù Krístì kì yíò kọjá lọ. Báyìí ni àkokò láti di gbogbo ẹ̀bùn iyebíye mú. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.