Èròjà Ìròhìn Rere
Nítorínáà, kíni ohun tí ó lè dàbí láti ṣe àfikún Jésù Krístì síi sínú ayé wa?
Bí ẹ bá bẹ ilé ìpínlẹ̀ wa ti Louisiana wò, bóyá ẹ ó ní ìfaramọ́ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ounjẹ dídún wa—gumbo, jambalaya, étouffée, àti títòsílẹ̀ tí ó nlọ tí ó sì nlọ.
Láti ìgbà sí ìgbà, mo ri ara mi ní níní ìmọ̀lára ìgboyà tí ó tó láti se ọ̀kan lára àwọn èròjà dídún wọnnì. Ìgbésẹ̀ ìgbẹ̀hìn àìkọsílẹ̀ lẹ́hìn ríro gbogbo ohun-èlò pọ̀ àti títẹ̀lé àlàyé-kíkún àwọn ìkọ́ni náà ni láti ṣe ìdánwò ìgbẹ̀hìn àtọ́wò kí a sì ri bí ohunkóhun bá sọnù. Ní àmì náà, mo lè gbọ́ tí Creole aláròsọ dídáná kùn sí mi létí “Fi ti Tony púpọ̀ síi nínú.” Ti Tony ni èròjà creole tí a ṣe ní Opelousas, Louisiana, ilú àbínibí mi. A máa nlò ó léraléra bí ohun “ohun-èlò àṣírí” láti jẹ́ ìsanpadà fún àwọn àìpé tí a ṣe nígbàtí à ntẹ̀lé ìjúwe náà.
Michelle àti èmi ní ìbọláfún láti sìn bí olùdarí míṣọ̀n ní Louisiana. A ní àṣà ti kíkọ́ àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere bí wọn ó ti se ìjúwe jambalaya pàtàkì ní alẹ́ tó gbẹ̀hìn wọn ní ilé míṣọ̀n ṣíwájú pípadà sọ́dọ̀ àwọn ẹbí wọn. Ní àfikún sí àwọn ẹ̀rí wọn nípa ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì, àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere wa fi míṣọ̀n sílẹ̀ pẹ̀lú ìmoore fún àwọn ìjúwe.
Oṣù díẹ̀ sẹ́hìn, mo nyíkiri nínú Ibi-ìkàwé Ìrohìn Ìjọ mo sì rí ìsopọ̀ kan sí àkójọ àwọn fídíò kékèké tí a pè ní Ìbárasọ̀rọ̀ Ìmúpadàbọ̀sípò pẹ̀lú Ààrẹ Russell M. Nelson. Àkọlé kan nípa ọ̀kan nípa àwọn fídíò kúkurú nínú ìtòsílẹ̀ tí ó gba àkíyèsí mi tí ó sì mú mi rẹrin. A pè é ní “Àwọn Ìwé Mímọ́ Ni Ìjúwe Ọlọ́run fún Gbígbé Ìdùnnú.” Mo tẹ̀ fídíò ìṣẹ́jú méjì náà lọ́gán mo sì wo Ààrẹ Nelson tí ó nkọ́ ẹgbẹ àwọn ọmọ Alakọbẹrẹ ní ọ̀rọ̀ ìrọ̀rùn àti alágbára nípa bí wọ́n ṣe lè ní ìdùnnú. Ó kọ́ni: “Bí ẹ bá nṣe àkàra òyìnbó, ẹ ó tẹ̀lé àwọn ìdarí, àbí ẹ kò ṣeé? Ẹ ó sì ní àbájáde rere nígbà gbogbo, ṣe ẹ kò ni?”
Ó tẹ̀síwájú, sísọ̀rọ̀ nípa dídà ọmọ ọdún marundinlọgọrun láìpẹ́: “àwọn ènìyàn nwípé, ‘Kíni o njẹ́? Kíni àṣírí rẹ?’” Ó fèsì, “Àṣírí tí à npè ní àwọn ìwé mímọ́. Ẹ lè kà wọ́n kí ẹ sì gbìyànjú wọn.”
Ó dára, níbẹ̀ ni a ní i. Àṣírí ìrọ̀rùn náà fún ìgbé ìdùnnú ni láti kàn tẹ̀lé ìjúwe Ọlọ́run bí a ti ṣe àlàyé kíkú nínú àwọn ìwé mímọ́. Mo pè é ní “Èròjà Ìròhìn Rere.”
Kíni ẹ ó ṣe bí ẹ bá ṣi ohunkan ṣe nígbàtí ẹ̀ ntẹ̀lé ìjúwe? Ó dára, wíwé sínú Èròjà Àwọn Ìròhìn Rere ni “èròjà àṣírí” láti mu dájú pé ẹ ṣé dáadáa ní ìkẹhìn. Ìdáhùn náà ni Jésù Krístì Nígbagbogbo.
Mo ròó pé gbogbo wa ní àwọn àkokò nígbàtí à nní ìmọ̀ pé àwọn èròjà wa kò dára tó, tàbí à nlàkàkà láti tẹ̀lé àwọn ìdarí, tàbí bóyá a ṣe ohunkan tí kò tọ́, tàbí ohunkan tí ó nṣẹlẹ̀ tí ó kọjá ìṣàkóso wa, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Kíni àtúnṣe náà? Ó kan jẹ́ láti ṣe àfikún síi nípa ohun tí ó npe Jésù Krístì wá sínú ayé yín.
Nítorínáà, kíni ohun tí ó lè dàbí láti ṣe àfikún Jésù Krístì síi nínú ayé wa?
Nígbàtí mò nsìn bí ààrẹ míṣọ̀n, mo ní inúdídùn ti pípàdé níti araẹni mi pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ti àwọn ọ̀dọ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere wa ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ mẹ́fàmẹ́fà. Ní ìgbà ìpàdé ojúkojú, ó wọ́pọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere láti wá ìtọ́sọ́nà lórí bí wọn ó ṣe mú dídárasi ti ojúgbà wọn gbèrú si.
Ní ọ̀ràn kan, ìránṣẹ́ ìhìnrere kan wá sínú ìfọ̀rọ̀wànilẹ́nuwò araẹni rẹ̀ ó sì joko sílẹ̀. Mo lè wí látinú èdè ara rẹ̀ pé ohunkan ntẹ̀ẹ́ mọ́lẹ̀ gidi nínú rẹ̀. Mo bèèrè, “Alàgbà, kíni ó fẹ́ láti sọ ní òní?” Ó bẹ̀rẹ̀ sí njúwe àwọn ìpènijà tí ó nní pẹ̀lú ojúgbà rẹ̀ àti bí ó ṣe npa ìlèṣe wọn láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn lára. Pẹ̀lú omijé ní ojú rẹ̀, ó wò mí ó sì bèèrè, “Ààrẹ, kíní mo níláti ṣe?”
Ní ẹsẹ̀kẹsẹ̀ náà, pẹ̀lú òtítọ́ inú èmì kò mọ̀ bí èmi ó ṣe fèsì. Lẹ́hìn àkokò díẹ̀, mo bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bí ó bá DÁRA fún wa láti kúnlẹ̀ papọ̀ nínú àdúrà fún ìtọ́nisọ́nà látinú Ẹ̀mí. Ó faramọ, a sì kúnlẹ̀ papọ̀ a sì gbàdúrà fún ìmísí.
Lẹ́hìn àdúrà, a tẹ̀síwájú láti kúnlẹ̀ fún ìgbà kúkurú a sì joko nígbànáà nínú àwọn àgà tí ó kọjú síra. Mo bèèrè bí a bá lè ka ìwé mímọ́ papọ. Bí a ṣe ṣí àwọn ìwé mímọ́ wa, “Alàgbà, bí a ṣe nka ìwé mímọ́ yí, jọ̀wọ́ bèèrè ìbèèrè wọ́nyí lọ́wọ́ ara rẹ̀: Bí mo bá gbé àwọn ìhùwà wọ̀nyí, ṣe yíò mú ojúgbà mi àti iṣẹ́ ìhìnrere wa gbèrú si?”
Nígbànáà a ṣí Mórónì 7:45 a sì kàá jáde: “Ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ a máa mú sũrù, a sì máa ṣeun, kì í sì íṣe ìlara, kì í sì í fẹ̀, kì íwá ohun tí ara rẹ̀, a kĩ múu bínú, kĩ gbèrò ohun búburú, kì í sì í yọ̀ nínú àìṣedẽdé, ṣùgbọ́n a máa yọ̀ nínú òtítọ́, a máa faradà ohun gbogbo, a máa gbà ohun gbogbo gbọ́, a máa reti ohun gbogbo, a sì máa fọkàn rán ohun gbogbo.”
Alàgbà náà nígbànáà wò mí pẹ̀lú omijé ní ojú rẹ̀ ó sì wípé, “Bẹ́ẹ̀ni, Ààrẹ, ṣùgbọ́n ìyẹn yíò le láti ṣe.” Mo faramọ mo sì rán an létí pé ó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, pẹ̀lú agbára ìlèṣe tọ̀run láti ṣe é papọ̀ pẹ̀lú Olúwa.
Nígbànáà a sọ̀rọ̀ òwe gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ díẹ̀ tí Alàgbà Clark G. Gilbert ti Àádọ́rin kọ́ni, èyítí ó rán wa létí pé a nílò láti bẹ̀rẹ̀ níbi tí a wà àti, papọ̀ pẹ̀lú Olúwa, lọ síwájú àti sókè ní ìdarí dídára. Mo lè sọ pé ó ṣì nní ìmọ̀lára ìbonimọ́lẹ̀ díẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìgbésẹ̀ tó tẹ̀le, nítorínáà mo ní kí ó júwe òye rẹ̀ nípa ìwé mímọ́ “nípa àwọn ohun kékeré àti ìrọ̀rùn ni àwọn ohun nlá nmú wá sí ìmúṣẹ.” Ó sì ṣe àpèjúwe ìrò náà nípa ṣíṣe àwọn ohun kékeré àti ìrọ̀rùn, àwọn ohun nlá lè ṣẹlẹ̀. Mo ní kí ó mú iṣẹ́jú kan kí ó sì dá àwọn ohun kékeré méjì àti ìrọ̀rùn tí ó lè ṣe láti jẹ́ onínúrere sí ojúgbà rẹ̀ mọ̀.
Lẹ́hìn àkokò díẹ̀, ó pín àwọn èrò rẹ̀. Nígbànáà mo ní kí ó mú iṣẹ́jú kan kí ó sì dá àwọn ohun kékeré méjì àti ìrọ̀rùn tí ó lè ṣe láti jẹ́ onísùúrù pẹ̀lú ojúgbà rẹ̀ mọ̀. Ní kété ó pín àwọn èrò rẹ̀ méjì. Ó hàn kedere pé ó ti njíròrò èyí tẹ́lẹ̀ ṣíwájú ìpàdé wa. Mo pè é láti mú àwọn ohun-èlò díẹ̀ wọnnì lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run nínú àdúrà àti láti bèèrè fún ìfẹsẹ̀múlẹ̀, ìdarí, àti ìmísí lórí bí yíò ṣe ṣe ètò rẹ̀ pẹ̀lú èrò-inú òdodo. Ó faramọ. Bí a ṣe parí, mo ní kí ó pèsè ìmúdójú-ìwọ̀n ránpẹ́ nínú lẹ́ta ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀.
Bí àwọn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tó tẹ̀le ti kọjá lọ, mo lè ríi nínú àwọn lẹ́tà rẹ̀ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ pé àwọn nkan ti ngbèrú si. Ṣùgbọ́n kìí ṣe pé mo lè rí gbígbèrú náà nìkan nínú àwọn lẹ́tà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ rẹ̀ bákannáà mo sì lè ríi nínú àwọn lẹ́tà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ti ojúgbà rẹ̀. Ní ìgbà ìpàdé ojúkojú wa tó tẹ̀le, mo rí ìyàtọ̀ alẹ́-àti-ọjọ́ kan nínú ìrírsí àti ẹ̀mí rẹ̀. Mo bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀, “Nítorínáà, Alàgbà, ṣe òtítọ́ ni pé ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ kìí kùnà rárá?’” Ó fèsì pẹ̀lú ẹ̀rín nlá: “Bẹ́ẹ̀ni, àti pé nípa àwọn ohun kékeré àti ìrọ̀rùn ni a ṣe nmú àwọn ohun nlá wá sí ìmúṣẹ.”
Bí ẹ ṣe ntẹ̀lé Ìjúwe Àwọn Ìròhìn Rere fún gbígbé inúdídùn, ẹ rántí ìkọ́ni Ààrẹ Nelson: “Eyikeyi àwọn ìbèèrè tàbí wàhálà tí ẹ ní, ìdáhùn náà ni à nrí nínú ìgbé ayé àti àwọn ìkọ́ni Jésù Krístì nígbàgbogbo. Ẹ kẹ́kọ̀ọ́ si nípa Ètùtù Rẹ̀, ìfẹ́ Rẹ̀, àánú Rẹ̀, ẹ̀kọ́ Rẹ̀, àti ìmúpadábọ̀sípò ìhìnrere ìwòsàn àti ìlọsíwájú Rẹ̀. Yípadà sí I! Ẹ Tẹ̀lé E!”
Nígbàtí ẹ bá nílò láti “gbọ́ Tirẹ̀” kí ẹ sì mọ bí ẹ ó ti pè Jésù Krístì sínú ayé yín, ẹ yẹ títẹ̀lé àwọn ìgbẹ́sẹ̀ tí Ààrẹ Nelson kọ́ wa nípa ìfihàn araẹni wò:
“Ẹ wá ibi jẹ́jẹ́ tí ẹ lè lọ léraléra. Ẹ rẹ arayín sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run. Ẹ tú ọkàn yín jáde sí Bàbá Ọ̀run. Ẹ yípada Sí I fún àwọn ìdáhùn àti fún ìtùnú.
“Ẹ gbàdúrà ní orúkọ Jésù Krístì nípa àwọn àníyàn yín, àwọn ẹ̀rù yín, àwọn àilera yín—bẹ́ẹ̀ni, àwọn ìfẹ́ inú ti ọkàn yín gan an. Àti nígbànáà tẹ́tísílẹ̀! Kọ àwọn èrò tí ó bá wá sí ọkàn rẹ sílẹ̀. Ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìmọ̀lára rẹ kí o sì tẹ̀lée pẹ̀lú àwọn ìgbésẹ̀ tí o bá ní ìmísí láti gbé. Bí ẹ ti nṣe àṣetúnṣe àwọn ètò yi ní ọjọ́ dé ọjọ́, oṣù dé oṣù, ọdún dé ọdún, ẹ̀yin ó ‘dàgbà sínú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ ti ìfihàn.’”
Mo jẹ́ri pé Jésù Krístì ni Olùgbàlà àti Olùràpadà wa. Ó ti “ṣe àṣeyọrí ohungbogbo tí a nílò láti lè padà sí ọ̀dọ Baba [wa] Ọ̀run.” Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.