Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Olúwa Nwo Ọkàn
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwàá 2025


10:41

Olúwa Nwo Ọkàn

Gbogbo ohun tí Ọlọ́run nílò láti mú àwọn èrèdí Rẹ̀ ṣẹ àti láti ṣèrànwọ́ fún wa láti di ẹni tí Ó fẹ́ ni fún olúkúlùkù wa láti yí ọkàn wa padà sí Iní kíkún.

Nígbàtí wọ́n pa á láṣẹ pé kí wọ́n yan ọba titun ní Ísráẹ́lì lára àwọn ọmọ Jésè, wòlíì Sámúẹ́lì, nígbàtí ó wo Élíábù, ọmọkùnrin Jésè, ó fi ìtara kígbe pé: “Dájúdájú, ẹni àmì òróró Olúwa wà níwájú rẹ̀.” Ṣùgbọ́n Élíábù kìí ṣe ìránṣẹ́ tí Olúwa yàn. Olùgbàlà kìlọ̀ fún Sámúẹ́lì pé: “Má ṣe wo ojú rẹ̀, tàbí sí gíga rẹ̀; nítorí èmi ti kọ̀ ọ́: nítorí Olúwa kò rí bí ènìyàn ti nrí; nítorí ènìyàn a máa wo òde ara, ṣùgbọ́n Olúwa a máa wo ọkàn.”

Bótilẹ̀jẹ́pé Dáfídì lè má jẹ́ alágbára jù lọ níti ara tàbí lòye jù lọ nínú àwọn arákùnrin rẹ̀, ọkàn rẹ̀ lágbára lójú Ọlọ́run. Ó fẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀ ó sì ní ìfẹ́ jíjinlẹ̀ láti ṣègbọràn sí I. Ó ní ìgbàgbọ́ àìyẹsẹ̀ nínú ìfẹ́, agbára, àti àwọn ìbùkún Ọlọ́run, gẹ́gẹ́bí ó ṣe fi hàn lẹ́yìn náà nígbàtí ó fi àìbẹ̀rù jagun tí ó sì ṣẹ́gun Goliath pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olúwa.

Ìtàn yí kọ́ wa pé gbogbo ohun tí Ọlọ́run nílò láti mú àwọn ìpinnu Rẹ̀ ṣẹ àti láti ṣèrànwọ́ fún wa láti di ẹni tí Ó fẹ́ kí á dì ni fún olúkúlùkù wa láti yí ọkàn wa padà ní kíkún sí I. Sí agbẹjọ́rò kan, O´ pàṣẹ, “Ìwọ o´ fẹràn Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ.” Sí Wòlíì Joseph Smith, Ó wípé, “Kíyèsíi, Olúwa bèèrè fún ọkàn àti inú ìfẹ́.” Àti sí àwọn Néfì, olùjínde Olùgbàlà nawọ́ ìfipè yí: “Ẹ ó fi ẹbọ ìrora ọ̀kàn àti ẹ̀mí ìròbìnújẹ́ fún mi.”

Kínidí tí ó fi jẹ́ bẹ́ẹ̀? Olùgbàlà kọ́ni pé bí ọkàn wa bá yí padà ní kíkún sí Ọ̀dọ̀ Rẹ̀, nítorí ìrúbọ ètùtù Rẹ̀, a lè jẹ́ alábùkún pẹ̀lú agbára àti àwọn ẹ̀bùn ti ẹ̀mí tí a nílò láti ṣẹ́gun àwọn ìpèníjà ayé ikú, kíkojú ìdánwò, gba ìdarí àti òye, kí a sì ní ìmọ̀lára ayọ̀ àti àlàáfíà nínú ìgbésí ayé wa. Nínú àwọn ohun kékeré ni èyí ti ó tóbi ti nwá.” Ó wí pé Òun lè “sọ àwọn ohun aláìlera di alágbára” kí ó sì bùkún wa pẹ̀lú ohun gbogbo tí a nílò láti ṣàṣeyọrí nínú ayé ikú yìí àti láti gba ìyè àìnípẹ̀kun. “Alábùkúnfun ni àwọn ọlọ́kàn mímọ́,” Ó wípé, “nítorí wọn yíò rí Ọlọ́run.”

Mo gbàgbọ́ pé èyí nìdí ti, ó kèrè jú ní apákan, Jèsú Krístì nígbàgbogbo ṣe àtúnṣe àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí nìgbá iṣẹ̀ ìrànṣẹ́ ayé ikú Rẹ̀. Bíótilẹ̀jẹ́ aláápọn láti pa òfin Rẹ̀ mọ́, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún àìtọ̀. Ó bá wọn wí pé, “Àwọn ènìyàn yìí fi ẹnu wọn súnmọ́ mi, wọ́n sì nfi ètè wọn bọlá fún mi, ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà sí mi.”

Èyí jẹ́ ìránnilétí tí ó fọkàn balẹ̀ fún gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀ pé kìí ṣe nípa ohun tí a nṣe nìkan—ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa—ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìdí tí a fi nṣe ohun tí Jésù Krístì ti ní kí a ṣe—àwọn ìfẹ́-ọkàn àti ìsúnniṣe wa. Ó wípé, “Nítorí èmi, Olúwa, yíò ṣe ìdájọ́ gbogbo ènìyàn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn wọn.” Baba wa Ọ̀run fẹ́ ju àwọn ìṣe ìgbọràn àti iṣẹ́ ìsìn lọ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Rẹ̀. Ó nfẹ́ ká ṣe àwọn nkan wọnnì pẹ̀lú èrò-inú gidi nítorípé a fẹ́ràn Rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa. Ó fẹ ká fẹ́ láti dàbí Òun.

Nísisìyí, bí ìlera tẹ̀mí ti ọkàn wa bá jẹ́ àníyàn àkọ́kọ́ ti Olùgbàlà—ohun tí Ó nretí nínú ọmọ-ẹ̀hìn tòótọ́—báwo ni a ṣe lè yẹ ọkàn wa wò kí a sì mọ̀ bóyá ó tọ̀nà níwájú Ọlọ́run?

Láìpẹ́ yìí, bí èmi àti ìyàwó mi ṣe padà dé láti iṣẹ́ míṣọ̀n wa ní ilẹ̀ Portugal, a ṣe onírúurú àyẹ̀wò ìlera láti ṣàyẹ̀wò ipò ara wa. Díẹ̀ nínú àwọn ìdánwò wọnnì da lórí ìlera ọkàn wa—bí irú àwọn àyẹ̀wò ẹjẹ, àwọn ìwò-ẹ̀jẹ̀, àti àwọn ìdànwó wàhálà. Mo gbàgbọ́ pé Olùgbàlà tún ti pèsè fún wa ní àkójọpọ̀ àwọn ìdánwò ti ẹ̀mí tí a lè lò làti ṣe àyẹ̀wò ipò ti ọkàn ẹ̀mí wa. Ẹ jẹ́ ki nṣe àbápín díẹ̀ pẹ̀lú yín.

Yíyẹ Ọkàn Yín Wò pẹ̀lú àwọn Ìdánwò Ti-ẹ̀mí

Ní àkọ́kọ́, ìkọjúsí wa, àwọn Ààyò, àti àwọn Ìmúniṣe

“Nítorí níbití ìṣúra yín bá wà, níbẹ̀ ni ọkàn yín yíò wà pẹ̀lú,” Jésù kọ́ni. Ìṣúra jẹ́ ohun iyebíye fún wa, ohun kan tí a yà sọ́tọ̀ fún ìtiraka àti àfiyèsí. Ibi tí a ti yàn láti lo àkókò wa àti tí a fi àfiyèsí wa sùn sí, àti ohun tí ó nmú wa láti ṣe ohun tí a ṣe, sọ púpọ̀ nípa ọkàn wa. Olùgbàlà kìlọ̀ pé nígbàtí ó jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni a pè nípasẹ̀ Rẹ̀, díẹ̀ ni a yàn “nítorí wọ́n gbé ọkàn wọn sórí àwọn ohun ti ayé yìí, [wọ́n] sì nlépa àwọn ọlá ènìyàn.” Njẹ́ mo fi Olùgbàlà ṣe ààyò ní ìgbésí ayé mi? Ojú mi ha ṣọ̀kanṣoṣo sí ògo Rẹ̀ ní gbogbo ohun tí mo nṣe bí?

Ìkejì, Níní-ìfẹ́ wa láti Gbọràn sí àwọn Òfin Ọlọ́run

Ní gbogbo ìwé mímọ́, Olúwa àti àwọn wòlíì Rẹ̀ ti so ìgbéraga àti àìgbọràn pọ̀ pẹ̀lú níní ọkàn líle. Néfì gba àwọn arákùnrin rẹ̀ níyànjú pé: “Báwo ni ó ṣe jẹ́ tí ẹ̀yin kò pa àwọn òfin Olúwa mọ́? Ẽṣe tí ẹ̀yin ó ṣègbé, nítorí líle ọkàn yín?” Sí Àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní Missouri, Olúwa kìlọ̀, “Ṣùgbọ́n ẹni tí kò bá ṣe ohunkóhun títí tí a fi pa á láṣẹ, tí ó sì gba òfin kan pẹ̀lú ọkàn iyèméjì, tí ó sì pa á mọ́ pẹ̀lú ìmẹ́lẹ̀, òun náà ni a dá lẹ́bi.” Nígbàtí Olùgbàlà kò nírètí pípé ní pípa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, Ó bèèrè pé kí á fẹ́ àti kí á gbìyànjù làti pa wọ́n mọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa.

Ìkẹta, Ìtara Wa nínú Ṣíṣe Àṣàrò àwọn Ìwé Mímọ́ àti Wíwá Ìfihàn

Olúwa gba Oliver Cowdery níyànjú láti “fi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pamọ́ sínú ọkàn yín.” A pè wá láti ṣe iwadii àwọn ìwé mímọ́ pẹ̀lú ìtara àti, nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́, wá láti gba òye àti ẹ̀rí ti jíjẹ́ òtítọ́ ìhìnrere náà nínú ọkàn wa.

Wòlíì Ábínádì bá àwọn àlùfáà Ọba Nóà búburú wí pé wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀, wípé: “Ẹ̀yin kò fi ọkàn yín sí òye; nítorí náà, ẹ kò gbọ́n.” Njẹ́ mo nṣe ìtiraka tòótọ́ láti ṣàṣàrò ìwé mímọ́ lójoójúmọ́ àti láti fi ọkàn mi sí àti lóye wọn nípa àdúrà?

Ẹ̀kẹ́rin, Àwọn Èrò àti àwọn Ọ̀rọ̀ Wa

Olùgbàlà kọ́ni pé “láti inú ọkàn ni àwọn èrò búburú ti jáde wá” àti pé “láti inú ọ̀pọ̀ yanturu ọkàn ni ẹnu nsọ.” Dídára àwọn èrò àti àwọn ọ̀rọ̀ wa jẹ́ àfihàn tí ó dára ti mímọ́ ọkàn wa. Njẹ́ mo nṣe ìgbèrò ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èrò òdì púpọ̀ nípa àwọn ìṣe tàbí àwọn ìsúnniṣe tí àwọn míràn, tàbí pàápàá nípa ara mi bí? Njẹ́ mo yára púpọ̀ láti ṣe ìdájọ́ àti da àwọn míràn lẹ́bi? Njẹ́ mo nwá àwọn àwáwí tàbí ìdáláre fún àwọn àṣìṣe mi? Àti kíni nípa àwọn ọ̀rọ̀ mi? Njẹ́ wọ́n gbésókè àti ṣèwúrí fún àwọn tí wọ́n wà ní àyíká mi? Tàbí wọ́n sábà máa ndá ìjà àti ìbínú sílẹ̀?

Lẹ́hìn tí àwọn àyẹ̀wò ti ara mi ti parí, dókítà mi sọ fún mi pé, lápapọ̀, ọkàn mí ní ìlera—ṣùgbọ́n àwọn ìfiyèsí díẹ̀ wà tí ó nílò kíkojú báyìí, ṣaájú kí wọ́n tó di pàtàkì. Lẹ́hìnnáà ó júwe díẹ̀ nínú àwọn ìyípadà ìgbésí ayé. Bákannáà, bí ẹ ṣe nṣe ìgbéléwọ̀n ẹ̀mí ti ọkàn yín tí ẹ ṣe àkíyèsí díẹ̀ nínú àwọn àmì àìsàn òdì tí ó bẹ̀rẹ̀ síí wọ inú, jọ̀wọ́ máṣe bẹ̀rù Olùgbàlà ti pèsè òògùn àti ìtọ́jú ti ẹ̀mí tó dára jùlọ láti ṣèrànwọ́ fún yín. Ó ti ṣèlérí pàápàá láti fún yín ní ọkàn titun! Nihin ni díẹ̀ nínú àwọn ìṣe tí ó lè mú okun ti-ẹ̀mí ọkàn yín dára si.

Mímú Ìlera Ọkàn Ti-ẹ̀mí Yín Dárasi

Àkọ́kọ́, Ẹ Fún Ìbáṣepọ̀ Yín pẹ̀lú Krístì Lókun

Bí a ṣe nya àkókò sọ́tọ̀ lójoojúmọ́ láti sún mọ́ Krístì síi, ọkàn wa nyípadà. Ṣíṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́ lójoojúmọ́, pẹ̀lú àdúrà àtọkànwá àti ààwẹ̀ déédé, yíò mú ìfẹ́ yín fún Olùgbàlà pọ̀ síi, yíò sì fún ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ yín láti ronúpìwàdà àti pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ so ọkàn yín fún Ọlọ́run. Gbé àpẹrẹ yìí láti ọ̀dọ̀ Néfì yèwò: “Nítorí-èyi, mo ké pe Olúwa; sì kíyèsíi ó bẹ̀ mí wò, ó sì rọ̀ mí lọ́kàn pé mo gba gbogbo ọ̀rọ̀ tí baba mi ti sọ gbọ́.”

Bí a ṣe ntẹ̀síwájú láti bọ́ irúgbìn ìgbàgbọ́ nípasẹ̀ àwọn ìfẹ́ òdodo àti ìṣe wa, a ó ní ìrírí ìsọdimímọ́ ọkàn wa kan náà gẹ́gẹ́bí àwọn ará Néfì: “Wọ́n gbààwẹ̀, tí wọ́n sì ngbàdúrà léraléra, wọ́n sì túbọ̀ lágbára síi nínú ìrẹ̀lẹ̀ wọn, wọ́n sì fẹsẹ̀múlẹ̀ àti fẹsẹ̀múlẹ̀ sìi nínú ìgbàgbọ́ ti Krístì, sí kíkún ọkàn wọn pẹ̀lú ayọ̀ àti ìtùnú, bẹ́ẹ̀ni, àní sí ìwẹ̀mọ́ àti ìyàsímímọ́ ọkàn wọn, ìyàsímímọ́ èyí tí ó wá nítorípé wọ́n yí ọkàn wọn sí Ọlọ́run.”

Ìkejì, fífi Ìfẹ́ Yín Sí Ìbámu pẹ̀lú Tirẹ̀

Olùgbàlà kọ́ni, “Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn mi, ẹ pa àwọn òfin mi mọ́⁠.” Ó pè wá láti ṣe àfihàn ìfẹ́ wa nípa ṣíṣe àti pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ pẹ̀lú Rẹ̀. Bí a ṣe nlàkàkà lójoojúmọ́ láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, tí a sì ronúpìwàdà tọkàntọkàn kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, tí a sì nforí tì ní gbígbé orúkọ Rẹ̀ lé ara wa, tí a sì nfi ìfẹ́ wa sí ìbámu pẹ̀lú Tirẹ̀, a lè rí ìbùkún gbà pẹ̀lú ojúgbà ìgbà gbogbo ti Ẹ̀mí Mímọ́.

Néfì jẹ́ ẹ̀rí pé: “Mo mọ̀ pé bí ẹ̀yin bá tẹ̀ lé Ọmọ, pẹ̀lú èrò ọkàn ní kíkún, láìṣe àgàbàgebè tàbí ẹ̀tàn kankan níwájú Ọlọ́run, ṣùgbọ́n pẹ̀lú èrò gidi, ní ìrònúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, ní jíjẹ́ ẹ̀rí sí Baba pé ẹ̀yin múra tán láti gbé orúkọ Krístì lé ara yín, nípa ṣíṣe ìrìbọmi … , nígbànáà ni ẹ̀yin yíò gba Ẹ̀mí Mímọ́.” Ẹ̀mí Mímọ́ yíò tọ́ yín sọ́nà, yíò sì ràn yín lọ́wọ́ láti mọ ìfẹ́ Olúwa àti láti ṣe àwọn yíyàn tí ó dára.

Níkẹhìn, Ẹ Sin Ọlọ́run àti àwọn Míràn pẹ̀lú Gbogbo Ọkàn Yín

Olùgbàlà npe gbogbo ènìyàn láti “fi gbogbo ọkàn yín sin In.” Nígbàtí a bá yàn láti ṣe ohun kọ̀ọ̀kan tí Olúwa ti ní kí a ṣe—gẹ́gẹ́bí pípa àwọn òfin mọ́, jíjẹ Oúnjẹ Olúwa, jíjọ́sìn nínú tẹ́mpìlì, àti sísin àwọn ẹlòmíràn—pẹ̀lú ọkàn òtítọ́ àti pẹ̀lú èrò gidi, iṣẹ́ ìsìn àti ìjọsìn kọ̀ọ̀kan di ìrírí ti ẹ̀mí alágbára tí ó fún ìgbàgbọ́ àti ẹ̀rí wa lókun tí yíò sì kún ọkàn wa pẹ̀lú ayọ̀ àti ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa.

Ìbéèrè wòlíì Alma ṣì njáde lónìí: “Ǹjẹ́ a bí yín nípa tẹ̀mí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí? Njẹ́ ẹ̀yin ti gba àwòrán rẹ nínú ìrísí yín bí? Njẹ́ ẹ̀yin ti ní ìrírí ìyípadà nlá yìi ní ọkàn yín bí?”

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, mo pè yín láti fi gbogbo ọkàn yín fún Olùgbàlà lónìí. Ẹ jẹ́ kí ìṣẹ ìjọsìn àti ìsìn kọ̀ọ̀kan jẹ́ òtítọ́ àti ìmọ̀mọ́mọ̀ ṣe. Ẹ fi àwọn ìdíwọ́ ti àgbáyé sílẹ̀ kí ẹ sì làkàkà láti ní àkókò tí ó nitumọ fún Olúwa ní gbogbo ọjọ́ ayé yín. Ẹ ronúpìwàdà kí ẹ sì padà sọ́dọ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín, Òun yíò dáríjì yín yíò sì yí yín ká nínú apá ìfẹ́ Rẹ̀. Ẹ máṣe wá ohun ayé yí, ṣùgbọ́n ẹ yàn kí ojú yín ṣọ̀kanṣoṣo fún ògo Rẹ̀ kí ẹ sì máa wá ohun tí ó dára jù. Ó mọ èrò yín àti àwọn ìfẹ́ ọkàn yín, bí ẹ sì ti ntọ̀ ọ́ wá, Òun yíò bukun yín pẹ̀lú agbára, ìgboyà, àlàáfíà, àti ayọ̀ ní ayé yìí àti ààyè nínú ìjọba sẹ̀lẹ́stíà Rẹ̀ títí ayérayé.

Mo mọ̀ pé Jésù Krístì wà láàyè. Òun ni Olùràpadà wa. Òun sì fẹ́ràn yín àti èmi pẹ̀lú gbogbo ọkàn Rẹ̀. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.