Ìrọ̀rùn nínú Krístì
Lílo ẹ̀kọ́ mímọ́ ti Krístì ní ọ̀nà ìrọ̀rùn àti ìdojúkọ yóò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa láti wá ayọ̀ nínú àwọn ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́.
1. Ọ̀rọ̀ Ìsáájú
Ní ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n-sẹ́hìn, mo gba ìpè mi láti sìn gẹ́gẹ́bí ìránṣẹ́ ìhìnrere ní Mísọ̀n Ìpínlẹ̀ Utah Ogden. Nítorí bẹ́ẹ̀, nítorí pé mò nbọ̀ láti Yúroopù, díẹ̀ nínú àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ utah bí “Jell-O aláwọ̀ ewé pẹ̀lú cárrọ̀tì” àti “àwọn ànọ̀mọ́ ìsìnkú” jẹ́ pàtàkì díẹ̀ sí mi!
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, mo ni ìwúrí tó jinlẹ̀ nípa ìfọkànsìn àti jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn ti púpọ̀ nínú àwọn Ènìyàn Mímọ́ náà, iye àwọn ènìyàn tí wọ́n nwá sí àwọn ìpàdé Ìjọ, àti ìwọ̀n àwọn ètò Ìjọ tí ó nṣiṣẹ́ ní kíkún. Nígbà tí iṣẹ́ àyànfúnni mi dé òpin, mo fẹ́ rí i dájú pé ayọ̀ tí mo ní àti okun tẹ̀mí àti ìdàgbàdénú tí mo rí yóò tún wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún ìdílé mi lọ́jọ́ iwájú. Mo pinnu kíákíá láti padà wá gbé ìgbésí ayé mi nínú “òjìji àwọn òkè nlá àìnípẹ̀kun.”
Ṣùgbọ́n, Olúwa ní àwọn èrò oríṣiríṣi tí ó yàtọ̀. Ní Ọjọ́ Ìsinmi àkọ́kọ́ ní ilé, ọlọ́gbọ́n bíṣọ́ọ̀pù mi pè mí láti sìn gẹ́gẹ́bí Ààrẹ àwọn Ọ̀dọ́mọkùnrin nínú wọ́ọ̀dù wa. Ní sísìn ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àgbàyanu yi, mo kọ́ ẹ̀kọ́ kíákíá pé ayọ̀ tí ó nwá láti inú jíjẹ́ ọmọ ẹ̀hìn Kristi kò fi bẹ́ẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú títóbi àwọn ìpàdé Ìjọ tàbí ìwọ̀n àwọn ètò.
Nítorínáà nígbàtí mo fẹ́ arẹwà ìyàwó mi, Margret, a fi tayọ̀tayọ̀ pinnu láti dúró sí Europe kí a sì tọ́jú ẹbí wa dàgbà ní orílẹ̀-èdè wa ní Germany. Lápapọ̀ a jẹ́rìí ohun tí Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hin: “Ayọ̀ tí a lérò kò ní nkan ṣe pẹ̀lú àwọn ipò ti ìgbé ayé wa àti pé ó ní ohun gbogbo í ṣé pẹ̀lú ìfojúsí àwọn ìgbé ayé wa.” Nígbàtí ìfojúsí ìgbésí ayé wa bá wà lóri Krístì àti ọ̀rọ̀ ìhìnrere Rẹ̀, a lè ní ìrírí àwọn ìbùkún kíkún ti ọmọ-ẹ̀hìn níbikíbi tí à ngbé.
2. Ìrọ̀rùn Tó Wà nínú Krístì
Bí ó ti wù kí ó rí, nínú ayé kan tí ó túbọ̀ npọ̀ sí i nínú àìlẹ́sìn, dídíjú, pẹ̀lú oríṣiríṣi àti àwọn ọ̀rọ̀ dídani láàmú ìgbàkugbà àti ìbèèrè, báwo ni a ṣe lè yẹra fún dídi afọ́jú kí ọkàn wa sì di líle kí a sì dúró ní ìfojúsí “àwọn ohun tó rọrùn àti iyebíye” ti ìhìnrere Jésù Kristi? Ní àárín àkókò ìdàrúdàpọ̀ kan, àpọ́stélì Páùlù fún àwọn èniyàn mímọ́ ní Kọ́ríńtì ní ìmọ̀ràn nlá nípa rírán wọn létí pé kí wọ́n fi ìdojúkọ wọn sórí “ìrọ̀rùn tí ó wà nínú Kristi.”
Ẹ̀kọ́ ti Krístì àti òfin ti ìhìnrere rọrùn púpọ̀ àní pé àwọn ọmọdé kékeré lè lóye wọn. A lè wọlé sí agbára ìràpadà Jésù Krístì kí a sì gba gbogbo àwọn ìbùkún ti ẹ̀mí tí Baba wa Ọ̀run ti pèsè sílẹ̀ fún wa nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, ìrònúpíwàpà, ṣíṣe ìrìbọmi, dídi mímọ́ nípa ẹ̀bùn ti Ẹ̀mí Mímọ́, àti fíforíti dé òpin. Ààrẹ Nelson ti ṣe àpèjúwe ìrìn àjò yí lọ́nà tí ó rẹwà bí “ọ̀nà májẹ̀mú” àti ètò dídà “ọmọ-ẹ̀hìn olùfọkànsìn ti Jésù Krístì.”
Tí ọ̀rọ̀ yi bá rọrùn púpọ̀, kílódé tí ìpènijjà fi wà púpọ̀ láti gbé òfin Krístì àti tẹ̀lé àpẹrẹ Rẹ̀? Ó lè jẹ́ pé a kò túmọ̀ ọ̀rọ̀ ìrọ̀rùn gẹ́gẹ́bí ohun kan tí ó rọrùn láti ṣe àṣeyọrí láìsí ìlàkàkà tàbí aápọn. Títẹ̀lé Krístì nílò ìlàkàkà léraléra àti ìyípadà nígbàgbogbo. A nìlò láti “[bọ́] ẹ̀dá ènìyàn àdánidá sílẹ̀ kí a sì … [dàbí ọmọ] kékeré.” Èyí pẹ̀lú fífi “ìgbẹ́kẹ̀lé wa sínú Olúwa” àti jíjẹ́ kí dídíjú lọ, gẹ́gẹ́bí àwọn ọmọ kékeré ti ṣe. Lílo ẹ̀kọ́ mímọ́ ti Krístì ní ọ̀nà ìrọ̀rùn àti ìfojúsí yíò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa láti wá ayọ̀ nínú àwọn ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́, fúnni ní ìtọ́sọ́nà nínú àwọn ìpè wa, dáhùn díẹ̀ nínú àwọn ìbéèrè dídíjú jùlọ ìgbésí ayé, kí a sì pèsè agbára láti kojú àwọn ìpènijà nlá wa.
Ṣùgbọ́n báwo la ṣe lè fi ìrọ̀rùn yi sí lílò nínú ìrìn àjò ìgbésí ayé wa gẹ́gẹ́bí ọmọ ẹ̀hìn Kristi? Ààrẹ Nelson rán wa létí láti dojúkọ “òtítọ́ mímọ́, ẹ̀kọ́ mímọ́, àti ìfihàn mímọ́” bí a ṣe nwá láti tẹ̀lé Olùgbàlà. Bíbèèrè nígbàgbogbo, “Kíni Olúwa Jésù Krístì yóò ní kì nṣe?” ṣàfihàn ìtọ́sọ́nà tí ó jinlẹ̀. Títẹ̀lé àpẹrẹ Rẹ̀ npèsè ọ̀nà àìléwu àídánilójú àti ìfẹ́, ọwọ́ ìtọ́sọ́nà láti dìmú láti ọjọ́ dé ọjọ́. Òun ni Ọba Aládé Àlàáfíà àti Olùṣọ́ Àgùntàn Rere. Òun ni Olùtùnú àti Olùgbàlà wa. Òun ni àpáta àti Olùgbàlà wa. Ó jẹ́ ọ̀rẹ́ kan—ọ̀rẹ́ rẹ àti ọ̀rẹ́ mi! Ó nké sí gbogbo wa láti nífẹ Ọlọ́run, pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, àti láti nífẹ ẹnìkéjì wa.
Bí a ṣe nyàn láti ṣe ìṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Krístì, gba agbára Ètùtù Rẹ̀ mọ́ra, tí a sì nrántí àwọn májẹ̀mú wa, ìfẹ́ ó kún ọkàn wa, ìrètí àti ìwòsàn ó gbé ọkàn wa ga, àti pé ìmoore àti sùúrù yíò rọ́pò kíkorò láti dúró de àwọn ìbùkún tí a ṣèlérí. Nígbà míràn, a lè nílò láti ya ara wa kúrò ní ipò tí kò ní ìlera tàbí wá ìrànlọ́wọ́ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n. Ṣùgbọ́n ní gbogbo ọ̀ràn, lílo àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ ìhìnrere tí ó rọrùn yíò ràn wá lọ́wọ́ láti kọjá nínú àwọn ìpèníjà wọ̀nyí ní ọ̀nà Olúwa.
Nígbàmíràn a máa nfojútẹ́mbẹ́lẹ́kú agbára tí a ngbà láti àwọn ìṣe tí ó rọrùn bíi àdúrà, ààwẹ̀, àṣàrò ìwé mímọ́, ìrònúpíwàdà ojoojúmọ́, ṣíṣe àbápín oúnjẹ Olúwa lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, àti jíjọ́sìn déédé ní ilé Olúwa. Ṣùgbọ́n nígbàtí a bá mọ̀ pé a kò nílò láti “ṣe àwọn ohun ńlá kan” tí a sì fi arawa sí oókan ẹ̀kọ́ mímọ́ àti rírọrùn, a ó bẹ̀rẹ̀sí rí bí ìhìnrere náà ṣe “ṣiṣẹ́ lọ́nà yíyanilẹ́nu” fún wa, àní nínú àwọn ipò pípeni-níjà jùlọ. A máa nrí okun àti “ìgbẹ́kẹ̀lé níwájú Ọlọ́run,” àní nígbàtí a bá ní ìrírí ìrora-ọkàn. Alàgbà M. Russell Ballard ti rán wa létí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, “Nínú ìrọ̀rùn yi ni [àwa] yóò rí … àlàáfíà, ìdúnnú, àti ayọ̀.”
Lílo ìrọ̀rùn tí ó wà nínu Jésù Krístì jẹ́kí a ààyò àwọn ènìyàn ṣáájú àwọn ìṣèto àti ìbáṣepọ̀ ayérayé lórí àwọn ìhùwàsí ìgbà-kúkurú. A fi ìdojúkọ sórí “àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ” nínú iṣẹ́ ìgbàlà àti ìgbéga Ọlọ́run dípò kíkópa nínú ṣíṣàkóso iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. A máa nsọ ara wa di òmìnira láti fi àwọn ohun ààyò tí a lè ṣe sànju jíjẹ́ kí àwọn ohun tí a kò le ṣe dè wá mọ́lẹ̀. Olúwa rán wa létí pé: “Nítorínáà, ẹ máṣe jẹ́kí agara dá yín ní ṣíṣe-rere, nítorí ẹ̀yin nfi ìpìlẹ̀ iṣẹ́ nlá lélẹ̀. Àti láti inú ohun kékeré ni ohun nlá ti jáde.” Irú ìgbani-níyànjú alágbára tí ó jẹ́ láti ṣe ìṣe ní ìrọ̀rùn àti ìrẹ̀lẹ̀, awọn ipokípò tó wù kí a wà.
3. Oma Cziesla
Ìyá mi àgbà Marta Cziesla jẹ́ àpẹ̀rẹ ìyanu ti ṣíṣe “àwọn ohun kékeré àti ìrọ̀rùn” láti mú àwọn ohun nlá ṣẹ. A fi pẹ̀lú ìfẹ́ pè é ní Oma Cziesla. Oma gba ìhìnrere náà ní abúlé kékeré ti Selbongen ní Ìlà-oòrùn Prussia papọ̀ pẹ̀lú ìya-àgbà mi ní Ọgbọnjọ́ Osù Karun, 1926.
Marta Cziesla (lọ́tun) ní ọjọ́ ìrìbọmi rẹ̀.
Ó nífẹ Olúwa àti ìhìnrere Rẹ̀ ó sì pinnu láti pa àwọn májẹ̀mú tí ó ti dá mọ́. Ní 1930 ó fẹ́ baba mi àgbà, ẹnití kì í ṣe ọmọ Ìjọ. Ní ààyè yi kò ṣeéṣe fún Oma láti lọ sí àwọn ìpàdé Ìjọ nítorí pé oko baba-àgbà mi jìnnà sí àpéjọ tí ó súnmọ́ jùlọ. Ṣùgbọ́n ó ìkọjúsí ohun tó lè ṣe. Oma tẹ̀síwájú láti gbàdúrà, ka àwọn ìwé mímọ́, ó sì kọ àwọn orin Síónì.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lè ti rò pé òun kò ṣe déédé mọ́ nínú ìgbàgbọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n èyí jìnà sí òtítọ́. Nígbàtí a bí àntí mi àti bàbá mi, láìsí oyè àlùfáà nínú ilé àti láìsí àwọn ìpàdé Ìjọ tàbí ààyè sí àwọn ìlànà tí ó wà nítòsí, ó tún ṣe ohun tí ó lè ṣe ó sì kọjúsí kíkọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ “láti gbàdúrà, àti láti rìn ní ìdúróṣinṣin níwájú Olúwa.” Ó ka àwọn ìwé mímọ́ fún wọn, ó kọ orin Síónì pẹ̀lú wọn, ó sì ngbàdúrà pẹ̀lú wọn—lójoojúmọ́. Ìrírí Ìjọ jẹ́ ìdá ọgọ́ọ̀rún kan àríngbùngbùn-ilé.
Ní 1945 baba mi àgbà nsìn nínú ogun tó jìnnà sí ilé. Nígbàtí àwọn ọ̀tá súnmọ́ oko wọn, Oma mú àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì ó sì fi oko àyànfẹ́ wọn sílẹ̀ lẹ́hìn láti wá ibi ìsádi sí ibi tí kò léwu. Lẹ́hìn ìrìn àjò tí ó ṣòro tí ó sì nmu ìwàláàyè-léwu, nígbẹ̀hìn wọ́n rí ibi ìsádi ní Oṣù Karun ti 1945 ní àríwá Germany. Wọn kò ní nkankan tí ó kù bíkòṣe aṣọ tí ó wà lára wọn. Ṣùgbọ́n Oma pẹ̀lú ohun tí ó lè ṣe: ó gbàdúrà pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀—lọ́jọ́ gbogbo. Ó bá wọn kọ àwọn orin Síónì tí ó ti há sórí—lójoojúmọ́.
Ìgbésí ayé rẹ̀ jẹ́ líle gidi àti pé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ó kàn fojúsí ríríi dájú nìkan pé oúnjẹ wà lórí tábìli. Ṣùgbọ́n ní 1955 baba mi, nígbànáà ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, nlọ sí ilé ẹ̀kọ́ òwò ní ìlú Rendsburg. Ó rìn lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé kan ó sì rí àmì kékeré kan lóde tó kà báyi “Kirche Jesu Christi der Heiligen der Letzten Tage”—“Ìjọ Jésù Kristi ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.” Ó ronú pé, “Ìyẹn wúni lórí; èyí ni Ìjọ Ìyá.” Nítorínáà nígbà tó délé, ó sọ fún Oma pé òun ti rí ìjọ rẹ̀.
Ẹ lè fojú inú wo bó ṣe máa rí lára rẹ̀ lẹ́hìn ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún mẹ́ẹdọ́gbọ̀n tí kò rí ìjọ rẹ̀. Ó pinnu láti lọ ní Ọjọ́-ìsinmi tó nbọ̀ ó sì rọ baba mi láti bá òun lọ. Rendsburg ju ogun (20) máìlì (ọgbọ̀n-ó-lé-méjì 32 kìlómítà) lọ kúrò ní abúlé kékeré ti wọn ngbé. Ṣùgbọ́n èyí kò ní dí Oma lọ́wọ́ láti lọ sí ilé ìsìn. Ní Ọjọ́-ìsinmi tó tẹ̀le, ó gun kẹ̀kẹ́ rẹ̀ papọ̀ pẹ̀lú baba mi wọ́n sì gun kẹ̀kẹ́ lọ sí ilé ìsìn.
Nígbàtí ìpàdé oúnjẹ Olúwa bẹ̀rẹ̀, baba mi jóko ní ìlà tó kẹ́hìn, nírètí pé yíò parí láìpẹ́. Èyí ni Ìjọ Oma kì í ṣe tirẹ̀. Ohun tí ó rí kò fúnni ní ìyànjú gan-an: àwọn àgbà obìnrin mélòó kan nìkan ni wọ́n wà ní ijoko àti pé àwọn ọ̀dọ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere méjì tí wọ́n nbójú tó gbogbo nkan ní ìpàdé dáradára. Ṣùgbọ́n nígbànáà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọrin, wọ́n sì kọ orin Síónì tí baba mi ti gbọ́ láti ìgbà ọmọdékùnrin rẹ̀ pé: “Wá, Wá, Ẹ̀yin Ènìyàn Mímọ́,” “Áà Baba mi,” “Ìyìn fún Ọkùnrin náà.” Gbígbọ́ agbo kékeré yi tí wọ́n nkọ àwọn orin tí òun ti mọ̀ láti ìgbà èwe gún ọkàn rẹ̀, ó sì mọ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ àti láìsí iyèmejì pé Ìjọ náà jẹ òtítọ́.
Ìpàdé oúnjẹ Olúwa àkọ́kọ́ tí ìyá àgbà mi lọ lẹ́hìn ọdún marundínlọ́gbọ̀n ni ìpàdé ibití baba mi ti gba ìjẹ́risí ti araẹni nípa jíjẹ́ òtítọ́ ìhìnrere Jésù Krístì tí a mú padàbọ̀sípò . Ó ṣe ìrìbọmi ní ọ̀sẹ̀ mẹ́ta lẹ́hìnnáà, ní ọjọ karùndínlọ́gbọ̀n (25) Oṣù Kẹsan, 1955, papọ̀ pẹ̀lú baba àgbà àti àbúrò baba mi.
Ó ti ju Àádọ́rin ọdún lọ láti ìgbà ìpàdé oúnjẹ Olúwa kékeré náà ní Rendsburg. Mo sábà máa nronú nípa Oma, bí yíò ṣe ti rí lára rẹ̀ ní àwọn alẹ́ tó dá nìkan wà, tó nṣe àwọn nkan kékèké àti àwọn nkan tó rọrùn tó lè ṣe, bí gbígbàdúrà, kíkàwé, àti kíkọrin. Bí mo ṣe dúró sí ìhìn ní òní ní ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò tí mo sì nsọ̀rọ̀ nípa Oma mi, ìpinnu rẹ̀ láti pa àwọn májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa láìka àwọn ìjàkadì rẹ̀ kún ọkàn mi pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ àti ìmoore—kì í ṣe fún òun nìkan ṣùgbọ́n fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Ènìyàn mímọ́ oníyanu jákèjádò ayé tí wọ́n fojúsí ìrọ̀rùn nínú Krístì nínú àwọn ipò ìpèníjà wọn, bóyá nípa rírí ìyípadà díẹ̀ nísisìyí ṣùgbọ́n níní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ohun ńlá náà yíò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú.
4. Àwọn nkàn kékeré àtí tó Rọrùn
Mo ti kọ́ ẹ̀kọ́ nípasẹ̀ ìrírí ti ara mi pé àwọn ohun kékèké àti rírọrùn ti ìhìnrere àti fífi ìṣòtítọ́ kọjúsí ọ̀dọ̀ Krístì máa ntọ́ wa sọ́nà sí ayọ̀ tòótọ́, nmú àwọn iṣẹ́ ìyanu nlá wá, o sì nfún wa ní ìdánilójú pé gbogbo àwọn ìbùkún tí a ṣèlérí yíò ṣẹ. Èyi jẹ́ òtítọ́ fún ọ bí ó ti jẹ́ òtítọ́ fún mi. Ní àwọn ọ̀rọ̀ Alàgbà Jeffrey R. Holland, “Àwọn ìbùkún kan máa nwá láìpẹ́, àwọn kan yíò pẹ́ wá, àwọn míràn kìí sì wá títí di ọ̀run; ṣùgbọ́n fún àwọn tí wọ́n gba ìhìnrere ti Jésù Krístì, wọ́n nwá.” Nípa èyí ni mo jẹ́rí bákannáà ni orúkọ Jésù Krístì, àmín.