Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Agbára Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ sí Ẹni Náà
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwàá 2025


10:27

Agbára Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ sí Ẹni Náà

Bí a ṣe nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún ẹni náà, à npe ẹni náà láti wá sọ́dọ̀ Jésù Krístì àti láti jọ́sìn nínú ilé Olúwa.

Ẹ̀yin arábìnrin àti arákùnrin, a dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ìfọkànsìn ìṣòtítọ́ yín ní wíwá sọ́dọ̀ Jésù Krístì ní àwọn àkókò pípèníjà wọ̀nyí. Ènìyàn àgbàyanu ni yín; ẹlẹ́wà ni yin; ọmọ Ọlọ́run ni ẹnìkọ̀ọ̀kan yín. Àdúrà mi ni pé kí a mọ ipa Ẹ̀mí Mímọ́ bí a ti ndi tí a sì nran ara wa lọ́wọ́ láti di olùfọkànsìn ọmọẹ́hìn Jésù Krístì tí a sì nní ìmọ̀lára ayọ̀ Rẹ̀ bí a ṣe njọ́sìn nínú ilé Olúwa.

Ààrẹ Russell M. Nelson kéde pé: “Ìsisìyí ni àkokò fún ẹ̀yin àti fún èmi láti múra sílẹ̀ fún Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì ti Olúwa àti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì náà. Ìsisìyí ni àkokò náà fún wa láti mú jíjẹ́-ọmọlẹ́hìn wa jẹ́ ààyò gígajùlọ wa. Nínú ayé kan tí ó kún fún ìpínyà ọkàn, báwo la ṣe lè ṣe èyí?”

Ó pèsè ìdáhùn pé: “Ìjọsìn déédé nínú tẹ́mpìlì yóò ràn wá lọ́wọ́. Nínú ilé Olúwa, a dojúkọ Jésù Krístì. … A wá láti mọ̀ Ọ́. … Gbogbo olùwá Jésù Krístì àtọkànwá yóò rí I nínú tẹ́mpìlì.”

Torí náà báwo la ṣe lè di kí a sì ran ara wa lọ́wọ́ láti olùfọkànsìn ọmọlẹ́hìn Jésù Kristi? A ó ṣe ìṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ẹni náà. Iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ọ̀nà Olùgbàlà wé mọ́ àánú, inúrere, sùúrù, àti ìfẹ́ láìsí ìdájọ́. Bí a ṣe nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún ẹni náà, à npe ẹni náà láti wá sọ́dọ̀ Jésù Krístì àti láti jọ́sìn nínú ilé Olúwa láti gba agbára ìràpadà Rẹ̀. Ní ọ̀rọ̀ míràn, a nran ara wa lọ́wọ́ láti di ọmọ-ẹ̀hìn olùfọkànsìn bí a ṣe nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún ẹni náà ní àwọn ọ̀nà tí ó ndarí lọ sí ilé Oluwa.

A nkọ́ ẹ̀kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jésù Kristi nípa agbára ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún ẹni náà pẹ̀lú ìfẹ́ àti láìsí ìdájọ́. Ẹ rántí obìnrin ará Samáríà níbi kànga. Obìnrin yi ti lè ní ìmọ̀lára àìjẹ́pàtàkì, dídánìkanwà, ìrẹ̀wẹ̀sì, àti àìrí. Ó ṣeé ṣe kó ti rò pé òun kò wà pẹ̀lú. Ní gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ ó ní ọkọ márun, ọkùnrin tí ó sì ngbé pẹ̀lú kì í ṣe ọkọ rẹ̀. Àwọn miran lè ti gbé ìdájọ́ àìṣòdodo kalẹ̀ láì mọ àwọn ipò ìgbésí-ayé rẹ̀. Èyí lè jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìdí tí ó fi dánìkan wá síbi kànga ní ọ̀sán tí ó gbóná jùlọ ti ọjọ́ náà. Síbẹ̀, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹni àkọ́kọ́ tí Jésù Kristi kéde fún pé òun ni Mèssíàh náà. Lójú Rẹ̀, ọmọbìnrin Ọlọ́run ni obìnrin yi.

Jésù Kristi kọ́ obìnrin náà pé nípasẹ̀ Òun ènìyàn lè gba ìyè àìnípẹ̀kun nípa mímu nínú omi ìyè. Ó kéde pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi tí èmi yóò fi fún un … kì yóò pòùngbẹ láé; ṣùgbọ́n omi tí èmi yóò fi fún un … yóò jẹ́ … kanga omi tí nsun sí ìyè àìnípẹ̀kun.”

Obìnrin ará Samáríà ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Olùgbàlà ó sì gba ẹ̀rí nípasẹ̀ Ẹ̀mí pé Òun ni Mèssíàh náà. Lẹ́hìn ìjẹ́ri yi, ó padà sí ìlú ó sì pe àwọn ẹlòmíràn láti wá wòó, ọ̀pọ̀ sì gbà pé Jésù “jẹ́ Krístì nítòótọ́, Olùgbàlà aráyé.” Kristi ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ẹni náà pẹ̀lú ìfẹ́; nítorí èyí, àwọn míràn di ọmọ-ẹ̀hìn olùfọkànsìn Rẹ̀.

A kẹ́kọ nípa agbára iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún ẹnití ó rí ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Àpọ́stélì Pétérù àti Jòhánnù. Ìwọ rántí ọkùnrin kan, arọ láti ìgbà ìbí, tó ndùbúlẹ̀ lójoojúmọ́ ní ẹnu ọ̀nà tẹ́mpìlì tó nbéèrè owó. Ọkùnrin yi lè ti ní ìmọ̀lára pé òun kò ṣe pàtàkì, nìkan wà, rẹ̀wẹ̀sì, àti àìrí. Ó lè ti rò pé òun kò wà pẹ̀lú.

“Nigbànáà ni Pétérù wípé, Fàdákà àti wúrà èmi kò ní; ṣùgbọ́n irú èyítí mo ní [mo] fi [fún] ọ: Ní orúkọ Jésù Krístì ti Násàrẹ́tì díde kí o sì rìn.”

Peteru mú ọkunrin náà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ó sì gbé e sókè, ara ọkunrin náà sì dá ṣáṣá. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́hìn iṣẹ́-ìyanu náà, ọkùnrin náà wọ tẹ́mpìlì lọ pẹ̀lú Pétérù àti Jòhánnù, “ó nrìn, ó nfò, ó sì nyin Ọlọ́run.” Pétérù àti Jòhánnù ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ẹni náà ní àwọn ọ̀nà tí ó darí sílé Olúwa, ọkùnrin náà sì di ọmọ-ẹ̀hìn olùfọkànsìn ti Krístì.

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, àwọn àkókò kan ti wà nínú ìgbésí ayé mi níbití èmi náà ti nímọ̀lára pé nkò jẹ́ pàtàkì, dá wà, rẹ̀wẹ̀sì, àti ṣàìrí. Mo ti nímọ̀lára bí ẹni pé nkò wà pẹ̀lú. Mo ṣe ìrìbọmi mo sì fẹsẹ̀múlẹ̀ bí ọmọ Ìjọ ti Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn-Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn nígbàtí mo jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún. Ọdún kan lẹ́hìn náà, mo tẹ́wọ́gba ìpè láti sìn gẹ́gẹ́bí ìránṣẹ́ ìhìnrere ìgbà kíkún, ṣùgbọ́n ohun púpọ̀ wà tí nkò tíì kẹ́kọ nípa ìtàn Ìjọ.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi, mo kẹ́kọ pé àkokò kan wà tí wọn ko jẹ́kí àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú ní Áfríkà gbádùn gbogbo àwọn ìbùkún jíjọ́sìn nínú ilé Olúwa. Kíkọ́ èyí fún ìgbà àkọ́kọ́ mú ìmọ̀lára ìbínú, ìdàrúdàpọ̀, iyèméjì, àti ìbẹ̀rù wá. Àwọn ìmọ̀lára wọ̀nyí le débi pé mo pàdánù agbára mi láti dá Ẹ̀mí Mímọ́ mọ̀ fún àkokò kan.

Níní oríire, mo ní ojúgbà ìránṣẹ́ ìhìnrere àgbàyanu kan, Kevin Vick, tó fi ìfẹ́, sùúrù, àti inú rere ṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́ sí mi. Ní alẹ́ kọ̀ọ̀kan bí ó ti nrí ìmọ̀lára iyèméjì àti àìdánilójú mi, òun yóò kàn sọ fún Alàgbà Johnson àbúrò pé, “Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.” Lẹ́hìn bí i ọ̀sẹ̀ méjì, mo gba ara mi láàyè láti lérò ti ìfẹ́ Kevin. Mo ní ìgboyà láti gbàdúrà sí Baba Ọ̀run ní orúkọ Jésù Krístì. Bí mo ṣe ngbàdúrà, wọ́n fà mí sí ìpín kẹfà ti Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú, àwọn ẹsẹ 21–23, tó sọ wípé:

“Kíyèsíi, Èmi ni Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run. … Èmi ni ìmọ́lẹ̀ tí ntàn nínú òkùnkùn. …

“… Fi ọkàn rẹ lelẹ li oru na ti iwọ kigbe pè mi li ọkàn rẹ, ki iwọ ki o le mọ̀ niti otitọ àwọn nkan wọnyi.

“Ṣé èmi kò sọ àlàáfíà ọkàn sí yín nípa ọ̀ràn náà? Ẹ̀rí wo ni o lè ní ju láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun lọ?”

Bí mo ṣe nkàwé, mo rántí. Mo rántí ọjọ́ tí mo gbààwẹ̀ tí mo sì gbàdúrà láti mọ̀ pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti pé Joseph Smith ni Wòlíì Ìmúpadàbọ̀sípò. Mo rántí àwọn májẹ̀mú tí a ṣe nínú ilé Olúwa tí ó so mí pọ̀ mọ́ Jésù Krístì ní irú ti araẹni àti ọ̀nà tímọ́tímọ́. Mo ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Olùgbàlà, àánú Rẹ̀, àti ti ìdánilójú Rẹ̀ pé Ìjọ ti Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn ni ìjọba Rẹ lórí ilẹ̀ ayé ó sì ṣe pàtàkì láti múra wa sílẹ̀ fún Bíbọ̀ Rẹ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì. Nítorípé mo rántí, mo tún lè dá Ẹ̀mí Mímọ́ mọ̀ àti láti ní òye ní kíkún pé Jésù ni Krístì àti pé èmi ni ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀.

Nígbà míràn àwa yóò ní àwọn ìbéèrè tí a kò dáhùn àti àwọn ìkùnsínú pé a kò ṣe pàtàkì, ìrẹ̀wẹ̀sì, dá wà, ati airi. Síbẹ̀síbẹ̀, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, a gbọ́dọ̀ tẹ̀ síwájú pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì kí a sì rántí àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀:

“Ẹ máṣe jẹ́ kí ọkàn yín kí ó dàmú.”

“Nínú ayé ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú: ṣùgbọ́n ẹ tújúká; Èmi ti ṣẹ́gun ayé.”

Èmi jẹ́ ẹlẹ́ri sí òtítọ́ yi àti ti ìbùkún ìlérí ti Olùgbàlà.

Nítorínáà kíni a lè ṣe láti rí i dájú pé iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa sí ẹni náà jẹ́ èyítí ó múnádóko jùlọ? Gbígbé ẹ̀kọ́ ti Krístì yóò ràn wá lọ́wọ́. “Bí a ṣe ngbé ẹ̀kọ́ ti Krístì,” bí Ààrẹ Nelson ti ṣàpèjúwe, “le mú àyípo oníwà rere tí ó lágbára jùlọ jáde, kí ó sì ṣẹ̀dá agbára ẹ̀mí sílẹ̀ nínú ìgbésí ayé wa.

“Bí a ṣe nlàkàkà láti gbé àwọn òfin gíga ti Jésù Krístì, … Olùgbàlà ngbé wa wa ga ju ìfàsí ayé tí ó ti ṣubú yi lọ nípa bíbùkún wa pẹ̀lú ìfẹ́ aìlẹ́gbẹ́ púpọ̀ síi, ìrẹ̀lẹ̀, inú-rere, àánú, ìsẹ́ra-araẹni, àlaáfíà, àti ìsimi.”

“[Ipa ti Ẹ̀mí yi] tí a mú jáde nípasẹ̀ gbígbé ẹ̀kọ́ ti Krístì,” Alàgbà Dale G. Renlund ṣàlàyé, “kì í fúnni ní agbára ìyípadà ti ìwà àtọ̀runwá wa sínú kádàrá ayérayé wa nìkan ṣùgbọ́n ó tún nsún wa láti ṣèrànwọ́ [láti ṣe ìránṣẹ́ sí] àwọn ẹlòmíràn ní àwọn ọ̀nà yíyẹ.” Alàgbà Renlund rán wa létí pé “iṣẹ́ Olùgbàlà ni láti mú wa láradá [láti sọ wá di odidi]. Iṣẹ́ wa ni láti nífẹ—láti nífẹ àti láti ṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́ lọ́nà tí àwọn ẹlòmíràn yóò fi fà mọ́ Jésù Kristi.”

Agbára wa láti gbé ẹ̀kọ́ Krístì yóò di púpọ̀ síi nípa kíkẹ́kọ Ìwé ti Mọ́mọ́nì lójoojúmọ́ àti jíjẹ oúnjẹ Olúwa lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ààrẹ Nelson kéde pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì “kọ́ni ní ẹ̀kọ́ ti Krístì … [ó sì] pèsè ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye àti [tí ó mọ́ jùlọ] ti Ètùtù ti Jésù Krístì tí a lé rí níbikíbi.” Mo fẹ́ràn i`wé yi. Ṣíṣe àbápín tàdúràtàdúrà nínú ìlànà ti oúnjẹ Olúwa lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ yóò mú òye wa pọ̀sí nípa Ètùtù ti Jésù Krístì àti ti ẹ̀kọ́ Rẹ̀ a ó sì pèsè ìmúdọ̀tun, ìtùnú, àti agbára ìwà-bí-Ọlọ́run sínú ayé wa. Rántí pé, “nínú àwọn ìlànà [ti oyè àlùfáà], agbára ìwà-bí-Ọlọ́run farahàn,” àti agbára yì, ti ó wá láti ọ̀dọ̀ Jésù Kristi nfún ìfẹ́-ọkàn wa lókun àti agbára wa láti ṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́ fún ẹni náà.

Ìkẹ́kọ mi ti Ìwé ti Mọ́mọ́nì àti jíjẹ oúnjẹ Olúwa ndín àwọn ìmọ̀lára ìrẹ̀wẹ̀sì kù, gbé ìpinnu mi sókè láti ṣe ìránṣẹ́ fún ẹni náà tí ó wà ní ọ̀nà Olùgbàlà, ó sì nṣèrànwọ́ láti sọ jíjẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn mi di ipò àkọ́kọ́ tí ó ga jùlọ.

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, mo ṣèlérí pé bí a ti ngbé ẹ̀kọ́ Krístì tí a sì nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún ẹni náà ní àwọn ọ̀nà tí ó ndarí sí ilé Olúwa, a ó lè tẹ̀ síwájú pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì àní láàrín àwọn ìbèèrè tí a kò dáhùn àti ìmọ̀lára jíjẹ́ àìṣepàtàkì, dídáwà, ìrẹ̀wẹ̀sì, àti àìríni. A ó pe ẹni náà láti wá sí ọ̀dọ̀ Jésù Krístì àti láti jọ́sìn nínú ilé Olúwa làti gba agbára ìràpadà àti ìfẹ́ Rẹ̀. Nínú ilé Olúwa, àwa yóò “ní ìmọ̀lára àánú ti [Olùgbàlà]. [Àwa] yóò rí àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbèèrè [wa] tí ó nruni nínú jùlọ. [Àti pé àwa] yóò ní òye ti ayọ̀ ìhìnrere Rẹ̀ dáradára jùlọ.” Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Russell M. Nelson, “Olúwa Jésù Krístì Yóò Pada Wá Lẹ́ẹ̀kansíi,” Lìàhónà, Oṣù kọkànlá. 2024, 121–22.

  2. Wo Jòhánnù 4:5–42.

  3. Ní Ìtàn-Àkọọ́lẹ̀, púpọ̀ jùlọ ṣàbẹ̀wò sí kànga Jákọ́bù ní kùtùkùtù òwúrọ̀. Ó jẹ́ ibìkan láti péjọ àti láti ṣe ìdàpọ̀-ọkàn pẹ̀lú ẹlòmíràn. Obìnrin ará Samáríà náà nìkan wá sí ibi kànga Jákọ́bù ní àárín àti ní ọ̀sán gangan ní wákàtí kẹfà, tí ó jẹ́ ní ọ̀sán gangan. Wíwá lákokò yi lè jẹ́ ká mọ bó ṣe mọ ohun táwọn èèyàn lèrò nípa rẹ̀ àti bó ṣe máa nrí lára rẹ̀.

  4. Jòhánnù 4:13–14.

  5. Jòhánnù 4:42

  6. Wo Iṣe àwọn Àpóstélì 3:1–11.

  7. Iṣe àwọn Àpóstélì 3:6.

  8. Wo Iṣe àwọn Àpóstélì 3:7.

  9. Iṣe àwọn Àpóstélì 3:8.

  10. Mo ṣe ìrìbọmi mo sì fẹsẹ̀múlẹ̀ bí ọmọ Ìjọ ti Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn ní Oṣù Kẹjọ 1986. Láti August 1987 sí August 1989, mo sìn gẹ́gẹ́bí ìránṣẹ́ ìhìnrere ní Ẹkùn Alabama Birmingham.

  11. Wo Ìjọ àti Àwọn Ìbèèrè Ìhìnrere, “Ẹ̀yà àti Ìjọ ti Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn,” Ibi Ìkàwé Ìhìnrere.

  12. Ìrírí yi ni a ṣe àlàyé rẹ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ púpọ̀ nínú ọ̀rọ̀ Peter M. Johnson, “Lílo Ẹ̀kọ́ Jésù Krístì sínú Ìgbésí Ayé Wa láti ọwọ́” (Brigham Young University–Idaho ìpàdé ìsìn-àkànṣe, Oṣù kẹta. 14, 2023), byui.edu.

  13. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 6:21–23.

  14. Johannu 14:27

  15. Jòhánnù 16:33

  16. Ẹ̀kọ́ ti Krístì jẹ́ ohun márùn tí ó so pọ̀: ìgbàgbọ́ nínú Olúwa Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀, ìrònùpíwàdà, gbigba awọn ilana ati bíbu-ọlá fún awọn majẹmu, sísọ di mimọ nipa Ẹmi Mimọ, ati ìforítì de opin. Ìgbàgbọ́ nínù Olúwa Jésù Kristì jẹ́ ìlànà ti ìṣe àti agbára àtọ̀runwá. Ìrònúpíwàdà jẹ́ lílo ìgbàgbọ́ ènìyàn nínú Krístì nípa yíyí ọkàn wa àti ẹ̀mí sọ́dọ̀ Rẹ̀. Ìrònúpíwàdà kì i ṣe ìjìyà. Ó jẹ́ ìlànà ti jíjẹ́ ti ẹ̀mí nípa ti Jésù àti gbígba àwòrán Rẹ̀ sí ojú wa. Gbígba àwọn ìlànà àti àwọn májẹ̀mú ọlá tí a ṣe pẹ̀lú Ọlọ́run àti Krístì fún wa ní ayé tí ó tóbi sí agbára Wọn àti ìfẹ́ Wọn àti gbà wá láyè láti di mímọ́ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. Ohun tó gbẹ̀yìn nínú ẹ̀kọ́ Kristi ni fíforítìí títí dé òpin, èyítí íṣe gbígbé ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ẹ̀kọ́ Kristi “léraléra àti ní àṣetúnṣe” kí a lè di àti láti ran ara wa lọ́wọ́ láti di ọmọ-ẹ̀hìn Jesu Kristi olùfọkànsìn kí a sì ní ìmọ̀lára ìdùnnú Rẹ̀ bí a ṣe njọ́sìn nínú ilé Olúwa (Dale G. Renlund, “Alágbára, Àyíká Ìwà Rere ti Ẹ̀kọ́ Krístì,” Lìàhónà, Oṣù Karun 2024, 81; tún wo Russell M. Nelson, “Borí Ayé Kí O Sì Rín Ìsimi,” Lìàhónà, Oṣù Kọkànlá. 2022, 97).

  17. Russell M. Nelson, “Ẹ Ṣẹ́gun Ayé kí ẹ sì Wá Ìsinmi97.

  18. Dale G. Renlund, “Alágbára, Àyíká Ìwà rere ti Ẹ̀kọ́ Krísti,” 82, 83; àfikún ìtẹnumọ́.

  19. Russell M. Nelson, “Ìwé ti Mọ́mọ́nì: Kíni Ìgbé Ayé Rẹ̀ Yíò Jẹ́ Láìsí Rẹ̀?,” Lìàhónà, Oṣù Kọkànlá. 2017, 62.

  20. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 84:20.

  21. Russell M. Nelson, “Jésù Krístì Olúwa Yíò Padàwá Lẹ́ẹ̀kansí i,,” Lìàhónà, Oṣù kọkànlá. 2024, 122.