Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ṣe Ipa Tìrẹ Pẹ̀lú Gbogbo Ọkàn Rẹ
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwàá 2025


15:22

Ṣe Ipa Tìrẹ Pẹ̀lú Gbogbo Ọkàn Rẹ

Gbẹ́kẹ̀lé Olùgbàlà kí o sì lọ́wọ́, pẹ̀lú sùúrù àti pẹ̀lú aápọn, nínú ṣíṣe ipa tìrẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ.

Lọ́dún tó kọjá ní àkókò ìrìnàjò kan sí Europe, mo ṣàbẹ̀wò sí ibi iṣẹ́ mi àtijọ́, Lufthansa German Airlines ní Frankfurt.

Láti fún àwọn awakọ̀ òfurufú wọn ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́, wọ́n máa nlo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀rọ ìsínjẹ ẹlẹgẹ́ tó nsáré ní kíkún bíi bàálù, tí ó le ṣẹ̀dáa ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ èyíkéyìí ipò bàálù dídára àti ti pàjáwìrì. Nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún mi bíi ọ̀gágun ọkọ̀ òfurufú, mo níláti yege bàálù yíyẹ̀wò kan nínú ẹ̀rọ ààbò bàálù ní oṣù mẹ́fà mẹ́fà láti mú kì ìwé àṣẹ awakọ̀ òfurufú mi le wúlò lọ́wọ́lọ́wọ́. Mo rántí dáradára àwọn àkokò líle ti iṣẹ́ àṣejù àti àníyàn ṣùgbọ́n bákannáà ìmọ̀lára àṣeyọrí lẹ́hìn yíyege ìdánwò náà. Mo jẹ́ ọ̀dọ́ nígbànáà mo sì fẹ́ràn ìpèníjà náà.

Ní àkokò ìbẹ̀wò mi, ọ̀kan lára àwọn lọ́gàá-lọ́gàá ní Lufthansa bèèrè bí mo bá fẹ́ láti gbìyànjú rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan síi kí nsì gbé ẹ̀rọ ìsínjẹ B747 fò ní ìgbà kan síi.

Kí ntó ní àkokò láti ronú ní kíkún sí ìbèèrè náà, mo gbọ́ ohùn kan—tó ndún pẹ̀lú ìyàlẹ́nu bíi tèmi—wípé, “Bẹ́ẹ̀ni, èmi ó fẹ́ èyí púpọ̀ gan an.”

Ní kété bí mo ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ náà, àwọn èrò bíi ti sùnámì ya bo ọkàn mi. Ó ti jẹ́ ìgbà pípẹ́ sẹ́hìn tí mo ti gbé 747 fò. Ní ìgbà náà mo jẹ́ ọ̀dọ́ àti ọ̀gágun kan tó dájú. Nísisìyí mo ní orúkọ rere láti gbé ró bíi ọ̀gá awakọ̀ òfurufú tẹ́lẹ̀rí. Njẹ́ èmi ó mú ìtìjú bá ara mi níwájú àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n wọ̀nyí?

Ṣùgbọ́n ó ti pẹ́ jù láti padà sẹ́hìn, nítorínáà mo tẹ̀dó sínú ìjókòó ọ̀gágun, mo gbé ọwọ́ sórí àwọn nkan ìdarí mímọ̀ àti ọ̀wọ́n, mo sì ní ìmọ̀lára, ní ìgbà kan síi, ìdùnnú bàálù bí ọkọ̀ òfurufú nlá náà ṣe pariwo sọ̀kalẹ̀ sí ojú ọ̀nà ìsáré tó sì gbéra sínú àlàfo ẹ̀rọ ààbò aláwọ̀ búlúù níwájú.

Inú mi dùn láti sọ pé fífò náà jẹ́ àṣeyege, ọkọ̀ bàálù náà dúró ní pípé, bẹ́ẹ̀ sì ni àwòrán araẹni mi ṣe.

Aní bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìrírí náà jẹ́ rírẹlẹ̀ fún mi. Nígbàtí mo wà ní ọ̀dọ́, fífò ti fẹ́rẹ̀ dàbíi adánidá kejì. Nísisìyí, ó gba gbogbo àfọkànsí mi láti ṣe àwọn ohun ti àkọ́bẹ̀rẹ̀.

Jíjẹ́ Ọmọ-ẹ̀hìn Gba Ìsẹ́ra-ẹni.

Ìrírí mi nínu ẹ̀rọ ìsínjẹ bàálù náà jẹ́ ìránnilétí pàtàkì kan pé dídára nínú ohunkóhun—bóyá ó jẹ́ fífò, sísún, gbígbìn, tàbí mímọ̀—gba sísẹ́ ara-ẹni àti iṣẹ́ ṣíṣe léraléra.

Ẹ lè lo àwọn ọdún ní gbígba ẹ̀kọ́ iṣẹ́ ọwọ́ tàbí mímú tálẹ́ntì kan dàgbà. Ẹ lè ṣiṣẹ́ kára tó bẹ́ẹ̀ tí yíò di adánidá kejì síi yín. Ṣùgbọ́n bí ẹ bá rò pé èyí túmọ̀ sí kí ẹ dáwọ́dúrò nínú iṣẹ́ àti àṣàrò ṣíṣe, díẹ̀díẹ̀ ẹ ó pàdánù ìmọ̀ àti àwọn agbára ìleṣe tí ẹ ti gbà nígbàkanrí ní iye nlá.

Èyí jẹ́ àmúlò sí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ bíi kíkọ́ èdè kan, lílo ohun èlò orin kan, àti gbígbé ọkọ̀ òfurufú kan fò. Ó jẹ́ àmúlò bákannáà sí jíjẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn Krístì kan.

Ní fífi ìrọ̀rùn sọ, jíjẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn gba sísẹ́ ara-ẹni.

Kìí ṣe ìdáwọ́lé yẹpẹrẹ kan, kìí sìí ṣẹlẹ̀ nípasẹ̀ àmúwá.

Ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì jẹ́ ẹ̀bùn, ṣùgbọ́n gbígbà á jẹ́ yíyàn àmọ̀ọ́mọ̀ ṣe kan tí ó gba ìfarajì ti gbogbo “agbára, inú àti okun” wa. Ó jẹ́ iṣẹ́ ṣíṣe ti gbogbo ọjọ́. Gbogbo wákàtí. Ó gba ẹ̀kọ́ kíkọ́ léraléra àti ìfarajì pípinnu. Ìgbàgbọ́ wa, ìfọkàntán wa sí Olùgbàlà, ndi lílágbára síi bí ó ti njẹ́ dídánwò dojúkọ àtakò tí a nkojú ní ìhín ní ayé kíkú. Ó nforítì nítorípé a ntẹ̀síwájú ní bíbọ́ ọ, a ntẹ̀síwájú ní mímú un lò déédé, a kò sí rẹ̀wẹ̀sì láé.

Ní ìdà kejì, bí a bá kùnà láti lo ìgbàgbọ́ àti agbára ìyíni-lọ́kàn-padà rẹ̀, a ndi dídínkú ní níní ìdánilójú nípa àwọn ohun tí a ti fi ìgbàkanrí dìmú ní mímọ́—dídínkù ní níní ìgbẹ́kẹ̀lé nípa àwọn ohun tí a ti fi ìgbàkanrí mọ̀ pé wọ́n jẹ́ òtítọ́.

Àwọn ìdánwò tí ìbá má lè wù wá láé nígbàkanrí á bẹ̀rẹ̀sí dínkù ní rírínilára yóò sì di wíwuni síi.

Iná ẹ̀rí ti àná le mú wa lóoru fún ìgbà díẹ̀ lásán. Ó nílò bíbọ́ léraléra láti tẹ̀síwájú ní jíjò dáradára.

Nínú Májẹ̀mú Titun, Olùgbàlà kọ́ni ní òwe kan nípa ọ̀gá kan tí ó fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé mímọ́ kan—iye owó kan tí a pè ní tálẹ́ntì. Àwọn ìránṣẹ́ tí wọ́n lo tálẹ́ntì wọn pẹ̀lú aápọn mú wọn pọ̀ síi. Ìránṣẹ́ tí ó bo tálẹ́ntì tirẹ̀ mọ́lẹ̀ pàdánù rẹ̀ nìgbẹ̀hìn.

Ẹ̀kọ́ Náà? Ọlọ́run nfún wa ní àwọn ẹ̀bùn—ti ìmọ̀, ti agbára, ti ànfààní—Ó sì nfẹ́ kí a lò wọ́n àti láti mú wọn tóbi kí wọn ó lè bùkún wa kí wọn ó sì bùkún àwọn ọmọ Rẹ̀ míràn. Èyí kìí ṣẹlẹ̀ bí a bá gbé àwọn ẹ̀bùn náà sókè gíga lórí ṣẹ́ẹ̀fù bìi ife ẹ̀yẹ tí ó njọ wá lóju láti igbà dé ìgbà. Àwọn ẹ̀bùn wa máa ndi títobi àti púpọ̀ síi nígbàtí a bá lò wọ́n nìkan.

A Fún Ọ Ní Ẹ̀bùn

“Ṣùgbọ́n Alàgbà Uchtdorf,” o le sọ, “èmi ò ní àwọn ẹ̀bùn tàbí tálẹ́ntì kankan—ó kéré tán, kò sí àwọn kankan tí wọ́n níyelórí tó bẹ́ẹ̀.” Bóyá o nwò àwọn míràn tí àwọn ẹ̀bùn tiwọn hàn síta àti tí ó wúnilórí, tí o sì wá nní ìmọ̀lára jíjẹ́ lásán nípa ìfarawéra. O lè rò pé nínú wíwà ṣaájú-ayé-ikú, ní ọjọ́ àkójọpọ̀ ẹ̀bùn àti tálẹ́ntì nlá, àwo tìrẹ dàbí pé ó ṣófo púpọ̀—pàápàá bí a bá fi wé àwọn àwo kíkún fọ́fọ́ àti àkúnwọ́sílẹ̀ ti àwọn ẹlòmíràn.

Áà, ó ti wù mí tó kí nlè gbà ọ́ mọ́ra kí nsì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní òye òtítọ́ nlá yìí: O jẹ́ ẹni alábùkún fún ti ìmọ́lẹ̀, ọmọ ẹ̀mí ti Ọlọ́run àìlópin kan! O sì ní líleṣe kan nínú rẹ tí ó kọjá agbára rẹ̀ láti fi ojú inú wò.

Bí àwọn akéwì ti ṣe àkọsílẹ̀, o wá sí ilẹ̀ ayé, “ní sísá tẹ̀le àwọn ikuukù ògo”!

Ìtàn orísun rẹ jẹ́ àtọ̀runwá, bẹ́ẹ̀ sì ni àyànmọ́ rẹ. O fi ọ̀run sílẹ̀ láti wá sí ìhín, ṣùgbọ́n ọ̀run kò fi ọ́ sílẹ̀ rí láé!

Ìwọ jẹ́ ohunkóhun ṣùgbọ́n kìí ṣe lásán.

A fún ọ ní ẹ̀bùn!

Nínú Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú, Ọlọ́run wí pé:

“Àwọn ẹ̀bùn púpọ̀ ló wà, àti pé olukúlùkù [ènìyàn] ni a fi ẹ̀bùn kan fún láti ọwọ́ Ẹ̀mí Ọlọ́run.

“Fún àwọn kan ni a fi ọ̀kan fún, àti fún àwọn kan ni a fi òmíràn fún, kí ẹni gbogbo lè jẹ èrè nípa bẹ́ẹ̀.”

Díẹ̀ lára àwọn ẹ̀bùn wa ni a tò sílẹ̀ nínú ìwé mímọ́. Púpọ̀ kò jẹ́ bẹ́ẹ̀.

Bí wòlíì nlá Mórónì ti sọ pé, “Ẹ máṣe sẹ́ àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run, nítorítí wọ́n pọ̀; wọ́n sì wá láti ọwọ́ Ọlọ́run kannáà.” Wọ́n le fi ara wọn hàn ní “oríṣiríṣi àwọn ọ̀nà … ; ṣùgbọ́n Ọlọ́run kannáà ni ẹni tí nṣe ohun gbogbo nínú ohun gbogbo.”

Ó le jẹ́ òtítọ́ pé àwọn ẹ̀bùn wa ti ẹ̀mí lè má fi ìgbà gbogbo jẹ́ wíwọni-lójú, ṣùgbọ́n èyí kò túmọ̀ sí pé wọ́n dínkù ni jíjẹ́ pàtàkì. Njẹ́ mo lè pín pẹ̀lú yín díẹ̀ lára àwọn ẹ̀bùn ti ẹ̀mí ti mo ti kíyèsí nínú àwọn ọmọ ìjọ jákèjádò àgbáyé? Ròó bóyá ìwọ ti jẹ́ bíbùkún pẹ̀lú ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ àwọn ẹ̀bùn bíi:

  • Fífi Ìyọ́nú hàn.

  • Fífiyèsí àwọn ènìyàn tí a kò rí.

  • Wíwá àwọn ìdí láti jẹ́ aláyọ̀.

  • Jíjẹ́ onílàjà kan.

  • Fífiyèsí àwọn iṣẹ́ iyanu kékèké.

  • Fífúnni ní àwọn oríyìn tòótọ́.

  • Dídáríjì.

  • Ríronúpìwàdà.

  • Fíforitì.

  • Ṣíṣe àlàyé àwọn nkan pẹ̀lú ìrọ̀rùn.

  • Bíbá àwọn ọmọdé ṣe.

  • Ṣiṣe ìmúdúró àwọn olùdarí Ìjọ

  • Ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mọ̀ pé wọ́n jẹ́ ara kan.

Ẹ lè má rìí àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí ní fífihàn níbi àfihàn tálẹ́ntì ní wọ́ọ̀dù. Ṣùgbọ́n mo nírètí pé ẹ lè rí bí wọ́n ti ṣe iyebíye tó sí iṣẹ́ Olúwa àti bí ẹ ti le fọwọ́kàn, bùkún, tàbí gba ọmọ Ọlọ́run kan là pàápàá nípa àwọn ẹ̀bùn yín. Ẹ rántí pé: “Nípa àwọn ohun kékeré àti rírọrùn ni a nmú àwọn ohun nlá wá sí ìmúṣẹ.”

Nítorínáà ẹ jẹ́ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ṣe ipa kékeré tiwa.

Sa Ipa Kékeré Tìrẹ

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi olùfẹ́, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n, mo gbàdúrà pé Ẹ̀mí yíò ràn wá lọ́wọ́ láti dá àwọn ẹ̀bùn àti àwọn tálẹ́ntì tí Ọlọ́run ti fún yín mọ̀. Nígbànáà, ẹ jẹ́ kí àwa, bíi ti àwọn ìránṣe olóotọ́ nínú òwe Olúwa, mú wọ́n di púpọ̀ àti títóbi síi.

Ọjọ́ náà yíò dé nígbàtí àwa ó dúró níwájú oníyọ̀ọ́nú Baba wa ní Ọ̀run láti ṣe ìṣirò iṣẹ́́ ìríjú wa. Òun yíò fẹ́ láti mọ̀ ohun tí a ṣe pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn tí Ó fún wa—ní pàtàkì, bí a ti lò wọ́n láti bùkún àwọn ọmọ Rẹ̀. Ọlọ́run mọ ẹnití a jẹ́ nítòótọ́, ẹnití a ya àwòrán wa láti dà, àti nítorínáà àwọn ìrètí Rẹ̀ fún wa jẹ́ gíga.

Ṣùgbọ́n Òun kò retí wa láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ àrà ọ̀tọ̀, akọni, tàbí tó lápẹrẹ kan láti dé ibẹ̀. Nínú ayé tí Ó dá, dídàgbà nṣẹlẹ̀ díẹ̀díẹ̀ áti pẹ́lú sùúrù—ṣùgbọ́n bákannáà lẹ́sọ̀lẹ́sọ̀ àti láìkáàrẹ̀.

Ẹ rántí pé, Jésù Krístì ni ẹnití ó ti ṣe abala tó lápẹrẹ tẹ́lẹ̀ nígbàtí Ó ṣẹ́gun ikú àti ẹ̀ṣẹ̀.

Ipa tiwa ni láti tẹ̀lé Krístì náà. Ó jẹ́ ipa tiwa láti yí kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀, kí a yí sí ọ̀dọ̀ Olùgbàlà, kí a sì rìn ní ọ̀nà Rẹ̀, ìgbésẹ̀ kan ní àkokò kan. Bí a ti nṣe èyí, pẹ̀lú aápọn àti pẹ̀lú ìgbàgbọ́, nígbẹ̀hìn a ó ké àwọn ẹ̀wọn àìpé àti ẹ̀bi sọnù àti ní pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ a ó di títúnṣe, títí di ọjọ́ pípé náà nígbàtí a ó sọ wá di pípé nínú Jésù Krístì.

Àwọn ìbùkún náà wà ní àrọ́wọ́tó. Àwọn ìlèrí náà wà ní àyè wọn. Ìlẹ̀kùn náà ṣí sílẹ̀. Àṣàyàn wa ni láti wọlé kí a sì bẹ̀rẹ̀.

Ìbẹ̀rẹ̀ lè jẹ́ kékeré. Ṣùgbọ́n èyí náà dára.

Níbi tí ìgbàgbọ́ bá ti jẹ́ àìlágbára, bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìrètí nínú Krístì Jésù àti agbára Rẹ̀ láti wẹ̀nù àti láti sọ di mímọ́.

Baba wa wí pé kí a kojú ìpèníjà ti ìgbàgbọ́ àti jíjẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn yí, kìí ṣe bíi arìnrìnàjò lásán, ṣùgbọ́n bíi onígbàgbọ́ tọkàn-tọkàn, ẹnití ó fi Bábílónì sílẹ̀ tí wọ́n sì gbé ọkàn, inú, àti àwọn ìgbésẹ̀ wọn sí ọ̀nà Síónì.

A mọ̀ pé àwọn ìtiraka wa nìkan kò lè sọ wa di ti sẹ̀lẹ́stíà. Ṣùgbọ́n wọ́n le sọ wa di olóòótọ́ àti olùfarajì sí Jésù Krístì, Òun sì lè sọ wa di ti sẹ̀lẹ́stíà.

Nítorí ti olùfẹ́ Olùgbàlà wa, kò sí irú ohun náà bíi ìsẹ̀lẹ̀ kosí-olúborí kan. Bí a bá fi ìrètí àti ìgbàgbọ́ wa sínú Rẹ̀, ìṣẹ́gun wa dáju. Ó ṣèlérí ààyè fún wa sí okun Rẹ̀, agbára Rẹ, oore ọ̀fẹ́ Rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀. Ìgbésẹ̀ sí ìgbésẹ̀, díẹ̀ díẹ̀, a ó jẹ́ sísúnmọ́ síi sí ọjọ́ nlá àti pípé náà nígbàtí a ó gbé pẹ̀lú Òun àti àwọn olùfẹ́ wa nínú ògo ayérayé.

Láti dé ibẹ̀, a gbọdọ̀ sa ipa tiwa lónìí àti ní ojoojúmọ́. A dúpẹ́ fún àwọn ìgbésẹ̀ tí a gbé lánàá, ṣùgbọ́n a kò dúró sí ibẹ̀. A mọ̀ pé a ṣì ní ọ̀nà jíjìn láti lọ, ṣùgbọ́n a kò jẹ́kí eyí fún wa ní ìrẹ̀wẹ̀sì.

Èyí ni kókó irú ẹni tí a jẹ́—bíi ọmọlẹ́hìn ti Krístì.

Mo bẹ̀ mo sì súre fún gbogbo ọmọ Ìjọ, àti gbogbo ẹnití ó ní ìfẹ́ inú láti jẹ́ ara rẹ̀, láti gbẹ́kẹ̀lé Olùgbàlà kí wọ́n sì lọ́wọ́, pẹ̀lú sùúrù àti aápọn, nínú ṣíṣe ipa tiyín pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín—kí ayọ̀ yín lè kún àti pé, ní ọjọ́ kan, ẹ̀yin yíò gba gbogbo ohun tí Baba ní. Nípa èyí ni mo jẹ́ ẹ̀rí ni orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Àwọn ọ̀gágun ọkọ̀ òfurufú máa nníláti ṣe àyẹ̀wò gbígbé bàálù fò pẹ̀lú ẹ̀rọ ààbò ni oṣù mẹ́fà mẹ́fà láti ṣe ìmúdúró iṣẹ́ ọwọ́ wọn àti sísọ ìwé àṣẹ wọn di ọ̀tun. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ líle yìí jẹ́ bíbéèrè lábẹ́ àṣẹ ti a gbékalẹ̀ lati ọwọ́ àwọn aláṣẹ òfurufú bíi FAA

  2. Wo 1 Kọ́ríntì 12:9.

  3. Mórónì 10:32.

  4. “Gẹ́gẹ́bí iṣan ara wa kò ti lè gbèrú tàbí di mímúdúró láìsí fífà ní ìdojúkọ òfin wíwálẹ̀, bẹ́ẹ̀ni ìdàgbà ayé ikú nílò wa láti fà ní ìdojúkọ àwọn àdánwò Sátánì àti àtakò ayé ikú míràn” (Dallin H. Oaks, “Àwọn Ìrànlọ́wọ́ Àtọ̀runwá fún Ayé Ikú,” Lìàhónà, Oṣù Karun 2025, 104).

  5. Wo Álmà 32:37–43.

  6. Wo Máttéù 25:14–30. Ní àwọn ọjọ́ ìbẹ̀rẹ̀ ti Ìmúpadàbọ̀sípò, Olúwa tọ́ka sí òwe yìí bí Ó ti bá àwọn wọnnì wí tí wọ́n fi àwọn tálẹ́ntì tí Ó ti fún wọn pamọ́. Ó tilẹ̀ kìlọ̀ fún wọn pé bí wọ́n bá tẹ̀síwájú láti bo tálẹ́ntì wọn mọ́lẹ̀ “[yíò] jẹ́ gbígbà lọ, àní èyí tí wọ́n ni” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 60:2–3).

  7. Nígbàmíràn a nṣe àṣejù àtẹnumọ́ patàkì àwọn ẹ̀bùn áti àwọn tálẹ́ntì náà láìka ti aápọn léraléra sí. Ọ̀kan nínú àwọn ònkọ̀wé ti ìgbà tiwa tó ṣe àṣeyege jùlọ kọ pé: “Ní tòótọ́ àwọn tálẹ́ntì kan níláti wà, ṣùgbọ́n tálẹ́ntì jẹ́ ohun kan tí ẹ̀dínwó rẹ̀ banilẹ́rù, ó dínwó ju iyọ̀ orí tábìlì lọ. Ohun tó ya àwọn tó ní tálẹ́ntì sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn aláṣeyege ni iṣẹ́ àṣekára púpọ̀ àti àṣàrò; àwọn ìlàna léraléra ti mímúdára síi” (Stephen King, Danse Macabre [2011], 88).

  8. “Ode: Àwọn Ìbáṣepọ̀ ti Ayé Kíkú kúrò ní Rírántí Ìbẹ̀rẹ̀ Ìgbà-ọmọdé,” Àwọn Iṣẹ́ Ewì ti William Wordsworth (1835), 249.

  9. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 46:11–12.

  10. Mórónì 10:8.

  11. Ní àwọn ọdún sẹ́hìn, Alàgbà Marvin J. Ashton ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá fúnni ní ọ̀rọ̀ tó lápẹrẹ kan nípa àwọn ẹ̀bùn díẹ̀ kan tí wọn kò hàn síta tó (wo “Àwọn Ẹ̀bùn Púpọ̀ Ló Wà,” Ensign, Oṣù Kọkànlá 1987, 20–23).

  12. Álmà 37:6.

  13. Wo Kólósè 3:23;; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 64:34

  14. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 50:24.

  15. Wo Ìtọ́nisọ́nà sí àwọn Ìwé-mímọ́, “Agbára Láti Yàn.”

  16. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 84:38.