Ìkede Ẹbí Náà—Àwọn Ọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run
Ìkéde ní ìbẹ̀rẹ̀ àtọ̀runwá, nítorí a gbọ́dọ̀ tọ́jú rẹ̀ pẹ̀lú ìbọ̀wọ̀ tí ó ní ẹ̀tọ́ sí àwọn ọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2025 yí di àjọ̀dún ọgbọ̀n ti ìpolongo “Ẹbí Náà: Ìkéde Kan Sí Àgbáyé.” Nípa àwòṣe tọ̀run, ìkéde yí, pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ti ìfihàn rẹ̀, ni a dásílẹ̀ láti “ṣe ìmúdúró àti ìfúnlókun ẹbí bí ìpìlẹ̀ ẹ̀ka àwùjọ̀.”
Gbogbo ènì jẹ́ ti ẹbí kan, bóyá ẹ jẹ́ aya, baba, ọmọbìnrin, ọmọkùnrin, ọmọ-ọmọ, òbí-àgbà, àùntí, ọnkúlú, arákùnrin, arábìnrin, tàbí kọ́sìnì. Nípàtàkì jùlọ, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, bí ìkéde ti sọ, “jẹ́ àyànfẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin ẹ̀mí òbí tọ̀run … [pẹ́lú] ìwà-ẹ̀dá àti àyànmọ́ tọ̀run.”
Nígbàtí a pè mí sí ipò-àpóstélì mímọ́ ní 2015, a gbàmí lámọ̀ràn, “Ìkéde yí báyìí jẹ́ tiyín. Orúkọ yín [tí ó nnawọ́ sí àwọn ọ̀rọ̀ náà ‘Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá nínú’ àkọlé] wà ní ìhín gan. Ẹ mọ̀ ọ́ lára kí ẹ sì kọ́ ọ bí ẹnipé ẹ̀yin lẹ ní.”
Mo fẹ́ràn ìkéde ẹbí. Mo ti jẹ́ ẹ̀rí káàkiri àgbáyé láti Áfríkà sí Australia àti ibi-gbogbo ní àárín ojúṣe ẹbí nínú ètò ayérayé Ọlọ́run. Ìkéde ní ìbẹ̀rẹ̀ tọ̀run, nítorí a gbọ́dọ̀ tọ́jú rẹ̀ pẹ̀lú ìbọ̀wọ̀ tí ó ní ẹ̀tọ́ sí àwọn ọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
Ẹ rántí, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, bí mo ti sọ nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ láti pẹpẹ yí, “Àwọn ọ̀rọ̀ Pọndandan.”
Ẹ jẹ́ kí nfún yín ní àwọn àtilẹ̀bá kan nípa ìkéde náà bí kókó ọ̀rọ̀ ti ohun tí a gbàgbọ́.
Ní 1994, ọdún kan ṣíwájú kí a tó gbé ìkéde kalẹ̀, Iyejú ti àwọn Àpóstélì Méjìlá sọ kíníkíní bí àwùjọ àti ìjọba ṣe nyí kúrò nínú òfin Ọlọ́run fún ẹbí, ìgbeyàwó, àti ẹ̀yà. “Ṣùgbọ́n ìyẹn kìí ṣe òpin ohun tí a rí,” Ààrẹ M. Nelson ṣe àlàyé lẹ́hìnwá. “A lè rí àwọn ìtiraka onírúurú àwọn ìletò láti mú gbogbo àwọn ọ̀ṣùwọ̀n àti ìdínkù lórí ìṣe ìbálòpọ̀ kúrò. A rí ìdàmú àwọn ẹ̀yà. A lè rí gbogbo rẹ̀ tó nbọ̀.”
Àwọn Méjìlá pinnu láti pèsè ìwé kan, ìkéde gbangba kan, tí ó ṣe àkópọ̀ ipò ìjọ lórí ẹbí . Nínú ọdún náà, àwọn Àpóstélì, aríràn tí Ọlọ́run pè wọ̀nyí, pèsè ìkéde kan nípa ẹbí. Ààrẹ Dallin H. Oaks rántí pé wọn fi pẹ̀lú àdúrà yí padà sí Olúwa fún “ohun tí [wọ́n] níláti sọ àti bí [wọ́n] ṣe níláti sọ ọ́.” Wọ́n gbekalẹ̀ fún Àjọ Ààrẹ Ìkínní—Ààrẹ Howard W. Hunter, Ààrẹ Gordon B. Hinckley, àti Ààrẹ Thomas S. Monson—fún agbéyẹ̀wò wọn.
Ní àwọn oṣù díẹ̀ lẹ́hìnnáà, ní Oṣù Kẹ́ta 1995 Ààrẹ Hunter kọjá lọ, Ààrẹ Hinckley sì di Ààrẹ káàrúndínlógún ti Ìjọ. Ìkéde náà báyìí wà ní ọwọ́ rẹ̀. Ìgbà wo ni yíò jẹ́ àkokò tótọ́ láti ṣe ìkéde yí fún Ìjọ? Àkokò náà dé ní oṣú mẹ́fà lẹ́hìnnáà.
Àwọn ọjọ́ ṣíwájú Ọjọ́ kẹtàlélógún Oṣù Kẹsan ìpàdé gbogbogbò àwọn obìnrin tí ó ṣíwájú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò, Ààrẹ Hinckley àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ pàdé nínú ìmọ̀ràn pẹ̀lú Àjọ Ààrẹ Gbogbogbò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́. Àwọn arábìnrin, bíiti àwọn Àpóstélì, ti ngbé àwọn ànìyàn yẹ̀wò nípa àwọn obìnrin àti ẹbí. Wọ́n ti ní ìkọjúsí nípa ìpàdé tó nbọ̀ lórí àwọn ẹbí.
À Hinckley ni a ṣètò láti bá àwọn obìnrin sọ̀rọ̀ níbi ìkórajọ. Ó ti nní àròjinlẹ̀ ti ìdárí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bí ìsọ̀rọ̀ kíníkíní náà ṣe nlọsíwájú, ó tọ́ka nípa orúkọ sí ìdásílẹ̀ titun náà ṣùgbọ́n tí kò ti wá sí gbangba “Ẹbí náà: Ìkéde Kan sí Àgbáyé.” Ṣé ìpàdé àwọn obìnrin yí jẹ́ àgbékalẹ̀ títọ́ láti ṣe àwọn ìkéde pípinnu nípa ẹbí?
Ààrẹ Gbogbogbò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ Elaine Kack ṣe àlàyé lẹ́hìnnáà pé: “A kò mọ ohun tí Ìkéde lórí Ẹbí jẹ́ ní àkokò náà. … [À]wa lè sọ nípa àkọlé náà, ṣùgbọ́n a ní ìmọ̀lára pé ohunkóhun lórí ẹbí … yíò jẹ́ ohun dídára. … Mo ní ìmọ̀lára dídára gidi pé a ní àwọn ọmọ Iyejú àwọn Méjìlá tí wọ́n ngba ìfihàn.”
Ìpàdé Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ ní Sátidé náà jẹ́ onítàn. Ààrẹ Hinckley ṣàfihàn ìkéde sí ẹbí náà pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì wọ̀nyí: “Pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àríyànjiyàn tí ó nkọjá bí òtítọ́, pẹ̀lú ẹ̀tàn nípa òdiwọ̀n àti iyì, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀fà àti ìfanimọ́ra láti gba àbàwọ́n díẹ̀díẹ̀ ti ayé a ní ìmọ̀lára láti kìlọ̀ àti láti kìlọ̀ ṣíwájú … ti òdiwọ̀n, ẹ̀kọ́, àti àwọn ìṣe ní ìbámu sí ẹbí èyí tí àwọn wòlíì, aríran, àti olùfihàn ti Ìjọ yí ti sọ léralérá ní gbogbo àkọọ́lẹ̀-ìtàn rẹ̀.”
Nígbànáà ó ka ìkéde náà tán pàtàpàtà. Bí Olúwa ti wípé, “Bóyá nípa ohun ara mi tàbí nípa ohun àwọn ìránṣẹ́ mi, ó jẹ́ ọ̀kannáà.”
Ìkéde náà sọ pé, “Ẹbí ni a yàn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Mo fẹ́ràn híhàn kedere ẹ̀là ọ̀rọ̀ náà. Ìkéde náà ni ìpè fún wa láti gbé ní ayé ikú ní fífura àtọ̀runwá tí ó wà nínú wa àti ọjọ́ ọ̀là ayérayé tí ó wà níwájú wa. Ààrẹ Nelson ti kọ́ni pé, “Ẹ jẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀mí ti Ọlọ́run gan an. … Ẹ máṣe ṣe àṣìṣe nípa rẹ̀: Agbára yín jẹ́ àtọ̀runwá. Pẹ̀lú aápọn yín ni wíwá, Ọlọ́run yio fún yín ní àwọn ìríran firi nípa ẹnití ẹ le da.”
Nígbàtí a gbekalẹ̀, ìkéde náà kò sí ní ìbámu pẹ̀lú ìwò ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ayé. Kìí ṣe nígbànáà. Kìí ṣe báyìí. Àwọn kan wà tí wọ́n ní ìdàmú pẹ̀lú ìkéde lórí ẹbí, ìgbeyàwó, àti ẹ̀yà. Àwọn kan dá àbá pé kí Ìjọ fàá padà, tunṣe, tàbí àní kí wọ́n gbé ìkéde náà sí ẹgbẹ́.
Ìkéde lórí ẹbí yí, bí Ààrẹ Hinckley ti sọ ni, ẹ̀kọ́, ẹ̀yín arákùnrin àti arábìnrin. Ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ kìí ṣe àìsí nínú ìgbésẹ̀ ṣùgbọ́n nínú ìgbésẹ̀ pípé pẹ̀lú àwọn ọ̀nà Olúwa àti ipa ọ̀nà Rẹ̀. Àwọn ìkọ́ni ti ìkéde náà ni a fihàn nípasẹ̀ Olúwa Jésù Krístì sí àwọn Àpóstélì Rẹ̀ nígbànáà àti báyìí. Èyí ni Ìjọ Rẹ̀; Ó ti gbe àwọn òtítọ́ kalẹ̀ nípa èyí tí a fi ngbé.
Àwọn kan lára yín lè ronú lórí ìkéde náà kí wọ́n sì wípé, “Èyí kìí ṣiṣẹ́ fún mi.” “Ó dàbí àìní-ìfura.” “Ẹbí mi kò dàbí ìyẹn.” “Èmi kò sí ní ìbámu.”
Fún àwọn tó ní àníyàn, ẹ mọ̀ pé ẹ jẹ́ ọmọ òbí ọ̀run, ara ẹbí baba yín Ọ̀run. Kò sí ẹni tí ó mọ̀ yín dárdára tàbí nṣètọ́jú jíjinlẹ̀ síi nípa yín ju bí Ó ti nṣe. Ẹ yípadà sí I, ẹ tú ọkàn yín jáde sí I, ẹ gbẹ́kẹ̀lé lé E àti àwọn ìlérí Rẹ. Ẹ ní ẹbí nínú Olùgbàlà yín Jésù Krístì, ẹnití ó fẹ́ràn yín. Ó wá sí ilẹ̀ ayé láti ṣe ètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa kí a sì gbé ẹrù àwọn àṣìṣe wa àti àwọn ọjọ́ búburú gan. Ó ní òye ohun tí ẹ̀ nkojú tí ẹ sì nní ìmọ̀lára. Ẹ yípadà sí I, ẹ gbẹ́kẹ̀lé E yíò sì rán Ẹ̀mí Mímọ́ láti wà pẹ̀lú yín, gbé yín ga, àti tọ́ ọ yín sọ́nà. Ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Wọn tí “ó tàn káàkiri ibi gbogbo nínú ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn; … ni ó dára ju ohun gbogbo … tí ó sì jẹ́ ayọ̀ tí ó pọ̀ jù sí ẹ̀mí.”
Gbogbo àwọn Àpóstélì Olúwa fẹ́ràn yín dénúdénú. A gbàdúra fún yín a sì wá ìtọ́sọ́nà Olúwa fún yín. Dúró pẹ̀lú wa. Ẹ̀ ngbé ní àwọn àkokò ìpènijà nígbàtí ọ̀tá nwá láti mú u yín jẹ́ tirẹ̀. Ẹ máṣe fà kúrò. Tí ẹ bá sì tì fa kúrò, ẹ padà wá. A na apa wa síta síi yín, bíi ti àwọn ẹlòmíràn tí ó fẹ́ràn yín.
Ìkéde náà sọ pé, “Àwọn òbí ní ojúṣe mímọ́ láti tọ́ àwọn ọmọ nínú ìfẹ́ àti òdodo.” Ìwé ti Mọ́mọ́nì pèsè ẹlẹ́ẹ̀rí kejì sí òtítọ́ yí. Nínú ẹsẹ kínní orí kínní, a ka, “Èmi, Néfì, nítorí tí a bí mi nípa àwọn òbí dídára.” Melo lára wa ti bẹ̀rẹ̀ Ìwé ti Mọ́mọ́nì—ó sì bẹ̀rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan àti lẹ́ẹ̀kansi—àti nínú ètò náà fi àwọn ọ̀rọ̀ wọnnì sí ìrántí. Fi wọ́n sí ọkàn.
Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀là-ọ̀rọ̀ dídùnmọ́ni mi nínú ìkéde ni èyí: “Ìdùnnú nínú ìgbé ayé ẹbí ni ó ṣeéṣe láti ṣe àṣeyege nígbàtí ó bá dá lórí àwọn ìkọ́ni … Jésù Krístì.”
Tani kò fẹ́ láti ní inú dídùn?
Kí sì ni àwọn ìkọ́ni Jésù Krístì? Lẹ́ẹ̀kansi, nínú ìkéde náà ni: “Ìgbàgbọ́, àdúrà, ìrònúpìwàdà, ìdáríjì, ọ̀wọ̀, ìfẹ́, àánú, iṣẹ́, àti àwọn ìṣe ìdárayá pípéye.”
Àwọn tí ìgbé ayé wọn kò ní dára síi nípa lílò àwọn kókó ìpinlẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ wọ̀nyí? Kò sí ẹnikẹ́ni lára wa tí yíò ṣe pípé; ṣùgbọ́n a lè tẹ̀lé àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n Ààrẹ Hinckley: “Ẹ ṣe dídárajùlọ tí ẹ lè ṣe.”
A kà nínú ìkéde náà pé, “Àwọn baba níláti ṣàkóso nínú ìfẹ́ àti òdodo,” àti pé “àwọn ìyá ní kókó ojúṣe fún títọ́jú àwọn ọmọ wọn.” Ṣàkóso kò túmọ̀sí dídarí, àti pé títọ́jú kò túmọ̀sí ojúṣe kejì. Ọlọ́run ti fún àwọn ọkùnrin àti obìnrin ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣùgbọ́n àwọn ojúṣe pàtàkì tó dọ́gbà tí ó gbóríyìn fún ara wa.
Ẹ jẹ́ ki nṣe àbápín ìtàn araẹni kan.
Aya mi àti èmi kọ́ láti ṣiṣẹ́ dáradára síi ní jíjẹ́ alábáṣepọ̀ dídọ́gba lẹ́hìn ọjọ́ kan nígbàtí mo pinnu láti ṣe ìpinnu pàtàkì láì bá a pèrò. Ìṣe mii yà á lẹnu, o mú ní ìjárafuru, ó sì fi í sí ipò ṣíṣòrò gidi kan. Lẹ́hìnwá, ó fi ọwọ́ rẹ̀ sí orí èjìká mi ó sì wí gbọingbọin pé, “Ron, jọ̀wọ́, máṣe ṣe èyí sí mi mọ́.” A ti wa ní ìdọ́gba dáadáa láti ìgbà náà lọ.
A ri nínú ìkéde ẹbí: “Àwọn baba àti ìyá ní ojúṣe láti ran ara wọn lọ́wọ́ bíi àwọn alábáṣepọ̀ dídọ́gba.”
Dídọ́gba ni ọ̀rọ̀ kan tí ó ṣe pàtàkì. Ní àwọn ọdún díẹ̀ Arábìnrin Rasband àti èmi ti ṣiṣẹ́ papọ̀ nínú ohun tí ìkéde ṣe àpèjúwe bí “àwọn ojúṣe mímọ́ wa,” a túnṣe a sì bádọ́gbà nínú ìgbeyàwó. Bí ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àwọn ọmọ wa ti gbéyàwó, Arábìnrin Rasband àti èmi tẹ̀síwájú láti gbà wọ́n àti tọkọ-taya wọn lámọ̀ràn bí wọn ó ti jẹ́ alábáṣepọ̀ dídọ́gba.
Nígbàtí à ngbé pẹ̀lú ojú wa nìkàn sí ọ̀gò Ọlọ́run, à nbọ̀wọ̀ fún ara wa a sì nti ara wa lẹ́hìn. Àwọn àwòṣe tọ̀run ti òdodo wọnnì ndarí sí ìdúróṣinṣin nínú ìgbé ayé olúkúlùkù wa, ẹbí wa, àti ní àwùjọ.
Baba wa ní Ọ̀run ti pèsè ìkéde náà lórí ẹbí láti ṣèrànwọ́ láti tọ́ wa sọ́nà sílé sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, láti ṣèrànwọ́ fún wa láti kọ́ a`ti láti kún fún ìfẹ́, okun, èrèdí, àti òye ayérayé. Pẹ̀lú gbogbo ẹ̀mí mi, mo bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú yín láti gbé ní sísún mọ́ Ọ àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀. Mo ṣe ìlérí bí ẹ ti nṣe bẹ́ẹ̀, Ẹ̀mí yíò mísí yíò sì tọ́ọ yín sọ́nà yíò sì ràn yín lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára nínú ọkàn yín nípa ìlérí àlàáfíà Wọn “tí ó kọjá gbogbo òye.” Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.