Ètùtù Ifẹ́ Jésù Krístì
Ìwòsàn àti ìdáríjì kọ̀ọ̀kan ni a rí ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ wọn nínú ìfẹ́ ètùtù Jésù Krístì.
Mo fi ìfẹ́ mi hàn fún Ààrẹ Russell M. Nelson àti mímoore fún ipa alápẹrẹ tí ó ní lórí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa. Àti fún gbogbo wa, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún dídásí àti gbígbéga ti ìgbé ayé ọlọ́lá ti Ààrẹ Dallin H. Oaks.
Pẹ̀lú ọ̀dún kọ̀ọ̀kan tí ó nkọjá lọ, mo ní ìmọ̀lára ìfẹ́ fún Olùgbàlà, Jésù Krístì, àti fún Ètùtù ti àánú Rẹ̀. Ìrúbọ̀ ọlọ́lá Rẹ̀, tí ó ṣe ìmúdúró ìṣẹ́gun lórí ikú àti ẹ̀ṣẹ̀ ni àbájáde ìdásí jùlọ ti àkọọ́lẹ̀-ìtàn gbogbo aráyé. Níní òye ẹ̀bùn àtọ̀runwá Rẹ̀ fún mi jẹ́ kíkọ́ni ṣíṣí-ìparí tọ̀run tí yíò tẹ̀síwájú kọjá ibojì.
Àánú alágbára ti Olùgbàlà ní dídáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àti ní wíwo àwọn ọgbẹ́ tí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn fà ni ìfihàn ìyanu jùlọ ti ìfẹ́ Ọlọ́run.
Ìfẹ́-inú mi láti fi ìrètí fún àwọn tí wọ́n nwá ìdáríjì fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ líle àti láti fi ìtùnú fún àwọn tí wọ́n nwá ìwòsàn kúrò nínú àwọn ọgbẹ́ olóró tí a fà nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ líle ti àwọn ẹlòmíràn.
Ìwòsàn àti ìdáríjì kọ̀ọ̀kan ni a rí ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ wọn nínú ìfẹ́ ètùtù Jésù Krístì.
Ìgbàgbọ́ Nínú Jésù Krístì
Bí ẹ bá ti dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ líle tí ẹ sì wà nínú ètò ti ríronúpìwàdà tàbí ní ìfẹ́-inú láti ronúpìwàdà ní kíkún kí ẹ sì ní ìmọ̀lára ayọ̀ àìlèsọ ti ìdáríjì, ẹ jọ̀wọ́ ẹ mọ̀ pé iṣẹ́ ìyanu yí ndúró dè yín. Olùgbàlà npè lemọ́lemọ́, “Wá sí ọ̀dọ̀ mi.”
Fífún ìgbàgbọ́ yín nínú Olùgbàlà, Jésù Krístì lókun, yíò ní ìtara ti ẹ̀mí yín láti mọ̀ Ọ́ nínú, gbàgbọ́ nínú Rẹ̀, àti fífí ọkàn yín fún Un. Énọ́sì bèèrè fún ìdáríjì ti ararẹ̀: “Olúwa, báwo ni a ṣe ṣe èyí?” Olúwa fèsì, “Nítorí ìgbàgbọ́ rẹ nínú Krístì, ẹnití ìwọ kò gbọ́ tàbí rí rí.”
Mórónì sì fikun pé, “Bí ẹ ó bá sẹ́ ara yín níti gbogbo àìwà-bí-Ọlọ́run, kí ẹ sì fẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo agbára, iyè àti ipá yín, nígbànáà ni oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ sì tó fún yín.”
Yíyí padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀, yíyí padà sí Ọlọ́run, àti fífún ìgbàgbọ́ yín nínú Jésù Krístì lókun ni ìbẹ̀rẹ̀ dídára. Fífi ìfẹ́ wa sílẹ̀ ní ìrẹ̀lẹ̀ sí Ọlọ́run pẹ̀lú jíjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ líle sí bíṣọ́ọ̀pù tàbí ààrẹ ẹ̀ka, ṣùgbọ́n ìdáríjì yín ní kíkún yíò wá láti ọ̀dọ̀ Olùgbàlà. Ìdáríjì ni ẹ̀bùn àtọ̀runwá tí a fúnni nípasẹ̀ oore ọ̀fẹ́ Jésù Krístì.
Òtítọ́
Ìfẹ́-inú láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run lódodo ni ó jẹ́ bíbárìn nípa ìpinnu láti jẹ́ olóòtítọ́ pátápátá pẹ̀lú Baba yín Ọ̀run, pẹ̀lú ara yín, pẹ̀lú àwọn wọnnì tí a palára, àti pẹ̀lú aṣaájú oyè àlùfáà yín. Baba yín Ọ̀run nyọ̀ nínú ìpinnu yín láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú ìrora ọkàn àti ẹ̀mí ìròbìnújẹ́. Níní ẹ̀mí ìròbìnújẹ́ ni fífi ìrẹ̀lẹ̀ gbé ara yín sí ọwọ́ Ọlọ́run; níní ọkàn ìrora nmú ohun tí Àpóstélì Páúlù ṣe àpèjúwe bí “ìkorò ti ọ̀run wá,” lílọ́ra ìjinlẹ̀ ti ẹ̀mí sí pípadà sí I eyikeyi oye tí ó gbà.
Mímúpadàbọ̀sípò Ohun Tí Ó Já
Lílọ́ra yín ndárí yín sí fífẹ́ láti tún ohun tí ẹ ti já ṣe. Síbẹ̀, dídámọ̀ pé àwọn ohun kàn kò sí nínú agbára yín láti túnṣe, ẹ o´ó gbàdúrà pẹ̀lú ìtara pé Olúwa, nípasẹ̀ oore ọ̀fẹ́ Rẹ̀, yíò ṣèrànwọ́ láti wo a`wọn tí a ti palára nínú a`yọrísí a`wọn ìṣe wọn.
Àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ líle lórí àwọn ẹlòmíràn nígbàkugbà wà pẹ̀lú ìrora nínira láti borí. Ṣé àwọn ìlàkàkà yín ntẹ̀lé àpẹrẹ àwọn ọmọ Mòsíàh, tí wọ́n fi “títara tiraka láti tún gbogbo àwọn ọgbẹ́ èyí tí wọ́n ti ṣe ṣe” Sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn wọ̀nnì tí ẹ nbọ̀wọ̀ fún nípa ohun tí ẹ lè má tilẹ̀ rí.
Bí mo ṣe nmúra ọ̀rọ̀ yí sílẹ̀, mo gba àtẹ̀ránṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ ẹnìkan tó wà nínú ètò ríronúpìwàdà àti níní ìfẹ́-inú láti padà sí Ìjọ. Aya rẹ̀ tẹ́lẹ̀rí ṣì njìyà látinú ` “ti ìgbeyàwó ayérayé [wọn] , [ìnira pẹ̀lú àwọn ọmọ], òfò àbò owó, … nì [àìlè] dé ojú-ìwọ̀n pẹ̀lú a`wọn ìnáwó, [àti] ìmọ̀lára ìfúnni jíjinlẹ̀ ti jíjẹ́ dídálẹ̀.”
Ó pín pẹ̀lú mi bí aṣaájú oyè àlùfáà rẹ̀ ṣe ní “ìmọ̀lára ìwọnilọ́kàn láti [ní kí ó] fi pẹ̀lú àdúra gbèrò ohun tí [òun lè ṣe síi fún aya àti àwọn ọmọ rẹ̀ tẹ́tẹ̀tẹ́lẹ̀ rí].” Pẹ̀lú àṣẹ, mo pín ara àtẹ̀ránṣẹ́ rẹ̀.
“Ní [àkọ́kọ́] mo ròó pé [owó] ti mo fi sílẹ̀ nínú òfin ìkọ̀sílẹ̀ ju inúrere lọ, ṣùgbọ́n ààrẹ ẹ̀ka mi gbà mí níyànjú láti gbàwẹ̀ kí nsì gbàdúrà nípa rẹ̀ fún ọ̀sẹ̀ méjì. …
“Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, mo lákákà pẹ̀lú èrò ti ìsànpapdà síwájú síi. Nígbàtí ẹ̀ṣẹ̀ mi kìí ṣe ti owó, ó yàmílẹ́nu ohún tí ‘ìsànpadà inúrere’ kan túmọ̀ sí nítòótọ́ … [ṣùgbọ́n] láìpẹ́ mo dá a mọ̀ pé kìí ṣe nípa owó lásán.
“Mo pàdé pẹ̀lú àwọn aṣaájú oyè àlùfáà mi [aya mi tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀rí] àti àwọn ọmọ mi mo sì damọ̀ pé wọ́n ṣì nlákàkà wọn kò sì tíì wòsàn. …
“Ìlépa titun mi ni láti lọ síwájú pẹ̀lú ìgbàgbọ́. … Mo kàn fi ìfẹ́-inú mi hàn láti ṣèrànwọ́ pẹ̀lú àìsí ìlẹ̀mọ́ kankan. … Mo pinnu láti [fi oye kan pàtó ránṣẹ́ sí aya mi tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀rí] ní ṣẹ́ẹ̀kì-ìsanwó kọ̀ọ̀kan, èyí tí ó ṣe apákan pàtàkì ti àpapọ̀ ìsanwó mi. Kété ṣíwájú sísan owó àkọ́kọ́, Olúwa [fi ìwọ̀lọ́kàn sí inú mi pé mo nílò] láti san [ìlọ́po méjì ti oye náà].
“Mo ti kọ́ pé ìsanpadà kìí kàn nṣe nípa owó. Ó jẹ́ nípa fífi ìrẹ̀lẹ̀ ya ayé mi sí mímọ́ sí Olúwa. … Owó náà jẹ́ láti ṣèrànwọ́ láti rọ́pò ohun tí mo gbà kúrò lọ́wọ́ ẹbí mi nítorí àwọn yíyàn àìdára. Ó jẹ́ nípa dídá àti pípa àwọn ìlérí mọ́ láì retí ohunkóhun ní àbábọ̀ àti ríràn án lọ́wọ́ láti máṣe dàmú nípa owó-sísàn kí òun lè wá Ẹ̀mí.”
Ìtiraka yín láti mú ohun tí ẹ já padàbọ̀sípò lè má ní ohunkóhun láti ṣe pẹ̀lú owó, ṣùgbọ́n bí ẹ ti nfi pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Olúwa, ẹ lè ri pé púpọ̀ síi wà tí ẹ lè ṣe.
Àṣẹ Àtọ̀runwá nípa àwọn Ìpele
Bí ẹ ṣe nwá ìdáríjì Olúwa, ẹ ní sùúrù bí ẹ ṣe ndúró lórí ìfàṣẹ sí Rẹ̀ ní kíkún. Ẹ gbèrò ìwé mímọ́ yí:
“Wọ́n … rẹ[ara] wọn sílẹ̀ nínú ìrẹ̀lẹ̀ jíjinlẹ̀; wọ́n sì … ké pẹ̀lú agbára sí Ọlọ́run; bẹ́ẹ̀ni, àní ní gbogbo ọjọ́. … [Ṣùgbọ́n] Olúwa lọ́ra láti gbọ́ igbe nwọn nítorí àìṣedéédé wọn.”
“Bíotilẹ̀ríbẹ́ẹ̀ Olúwa gbọ́ igbe wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ … sí mú ẹrù wọn fúyẹ́; … wọ́n sì … bẹ̀rẹ̀sí ṣe rere díẹ̀díẹ̀.”
Ẹ ní sùúrú, bí Olúwa ṣe nfún yín ní ìbùkún Rẹ̀ àti ìfáṣẹsí díẹ̀díẹ̀.
Ní àkokò Olúwa, ẹ yíò ní ìmọ̀lára ohùn Rẹ̀ tí ó nwí fún yín pé, “Máṣe jẹ́ kí ohun wọ̀nyí dà yín lámú mọ́ rárá.” Ní ọjọ́ kan, bí ẹ ṣe ntẹ̀síwájú láti yí padà sí Olùgbàlà, Baba yín Ọ̀run yíò mú “ẹ̀bi kúrò [lọ́kàn yín], nípasẹ̀ èrè Ọmọ rẹ̀.”
Palára àti Jíjìyà
Fún yín ẹnití a ti palárà láìdára gidi nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíràn, mó fẹ́ pín ìfẹ́ àti àánú Olùgbàlà, ìtùnú àti àlàáfíà Rẹ̀.
Ìbànújẹ́ tí ẹ ní ìmọ̀lára, ìrora-ọkàn, òfò, ìmọ̀lára ìfúnni ti dídalẹ̀, ìgbéga ìgbé ayé yín bí ẹ ti ròó láti jẹ́—mo fún yín ní ìdánilójú mí tán, Olùgbàlà mọ̀ yín o´ sì fẹ́ràn yín. Ẹ nawọ́ jáde sí I. Òun yíò jẹ́ olùtùnú àti okun yín; Òun yíò rán àwọn ángẹ́lì Rẹ̀ láti gbé yín sókè. Nígbàwo ni ìrora yín yíò lọ, tí ọ̀fọ̀ yín yíò dínkù, tí àwọn ìrántí àìfẹ́ tí a ti gbàgbé? Èmi kò mọ̀. Ṣùgbọ́n èyí ni mo mọ̀: Òun ní agbára láti mú ẹwà wá látinú eérú ìjìyà yín.
Àwọn àyànfẹ́ arákùnrin àti arábìnrin wa ti Grand Blanc, Michigan, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àìyẹ̀ nínú Jésù Krístì, pẹ̀lú ìgboyà àti àìní-ìmọtaraẹni-nìkàn, ti gbà wọn yíò, nínú àwọn ọ̀sẹ̀ àti oṣù tó nbọ̀ níwájú, gba ìfẹ́ àti àlàáfíà àìláfiwé ti Olúgbàlà lọ́pọ̀lọpọ̀.
Bí ẹ ṣe ntẹ̀síwájú láti fi ìgbẹ́kẹ̀lé yín sínú Rẹ̀, àwọn ìkuùkù òkùnkùn àti àròkàn ìsọkún-sínú ní alẹ́ yíò yípòpadà sínú ọ́ṣọ̀rọ̀ omijé ayọ̀ àti àlááfíà ní òwúrọ̀ ìmọ́lẹ̀. “Ìbànújẹ́ Wa Yìo Yípadà sí Ayọ̀. … Kò sì sí [ẹni] tí yíò gba ayọ̀ yín kúrò lọ́wọ́ yín.” Àkokò náà yíò wá. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé yíò wá.
Ètùtù ifẹ́ Jésù Krístì ni a lè rí nínú àwọn ipò nínira jùlọ, ṣùgbọ́n gbogbo wa nílò ètùtù oore ọ̀fẹ́ Olùgbàlà wa léraléra. Ààrẹ Dallin H. Oaks ti kọ́ni pé: “Nítorí ìrírí ètùtù Rẹ̀ nínú ayé ikú, Olùgbàlà wa lè tùnínú, wòsàn, àti láti fún gbogbo ọkùnrin àti obìnrin lókun níbigbogbo, ṣùgbọ́n mo gbàgbọ́ pé Ó nṣe é fún àwọn ẹní tí ó nwá A tí ó sì nbèèrè fún ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀ nìkan. Àpóstélì Jákọ́bù kọ́ni pé, ‘Ẹ rẹ̀ ara yín sílẹ̀ níwájú Olúwa, o`un o´ sì gbé yín sókè’ (Jákọ́bù 4:10). À nyege fún ìbùkún náà nígbàtí a bá gbàgbọ́ nínú Rẹ̀ tí a sì gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀.”
Alàgbà Robert E. Wells
Mo gba àṣẹ láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n àti olùfẹ̀hìntì Aláṣẹ Gbogbogbò, Alàgbà Robert E. Wells, nísisìyí ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ọ̀rún, láti pín ìrírí rẹ̀ ti ó ju ọgọ́ta ọdún sẹ́hìn:
Nígbàtí ó ngbé ní Paraguay ní 1960 tí a sì gbà á síṣẹ́ bí olùtọ́jú owó ìlú òkèèrè, Robert Wells, nígbànáà jẹ́ ọmọ ọdún méjìlélọ́gbọ̀n, àti aya rẹ̀, Meryl, ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ awakọ̀ òfúrufú nínú ọkọ̀ òfúrufú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, wọ́n nfò láti ilé ní Uruguay lọ sí Paraguay. Ní dídojúkọ ìkúùkù ribiribi, Robert àti Meryl sọ ìkànsíni rírí àti asọ̀rọ̀mágbèsì pẹ̀lú ara wọn nù. Robert balẹ̀ kíákíá, níbití ó kọ́ pẹ̀lú ìbànújẹ́ pé ọkọ̀ òfúrufú aya rẹ̀ ti jábọ́. Àti aya rẹ̀ tàbí àwọn ọ̀rẹ́ méjì tí wọ́n fò pẹ̀lú rẹ̀ ní wọ̀n kò yè. Àwọn ọmọ rẹ̀, ní ilé ní Asunción, jẹ́ ọjọ́ orí méje, marun, àti méjì.
Alàgbà Wells sọ̀rọ̀ nípa ọ̀fọ̀ rẹ̀:
“Àwọn ọ̀rọ̀ kò lè tó láti fi ìrora tí ó kún inú mi, jẹ ẹ̀dùn ọkàn mi run ó sì fi àìní ìmọ̀ sí ọgbọ́n mi. Omijé jíjinlẹ̀ ti ìkorò kò fìrọ̀rùn dúró ní ṣíṣàn. Láti mú ọ̀ràn burú si, bí iyè-inú mi ṣe ngbìyànjú láti kojú ìdámọ̀ àjálù ti kíkọjá lọ aya mi, mo rí ara mi ní ìrírí ẹ̀bi títóbi fún ìmọ̀lára tí ó fa jíjábọ́ náà.
Robert dá ararẹ̀ lẹ́bi fún àìṣe ìyẹ̀wò ọkọ̀ òfúrufú síi dáadáa àti fún àìfún aya rẹ ní ohun-èlò ìkọ́ni tótó fún fífò. Ó ní ìmọ̀lára ẹ̀bi ti ìpatì.
Robert wípé:
“Iyè-inú mi lọ́ sí ṣíṣókùnkùn biri. … Mo kàn wà láyé —[nítorí àwọn ọmọ ni,] kò sí ohunkóhun jù bẹ́ẹ̀ lọ.”
Mo … sọ ìfẹ́-inú mi láti tẹ̀síwájú nù.”
Ní àkokò, Robert di alábùkúnfún pẹ̀lú ìrírí ìjìnlẹ̀ ti ẹ̀mí. Ó tunsọ:
“Ní ìrọ̀lẹ́ kan, ní bi ọdún kan lẹ́hìnnáà, nígbàtí mo wà lórí orúkún mi nínú àdúrà, iṣẹ́ ìyànu kan ṣẹlẹ̀. Nígbàtí mò ngbàdúrà tí mo sì nbẹ̀bẹ̀ sí Baba mi Ọ̀run, mo ní ìmọ̀lára bí ẹnipé Olùgbàlà wá sí ẹ̀gbẹ́ mi tí mo sì gbọ́ ohùn híhàn kan tí ó nsọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí ọkàn mi àti sí ẹtí mi: ‘Robert, ìrúbọ ètùtù mi san oye fún ẹ̀ṣẹ̀ yín àti àwọn àṣìṣe yín. Aya rẹ daríjì ọ́. Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ dáríjì ọ́. Èmi ó gbé ẹrù rẹ. …’
“Láti àkokò náà lọ, ẹrù ẹ̀bi náà [àti àìní-ìrètí] ni a gbé kúrò lórí mi pẹ̀lú ìyanu. A ti gbà mi là! Lọ́gán mo ní òye ti agbára rírọ̀mọ́ni ti Ètùtù Olùgbàlà àti … pé ó wúlò tààrà sí mi. … Mo ní … ìrírí ìmọ́lẹ̀ àti ayọ̀ bí èmi kò ti mọ̀ rí tẹ́lẹ̀. … A ti fún mi ní ẹ̀bùn àìṣiṣẹ́ fún—ẹ̀bùn Olúwa ti oore ọ̀fẹ́. … Kò tọ́ sí mi—èmi kò ṣe ohunkankan láti jèrè rẹ̀, ṣùgbọ́n Ó fi fún mi bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀.”
Njẹ́ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan jẹ́ “yíyàsímímọ́ nínú Krístì nípa oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, nípasẹ̀ títàsílẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Krístì, … [ní dídà] mímọ́, láìní àbàwọ́n.”
Mó jẹ́ ẹ̀rí ìfẹ́, àánú àti oore ọ̀fẹ́ Olùgbàlà àti Olùràpadà wa. Ó wà láàyè. A jẹ́ Tirẹ̀, a jẹ́ àwọn ọmọ májẹ̀mú. Bí a ṣe ngbàgbọ́ nínú Rẹ̀, tí a sì gbẹ́kẹ̀lé E, Òun yíò gbé wa kúrò nínú àwn ìkorò àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Nígbànáà, kọjá ayé ikú yí, nínú ilé Baba wa, a yíò gbé pẹ̀lú Rẹ̀ Láé àti títí láé Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.