Àti Nísisìyí Mo Ríran
Ipa Ìwé ti Mọ́mọ́nì nínú ayé mi kò dínkù ní jíjẹ́ iṣẹ́ ìyanu sí mi ju bí lílo itọ́ àti amọ̀ tí a fi sí ojú ọkùnrin afọ́ju náà ti jẹ́ lọ.
Pẹ̀lú ìfẹ́ tòótọ́ gbogbo wa ṣe àtúnsọ ọ̀rọ̀ oríyìn Ààrẹ Oaks sí kíkọjálọ ti Ààrẹ Russell M. Nelson. Àti pẹ̀lú ìfẹ́ tó dọ́gba àti ìjìnlẹ̀ ọ̀fọ̀ ṣíṣe, gbogbo wa jẹ́wọ́ àwọn àjálù ni Michigan láìpẹ́ yí àti ní ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ ojoojúmọ́ káàkiri àgbáyé. A jẹ́wọ́ àwọn ohun wọ́nyí pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa Jésù Krístì.
Orí kẹsan ti Jòhánnù ṣe àkọsílẹ̀ ìrírí Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀ tí wọ́n nkọjá nítosí alágbe kan, tí ó fọ́jú láti igbà ìbí. Èyí mú kí àwọn ọmọ ẹ̀hìn bèèrè oríṣiríṣi àwọn ìbèérè ẹ̀sìn tó líle nípa orísun àti ìtànkálẹ̀ àlébù ọkùnrin yí. Olùkọ́ni náà fèsì nípa ṣíṣe ohun kan tó rọrùn gidi tó sì yanilẹ́nu gidi. Ó tutọ́ sínú ìdọ̀tí ó sì ṣe àpòpọ̀ amọ̀ kékeré kan. Lẹ́hìnnáà Ó lo èyí sí àwọn ojú ọkùnrin náà, ní sísọ fún un láti lọ wẹ̀ nínú adágún Sílóámù. Gbogbo èyí ni ọkùnrin aláìríran náà ṣe pẹ̀lú ìgbọ́ràn ó sì “[jáde] wá ní ríríran,” ni ìwé mímọ́ sọ. Bí ẹ̀rí ti jẹ́ pàtàkì tó, bí àtako sí àwọn ìfẹ́-inú tàbí àríyànjiyàn tàbí odì yíyàn pàápàá ní àtakò sí òtítọ́ náà.
Ó dára, ní bíbẹ̀rù pé iṣẹ́ ìyanu yìí yíò tún fi kún ìjayà tí Jésù ti jẹ́ tẹ́lẹ̀ sí àṣẹ tí wọ́n rò pé àwọn ní, àwọn ọ̀tá Olùgbàlà dojúkọ ọkùnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ríran náà wọ́n sì wí nínú ìbínú pé, “Àwa mọ̀ pé [Jésù] jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀.” Ọkùnrin náà fetísílẹ̀ fún àkókò kan, nígbànáà ó wí pé, “Bóyá òun jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ … , èmi kò mọ̀: [ṣùgbọ́n] ohun kan [ni] èmi mọ̀, … tẹ́lẹ̀rí mo fọ́ju, nísisìyí mo ríran.”
Jésù fúnni ní ìtumọ̀ àkọ́kọ́ sí pàṣípààrọ̀ yí, ní sísọ fún àwọn ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀ pé gbogbo ohun yìí ti ṣẹlẹ̀ “kí àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run lè di fífihàn.” Ẹ rántí pé lẹ́ẹ̀mejì nínú àlàyé ṣíṣe yí ìṣe Olùgbàlà ni a tọ́ka sí bíi “sísàmì oróró” sí ojú ọkùnrin afọ́jú náà, ìṣe kan tí ó níláti jẹ́ píparí nípa wíwẹ̀. Àpèjúwe yìí ti “àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run [ní jíjẹ́] fífihàn” le ṣeéṣe kí ó dá àbá ṣíṣípayá ti ìlànà kan.
Òtítọ́ míràn tó fojúhàn ní ìhín ni àwọn ohun èlò tí Ẹlẹ́dàá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, àti ohun gbogbo tó wà nínú wọn, lò láti pèsè iṣẹ́ ìyanu yìí: itọ́ àti ìdọ̀tí ẹ̀kúnwọ́ kan! Àwọn èròjà gan tí kò dàbí ìwọ̀nyí kéde pé Ọlọ́run lè bùkún wa nípasẹ̀ èyíkeyìí ọ̀nà tí Ó bá yàn. Bíi Náámánì tó nkọ Odò Jọ́dánì tàbí àwọn ọmọ Isráẹ́lì tí wọ́n nkọ̀ láti wo ejò lórí ọ̀pá, ó ti rọrùn tó fún wa láti ti orísun ìràpadà wa sọnù nítorípé àwọn èròjà àti ohun èlò dàbí pé ó ṣe kedere tí wọn fẹ́ tini lójú.
Ṣùgbọ́n a rántí láti inú Ìwé ti Mọ́mọ́nì pé àwọn ohun kan jẹ́ kedere àti iyebíye àti pé ṣaájú ìbí Jésù, yíò jẹ́ sísọtẹ́lẹ̀ pé “òun kì [yíò ní] ìrísí tàbí kí ó jẹ́ wíwuni; àti pé nígbàtí àwa [yíò] rí i, kò sí ẹwà tí àwa kò bá fi fẹ́ ẹ.” Bí ó ti jẹ́ léraléra tó tí Ọlọ́run ti rán ọ̀rọ̀ ọlánlá Rẹ̀ nípasẹ̀ ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ kan tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ pè tó sì ní ìtara gidi tàbí ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí kò mọ nkankan nínú oko kan ní New York, tàbí ìránṣẹ́ ìhìnrere titun-gidi kan tàbí ọmọ ọwọ́ kan tó dùbúlẹ̀ ní ibùjẹ ẹran.
Nítorínáà bí àwọn ìdáhùn sí àwọn àdúrà wa bá wá ní àwọn ọ̀nà kedere tàbí dídíjú bẹ́ẹ̀ nkọ́? Njẹ́ a fẹ́ láti faradà, láti tẹ̀síwájú ní gbígbìyànjú láti gbé ìgbé ayé ìhìnrere Krístì láìka iye itọ́ àti amọ̀ tí ó gbà sí? Ó lè má ṣe kedere sí wa ohun tí ó njẹ́ ṣíṣe àti ìdí rẹ̀, àti pé, láti ìgbà dé ìgbà, gbogbo wa yíò ní ìmọ̀lára díẹ̀ bíi ti arábìnrin àgbà tó wí pé, “Olúwa, báwo ni ti ìbúkún kan tí kò sí ní ìfarapamọ́?”
Ẹ ronú sí ẹ̀rí ti òtítọ́ míràn, eléyí nípa oyè àlùfáà mímọ́. Ní ṣíṣe àkọsílẹ̀ àgbékalẹ̀ Ìjọ ìgbà ọ̀sán, ìlà kínní ti Lúkù kà pé: “Nígbànáà ni ó pe àwọn ọmọ ẹ̀hìn rẹ̀ méjìlá papọ̀, Ó sì fún wọn ní agbára àti àṣẹ,” àwọn ẹ̀bùn tí a kìí fúnni dá lórí àwọn ìṣe ìwúrí tàbí ìpinnu nípa àṣà tàbí ẹ̀tọ́-ìbí. Wọn kìí jẹ́ fífi fúnni nípasẹ̀ ilé ìwé jíjẹ́ tọ̀run kan tàbí ibi idánilẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ẹ̀sìn. A nfi fúnni nípa gbígbé ọwọ́ léni lórí nìkan nípasẹ̀ ẹni kan tí ó ní ọwọ́ tí a fi àṣẹ fún ní gbígbé lé orí tirẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé tí kò já, padà sí orísun gbogbo àṣẹ ti ọ̀run, Olúwa Jésù Krístì.
Àti pé nínú ìjọ tí ó ní òye ẹ̀bùn àánú, njẹ́ kì yíò ha jẹ́ ẹ̀rí yíyanilẹ́nu míràn nípa òtítọ́ ti ìjọ náà láti rí àwọn ìbùkún àti àwọn májẹ̀mú wọ̀nyí ní lílọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ìbátan wa tí wọ́n ti kú, àwọn wọnnì lára àwọn ẹbí wa tí wọ́n ti lọ ṣaájú wa? Njẹ́ wọ́n níláti jẹ́ jíjẹníyà nítorípé wọn kò ní ààyè sí ìhìnrere tàbí nítorípé a bí wọn ní àkókò tàbí ní ibi kan nígbàtí àwọn ìlànà àti àwọn májẹ̀mú ti ọ̀run kò tíì wà ní àrọ́wọ́tó sí wọn? Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ní àwọn ilé Olúwa tó jẹ́ mímọ́, tí a ti yàsímímọ́ nínú èyítí iṣẹ́ tó kún fún àánú, tó ngbanilà njẹ́ ṣíṣe ní ìrọ́pò ní gbogbo ọ̀sán àti òru fún àwọn tí wọ́n ti kú wọ̀nyí, àti bákannáà ní fífi àwọn ànfààní sílẹ̀ fún ìjọsìn àti àwọn ìlànà fún àwọn alààyè. Sí ìmọ̀ mi, ẹ̀rí yìí gan an ti òtítọ́ Ọlọ́run, ìfẹ́ Rẹ̀ káríayé fún alààyè àti àwọn òkú, kò jẹ́ rírí níbikíbi míràn ní àgbáyé—bíkòṣe nínú Ijọ kan tó nṣe àfihàn òtítọ̀ ní ọ̀nà yìí gan an: Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.
Àkọ́kọ́ ìbápàde mi pẹ̀lú ẹ̀rí gidi ti òtítọ́ tó nfúnni ní ìríran, tó nfúnni ní ìyè, kò wá pẹ̀lú isàmì òróró amọ̀ tàbí nínú adágún Sílóámù. Rárá, ohun èlò òtítọ́ tó mú ìwòsàn mi wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá bíi àwọn ojú ewé nínú ìwé kan, bẹ́ẹ̀ni, Ìwé ti Mọ́mọ́nì: Ẹ̀rí Míràn ti Jésù Krístì! Àwọn ìtẹ́wọ́gbà nípa ìwé yí ti jẹ́ kíkọlù àti gbígbé sọnù nípasẹ̀ àwọn aláìgbàgbọ́ kan, ìbínú náà nfi gbogbo ìgbà dọ́gba pẹ̀lú ìkórìíra ti àwọn tí wọ́n sọ fún ọkùnrin tí a wòsàn náà pé bóyá kò ṣeéṣe kí ó ti ní ìrírí ohun tí ó mọ̀ pé òun ti ní ìrírí.
Ó ti jẹ́ sísọ fún mi rí pé ọ̀nà náà nípa èyítí ìwé yí fi wá kò dabí pé ó ṣeéṣe, kò ṣeé gbàgbọ́, ó tini lójú, àní ó jẹ́ àìmọ́. Nísisìyí, èyí jẹ́ èdè líle láti ọ̀dọ̀ ẹnìkẹ́ni tí ó nrò pé òun mọ ọ̀nà nípa èyítí ìwé náà fi wáyé, níwọ̀n ìgbà tí àpèjúwe kanṣoṣo tí a fifúnni nípa àwọn ọ̀nà náà ni pé ó jẹ́ títúmọ̀ “nípasẹ̀ ẹ̀bùn àti agbára Ọlọ́run.” Òun nìyí. Gbogbo rẹ̀ nìyí. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ipa Ìwé ti Mọ́mọ́nì nínú ayé mi kò dínkù ní jíjẹ́ iṣẹ́ ìyanu sí mi ju bí lílo itọ́ àti amọ̀ tí a fi sí ojú ọkùnrin afọ́ju náà ti jẹ́ lọ. Ó ti jẹ́, fún mi, ọ̀pá irin ààbò kan fún ọkàn mi, ìmọ́lẹ̀ títayọ àti gígúnni ti ìfihàn, ìmọ́lẹ̀ kan sí ipa ọ̀nà tí mo gbọ́dọ̀ rìn nígbàti àwọn ìkuukù òkùnkùn bá dé. Àti pé dájúdájú wọ́n ti wá, dájúdájú wọn ó sì wá.
Àti nítorí ìran tí ó ti fi fúnmi nípa ìfẹ́ àti oore ọ̀fẹ́ tó nranipadà káríaye ti Olùgbàlà mi, mo pín ẹ̀rí mi pẹ̀lú yín, ní dídáláre ní ìhín bí àwọn òbí ọkùnrin tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bùkúnfún náà ti wí pé kí a gbọ́ ọmọ wọn nítorípé ó ti dàgbà tó ní ọjọ́ orí.” Ó dára, bẹ́ẹ̀ni èmi náà. Ó ti dàgbà tó láti jẹ́ kí a gba ohun tí ó sọ pẹ̀lú èrò, ni wọ́n ní nínú. Ó dára, bẹ́ẹ̀ni èmi náà. Mo ní oṣù méjì ṣíwájú ọjọ́ ìbí mi 85th. Mo ti wà ní bèbè ikú rí ti mo sì padà. Mo ti rìn pẹ̀lú àwọn ọba àti àwọn wòlíì, pẹ̀lú àwọn ààrẹ àti àwọn àpóstélì. Dídára jùlọ nínú ohun gbogbo, ní àwọn ìgbà míràn, mo ti njẹ́ yíyàlẹ́nu láti ipasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run. Mo gbàgbọ́ pé ẹ̀rí mi yíò jẹ́ fífún ní ó kéré tán àgbéyẹ̀wo díẹ̀ ní ìhín.
Nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, mo wá sí ìdánilójú gbogbo ọkàn mi pé Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn jẹ́ ìmúpadàbọ̀sípò òtítọ́ ti ìjọ Májẹ̀mú Titun—àti díẹ̀ síi—nítorípé èmi kò lè sẹ́ ẹ̀rí ti ìmúpadàbọ̀sípò náà. Láti ìgbà àwọn ìrírí àkọ́kọ́ wọnnì, mo rò pé mo ti ní ẹgbẹ̀rún kan—ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá?—àwọn ẹ̀rímíràn pé ohun tí mo ti sọ nípa rẹ̀ lónìí jẹ́ òtítọ́. Nítorínáà, mo ni inú dídùn nísisìyí láti dàpọ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́ mi kíkójọpọ̀ ní àwọn òpópónà Jérúsálẹ́mù, níbití èmi ó kọrin pẹ̀lú ohùn mi tó ti dínkù:
Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.