Dídánwò àti Fífúnlókun nínú Krístì
Àwọn àkokò ìdánniwò kìí ṣe ẹ̀rí pé Olúwa ti kọ̀ yín sílẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n jẹ́ ẹ̀rí pé Ó fẹ́ràn yín tó láti tún yín ṣe kí ó sì fún yín lókun.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, mo ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Olúwa bí a ṣe npade papọ̀. Mo ni ìrẹ̀lẹ̀ láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú yín. Mo gbàdúrà pé Ẹ̀mí yíó gbé ohun tí Olúwa fẹ́ kí ẹ gbọ́ lọ sínú ọkàn yín, jìnnà kọjá àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí èmi ó sọ.
Ní ìgbà pípẹ́ sẹ́hìn, mo lépa láti kọ́ ẹ̀kọ́ físíìksì àti ìṣirò ni àwọn ọdún mi ní kọ́lẹ́ẹ̀jì. Mo ní ìmọ̀lára ìbonimọ́lẹ̀. Mo bẹ̀rẹ̀ sí ní ìmọ̀lára pé mo ngbìyànjú láti kọ́ ohun kan to jù mi lọ. Bí mo ti nmọ ìrẹ̀wẹ̀sì lára sí, bẹ́ẹ̀ ni mo nmọ̀lára pé okun nkéré síi láti máa gbìyànjú. Ìrẹ̀wẹ̀sì mi darí mi sí mímọ̀lára pé àwọn aápọn mi fẹ́rẹ̀ dàbí aláìléso. Mo bẹ̀rẹ̀ sí ronú nípa fífisílẹ̀, nípa ṣíṣe ohun tó rọrùn díẹ̀ síi.
Mo ní ìmọ̀lára àìlágbára. Bí mo ṣe gbàdúrà, mo ní ìmọ̀lára ìdánilójú jẹ́jẹ́ ti Olúwa. Mo ní ìmọ̀lára tí Ó nsọ sínú ọkàn mi pé, “Mo ndán ọ wò ni, ṣùgbọ́n mo wà pẹ̀lú rẹ bákannáà.”
Èmi kò mọ gbogbo ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nígbànáà. Ṣùgbọ́n mo mọ ohun tí mo níláti ṣe—mo bẹ̀rẹ̀ síṣẹ́.
Nípa àròjinlẹ̀ àti iṣẹ́ ṣíṣe nínú àwọn ọdún tó tẹ̀lé, mo wá ní òye ọ̀rọ̀ ìgbani-níyànjú yìí nínú àwọn ìwé mímọ́ pé.: “Èmi lè ṣe ohun gbogbo nínú Krístì ẹnití ó nfi agbára fún mi.”
Mo kọ́ ẹ̀kọ́ pé ìtiraka mi pẹ̀lú físíìksì nítòótọ́ jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Olúwa. Ó nkọ́ mi pé pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀, mo lè ṣe àwọn ohun tó dàbí pé kò ṣeéṣe bí mo bá ní ìgbàgbọ́ pé Òun yíò wà níbẹ̀ láti rànmí lọ́wọ́. Nípasẹ̀ ẹ̀bùn yí, Olúwa nṣiṣẹ́ láti dán mi wò àti láti fúnmi lókun.
Ọ̀rọ̀ náà dánwò ní àwọn ìtumọ̀ púpọ̀. Láti dán ohun kan wò kìí ṣe láti yẹ̀ ẹ́ wò lásán. Ó jẹ́ láti fi kún agbára rẹ̀. Láti dán irin kan wò jẹ́ láti fi sí abẹ́ gbígbá. Ooru, ẹrù wúwo, àti ìtẹ̀mọ́lẹ̀ jẹ́ àfikún, títí tí adánidá rẹ̀ tòótọ́ fi jẹ́ títúnṣe àti fífihàn. Irin náà kò jẹ́ sísọ di aláìlágbára nípa dídánwò. Ní tòótọ́, ó ndi ohun kan tí a lè gbẹ́kẹ̀lé, ohun kan to lágbára tó láti gba àwọn ẹrù títóbi síi.
Olúwa ndán wa wò ní ọ̀nà kannáà láti fúnwa lókun. Ìdánwò náà kìí wá ní àwọn àkókò ìrọ̀rùn tàbí ìtura. Ó nwá ní àwọn àkókò tí a ní ìmọ̀lára fífà kọjá ohun tí a rò pé a lè faradà. Olúwa nkọ́ wa pé a níláti tẹ̀síwájú láti dàgbà kí a má sì ṣàárẹ̀ láé nínú àwọn aápọn wa, pé kí a sáà máa gbìyànjú.
Nígbàtí a bá tẹ̀síwájú láti ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì—àní nígbàtí àwọn nkan lè dàbí pé kò ṣeéṣe sí wa ní àkókò náà—a ndi alágbára síi ní ti ẹ̀mí. Àwọn àkọsílẹ̀ mímọ́ ti ìwé mímọ́ tẹnumọ́ òtítọ́ yìí.
Wòlíì Mórónì, fún àpẹrẹ, jẹ́ dídánwò àti fífúnlókun ní irú ọ̀nà bẹ́ẹ̀. Ó gbé àwọn ọdún ìgbẹ̀hìn rẹ̀ ní dídáwà. Ó kọ̀wé pé òun kò ní àwọn ọ̀rẹ́, pé baba òun ti di pípa, pé àwọn ènìyàn òun ti di píparun. Ó jẹ́ dídọdẹ nípasẹ̀ àwọn tí wọ́n lépa ẹ̀mí rẹ̀.
Síbẹ̀ Mórónì kò sọ ìrètí nù. Dípò bẹ́ẹ̀ ó fín ẹ̀rí rẹ̀ nípa Jésù Krístì sí orí àwọn àwo fún àwọn ènìyàn tí òun kò ní wà láyé láti rí, pẹ̀lú àwọn àtẹ̀lé irú ọmọ àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ifẹ́ inú láti pa á. Ó kọ̀wé fún wa. Ó mọ̀ pé àwọn kan yíò fi àwọn ọ̀rọ̀ òun ṣe yẹ̀yẹ́. Ó mọ̀ pé àwọn kan yíò kọ̀ wọ́n. Síbẹ̀ ó tẹ̀síwájú nínú ìwé kíkọ.
Nínú ìdánwò rẹ̀, ìgbàgbọ́ Mórónì di títúnṣe áti fífúnlókun. Ó di àìléerí síi. Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbé agbára ti ẹni nàà tí ó faradà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ títí dé òpin. A lè nímọ̀lára agbára náà bí a ti nka ẹ̀rí rẹ̀.
“Nísisìyí èmi, Mórónì, kọ àwọn ohun díẹ̀ bí ó ti dára lójú mi; èmi sì kọ̀we sí àwọn arákùnrin mi, àwọn ara Lámánì; èmi sì fẹ́ kí wọn ó mọ̀ pé irínwó àti ogún ọdún ti kọjá láti ìgbà tí a ti fúnni ní àmì nípa bíbọ̀ Krístì.
“Èmí sì fi èdìdí dì àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí, lẹhìn tí mo ti sọ̀rọ̀ díẹ̀ láti gbà yín níyànjú.
“Ẹ kíyèsíi, èmi yíò rọ̀ yín pé nígbàtí ẹ̀yin yio bá kà àwọn ohun wọ̀nyí, bí ó bá jẹ́ ọgbọ́n nínú Ọlọ́run pé kí ẹ̀yin ó kà wọ́n, pé ẹyin ó rántí bí Olúwa tí ní àánu tó sí àwọn ọmọ ènìyàn, láti igbà dídá Ádámù àní títí dé ìgbà tí ẹ̀yin yíò rí àwọn ohun wọ̀nyí gbà, kí ẹ sì ṣe àsarò lórí rẹ̀ nínú ọkàn yín.
“Àti nígbatí ẹ̀yin yíò sì gbà àwọn ohun wọ̀nyí, èmi gbà yín níyànjú pé kí ẹ bẽrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Baba Ayérayé, ní orukọ Krístí, bí àwọn ohun wọ̀nyí kì bá í ṣe òtítọ́; bí ẹ̀yin bá sì bẽrè tọkàn-tọkàn, pẹ̀lú gbogbo ìfẹ́ inú yín, níní ìgbàgbọ́ nínú Krístì, òun yíò fi òtítọ́ inú rẹ̀ hàn sí yín, nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ̀.
“Àti nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́ ẹ̀yin lé mọ̀ òtítọ́ ohun gbogbo.”
Ẹ̀rí ti Mórónì jẹ́ títúnṣe nínú àdánìkanwà, ṣùgbọ́n ó tàn pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ láti tọ́ gbogbo ìran láti wá Baba ní Ọ̀run àti Olùgbàlà Jésù Krístì.
Wòlíì míràn nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, Jákọ́bù, ni a dánwò ti a si fúnlókun bíi ọmọ kan ẹnití ó ní ìrírí àwọn ìpọ́njú àti ìrora-ọkàn púpọ̀. Ṣùgbọ́n baba rẹ̀, Léhì, kọ́ ọ pé Ọlọ́run yíò bùkún un nípasẹ̀ àwọn àdánwò rẹ̀.
“Sì kíyèsíi, ní ìgbà èwe rẹ ìwọ ti ní ìpọ́njú àti ìrora-ọkàn púpọ̀, nítorí ti ìwàkúwà àwọn arákùnrin rẹ.
“Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, Jákọ́bù, àkọ́bí mi nínú aginjù, ìwọ mọ́ títóbi Ọlọ́run; òun yíò sì ya àwọn ípọ́njú rẹ sí mímọ́ fun èrè rẹ.
“Nítorí-èyi, ọkàn rẹ ni a ó bùkún fún, ìwọ yíò sì gbé láìléwu pẹ̀lú arákùnrin rẹ, Néfì; àwọn ọjọ́ rẹ ni ìwọ yíò sì lò nínú iṣẹ́-ìsìn Ọlọ́run rẹ. Nítorí-èyi èmi mọ̀ pé a ti rà ọ́ padà, nítorí ti òdodo Olùràpadà rẹ; nítorí ìwọ ti kíyèsíi pé ní kíkún àkókò ó nbọ̀wá láti mú ìgbàlà wá fún àwọn ènìyàn.”
Wòlíì Joseph Smith ní ìrírí irú dídánwò áti fífúnlókun bẹ́ẹ̀ nígbàtí ó wà ní Ẹ̀wọ̀n Liberty. Nínú àwọn ibú ìbànújẹ́ rẹ̀, Wòlíì Joseph kígbe jáde pé:
“Áà Ọlọ́run, níbo ni ìwọ wà?” …
“Yíò ti pẹ́ tó tí ọwọ́ rẹ yíò jẹ́ dídá dúró?”
Olúwa rí ayọrísí tó nyani símímọ́ nínú ìjìyà Joseph tí ó bá faradà á dáradára nígbàti Ó fèsì pé:
“Ọmọ mi, àlàáfíà fún ọkàn rẹ; àwọn ìrora rẹ àti àwọn ìpọ́njú yíò jẹ́ fún ìgbà díẹ̀;
“Àti pé nígbànáà, bí ìwọ bá fi ara dàá dáradára, Ọlọ́run yíò gbé ọ ga sókè; ìwọ yíò borí gbogbo ọ̀tá rẹ.”
Àpẹrẹ títóbijùlọ ti dídánwò áti fífúnlókun ṣẹlẹ̀ nípasẹ̀ Ètùtù Olùgbàlà. Ó gba àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aráyé lé orí Ararẹ̀. Ó gbé àwọn ìrora àti ìbànújẹ́ wa. Ó mu ago kíkorò. Ó yege ìdánwò bíi onígbàgbọ́ ní gbogbo àkokò.
Nítorí Ètùtù ológo Rẹ̀, Jésù Krístì le fún wa lókun nínú àwọn àkokò ìdánwò wa. Ó mọ bí yíò ti ràn wá lọ́wọ́ nítorí Òun ti ní ìmọ̀lára gbogbo àwọn ìpèníjà tí a lè mọ̀lára ní ayé ikú. “Òun yíò mú ìrora àti àìsàn ti àwọn ènìyàn rẹ̀ lé ara rẹ̀ … kí ó le mọ̀ ní ìbámu sí ẹran ara, láti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú gẹ́gẹ́bí àwọn àìlera wọn.”
A kọ́ ẹ̀kọ́ pé nigbàti Ó wà nínú Ọgbà Gẹ́tsémánè, Olùgbàlà béèrè lọ́wọ́ Baba bí ìdánwò náà bá le kọjá lórí Òun—ṣùgbọ́n nígbànáà Ó sọ bákannáà pé bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ ti Baba, nígbànáà Olùgbàlà yíò ṣe é. Ní àwọn ọ̀rọ̀ míràn, Olùgbàlà gbé àní iyèméjì àti àìdánilójú, ṣùgbọ́n Ó ní ìgbàgbọ́ nínú Baba Rẹ̀ Ọ̀run.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, dídánniwò àti fífúnnilókun yín lè má rí bíi ti Mórónì tàbí ti Jákọ́bù tàbí ti Wòlíì Joseph. Ṣùgbọ́n yíò wá. Ó le wá jẹ́jẹ́, nípasẹ̀ àwọn ìdánwò ti igbé ayé ẹbí. Ó le wá nípasẹ̀ àìsàn tàbí ìjákulẹ̀ tàbí ìbànújẹ́ tàbí ìdánìkanwà.
Mo jẹ́rìí pé àwọn àkokò wọ̀nyí kìí ṣe ẹ̀rí pé Olúwa ti kọ̀ yín sílẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n jẹ́ ẹ̀rí pé Ó fẹ́ràn yín tó láti tún yín ṣe kí ó sì fún yín lókun. Ó nmú kí ẹ ní agbára tó láti gbé ìwúwo ti ìyè ayérayé.
Bí a bá dúró bíi olóòótọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn wa, Olúwa yíò tún wa ṣe. Òun yíò fún wa lókun. Àti pé ní ọjọ́ kan, a ó wo ẹ̀hìn a ó sì rí pé àwọn àdánwò wọnnì gan-an jẹ́ ẹ̀rí ìfẹ́ Rẹ̀. A ó ríi pé Ó ntún wá ṣe láti lè dúró pẹ̀lú Rẹ̀ nínú ògo. Bí Páùlù Àpóstélì Olúwa ti sọ ní ìparí ayé tirẹ̀, “Èmi ti ja ìjà rere, mo ti parí iṣẹ́ mi, mo ti pa òtítọ́ mọ́.”
Mo jẹ́rìí pé Ọlọ́run mọ̀ yín. Ó mọ àwọn àdánwò tí ẹ ndojú kọ. Ó wà pẹ̀lú yín. Òun kì yíò kọ̀ yín sílẹ̀. Mo jẹ́rìí pé Jésù Krístì ni Ọmọ Ọlọ́run. Òun ni okun wa, Olùràpadà wa, ìrètí wa. Bí a bá gbẹ́kẹ̀lé E, Òun ó mú kí agbára ti ẹ̀mi wa dọ́gba sí gbogbo àdánwò tí a pè wá láti gbé. Mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.