Ẹbí Náà-Oókan Ìhìnrere Jésù Krístì
Ẹ̀kọ́ wa àti ìgbàgbọ́ wa nínú àwọn ẹbí ayérayé nfún wa lókun ó sì nso wá pọ̀.
Ẹ̀yin olùfẹ́ni arákuǹrin àti arábìnrin mi, ẹ ṣeun fún àwọn àdúrà yín ní ìtìlẹhìn mi. Mo ti ni ìmọ̀lára wọn.
1.
Ẹ̀kọ́ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn wà ní oókan ẹbí. Pàtàkì sí ẹ̀kọ́ wa lórí ẹbí ni tẹ́mpìlì. Àwọn ìlànà tí a gbà níbẹ̀ nfi ààyè gbà wá láti padà bí ẹbí ayérayé sí ọ̀dọ̀ Baba wa Ọ̀run.
Títí di ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2025, Ààrẹ Russell M. Nelson ti kéde kíkọ́ ti àwọn tẹ́mpìlì titun igba. Ó fẹ́ràn láti kéde àwọn tẹ́mpìlì titun ní ìparí ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò kọ̀ọ̀kan, gbogbo wa sì yọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Bákannáà, pẹ̀llú oye púpọ̀ àwọn tẹ́mpìlì nísisìyí ní ipò ìṣètò àti kíkọ́ ṣíṣíwájú jùlọ gan, ó tọ́ kí a dín ìkéde àwọn tẹ́mpìlì titun kù. Nítorínáà, pẹ̀lú àṣẹ Iyejú àwọn Méjìlá, a ko ní kéde àwọn tẹ́mpìlì titun kankan nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò yí. Nísisìyí a ó tẹ̀síwájú ní pípèsè àwọn ìlànà tẹ́mpìlì fún àwọn ọmọ Ìjọ káàkiri àgbáyé, pẹ̀lú ìgbàtí àti ibití a ó ti nkéde kíkọ́ àwọn tẹ́mpìlì titun.
Apákan ọ̀rọ̀ mi tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ fúnni ní ọ̀sán yí ni a kọ lẹ́hìn ikú àyànfẹ́ Ààrẹ wa Ààrẹ Russell M. Nelson. Ohun tí ó tẹ̀lé nísisìyí ni a kọ tí a sì fi àṣẹ sí ní àwọn ọ̀sẹ̀ ṣíwájú, ṣùgbọ́n ó ṣì rọ́pò àwọn ìkọ́ni mi, tí a mísíni láti ọ̀dọ̀ Olúwa.
ll.
Ìkéde ẹbí, tí a polongo ní ọgbọ̀n ọdún sẹ́hìn, kéde pé “ẹbí náà ni a yàn láti ọwọ́ Ọlọ́run” àti pé “ó sì jẹ́ àárín-gbùngbun sí ètò ìṣẹ̀dá fún àyànmọ́ ayérayé ti àwọn ọmọ Rẹ̀.” Bákannáà ó kéde “pé òfin Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Rẹ̀ láti bí si àti láti rẹ̀ si ní ayé ṣì wà nípá.” Àti pé,“A kéde síwájú síi pé Ọlọ́run ti pàṣẹ pé agbára mímọ́ ti ìṣẹ̀dá ni a gbọ́dọ̀ mú ṣiṣẹ́ ní àárín ọkùnrin àti obìnrin nìkan, tí a ṣe ìgbeyàwó fún lábẹ́ òfin bíi ọkọ àti aya.” Bí Alàgbà Russell M. Nelson nígbànáà ti kọ́ àwọn èrò BYU pé ẹbí jẹ́ “ìrọ̀gbàká sí ètò Ọlọ́run. … Ní òtítọ́, èrèdí ti ètò náà ni láti gbé ẹbí ga.”
Ìjọ Jésù Krístì ni a mọ̀ nígbàmíràn bíi ìjọ ààrin gbùngbùn-ẹbí. Ó jẹ́ bẹ́ẹ̀! Ìbáṣepọ̀ wa sí Ọlọ́run àti èrèdí ti ìgbé ayé ikú wa ni a ṣe àlàyé nínú àwọn ọ̀ràn ti ẹbí. Ìhìnrere Jésù Krístì ni ètò Baba Ọ̀run fún èrè àwọn ọmọ ẹ̀mí rẹ̀. A lè sọ nítòótọ́ pé ètò ìhìnrere ni a kọ́kọ́ kọ́ wa nínú ìgbìmọ̀ ẹbí ayérayé kan, ó di ṣíṣe nípasẹ̀ àwọn ẹbí ayérayé, àti pé ìgbìrò àyànmọ́ rẹ̀ ní láti gbé àwọn ọmọ Ọlọ́run ga nínú ẹbí ayérayé.
lll.
Pẹ̀lú àkóónú ti ẹ̀kọ́ náà, àtakò wà. Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà à njìyà látinú ìrẹ̀hìn nínú ìgbeyàwó àti ọmọ-bíbí. Fún bíi ọgọ́ọ̀rún ọdún ìwọ̀n àwọn ìdílé tí à ndarí nípa àwọn tọkọtaya tó ti gbéyàwó ti rẹlẹ̀, bẹ́ẹ̀náà ni oye ìbí. Àwọn ìgbeyàwó àti oye ìbí ti àwọn ọmọ Ìjọ pọ̀ síi ní dídára, ṣùgbọ́n bákannáà wọ́n ti rẹlẹ̀ gidigidi. Ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ikẹhìn máṣe sọ òye wọn nípa èrèdí ìgbeyàwó nù àti iyì àwọn ọmọ. Ìyẹn ni ọjọ́ ọ̀la fún èyí tí à ntiraka. “Ìgbéga ni ọ̀ràn ẹbí kan,” ni Ààrẹ Nelson ti kọ́ wa. “Nípasẹ̀ àwọn ìlànà ìgbàlà ìhìnrere Jésù Krístì nìkan ni àwọn ẹbí fi lè ní ìgbéga.”
Ìdínkù nínú ìgbeyàwó ti orílẹ̀-èdè àti ọmọbíbí ní ó yéni fún àwọn ìdí tó nítàn, ṣùgbọ́n iyì àti ìṣe àwọn Ẹ̀nìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn níláti mú gbèrú—kìí ṣe láti tẹ̀lé—àwọn àṣà wọnnì.
Ní jíjẹ́ ọmọdékùnrin mi ní àádọ́rin ọdún sẹ́hìn, mo gbé ní oko àwọn òbí àgbà mi ní àgbékalẹ̀ kan níbití ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ohun tí ó nṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ náà wà lábẹ́ ìdarí ẹbí. Kò sí amóhùnmáwòrán tàbí àwọn ẹ̀rọ̀ míràn láti díwalọ́nà kúró nínú àwọn ìṣe ẹbí. Ní ìlòdì sí, ní àwùjọ ìlú òde òní, díẹ̀ lára àwọn ọmọ ìjọ nní ìrírí lemọ́lemọ́ ti àwọn ìṣe ní oókan-ẹbí. Àwọn tí wọ́n ngbé ìlú àti gbígbéni òde òní, ìṣètò ìbi eré, àti ìyára-gíga ìbárasọ̀rọ̀ ti ó nmú kí ó rọrùn fún àwọn ọ̀dọ́ láti tọ́jú ilé wọn bí àwọn ìlé-gbígbé níbití wọ́n kàn nsùn sí àti tí wọ́n sì nní oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ṣùgbọ́n níbití wọ́n ti ní ìdínkù ìdarí gidi ti òbí nípa àwọn ìṣe wọn.
Àwọn ipa òbí bákannáà ti di àdàlù nípa àwọn ọ̀nà nínú èyí tí àwọn ọmọ Ìjọ jùlọ lọ́wọ́lọ́wọ́ fi ntọ́jú araẹni. Ní àkokò tó kọjá, ọ̀kan lára àwọn ipa títóbi tí ó nda àwọn ẹbí pọ̀ ni ìrírí ìlàkàkà papọ̀ nínú ìfojúsí ti ìwọpọ̀ ìlépa—bí irú títẹ̀ba aginjù tàbí tọ́jú araẹni. Ẹbí náà jẹ́ ìṣètò kan àti àkóso ẹ̀ka ti ìmújáde ìṣúná. Ní òní, púpọ̀jùlọ àwọn ẹbí ni àwọn ẹ̀ka ti jìjẹ ìṣúná, èyí tí kò bèèrè fún òye gíga ti ṣíṣètò ẹbí àti àjùmọ̀ṣe.
IV.
Gẹ́gẹ́bí ipa òbí ṣe ndínkù, àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ṣì ní ojúṣe tí Ọlọ́run fúnni láti kọ́ àwọn ọmọ láti múrasílẹ̀ fún àyànmọ́ ẹbí wa ní ayé àìlópin (wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 68:25) Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára wa gbọ́dọ̀ ṣe èyí nígbàtí ó bá jẹ́ pé kíí ṣe gbogbo àwọn ẹbí wa ni oníṣẹ̀ṣe. Ìkọ̀sílẹ̀, ikú, àti ìyapa jẹ́ ódodo. Mo ní ìrírí èyí nínú ẹbí èyí tí a ti tọ́ mi.
Baba mi kú nígbàtí mo wà ní ọmọ ọdún méje, nítorínáà arákùnrin mi kékeré àti arábìnrin àti èmi ni a tọ́ láti ọ́wọ́ ìyá opó kan. Nínú àwọn ipò nínira jùlọ, ó tẹ̀síwájú. Ó dánìkànwà ó sì ní ìrora, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olúwa, ìkọ́ni alágbára rẹ̀ nípa ẹ̀kọ́ ti Ìjọ mímúpadàbọ̀sípò ntọ́ wa sọ́nà. Bí ó ṣe gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ tọ̀run ní títọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì di alábùkún-fun! A tọ́ wa nínú ìlé ìdùnnú nínú èyí tí baba wa olóògbé ti jẹ́ òdodo nígbàgbogbo. Ó kọ́ wa pé a ní baba kan àti pé óun ní ọkọ kan àti pé a yíò di ẹbí kan nítorí ti ìgbeyàwó tẹ́mpìlì wọn. Baba wa kàn kúrò ránpẹ́ ni nítorí Olúwa ti pè é sí iṣẹ́ tó yàtọ̀.
Mo mọ̀ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹbí míràn kò ní ìdùnnú bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n gbogbo ìyá kọ̀ọ̀kan lè kọ́ nípa ìfẹ́ Baba Ọ̀run àti àwọn ìbùkún ti ìgbeyàwó tẹ́mpìlì ní òpin. Ẹ̀yin náà lè ṣe èyí! Ètò Baba Ọ̀run fi ìṣeéṣe yí dájú fún gbogbo ènìyàn. A ní ìmoore fún ìgbeyàwó tẹ́mpìlì àti fún ìfojúsọ́nà àwọn ìbùkún ti jíjẹ́ fífi èdìdi dì bí ẹbí ayérayé kan. Bíiti ìyá mi, a fẹ́ràn láti ṣe àyọsọ ìlérí Léhì sí ọmọ rẹ̀ Jákọ́bù pé Ọlọ́run “ya àwọn ìpọ́njú rẹ̀ sí mímọ́ fún èrè rẹ” (2 Néfì 2:2). Èyí wà fún gbogbo ẹbí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, ní pípé tàbí àìpé lọ́wọ́lọ́wọ́. A jẹ́ ẹbí ìjọ kan.
Ẹ̀kọ́ wa àti ìgbàgbọ́ wa nínú àwọn ẹbí ayérayé nfún wa lókun ó sì nso wá pọ̀. Èmi kò ní gbàgbé ìlérí ti baba ìyá mi Harris, nígbàtí àwa ọmọ ngbé ní oko rẹ̀ nítòsí Payson, Utah. Ó fún mi ní àjálù ìròhìn pé baba mi ti kú ní ọ̀nà-jíjìn Denver, Colorado. Mo sáré lọ sínú yàrá-ibùsùn mo sì kúnlẹ̀ lẹgbẹ ibùsùn, mo sọkún púpọ̀. Baba àgbà tẹ̀lé mi ó sì kúnlẹ̀ lẹgbẹ mi ó wípé, “Èmi ó jẹ́ baba rẹ.” Ìlérí ìrọ́nú yí ni àpẹrẹ alágbára kan nípa ohun tí àwọn òbí àgbà lè ṣe láti dí àlàfo náà nígbàtí àwọn ẹbí bá pàdánù tàbí ndárò ọmọ ẹbí kan.
Àwọn òbí, àdánìkanwà tàbí onígbeyàwó—bíiti àwọn obí àgbà tí wọ́n dí ojúṣe náà fún àwọn ọmọ—jẹ́ ọ̀gá àwọn olùkọ́. Ìkọ́ni wọn dídára jùlọ jẹ́ nípa àpẹrẹ. Agbo ẹbí ni ibi tó yẹ láti júwe àti láti kọ́ ẹ̀kọ́ àwọn iyì ayérayé, bíiti irú jíjẹ́ pàtàkì ìgbeyàwó àti àwọn ọmọ, èrèdí igbé ayé, àti orísun òtítọ́ ti ayọ̀. Bákannáà ó jẹ́ ibi dídarajùlọ láti kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì àwọn ẹ̀kọ́ ti ìgbé ayé, bíi ti inúrere, ìdáríjì, ìkóra-ẹni-níjánu, àti iyì ẹ̀kọ́ àti íṣẹ́ òtítọ́.
Bẹ́ẹ̀ni, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Ìjọ ní àwọn àyànfẹ́ ọmọ ẹbí tí wọn kò rọ̀mọ́ àwọn ìyì ìhìnrere àti ìgbìrò. Irú àwọn ọmọ ìjọ bẹ́ẹ̀ nílò ìfẹ́ àti sùúrù wa. Ní bíbá ara wa ṣe, a níláti rántí pé jíjẹ́ pípé tí à nwá kò dínkù sí àwọn ipò ìnira ti ayé ikú. Ìkọ́ni nlá nínú Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 138:57–59 fi dá wa lójú pé ìrònúpìwàdà àti ìdàgbà ti ẹ̀mí lè tẹ̀síwájú nínú ayé ẹ̀mí tí ó tẹ̀lé ayé ikú. Pàtàkì púpọ̀ ni, bí àwọn ẹbí ṣe ndàpọ̀ láti fún ara wọn lókun, gbogbo wa níláti rántí pé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn àìlera kò ṣeémáṣe tí gbogbo wa nní ìrírí nínú ayé ikú ni a lè gbà ìdáríjì fún nípasẹ̀ ìrònúpìwàdà nítorí ti Ètùtù ológo àti ìgbàlà ti Jésù Krístì.
V.
Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, ni àwòkọ́ṣe wa ìgbẹ̀hìn. A ó di alábùkún-fún bí a bá ṣe ìgbé ayé wa ní ìtìlẹhìn àwọn ìkọ́ni àti ìrúbọ-araẹni Rẹ̀. Títẹ̀lé Krístì àti fífi arawa sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn sí ara wa ni àtúnṣe fún ìmọ̀tara-ẹni-nìkan àti wíwà lọ́kọ̀ọ̀kan tí ó dàbí ó wọ́pọ̀ báyìí.
Bákannáà àwọn òbí ní ojúṣe kan láti kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ìmọ̀ ti ara yàtọ̀ sí àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ ìhìnrere. Àwọn ẹbí nní ìrẹ́pọ̀ nígbàtí wọ́n bá nṣe àwọn ohun onítumọ̀ papọ̀. Ọgbà ẹbí ngbé àwọn ìbáṣepọ̀ ẹbí ró. Àwọn ìrírí ìdùnnú ẹbí nfún ìsopọ̀ ẹbí lókun. Pípàgọ́, ìṣeré ìdárayá, àti àwọn eré ṣíṣe míràn nípàtàkì jẹ́ iyì sí sísopọ àwọn ẹbí. Àwọn ẹbí níláti ṣètò ìtúndàpọ̀ ẹbí láti rántí àwọn babnlá, èyí tí ó darí sí tẹ́mpìlì.
Àwọn òbí níláti kọ́ àwọn ọmọ ní kókó iṣẹ́ ti gbígbé, pẹ̀lú ṣíṣe iṣẹ́ nínú ọgbà àti ilé. Kíkọ́ni ní àwọn èdè ni ó wúló fún iṣẹ́-ìsìn ìránṣẹ́ ìhìnrere àti ìgbé ayé òde òní. Àwọn olùkọ́ àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyí lè jẹ́ òbí tàbi òbí-òbí tàbí àwọn ọmọ ẹbí jíjìnnà Àwọn ẹbí ngbèrú nígbàtí wọ́n bá kọ́ ẹ̀kọ́ bíi ẹgbẹ́ tí wọ́n sì gbàmọ̀ràn papọ̀ lórí gbogbo àwọn ọ̀ràn ti àníyàn sí ẹbí àti àwọn ọmọ rẹ̀.
Àwọn kan lè wípé, “Ṣùgbọ́n a kò ní àkokò fún eyikeyi lára ìyẹn.” Láti wá àkokò láti ṣe ohun tí ó ṣekókó nítòótọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òbí yíò ri pé wọ́n lè rí ìfọkànsí ẹbí wọn tí wọ́n bá yí àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé wọn pa. Àti pé àwọn òbí , ẹ rántí, pé ohun tí àwọn ọmọdé nfẹ́ lódodo fún oúnjẹ alẹ́ ni àkokò pẹ̀lú yín.
Àwọn ìbùkún títóbi nwá fún ẹbí bí wọ́n bá gbàdúrà papọ̀, ní kíkúnlẹ̀ lálẹ́ àti òwúrọ̀ láti fi ọpẹ́ fún àwọn ìbùkún àti láti gbàdúrà lórí àwọn àníyàn tó wọ́pọ̀. Bákannáà àwọn ẹbí ndi alábùkún-fún bí wọ́n ṣe njọ́sìn papọ̀ nínú isìn ìjọ àti nínú àwọn àgbékalẹ̀ ìsìn àkànṣe míràn. Àwọn ìsopọ̀ ẹbí bákannáà jẹ́ fífún lókun nípasẹ̀ àwọn ìtàn ẹbí, dídá àṣà ẹbí sílẹ̀, àti pípín àwọn ìrírí mímọ́. Ààrẹ Spencer W. Kimball rán wa létí pé “àwọn ìtàn ìmísí látinú ìgbé ayé ara wa àti ti àwọn babanla wa … jẹ́ àwọn ohun-èlò alágbára.” Wọ́n máa njẹ́ orísun dídárajùlọ ti ìmísí fún wa àti àwọn ìran wa.
Mo jẹ́ ẹ̀rí nípa Olúwa Jésù Krístì ẹni tí ó jẹ́ Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo Ọlọ́run Baba wa Ayérayé. Ó pè wá láti tẹ̀lé ipa ọ̀nà májẹ̀mú tí ó darí lọ sí ìtúndàpọ̀ ẹbí ti ọ̀run. Agbára èdìdi ti oyè àlùfáà, tí a ndarí nípasẹ̀ àwọn kọ́kọ́rọ́ tí a mú padàbọ̀sípò nínú Tẹ́mpìlì Kirtland, nmú àwọn ẹbí wá papọ̀ fún ayé àìlópin (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 110:13–16). Lọ́wọ́lọ́wọ́ à nlò wọ́n nínú ìdàgbà oye àwọn tẹ́mpìlì ti Olúwa káàkiri ayé. Èyí jẹ́ òdodo. Ẹ jẹ́ kí a jẹ́ ara rẹ̀, ni mo gbàdúrà, ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.