Àwọn Wòlíì Ọlọ́run
Láti fetísílẹ̀ àti láti gbọ́ran sí ohùn wòlíì ṣe pàtàkì láti di gbogbo ohun rere mú títí di Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Olùgbàlà.
Ẹ̀yin ọ̀dọ́ ọ̀wọ́n, bí èyí ti jẹ́ ìpàdé àpapọ̀ rírẹwà tí a nní! A ti gbọ́ àwọn Àpóstélì alààyè mẹ́ta ti Jésù Krístì. Ó ti jẹ́ ìbùkún àgbàyanu kan tó! Àti pé a yíò tún gbọ́ ọ̀kan díẹ̀ síi, Ààrẹ Henry B. Eyring. Àpèjẹ ti ẹ̀mí náà ntẹ̀síwájú!
Nígbàtí mo sọ̀rọ̀ lọ́dún tó kọjá, a kọ́ bí a ṣe lè kojú ayé yí nípasẹ̀ ìrírí Dáfídì pẹ̀lú Goliath. Ẹ rántí òkúta marun bí? Lónìí, mo npín ìtàn Májẹ̀mú Láéláé kan tí mo ka ní ọjọ́-orí yín, èyítí ó jẹ́ kí nfẹ́ láti dàbí akọni rẹ̀. Bíbélì ò sọ orúkọ rẹ̀ fún wa, nítorínáà a máa pè é ní obìnrin Ṣúnémù torí pé èyí ni orúkọ ìlú rẹ̀.
Lọ́jọ́ kan, wòlíì Èlíṣà ń la Ṣúnémù kọjá, a sì kà pé “obìnrin ńlá kan wà, [ó sì pè] é láti jẹ àkàrà. Ó sì rí bẹ́ẹ̀, nígbàkúùgbà tí ó bá ń kọjá, ó yíjú sí … láti jẹ búrẹ́dì.” Mo fojú inú wò ó pé inú wòlíì Èlíṣà dùn gan-an sí ìkésíni láti jẹun ní ilé rẹ̀! Ó ti lọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, nígbàtí ọjọ́ kan obìnrin náà sọ fún ọkọ rẹ̀ pé, “Nísisìyí, mo rí i pé ènìyàn mímọ́ Ọlọ́run ni èyí.”
Arábìnrin náà wípé, “Nísisìyí, mo wòye.” Ó dàbíi pé ó pe Èlíṣà wá sí ilé rẹ̀ láìmọ̀ pé wòlíì ni; ó gba ẹ̀rí rẹ̀ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ nípa fífetísílẹ̀ fínnífínní sí ohun tí Èlíṣà sọ àti ohun tí ó kọ́ni. Ẹ rántí pé, kò sí àwọn àwòrán ní àkokò náà! Nítorínáà ó ṣòro láti dá wòlíì náà mọ̀ ní ojú rẹ̀.)
Ṣùgbọ́n ìtàn náà kò parí síbẹ̀. Ní ọjọ́ kan, obìnrin náà sọ fún ọkọ rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí a ṣe yàrá díẹ̀, … kí a sì tẹ́ ibùsùn kan fún un níbẹ̀, àti tábìlì kan, àtẹ̀gùn, àti ọ̀pá fìtílà kan: yíò sì ṣe, nígbàtí ó bá dé ọ̀dọ̀ wa, yíò sì wọlé.”
Obìnrin olóòótọ́ yìí ní ìfẹ́ láti kọ́ yàrá kan sínú ilé rẹ̀, kí wòlíì náà tó ngba ìlú náà kọjá, lè ní ààyè láti gbé!
Lónìí, a lè kọ́ ẹ̀kọ́ alágbára kan láti inú ìrírí yìí.
Olúwa jẹ́ ẹ̀rí fún obìnrin Ṣúnémù náà pé wòlíì Ọlọ́run ni Èlíṣà, ó sì ṣe ìṣe nípa ṣíṣí ilé rẹ̀ láti gbà á.
Àwa pẹ̀lú lè gba ẹ̀rí ti ara ẹni ti wòlíì Ọlọ́run lónìí kí a sì ṣí ọkàn àti èrò inú wa—ilé wa—sí ọ̀rọ̀ tí Baba wa Ọ̀run ní fún wa ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí.
Ẹ̀yin ọ̀dọ́ ọ̀wọ́n, mo pè yín láti bi ara yín léèrè ìbèèrè yìí: “Njé mo ní ẹ̀rí ti ara ẹni nípa wòlíì Ọlọ́run alààyè?”
Ẹ jẹ́ kí a bẹ̀rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀.
Kíni wòlíì kan? Wòlíì ni ènìyàn tí Ọlọ́run pè láti sọ̀rọ̀ fún Un. Àwọn wòlíì wà ní ilẹ̀-ayé lónìí gẹ́gẹ́bí wọ́n ṣe wà ní ìgbà àtijọ́.
Àwọn wòlíì ni àwọn aríran àti olùfihàn. Ìyẹ́n túmọ̀ sí pé wọ́n lè rí ohun tí àwọn ẹlòmíràn kò lè rí, wọ́n sì lè sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ iwájú. Wọ́n tún lè múra wa sílẹ̀ fún àjálù. Àwọn wòlíì ngba òfin àti ìfihàn láti ọ̀dọ̀ Olúwa. Ikẹsan Nkan Ìgbàgbọ́ sọ̀rọ̀ nípa ìfihàn títẹ̀síwájú ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyi. Ó wípé, “A gbàgbọ́ nínú gbogbo ohun ti Ọlọ́run ti fihàn, gbogbo ohun tí Ó nṣàfihàn rẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́, a sì gbàgbọ́ wípé Ó mã ṣàfihàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun nlá àti pàtàkì tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìjọba Ọlọ́run.”
Alàgbà Gary E. Stevenson wípé, “Olúwa ntẹ̀síwájú láti fi àwọn òfin Rẹ̀ àti ìfẹ́ Rẹ̀ hàn sí àwọn wòlíì Rẹ̀ lónìí nítorí Ó fẹ́ láti tọ́ wa lọ sí ayọ̀ ní ayé yìí àti sí ògo ọ̀run ní ayé tó kàn.”
Àwọn wòlíì tún kéde ìhìnrere àti pé wọ́n jẹ́ onímísí olùkọ́ àti àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé.
Olúkúlùkù ọmọ ẹgbẹ́ Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá jẹ́ wòlíì, aríran, àti olùfihàn. Sísìn bíi ìgbìmọ̀ lábẹ́ ìdarí Olúwa, wọ́n ní àṣẹ láti kéde àti láti túmọ̀ ẹ̀kọ́ àti gbígbé ìlànà kalẹ̀ fún Ìjọ Rẹ̀. Wọ́n nfara balẹ̀ gbadura, wọ́n sì nfọ̀rọ̀ wérọ̀, nítorí pé àwọn ìpinnu àwọn iyejú wọ̀nyí gbọ́dọ̀ jẹ́ ìṣọ̀kan. Lọ́nà yí, Olúwa fi dá wa lójú pé ìfẹ́ Rẹ̀ ni yíò jẹ́ ṣíṣe.
Àwọn wòlíì jẹ́ ẹ̀rí nípa Krístì—wíwà Rẹ̀, iṣẹ́́ ìrànṣẹ́ Rẹ̀, àti àtọ̀runwa Rẹ̀.
Ẹ jẹ́ kí a ka àwọn ẹ̀rí àwọn wòlíì láti inú Ìwé ti Mọ́mọ́nì.
Ábínádì kéde:
Ábínádì kéde pé: ”Ọlọ́run fúnrarẹ̀ yíò sọ̀kalẹ̀ wá sí ãrin àwọn ọmọ ènìyàn, yíò sì ra àwọn ènìyàn rẹ̀ padà.
“Àti nítorítí ó ngbé inú ara, Ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè é.”
Sámúẹ́lì ará Lámánì tún jẹ́ ẹ̀rí pé Jésù Krístì ni “Ọmọ Ọlọ́run, Baba ọ̀run àti ti ayé, Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo láti àtètèkọ́ṣe.”
Wòlíì Mórónì sì wípé, “Mo ti rí Jésù, àti pé … ó sì ti bá mi sọ̀rọ̀ lójúkojú.”
Nígbàtí Krístì bẹ àwọn ará Néfì wò, ọ̀kan nínú àwọn ohun àkọ́kọ́ tí Ó ṣe ni pípe Àpọ́stélì Méjìlá. Ó sì wí fún àwọn ènìyàn náà pé, “Alábùkún fún ni ẹ̀yin bí ẹ̀yin bá fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ àwọn méjìlá wọ̀nyí tí Èmi ti yàn.”
Ní báyìí, ẹ jẹ́ kí npín àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀ fún àwọn òbí tàbí àwọn ọmọ ẹbí míràn tí wọ́n ntọ́ àwọn ọmọ. Olúwa fúnra rẹ̀ kọ́ Ádámù àti Éfà ní àwọn òtítọ́ ètò ìgbàlà. Ó sì wí fún wọn pé, “Mo fún yín ní òfin kan láti kọ́ àwọn ọmọ yín ní àwọn nkan wọ̀nyí lọ́fẹ̀ẹ́.”
Kíni ó túmọ̀ sí láti kọ́ni lọ́fẹ̀ẹ́? Ó jẹ́ kíkọ́ àwọn òtítọ́ ìhìnrere, níní ẹ̀rí ti araẹni nípa wọn, àti pípín ìmọ̀ náà pẹ̀lú àwọn ọmọ wa. Ó jẹ́ láti ṣe àgbéga méjèèjì àwọn àkokò ìkọ́ni tí ó múnádóko àti èyí tí kò múnádóko. Ó jẹ́ gbígbé ní ìbámu sí ìmọ̀ àti ẹ̀rí náà.
Ìwé ti Mọ́mọ́nì ṣàpèjúwe àwọn ẹgbẹrun meji àti ọgọta ọmọẹgbẹ́ jagunjagun gẹ́gẹ́bí “àwọn ènìyàn òtítọ́ àti olùfarabalẹ̀ nítorí a ti kọ́ wọn láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ àti láti rìn ní ìdúróṣinṣin níwájú rẹ̀.” Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọ̀nyí fi ìṣòtítọ́ ṣègbọràn sí Hẹ́lámánì, ẹnití ó jẹ́ olórí ológun wọn nígbà náà àti wòlíì wọn pẹ̀lú, wọ́n sì mọ̀ pé àwọn ìyá wọn ti fi òtítọ́ àti ìgbàgbọ́ kún ọkàn wọn.
Ẹ̀yin òbí, nínú ayé yìí tí ohùn púpọ̀ wà, tí òkùnkùn sì pọ̀ nígbà míràn, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ti pàṣẹ fún wa láti tọ́ àwọn ọmọ wa dàgbà nínú ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́. Ó fi ojúṣe wa lé wa lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ọmọ wa ní òtítọ́ ìgbàlà ti ìhìnrere. Bí a bá kùnà láti ṣe bẹ́ẹ̀, aráyé kò ní ṣe é.
Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ọ̀dọ́ ọ̀wọ́n, mo ní ìpè kan fún yín: Ní àwọn ọjọ́ tó nbọ̀, mo pè yín láti kúnlẹ̀, kí ẹ ṣí ọkàn yín sílẹ̀, kí ẹ sì gbàdúrà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ sí Baba Ọ̀run, bíbéèrè kí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún yín pé àwọn wòlíì àti àwọn Àpọ́stélì Méjìlá jẹ́ ohùn Rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé lónìí.
Obìnrin Ṣúnémù kọ́ wa pé a lè ní ẹ̀rí náà nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. Mo ṣèlérí fún yín pé tí a bá ti mọ̀ pé ẹni àmì òróró Ọlọ́run ni wọ́n, ìgbésí ayé wa á túbọ̀ rọrùn láìka àwọn ìpèníjà tó nlọ lọ́wọ́ sí, bí a ó ṣe máa ṣègbọràn sí ohùn wọn pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé, ìgbàgbọ́, àti ìrètí. Láti fetísílẹ̀ àti gbọ́ran sí ohùn wòlíì ṣe pàtàkì láti di gbogbo ohun rere mú títí di Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Olùgbàlà.
Ìwà búburú ayé ndàgbà, ṣùgbọ́n Ìjọ Jésù Krístì àti ìjọba Rẹ̀ lágbára ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Síónì nwọ àwọn ẹ̀wù rírẹwà rẹ̀, àti pé ìtẹ́ Krístì kì yíò ṣubú. Oluwa fẹ́ kí á jẹ alágbára nínú àwọn ẹ̀rí wa, láti kún fún ìgbàgbọ́, àti láti ronúpìwàdà lójoójúmọ́. Olùgbàlà wa Jésù Krístì ngbára lé ẹnìkọ̀ọ̀kan wa láti máa bá iṣẹ́ Rẹ̀ lọ.
Wòlíì Joseph Smith wípé, “Ẹ̀yin ará, njẹ́ a kì yío ha tẹ̀síwájú ninu iṣẹ́ nlá kan?” Bíótiwùkíórí, níwọ̀n bí ìfiránṣẹ́ yìí ti jẹ́ ti ọ̀dọ́, mo fẹ́ lo ọ̀rọ̀ náà ẹ̀yin ọ̀dọ́ dípò ẹ̀yin ara Ẹ ṣetán bí?
“[Ẹ́yin ọ̀dọ́], njẹ́ a kì yío ha tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ nlá kan? Tẹ̀ síwájú kìí ṣe sẹ́hìn. Ìgboyà, [ọ̀dọ́]; àti síwájú, síwájú sí ìṣẹ́gun! Ẹ jẹ́ kí ọkàn yín yọ̀, kí inú yín sì dùn gidigidi.”
Mo dúpẹ́ fún ìtọ́sọ́nà àti àwọn ìyànjú yíyà símímọ́ ti àwọn wòlíì alààyè. Mo fún yín ní ẹ̀rí ọ̀wọ̀ mi pé Ọlọ́run pè wọ́n láti gbé, fìdí múlẹ̀, àti láti darí ìjọba Rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé lónìí. Yíò sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀ nígbàgbogbo. Olúwa ni yíò máa yan àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ nígbàgbogbo. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.