Kò Sí Ẹni Tí Ó Ndánìkan Joko
Gbígbé ìhìnrere Jésù Krístì pẹ̀lú wíwá àti ṣíṣe yàrá fún gbogbo ènìyàn nínú Ìjọ ìmúpadàsípò Rẹ̀.
1.
Fún Àádọ́ta ọdún, mo ti kọ́ ọ̀làjú, pẹ̀lú ọ̀làjú ìhìnrere. Mo bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àkàrà ọrọ̀ òyìnbó.
Ní San Francisco’s Chinatown, oúnjẹ alẹ́ ẹbí Gong máa nparí pẹ̀lú àkàrà ọrọ̀ òyìnbó àti sísọ̀rọ̀ ọgbọ́n bíti “Ìrìn-àjò ti ẹgbẹ̀rún máìlì tí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìgbésẹ̀ kan.”
Bí ọ̀dọ́ àgbà kan, mo ṣe àwọn àkàrà ọ̀rọ̀ òyìnbó. Ní wíwọ ìbọ̀wọ́ kọ́tìnì funfun, mo yíi papọ̀ mo sì ge àwọn àkàrà òyìnbó náà sí ìwọ̀n yíká gbígbóná jáde nínú ìdáná.
Sí ìyàlẹ́nu mi, mo kọ́ ẹ̀kọ́ pé àwọn àkàrà ọrọ̀ òyìnbó kìí ṣe ara ọ̀làjú Chinese tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Láti mọ ìyàtọ̀ ọ̀làjú àkàrà ọrọ̀ òyìnbó Chinese, Amẹ́ríkà, àti European, mo wá àwọn àkàrà ọrọ̀ òyìnbó lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè—gẹ́gẹ́bí ẹnìkan yíò ti lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìbi láti yíká igun-mẹ́ta iná aginjù kan. Àwọn ilé-ìtàjà oúnjẹ Chinese ní San Francisco, Los Angeles, àti New York nta àwọn àkàrà ọ̀rọ̀ òyìnbó, ṣùgbọ́n kìí ṣe àwọn ti Beijing, London, tàbí Sydney. Àwọn Amẹ́ríkà níkan ni wọ́n nṣe ayẹyẹ Orílẹ̀-èdè Ọjọ́ àwọn Àkàrà Ọrọ̀ Òyìnbó. Chinese nìkan ni wọ̀n npolówó ìfúnni ìtàjà “Ojúlówó àwọn Àkàrà Ọrọ̀ Òyìnbó Amẹ́ríkà.”
Àwọn àkàrà ọ̀rọ̀ òyìnbó jẹ́ ìgbádùn, àpẹrẹ ìrọ̀rùn. Ṣùgbọ́n irú ìpìlẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀ká kannáà ti fifi àwọn ìṣe ọ̀làjú wé ní àgbékalẹ̀ yíyàtọ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ọ̀làjú ìhìnrere ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àti nísisìyí Olúwa nfúnni ní àwọn ànfàní titun láti kọ́ ẹ̀kọ́ ọ̀làjú ìhìnrere bíi ti ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Ìwé ti Mọ́mọ́nì àti òwe àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Májẹ̀mú Láéláé ni a ti múṣẹ.
ll.
Níbigbogbo àwọn ènìyàn nlọsíwájú. Orílẹ̀-èdè United ròhìn míllíọ́nù 281 olùkólọ ilẹ̀-òkèèrè. Míllíọ́nù 128 yí ju àwọn olúkúlùkù síi ní 1990, àti ìlọ́po mẹ́ta ti ìṣirò 1970. Níbigbogbo, àwọn nọ́mbà olùyípadà nrí Ìjọ ti Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ìgbà Ìkẹhìn. Gbogbo Ọjọ́-Ìsinmi, àwọn ọmọ ìjọ àti ọ̀rẹ́ láti àwọn orílẹ̀-èdè àti agbègbè nkórajọ ní àwọn 31,880 àkójọ Ìjọ. À nsọ àwọn èdè marundinlaadọ́je.
Láìpẹ́, ní Albania, Àríwá Macedonia, Kosovo, Germany, àti Switzerland, mo jẹ́ ẹlẹ́ẹ̀rí àwọn ọmọ ìjọ̀ titun tí wọ́n nmú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ti igi ólífì Ìwé ti Mọ́mọ́nì ṣẹ. Nínú Jákọ́bù 5, Olúwa ọgbà-àjàrà àti ìránṣẹ́ Rẹ̀ fún méjèèjì gbòngbò àti ẹ̀ka igi ólífì lókun nípa kíkójọ àti gbígbẹ́ àwọn wọ̀nnì láti onírúurú ibi wọnú ara papọ̀. Ní òní àwọn ọmọ Ọlọ́run nkórajọ bí ọ̀kan nínú Jésù Krístì; Olúwa nfúnni ní ọ̀nà àdánidá alápẹrẹ láti gbòòrò ìgbé ayé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ wa ti ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Rẹ̀.
Ní mímúra wa sílẹ̀ fún ìjọba ọ̀run, Jésù sọ àwọn òwe ti oúnjẹ alẹ́ nlá àti àpèjẹ ìgbeyàwó. Nínú àwọn òwe wọ̀nyí, àwọn àlejò tí a pè ṣe àwáwí láti máṣe wá. Olùkọ́ni pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ láti “jáde lọ kíákíá sí àwọn àdúgbò àti ọ̀nà ìlú” àti “òpópónà àti afárá” láti “mú” àwọn òtòṣì, amúkùún, arọ, àti afọ́jù wá. Sísọ̀rọ̀ níti ẹ̀mí, èyí ni ọ̀kọ̀ọ̀kan wa.
Ìwé mímọ́ kéde:
“Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni a ó pè” sí “oúnjẹ alẹ́ ilé Olúwa.”
“Ẹ múra ọ̀nà Olúwa sílẹ, … kí ìjọba rẹ̀ lè jáde lọ lórí ilẹ̀ ayé, kí àwọn olùgbé ibẹ̀ lè gbà á, kí wọ́n sì múrasílẹ̀ fún ọjọ́ tí ó nbọ̀.”
Ní òní, àwọn wọnnì tí a pè sí oúnjẹ alẹ́ Olúwa nwá láti ibi gbogbo àti ọ̀làjú. Àgbà àti ọmọdé, ọlọ́rọ̀ àti òtòṣì, ìbílẹ̀ àti gbogbogbò, à nmú gbogbo Ìjọ wa dà bí àwọn ìletò wa.
Bí Olórí Àpóstélì, Pétérù ṣe rí ọ̀run ní ṣíṣí ìran kan nípa “ìwé kan tí a ṣẹ́ ní etí mẹ́rin, … níbi tí onírúurú … àwọn ẹranko wà.” Pétérù kọ́ni: “Ní òtítọ́ mo ri pé Ọlọ́run kìí ṣe ojúṣájú ènìyàn. … Ní gbogbo orílẹ̀-èdè ẹnití ó bá bẹ̀rù [Olúwa], tí ó sì nṣiṣẹ́ òdodo, ẹni ìtẹ́wọ́gbà ni lọ́dọ̀ rẹ̀.”
Nínú òwe ara Samáríà rere, Jésù pè wá láti wá sọ́dọ̀ arawa àti Òun nínú ilé ìgbàlejò Rẹ̀—Ìjọ Rẹ̀. Ó npè wá láti jẹ́ àwọn aladugbo. Ará Samáríà rere ṣe ìlérí láti padà kí ó sì ṣe ìsanpadà ìtọ́jú àwọn wọnnì nínú ilé ìgbàlejò Rẹ̀. Gbígbé ìhìnrere Jésù Krístì pẹ̀lú wíwá àti ṣíṣe yàrá nínú Ìjọ ìmúpadàsípò Rẹ̀.
Ẹ̀mí ti “yàrá níú ilé ìgbàlejò” pẹ̀lú “kò sí ẹni tí ó ndánìkan joko.” Nígbàtí ẹ bá wá sí ilé ìjọsìn, bí ẹ bá rí ẹnìkan tí ó dánìkanwà, njẹ́ ẹ yíò wípé báwo ni kí ẹ sì joko pẹ̀lú rẹ̀ lókùnrin tàbí lóbìnrin? Èyí lè má jẹ́ àṣà yín. Ẹni náà lè wò tàbí sọ̀rọ̀ tàbí jẹ́ yíyàtọ̀ sí yín. Àti pé, bẹ́ẹ̀ni, bí àkàrà ọrọ̀ òyìnbó lè wípé, “Ìrìn-àjo ìbáṣọ̀rẹ́ ìhìnrere àti ìfẹ́ lè bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú báwo ni àkọ́kọ́ àti àìsí ẹni tí ó ndánìkan joko.”
“Kò sí ẹnití ó ndánìkan joko” bákannáà túmọ̀ sí kò sí ẹni tí ó ndánìkan joko níti ẹ̀dùn ọkàn àti níti ẹ̀mí. Mo lọ pẹ̀lú oníròbìnújẹ-ọkàn baba kan làti bẹ ọmọkùnrin rẹ̀ wò. Àwọn ọdún ṣíwájú, ọmọkùnrin náà ní ìnúdidùn láti di díákónì titun. Ọ̀ràn náà pẹ̀lú èyítí ẹbí rẹ̀ fi ra ẹsẹ̀-batà méji titun àkọ́kọ́ fún un.
Ṣùgbọ́n ní ilé ìjọsìn, àwọn díákónì fi rẹrin. Àwọn bàtà rẹ̀ titun, ṣùgbọ́n kìí ṣe ti àsìkò. Nínú ìdójútì àti pípalára, díákónì ọ̀dọ́ náà wípè òun kò ní lọ sílé ìjọsìn mọ́. Ọkàn mi ṣì ní ìrora ṣíbẹ̀ fún un àti ẹbí rẹ̀.
Ní ọ̀nà eléruku sí Jẹ́ríkò, ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ni a ti fi rẹrin, dójúti tí a sì palára, bóyá fi ṣẹ̀sín tàbí lò nílòkulò. Àti pé pẹ̀lú oríṣiríṣi ipò èrò-inú, ọ̀kọ̀ọ̀kan wa bákànnáà ni a ti ṣe àìkàsí sí, àìríni tàbí gbọ́ ni, bóyá ní mímọ̀ọ́mọ́ pa àwọn ẹlòmíràn lára. Ó jẹ́ rẹ́gí nítorí a ti ní ìpalára a sì ti pa àwọn ẹlòmíràn tí Jésù Krístì mú wá sí ilé ìgbàlejò Rẹ̀ lára. Nínú Ìjọ Rẹ̀.àti nípasẹ̀ àwọn i`lànà àti májẹ̀mú Rẹ̀, à nwá sọ́dọ̀ ara wa àti sọ́dọ̀ Jésù Krístì. À nní ìfẹ́ a sì ngba ìfẹ́, à nsìn a sì ngba sísìn, à ndáríjì a sì gba ìdáríjì. Ẹ jọ̀wọ̀ ẹ rántí, “ayé kò ní ìkorò tí ọ̀run kò lè wòsàn” ẹrù ayé nfúyẹ́—ayọ̀ Olùgbàlà wa jẹ́ òdodo.
Nínú 1 Néfì 19, a kà pé: “Àní Ọlọ́run tó ni Ísráẹ́lì gan-an ni [wọ́n] tẹ̀mọ́lẹ̀ ní abẹ́ ẹsẹ wọn; … wọ́n sọ di asán. … Nítorínáà wọ́n jẹ́ ẹ́ níyà, ó sì jìyà rẹ̀, wọ́n sì lù ú, ó sì jìyà rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ni, wọ́n tutọ́ si lára, ó sì jìyà rẹ̀.”
Ọ̀rẹ́ mi Ọ̀jọ̀gbọ́n Terry Warner wípé ṣíṣe ìdájọ́, jíjẹníyà, lílù, àti títutọ́ kìí ṣe àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan tí ó ṣẹlẹ̀ nìkan ní ìgbà ayé ikú ti Krístì. Báwo ni a ṣe nhùwasí ara wa—nípàtàkì àwọn tí ebi npa, tí òhùngbẹ ngbẹ, àwọn wọnnì tí a dánìkan fisílẹ̀—ni bí a ṣe nhùwasí I.
Nínú Ìjọ ìmúpadàbọ̀sípò rẹ̀, gbogbo wa dára síi nígbàtí kò sí ẹni tí ó ndánìkan joko. Ẹ máṣe jẹ́ kí a kàn gbàmọ́ra tàbi faradà. Ẹ jẹ́ kí a fi tinùtinú kíni káàbọ̀, dámọ̀, ṣe iṣẹ́ ìrànṣẹ́ sí, fẹ́ràn. Njẹ́ kí ọ̀rẹ́, arábìnrin, arákùnrin kọ̀ọ̀kan máṣe jẹ́ ẹni òkèèrè tàbí àjèjì ṣùgbọ́n ọmọ kan ní ilé.
Ní òní, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nní ìmọlára ìdánìkanwà àti ìpatì. Ìròhìn ìbákẹgbẹ́ àti òye àfọwọ́dá lè fi wa sílẹ̀ ní ìpòngbẹ fún sísúnmọ́ ènìyàn àti ìfọwọ́kan ènìyàn. A fẹ́ láti gbọ́ àwọn ohùn ara wa. A fẹ́ wíwà-pẹ̀lú àti inúrere òtítọ́.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èrèdí ni ó wà tí a lè fi ní ìmọ̀lára pé a kò wà ní ìbámu ní ìjọ—pé, ní sísọ̀rọ̀ pẹ̀lú àfiwé, à ndánìkan joko. A lè ní ìdàmú nípa ohùn wa, aṣọ, ipò ẹbí. Bóyá a ní ìmọ̀lára àìkúnjú-ìwọ̀n; òórún èéfín; ìlọ́ra fún ìwà ìmọ́tótó; ti bá ẹnìkan jà tí a sì ní ìmọ̀lára ìpalára àti ìdójútì; ní àníyàn nípa èyí tàbí ìṣètò Ìjọ náà. A lè jẹ́ àdánìkanwà, kíkọ̀sílẹ̀, opó. Àwọn ọmọ wa jẹ́ aláruwo; a kò ní àwọn ọmọ. A kò sìn ní míṣọ̀n tàbí a wá sílé ṣíwájú. Títòsílẹ̀ náà nlọ bẹ́ẹ̀.
Mòsíàh 18:21 pè wá láti so ọkàn wa papọ̀ nínú ìfẹ́. Mo pè wá láti dínkù nínú ìdàmú, dínkù ní ìdájọ́, jẹ́ dídínkù ní ìbèèrè láti ọwọ́ àwọn ẹlòmíràn—àti, nígbàtí a bá nílò, láti dínkù ní líle lórí arawa. A kìí dá Síónì sílẹ̀ ní ọjọ́ kan. Ṣùgbọ́n ọ̀kọ̀ọ̀kan “báwo ni,” ọ̀kọ̀ọ̀kan ìṣesí ìyárí, nmú Síónì súnmọ́ síi. Ẹ jẹ́ kí a gbẹ́kẹ̀lé Olúwa síi kí a sì yàn láti gbọ́ran sí gbogbo òfin Rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀.
lll.
Níti ẹ̀kọ́, nínú agbo-ilé ìgbàgbọ́ àti ìjọ́sìn àwọn Ènìyàn Mímọ́, kò sí ẹnití ó ndánìkan Joko nítorí májẹ̀mú wíwà-pẹ̀lú nínú Jésù Krístì.
Ni Wòlíì Joseph kọ́ni: “Ó kù fún wa láti rí, kópa nínú kí a sì ṣèrànwọ́ láti yí síwájú ògo Ọjọ́-ìkẹhìn, ‘ìgbà ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iṣẹ́ ìríjú ti àwọn àkokò … ,’ nígbàtí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọlọ́run yíò kórajọ ní ọ̀kan láti gbogbo orílẹ̀-èdè, àti ìbátan, àti ènìyàn.”
Ọlọ́run “kò ní ṣe ohunkóhun bíkòṣe fún èrè aráyé; … kí ó lè fa gbogbo arákùnrin [àti arábìnrin] súnmọ́ ọ. …
“… Ó pè gbogbo wọn láti wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ kí wọ́n sì pín nínú oore rẹ̀; … gbogbo ènìyàn sì jẹ́ bákannáà sí Ọlọ́run.”
Ìyípadà nínú Jésù Krístì bèèrè fún wa láti mú ẹ̀nìyàn ẹlẹ́ran ara súrò àti àṣà ti ayé. Bí Ààrẹ Dallin H. Oaks ṣe kọ́ni, a níláti fi eyikeyi ìṣe àṣà àti ọ̀làjú tí ó wà ní ìlòdì sí àwọn òfin Ọlọ́run sílẹ̀ kí a sì di àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ikẹhìn. Ó ṣe àlàyé, “Ọ̀làjú àíláfiwé ìhìnrere wà, àwọn iyì àti ìgbèrò àti ìṣe tí ó wọ́pọ̀ sí gbogbo [àwọn] ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.” Ọ̀làjú ìhìnrere pẹ̀lú ìparaẹnimọ́, lílọ sí ìjọ̀ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, síséra kúrò nínú ọtí-líle, tábà, tíì, àti kọfí. Ó pẹ̀lú ìwà òtítọ́ àti òtítọ́ inú; níní òye pé à nlọ síwájú, kìí ṣe sókè tàbí sílẹ̀ nínú àwọn ipò Ìjọ.
Mo nkẹkọ látinú ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ ìjọ̀ àti ọ̀rẹ́ ní gbogbo ilẹ̀ àti ọ̀làjú. Àwọn ìwé mímọ́ tí à nṣe àṣàrò ní oríṣiríṣi àwọn èdè àti ìrísí ọ̀làjú nmú òyè ìhìnrere wa jinlẹ̀. Àwọn ìfihàn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti ìhùwà bíiti Krístì mú ìfẹ́ mi àti òyè Olùgbàlà mi jinlẹ̀. Gbogbo ènìyàn di alábùkúnfún nígbàtí a bá túmọ̀ ọ̀làjú ìdánimọ̀ wa, bí Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni, bí ọmọ Ọlọ́run, ọmọ májẹ̀mú, ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì.
Àláfíà ti Jésù Krístì wà fún wa níti araẹni. Láìpẹ́, ọ̀dọ́mọkùnrin kan bèèrè pẹ̀lú ìtàra, “Alàgbà Gong, ṣe mo ṣì lè lọ̀ sí ọ̀run?” Ó ròó bóyá òun lè ní ìdáríjì láé. Mo bèèrè orúkọ rẹ̀, fetísílẹ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, pè é láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú bíṣọ́ọ̀pù rẹ̀, fún un ní ìdìmọ́ra nlá. Ó kúrò pẹ̀lú ìrètí nínú Jésù Krístì.
Mo dárúkọ ọ̀dọ́mọkùnrin náà nínú àgbékàlẹ̀ míràn. Lẹ́hìnnáà mo gba lẹ́tà àìyàn kan tí ó bẹ̀rẹ̀ pé, “Alàgbà Gong, aya mi àti èmi ti tọ́ àwọn ọmọ mẹsan … méjì sì ti sìn ní míṣọ̀n.” Ṣùgbọ́n “mo máà nní ìmọ̀lára pé a kò ní fi ààyè gbà mí nínú ìjọba Sẹ̀lẹ́stíà … nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi bí ọ̀dọ́ burú gan!”
Lẹ́tà náà tẹ̀síwájú, “Alàgbà Gong, nígbàtí o sọ̀rọ̀ nípa ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó njèrè ìrètí fún ìdáríjì, mo kún fún ayọ̀, ní bíbẹ̀rẹ̀ láti dàmọ̀ pé bóyá èmi [lè jẹ́ dídáríjì].” Lẹ́tà náà parí pé, “Èmi tilẹ̀ fẹ́ràn arami nísisìyí!”
Májẹ̀mú wíwà-pẹ̀lú njìnlẹ̀ bí a ṣe nwá sọ́dọ̀ arawa àti sí ọ̀dọ̀ Olúwa nínú ilé ìgbàlejò Rẹ̀. Olúwa nbùkún gbogbo wa nígbàtí kò sí ẹnìkankan tí ó ndá Joko. Tani ó mọ̀? Ẹni náà tí a joko tì lè di ọ̀rẹ́ wa dídárajùlọ ti àkàrà òyìnbó ọrọ̀. Njẹ́ kí a fi ìrẹ̀lẹ̀ wá kí a sì wá ààyè fún Un àti arawa níbi oúnjẹ alẹ́ Ọ̀dọ́-àgùtàn, ni mo fi pẹ̀lú ìtàra gbàdúrà ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.