Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Yí Ọkàn Rẹ sí Jésù Krístì: Ẹ̀bùn Mímọ́ ti Orin Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwàá 2025


10:36

Yí Ọkàn Rẹ sí Jésù Krístì: Ẹ̀bùn Mímọ́ ti Orin Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀

Àwọn orin Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ jẹ́ ìwàásù fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Jésù Krístì, àwọn ẹ̀rí sí jíjẹ́ òtítọ́ ti ìhìnrere tí a mú padàbọ̀ sípò, àti àwọn àdúrà ṣíṣe sí orin.

Ọ̀kan lára àwọn ìbùkún iṣẹ́ ìsìn mi ní Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ni pé ọkàn mi ti kọ́ ẹ̀kọ́ láti fẹ̀ràn ní àwọn èdè tí ahọ́n mi kò fi sọ̀rọ̀. Mo ti rí ayọ̀ nínú sísopọ̀ pẹ̀lú àwọn Ènìyàn Mímọ́ ẹlẹgbẹ́ nípasẹ̀ èdè orin mímọ́ tí a pín. Àti nípàtàkì nípasẹ̀ àwọn orin rírọrùn ti àwọn Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ ti tayọ àwọn ìdènà èdè ó sì kún ọkàn mi pẹ̀lú ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ Rẹ̀. Nínú ohùn àwọn ọmọdé, ìfẹ́ Ọlọ́run àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, ti jẹ́ kíkéde nínú òtítọ́ kedere àti gígúnni.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi ko dàgbà sókè nínú Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, Ẹ̀mí ti yára kọ́ mi ní jíjẹ́ mímọ́ àwọn orin rẹ̀, wọ́n sì ti di apákan ìjọ́sìn ti araẹni mi. Àwọn orin Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti gbé ipá mímọ́ nínú ayé mi ó sì ti gbé ọkàn mi sókè, ó ti kọ́ mi ni àwọn òtítọ́ ayérayé, àti pé ó ti fà mí súnmọ́ Olùgbàlà àti sí ìhìnrere Rẹ̀ síi.

Ààrẹ Dallin H. Oaks ti kọ́ni nígbàkanrí pé:“Kíkọ àwọn orin jẹ́ ọ̀kan lára​àwọn ọ̀nà tó dárajùlọ láti kọ́ ẹ̀kọ́ ìhìnrere tí a mú padàbọ̀ sípò.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí jẹ́ òtítọ́ fún gbogbo wa ṣùgbọ́n ó rí bẹ́ẹ̀ nípàtàkì fún àwọn ọmọdé. Orin Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun èlò ẹlẹgẹ́ ti Ọlọ́run fún gbígbin àwọn irúgbìn ẹ̀rí sínú ọkàn àwọn ọ̀dọ́ ọmọ-ẹ̀hìn Olùgbàlà. Àwọn òbí, olùdarí, àti olùkọ́ nfi ìtọ́jú fún irúgbìn náà bí wọ́n ti njẹ́rìí sí tí wọ́n sì npe àwọn ẹ̀rí ti àwọn ọmọdé nípa gbogbo ohun tí wọ́n ti nmọ̀ nípa Baba Ọ̀run; Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì; àti Ẹmí Mímọ́.

Nínú àwọn ọ̀pọ̀ ọdún ìkẹhìn wọ̀nyí ti iṣẹ́ ìsìn mi, mo ti lo àkókò ní kíkọrin àti kíkọ́ ẹ̀kọ́ láti inú orin àwọn Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ bí mo ṣe nrò nípa ìbéèrè díẹ̀.

  • Báwo ni àwọn orin Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ tí a kọ́ nígbà èwe ṣe di èdè ti ẹ̀mí tí àwọn ọmọdé nlò láti jẹ́rìí fún ìyókù ìgbésí ayé wọn?

  • Báwo ni kíkọ orin àwọn òtítọ́ ìhìnrere ṣe nran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti rántí Olúwa bíi apákan májẹ̀mú wọn kí ó sì múra wọn sílẹ̀ fún àwọn ìlànà?

  • Àti pé báwo ni àwọn orin Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe le rannilọ́wọ́ láti kọ òfin Ọlọ́run sí ọkàn àwọn ọmọ-ẹ̀hìn tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ jùlọ wọ̀nyí?

Nígbàtí Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ní 1878, ààrẹ rẹ̀ àkọ́kọ́, Aurelia Spencer Rogers, kíyèsí pé “orin kíkọ jẹ́ dandan.” Orin ti nfi ìgbà gbogbo wà ní oókan àyà kíkọ́ àwọn ọmọdé ní ìhìnrere. Àwọn orin Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ le di àkọ́kọ́ èdè ti ẹ̀mí fún ọmọ kan nítorípé ìró aládùn wọn tó rọrùn, to ṣeé rántí nfi ohùn fún àwọn òtítọ́ ìhìnrere. Àwọn orin wọ̀nyí ní agbára láti dúró pẹ̀lú àwọn ọmọdé fún ọjọ́ ayé, ní dídi apákan jíjẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn wọn àti ọ̀nà adánidá àti dídára kan fún wọn láti jẹ́rìí nípa Olùgbàlà.

Kíkọ́ni Ní Ẹ̀kọ́ Jésù Krístì Nípasẹ̀ Orin

Àwọn orin Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ bákannáà le jẹ́ àwọn ohun èlò alágbára ti ìkọ́ni ní ẹ̀kọ́. Àwọn orin míràn sọ àwọn ìtàn nípa ìgbé ayé àti iṣẹ́ ìrànṣẹ́ ti Olùgbàlà. Àwọn míràn kọ́ni nípa àwọn ìhùwàsí Rẹ̀, bí irú ìgbàgbọ́ Rẹ̀, ìrètí Rẹ, àti ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ Rẹ̀. Àwọn orin tí wọ́n sì jẹ́ mímọ́ jùlọ jẹ́rìí nípa Ètùtù àìlópin Rẹ̀ àti ìfẹ́ tó nṣàn láti ibi ìṣe ìgbàlà náà.

Wòlíì Olúwa kan, Ààrẹ Russell M. Nelson, ti kọ́ni pé: “[Orin] le ṣe àmúlò ipá títẹ̀síwájú kan fún rere pẹ́ títí tayọ àwọn àkókò ìgbàtí àwọn ọmọdé ṣì kéré. … [Ó] ní agbára [náà] láti pèsè ìtọ́jú ti ẹ̀mí. Ó ní agbára ìwòsàn. Ó ní agbára [náà] láti mú kí ìjọ́sìn ṣeéṣe; ó nfi ààyè gbà wá láti ronú Ètùtù [ti Olùgbàlà] àti Ìmúpadà sípò ti ìhìnrere pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ rẹ̀ tí ngbanilà àti àwọn ìlànà tí ngbéniga. Orin npèsè agbára fún wa láti sọ àwọn èrò inú kíkún fún àdúrà kí a sì sọ ẹ̀rí nípa àwọn òtítọ́ mímọ́.”

Bíi òbí, olùdarí, àti olùkọ́, aápọn wa ní ríran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ nínú láti rí ààyè sí àwọn ìbùkún tí a ṣèlérí wọ́nyí nípa kíkọ́ni, pẹ̀lú èrò inú, ní àwọn òtítọ́ ìhìnrere tí a nrí nínú orin Ààrẹ Nelson bákannáà kọ́ni pé “àwọn ọmọdé lè kọ́ ẹ̀kọ́ náà nígbàtí wọ́n bá nkọ́ láti kọrin ní púpọ̀ gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe lè kọ́ nípa ẹ̀kọ́ náà nínú kíláàsì kan.” Àwọn orin wọ̀nyí lè pèsè ibi ipamọ́ kan ti àwọn ìwàásù kíkún fún ìgbàgbọ́ tí ó ntọ́ka àwọn ọmọdé sí Olùgbàlà tí ó sì nràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe ìmúdàgbà ìfọkànsìn sí ìhìnrere Rẹ̀.

Àwọn ìwé mímọ́ kọ́ni pé àwọn orin olódodo ti ó bá wá láti ọkàn jẹ́ inú dídùn sí Olùgbàlà. Mo kàn le níyanu sí inú dídùn tí ohùn àwọn ọ̀dọ́ jùlọ ọmọ-ẹ̀hìn Olùgbàlà nmú wá. Mo mọ̀ pé àwọn orin wọn tó kún fún àdúrà ndé ọ̀run bíi àwọn ọ̀rọ̀ sísọ ìgbàgbọ́ tí ó npe Ẹ̀mí Mímọ́ láti fi ẹsẹ̀ òtítọ́ ayérayé múlẹ̀ kí ó sì fi jẹ́ẹ́jẹ́ àti ẹlẹgẹ́ pe àwọn ẹlòmíràn láti gba ìpè Olùgbàlà wa láti tẹ̀lé Òun kí wọ́n sì wá sílé. Bí Ààrẹ Henry B. Eyring ti rán wa létí, ó jẹ́ pé ní àwọn àkókò níní ìmọ̀lára Ẹ̀mí ni a nní ẹ̀rí Ètùtù Olùgbàlà tí nṣiṣẹ́ nínú ayé wa.

Títẹ Òtítọ́ mọ́ Ọkàn

Orin àwọn Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ le jẹ́ iṣẹ́ ìyanu kan tí a gbé ní gbogbo ọjọ́ ayé ní ipa ọ̀nà jíjẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn tí àwọn ọmọ wa yíò rìn. Orin kan tí a kọ́ ní ọjọ́ ori ọdún mẹ́fà ní agbára láti dúró tì wá—ó sì le padà wá ní àwọn dẹ́kéédì lẹ́hìnwá ní àwọn àkókò ìpinnu, ìdánwò, ẹ̀dùn ọkàn, tàbí ayọ̀. Bóyá ní àwọn ọdún wa lẹ́hìnwá, àwọn ọ̀rọ̀ orin ti “Èmi Ó Tẹ̀lé Ètò ti Ọlọ́run” le ṣiṣẹ́ bíi ìdákọ̀ró ti ẹ̀mi tí ó nṣe agbohùn ẹ̀rí ti Páulù Àpóstélì nípa ìdánilójú àwọn ìlérí Ọlọ́run fún wa. Tàbí wọ́n le ránwa létí pé nítorípé Ọlọ́run npa àwọn ìlérí Rẹ̀ mọ́, àwọn májẹ̀mú Rẹ̀ nfúnni ní ìtùnú àti ibi ìsádi kan tó lágbára, wọ́n sì npè wá láti fi ìrètí àti ìdánilójú wa sí ara Jésù Krístì àti sínú agbára ètùtù Rẹ̀ pẹ̀lú ìdúróṣinṣin.

Àwọn àgbàlagbà ọmọ ìjọ káàkiri àgbáyé, nínú àwọn àkókò ìṣòro, máa nsáábà rántí àti yí sí àwọn orin Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ tí wọ́n ti kọ́ bíi ọmọdé. Fún ẹni púpọ̀, àwọn orin wọ̀nyí ṣe àtìlẹ́hìn fún àwòrán ìbẹ̀rẹ̀ ìgbàgbọ́ wọn nínú Jésù Krístì wọ́n sì máa nṣáábà jẹ́ ibi àkọ́kọ́ tí ìyípadà ọkàn sí ìhìnrere Rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀. Àwọn òbí, olùdarí, àti olùkọ́ nṣe ìtọ́jú ìgbàgbọ́ náà nínú àwọn ọdún nípa kíkọ́ni, kíkọrin, àti jíjẹ́rìí sí àwọn ọmọdé pẹ̀lú ìṣọ́ra.

Arábìnrin kan pín pẹ̀lú me pé òun ṣìkẹ́ orin Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, àti pé lẹ́hìn ogún ọdún ó gbé oríyìn fún un pẹ̀lú mímú ìyípadà ọkàn rẹ̀ sí ìhìnrere Jésù Krístì tẹ̀síwájú. Ọmọ ìjọ míràn jẹ́rìí pé Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ gbin irúgbìn mústádì kan ti ìgbàgbọ́ nígbàtí ó wà ní èwe òun sì ni ìdí tí ó fi lè padà wá sí Ìjọ Olúwa ní ọjọ́ orí ọgbọ̀n ọdún rẹ̀. Olùgbàlà ṣe ìlérí pé, “Olùtùnú náà … yíò kọ́ yín ní ohun gbogbo, yíò sì mú ohun gbogbo wá sí ìrántí yín.” Orin Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ lè jẹ́ ọ̀nà kan tí ìlérí fi nwá sí ìmúṣẹ.

Orin Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ míràn ti a fẹ́ràn ṣe àkámọ́ agbára ìgbàgbọ́ rírọrùn àti ẹ̀rí pípẹ́ títí.

Bí mo ti nrìn pẹ̀lu Jésù sí ilé mi lókè,

Òun yíò bùkún mi pẹ̀lu Ẹ̀mí Rẹ̀ yíò sì kún mi pẹ̀lú ìfẹ́ Rẹ̀,

Yí ọkàn mi padà títí láé sí rànmí lọ́wọ́ láti ríran kedere.

Èmi ó rìn pẹ̀lú Jésù, Òun ó sì rìn pẹ̀lú mi.

Bí àwọn ọmọdé ti nkọrin, wọ́n nṣe àfihàn ìfẹ́ inú ọmọ-ẹ̀hìn wọ́n sì nkọ́ àpẹrẹ ìgbé ayé májẹ̀mú. Ẹ̀mí lè lo orin láti fín àwọn òtítọ́ ayérayé sí ọkàn ẹlẹgẹ́ wọn. Àti pé ní àkókò, àwọn ọmọdé le yàn láti gbé àti láti yí ọkàn wọn àti ìgbé ayé wọn sí ọ̀dọ̀ Jésù Krístì nípa dídá àti ṣíṣe ìpamọ́ àwọn májẹ̀mú mímọ́ pẹ̀lú Rẹ̀.

Rírántí àwọn Májẹ̀mú Wa àti Mímúrasílẹ̀ fún àwọn Ìlànà

Orin mímọ́ le ṣèrànwọ́ láti kọ ẹ̀kọ́ Krístì sínú ọkàn kí ó sì múra wa sílẹ̀ láti gba àwọn ìlànà Rẹ̀. Ó ndarí ẹ̀kọ́ Olùgbàlà sí ìrántí wa àti ìrántí náà sí jíjẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn wa nínú Rẹ̀.

Bíi olùdarí Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, a ní ànfààní àti ojúṣe mímọ́ láti ríi dájú pé orin ní Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ njẹ́ kíkọ́ni pẹ̀lú ayọ̀, pẹ̀lú òye ti ẹ̀kọ́, àti pẹ̀lú Ẹ̀mí. Nínú èyí ni pípe àwọn ọmọ láti fura sí irú ìmọ̀lára tí wọ́n ní bí wọ́n ṣe nkọ orin náà, àti ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti dáa mọ̀ pé àwọn ìmọ̀lára wọ̀nyí nwá láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. Àwọn akitiyan wọ̀nyí nṣèrànwọ́ láti múra àwọn ọmọ wa sílẹ̀ fún àwọn ìlànà mímọ́, bí irú ìrìbọmi àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀, bákannáà bíi mímísí ìrántí májẹ̀mú wọn bí wọ́n ti nsọ àwọn ìlérí wọn sí Ọlọ́run dọ̀tun.

Ní ibi Oúnjẹ Alẹ́ Ìkẹhìn, lẹ́hìn ti Olùgbàlà ṣe àgbékalẹ̀ oúnjẹ Olúwa, Máttéù kọ àkọsílẹ̀ pé “nígbàtí wọ́n ti kọ orin kan, wọ́n jáde lọ sí orí òkè Ólífì.” Ní ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan, àwọn ọmọ ìjọ tí a ti rìbọmi tí a sì ti fi ẹsẹ̀ wọn múlẹ̀ sí Ìjọ Olúwa tí a múpadà sípò, pẹ̀lú àwọn ọmọdé tí a ti ríbọmi bí ẹni ọdún mẹ́jọ, nmúra láti gba oúnjẹ Olúwa. Nípasẹ̀ kíkọ orin mímọ́, àwọn ìpéjọpọ̀ àwọn ọmọ Ọlọ́run njẹ́ fífún ní ànfààní láti pèsè ọkàn wọn fún ìlànà mímọ́ náà láti gba orúkọ Rẹ̀ sí orí ara wọn, láti máa fi ìgbà gbogbo rántí Rẹ, àti láti máa pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́.

Ìjẹ́rìí Ìparí

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n, mo jẹ́rìí pe àwọn orin Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ nkọ́ni ní àwọn òtítọ́ àti ẹ̀kọ́ ayérayé tí ó ndarí wa sí Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀. Mo pè yín láti gbèrò kínni àwọn òtítọ́ ìpìlẹ̀ tí ó ti jẹ́ kíkọ sínú ọkàn yín, nípasẹ̀ àwọn ìkọ́ni ìrọ̀rùn ti àwọn orin wọ̀nyí, àti láti jẹ́rìí nípa àwọn òtítọ́ náà sí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Olùgbàlà tó jẹ́ ọ̀dọ́ jùlọ, bí ẹ ti nkọ́ wọn ní àwọn ìròhìn dáradára ti ìhìnrere nípasẹ̀ orin.

Mo mọ̀ pé Ọlọ́run Baba wa, nínú ìfẹ́ àìlópin Rẹ̀, rán Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀ sí ilẹ̀ ayé láti kọ́ wa, láti fi ọ̀nà hàn wá, àti láti rà wá padà nípasẹ̀ Ètùtù Rẹ̀.

Mo mọ̀ pé ìgbé ayé àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ Olùgbàlà jẹ́ òtítọ́ àti ti ara ẹni. Àwọn ìwé mímọ́ kún fún àwọn ìtàn nípa ìwòsàn Rẹ̀, àánú Rẹ̀, àti àwọn iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀.

Mo mọ̀ pé Baba Ọ̀run ngbọ́ Ó sì ndáhùn áwọn àdúrà tòótọ́ àwọn ọmọ Rẹ̀, bí ó ti wù kí ọjọ́ orí wọn, ipò wọn, tàbí èdè wọn jẹ́. Ó nfi etí sí àwọn ẹ̀bẹ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ ti inú ọkàn wa.

Mo jẹ́rìí pé ní Gétsémánè, Jésù Krístì gbé ìwúwo àwọn ẹ̀ṣẹ̀, àwọn ìbànújẹ́, àti àwọn ìrora wa. Ó jìyà pẹ̀lú ìfẹ́-inú nítorí ìfẹ́ Rẹ̀ fún wa Ó sì mú kí ó ṣeéṣe fún wa láti jẹ́ dídáríjì àti láti padà sílé.

Mo mọ̀ pé a jẹ́ ọmọ Ọlọ́run gan an, tí a dá ní àwòrán Rẹ̀, tí a fún ní ẹ̀bùn pẹ̀lú ìleṣe àtọ̀runwá, àti tí a pè láti padà láti gbé pẹ̀lú Rẹ̀ bí a bá yàn láti tẹ̀lé Jésù Krístì.

Mo mọ̀ pé Jésù Krístì ni àpẹrẹ pípé wa, àti pé bí a ti ntẹ̀lé E nípa sísìn, dídáríjì, àti fífẹ́ràn àwọn ẹlòmíràn, a ó dàbíi Rẹ̀ síi ní ọjọ́ dé ọjọ́.

Mo sì mọ̀ pé àwọn tẹ́mpìlì Olúwa jẹ́ ilé Rẹ̀ ní ìhín lórí ilẹ̀ ayé. Nínu wọn, a ndá àwọn májẹ̀mú mímọ́, a ngba àwọn ìbùkún ayérayé, a sì nkọ́ ẹ̀kọ́ síi nípa Rẹ̀ àti ní ìmọ̀lára síi nípa wíwà níbẹ̀ Rẹ̀. Tẹ́mpìlì jẹ́ ibi ìkẹ́kọ̀ọ́, ibi àlàáfíà, àti ibi ìmúrasílẹ̀ fún ìgbé ayé wa.

Mo jẹ́rìí pé àwọn akitiyan tí a nṣe láti kọ́ni àti láti kọ àwọn orin Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ wọ̀nyí sí àwọn ọmọdé wa kìí ṣe ipa dídára lásán ti àṣà ẹ̀sìn wa. Wọ́n jẹ́ ìwàásù fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Jésù Krístì, àwọn ẹ̀rí sí jíjẹ́ òtítọ́ ti ìhìnrere tí a mú padàbọ̀ sípò, àti àwọn àdúrà ṣíṣe bíi orin. Orin mímọ́ le tan Ìmọ́lẹ̀ Krístì sí orí olùgbọ́ ó sì le tú u sínú ọkàn akọrin. Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n, Jésù ṣì nfẹ́ wa fún ìtànṣán oòrùn kan síbẹ̀. Mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ mímọ́ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Dallin H. Oaks, “Ìjọ́sìn nípasẹ̀ Orin,” Ensign, Oṣù Kọkànlá 1994, 10.

  2. ““Orin awọn olódodo jẹ́ àdúrà sí mi” ” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 25:12).

  3. “Àwọn orin mímọ́ jẹ́ apákan pàtàkì ti ìpàdé oúnjẹ Olúwa àti àwọn ìpàdé Ìjọ míràn. … Àwọn ọmọ ìjọ nkórajọpọ̀ nínú ìpàdé oúnjẹ Olúwa láti rántí Jésù Krístì nípa níní ìpín nínú oúnjẹ Olúwa. Wọ́n kórajọ láti mú ìgbàgbọ́ àti ẹ̀rí dàgbà àti láti jọ́sìn Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì. Orin níláti jẹ́ yíyàn láti ṣèrànwọ́ ní àṣeyọrí àwọn èrèdí wọ̀nyí. … Orin isìn oúnjẹ Olúwa níláti tọ́kasí oúnjẹ Olúwa fúnrarẹ̀ tàbí sí ìrúbọ Olùgbàlà” (Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò: Sísìn nínú Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn, 19.3, 19.3.2, Ibi ìkàwé Ìhìnrere).

  4. “Èmi yíò fi òfin mi si àwọn abala inú wọn, èmi ó sì kọ ọ́ sínu ọkàn wọn” (Jeremíàh 31:33).

  5. Aurelia Spencer Rogers, nínú “Ìtàn kan nípa Ìgbékalẹ̀ Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀,” history.ChurchofJesusChrist.org.

  6. Russell M. Nelson, “Agbára àti Ààbò Tí A Pèsè nípasẹ̀ Orin Yíyẹ” (Ìsìn àkanṣe ní Yunifásítì Brigham Young, 4 Oṣù Karun, 2008), 4, 5, speeches.byu.edu.

  7. Russell M. Nelson, nínú “Ẹ Tẹ̀síwájú Ní Kíkọ áwọn Orin Tó Kọ́ni Ní Ẹ̀kọ́, Ni Ààrẹ Nelson wí” (fídíò), ChurchofJesusChrist.org.

  8. “A lérò pé àwọn olùdarí, àwọn olùkọ́, àti àwọn ọmọ ìjọ tí a pè láti sọ̀rọ̀ yíò yí nígbàkugbà sí ìwé orin láti wá àwọn ìwàásù tí a gbékalẹ̀ pẹ̀lú agbára àti pẹ̀lu ẹwà nínu ẹsẹ. …

    “Orin ní àwọn agbára tí kò ní ààlà fún sísún àwọn ẹbí sí ọ̀nà jíjẹ́ ti ẹ̀mí àti ìfọkànsìn títóbijù sí ìhìnrere náà. Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ikẹhìn níláti kún ilé wọn pẹ̀lú ìró orin yíyẹ. …

    “Ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín láti fẹ́ràn àwọn orin isìn. Ẹ kọ wọ́n ni ọjọ́ Ìsinmi, nínú ilé nírọ̀lẹ́, ní ìgbà àṣàrò ìwé mímọ́, àti ní àkókò àdúrà. Ẹ máa kọrin bí ẹ ti nṣiṣẹ́, bí ẹ ti nṣeré, àti bí ẹ ti nrin ìrìnàjò papọ̀. Ẹ máa kọ àwọn orin isìn bíi arẹmọ láti mú ìgbàgbọ́ àti ẹ̀rí dàgbà nínú àwọn ọmọdé yín” (“Ọ̀rọ̀ Ìṣaájú Àjọ Ààrẹ Kínní,” Àwọn Orin isìn, ix, x).

  9. Wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 25:12.

  10. “Bí ẹ bá ti ní ìmọ̀lára agbara Ẹ̀mí Mímọ́ … , ẹ lè gbà á bí ẹ̀rí pé Ètùtù náà nṣiṣẹ́ nínú ayé yín” (Henry B. Eyring, “Àwọn Ẹ̀bùn ti Ẹ̀mi fún àwọn Akókò Líle” [Ìsìn àkanṣe Yunifásítì Brigham Young, 10 Oṣù Kẹsan, 2006], 5, speeches.byu.edu).

  11. Wo Hébérù 6:17–19.

  12. Wo Mórónì 7:41.

  13. Jòhánnù 14:26.

  14. “Èmi Yíò Rìn pẹ̀lú Jésù,” Àwọn Orin Ìsìn—Fún Ilé àti Ìjọ, Ibi Ìkàwé Ìhìnrere.

  15. Máttéù 26:30.

  16. “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlànà oúnjẹ Olúwa wà fún àwọn ọmọ Ìjọ, a kò gbọdọ̀ ṣe ohunkóhun láti dènà àwọn ẹlòmíràn ní kíkópa nínú rẹ̀”.(Iwé Ìléwọ́ Gbogbogbò, 18.9.3). Ní pàtó, ó jẹ́ tó tọ́ fún àwọn ọmọdé láti kópa nínú oúnjẹ Olúwa ṣaájú kí wọn ó tó dé ọjọ́ orí ṣíṣe ìjíhìn kí wọn ó le ní ìmoore púpọ̀ síi fún ẹbọ ọrẹ Jésù Krístì kí wọn ó sì múra láti wọnú àwọn májẹ̀mú mímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ní ọjọ́ iwájú.

  17. Wo “Ó Rán Ọmọ Rẹ̀,” Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 34–35.

  18. wo “Sọ àwọn Ìtàn Jésù Fún Mi,” Children’s Songbook, 57.

  19. Wo “Àdúrà Ọmọdé,” Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 12–13.

  20. Wo “Gẹ́tsémánè,” Àwọn Orin Ìsìn—Fún Ilé àti Ìjọ.

  21. Wo “Ọmọ Ọlọ́run Ni Mí,” Ìwé Orin àwọn Ọmọdé, 2–3.

  22. Wo “Èmi Ntiraka láti Dàbíi Jésù,” Ìwé-Orin àwọn Ọmọdé, 78–79.

  23. Wo “Mo Fẹ́ràn láti Rí Tẹ́mpìlì,” Ìwé-Orin àwọn Ọmọdé, 95.

  24. Wo “Jésù Fẹ Mí fún Ìtànṣán òòrùn,” Ìwé-Orin àwọn Ọmọde, 60.