Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àwọn Ojú Ẹ̀rín àti Àwọn Ọkàn Ìmoore
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwàá 2025


10:52

Àwọn Ojú Ẹ̀rín àti Àwọn Ọkàn Ìmoore

Àní títóbi àwọn Ènìyàn Mímọ́ wa ní Áfríkà ndi híhàn gbangba bí wọ́n ṣe ndojúkọ àwọn ìpèníjà ìgbésí-ayé àti ìbèèrè ti Ìjọ tó ndàgbà.

Ní nkan bí ọdún kan sẹ́hìn, wọ́n dá mi sílẹ̀ láti ibi iṣẹ́ yíyànfúnni mi nínú Àjọ Ààrẹ Àádọ́rin, ìyípadà kan tí a kéde níbí ní ìpàdé gbogbogbò. Nítorípé orúkọ mi jẹ́ kíkà nítòsí ti Àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò ti wọ́n di afẹ̀hìntìṣiṣẹ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ rò pé èmi náà nparí àkókò iṣẹ́-ìsìn mi. Lẹ́hìn ìpàdé gbogbogbò náà, Mo gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìfiránṣẹ́ ti ìdúpẹ́ àti àwọn ìfẹ́ tí ó dára fún ipele àtẹ̀lé mi ní ìgbésí ayé. Díẹ̀ nínú wọn paapa pèsè láti ra ilé mi ní Àriwá Salt Lake. Ó jẹ́ ohun tí ó dára láti ri pé wọn yóò pàdánù mi àti láti mọ̀ pé a kì yóò ní wàhálà láti ta ilé wa nígbàtí mo bá parí. Ṣùgbọ́n Èmi kò tíì sí níbẹ̀ síbẹ̀.

Iṣẹ́ yíyànfúnni titun mi mú èmi àti Monica lọ sí Áfríkà rírẹwà, níbi tí Ìjọ ti ngbilẹ̀. Ó ti jẹ́ ìbùkún láti sìn ní àárín àwọn ènìyan Mímọ́ olóòtọ́ ní Agbègbè ìhà Gúsù Áfríkà àti láti jẹ́ri ìfẹ́ Olúwa fún wọn. Ó jẹ́ ìwúnilorí láti rí àwọn ẹbí ìrandíran ti gbogbo ìpilẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Ìjọ tí ó ṣàṣeyọrí àti tí ó ní ẹ̀kọ́-dáradára, tí nya àkókò àti àwọn tálẹ̀ntì wọn sọ́tọ̀ láti sin àwọn miran.

Ní àkókò kannáà, ní fífúnni nípa àwọn ìṣẹ̀ǹbáyé ẹkùn náà, ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ọ̀nà ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ndarapọ̀ mọ́ Ìjọ tí wọ́n sì nyí ìgbésí ayé wọn padà nípasẹ̀ àwọn ìbùkún ti ìṣòtítọ́ ìdámẹ́wàá àti àwọn ànfàní ẹ̀kọ́ tí Ìjọ funni. Àwọn ètò bi Succeed in School, EnglishConnect, BYU–Pathway Worldwide, ati Perpetual Education Fund bùkún àwọn ìgbésí ayé ọ̀pọ̀lọpọ̀, pàápàá àwọn ìran tí nbọ̀wá.

Ààrẹ James E. Faust nígbàkanrí sọ pé, “A ti sọ pé ìjọ yi kò fi dandan fa àwọn ènìyàn nlá mọ́ra ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà ló máa nmú kí àwọn èèyàn lásán di nlá.”

Àní títóbi àwọn Ènìyàn Mímọ́ wa ní Áfríkà ndi híhàn gbangba bí wọ́n ṣe ndojúkọ àwọn ìpèníjà ìgbésí-ayé àti ìbèèrè ti Ìjọ tí ó ndàgbà. Wọn nfi ìgbàgbogbo súnmọ ọn pẹ̀lu ìwa rere. Wọ́n fi ẹ̀kọ́ tí a mọ̀ dáradára mọ́ra láti ọ̀dọ̀ Ààrẹ Russell M. Nelson:

“Ayọ̀ tí à nní ìmọ̀ rẹ̀ ní díẹ̀ íṣe pẹ̀lú àwọn ipò ti ìgbésí ayé wa àti ní ohungbogbo íṣe pẹ̀lú ìdojúkọ àwọn ìgbésí ayé wa.

“Nígbàtí ìkojúsí ti ìgbésí ayé wa bá wà ní orí ètò ìgbàlà ti Ọlọ́run … àti Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ, a lè ní ìmọ̀lára ayọ̀ láìka ohun tí ó nṣẹlẹ̀—tàbí tí kò ṣẹlẹ̀—nínú ìgbésí ayé wa sí.”

Wọ́n rí ayọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìdojúkọ wọn. Wọ́n ti kẹ́kọ pé àjọṣe wa pẹ̀lú Olùgbàlà njẹ́ kí a lè súnmọ́ àwọn ìṣòro pẹ̀lú ojú ẹ̀rín àti ọkàn ìmoore.

Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Áfríkà

Jẹ́ kí npín díẹ̀ nínú àwọn ìrírí mi pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ́ olóotọ́ wọ̀nyí tí wọ́n ṣe àpèjúwe ìlànà yi, bíbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Mozambique.

Mozambique

Ní oṣù mélòó kan sẹ́hìn, mo ṣe olùdarí lòrí ìpàde àpapọ̀ ti èèkàn fún èèkàn ọlọ́dún-kan tí ó ti ní ẹ̀ka mẹ́wàá tẹ́lẹ̀. Lílé ní ẹgbẹ̀rún méjì ènìyàn ló kún ilé ìjọsìn kékeré náà pẹ̀lú àwọn àgọ́ mẹ́ta tí a ṣètò sí ìta. Ààrẹ èèkàn jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n (31) lọ́jọ́ orí, ìyàwó rẹ̀ jẹ́ mẹ̀rìndínlọ́gbọ̀n, wọ́n sì ní ọmọ kékeré méjì. Ó ndarí èèkàn tó ndàgbà pẹ̀lú ìpènijà láìsí àròyé—bíkòṣe ojú ẹ̀rín àti ọkàn ìmoore.

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú pátríàkì, mo gbọ́ pé aya rẹ̀ nṣàìsàn gan-an, ó sì tiraka láti pèsè fún ìtọ́jú rẹ̀. Lẹ́hìn sísọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ààrẹ èèkàn, a fún un ní ìbùkún oyè àlùfáà. Mo béèrè lọ́wọ́ pátríàkì náà iye ìbùkún babańlá tí ó ti fúnni ní ìpíndọ́gba.

“Mẹ́jọ sí mẹ̀wa,” ló sọ.

Mo bèèrè, “Ní oṣoòṣù?”

Ó fèsì, “Ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀!” Mo gbà á nímọ̀ràn pé ṣíṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ bẹ́ẹ̀ lópin ọ̀sẹ̀ kò lọ́gbọ́n.

“Alàgbà Godoy,” ni ó sọ, “wọn nwá lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, títí kan àwọn ọmọ ìjọ tuntun àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́.” Lẹ́ẹ̀kansíi, kò sí àròyé—bíkòṣe ojú ẹ̀rín àti ọkàn ìmoore.

Lẹ́hìn abala àṣálẹ́ Sátidè ti ìpàdé àpapọ̀ ti èèkàn, ní ọ̀nà mi sí hòtẹ́lì, mo ṣàkíyèsí àwọn ènìyàn tí nra oúnjẹ ní òpòpónà ní alẹ́. Mo béèrè lọ́wọ́ awakọ̀ mi kínìdí tí wọ́n fi nṣe é nígbàtí òkùnkùn ṣú ju dípò ọ̀sán. Ó dáhùn pé wọ́n nṣiṣẹ́ lójú ọ̀sán láti ní owó láti ṣe é lẹ́hìnwá.

“Áà, wọ́n nṣiṣẹ́ lóni láti jẹun ní ọ̀la,” ni mo sọ.

Ṣùgbọ́n ó bá mi wí pé: “Rárá, wọ́n nṣiṣẹ́ lọ́sàn-án láti jẹun lálẹ́ òní.” Mo ti nírètí pé àwọn ọmọ ìjọ wa lè wà ní ipò tí ó dára jùlọ, ṣùgbọ́n ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ kojú irú àwọn ìpèníjà kannáà ní apákan orílẹ̀-èdè náà. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, lákòókò abala ọjọ́ Ìsimi àti tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ nípa ipò wọn, mo túbọ̀ ní ìwúrí gan-an nípa ojú ẹ̀rín wọn àti ọkàn ìmoore.

Zambia

Ní ojú ọ̀nà sí ìpàdé Ọjọ́ ìsinmi, èmi àti ààrẹ èèkàn náà rí tọkọtaya kan tí wọ́n nrìn lọ́nà pẹ̀lú ọmọdé kan àti àwọn ọmọ kékèké méjì. A dúró láti gbé wọn. Ẹnu yà wọ́n inú wọn sì dùn. Nígbàtí mo béèrè ibi tí wọ́n nílò láti rìn lọ sí ilé ìpàdé náà, bàbá náà fèsì pé ó lè gba ìṣẹ́jú márundínláadọ́ta sí wákàtí kan, ní ìbámu pẹ̀lú ìṣísẹ̀ àwọn ọmọdé. Wọn dojukọ irin-ajo yi ní àlọ àti àbọ̀, ni gbogbo Ọjọ-ìsinmi, laisi àròyé—bìkòṣe ojú ẹ̀rín àti ọkàn ìmoore.

Malawi

Ní Ọjọ́-ìsinmi kan ṣáájú ìpàdé gbogbogbó èèkàn, mo ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka méjì tí wọ́n nlo àwọn ilé ẹ̀kọ́ ìjọba gẹ́gẹ́bí ilé ìjọsìn. Ẹnú yà mí nípa àwọn ipò ìrẹ̀lẹ̀ àti ìwọ̀ntuwọ̀nsì àwọn ilé náà, tí kò tilẹ̀ ní àwọn ohun èlò àmúlò pàtàkì kankan. Bí mo ṣe pàdé àwọn ọmọ ìjọ díẹ̀ níbẹ̀, mo ṣe tán láti tọrọ àforíjì fún àìtó ilé ìpàdé wọn, ṣùgbọ́n inú wọn dùn pé wọ́n ní ibi tó wà nítòsí láti péjọ, ní yíyẹra fún ìrìn àjò gígùn tí wọ́n máa nṣe. Lẹ́ẹ̀kansíi, kó sí àwọn àròyé, bíkòse àwọn ojú ẹ̀rín àti àwọn ọkàn ìmoore.

Zimbabwe

Ní títẹ̀lé Sátidé ti idanilẹkọ àwọn olùdarí, Ààrẹ èèkàn mú mi lọ sí àwọn ìsìn Ọjọ́ ìsinmi tí wọ́n nṣe ní ilé àyálò kan. Àwọn òjìlélúgba ènìyàn ni ó wà ní ìkàlẹ̀. Lẹ́hìnnáà ni bíṣọ́ọ̀pù fi àwọn ọmọ ìjọ titun mẹ́wàá tí wọ́n ṣèrìbọmi ní ọ̀sẹ̀ náà hàn. Ìjọ náà ni a tàn káàkiri àwọn yàrá kékeré méjì, pẹ̀lú àwọn ọmọ ìjọ kan tó tún jóko ní ìta ilé náà, tí nwo ìpàdé nípasẹ̀ àwọn fèrèsé àti àwọn ilẹ̀kùn. Kó sí àwọn àròyé—bíkòṣe ojú ẹ̀rín àti ọkàn ìmoore.

Lesotho

Mo ṣèbẹ̀wò sí orílẹ̀-èdè kékeré rírẹwà yi, tí a tún mọ̀ sí “ìjọba òkè,” láti rí àgbègbè Ìjọ kan tí ó nmúra sílẹ̀ láti di èèkàn. Ní títẹ̀lé Sátidé kan tí ó kún fún àwọn ìpàdé, mo lọ sí ìsìn Ọjọ́-ìsinmi ní ọ̀kan lára ẹ̀ka wọn nínú ilé àyálò kan. Yàrá oúnjẹ Olúwa ti kún àkúnwọ́sílẹ̀, pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n dúró ní ìta ẹnu-ọ̀nà láti kópa. Mo sọ fún ààrẹ ẹ̀ka náà pé ó nílò ilé títóbi síi kan. Sí ìyàlẹ́nu mi, ó sọ fún mi pé èyí jẹ́ ìdajì àwọn ọmọ ìjọ òun. Ìdajì míran yíò lọ sí ìpàdé oúnjẹ Olúwa kejì lẹ́hin wákàtí kejì. Lẹ́ẹ̀kansíi, kó sí àwọn àròyé, bíkòse àwọn ojú ẹ̀rín àti àwọn ọkàn ìmoore.

Mo padà sí Lesotho lẹ́hìnnáà nítorí jàmbá ọkọ̀ apànìyàn kan tí ó kan ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀dọ́ wa, tí Alàgbà by Elder D. Todd Christofferson sọ tẹ́lẹ̀. Nígbàtí mo ṣàbẹ̀wò sí àwọn ẹbí àti àwọn aṣaájú, mo nírètí ojú-ayé tó ní ìtara. Dípò bẹ́ẹ̀, mo pàdé àwọn ènìyàn mímọ́ alágbára àti olùfọkànsìn tí wọ́n nfarada ipò náà ní ọ̀nà gbígbéga àti ìmísí.

Mpho Aniciah Nku

Mpho Aniciah Nku, 14, ẹnití ó yè nínú ìjàmbá ọkọ̀ tí ó wà nínú àwòrán yì, ṣe àkàwé rẹ̀ dáradára nínú àwọn ọ̀rọ̀ tirẹ̀ pé: “Gbẹ́kẹ̀lé Jésù kí o sì kọjú sí I nígbàgbogbo, nítorí nípasẹ̀ Rẹ̀ ni ìwọ yíò rí àláfíà, Òun yíò sì ràn ọ́ lọ́wọ́ nínú ètò ìwòsàn.”

Ìwọ̀nyí jẹ́ àpẹrẹ díẹ̀ níbití a ti rí ìwà rere wọn nítorí pé wọ́n gbé ìgbésí ayé wọn sí oókan ìhìnrere Jésù Krístì. Wọ́n mọ ibi tí wọ́n ti lè wá ìrànlọ́wọ́ àti ìrètí.

Agbára Ìmúláradá Olùgbàlà

Kínìdí tí Olùgbàlà fi lè tù àwọn àti àwa lára nínú èyíkéyi ipò ìgbésí ayé wa? Ìdáhùn si ni a lè rí nínú àwọn ìwé mímọ́:

“Òun yíò sì jáde lọ, ní ìjìyà ìrora àti ìpọ́njú àti àwọn àdànwò onírúurú. …

“… Òun yíò sì gbé gbogbo àìlera wọn lé ara rẹ̀, kí ìnu rẹ̀ lè kún fún àánú, … kí òun kí ó lè mọ̀ … bí ó ṣe lè ran àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́ gẹ́gẹ́bí àìlera wọn.”

Gẹ́gẹ́bí Alàgbà David A. Bednar ti kọ́ni, kò sí ìrora ti ara, ìdààmú, tàbí àìlera tí a ní ìrírí tí Olùgbàlà kò mọ̀. “Ìwọ àti èmi lè kígbe síta ní àkókò àìlera pé, ‘Kò sí ẹnití ó lóye [ohun tí mo nlà kọjá]. …’ Kò sí ẹ̀dá ènìyàn, bóyá, tó mọ̀. Ṣùgbọ́n Ọmọ Ọlọ́run mọ̀ ní pípé ó sì lóye.” Àti kínìdí? Nítorí “Ó nímọ̀lára ó sì ru ẹrù wa ṣáájú kí àwa tó ṣe bẹ́ẹ̀.”

Mo parí pẹ̀lú ẹ̀rí mi nípa àwọn ọ̀rọ̀ Krístì tí ó wà nínu Máttéù 11:

“Ẹ wa sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ó nṣiṣẹ́, tí a sì di ẹrù wúwo lé lórí, èmi yíò sì fi ìsinmi fún yín.

“Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì máa kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi; nítorí onínú tútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni èmí: ẹ̀yin ó sì rí ìsinmi fún ọkàn yín.

“Nítorí àjàgà mi rọrùn, ẹrù mi sì fúyẹ́.”

Gẹ́gẹ́bí àwọn Ènìyàn ní Áfríkà, Mo mọ̀ pé òtítọ́ ni ẹ̀rí yi. Ó jẹ́ òtítọ́ níbẹ̀, àti pé ó jẹ́ òtítọ́ níbi gbogbo. Nípa èyí ni mo jẹ́ ẹ̀rí ni orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. James E. Faust, “Ìṣù Àkàra Marun àti Ẹja Wẹ́wẹ́ Méjì,” Ẹ́nsìgnì, Oṣù Karun 1994, 5.

  2. Russell M. Nelson, “Ayọ̀ àti Ìtúsílẹ̀ Ẹ̀mí,” Lìàhónà, Oṣù Kọkànlá. 2016, 82.

  3. Álmà 7:11–12

  4. David A. Bednar, “Ètùtù àti Ìrìn-àjò Ikú,” Lìàhónà, Oṣù Kẹrin. 2012, 19.

  5. Máttéù 11:28–30