Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Olúwa Nyára Kánkán Ṣiṣẹ́ Rẹ̀
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwàá 2025


14:55

Olúwa Nyára Kánkán Ṣiṣẹ́ Rẹ̀

Bí Olúwa ṣe nyára kánkán ṣiṣẹ́ Rẹ̀, a níláti fẹ́rán, ṣìkẹ́, kí a sí sin àwọn tí wọ́n tẹ́wọ́gba ìhìnrere Rẹ̀.

Charles Dickens pẹ̀lú òkìkí bẹ̀rẹ̀ ìwé àràmọ̀dà rẹ̀ Ìtàn Àwọn Ilú Méjì pẹ̀lú àtẹnumọ́ pé “Ó jẹ́ àwọn àkokò dídárajùlọ; ó jẹ́ àwọn àkokò tó burújùlọ.” Nínú ọgbọ́n kan, èyí jẹ́ òtítọ́ ní ọjọ́ wa.

À ngbé nínú àkokò ewu nígbàtí “gbogbo ilẹ̀ ayé [wà] nínú ìrúkèrúdò.” Ìkìlọ̀ Ààrẹ́ Russell M. Nelson láti jẹ́ àwọn onílàjà, gẹ́gẹ́bí ọmọlẹ́hìn Jésù Krístì, ni a tẹnumọ́ dáradára ní òwúrọ̀ yí láti ẹnu Gary E. Stevenson. Èyí jẹ́ ara pàtàkì ti mímú ìrẹ́pọ̀, àlàáfíà, àti ìwòsàn dìde fún “àwọn àkokò bíburújùlọ.”

Bákannáà à ngbé nínú “àwọn àkokò dídára jùlọ,” èyí yíò jẹ́ àtẹnumọ́ mi. Olúwa, nínú ọ̀rọ̀ ìṣíwájú sí Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú, ìpín 1, kéde pé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere ni a ó “kéde … sí òpin ayé.” Olúwa nyára kánkán ṣíṣẹ́ Rẹ̀ ní àkokò wa nítòótọ́. A ní láti ní ìmoore ìjìnlẹ̀ fún yíyára kankan, éyí tí ó ti ṣẹlẹ̀ tí ó sì nṣẹlẹ̀ pẹ̀lú àwọn àkokò ìpènijà wọ̀nyí. À ngbé ní ọjọ́ kan nígbàtí àwọn ọmọlẹ́hìn Olúwa nní ànfààní láti gbọ́ ohùn kí a sì fèsì pẹ̀lú ọkàn àti iyè-inú ṣíṣísílẹ̀. Àwọn ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, tí wọ́n ní ìfarajì sí Olùgbàlà àti òfin Rẹ̀, nrí èrèdí àti ìjìnlẹ̀ àlááfíà araẹni.

Ní onírúurú àwọn àkokò ní àkọọ́lẹ̀-ìtàn Ìjọ, àlékún pàtàkì ti wà nínú àwọn tí wọ́n ti wọnú ipa-ọ̀nà májẹ̀mú. Irú ọ̀kan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ ní àárín 1837 àti 1850. Àwọn kan lára àwọn Àpóstélì ìṣíwájú nínú Ìjọ ìmúpadàbọ̀sípò Olúwa sin àwọn míṣọ̀n ní United Kingdom. Àwọn míṣọ̀n wọ̀nyí yọrísí ẹgbẹgbẹ̀rún tí ó darapọ̀ mọ́ Ìjọ, àti pé ní 1850 àwọn ọmọ Ìjọ tí wọ́n ngbé ní United Kingdom ju ti United States lọ. Ní àkokò náà, Olúwa darí àwọn Ènìyàn Mímọ́ wọ̀nyí láti korajọ sí Utah. Ìṣípò-kiri púpọ̀ kan ṣẹlẹ̀, àwọn kan tí a tìlẹ́hìn nípa ìyánilówó tí a pèsè nípasẹ̀ Owó Olùṣípò-kiri.

Mo fẹ́ràn àkọsílẹ̀ ti dídé sí Àfonífojì Salt Lake ti àwọn oye títóbi ti àwọn olùyípadà láti England àti Wales ní 1852. Ẹgbẹ́ náà ni a pàdé nípasẹ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní ní ẹnu Ìṣípò-kiri Canyon tí a bárìn nípa Ọ̀gágun Ọ̀gbà Pitt. Àwọn Ìròhìn Deseret ṣe àpèjúwe wọn bí “ọ̀gbà àwọn arìnrìnàjò [tí ó pẹ̀lú] àwọn arábìnrin àti ọmọdé, tí wọ́n rìn, jóná-ara, àti tí ojú-ọjọ́ lù, ṣùgbọ́n kìí ṣe kíkọ̀sílẹ̀; ọkàn wọn fúyẹ́ ó sì ní ìyárí, èyí tí ó ṣe àfihàn kedere nípa ìrísí ìdùnnú àti aláyọ̀ wọn.”

Bí wọ́n ṣe “kọjá ilé tẹ́mpìlì, … ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti ọmọdé, kórajọ, láti onírúurú apákan ilú náà, láti dàpọ̀ nínú ìkìni-káàbọ̀ ológo àti aláyọ̀.” Ààrẹ Brigham Young bá wọn sọ̀rọ̀: “Njẹ́ kí Olúwa Ọlọ́run Ísráẹ́lì ó bùkún yín. … A ti gbàdúrà fún yín lemọ́lemọ́; ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn àdúrà ni a ti gbà fún yín, ní ọjọ́ sí ọjọ́, sí I ẹnití ó ti pàṣẹ fún wa láti kó Ísráẹ́lì jọ, gba àwọn ọmọ ènìyàn là nípa wíwàásù ìhìnrere, àti mímúra wọn sílẹ̀ fún bíbọ̀ ti Mèssíàh.”

Nínú ẹ̀mí ti ọ̀ràn aláyọ̀ náà, ẹ jẹ́ kí nmu dá gbogbo olùyípadà titun àti àwọn tí ó npadàbọ̀ sí Ìjọ Olúwa: a fẹ́ràn yín; a nílò yín; Olúwa nílò yín. A lè má kíi yín káàbọ̀ pẹ̀lú ọ`gbà ẹlẹ́ré, ṣùgbọ́n a gbàdúrà pé àwọn ìbùkún ọ̀run yíò wà pẹ̀lú àwọn ìtiraka yín láti nílọsíwájú lẹgbẹ ipa-ọ̀nà májẹ̀mú tí ó ndarí sí Ọlọ́run Baba àti Jésù Krístì nínú ìjọba sẹ̀lẹ́stíà.

Ẹ̀rí kedere wà pé ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì nlékún si ní ọjọ́ wa. Nínú Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, àlékún alámì ti wà nínú àwọn olùyípadà àti kíkópa olùyípadà. Ní oṣù mẹ́rìndílógójì tó kọjá ó súnmọ́ olùyípadà 900,000 tí ó darapọ̀ mọ́ Ìjọ. Àwọn olùyípadà wọ̀nyí jẹ́ bíi déédé ìpín máàrún ti àpapọ̀ àwọn tó jẹ́ ọmọ Ìjọ. A kí àwọn ọmọ ìjọ titun káàbọ̀ pẹ̀lú ìṣíwọ́ àti ìmoore ìjìnlẹ̀ fún ipa-ọ̀nà tí ẹ ti yàn.

Àwọn olùyípadà 900,000 wọ̀nyí ní oṣù mẹ́rìndínlógójì tó kọjá tayọ àpapọ̀ àwọn ọmọ Ìjọ ní àjọ̀dún ọgọ́ọ̀rúnlémẹ́wàá rẹ̀ ní 1940, èyí tí ó kàn jẹ́ àwọn ọmọ ìjọ 860,000. Èyí ni ọdún tí a bí Alàgbà Jeffrey R. Holland, Alàgbà Dieter F. Uchtdorf, àti èmi.

Àwọn oníyanu olùyípadà titun wọ̀nyí wá láti gbogbo apákan ayé. Ní oṣù kẹfà ọdún yí, àwọn olùyípadà ti pọ̀ si nípa ó ju ìpín ogun lórí ọdún titẹ́lẹ̀ ní Europe, Áfríkà, Ásíà, Pacific, àti Látìn Amẹ́ríkà. Ní United States a ní àlékún ìpín mẹ́tàdínlógún. Iṣẹ́ Olúwa ntẹ̀síwájú láti lọsíwájú nínú àwọn ọ̀nà alágbára. Àwọn oye tó npọ̀si wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀rí híhàn kedere pé ìhìnrere nfọwọ́tọ́ ọkàn ó sì nyí ìgbé ayé padà níbi-gbogbo.

Ní ọjọ́ wa, àwọn olùyípadà iyebíye wọ̀nyí kìí kórajọ sí ibi ààrin-gbùngbun kan mọ́. Nítorí ìgbàgbọ́ àti ìyàsọ́tọ́ ti àwọn ọmọ Ìjọ, àwọn ohun-èlò wà ní àrọ́wọ́tó láti ti gbogbo ìjọ lẹ́hìn—pẹ̀lú ìkọ́lé ilé ìjọsìn àti tẹ́mpìlì káàkiri gbogbo àgbáyé. Pẹ̀lú àwọn kọ́kọ́rọ́ oyèàlùfáà tó ṣe pàtàkì àti àwọn ohun-èlò tí a pèsè, àwọn ìlànà ìgbàlà wà ní àrọ́wọ́tó báyìí ni púpọ̀jùlọ àwọn apákan àgbáyé.

Láìka ti ibi tí a ngbé sí, àwọn ọmọ ìjọ lọ́wọ́lọ́wọ́ níláti kí àwọn ọgọgọ́ọ̀rún ti ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ ìjọ titun káàbọ̀ bí a ṣe ṣe sí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Gẹ̀ẹ́sì àti Welsh tí mo ṣe àpèjúwe látinú àkọọ́lẹ̀-ìtàn wa ìṣíwájú. Mo fẹ́ràn ọ̀rọ̀ Alàgbà Gerrit W. Gong nínú abala yí níbití ó ti kọ́ wa pé kò sí ẹni tí ó níláti dánìkan joko bóyá níti ẹ̀dùn ọkàn tàbí níti ẹ̀mí.

Ojúṣe mímọ́ wa ni láti tẹ́wọ́gbà kí a sì kí àwọn ọmọ ìjọ titun àti pípadàbọ̀ káàbọ̀. Bí Olúwa ṣe nyára kánkán ṣiṣẹ́ Rẹ̀, a níláti fẹ́rán, ṣìkẹ́, kí a sí sin àwọn tí wọ́n tẹ́wọ́gba ìhìnrere Rẹ̀. A lè ṣèrànwọ́ láti gbé àwọn ènìyàn Síónì ga, níbi tí a wà “ti ọkàn kan àti inú kan, kí a sì [gbé] nínú òdodo.” Láti jẹ́ ọ̀kàn pẹ̀lú Olúwa, a gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀kan níwájú Olúwa. Gbogbo ọmọ ìjọ láìka ọjọ́ ìrìbọmi sí pín ojúṣe kan láti kí àwọn ẹlòmíràn káàbọ̀.

Àmọ̀ràn mi sí àwọn ọmọ Ìjọ ni láti wé apá wa yíká àwọn ènìyàn iyebíye, tí a yàn tí wọ́n ti tẹ́wọ́gba ìhìnrere Jésù Krístì.

Ààrẹ Gordon B. Hinckley kọ́ wa pé àwọn olùyípada titun nílò “ọ̀rẹ́ kan, ojúṣe kan, àti ṣíṣìkẹ́ pẹ̀lú ‘ọ̀rọ̀ rere ti Ọlọ́run’ (Mórónì 6:4).” A lè wà ní àárín àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n mú dá àwọn olùyípadà titun wọ̀nyí lójú pé wọ́n wà-pẹ̀lú wọ́n kìí sì ṣe àlejò lásán. A lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní òye pé wọ́n jẹ́ ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì tí ó lè ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn kí wọ́n sì tẹ́wọ́gba àwọn ìpè làti sìn. Ọ̀dọ́ olùyípadà níláti gbèro sísìn ní míṣọ̀n ìgbà-kíkún. Gbogbo ènìyàn níláti pinnu láti tiraka láti gbé ìgbé ayé bíiti Krístì.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ darapọ̀ mọ́ Ìjọ nínú ìrúbọ araẹni nlá pẹ̀lú ìtara wọ́n sì nílò ìfẹ́ àti àtìlẹhìn ti ọmọnìkejì Ènìyàn Mímọ́ wọn.

Sí àwọn wọnnì lára yín tí ẹ jẹ́ titun tàbí npadàbọ̀ sí ìgbàgbọ́, àwọn ìpènijà wà tí ẹ lè kojú. Ẹ ní sùúrù pẹ̀lú arayín. Àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ti kọ́ yín ní ẹ̀kọ́ pàtàkì wọ́n sì ti ṣe àlàyé àwọn májẹ̀mú àti ìlànà ti ìjọba èyí tí a gbé kalẹ̀ nínú àwọn ìwé mímọ́ àti nínú Wàásù Ìhìnrere Mi.

Gbígba àwọn ìlànà àti májẹ̀mú àti gbígbé àwọn òfin ṣe kókó. Ẹ kọjúsí orí àwọn májẹ̀mú tí ó ṣe pàtàkì fún ìgbéga. Ìhìnrere nmú ìgbéga ṣeéṣe, èyí tí ó bèèrè fún dídá àti pípa àwọn májẹ̀mú mímọ́ mọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Bíkòṣe fún ìrìbọmi, ìfẹsẹ̀múlẹ̀, àti ìfúnni ti Oyè-àlùfáà Mẹ́lkisédẹ́kì fún àwọn Ọkùnrin, àwọn májẹ̀mú tí a nwọ inú rẹ̀ ni à nṣe nínú tẹ́mpìlì. Fún àwọn òkú, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìlànà ìgbàlà wọ̀nyí ni à nṣe nìkan nínú tẹ́mpìlì. Bẹ́ẹ̀náà, mímúra ara yín sílẹ̀ fún tẹ́mpìlì níláti jẹ́ ìlépa kíákíá.

Nígbàmíràn ẹ ó ní ìmọ̀lára àìkúnojú-ìwọ̀n. Ìmọ̀ ìhìnrere ni ìbùkún nlá tí a ngbà ní àlékún-àlékún ní ìgbà pípẹ́, ṣùgbọ́n kìí ṣe ìlànà ìgbàlà. Ìhìnrere kìí ṣe ìdánwò ti ìmọ̀. Bákannáà, bí Ààrẹ Russell M. Nelson ti ṣèlérí pé: “Bí ẹ ṣe nfi tàdúràtàdúrà ṣe àṣarò Ìwé ti Mọ́mọ́nì lójoojúmọ́, ẹ ó ṣe àwọn ìpinnu dídára síi—lójoojúmọ́. … Bí ẹ ṣe njíròrò ohun tí ẹ ṣe àṣàrò rẹ̀, àwọn fèrèsé ọ̀run yíò ṣí sílẹ̀, ẹ ó sì gba àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbèèrè ti ara yín àti ìdarí fún ìgbé ayé ti ara yín.”

Nní àfikún, ọdún kọ̀ọ̀kan ní àyídà ohun-èlò ìjọ ní àwọn ìpàdé Ọjọ-ìsinmi borí Májẹ̀mú láéláé, Májẹ̀mú Titun, Ìwé ti Mọ́mọ́nì, àti Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú. Ní ìgbà díẹ̀ ẹ ó ní ìmọ̀lára ìgbẹ́kẹlé síi bí ìmọ̀ ìhìnrere yín ṣe ndàgbà. Àṣàrò déédé ti ìwé mímọ́ yíò bùkún yíò sì ṣìkẹ́ ìgbé ayé yín nípa mímú ìyípadà yín sí ìhìnrere Jésù Krístì jinlẹ̀.

Kíkọ́ ẹ̀kọ́ mímọ́ ti Jésù Krístì ni ìlépa ayé-pípẹ́, méjèèjì ní níní òye ẹ̀kọ́ àti gbígbé ìgbé ayé bìiti Krístì. Àwọn májẹ̀mú pàtàkì pèsè ìlànà èyí tí a ṣe àpèjúwe bi ipa-ọ̀nà májẹ̀mú. Àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ ni a ti kọ́ pẹ̀lú agbára nípasẹ̀ Ààrẹ Nelson. Gbogbo àwọn ọmọ ìjọ, nípàtàkì titun àti àwọn tó npadàbọ̀, yíò di alábùkún-fún nípa ṣíṣe àṣàrò kí wọ́n sì gba àwọn ọ̀rọ̀ ti wòlíì lórí àwọn májẹ̀mú àti ipa-ọ̀nà májẹ̀mú.

Bí ẹ bá gbé ìlépa yíyẹ ti gbígba ọ̀kọ̀ọ̀kan májẹ̀mú tí ó ṣeéṣe fún ìgbéga, ẹ ó wà lórí ipa-ọ̀nà tí ó darí lọ sí ìjọba sẹ̀lẹ́stíà. Tẹ́mpìlì àti àwọn ìlànà ti tẹ́mpìlì gbọ́dọ̀ jẹ́ ìfojúsí wa. Púpọ̀jùlọ àwọn májẹ̀mú wà ní àrọ́wọ́tó sí ẹnìkọ̀ọ̀kan. Májẹ̀mú kan, ìgbeyàwó ayérayé, ní dída àwọn ìtiraka wa pọ̀ ojúgbà kan nínú. Ìlépa wa níláti jẹ́ láti wá ojúgbà ayérayé náà.

Bákannáà, ẹ máṣe ní ìrẹ̀wẹ̀sì bí ìgbeyàwó ayérayé kò bá ṣeéṣe ní àkokò yí. Àwọn wòlíì ti kọ́ni pé kò sí ìbùkún tí a ó dìmú kúrò lọ́wọ́ àwọn olóòótọ́ ọmọ ìjọ tí wọ́n pa àwọn òfin mọ́. Wòlíì Ìwé ti Mọ́mọ́nì kan, Ọba Benjamin, sọ dáradára pé: “Àwọn tí ó pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ … di alábùkúnfún nínú ohun gbogbo, … bí wọ́n bá sì … [jẹ́] olóòótọ́ dé òpin … wọ́n lè bá Ọlọ́run gbé ní ipó ìdùnnú àìnípẹ̀kun.”

Ẹ ó ri, bí ẹ kò bá tíì ri tẹ́lẹ̀, pé àwọn ọmọ ìjọ jẹ́ aláìpé. Ẹ̀kọ́ tí a fihàn nmu dajú pé nínú àtìpó wa ní ìhín lórí ilẹ̀ ayé, a ó ṣe àwọn àṣìṣe. À ngbé ní ayé àìpé àti ìṣubú, kìí ṣe ayé sẹ̀lẹ́stíà. Ayé yí ni àkokò ti dídánwò, pẹ̀lú àwọn ànfààní léraléra láti ronúpìwàdà kí a sì jẹ́wọ́ arawa.

Gbogbo wa nní ìmọ̀lára àìkúnjú-ìwọ̀n bí a ṣe ndàbíi ti Jésù Krístì. Ètùtù Rẹ̀ fi ààyè gbà wá láti ronúpìwàdà lojojúmọ́ bí a ti nkùnà. Bí Néfì, wòlíì míràn Ìwé ti Mọ́mọ́nì, wípé: “[A] gbọ́dọ̀ tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìdúróṣinṣin kan nínú Krístì, níní ìrètí ìmọ́lẹ̀ pípé, àti ìfẹ́ Ọlọ́run àti ti gbogbo ènìyàn. Nítorí-èyi, bí ẹ̀yin yíò bá tẹ̀síwájú, tí ẹ̀ nṣe àpèjẹ lórí ọ̀rọ̀ Krístì, tí ẹ sì forítì í dé òpin, kíyèsĩ i, báyĩ í ni Baba wí: Ẹ̀yin yíò ní ìyè àìnípẹ̀kun.”

Bí a ti ngbèrò àwọn ìpènijà ọjọ́ wa, a gbọ́dọ̀ rántí pé Olùgbàlà, ní ìgbà iṣẹ́ ìránṣẹ́ ilẹ̀ ayé Rẹ̀, bákannáà gbé nínú àkokò ewu àti ìjà. Ifojúsí Rẹ̀ kìí ṣe lórí àwọn ìpènijà òṣèlú ti ọjọ́ náà; ó jẹ́ lórí jíjẹ́ pípé ti àwọn Ènìyàn Mímọ́.

Títẹ̀lé Olùgbàlà àti ẹ̀kọ́ àti ìkọ́ni Rẹ̀ kò tíì rọrùn rí nínú ayé tí ó wà nínú ìrúkèrúdò léraléra. Kò rọrùn fún Olùgbàlà nínú ayé líléfò ní ìgbà àtìpó ayé ikú rẹ̀, kò rọrùn fún àwọn aṣaájú wa ìṣíwájú àti àwọn ọmọ ìjọ, kò sì rọrùn fún wa. Ní dídára, àwọn wòlíì pèsè ìtọ́sọ́nà tí a nílò gan fún ọjọ́ wa. Ààrẹ Dallin H. Oaks yíò mú ohun-ìní alágbára ti ẹ̀mí náà tẹ̀síwájú.

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé ẹ̀kọ́ Ìjọ Jésù Krístì jẹ́ ayérayé àti òtítọ́. Mo jẹ́ ẹ̀rí dídájú àtì pàtó mi pé Jésù Krístì wà láàyè àti pé nítorí Ètùtù Rẹ̀, a lè jẹ́ ọ̀kan pẹ̀lú Krístì. Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Charles Dickens, Ìtàn Ìlú Meji (1859), 1.

  2. Aàwọn Àkórí Dickens ni èrò ìyípadà olúkúlùkù ní àkokò àìsimi àwùjọ kan.

  3. Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 45:26.

  4. Wo Gary E. Stevenson, “Ìbùkún Ni Fún Awọn Onílàjà,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2025, 6–9.

  5. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 1:23.

  6. Wo Doctrine and Covenants 88:73.

  7. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 59:23; bákannáà wo Jòhánnù 14:27.

  8. Wo Ìṣe Àwọn Àpóstélì 2:41.

  9. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 112. Ìfihàn yí ni a gbà ní Ọjọ́ Kẹtàlélógún Oṣù Kéje, 1837, ní ọjọ́ náà ni a kọ́kọ́ wàásù ìhìnrere ní England ní àkokò iṣẹ́ ìríjú yí. Fún púpọ̀ síi lórí àwọn míṣọ̀n wọ̀nyí, wo James B. Allen, Ronald K. Esplin, àti David J. Whittaker, Àwọn Ọkùnrin Pẹ̀lú Iṣẹ́ Ìránṣẹ́: Iyejú Àwọn Àpóstélì Méjìlá ní Erékùṣù British, 1837–1841 (1992).

  10. Púpọ̀jùlọ lára àwọn olùyípadà wọ̀nyí wá látinú kílásì àwọn òṣìṣẹ́. Charles Dickens ṣe àkíyèsí àwọn kan lára wọn bí wọ́n ṣe nmúrasílẹ̀ fún ìrìnàjò lọ sí United States, lórí ọkọ̀ ojú omi Amazon. Ó ní ojúrere nínú àyẹ̀wò rẹ̀. Ó ṣe àpèjúwe wọn bíi “nínú òye wọn, mímú àti òdòdó ti England” (“Arìnrìn-àjò Aìjẹ́towò,” Yíká Gbogbo Ọdún, Ọjọ́ Kẹ́rin Oṣù Kéje, 1863, 446) Bákannáà wo 1 Kọ́ríntì 1:26-28.

  11. Wo “Dídé láti England, nípa ‘Owó Ìṣípò-kiri Perpetual,’” Àwọn Ìròhìn Deseret, Oṣù Kẹsan. 18, 1852, 90.

  12. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 76:62, 70; bákannáà wo 1 Kọ́ríntì 15:40-42.

  13. Ìwífúnni tí a pèsè nípasẹ̀ Ṣíṣírò Àkọsílẹ̀ àwọn Ọmọ Ìjọ àti Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìhìnrere.

  14. Ìwífúnni tí a pèsè nípasẹ̀ Ṣíṣírò Àkọsílẹ̀ àwọn Ọmọ Ìjọ àti Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìhìnrere.

  15. Ìwífúnni tí a pèsè nípasẹ̀ Ṣíṣírò Àkọsílẹ̀ àwọn Ọmọ Ìjọ

  16. Ìwífúnni tí a pèsè nípasẹ̀ Ṣíṣírò Àkọsílẹ̀ àwọn Ọmọ Ìjọ àti Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìhìnrere.

  17. Ní 1890, àwọn aṣaájú Ìjọ bẹ̀rẹ̀ sí gba àwọn ọmọ ìjọ níyànjú láti dúró nínú ilẹ̀ àbínibí wọn sànju kíkórajọ sí Utah. Àwọn èèkàn àkọ́kọ́ ní òde Ìlà-oòrùn Intermountain ni a dásílẹ̀ ní 1920, àti pé èèkàn àkọ́kọ́ ní òde Àríwá Amẹ́ríkà ní a dásílẹ̀ ní New Zealand (wo Brandon S. Plewe, ed., Yíyàwòrán ti Mọ́mọ́nì: Ìwé àwòrán ti Ẹ̀nìyàn Mímọ́ Àkọọ́lẹ̀-ìtàn [2014], 184–85).

  18. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 110:11–16.

  19. Wo Gerrit W. Gong, “Kò Sí Ẹni Tí Ó Nndánìkan Joko,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2025, 42–45.

  20. Mósè 7:18.

  21. Wo Jóhánnù 17:20–21; 1 Kọ́ríntì 12:11–31.

  22. Gordon B. Hinckley, “Àwọn Olùyípadà àti Awọn Ọ̀dọ́mọkùnrin,” Ẹ́nsáìnì, Oṣù Karun 1997, 47.

  23. Wo Jákọ́bù 2:5; bákannáà wo Máttéù 19:29; Rómù 2:11; Éfésù 2:19; Mòsíàh 18:8–9.

  24. Wo Wàásù Ìhìnrere Mi: Atọ́nà Kan Sí Pípín Ìhìnrere Jésù Krístì (2023), 17.

  25. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 14:7.

  26. Russell M. Nelson, “Ìwé ti Mọ́mọ́nì: Báwo ni Ìgbé Ayé Yín Ìbá Tirí Láìsí i Rẹ̀?,” Làìhónà, Nov. 2017, 62–63; bákannáà wo Spencer W. Kimball: “Nígbàtí ó dàbí kò sí ẹtí tọ̀rin tí ó nfetísílẹ̀ kò sì sí ohùn tí ó nsọ̀rọ̀, … Bí [a] bá ri [arawa] sínú ìwé mímọ́ ààyè náà ndínkù ẹ̀mí sì npadàwá” (Ìkọ́ni àwọn Ààrẹ Ìjọ: Spencer W. Kimball [2006], 67).

  27. Wo Jòhánnù 5:39.

  28. Fún àpẹrẹ, wo, Russell M. Nelson, “Ẹ Jẹ́ Kí Ọlọ́run Borí,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2020, 92–95; “Ipa Agbára Ti Ẹ̀mí,” Làìhónà, Oṣù Karun 2022, 97–100; “Ẹ Borí Ayé kí ẹ Sì Rí Ìsinmi,” Làìhónà, Oṣù. 2022, 95–98.

  29. Mòsíàh 2:41.

  30. Wo Álmà 34:32.

  31. 2 Nefì 31:20.

  32. Wo Éfésù 4:11–15.

  33. Wo Jòhánnù 17:20–22.