Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ẹ Gba Ẹ̀bùn Rẹ̀
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2025


14:4

Ẹ Gba Ẹ̀bùn Rẹ̀

Ẹ jẹ́ àyànfẹ́ ọmọbìnrin Ọlọ́run, ẹ jẹ́ ọmọkùnrin tí Ọlọ́run mọyì, Òun si ti fi Ọmọ Rẹ̀ pípé, mímọ́ fùn yín bí ẹ̀bùn.

Ẹ̀bùn Fífúnni

Ẹ̀bùn fífúnni jẹ́ àṣà àwùjọ tí ó kárí gbogbo àṣà, ọ̀làjú, àti mìllẹ́níà. La gbogbo àkókò já, àwọn ènìyàn ti fi àwọn ẹ̀bùn fún ara wọn láti fún ìbáṣepọ̀ lókun, láti fi ìfẹ́ àti ìmoore hàn, àti láti sàmì àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì bíi ìgbéyàwó, ọjọ́ ìbí, àti àwọn ìsinmi. Àti pé kìí ṣe ènìyàn nìkan ni ẹ̀dá Ọlọ́run tí wọ́n nfi ẹ̀bùn fún ara wọn! Láàrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àpẹrẹ míràn ti a lè tọ́ka sí, àwọn pẹ́ngúin ni a mọ̀ tí wọ́n máa nfi àwọn òkúta dídán kékèké fún àwọn tí wọ́n bá fẹ́ kí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ́ wọn, àti pé àwọn bònònó (ìbátan ìnàkí) máa nfi èso fúnni láti mú agbo ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wọn gbòòrò síi.

Àwọn Pẹ́ngúìn nfúnni ní àwọn òkúta dídán kékeré.
Àwọn Bònònó npín èso.

Àwọn ẹ̀bùn wo ni ìwọ ti fi fúnni? Ẹ ronú nípa àkókò kan nígbàtí ẹ rí—tàbí ṣe—ẹ̀bùn pípé kan fún ẹnìkan tí ẹ fẹ́ràn. Ẹ kàn mọ̀ pé ẹ̀bùn náà jẹ́ ohun gan-an tí olùfẹ́ yí fẹ́ àti ohunkan tí wọn yíó tọ́jú bíi ìṣúra. Kínni ẹ̀bùn náà? Njẹ́ ó jẹ́ fún ìyá yín? ọ̀rẹ́ kan? ọmọ yín? olùkọ́ kan? baba yín àgbà? Báwo ni ẹ ṣe ní imọ̀lára sí nígbàtí ẹ rí ẹ̀bùn yí? Báwo ni ẹ ṣe ní ìmọ̀lára sí nígbàtí ẹ ronú nípa ẹni tí ẹ fẹ́ràn yí tí ó nṣí ẹ̀bùn náà? Ní ìfarajọ, nígbàwo ni ẹnìkan fún yín ní ẹ̀bùn pípé kan, báwo ni ẹ sì ti ríi sí láti gbà á?

Ẹ̀bùn ti Baba Mi sí Mi

Nígbàtí mo wà bíi ẹni ọdún méje, ti mo ngbé pẹ̀lú àwọn òbí mi ni Arábíà, wọ́n ṣe eré ọmọdé aláwòrán kan ti a pè ní Chítì Chítì Bángi Bángì jáde. Eré náà jẹ́ nípa ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ onídán kan tí ó le wa ara rẹ̀, ó le léfòó lórí omi, o sì le fò nínú afẹ́fẹ́! Mo mọ̀ pé ní ìlú wa ni England wọ́n ṣe ìṣere ọmọdé kékeré ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan bíi Chítì Chítì Bángi Bángì, àti pé áà, mo ti fẹ́ láti ní ọ̀kan tó! Ẹ le fa lẹ́fà kan, àwọn apá ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ìṣeré náà yíó sì yọ jáde! Baba mi lọ ìrìnàjò iṣẹ́ kan sí England ó sì béèrè bóyá mo fẹ́ kí òun mú ohunkóhun bọ̀ fúnmi, mo si sọ fún un bi mo ti fẹ́ gidigidi tó láti ní ọ̀kan nínu àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ Chítì Chítì Bángi Bángì náà.

Ó padà dé láti ìrìnàjò rẹ̀, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kankan kò sì farahàn. Inú mi bàjẹ́ mo sì rò pé ó níláti jẹ́ pé ó ti gbàgbé. Ṣùgbọ́n bì ọjọ́ mẹ́wàá lẹ́hìnnáà ni ọjọ́ ìbí mi, àti ohun kan, tí a ti wé dáradára, ndúró dè mí. Pẹ̀lú ìfojúsọ́nà nlá, tí o nira láti máṣe ní ìrètí púpọ̀jù, mo ṣí ẹ̀bùn náà mo sì rí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mi. Inú mi dùn débi pé mo sunkún. Mo fa lẹ́fà náà, àwọn apá sì yọ jáde, gẹ́gẹ́bíi ti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ inú eré aláwòrán náà! Bí mo ti dúpẹ́ lọ́wọ́ baba mi tó fún ẹ̀bùn ìṣúra jùlọ yí. Mo ṣeré pẹ̀lú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà fún ọ̀pọ̀ ọdún mo si fi pamọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ síi. Mo ro pé baba mi fẹ́ràn láti fúnmi ni ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà bí èmi náà ṣe fẹ́ràn láti gbà á.

Fífúnni, Títẹ́wọ́gbà àti Ṣíṣí, àti Gbígbà

A lè ronú nípa ẹ̀bùn fífúnni bíi níní abala mẹ́ta sí i:

  1. Ìṣe fífúnni ní ẹ̀bùn, níbití olùfúnni ti nyàn, nmú, tàbí npèsè ẹ̀bùn náà tí ó sì nfi í fún olùfẹ́ kan. Èyí ní í ṣe sí èrò ọkàn àtinúwa láti ọ̀dọ̀ olùfúnni láti funni ní ohun tó nítumọ̀.

  2. Iṣe títẹ́wọ́gbà àti ṣíṣí ẹ̀bùn náà, nígbàtí olùgbà tẹ́wọ́gba ẹ̀bùn náà láti ọ̀dọ̀ olùfúnni—nígbà púpọ̀ pẹ̀lú àfihàn ti ìyanu, ìmoore, àti ara yíyá—ṣaájú ṣíṣí i, nígbà míràn títú okùn kan àti yíyọ nkan ti a fi wé ìdí náà kúrò láti rí ẹ̀bùn gan-an.

  3. Àti nígbànáà apákan bóyá tó ṣe pàtàkì jùlọ wà, ti gbígba ẹ̀bùn náà. Láti gba ẹ̀bùn kan tí a fi tọkàntọkàn fùnni jẹ́ títóbi ju títẹ́wọ́gbà àti ṣíṣí lọ. Ó pọ̀, àní, ju dídá iyì ẹ̀bùn náà mọ̀ àti fífi ìmoore hàn sí olùfúnni lọ. Láti gba ẹ̀bùn kan ní tòótọ́, a níláti mọ ìwúlò rẹ̀ fún ara wa kí a fi sí lòó ní kíkún nínú ayé wa, kí a sì rántí olùfúnni pẹ̀lú dídúpẹ́.

Gbígba ẹ̀bùn kan kìí ṣe ohun lásán ṣùgbọ́n ìlànà àtinúwá to nítumọ̀ ti ó lọ jìnnà sí kí a kàn ṣí ìdí kan lọ. Láti gbà jẹ́ láti mọrírì kí a sì ní àsopọ̀ pẹ̀lú ẹ̀bùn náà àti ọkàn olùfúnni ní ọ̀nà kan tí ó nfi okun fún àwọn àsopọ̀ láàrin olùfúnni àti olùgbà. Ríronú nípa ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ìṣeré náà nmú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìrántí aládùn padà wá, bí mo ti nní ìmọ̀lára lẹ́ẹ̀kansíi ti ìjinlẹ̀ ìfẹ́ àti ìtọ́jú baba mi fún mi, tó jẹ́ dídúró fún nípasẹ̀ ẹ̀bùn náà àti àìníye àwọn ìṣe inú rere míràn.

Àwọn Ẹ̀bùn ti Baba Wa Ọ̀run

Baba wa ní Ọ̀run ní àwọn ẹ̀bùn àìlónkà ti ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ tí a pèsè láti rọ̀jò sọ̀kalẹ̀ sórí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, àwa ọmọ ìsúra Rẹ̀. Wọ́n nṣàn láti ọ̀dọ̀ Olùfúnni ní Ọ̀pọ̀ yanturu wa bíi orísun kànga kan nínu aginjù ọkàn ìṣoore Rẹ̀. “Gbogbo ẹ̀bùn dídára àti gbogbo ẹ̀bùn pípé jẹ́ láti òkè, wọ́n sì nwá sísàlẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba àwọn ìmọ́lẹ̀.” Nínú májẹ̀mú àsopọ̀ wa pẹ̀lú Baba, Òun ni Olùfúnni títíláé àwa sì ni onírẹ̀lẹ̀ olùgbà.

Títóbijùlọ nínu Gbogbo àwọn Ẹ̀bùn Baba, Nípasẹ̀ Èyítí Gbogbo àwọn Míràn Nṣàn

Ṣùgbọ́n a kò le gba ohunkóhun láìsí èyítí ó tóbijùlọ nínu gbogbo àwọn ẹ̀bùn Baba, àyànfẹ́ Ọ̀dọ́-Àgùtàn Rẹ̀, Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì. Gbogbo àwọn ẹ̀bùn Baba nṣàn wọ́n sì njẹ́ mímú ṣiṣẹ́ láti ipasẹ̀ ẹbọ-ọrẹ àtinúwa ti Olùgbàlà ní Gẹ́tsémánè àti lórí àgbélèbú àti Àjínde ìṣẹ́gun Rẹ̀. Jésù Krístì, Olùràpadà wa aláànú, ni ẹ̀bùn gígajùlọ náà láti ọ̀dọ̀ Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ wa. “Nínú ẹ̀bùn ti Ọmọ rẹ̀ ni Olọ́run pèsè ọ̀nà tí ó dára jù [fún wa].”

Ẹ̀bùn Kan ti Òtítọ́ Ayérayé Tó Kó Gbogbo Rẹ̀ Sínú

Yíó wù mí láti sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀bùn kan tó ká ìyókù mọ́ ti òtítọ́ ayérayé tí ó ṣe àtilẹ́hìn fún agbára wa láti gba gbogbo ìyókù tí Baba wa ní ìfẹ́-inú láti bùkún wa pẹ̀lú—ẹ̀bùn pàtàkì kan tí, nígbàtí ó bá jẹ́ títẹ́wọ́gbà ní kíkún tí ó sì jẹ́ gbígbà jìnlẹ̀ nínú ẹ̀mí nfi awọn ayọ̀ ati awọn inira inú ayé ati awọn ìbéèrè wa tí kò tíì ní ìdáhùn sínú àyè tó yẹ hàn: Tí ó jẹ́ pé ọmọ Ọlọ́run ni wá lódodo Òtítọ́ náà jẹ́ dídùnmọ́ni! Yíyanilẹ́nu! Kì í sì ṣe yẹpẹrẹ.

Ẹ ròó pé ẹ ngbọ́ eléyìí fún ìgbà àkọ́kọ́! Ẹ jẹ́ ọmọbìnrin Rẹ̀ tí ó mọyì lódodo. Ẹ jẹ́ ọmọkùnrin Rẹ̀ iyebíye lódodo. Ipa ọ̀nà tí ẹ sì wà jẹ́ ètò ìdùnnú Rẹ̀. Pẹ̀lú ifẹ́ Rẹ̀ to borí ohun gbogbo, Ó mọ ẹnití ẹ jẹ́ gan-an ṣaájú ki a tó rán yín wá sí ilẹ̀ ayé àti ohun tí ẹ ti ní ìrírí rẹ̀ dé àkókò yí nínú ayé ikú yín, Òun si ti fi àánú ṣètò fún gbogbo ọ̀la ryín. Àti pé áà, báwo ni Ó ti npòngbẹ tó láti ríi pé ẹ padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ní ọjọ́ kan, láti gba èrò inú gígajùlọ ti gbogbo àwọn ẹ̀bùn rírẹwà Rẹ̀ ayérayé pẹ̀lú Rẹ̀.

Ìbéèrè náà kìí ṣe bóyá ẹ̀bùn náà jẹ́ òtítọ́ ṣùgbọ́n bóyá a ó rí i tí a ó sì gbà á. Ẹ̀bùn náà ti jẹ́ fífi fún wa tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ Baba. Gbèsè náà fún èrèdí ìgbẹ̀hìn ti ẹ̀bùn yí ti jẹ́ sísan tẹ́lẹ̀ láti ọwọ́ Olùgbàlà. Ṣugbọ́n bí a bá ti kọ́ yín ní èyí, tí ẹ ti sọ èyí, tí ẹ ti kọ òtítọ́ yí lórin fùn awọn ọdún, bóyá ọ̀wọ̀ ìyanu rẹ̀ ti parẹ́ tipẹ́ tí ẹ kò sì ní ìmọ̀lára agbára ati alàáfíà rẹ̀ mọ́.

Bí ẹ̀bùn àìdíyelé ti òye yìí—àti gbogbo ìṣerere, alàáfíà, àti ìrètí tí nṣàn láti ibẹ̀—bá jẹ́ fífi sílẹ̀ ní àìtẹ́wọ́gbà, àìṣí, àti àìgbà, yíó ti jẹ́ àdánù búburú tó fún wa! Yíó ti jẹ́ ìbànújẹ́ fún Olùfunni tó!. “Nítorí èrè kilo jẹ́ fún ènìyàn tí a ba fun ni ẹ̀bùn, tí òun kò sì gba ẹ̀bùn náà? Kíyèsíi, kò dunnú sí èyí tí a fifun un, bẹ́ẹ̀ni kò sì dunnú sí ẹni tí ó jẹ́ olùfúnni ní ẹ̀bùn náà.”

Mo pè yín láti gba, bóyá fún ìgbà àkọ́kọ́ tàbí ní títóbi ju bí ó ti nwá ṣíwájú rí lọ, ìmọ̀ ọlọ́lá pé ẹ̀yin jẹ́ àyànfẹ́ ọmọ Ọlọ́run nítòótọ́. Ẹ níláti tú okùn náà, fa bébà fífiwé náà ya kúrò, ṣí àpótí náà, kí ẹ sì fi ayọ̀ gbàá pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ìmoore, òye àìlábàwọ́n ti òtítọ́ ìpìlẹ̀ yí. Ẹ̀mí Mímọ́ lẹ̀ jẹ́rìí sí ọkàn yín pé ní tòótọ́ ẹ jẹ́ ọmọ Ẹni Gíga Jùlọ.

Nígbàtí ẹ bá gba òtítọ́ ọlọ́lá yìí sínú ọkàn yín gàn-an tí ẹ sì ní ìmọ̀lára ìtùnú àti ìdùnmọ́ni rẹ̀, gbogbo ọ̀nà ìrònú yín yíó yàtọ̀! Ẹ lè ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Rẹ̀, gbọ́ ohu`n Rẹ̀, kí ẹ sì dá ọwọ́ Rẹ̀ mọ̀, ohun èyíówù kí ó máa ṣẹlẹ̀, tàbí tí kò ṣẹlẹ̀, nínú ayé yín. Ẹ lè tún bí ẹ ti rí arayín àti àwọn ẹlòmíràn sí ṣe. Májẹ̀mú àsopọ̀ yín pẹ̀lú Olùgbàlà yín ndi lílágbára síi, àti pé nípasẹ̀ ìwò ojú ti ẹ̀bùn dídùn yí, ìgbé ayé ngbé ìwurí, ẹwà, àti ìrètí titun wọ̀.

Ẹ jọ̀wọ́, njẹ́ ẹ ó gbàdúrà láti ní òye bí ẹ̀yin bá ngba ìmọ̀ ayínipadà yí nítòótọ́ ní jíjinlẹ̀ nínú ọkàn yín? Njẹ́ ẹ̀yin yíó tẹ́wọ́gba ẹ̀bùn náà? Njẹ́ ẹ̀yin ó ṣe bẹ́ẹ̀ ní jíjinlẹ̀ síi, ní ọ̀fẹ́ síi, àti ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ síi ju bí ẹ ti ṣe ṣaáju rí lọ—àti ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ kí a rọ̀jò lé yín pẹ̀lú gbogbo àwọn ẹ̀bùn míràn tí ó nwá pẹ̀lú rẹ̀?

Gbígba Ẹ̀bùn Òtítọ́ Ayérayé Yí

Ẹ le máa ròó pé, Kínni mo nílò láti ṣe láti gba ẹ̀bùn yí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run? Ò dára, ní tòótọ́, kò sí. Ó jẹ́ ẹ̀bùn kan láti ọ̀dọ̀ Olùfúnni. Ó jẹ́ ìrọ̀rùn òtítọ́ kan. Ẹ kan gbà á sínú. Ẹ jẹ́ ọmọ Rẹ̀. Ẹ jẹ́ àyànfẹ́ Rẹ̀. Ẹ má jẹ́ kí ó díjú. Ẹ máṣe dínà mọ́ gbígba ẹ̀bùn yí pẹ̀lú àwọn èrò pé ẹ̀yin jẹ́ aláìyẹ bákan. Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé kò sí ẹnikankan nínú wa to “yẹ”—gbogbo àwọn ẹ̀bùn Baba ni à ngba nípasẹ̀ ìkàyẹ, àánú, àti oore-ọ̀fẹ́ ti Mèssíàh Mímọ́ nìkan, ṣùgbọ́n ọkàn inúrere Rẹ̀ ti npòngbẹ tó fún ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àwọn ọmọ Rẹ̀ láti gbà wọ́n! Nígbànáà, bí òye yín titun tàbi sísọdọ̀tun ti nwá sí ìmọ̀ yín, ẹ yọ̀ nínú dídúpẹ́ fùn Olùfúnni ẹ̀bùn náà.

Láti ìgbà tí mo ti rí ìgbàgbọ́ mi nígbàtì mo wà ní ààrin àwọn oguń ọdún mi, mo ti tají sí ìmọ̀ pé mo jẹ́ ọmọkùnrin Ọlọ́run ni tòótọ́. Bi mo bá ti lo ẹ̀bùn yí ní kíkún tó, bẹ́ẹ̀ ni mo nmọ ẹnití mo jẹ́ si àti bí a ti fẹ́ràn mi ní pípé tó. Àwọn ohun kan tó ti rànmí lọ́wọ́ dàgbà nínú òye ni àwọn ọ̀rọ̀ ìwé mímọ́, ìbùkún babanlá mi, ìjọ́sìn tẹ́mpìlì, sísin àwọn ẹlòmíràn, fífi ìmoore hàn, àti àdúrà mímọ́ pẹ̀lú Baba mi. Mo níyanu sí bí ìbànújẹ́, ìrora, àti ẹ̀dùn ọkàn ti ìbẹ̀rẹ̀ nínú ayé mi ìbá ti jẹ́ títúnṣe, títuni nínú, àti bibori ọ̀pọ̀ wọn kání mo ti mọ òtítọ́ rírẹwà yí ṣíwájú.

Ẹ wá sọ́dọ̀ Krístì kí ẹ sì Gbà

Mórónì gbà wá níyànjú láti “máṣe sẹ́ àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run” ṣùgbọ́n láti “wá sí ọ̀dọ̀ Krístì, kí a sì gbá gbogbo ẹ̀bùn rere mú.” Ẹ lè wá sí ọ̀dọ̀ Krístì pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìfẹ́ni-inurere Rẹ̀ kí ẹ sì gba gbogbo awọn ẹ̀bùn Rẹ̀ ti ayọ̀, àlàáfíà, ìrètí, ìmọ́lẹ̀, òtítọ́, ìfihàn, ìmọ̀, àti ọgbọ́n—pẹ̀lú ori yín ní gbígbé sókè, apá yín ní nínà jáde, ati ọwọ́ yín ní ṣíṣí sílẹ̀, ní ṣíṣetán láti gbà. Ẹ le gba àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí nítorípé ẹ wà láìléwu àti fífẹsẹ̀múlẹ̀ nínú ìmọ̀pé ẹ jẹ́ àyànfẹ́ ọmọbìnrin Ọlọ́run, ẹ jẹ́ ọmọkùnrin tí Ọlọ́run mọyì, Òun sì ti fún yín ní ẹ̀bùn Ọmọ Rẹ̀ pípé, mímọ́ láti rà yín padà, dá yín láre, kí ó sì yà yín sí mímọ́.

Ẹ̀yin jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. Èyí kìí ṣe orin dáradára kan lásán tí a nkọ. Njẹ́ ẹ̀yin ó jọ̀wọ́ tẹ́wọ́gba, ṣí, kí ẹ sì gba ẹ̀bùn ti ìmọ̀ àti òye yí láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀? Njẹ́ ẹ̀yin ó dì í mú pẹ́kípẹ́kí bíi ìṣura iyebíye tí ó jẹ́? Ẹ tún ẹ̀bùn yí gbà, tàbí bóyá ẹ gbà á nitòótọ́ fún ìgbà àkọ́kọ́ gan-an, kí ẹ sì jẹ́ kí ó ṣe àtúnṣe gbogbo abala ìgbé ayé yín. Èyí ni ọ̀nà dídára jù tí Ọlọ́run ti pèsè fún yín nípasẹ̀ ẹ̀bùn ti Ọmọ Rẹ̀. Ẹ wà lódodo kí ẹ lè ní ayọ! Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.