Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìmúrasílẹ̀ Araẹni láti Pàdé Olùgbàlà
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2025


14:9

Ìmúrasílẹ̀ Araẹni láti Pàdé Olùgbàlà

Ẹ tẹ̀lé àwọn ìkọ́ni Olùgbàlà. Àwọn ìkọ́ni Rẹ kìí ṣe ohun ìjìnlẹ̀ tàbí líle. Nígbàtí a bá tẹ̀le wọn, a kò níláti bẹ̀rù tàbí ní ìtara.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi Ọ̀wọ́n, ní Oṣù kẹwa tó kọjá, Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni pé, “ìsisìyí ni àkokò náà fún yín àti fún èmi láti múrasílẹ̀ fún Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì ti Olúwa àti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì.” Nígbàtí Ààrẹ Nelson sọ̀rọ̀ nípa Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì, ó jẹ́ pẹ̀lú ìrètí ayọ̀ nígbàgbogbo. Bákannáà, ọmọdébìnrin kan nínú Alakọbẹrẹ láìpẹ́ wí fún mi pé òun ndi onítara nígbàkugbà tí a bá dárúkọ Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì. Ó wípé, “Ẹ̀rù bà mí nítorí àwọn ohun búburú tí ó máa ṣẹlẹ̀ ṣíwájú kí Jésù tó wá lẹ́ẹ̀kansi.”

Kìí ṣe àwọn ọmọ tí wọ́n lè ní ìmọ̀lára ọ̀nà yí lásán. Àmọ̀ràn tó dárajùlọ fún un, fún yín, àti fún mi ni láti tẹ̀lé àwọn ìkọ́ni Olùgbàlà. Àwọn ìkọ́ni Rẹ kìí ṣe ohun ìjìnlẹ̀ tàbí líle. Nígbàtí a bá tẹ̀le wọn, a kò níláti bẹ̀rù tàbí ní ìtara.

Síwájú òpin ti iṣẹ́ ìránṣẹ́ ayé ikú Rẹ̀, Jésù Krístì ni a bèèrè ìgbà tí Òun yíò wá lẹ́ẹ̀kansi. Ní dídáhùn, Ó kọ́ àwọn òwe mẹ́ta, tí a kọsílẹ̀ nínú Matteu 25, nípa bí a ó ti múrasílẹ̀ láti pàdé Rẹ̀—bóyá ní Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì tàbí ìgbàkugbà tí a bá fi ayé yí sílẹ̀. Àwọn ìkọ́ni wọ̀nyí jé pàtàkì nítorí ìmúrasílẹ̀ araẹni láti pàdé Rẹ̀ ní ààrin-gbùngbun sí èrèdí ayé.

Olùgbàlà kọ́kọ́ sọ òwe àwọn wúndíá mẹwa sọ. Nínú òwe yí, àwọn wúndíá mẹwa lọ sí ayẹyẹ ìgbeyàwó. Marun ọlọgbọ́n mú òróró wá láti kún inú fìtílà wọn, márun aláìgbọ́n kò sì ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbàtí a ti kéde dídé ọkọ-ìyàwó; àwọn wúndíá aláìgbọ́n kúrò láti lọ ra òróró. Nígbàtí wọ́n padàdé, ó ti pẹ́ jù; a ti ti ìlẹ̀kùn ibi ayẹyẹ náà.

Jésù yẹ abala mẹ́ta ti òwe náà wò láti ràn wá lọ́wọ́. Ó ṣàlàyé:

“Àti ní ọjọ́ náà, nígbàtí Èmi ó wá nínú ògò mi, ni òwe èyí tí Èmi ti sọ nípa àwọn wúndíà mẹ́wa ó wá sí ìmúṣẹ.

“Nítorí àwọn tí wọ́n jẹ́ ọlọ́gbọ́n tí wọ́n sì gba òtítọ́, àti tí wọ́n ti fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe atọ́nà wọn, tí a kò sì tíì tàn wọ́n jẹ—lootọ ni mo wí fún yín, wọn yíò … gbé ní ọjọ́ náà.”

Ní ọ̀rọ̀ míràn, wọ́n kò nílò láti bẹ̀rù tàbí ní ìtara, nítorí wọn yíò yè wọn yíò sì ṣe rere. Wọn yíò borí.

Bí a bá jẹ́ ọlọ́gbọ́n, a ó gba òtítọ̀ nípa títẹ́wọ́gba ìhìnrere Jésù Krístì nípasẹ̀ àwọn ìlànà àti májẹ̀mú oyè-àlùfáà. Tó tẹ̀le, a ntiraka láti dúró ní yíyẹ ti níní Ẹ̀mí Mímọ́ pẹ̀lú wa nígbàgbogbo. Lílèṣe yí ni a gbọ́dọ̀ gbà níkọ̀ọ̀kan àti níti araẹni, ní díẹ̀ díẹ̀. Ìṣe ìfọkànsìn lemọ́lemọ́, araẹni, ìkọ̀kọ̀, npe Ẹ̀mí Mímọ́ láti tọ́wasọ́nà.

Èròjà kẹ́ta tí Jésù fihàn ní yíyẹra fún ẹ̀tàn. Olùgbàlà kìlọ̀:

“Ẹ kíyèsára kí ẹnikẹ́ni kí ó máṣe tàn yín jẹ.

“Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yíò wá ní orúkọ mi, wípé Èmi ni Krístì; wọn ó sì tan ọ̀pọ̀lọpọ̀ jẹ.”

Olùgbàlà mọ̀ pé àwọn ẹlẹ̀tàn yíò gbìyànjú láti tan àyànfẹ́ gan an jẹ àti pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọẹ̀hìn ni a ó lù ní jìbìtì. A kò níláti gbà àwọn wọnnì tí wọ́n nfi irọ́ gba ìbáwí tọ̀run tàbí wọ inú àkàwé afinjù tàbí ibi ìkọ̀kọ̀ ìyẹ̀wù láti kọ́ni nípa ayédèrú.

Ìwé ti Mọ́mọ́nì kọ́ wa bí a ṣe lè mọ ìyàtọ̀ nínú àwọn ẹlẹ̀tàn kúrò nínú àwọn ọmọẹ̀hìn. Àwọn ọmọẹ̀hìn ngbé ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run ga, sìn In, kí a sì ṣe rere nígbàgbogbo. A ó ni di títànjẹ nígbàtí a bá wá tí a sì gba àmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ àwọn olúkúlùkù tó ṣe gbẹ́kẹ̀lé tí wọ́n jẹ́ olóòtọ́ ọmọẹ̀hìn Olùgbàlà.

Bákannáà a lè yẹra fún ẹ̀tàn nípa jíjọ́sìn déédé nínú tẹ́mpìlì. Èyí nṣe ìrànwọ́ fún wa láti ṣe ìmúdúró ìrísí ayérayé kí ó sì dá ààbó bò wá kúrò nínú àwọn ipa tí ó lè dàláàmú tàbí yí wa kúrò ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú.

Ẹ̀kọ́ pàtàkì nípa òwe wúndíá mẹwa yí ni pé a jẹ́ ọlọ́gbọ́n nígbàtí a bá tẹ́wọ́gba ihìnrere, wá láti ní Ẹ̀mí Mímọ́ pẹ̀lú wa, kí a sì yẹra fún ẹ̀tàn. Àwọn wúndíá marun kò lè ran àwọn tí kò ní òróró lọ́wọ́; kò sí ẹnití ó lè tẹ́wọ́gba ìhìnrere, gba Ẹ̀mí Mímọ́ bí atọ́nà kan, kí wọ́n sì yẹra fún ẹ̀tàn ní ìtìlẹhìn wa. A níláti ṣe èyí fún arawa.

Olùgbàlà lẹ́hìnnáà sọ òwe àwọn tálẹ́ntì. Nínú òwé yí, ọkùnrin kan fi àwọn iye yíyàtọ̀ ti owó, tí a tọ́ka sí bí àwọn tálẹ́ntì, fún àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ mẹ́ta. Sí ìránṣẹ́ kan ó fun ní tálẹ́ntì marun, sí òmíràn ó fun ní méjì, àti sí ìkẹ́ta ó fun ní ọ̀kan. Ní ìgbà díẹ̀, àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ méjì sọ ohun tí wọ́n gbà di ìlọ́po méjì. Ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ kẹ́ta kàn ri tálẹ́ntì rẹ̀ ẹyọkàn mọ́lẹ̀. Sí àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ méjèèjì tí wọ́n sọ tálẹ́ntì wọn di ìlópọ̀ méjì, ọkùnrin náà wípé, “Káàbọ̀, … ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere àti olõtọ́: ìwọ ṣe olõtọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi ó mú ọ ṣe olórí ohun púpọ̀: ìwọ bọ́ sínú ayọ̀ Olúwa rẹ.”

Nígbànáà ọkùnrin náà ba ọmọ-ọ̀dọ̀ náà tí ó ri tálẹ́ntì rẹ̀ mọ́lẹ̀ wí fún jíjẹ́ “ẹni búburú àti onilọra.” Tálẹ́ntì ọmọ-ọ̀dọ̀ yí ni a gbà kúrò, tí a sì le kúrò. Síbẹ̀, kání ọmọ-ọ̀dọ̀ yí sọ tálẹ́ntì rẹ di ìlọ́po méjì, òun ìbá ti gba irú oríyìn kannáà àti èrè bíi ti àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ míràn.

Ọ̀rọ̀ kan nípa òwé yí ni pé Ọlọ́run nretí wa láti gbé àwọn okun tí a ti fún wa ga, ṣùgbọ́n Òun kò fẹ́ kí a fi okun wa wé ti àwọn ẹlòmíràn. Ẹ ronú lórí ìwòye yí tí a pèsè nípasẹ̀ ọmọwé Hasidic scholar Zusya ti Anipol ní sẹ́ntúrì méjìdínlógún. Zusya ni olókìkí olùkọ́ tí ó bẹ̀rẹ̀ láti bẹ̀rù bí òun ti ndé ojú ikú. Àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ bèèrè, “Olùkọ́ni, èéṣe tí ìwọ fi nbẹ̀rù? Ìwọ ti gbé ìgbésí ayé rere; dájúdájú Ọlọ́run yíò fún ọ ní èrè títóbi.”

Zusya wípé: “Bí Ọlọ́run bá wí fún mi pé, ‘Zusya, èéṣe tí ìwọ kìí ṣe Mósè míràn?’ Èmi ó wípé, ‘Nítorí ìwọ kò fún mi ní ẹ̀mí títóbi jùlọ tí ìwọ fún Mósè.’ Àti pé bí mo bá dúró níwájú Ọlọ́run tí Ó sì wípé, ‘Zusya, èéṣe tí ìwọ kìí ṣe Sólómọ́nì míràn?’ Èmi ó wípé, ‘Nítorí ìwọ kò fún mi ní ẹ̀mí títóbi jùlọ tí ìwọ fún Sólómọ́nì.’ Ṣùgbọ́n, wòó, kíni èmi yíò sọ bí mo bá dúró níwájú Aṣẹ̀dá mi tí Ó sì wípé, ‘Zusya, èéṣe tí ìwọ kìí ṣe Zusya? Èèṣe tí ìwọ kìí ṣe ọkùnrin tí mo fún ọ ní agbára láti jẹ́?’ Ah, ìdí ni èyí tí mo fi bẹ̀rù.”

Nítòọ́tọ́, Ọlọ́run yíò ní ìjákulẹ̀ bí a kò bá gbẹ́kẹ̀lé èrè, àánú, àti oore-ọ̀fẹ́ Olùgbàlà láti gbé àwọn okun ìfúnni-Ọlọ́run tí a ti gbà ga. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ìfẹ́ni Rẹ̀, Ó nretí wa láti di ẹ̀yà dídárajùlọ ti arawa. Kí a lè bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn okun yíyàtọ̀ kìí ṣe pàtàkì sí I. Ó sì yẹ́ kí ó jẹ́ bẹ́ẹ̀ sí wa.

Ní òpin, Olùgbàlà sọ òwe àwọn àgùtàn àti ewúrẹ́. Nígbàtí Ó bá pada dé nínú ògo Rẹ̀, “níwájú rẹ̀ ni gbogbo orílẹ̀-èdè yíò kórajọ: òun ó sì ya wọ́n sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ ara wọn, bí olùṣọ́-àgùtàn ti npín àwọn àgùtàn rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ ewúrẹ́: tí yíò si gbé àgùtàn sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ewúrẹ́ ní ọwọ́ òsì.”

Àwọn wọnnì ní ọ̀tún Rẹ̀ di àwọn ajogún nínú ìjọba Rẹ̀, àti pé àwọn wọnnì ní òsì Rẹ̀ kò gba ogún. Ìhùwàsí yíyàtọ̀ ni bóyá wọ́n bọ́ Ọ nígbàtí ebi npa Á, fun Un ní ohun mímu nígbàtí ohungbẹ ngbẹ Ẹ́, fun Un nílé nígbàtí òun jẹ́ àlejò, fun Un laṣọ nígbàtí Òun wà ní ìhòhò, kí ó sì bẹ̀ Ẹ́ wò nígbàtí Ó nṣe àárẹ̀ tàbí wà ní àtìmọ́lé.

Ẹ̀rù ba gbogbo ènìyàn, méjèèjì àwọn wọnnì ní ọ̀tún àti àwọn wọnnì ní òsì. Wọ́n bèèrè ìgbà tí wọ́n ṣeé, tàbí ìgbàtí wọn kò, fún Un ní oúnjẹ, ohun mímu, àti aṣọ tàbí ràn Án lọ́wọ́ nígbàtí Ó wà ní àìlera. Ní ìdáhùn, Olùgbàlà wípé, “Lootọ ni mo wí fún yín, Níwọ̀n tí ẹ bá ti ṣé sí ọ̀kan tó kéréjù lára àwọn arákùnrin mi wọ̀nyí, ẹ ti ṣé sí mi.”

Ọ̀rọ̀ òwe náà hàn kedere: nígbàtí a bá sin àwọn ẹlòmíràn, à nsin Ọlọ́run; nígbàtí a kò bá sìn, a njá A kulẹ̀. Ó nretí wa láti lo àwọn ẹ̀bùn, tálẹ́ntì, àti okun wa láti bùkún àwọn ìgbésí ayé ti àwọn ọmọ Baba Ọ̀run. Ìrò tọ̀run láti sin àwọn ẹlòmíràn ni a júwe nínú ewì tí a kọ ní sẹ́ntúrì mọ́kàndínlógún láti ọwọ́ akéwì Finnish Johan Ludvig Runeberg. Àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò mi àti èmi ṣe àtúngbọ́ ewì náà “Àgbẹ̀ Paavo” ní gbogbo àwọn ìgbà èwe. Nínú ewì náà, Paavo ni àgbẹ̀ tálákà tí ó gbé pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọ mẹwa ní ẹ̀kún lake ti central Finland. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn ní ọ̀nà kan, ni wọ́n ti pa èyí tó pọ̀ jù lọ lára ​​àwọn irè oko rẹ̀ run, yálà nípasẹ̀ ìṣàn omi tí yìnyín ìgbà ìrúwé máa nyọ́, òjò yìnyín ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, tàbí àtètèkọ́ yọ yìnyìn ìgbà ìwọ́wé. Ìgbà kọ̀ọ̀kan tí ìkórè kékere bá wọlé, ìyàwó àgbẹ̀ náà ó pohùnréré pé, “Paavo, Paavo, ìwọ aláìlóríre àgbàlagbà, Ọlọ́run ti pa wá tì.” Paavo, ní ìdáhùn, fi àìjìyan wípé, “Yí jolo pọ̀ pẹ̀lú wóró ìyẹ̀fun láti ṣe búrẹ́dì kí ebi má baà pa àwọn ọmọ. Èmi ó ṣiṣẹ́ àṣekára láti mú pápá Máṣì gbẹ. Ọlọ́run ndán wa wo, ṣùgbọ́n Òun yíò pèsè.”

Ìgbà kọ̀ọ̀kan tí àwọn ohun ògbìn bá di píparun, Paavo ó dárí ìyàwó rẹ̀ láti fi oye jolo tí ó nyípọ̀ sínú ìyẹ̀fun ṣe ìlọ́po méjì láti le ebi kúrò. Bákannáà ó ṣiṣẹ́ àṣekára, ní gbígbẹ́ àwọn àwọn yàrá láti mú ilẹ̀ gbẹ tí yíò sì dín àìlágbára pápá rẹ̀ kù sí orísun àyàngbẹ̀hìn àti ìrẹ̀dànù dídì kùtùkùtù.

Lẹ́hìn àwọn ọdún ìnira, ní òpin Paavo rí ìkórè ọ̀gbìn ọlọ́rọ̀. Ìyàwó rẹ̀ yọ̀, “Paavo, Paavo, ìwọ̀nyí ni ìgbà inúdídùn! Ó jẹ́ àkokò láti ju àwọn jolo nù, kí a sì béèkì búrẹ́dì tí a ṣe pẹ̀lú wóró nìkan.” Ṣùgbọ́n Paavo fi pẹ̀lú ọ̀wọ̀ mú ọwọ́ ìyàwó rẹ̀ ó sì wípé, “Yí ìlàjì ìyèfun pọ̀ pẹ̀lú joro, nítorí pápá aladugbo wa ti di dídì lórí.” Paavo rúbọ ẹ̀bùn ọpẹ́ tirẹ̀ àti ti ẹbí rẹ̀ láti ṣèrànwọ́ fún aladugbo rẹ̀ tó ṣòfò tí ó sì jẹ́ aláìní.

Ẹ̀kọ́ ti òwe Olùgbàlà nípa àwọn àgùtàn àti ewúrẹ́ ni pé a níláti lo àwọn ẹ̀bùn tí a fún wa—ti àkokò, tálẹ́ntì, àti àwọn ìbùkún—láti sin àwọn ọmọ Baba Ọ̀run, nípàtàkì àwọn aláìlera àti aláìní jùlọ.

Ìfipè mi sí ọmọ Alakọbẹrẹ onítara tí mo dárúkọ ṣíwájú, àti sí ọ̀kọ̀ọ̀kan yín, ni láti tẹ̀lé Jésù Krístì kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Ẹ̀mí Mímọ́ bí ẹ ó ti ṣe si ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Ẹ gbẹ́kẹ̀lé àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ràn yín àti ẹnití ó fẹ́ràn Olùgbàlà. Ẹ wá ìtọ̀sọ́nà Ọlọ́run láti mu àwọn okun àìláfiwé yín gbèrú, kí ẹ sì ran àwọn ẹlòmírán lọ́wọ́, àní nígbàtí kò rọrùn. Ẹ ó ṣetán láti pàdé Olùgbàlà, ẹ ó sì lè darapọ̀ mọ́ Ààrẹ Nelson ní jíjẹ́ onírètí pẹ̀lú ayọ̀. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ẹ nṣèrànwọ́ láti múra ayé sílẹ̀ fún Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì ti Jésù Krístì, ẹ ó sì di alábùkúnfún pẹ̀lú ìrètí tótó láti wọnú ìsinmi àti ayọ̀ Olúwa, nisisìyí àti ní ọjọ́ ọ̀la.

Bí a ti nkọrin nínú ọ̀kan lára àwọn orin titun wa:

Yọ̀! Tí a sì nmúrasílẹ̀ fún ọjọ́ náà! …

Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó mọ ọjọ́ náà nígbàtí Òun yíò wá lẹ́ẹ̀kansi,

Ṣùgbọ́n Òun yíò padà wá bí àwọn ìwé mímọ́ ti wí; yíò jẹ́ ọjọ́ aláyọ̀

Nígbàtí àyànfẹ́ Olùgbàlà wa bá wá lẹ́ẹ̀kansi.

Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Russell M. Nelson, “Jésù Krístì Olúwa Yíò Padàwá,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá 2024, 121.

  2. A kò nílò láti ní ìmọ̀lára ìtara, nítorí Jésù Krístì yíò yí wa padà kí a lè ṣetán láti pàdé Rẹ̀. Bí a ti nfi lemọ́lemọ́ bú-ọlá fún àwọn májẹ̀mú wa tí a sì npa àwọn òfin mọ́, à nrọra dà, bíi ti Olùgbàlà púpọ̀ síi àti pupọ̀ síi, nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ àti àwọn ìbùkún. Bí a ti nṣe é, a ó múrasílẹ̀ fún Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Rẹ̀. Bí a ti sọ nínú 1 Johanu 3:2–3:

    “Olùfẹ́, ọmọ Ọlọ́run ni àwa í ṣe nísisìyí, a kò sì tíì fihàn wá bí àwa ó ti rí: ṣùgbọ́n àwa mọ̀ pé, nígbàtí a bá fihàn, a ó dàbí rẹ̀;nítorí àwa ó rí i bí òun ti rí.

    “Olúkúlùkù ẹnití ó bá sì ní ìrètí yí nínú rẹ̀, a wẹ ara rẹ̀ mọ́, àní bí òun ti mọ́.”

  3. Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Olúwa yíò ṣẹlẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ àkokò mìllẹ́níà, nígbàtí Ó bá padà nínú ògo, àti pé gbogbo ènìyàn yíò jẹ́wọ́ pé Òun ti jẹ́ Òun sì ni Mèsíàh tí a ṣèlérí (wo Isaiah 45:23; Zechariah 12:10; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú). 88:104).

  4. Wo Russell M. Nelson, “Ọ̀rọ̀ Ìṣíwájú,” Làìhónà, Oṣù Karun 2020, 6.

  5. Wo Ìyírọ̀padà Joseph Smith, Matteu 25:1 (in Matteu 25:1, footnote a); Matteu 25:1–4, 6–13.

  6. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 45:56-57.

  7. David A. Bednar, “Ìyípadà sí Olúwa,” Lìáhónà, Oṣù Kọkànlá 2012, 109.

  8. Wo 2 Néfì 32:5.

  9. Máttéù 24:4–5.

  10. Wo Joseph Smith—Matteu 1:5–6, 8–9, 21–22, 25–26.

  11. Wo Moroni 7:13, 15–17. Àwọn ìkọ́ni Ìwé ti Mọ́mọ́nì papọ̀ pẹ̀lú ó sì fi àwọn ìkọ́ni bíbélì hàn “sí dídàmú àwọn ayédèrú ẹ̀kọ́” (2 Nefi 3:12). Bóyá èyí ni ara iyè-inú fún ìkọ́ni Ààrẹ Russell M. Nelson pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni ohun èlò tí Ọlọ́run fi múra ayé sílẹ̀ fún Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì (wo “Ìwé ti Mọ́mọ́nì, Kíkójọ Ísráẹ́lì, àti Bíbọ̀Ẹ̀ẹ̀kejì,” Làìhónà, July 2014, 27).

  12. Russell M. Nelson, “Ronú Sẹ̀lẹ́stíà!,” Liahona, Nov. 2023, 118. Ààrẹ Nelson kọ́ni bákannáà: “Ẹ máṣe fi èérí sí [ẹ̀rí yín] pẹ̀lú ìmọ̀ irọ́ ti àìgbàgbọ́ àwọn ọkùnrin àti obìnrin” (“Ẹ Ṣẹ́gun Ayé Kí Ẹ Sì Rí Ìsinmi,” Làìhónà, Nov. 2022, 97). “Ẹ mú ìbèèrè yín tọ Olúwa lọ àti sí àwọn orísun òtítọ́ míràn. … Dáwọ́ mímú iyèméjì pọ̀si dúró nípa títún wọn ṣe pẹ̀lú àwọn olùṣiyèméjì míràn” (“Krístì ti Jínde; Ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀ Yíò Yí àwọn Òkè,” Làìhónà, May 2021, 103). Gẹ́gẹ́bí wòlíì Álmà Ìwé ti Mọ́mọ́nì ṣe dámọ̀ràn, “Ẹ máṣe gbẹ́kẹ̀lé ẹnìkẹ́ni láti jẹ́ olùkọ́ yín tàbí àlùfáà yín, àyàfi tí ó bá jẹ́ ẹni Ọlọ́run, tí ó nrìn ní ọ̀nà rẹ tí ó sì npa àwọn òfin rẹ̀ mọ́” (Mosiah 23:14). Ní àkokò iṣẹ́-ìríjú yí, Olùgbàlà kọ́ wa láti gbẹ́kẹ̀lé àwọn wọnnì “tí wọ́n ní ẹ̀mí ìrora, … tí èdè rẹ ṣe pẹ̀lẹ́, … [tí] ó wàrìrì lábẹ́ agbára mi … àti … òun yíò mú èso ìyìn àti ọgbọ́n jáde wá, gẹ́gẹ́bí àwọn ìfihàn àti òtítọ́ èyí tí mo ti fún yín” (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 52:14–19).

  13. Wo Russell M. Nelson, “Olúwa Jésù Krístì Yíò Wá Lẹ́ẹ̀kansi,” 121.

  14. Nígbàtí a bá ṣe àwọn ìlànà arọ́pò ní ìtìlẹhìn àwọn olóògbé babanlá, àwọn babanlá wọnnì ó pinnu fúnra wọn bóyá wọ́n tẹ́wọ́gba ìhìnrere kí wọ́n sì dúró nínu òtítọ́ tàbí bẹ́ẹ̀kọ́. Aní nínú àwn ipò wọnnì, kò sí ẹnìkankan tí ó nṣe ìpinnu fún ẹlòmíràn.

  15. Wo Máttéù 25:14–30.

  16. Wo Ìtọ́nisọ́nà sí àwọn Ìwé-mímọ́, “Tálẹ́ntì.” Tálẹ́ntì kan ní ìwọ̀n ẹyọ àtijọ́ àti oye owó ní àwọn àkokò Greek àti Roman. A díwọ̀n rẹ̀ pé tálẹ́ntì yẹ fún ẹgbẹ̀eún mẹ́fà dínárì, àti pé nígbàtí dínárì jẹ́ bíi owó ọya ọjọ́ kan fún lébìrà, tálẹ́ntì kanṣoṣo yíò jẹ́ ìdọ̀gba sí bíi owó ọya ogun ọdún fún agbede òṣìṣẹ́.

  17. Matteu 25:21; bákannáà wo ẹsẹ 23.

  18. Wo Máttéù 25:24–26.

  19. Mímú òwe náà gbòòrò, nínú ète inú ti ohun gbogbo, nígbàkan tí ìránṣẹ́ kọ̀ọ̀kan nwọnú ayọ̀ olúwa rẹ̀ àti láti di ajogún sí gbogbo ohun tí olúwa ti ní, ní gbangban, àwọn ìyàtọ̀ díẹ̀ nínú ohun tí ìránṣẹ́ kọ̀ọ̀kan ní ní ìbẹ̀rẹ̀ di pípatì.

  20. Ní àfikún, Olúwa fi tálẹnti tí a tọ́ka sí nínú òwe yí wé onírurú abala ti ìgbé ayé àti ìhìnrere, pẹ̀lú ìmọ̀ àti ẹ̀rí (wo Ẹ́térì 12:35; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 60:2, 13) as well as property and stewardship (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 82:18).

  21. Wo Harold S. Kushner, Bíborí àwọn Ìjákulẹ̀ Ayé (2006), 26.

  22. As stated in Wàásù Ìhìnrere Mi: Ìtọ́nisọ́nà kan sí Pípín Ìhìnrere ti Jésù Krístì (2023), 48, “Gbogbo àwọn ohun tí kò tọ́ nínú ayé ni a lè mú tọ́ nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì.”

  23. Wo Máttéù 25:31–46.

  24. Máttéù 25:32–33.

  25. Wo Matteu 25:37-39, 44.

  26. Máttéù 25:40; bákannáà wo ẹsẹ 45.

  27. Wo Mòsíàh 2:17. À nkópa nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ Olùgbàlà nígbàtí a bá pín ìhìnrere Rẹ̀, ṣèrànwọ́ láti wo ọlọ́kàn ìrora sàn (wo Isaiah 61:1–3àti Luke 4:16–21tu aláìlera nínú, gbé ọwọ́ tó rẹlẹ̀ ga, àti fífún orókún rírọ̀ lókun (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 81:5).

  28. The inner layer of the bark from a birch tree contains some carbohydrates and fiber. A lè parun gẹ́gẹ́bí àbájáde ìkẹhìn.

  29. Wo Johan Ludvig Runeberg, “Högt Bland Saarijärvis Moar,” Idyll och epigram Dikter (1830), nummer 25; Suomen kansalliskirjallisuus (Helsinki, 1941), 9:50–52; sv.wikisource.org/wiki/Högt_bland_Saarijärvis_moar. Ìyírọ̀padà kúrò ní Swedish ni tèmi.

  30. Èyí ni aṣojú ohun tí Ọlọ́run darí àwọn Ísráẹ́lì àtijọ́ láti ṣe: “Nítorípé tálákà kò lè tán lórí ilẹ̀ náà: nítorínáà ni mo ṣe pàṣẹ́ fún ọ, wípé, Kí ìwọ kí ó la ọwọ́ rẹ fún arákùnrin rẹ, fún tálákà rẹ̀, àti fún aláìní rẹ̀” (Deuteronomy 15:11).

  31. Wo Dallin H. Oaks, “Mímúrasílẹ̀ fún Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì,” Làìhónà, Oṣù Karun 2004, 7-10, fún ìwàásù oníyanu nípa Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì àti àwọn ọ̀nà láti múrasílẹ̀ fún un.

  32. Russell M. Nelson, “Ẹ Ṣẹ́gun Ayé kí ẹ sì Rí Ìsinmi,” 95–98. Ààrẹ Nelson kọ́ni, “Ohun èlò pàtàkì kan nípa kíkójọ yí ni mímúra àwọn ènìyàn kan sílẹ̀ tí wọ́n léṣe, tí wọ́n ṣetán, tí wọ́n sì yẹ láti gba Olúwa nígbàtí Ó bá wá lẹ́ẹ̀kansi; àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ti yan Jésù Krístì lórí ayé ìṣubú yí; àwọn ènìyàn kan tí wọ́n láyọ̀ nínú agbára òmìnira wọn láti gbé ìgbé ayé gíga jù, mímọ́ jù àwọn òfin Jésù Krístì” (“Ẹ Ṣẹ́gun Ayé kí Ẹ sì Rí Ìsinmi,” 98).

  33. Wo Mórónì 7:3. Ààrẹ Joseph F. Smith kọ́ni: “Ìsinmi … tọ́ka sí kìí ṣe ìsinmi ti ara . … [Ó jẹ́] ìsinmi ti ẹ̀mí àti àláfíà èyí tí ó jáde látinú ìdánilójú tó dúró nípa òtítọ́. … Báyìí a lè wọlé sínú ìsinmi Olúwa ní òní, nípa wíwá sí níní ìmọ̀ ti àwọn òtítọ́ ìhìnrere. … [Àwọn wọnnì tí wọ́n ti wọnú ìsinmi yí ni àwọn wọnnì] tí a ti tẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn, àti ẹni tí ó ti fi ojú rẹ̀ lé àmì ti ìpè gíga wọn pẹ̀lú ìpinnu àìrí nínú ọkàn wọn láti dúró ṣinṣin nínú òtítọ́, àti tí wọ́n nrìn nínú ìrẹ̀lẹ̀ àti òdodo ipa-ọ̀nà tí a fàmì sí fún … àwọn ọmọlẹ́hìn Jésù Krístì. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni wọ́n wà tí, wọ́n ti dé àmì ti ìdánilójú ìpinnu yí, ni à ndarí nípa gbogbo afẹ́fẹ́ ẹ̀kọ́, báyìí ndi aláárẹ̀ ní ìrọ̀rùn, àìbalẹ̀, àìsinmi. Ìwọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n ní ìjákulẹ̀ lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ nínú Ìjọ, àti nínú Orílẹ̀-èdè, àti nínú ìrúkèrúdò àwọn ènìyàn. … Wọ́n gba ìmọ̀lára ìfura, àìsinmi, àìní-ìdánilójú. A dà àwọn èrò wọn láàmú, wọ́n sì ní inú dídùn pẹ̀lú ìyípadà kíkéréjù, bíiti ọ̀kan ní òkun tí ó ti sọ wíwà rẹ̀ nù” (Ẹ̀kọ́ Ìhìnrere, 5th ed. [1939], 126).

  34. “Nígbàtí Olùgbàlà Bá Wá Lẹ́ẹ̀kansi,” Àwọn Orin—Fún Ilé àti Ìjọ, Ibi Ìkàwé Ìhìnrere.