Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìmúláradá Níti Ẹ̀mí nínú Rẹ̀
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2025


11:28

Ìmúláradá Níti Ẹ̀mí nínú Rẹ̀

Ìmúláradá kò fi dandan túmọ̀ sí ìmúpadàbọ̀sípò ti ara àti ẹ̀dùn ọkàn nínú ìgbésí-ayé yi. Ìmúláradá ni a bí nípa ìgbàgbọ́ nínú àti ìyípadà sí Jésù Krístì.

Àwọn adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá kígbe sí Olùgbàlà, “Ṣàánú fún wa.” Jésù Kristi sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sọ fún wọn pé kí wọ́n fi ara wọn hàn fún àlùfáà, àti pé bí wọ́n sì ti lọ, a wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò nínú àrùn náà.

Ó sì ṣe ọ̀kan nínú wọn, nígbàtí o rí i pé ara òun ti dá, ó kígbe ìyìn sí Ọlọ́run. Ó padà sọ́dọ̀ Olùgbàlà, ó wólẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó sì fi ìmoore hàn.

Olùgbàlà sì sọ fún ẹnití ó dúpẹ́ wípé, “Ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ láradá.”

Jésù Kristi ti wo àwọn adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá sàn. Ṣùgbọ́n ọ̀kan, tí ó padà sọ́dọ̀ Olùgbàlà, gba ohun kan ní àfikún. A mú un láradá.

Àwọn adẹ́tẹ̀ mẹ́sàn-án ni a wò sàn.

Ọ̀kan ni a múlárada nípa ti ara ó sì di mímúláradá níti ẹ̀mí.

Ní ṣíṣe àròjinlẹ̀ ìtàn yi, mo ti ní ìyàlẹ́nu bóyá ọ̀rọ̀ náà jẹ́ òtítọ́. Tí ìwòsàn àti ìmúláradá kò bá jẹ́ bákannáà, ṣé a le mú ènìyàn láradá níti ẹ̀mí láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀ kò má ní ìwòsàn níti ara àti ẹ̀dùn-ọkàn?

Ọ̀gá Olùwòsàn yíò wo gbogbo àwọn ìpọ́njú wa sàn—níti ara àti ẹ̀dùn-ọkàn—ní àkókò Rẹ̀. Ṣùgbọ́n nínú dídúró láti jẹ́ wíwòsàn, ṣé ẹnìkan le di mímúláradá?

Kí ló lè túmọ̀ sí láti jẹ́ mímúláradá níti ẹ̀mí?

Àwa di mímúláradá nínú Jésù Krístì nígbàtí a bá lo agbára òmìnira wa láti tẹ̀le E nínú ìgbàgbọ́, fi ọkàn wa sílẹ̀ fún Un kí Ó le yí wọn padà, pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, tí a sì wọ inú ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ̀, tí a nfi ọkàn tútù forítì tí a sì nkọ́ ẹ̀kọ́ láti inú àwọn ìpèníjà ti ipò ayé-ikú yi títí tí a ó fi padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ tí a ó sì mú wa láradá ní gbogbo ọ̀nà. Mo le jẹ́ mímúláradá nígbàtí mo ndúró fún ìwòsàn tí mo bá fi gbogbo ọkàn mi ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀.

Ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì máa nbí ìrètí. Mo rí ìrètí nínú lílàkàkà láti jẹ́ mímúláradá—ìmúláradá tí a bí nípa ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì. Ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀ nmú kí ìrètí mi fún ìwòsàn pọ̀ síi, ìrètí náà sì fún ìgbàgbọ́ mi nínú Jésù Kristi lágbára. Ó jẹ́ ìyípo tí ó lágbára.

Olúwa sọ fún Énọ́sì pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ ti mú un “láradá.” Ìmúláradá wá bí Énósì ṣe ronújinlẹ̀ lórí àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì-baba rẹ̀ Jákọ́bù, bí ó ti pebi láti lóye ànfààní fún ìyè ayérayé, bí ó ti képe Ọlọ́run nínú àdúrà nlá. Àti pé nínu ipò ti ìfẹ́ àti ìrẹ̀lẹ̀ yi, ohùn Oluwa tọ̀ ọ wá, ti o kéde pé a ti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ rẹ̀ jì í. Énósì sì bèrè lọ́wọ́ Olúwa pé, “Báwo ni a ti ṣe é?” Olúwa sì dáhùn pé, “Nítorí ìgbàgbọ́ rẹ nínú Krístì, … ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ láradá.”

Nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì, a lè lépa láti jẹ́ mímúláradá níti ẹ̀mí nígbàtí a bá dúró tí a sì ní ìrètí fún ìwòsàn ti ara àti ti ẹ̀dùn ọkàn.

Nípasẹ̀ ẹbọ ètùtù Rẹ̀, àti nígbàtí a bá ronúpìwàdà tọkàntọkàn, Olùgbàlà wò wá sàn kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀, bí Ó ti ṣe pẹ̀lú Énósì. Ètùtù Rẹ̀ tí kò lópin bákannáà débi ìbànújẹ́ àti ìrora wa.

Ṣùgbọn Ó le má pèsè ìwòsàn kúrò nínú àìsàn àti àrùn—ìrora líle, àrùn àjogúnbá bí i onírúurú àrùn iṣan, jẹjẹrẹ, àníyàn, ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Ìrú ìwòsàn náà wà ní àkókò Olúwa. Àti ní báyìí ná, a lè yàn láti jẹ́ mímúláradá nípa lílo ìgbàgbọ́ wa nínú Rẹ̀!

Láti jẹ́ mímúláradá túmọ̀ sí láti wà ní pípé àti kíkún. Gẹ́gẹ́bí àwọn wúńdíá ọlọ́gbọ́n máàrùn tí àwọn fìtílà wọn kún fún òróró nígbàtí ọkọ ìyàwó dé, a lè jẹ́ mímúláradá nínú Jésù Kristi bí a ṣe nkún fìtílà wa pẹ̀lú òróró afúnnilókun ti yíyípadà sí Ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ní ọ̀nà yí, a ti múra sílẹ̀ de ṣíṣe àpẹrẹ oúnjẹ alẹ́ ìgbéyàwó, Bíbọ̀ Rẹ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì.

Nínú òwe náà gbogbo àwọn wúńdíá mẹ́wẹ̀wá náà wà ní ibi tó yẹ, wọ́n ndúró de ọkọ ìyàwó. Olúkúlukú wọn wá pẹ̀lú fìtílà kan.

Ṣùgbọ́n nígbàtí Ó dé, ní wákàtí ọ̀gànjọ́ òru tí a kò retí, àwọn aláìgbọ́n máàrùn náà kò ní òróró tí ó tó fún fìtílà wọn. Wọn kò ṣe àpèjúwe wọn bí ènìyàn búburú ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ bíi aláìgbọ́n. Àwọn aláìgbọ́n kùnà láti múra sílẹ̀ dáadáa láti mú kí fìtílà wọn máa jó pẹ̀lú òróró ìyípadà.

Ati nítorínáà, ní ìdáhùn sí ẹ̀bẹ̀ wọn pé kí wọ́n yọ̀ọ̀da fún wọn láti wọ inú oúnjẹ alẹ́ ìgbéyàwó náà, ọkọ ìyàwó dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò mọ̀ mí.”

Tó túmọ̀sí, nígbànáà, wípé àwọn wùndíá ọlọ́gbọ́n márun náà wọ́n mọ̀ Ọ́. Wọ́n wà ní ìmúláradá nínú Rẹ̀.

Àwọn fìtílà wọn kún fún òróró iyebíye, ti ìyípadà tí ó gba àwọn wúndíá ọlọgbọ́n láàyè láti wọ inú àjọ ìgbeyàwó ní ọwọ́ ọ̀tún ọkọ ìyàwó.

Bí Olùgbàlà ti fi hàn, “Ẹ jẹ́ olóòótọ́, ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ tún àwọn fìtílà yín ṣe kí wọ́n sì máa jó, àti òróró pẹ̀lú yín, kí ẹ lè jẹ́ mímúra sílẹ̀ dí dídé Ọkọ Ìyàwó.”

Àwọn Wúndíá Ọlọgbọ́n Marun, láti ọwọ́ Ben Hammond

Àwọn Wúndíá Ọlọgbọ́n Marun, láti ọwọ́ Ben Hammond

Àwòrán tí ó wuyì kan tí ó nṣàfihàn Àwọn Wúndíá Ọlọgbọ́n Márun ni a gbé láìpẹ́ yìí sórí Igun Tẹ́mpìlì ní ìta àwọn ilẹ̀kùn sí Ilé Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ àti nínú òjìji ti Tẹ́mpìlì ìlú Salt Lake.

Ó jẹ́ ipò tí ó yẹ fún lílò ti òwe náà. Nítorípé nígbàtí a bá dá tí a sì pa àwọn majẹmu mọ, paapaa àwọn tí ó wà ní àrọ́wọ́tó nínú ilé Olúwa, a nkún àwọn fìtílà wa pẹ̀lú òróró ìyipadà.

Àwọn Wúndíá Ọlọgbọ́n Máàrún pín ìmọ́lẹ̀ wọn.
Àwọn Wúndíá Ọlọgbọ́n Marun nṣe àtìlẹhìn fún ara wọn.

Nígbàtí àwọn obìnrin náà ṣe aṣojú bíi àwọn wúndíá ọlọgbọ́n marun tí wọn kò pín òróró iyípadà wọn, wọ́n nṣe àbápín ìmọ́lẹ̀ wọn bí wọ́n ṣe gbé àwọn fìtílà wọn sókè, èyítí ó kún fún òróró tí ó sì njó ní títànmọ́lẹ̀. Nípàtàkì wọ́n ṣe àpẹrẹ wọn pé wọ́n nti ara wọn lẹ́hìn—èjìká sí èjìká, apá kan yíká òmíràn, ní wíwo ojú ara wọn nṣẹ́wọ́ sí àwọn miran láti wá sínú ìmọ́lẹ̀.

Nítòótọ́, “[Àwa] ni ìmọ́lẹ̀ ayé.” Olùgbàlà kéde pé:

“Mo fi fún yín kí ẹ̀yin ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀ àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Ìlú tí a tẹ̀dó sórí òkè kò lè farasin.

“… Njẹ́ [a] tan àbẹ́là kan kí a sì gbé e sábẹ́ àgbénákà kan bi? Rárá, ṣùgbọ́n lórí ọ̀pá fìtílà; òun a sì fi ìmọ́lẹ̀ [fún] gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ilé;

“Nítorínáà ẹ jẹ́kí ìmọ́lẹ̀ yín ó tàn tóbẹ́ẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn yí, kí wọn ó le rí iṣẹ́ rere yín kí wọn ó le máa yin Baba yín [èyítí] mbẹ ní ọ̀run lógo.”

A pàṣẹ fún wa láti pín ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀. Nítorínáà ẹ jẹ́ kí fìtílà yín kún fún òróró ìyípadà sí Jesu Kristi kí ẹ sì múra láti tún fìtílà yín ṣe kí ó sì máa jó. Lẹ́hìnnáà jẹ́kí ìmọ́lẹ̀ náà ó tàn. Nígbàtí a bá pín ìmọ́lẹ̀ wa, a nmú ìdẹ̀rùn Jésù Krístì wá fún àwọn ẹlòmíràn, ìyípadà wa sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ njinlẹ̀ síi, àti pé a le di mímúláradá àní nígbàtí a ndúró fún ìwòsàn. Bí a sì ṣe njẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa máa tàn yòò, a lè kún fún ayọ̀ àní bí a ti ndúró.

Àpẹrẹ ti ìwé mímọ́ kan wúlò nínú fífi ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ náà múlẹ̀ pé a lè jẹ́ mímúláradá bí a ṣe ndi yíyípadà sí Jésù Kristi tí a sì ngba okun láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, àní bí a ti ndúró fún ìwòsàn.

Àpóstélì Páùlù náà ní irú ìpọ́njú kan—ohun tí ó ṣàpèjúwe bíi “ẹ̀gún kan nínú ẹran ara,” èyítí ó ti sọ ní ìgbà mẹ́ta pé kí Olúwa mú kúrò. Olúwa sì wí fún Paulu pé, “Ore-ọ̀fẹ́ mi tó fún ọ: nítorí a sọ agbára mi di pípe nínú àìlera.” Sí èyítí Páulù kéde:

“Nítorí náà tayọ̀tayọ̀ ni èmi yóò fi … ṣògo nínú àìlera mi, kí agbára Kristi lè bà lé mi.

Nítorínáà mo ní inú dídùn sí àìlera, … nínú àwọn wàhálà nítorí Kristi: nítorí nígbàtí mo bá jẹ́ aláìlera, nígbànáà ni mo ṣe alágbára.”

Àpẹrẹ Paulu dábàá pé àní nínú àìlera wa, agbára wa nínú Krístì ni a le sọ di pípé—ìyẹn ni pé, pátápátá àti ìmúláradá. Àwọn wọnnì tí wọ́n njìjàkadì pẹ̀lú àwọn ìlàkàkà aye-íkú tí wọ́n sì yí sí Ọlọ́run nínú ìgbàgbọ́ bíi Paulu lè gba àwọn ìbùkún dídi ojúlùmọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.

A kò wo Paulù sàn nínú ìpọ́njú rẹ̀, ṣùgbọ́n ó jẹ́ mímúláradá nípa ti ẹ̀mí nínú Jésù Kristi. Àti pé nínú ìpọ́njú rẹ̀ pàápàá, ìmọ́lẹ̀ ìyípadà rẹ̀ sí àti agbára láti ọ̀dọ̀ Jésù Krístì ntàn, ó sì láyọ̀. Nínú èpístélì rẹ̀ sí àwọn ará Fílípì, ó kígbe pé, “Ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa nígbà[gbogbo]: mo sì tún tunsọ wípé, Ẹ yọ̀.”

Ẹ̀yin arábìnrin àti arákùnrin, ìdáhùn náà jẹ́ bẹ́ẹ̀ni, a le jẹ́ mímúláradá nípa ti ẹ̀mí, àní bí a ti ndúró fún ìwòsàn níti ara àti ẹ̀dùn ọkàn. Ìmúláradá kò fi dandan túmọ̀ sí ìmúpadàsípò ti ara àti ẹ̀dùn ọkàn nínú ìgbésí-ayé yi. Ìmúláradá ni a bí nípa ìgbàgbọ́ nínú àti ìyípadà sí Jésù Krístì àti ní jíjẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ ìyípadà náà ó tàn.

“Ọ̀pọ̀ la pè, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni a [yàn láti jẹ́] àyànfẹ́.”

Gbogbo ènìyàn ni yíò wà nínú ìwòsàn nípa ti ara àti ẹ̀dùn-ọkàn ní Àjínde. Ṣùgbọ́n ṣé ìwọ yíò yan nísínsìnyí láti jẹ́ mímúláradá nínú Rẹ̀?

Mo kéde pẹ̀lú ayọ̀ pé mo ti yípadà sí Olúwa Jésù Krístì. Mò ngbìyànjú láti jẹ́ mímúláradá nínú Rẹ̀. Ó dámi lójú pé ohun gbogbo yíò padàbọ̀sípò ìwòsàn yíò sì dé, ní àkókò Rẹ̀, nítorípé Ó wà láàyè.

Màríà Magidalénì jẹ́ obìnrin kan tí a múláradá nípasẹ̀ Jésù Kristi. Ó sì jẹ́ obìnrin mímúláradá nínú Jésù Kristi. Gẹ́gẹ́bí ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀ ó tẹ̀lé Olùgbàlà jákèjádò Gálílì ó sì ṣe ìránṣẹ́ fún Un.

Ó wà níbẹ̀ ní ẹsẹ̀ àgbélébu, ẹlẹ́ri kan sí ikú Rẹ̀.

Ó lọ sí ibojì rẹ̀ láti parí ìmúrasílẹ̀ ìsìnkú rẹ̀ ó sì rí i pé a ti gbé òkúta ìbòrí ibojì náà kúrò, pé ara Olúwa ti lọ. Màríà wà níbi ibojì náà ó nsọkún nígbàtí wọ́n bií léèrè, lákọ̀ọ́kọ́ láti ẹnu àwọn áńgẹ́lì àti lẹ́hìnnáà láti ẹnu Olùgbàlà fúnra rẹ̀, “Obìnrin, èéṣe tí ìwọ nsọkún? Tani ìwọ nwá?”

Màría kígbe pé, “Wọ́n ti gbé Olúwa mi lọ, èmi kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.”

Jésù sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ pe orúkọ rẹ̀ pé, “Màríà.” Ó sì dá A mọ̀ ó sì fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ dáhùn pé, “Ràbbónì … Olùkọ́.”

Sísọtẹ́lẹ̀ nípa Olùgbàlà, Isáíàh sọ pé, “Yíò gbé ikú mì ní ìṣẹ́gun; Olúwa Ọlọ́run yíò sì nu omijé nù kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.”

Àjínde Rẹ̀ jẹ́kí a nu omijé Màríà nù. Dájúdájú Òun yíò nu tìrẹ náà nù.

Màríà jẹ́ ẹlẹ́ri àkọ́kọ́ Olùgbàlà tí ó jínde. Òun sì ni ẹni àkọ́kọ́ tó jẹ́rìí sí àwọn ẹlòmíràn nípa ohun tó ti rí.

Mo fi ìrẹ̀lẹ̀ fi ẹ̀rí mi kún ti Màríà. Ó ti jínde. Jésù Krístì wà láàyè. Nígbẹ̀hìn ẹni gbogbo ni a ó wò sàn, níti ara àti níti ẹ̀dùn ọkàn, nínú Rẹ̀. Àti pé nínú dídúró de ìwòsàn náà, ìgbàgbọ́ nínú Ọ̀gá Olùwòsàn náà yíò mú wa láradá níti ẹ̀mí. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Wo Lúkù 4:16-19 Ọ̀rọ̀ náà “mú láradá” ni a túmọ̀ láti inú ọ̀rọ̀ Greek kan tó túmọ̀ sí láti pamọ́, láti gbà sílẹ̀, láti dánidè, tàbí láti wòsàn. Iyẹn dabi ẹnipe o fẹnutẹ́ otitọ pataki ti Jesu Kristi le mu wa láradá nipa ti ara àti Ó tún le gbà, yọ, pamọ́, àti wòsàn ní àwọn ọ̀nà míran.

  2. Wo Álmà 40:23: “Ẹ̀mí yóò padà sí ara, àti ara sí ọkàn; bẹ́ẹ̀ni, àti gbogbo ẹsẹ̀ àti ìsẹ́po ni aó dá padà sí ara rẹ̀; nítòótọ́, àni irun orí kan kì yio sọnù; ṣùgbọ́n ohun gbogbo ni aó múpadàbọ̀sípò sí ipò dídára àti pípé rẹ̀.” Tún wo Russell M. Nelson, “Jésù Krístì—Ọ̀gá Olùwòsàn,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2005, 87: “Ẹ̀bùn àjínde ni ìṣe ìwòsàn pípé ti Olúwa.”

  3. Wo Mórónì 7:40–42.

  4. Énósì 1:8.

  5. Ẹ́nọ́sì 1:7

  6. Énósì 1:8.

  7. Wo Máttéù 25:1–13.

  8. Òmùgọ̀ nítorí pé wọn kò rò pé níní òróró àfikún ṣe pàtàkì tàbí dandan.

  9. Ìyírọ̀padà èdè Joseph Smith, Máttéù 25:12 (in Máttéù 25:12, àkọsílẹ̀ ránpẹ́ a).

  10. Níti òwe àwọn wúndíá mẹ́wa, Alàgbà Bednar kọ́ni:

    “Jọ̀wọ́ ronú nípa àwọn fìtílà tí àwọn wúńdíá lò gẹ́gẹ́bí fìtílà ẹ̀rí. Àwọn wundia òmùgọ̀ náà gbé fìtílà ẹ̀rí wọn ṣugbọn wọn kò mú òróró. Ro òróró náà láti jẹ́ òróró ìyípadà. …

    “Ṣé àwọn wúńdíá ọlọ́gbọ́n márùn-ún náà jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan tí wọn kò sì fẹ́ láti ṣàjọpín, tàbí wọ́n ntọ́ka sí lọ́nà tó tọ́ pé a kò lè yá òróró ìyípadà? Njẹ́ a lè fi agbára ti ẹ̀mí tí ó ńjáde láti inú gbígbọ́ran léraléra sí àwọn òfin fún àwọn ènìyàn míràn bí? Ǹjẹ́ ìmọ̀ tí a nrí gbà nípasẹ̀ kíkẹ́kọ̀ọ́ taápọntaápọn àti ṣíṣàṣàrò lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà lè jẹ́ sí ẹnití ó nílò rẹ̀? Njẹ́ àlàáfíà tí ìhìnrere ti múwá fún olùsòtítọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn le jẹ́ gbígbé lọ sí ọ̀dọ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó ní ìrírí ìpọ́njú tàbí ìpènijà nla? Ìfèsì sí gbogbo àwọn ìbèèrè wọ̀nyí ni bẹ́ẹ̀kọ́!

    Ó tẹ̀ síwájú láti ṣàlàyé pé a ní “ojúṣe ẹnìkọ̀ọ̀kan láti jẹ́ kí fìtílà ẹ̀rí wa máa jó àti láti gba ìpèsè tí ó pọ̀ tó ti òróró ìyípadà. Epo iyebíye yi ni a rí gbà ní ẹyọ kan nií àkókò kan—‘ẹsẹ lórí ẹsẹ [àti] ìlànà lórí ìlànà’ (2 Néfì 28:30), pẹ̀lú sùúrù àti aláìdúró. Kò sí ọ̀nà àbùjá; kò sí-ìrúsókè ìmúrasílẹ̀ ìgbẹ̀hìn tí ó ṣeéṣe” (“Ìyípadà sí Olúwa,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá. 2012, 109).

  11. Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 33:17. Ààrẹ Russell M. Nelson ti gbani nímọ̀ràn: “Nísisìyí ni àsìkò fún ẹ̀yin àti fún èmi láti múrasílẹ̀ fún Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì ti Olúwa àti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì náà. Bayi ni àkokò náà fún wa láti mú jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn wa jẹ́ ààyò gígajùlọ wa” (“Olúwa Jésù Krístì Yóò Padà Lẹ́ẹ̀kansíi,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá. 2024, 121).

  12. Olùgbẹ́ ère ti Àwọn Wúndíá Ọlọgbọ́n Marun jẹ́ olórin Ben Hammond, ẹnití ó ṣe àfihàn àwọn wúndíá ọlọgbọ́n marun náà gẹ́gẹ́bí àwọn obìnrin ti onírúurú ọjọ́-orí àti ẹ̀yà, ti o nsoju oríṣiríṣi àwọn obìnrin tí ó jẹ́ ọmọ ẹ̀hìn Jésù Krístì tí ó yípadà.

  13. Nígbàtí a bá ṣe alábapín oúnjẹ Olúwa, a sọdọ̀tun gbogbo àwọn májẹ̀mú tí a ti ṣe pẹ̀lú Olúwa a sì dá májẹ̀mú titun kan pé a fẹ́ láti gba orúkọ Jésù Krístì sórí wa àti láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́. Ìkópa mímọ́ tí ó yẹ nínú àwọn ìlànà oyè àlùfáà àti ṣíṣe àti pípa àwọn májẹ̀mú mọ njẹ́ kí a di mímúláradá. Ìlàná yíi jẹ́ àfihàn dáradára ní orin ìyìn sácrámẹ́ntì “Búrẹ́dì ti Ìyè, Omi Ìyè

    “Búrẹ́dì ti Ìyè, Omi Ìyè,

    Bọ́ ọkàn mi, kún ọkàn mi.

    Olúwa, fún mi ní ayé titun nínú Rẹ

    Kí o sì sọ mí di mímúláradá—pípé àti mímọ́—

    Sísopọ̀ mọ́ Ọ láéláé.”

    Àwọn Orin—Fún Ilé àti Ìjọorí. 1008, Yàrá Ìkàwé Ìhìnrere; a ṣe Àfikùn).

  14. Máttéù 5:14.

  15. 3 Néfì 12:14–16.

  16. Nínú àwọn ọ̀rọ̀ orin alárinrin kan:

    Ìmọ́lẹ̀ kékeré tèmi yi, Èmi yóò jẹ́ kí ó tàn. …

    Níbikíbi tí mo bá lọ, Èmi yóò jẹ́ kí ó tàn. …

    Jésù ló fi fún mi; Èmi yóò jẹ́ kí ó tàn.

    Jẹ́kí ó tàn, Jẹ́kí ó tàn, Jẹ́kí ó tàn.

    (“Ìmọ́lẹ̀ kékeré tèmi yi,” Àwọn Orin—Fún Ilé àti Ìjọ, Yàrá I`kàwé Ìhiinrere.)

  17. 2 Kọ́ríntì 12:7

  18. Wo 2 Kọ́ríntì 12:8

  19. 2 Kọ́ríntì 12:9

  20. 2 Kọ́ríntì 12:9–10

  21. Fílípì 4:4; tún wo 2 Kọ́ríntì 1:3–4: “Ìbùkún ni fún Ọlọ́run, àní Baba Olúwa wa Jésù Krístì, Baba àláanú, àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo; ẹnití ntù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa, kí àwa lè tu àwọn tí ó wà nínú ìdààmú èyíkéyìí nínú, nípa ìtùnú tí àwa fúnra wa fi rí ìtùnú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”

  22. Wo David A. Bednar, “Gbé Agbára Rẹ Wọ̀, Ìwọ Síónì,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá. 2022, 94.

  23. Máttéù 22:14; tún wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 121:34–35.

  24. Wo Lúkù 8:2–3.

  25. Wo Jòhánnù 14:15

  26. Jòhánnù 20:15; tún wo ẹsẹ 13.

  27. Jòhánnù 20:13.

  28. Jòhánnù 20:16.

  29. Isáíàh 25:8.