Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìsanpadà Àwọn Ìbùkún
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2025


11:18

Ìsanpadà Àwọn Ìbùkún

Mo jẹri pé lakoko tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ipò ní ìgbésí ayé le kọjá ìṣàkóso wa, kò sí ọ̀kan nínú wa tí ó kọjá ìnawọ́sí àwọn ìbùkún àìlópin ti Olúwa.

Sísìn nínú Bìṣọ́príkì, mo ti ní ànfàní láti pàdé àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-i`kẹhìn láyiká àgbáyé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibi àti àwọn àṣà. Mo ti ní ìmísí nígbàgbogbo nípasẹ ìgbàgbọ́ àti ìfọkànsìn yín tí ó dúró sí Olúwa Jésù Krístì. Síbẹ̀síbẹ̀ èmi náà ti gbé nípasẹ̀ oríṣiríṣi àti ipò ìṣòro tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yín ndojú kọ—àwọn ìpèníjà bí àìsàn, àìlera, àwọn ohun èlò tó lópin, àwọn àyè díẹ̀ fún ìgbéyàwó tàbi ẹ̀kọ́, ìlòkulò nípasẹ̀ àwọn miran, àti àwọn ìdíwọ́ tábi ìhámọ́ miran. Nígbàmíràn ẹ̀wẹ̀, ó lè dà bíi pé àwọn àdánwò wọ̀nyí ndí ìlọsíwájú yín lọ́wọ́ kí ó sì pe ìtiraka tòótọ́ yín láti gbé ìhìnrere náà ní kíkún, tí ó sì nmu ṣòro síi láti sìn, jọ́sìn, àti láti mú àwọn ojúṣe mímọ́ ṣẹ.

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, tí ẹ̀yin bá ní ìmọ̀lára ìdíwọ́ tàbí àìdára nípa àwọn ipò ìgbésí ayé yín, mo fẹ́ kí ẹ mọ èyí: Olúwa nífẹ̀ẹ́ yín níti araẹni. Ó mọ àwọn ipò yín, àti pé ilẹ̀kùn sí àwọn ìbùkún Rẹ̀ wà ní ṣíṣí sílẹ̀ fún yín láìbìkítà àwọn ìpèníjà tí ẹ nkojú.

Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ yìí nípasẹ̀ ìrírí araẹni pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dà bíi pé kò já mọ́ nkan kan, ó fi ìmọ̀ràn pípẹ́ títí sílẹ̀ fún mi. Nígbàtí mo pé ọmọ ọdún méjìlélógún, nígbàtí mo nsìn ní Ẹgbẹ́ Ológun Òfúrufú ti Faransé ní Paris, inú mi dùn láti gbọ́ pé Alàgbà Neal A. Maxwell, Àpóstélì Olúwa, yíò máa sọ̀rọ̀ ní ìpàdé gbogbogbò kan ní Champs-Élysées. Ṣùgbọ́n, ní kété ṣáájú ìṣẹ̀lẹ̀ náà, mo gba àṣẹ láti wakọ̀ ọ̀gá àgbà kan lọ sí pápákọ̀ òfúrufú ní àkókò náà pàtó tí ìpàdé gbogbogbò náà yíò wáyé.

Mo ní ìjákulẹ̀. Níwọ̀n bí mo ti pinnu láti lọ, mo gbé ọ̀gá àgbà náà débẹ̀ mo sì sáré lọ sí ìpàdé àpapọ̀ náà. Lẹ́hìn tí mo ti rí ibùdó ọkọ̀ kan láti pa ọkọ̀ mọ́ sí, mo sáré lọ síbi tí wọ́n ti nṣè ìpàdé ní Champs-Elysées mo sì gúnlẹ̀ láìní èémí ní ìṣẹ́jú máàrún péré tó kù kí ìpàdé tó parí. Bí mo ṣe wọlé, mo gbọ́ Alàgbà Maxwell tí ó sọ pé, “Èmi yíò fún ọ ní ìbùkún àpọ́stélì.” Ní ojú ẹsẹ̀ náà, mo ní ìrírí, mánigbàgbé ti ẹ̀mí tó rẹwà. Ẹ̀mí borí mi, àti pé àwọn ọ̀rọ̀ ìbùkún náà dàbi ẹnipé wọ́n wọ gbogbo okun ti ẹ̀mí mi bí ẹnipé wọ́n ṣètò wọn fún èmi nìkan.

Ohun tí mo ní ìrírí ní ọjọ́ náà jẹ́ ìfarahàn kékeré ṣùgbọ́n tí ó lágbára ti apákan títuni-nínú ti ètò Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Rẹ̀: Nígbàtí àwọn ipò tí ó kọjá agbára wa bá dí wa lọ́wọ́ láti mú àwọn ìfẹ́-inú òdodo wa ṣẹ, Olúwa yíò san án padà ní àwọn ọ̀nà tí yíò jẹ́ kí a gba àwọn ìbùkún tí Ó ṣèlérí.

Òtítọ́ tí ntúni dálójú yìí wà nínú àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ pàtàkì mẹ́ta tí a rí nínú ìhìnrere Jésù Krístì tí a múpadàbọ̀sípò:

  1. Ọlọrun fẹ́ràn ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ní pípé. “Ó pe gbogbo [wa] láti wá sọ́dọ̀ rẹ̀ kí a sì ṣe alabapin ti oore rẹ̀.” Ètò ìràpadà rẹ̀ ní ìdánilójú pé gbogbo ènìyàn, láìsí ìyàsọtọ̀, ni a ó fún ní àyè òdodo láti gba àwọn ìbùkún ìgbàlà àti ìgbéga ní ọjọ́ kan.

  2. Nítorípé Ọlọ́run jẹ́ olódodo àti aláanú àti pé ètò Rẹ̀ pé, Òun kì yóò mú wa jíyìn fún àwọn ohun tí ó kọjá ìṣàkóso wa. Alàgbà Neal A. Maxwell ṣàlàyé pé “Ọlọ́run … gbà sínú àkọsílẹ̀ aláanú kì í ṣe àwọn ìfẹ́-inú wa àti iṣẹ́ wa nìkan, ṣùgbọ́n àwọn ìwọ̀n ìṣòro tí onírurú ipò wa ngbé lé wa lọ́wọ́.”

  3. Nípasẹ̀ Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀, a lè rí okun láti faradà àti níkẹhìn borí gbogbo àwọn ìpèníjà ìgbésí ayé. Gẹ́gẹ́ bí Alma ti kọ́ni, kìí ṣe àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àwọn olùrònúpìwàdà nìkan ni Olùgbàlà gbé lé ara Rẹ̀ ṣùgbọ́n pẹ̀lú “àwọn ìrora àti àìsàn àwọn ènìyàn rẹ̀” àti “àwọn àìlera wọn pẹ̀lú.” Nípa bẹ́ẹ̀, yàtọ̀ sí rírà wá padà lọ́wọ́ àwọn àṣìṣe wa, àánú àti oore-ọ̀fẹ́ Olúwa gbé wa dúró nípasẹ̀ àìṣèdájọ́ òdodo, àwọn ìdíwọ́ tí a gbé lé wa lọ́wọ́ nípasẹ̀ ìrírí ayé ikú.

Gbígba àwọn ìbùkún ìsanpadà wọ̀nyi wá pẹ̀lú àwọn ipò kan. Olúwa ní kí a ṣe “gbogbo ohun tí a lè ṣe” àti láti “fi gbogbo ọkàn [wa] rúbọ gẹ́gẹ́bí ọrẹ fún òun.” Èyí nbèèrè fún ìfẹ́-inú jíjinlẹ̀, ọkàn òtítọ́ àti ìgbàgbọ́, àti ìtara wa ní pípa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́ àti títọ́ ìfẹ́ wa ní ìbámu pẹ̀lú Rẹ̀.

Nígbàtí ìtiraka àtọkànwá wa bá kùnà sí àwọn ìlépa wa nítorí àwọn ipò tí ó kọjá ìṣàkóso wa, Olúwa ṣì tún lè tẹ́wọ́gba àwọn ìfẹ́-inú ti ọkàn wa bí ẹbọ yíyẹ. Ààrẹ Dallin H. Oaks kọ́ni pé, “A ó bùkún fún àwọn ìfẹ́-inú òdodo ti ọkàn wa àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ òde kan ti jẹ́ kó ṣòro fún wa láti gbé àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọnnì sí ìṣe.”

Bí Wòlíì Joseph Smith ti dààmú nípa arákùnrin rẹ̀ Alvin, ẹnití ó ti kú láìsí gbígba àwọn ìlana ìhìnrere pàtàkì, ó gba ìfihàn ìtùnú yii: “Gbogbo àwọn tí ó bá kú làti ìsinsìyí láìsi ìmọ̀ [ìhìnrere], tí wọ́n ìbá ti gbà á pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn, yíò jẹ́ àrólé ti [ìjọba ọ̀run sẹ̀lẹ̀stíà ti Ọlọ́run].” Olúwa lẹ́hìnnáà fi kun un pé, “Nítorí Èmi, Olúwa, yíò ṣe ìdájọ́ gbogbo ènìyàn gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ wọn, gẹ́gẹ́bi ìfẹ́ ọkàn wọn.”

Ohun tí ó ṣe pàtàkì sí Olúwa kì í ṣe bóyá a le ṣe nìkan ṣùgbọ́n bóyá a fẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tí a le ṣe láti tẹ̀le E gẹ́gẹ́bí Olùgbàlà wa.

Ọ̀rẹ́ kan tu ọ̀dọ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere kan nínú nígbàkan tí ó nṣọ̀fọ̀ nítorí ìdásílẹ̀ rẹ̀ ní kùtùkùtù nítorí àwọn èrèdí ìlera rẹ̀, láìka àdúrà àtọkànwá àti ìfẹ́-inú rẹ̀ láti sìn sí. Ọ̀rẹ́ yi ṣe àbápín ìwé mímọ́ kan níbi tí Olúwa ti kéde pé nígbàtí àwọn ọmọ Rẹ̀ bá “lọ pẹ̀lú gbogbo agbára wọn” àti “tí wọn kò bá ṣe ìmẹ́lẹ́” láti mú àwọn òfin Rẹ̀ ṣẹ, “àti àwọn ọ̀tá wọn [èyítí ó lè ní àwọn ipò búburú nínú ìgbésí ayé wa] dí wọn lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ náà, kíyèsí i, ó yẹ kí nbéèrè pé kí nmá ṣe iṣẹ́ náà mọ́ lọ́wọ́ àwọn [ènìyàn], ṣùgbọ́n láti gba nínú ọrẹ ẹbọ wọn.”

Ọ̀rẹ́ mi jẹ́rìí sí ọ̀dọ́mọkùnrin náà pé Ọlọ́run mọ̀ pé òun ti fi ohun tó dára jùlọ fúnni ní dídáhùn ìpè láti sìn. Ó mú un dá a lójú pé Olúwa ti gba ọrẹ rẹ̀ àti pé àwọn ìbùkún tí a ṣèlérí fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere olóòótọ́ ni a kò ní dádúró.

Àwọn ìbùkún Olúwa máa nwá nípasẹ̀ inúrere àti iṣẹ́ ìsìn àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n nràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ohun tí a kò lè ṣe fúnra wa. Mo rántí àkókò nígbàtí, a ngbé jìnnà sí ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin wa ní ilẹ̀ Faransé, a ní ìmọ̀lára àìní ìrànlọ́wọ́ fún un lẹ́hìn ìbímọ kan tó nira. Ní ọ̀sẹ̀ kannáà, ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Utah wá ìrànlọ́wọ́ fún ìyá kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ìbejì. Ìyàwó mi, Valérie, yọ̀ọ̀da láti mú oúnjẹ wá fún un, pẹ̀lú àdúrà nínú ọkàn rẹ̀ fún ìyá titun yìí àti ọmọbìnrin wa nínú àìní. Láìpẹ́ lẹ́hìn náà, a gbọ́ pé àwọn arábìnrin tó wà ní ẹ̀ka àwọn ọmọbìnrin wa ní ilẹ̀ Faransé ti ṣètò láti pèsè oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀. Lójú wa, Ọlọ́run ti dáhùn àwọn àdúrà wa, ní rírán àwọn ángẹ́lì Rẹ̀ láti mú ìtùnú wá nígbàtí a kò lè ṣe bẹ́ẹ̀.

Nígbàtí a bá dojúkọ àwọn ìdíwọ́ àti ìpèníjà, a lè dá àwọn ìbùkún ti ara wa mọ̀—àwọn ẹ̀bùn, ohun èlò, àti àkókò wa—kí a sì lò wọ́n láti sin àwọn tí wọ́n wà nínú àìní. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a kì yíò bùkún àwọn ẹlòmíràn nìkan ṣùgbọ́n a ó pe ìmúláradá àti ẹ̀san wá sínú ìgbésí ayé tiwa.

Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó lágbára jùlọ tí a lè gbà dásí sí àwọn ìsanpadà ìbùkún ti Ọlọ́run ni nípasẹ̀ iṣẹ́ ìrọ́pò tí a nṣe fún àwọn babańlá wa nínú ilé Olúwa. Bí a ṣe nṣe àwọn ìlànà ní ìtìlẹhìn wọn, a nkópa taratara nínú iṣẹ́ ìgbàlà títóbi ti Olúwa, ní lílo àwọn ẹ̀bùn àti agbára wa láti pèsè àwọn ìbùkún fún àwọn tí kò ní ànfàní láti gbà wọ́n lákokò ayé íkú wọn.

Iṣẹ́ ìsìn ìfẹ́ni tí a nṣe ní àwọn tẹ́mpìlì mímọ́ nrán wa létí pé oore-ọ̀fẹ́ Olùgbàlà gbòòrò ju ayé yìí lọ. Ní ìgbésí ayé tí ó nbọ̀, a le fún wa ní àwọn ànfàní titun láti ṣe àṣeyọrí ohun tí a kò le ṣe nínú ìgbésí ayé ikú yíi. Ní bíbá àwọn arábìnrin sọ̀rọ̀ tí wọn kò tíì rí ojúgbà ayérayé sọ̀rọ̀, Ààrẹ Lorenzo Snow fi tìfẹ́tìfẹ́ sọ pé: “Kò sí Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn kan tí ó kú lẹ́hìn tí ó ti gbé ìgbé ayé olóòótọ́ tí yíò pàdánù ohunkóhun nítorí pé ó kùnà láti ṣe àwọn ohunkan nígbàtí àwọn ànfààní kò bá ṣí sílẹ̀ fún ọkùnrin tàbí obìnrin náà. … Wọn yíò ní gbogbo àwọn ìbùkún, ìgbéga àti ògo tí ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó ní ànfàní yii yíò ní.”

Ọ̀rọ̀ ireti ati itunu yìí wà fún gbogbo wa, àwa ọmọ́ Ọlọ́run. Kò sí ọ̀kan nínú wa tí ó le sá fún àwọn ìpèníjà àti àwọn ìdíwọ́ ti ikú. Lẹ́hìnnáà, gbogbo wa ni a bí pẹ̀lú àìlágbara láti gba ara wa là. Síbẹ̀ a ní Olùgbàlà olùfẹ́ni, àti pé “a sì mọ̀ pé nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́ [Rẹ̀] ni a fi gbà wá là, lẹ́hìn gbogbo ohun tí a lè ṣe.”

Mo jẹri pé lakoko tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ipò ní ìgbésí ayé le kọjá ìṣàkóso wa, kò sí ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú wa tí ó kọjá àrọ́wọ́tó àwọn ìbùkún àìlópin ti Olúwa. Nípasẹ̀ ẹbọ ètùtù Rẹ̀, Olùgbàlà yíò san ẹ̀san fún gbogbo àìlágbára àti àìṣòdodo tí a bá fi gbogbo ẹ̀mí wa fún Un. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.