À Sọ̀rọ̀ Nípa Krístì
À jẹ́ àwọn ọmọ-ẹ̀hin Jésù Krístì, a sì nwá láti gbà àti láti pín ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú.
Ọ̀rọ̀-ìṣíwájú
Ní òpin ìyànnisíṣẹ́ gígùn òkè-òkun, ìyàwó mi Lesa àti èmi gbésẹ̀ wọnú ibùdókọ̀ ọkọ̀ òfúrufú ní mímúrasílẹ̀ fún fífò ní ẹ̀ẹ̀kanṣoṣo síi—ní ojú pípọ́n—láti dé ilé. Bí a ti dúró pẹ̀lú àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ míràn tí wọ́n nrìn ní ìgbésẹ̀ kan ní àkokò kan nínú àwọn ìlà gígùn, a lè ní ìmọ̀lára ìdàmú dídàgbà àníyàn ti àwọn ọmọnìkejì arìnrìnàjò nípa ṣíṣe àwọn fífò, wíwo iwé-ìrìnnà àti àyẹ̀wò ìsọdá-ibodè, àti sísọdá àwọn ààbò àyẹ̀wò pẹ̀lú àṣeyege.
Ní òpin a dé ibùdókọ̀ kan tí àwọn òṣìṣẹ́ aṣọ́bodè wà tí ó dàbíi pé wọn kò mira pẹ̀lú ipò gíga ti wàhálà àti àníyàn nínú yàrá náà. Pẹ̀lú ìdarí ó fẹ́rẹ̀, jẹ́ láì sí ojúkojú, ni ó fi nawọ́ fún àwọn ìwé mi, ó wò àwòrán mi, ó tẹ̀ka sínú ojú-ewé kan lẹ́hìn òmíràn, ó sì tẹ ìwé-ìrìnnà mi pẹ̀lú títẹ̀ tó le koko.
Nígbànáà ó nawọ́ fún àwọn ìwé ti Lesa. Láìsí ẹ̀dùn ọkàn, ní ìdoríkodò àti ìdojúkọ sí iṣẹ́ rẹ̀, ó fi ọgbọ́n tẹka sí àwọn ojú-ewé náà pẹ̀lú ojú ìmòye, ní ìdojúkọ lórí àlàyé kíníkíní ti àwọn ìwé ní iwájú rẹ̀. Ó yà wá lẹ́nu bákan nígbàtí ó dédé dúró, ó gbé ojú sókè, ó sì wo Lesa lójúkojú ní ìmọ̀ọ́mọ̀ àti ìwò ìtújúká sókè. Pẹ̀lú ẹ̀rín jẹ́jẹ́, ó fi ìrẹ̀lẹ̀ tẹ ìwé-ìrìnà Lesa ó sì fi àwọn ìwé rẹ̀ padà fún un. Ìyàwó mi rẹrin padà, ó tẹ́wọ́gba àwọn ìwé náà, ó sì fún ní àwọn ọ̀rọ̀ ìdágbére.
“Kíni ó ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀?” Mo bèèrè pẹ̀lú àìgbàgbọ́.
Nígbànáà Lesa fi ohun tí òṣìṣẹ́ náà rí hàn mi—káàdì kékeré kan pẹ̀lú àwòrán Olùgbàlà. Ó ti jábọ́ lójijì látinú àpamọ́wọ́ Lesa sínú ewé ìwé-ìrìnà rẹ̀. Èyí ni ohun tí òṣiṣẹ́ aṣọ́bọdè rí. Èyí ni ohun tí ó yí gbogbo ìhùwàsí rẹ̀ padà.
Oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́, nípasẹ̀ Simon Dewey, láti ọwọ́ altusfineart.com, © 2025, tí a lò pẹ̀lú àṣẹ
Àwòrán kékeré yí nípa Olùgbàlà so ọkàn méjì tí ìbá jẹ́ àìní-ìsopọ̀ àwọn àjèjì pọ̀. Ó yí àìjẹ́-ti-araẹni padà sí araẹni, ó mú ẹ̀wà náà, ìṣẹ́ ìyanu, àti òdodo Ìmọ́lẹ̀ Jésù Krístì padà. Fún ìyókù ọjọ́ náà àti léraléra lẹ́hìnnáà, mo ti ngbèrò àkokò dídùn, ìrọ̀rùn náà pẹ̀lú ọ̀wọ̀ mo sì ti yọ̀ nínú àyọrísí ológo ti Ìmọ́lẹ̀ Krístì lórí àwọn ọmọ Ọlọ́run.
À Sọ̀rọ̀ Nípa Krístì
À ntẹ̀lé Jésù Krístì, a sì nwá láti gbà àti láti pín ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú. Ìdámọ̀ nínú orúkọ Ìjọ ni ẹ̀sìn wa nípa “Jésù Krístì fúnrarẹ̀ bí olórí igun òkúta.” Nípasẹ̀ àwọn wòlíì àtijọ́ àti alààyè, Baba Ọ̀run ti pàṣẹ fún wa láti “Gbọ́ Tirẹ̀!” àti láti “wá sọ́dọ̀ Krístì.” “À nsọ̀rọ̀ nípa Krístì, a nyọ̀ nínú Krístì, à nwàásù nípa Krístì, [a sì] nsọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Krístì.”
À nkọ́ni pé Jésù Krístì ni Ọmọ Ọlọ́run, àti pé nígbà iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti ayé Rẹ̀, Jésù kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀ ní ìhìnrere ó sì gbé Ìjọ Rẹ̀ kalẹ̀.
A jẹri pé ní òpin ayé Rẹ̀, Jésù ṣe ètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa nígbàtí ó jìyà nínú Ọgbà Gethsemane, a kàn án mọ́ àgbélèbú, àti pé lẹ́hìnnáà ó jínde ó sì díde lẹ́ẹ̀kansi ní ọjọ́ kẹta.
A yọ̀ nítorí ìrúbọ ètùtù Olùgbàlà, a lè gba ìdáríjì àti ìwẹ̀nùmọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa bí a ti nronúpìwàdà. Èyí nmú àláfíà àti ìrètí wá fún wa nígbàtí ó nmu ṣeéṣe fún wa láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
A sọtẹ́lẹ̀ pé nítorí Àjínde Jésù, ikú kìí ṣe òpin ṣùgbọ́n ìgbésẹ̀ pàtàkì kan síwájú. “Gbogbo wa yíò jínde lẹ́hìn tí a bá kú. Ó túmọ̀ sí pé ẹ̀mí ẹnìkọ̀ọ̀kan àti ara yíò di dídàpọ̀ wọn ó sì gbé títíláé.”
Wá sí ọ̀dọ̀ Krístì
Àwọn wòlíì alààyè ní ọjọ́ wa—tí wọ́n ngba ìfihàn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti kọ́ àti láti darí wa—npè wá lọ́pọlọpọ̀ láti wá sọ́dọ̀ Krístì. Wọ́n nràn wá lọ́wọ́ láti fi ọkàn, etí àti ojú wa sí oókan kíkún sí orí Rẹ̀. A lè sọ onírurú àwọn àpẹrẹ ti ìkéde àwọn àtúnṣe àti ìgbèrúsi nípasẹ̀ àwọn Àjọ Ààrẹ Ìkínní tí a ṣe láti dojú wa kọ Jésù Krístì. Díẹ̀ lára ìwọ̀nyí pẹ̀lú:
-
Ìpinnu láti pa orúkọ “Ìjọ Mọ́mọ́nì” tì àti láti rọ́pò rẹ̀ pẹ̀lú orúkọ títọ́, Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.
-
Wíwà ní àrọ́wọ́tó ti titun, ìmísí iṣẹ́-ọnà ti àkórí-Krìstì fún fífihàn nínú àwọn ilé-ìjọsìn.
-
Àkórí àti orin àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin àti Ọ̀dọ́mọkùnrin dojúkọ Jésù Krístì bíi ti “Ọmọ-ẹ̀hìn Krístì” àti “Wo Ọ̀dọ̀ Krístì.”
-
Àtẹnumọ́ púpọ̀jù lórí Ètùtù àti Àjínde ní ọ̀rọ̀ gan nípa Jésù Krístì bí ìṣẹ̀lẹ̀ ológo jùlọ ní gbogbo ìwé-ìtàn.
-
Ayẹyẹ Ọdún Àjínde bí àkokò kan kìí ṣe ìsinmi lásán, pẹ̀lú àtẹnumọ́ kan lórí Jésù Krístì.
-
Ọ̀rọ̀-ìsaájú ti ìrísí ìfinihàn Ìjọ Jésù Krístì àti àmì ìwà-ẹ̀dá rẹ̀.
Ẹ jẹ́ kí a wo ipa díẹ̀ lára ìwọ̀nyí dáadáa. Àkọ́kọ́, àmì Ìjọ náà.
Àmì Ìjọ Náà.
Ní 2020, Ààrẹ Russell M. Nelson fi ìrísí ìfinihàn titun fún Ìjọ hàn. Àmì yí nfi òtítọ́ hàn pé Krístì wà ní oókan Ìjọ Rẹ̀ ó sì níláti wà ní oókan ìgbésí ayé wa. Nísisìyí a rí ìfaramọ́ àmì yí lórí àwọn ìkaniyẹ tẹ́mpìlì, ibi-wẹ́ẹ̀bù Ìjọ àti àwọn ìròhìn, bí ti àmì fún áàpù Ibi-ìkàwé Ìhìnrere, àní àti lórí àwọn táàgì ìdánimọ̀ ológun fún àwọn ọmọ Ìjọ tí wọ́n nsìn nínú ológun. Àmì náà pẹ̀lú orúkọ Ìjọ tí ó wà ní igun-òkúta kan, ìrántí kan pé Jésù Krístì ni Olórí igun-òkúta, tí a fihàn nihin ní Cambodian àti ní àwọn èdè máàrúndínláàdọ́jọ.
Oókan àmì náà ni ìrọ́pò ti Albert Bertel Thorvaldsen nípa èrè mábù Christus wíwuni, èyí tí ó di bíbárẹ́ gidi pẹ̀lú Ìjọ tí a sì rí nínú gbàgede àwọn àlejò àti ní ilẹ̀ tẹ́mpìlì yíká ayé. Híhàn kétékété rẹ̀ nínú àmì Ìjọ dá àbá pé Krístì níláti wà ní oókan gbogbo ohun tí à nṣe. Bákannáà, nínawọ́ síta Olùgbàlà fi ìlérí Rẹ̀ hàn láti gba gbogbo àwọn ẹnití yíò wá sọ́dọ̀ Rẹ̀ mọ́ra. Àmì yí ni ìrọ́pò ìrísí ìfẹ́ Olùgbàlà Jésù Krístì àti ìrántí lemọ́lemọ́ ti Krístì alààyè.
Nínú ọ̀fíntótó, mo ti bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbí àti ọ̀rẹ́ nípa ohun-èlò kan pàtàkì ti àmì Ìjọ náà. Pẹ̀lú ìyàlẹ́nu, ọ̀pọ̀lọpọ̀ kò ní ìfura ti ẹ̀yà ọ̀wọ̀ tí ó ní nínú. Jésù Krístì dúró lábẹ́ áàkì náà. Èyí rọ́pò olùjínde Olùgbàlà tí ó ndìde kúrò nínú ibojì. À nṣe ayẹyẹ olùjínde, Krístì alààyè nítòótọ́, àní nínú lílò àmì Ìjọ náà.
Ọdún Àjínde Gígajù àti Mímọ́jù
Nísisìyí ẹ jẹ́ kí a gbèrò pàtàkì Ọdún Àjínde. Nínú àwọn ọ̀rọ̀ àìpẹ́ ti Àjọ Ààrẹ Ìkínní nípa Ọdún Àjínde, a ti pè wá níjà láti “ṣe ayẹyẹ Ajinde Olùgbàlà alààyè nípa ṣíṣe àṣàrò àwọn ìkọ́ni Rẹ̀ àti ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ láti fìdí àwọn àṣà Ọdún Àjínde múlẹ̀ ní àwùjọ wa lápapọ̀, ní pàtàkì nínú àwọn ẹbí tiwa.” Ní kúkurú, a ti gba wá níyànjú láti lọsíwájú ní ṣe ayẹyẹ Ọdún Àjínde gígajù àti mímọ́jù.
Mo ní ìfẹ́ ìfihàn Ọdún Àjínde tí ó ntẹ̀síwájú mo sì ní ìgbádùn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtiraka yín láti mú Ọdún Àjínde jẹ́ ọ̀nà ọ̀wọ̀ àti mímọ́. Ní àfikún sí ṣíṣe ìpàdé oúnjẹ Olúwa ní wákàtí-kan ní Ọjọ́ Ìsinmi Ọdún Àjínde, àwọn àpẹrẹ míràn ti àwọn ìṣe ṣíṣe yíyẹ pẹ̀lú àwọn ìfọkànsìn àti ìṣe ṣíṣe wọ́ọ̀dù àti eèkàn ní Ọjọ́ Ìsinmi Ọ̀pẹ bákannáà ni a ṣe bí Ọ̀sẹ̀ Mímọ́. Àwọn ìrántí wọ̀nyí wà nínú ìṣe ṣíṣe pẹ̀lú àwọn ọmọdé àti ọ̀dọ́ àti fífi àwọn akọrin ìgbàgbọ́ míràn si nínu. Àwọn ẹlòmíràn ti ṣe àwọn ilé ṣíṣí “Krístì Alààyè” fún àwọn ọmọ ìjọ àti ọ̀rẹ́ ti wọ́n sì ti kópa nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ oríṣiríṣi ẹ̀sìn ìletò Ọdún Àjínde.
Irú àwọn ìṣe ṣíṣe bẹ́ẹ̀ fi ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn hàn nínú ìlú Jérúsálẹ́mù tí àwọn ohùn dara papọ̀ láti yin Olùgbàlà ní ìgbà fífi ìṣẹ́gun wọlé Rẹ̀. Wíwọnilọ́kàn pẹ̀lú ni àwọn ìròhìn ti ìfèsì yín sí ìfipè Àjọ Ààrẹ Ìkínní láti jọ́sìn ní ilé bí àwọn ẹbí láti ṣe àjọ̀dún ìsinmi pàtàkì jùlọ yí.
Mo gbàgbọ́ pé ìjọ́sìn ẹbí tí ó yí Ọdún Àjínde ká ti gbéniga pẹ̀lú òkìkí. Ọdún méjì sẹ́hìn, mo sọ̀rọ̀ nípa ìpinnu ẹbí wa láti tún ọ̀nà tí a fi nbu ọlá fún Ọdún Àjínde. Ní ìfaramọ́, èyí ṣì jẹ́ iṣẹ́ tí ó nlọsíwájú. A ti máa ngbádùn oúnjẹ Ọdún Àjínde pàtàkì, àwọn apẹ̀rẹ̀ Ọdún Àjínde àti ìdọdẹ ẹyin Ọdún Àjínde nígbàgbogbo, a sì ṣì nṣe bẹ́ẹ̀. Bákannáà, ṣíṣe àfikún ọ̀nà àmọ̀ọ́mọ̀ ti ẹ̀mí tí ó dojú Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀ kọ ayẹyẹ wa tí ó mú ìbámu dídùn wá sí àjọ̀dún wa nípa àwọn mímọ́ jù gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ lọ.
Ọdún yí yíò jẹ́ ìgbìyànjú kẹta wa láti mú Ọdún Àjínde jẹ́ oókan Krístì síi. Bíi ti Ìbí Kérésìmesì, eré ẹbí Ọjọ́ Ọdún Àjínde pẹ̀lú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀wù, kíka àwọn ìwé mímọ́ látinú Májẹ̀mú Titun àti Ìwé ti Mọ́mọ́nì, orin, àwọn àwòrán Ọdún Àjínde, màrìwò ọ̀pẹ—àti aruwo díẹ̀, bí mo bá jẹ́ olóòtítọ́ tán pátápátá. Àwọn ọmọ àti ọmọ-ọmọ nkàwé wọ́n sìn nsọ àwọn ìyìn Ọjọ́ Ìsinmi Ọ̀pẹ “Hosanna … Alábùkúnfún ni ẹni tí ó nbọ̀wá ní orúkọ Olúwa; Hosanna lókè ọ̀run” àti pé “Èyí ni Jésù … ti Galilee” dàbíi pàtàkì bí “Àláfíà ní ilẹ̀ ayé, ìwàrere sí ènìyàn” ni ní àkokò Kérésìmesì.
Nísisìyí a ngbàdùn àpapọ̀ àwọn ọ̀ṣọ́. Ohun tí ó ti fìgbàkan fẹ́rẹ̀ jẹ́ ehoro kékeré àti àwọn ẹyin Ọdún Àjínde ti báramu nísisìyí pẹ̀lú Christus àti àwọn àwòrán ibojì ṣíṣòfo, Olùgbàlà nfarahàn nínú Ọgbà níta ibojì, àti ìfarahàn Olùgbàlà sí àwọn ará Néfì. Bákannáà à nlàkàkà láti mú Ọdún Àjínde jẹ́ àkokò sànju ọjọ́ kan lásán. À ngbìyànjú láti jẹ́ olùbáraẹnisọ̀rọ̀, aláníyàn, àti ṣíṣe àjọ̀dún Ìsìnmi ọ̀pẹ àti Ọjọ́-ẹtì Rere àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mímọ́ tí ó ṣẹlẹ̀ ní ìgbà gbogbo Ọ̀sẹ̀ Rere.
Ọdún Àjínde nfi ààyè gbà wá láti bu ọlá fún méjèèjì ìrúbọ ètùtù Jésù Krístì àti bí ọ̀rọ̀ gan àti Àjínde aláyọ̀ Rẹ̀. Ọkàn wa bàjẹ́ bí a ti nronú ìjìyà Olùgbàlà nínú Ọgbà àti lórí Kalfárì, ṣùgbọ́n ọkàn wa yọ̀ bí a ti nní ìrísí ibojì ṣíṣòfo àti àṣẹ ọ̀run “Ó ti Jínde!”
Àjínde Kan Bí Ọ̀rọ̀ Gan
Àwọn ọ̀rọ̀ ìgbani-níyànjú ti Àjọ Ààrẹ Ìkínní láti “wo iwájú sí Ọdún Àjínde àti Àjínde Jésù Krístì—ológo jùlọ ti gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ sí ẹ̀dá ènìyàn” fi àmì títóbi ti àkokò yí hàn. Nígbàtí ó hàn pé ìdàgbà àṣà ní àárín oríṣiríṣi àwọn ọ̀mọ̀wé ẹ̀sìn Krìstẹ́nì wà láti wo Àjínde ní ọ̀ràn àfiwé àti alámì, a tẹnumọ ẹ̀kọ́ wa pé “Àjínde túmọ̀ sí pé gbogbo ẹni tí ó ti gbé rí ni yíò jínde, àti pé Àjínde jẹ́ bí ọ̀rọ̀ ti rí gan.” “Nítorí bí gbogbo ènìyàn ṣe kú nínú Ádámù, àní bẹ́ẹ̀ni a ó sọ gbogbo ènìyàn di alààyè nínú Krístì.” Jésù Krístì já ìdè ikú fún gbogbo ẹ̀mí alààyè.
Nítòótọ́ a dúró ní gbogbo ìyanu ní oore-ọ̀fẹ́ tí Jésù fún wa. A rọ̀mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ pé “kò sí ẹnìkan tí ó ní ìfẹ́ tí ó tobi ju èyí lọ, pé kí ẹnìkan fi ẹ̀mi rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.”
C.S. Lewis sọ pé “láti wàásù ti Krìstẹ́nì túmọ̀ sí [àwọn Àpóstélì] ní pàtàkì láti wàásù Àjínde. … Àjínde ni oókan àkórí nínú ìwàásù Krìstẹ́nì tí a ròhìn nínú àwọn ìṣe àpóstélì. Àjínde náà, àti àbájáde rẹ̀, ni ‘ìhìnrere’ tàbí ìròhìn rere èyí tí àwọn Krìstẹ́nì mú wá.”
Mo kéde pé “àjĩnde kan wà, … ìsà-òkú kò ní ìṣẹ́gun, oró ikú sì jẹ́ gbígbémì nínú Krístì.”
Ìparí àti Ẹrí
Ní ìparí, mo jẹ́ ẹ̀rí pé gbogbo ẹni tí ó bá tẹ́wọ́gba àwọn ìfipè láti ẹnu wòlíì alààyè wa àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ láti mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ayẹyẹ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mímọ́ tí Ọdún Àjínde rọ́pò yíò ri pé ìsopọ̀ náà pẹ̀lú Jésù Krístì ndàgbà pẹ̀lú agbára síi títíláe.
Ọjọ́ díẹ̀ sẹ́hìn, mo kẹkọ nípa ìyá-àgbà kan tí ó tún ìtàn Ọdún Àjínde sọ fún ọmọ-ọmọ rẹ̀ ọkùnrin ọmọ ọdún mẹ́rin nípa lílo ìjọra rírọrùn ti isà-òkú, òkúta tí ó bo ìbojì, Jésù, Mary, àwọn ọmọ-ẹ̀hìn, àti àngẹ́lì. Ọmọdékùnrin náà wòó ó sì fétisílẹ̀ tímọ́tímọ́ bí ìyá àgbà rẹ̀ ti npín ìsìnkú náà, pípadé àti ṣíṣí ibojì, àti ìran ọgbà ti Àjínde. Lẹ́hìnnáà ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tún ìtàn náà sọ nínú àlàyé yíyanilẹ́nu bí ó ti nyí àwọn àwòrán náà ká ara rẹ̀. Títẹ̀lé àkokò dídùn yí, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bí ó bá mọ ìdí tí a fi ní Ọdún Àjínde. Ọmọdékùnrin náà wo òkè àti pẹ̀lú ìronú ọmọdé ó dáhùn, “nítorí Ó wà láàyè.”
Mo fi ẹ̀rí mi kùn tirẹ̀, àti sí tiyín àti sí ti àwọn ángẹ́lì àti wòlíì, pé Ó ti jínde àti pé Ó wà láàyè, nípa èyí tí mo jẹri ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.