Ayọ̀ Nípasẹ̀ Jíjẹ́ Ọmọ-ẹ̀hìn Májẹ̀mú
Bí a ti nso ara wa pọ̀ láti ṣiṣẹ́ bíi àwọn ọmọ-ẹ̀hìn májẹ̀mú, ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Baba àti Ọmọ njẹ́ mímúdára síi, ayọ̀ wa ndi títúnṣe, ìwòye ayérayé wa sì ndi gbígbòòrò.
Ní ọjọ́ kan ní 2023, Uyanga Altansukh wà ni ibi iṣẹ́ ní ilú Darkhan ti àríwá Mongolian nígbàtí ààrẹ iṣẹ́ ìhìnrere ní Mongolian wọ ibi iṣẹ́ rẹ̀. Ní àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀:
“Mo rí i mo sì rò pé ó ní ìmọ́lẹ̀ dídán yí ní ìwò ojú rẹ̀. Ó jẹ́ aláànú àti aláwàdà sí àwọn tí wọ́n wà ní àyíká rẹ̀, mo sì ní ìmọ̀lára ọ̀yàyà. Kí ó tó lọ, mo bií léèrè àwọn ìbéèrè díẹ̀. Ní àwọn ọjọ́ díẹ̀ lẹ́hìnnáà, ó tún wá sí ibi iṣẹ́ mi ó sì béèrè bí mo bá le wá sí ilé ìjọsìn rẹ̀. Mo rò pé èyí le ṣe ìrànlọ́wọ́. Mo ṣàníyàn fún ọjọ́ ọ̀la àwọn ọmọ mi, bí àwùjọ ṣe dàbí pé ó kún fún ìdààmú àti òkùnkùn. Mo fẹ́ kí àwọn ọmọ mi dàbí ọkùnrin yí pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ ní ìwò ojú wọn, kí wọn ó máa tan ayọ̀ ká sí àwọn ẹlòmíràn ní àyíká wọn.
“Ní ọjọ́ kan àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere kọ́ wa ni òfin ìdámẹ́wàá. Àwọn ọmọ mi sọ pẹ̀lú ìtara pé, ‘A gbọ́dọ̀ san ìdámẹ́wa wa, Ìyá.’ Mo le rí ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ mi ni àkókò náà. Ki ntó darapọ̀ mọ́ Ìjọ, mo wo ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò mo sì fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ Ààrẹ Russell M. Nelson. Ó kéde àwọn tẹ́mpìlì titun ní gbogbo àgbáyé ó sì wí pé a ó kọ́ tẹ́mpìlì titun kan ní Ulaanbaatar, Mongolia. Mo yọ̀ mo sì sọkún, àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdí rẹ̀ kò yé mi. Pẹ̀lú ayọ̀ yí, mo lè sọ pé ìgbàgbọ́ àti ẹ̀rí mi ti ndàgbà.”
Uyanga, bíi ti mílíọ́nù àwọn ẹlòmíràn, jẹ́ ara ìkójọ nlá ti Ísráẹ́lì ní ìmúrasílẹ̀ fún Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì ti Jésù Krístì. Ó ti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ̀ ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú ó sì ti di ọmọ-ẹ̀hìn Krístì kan. Kíni ó túmọ́sí láti jẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn Krístì? Mo mọrírì ọ̀rọ̀ ni èdè Japan fún ọmọ-ẹ̀hìn—deshi—de tí ó túmọ̀ sí àbúrò ọkùnrin, àti shi ti ó túmọ̀ sí ọmọ.
Jésù Krístì wí pé, “Èmi wà ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Baba, èmi sì ni Àkọ́bí.” Nítorí ti ẹnití Ó jẹ́ àti ohun tí Ó ti ṣe, àwa nsìn Ín, a nbọ̀wọ̀ fún Un, a nfi ògo fún Un, a sì ntẹ̀lé E. Krístì ti rà wá padà, àwa sì nfi ìmoore hàn títí láé fún ẹbọ àìlópin áti ètùtù Rẹ̀.
A ní Baba Ọ̀run kan, tí ó fẹ́ràn wa bí ọmọ Rẹ̀. Ìfẹ́ Rẹ̀ fún wa jẹ́ pípé. Jésù Krístì àti iṣẹ́ Rẹ̀ ṣe àpèjúwe ìfẹ́ Ọlọ́run fún wa. Bí Jòhánnù ti kọ̀wé, “Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tóbẹ́ẹ́ gẹ́, tí ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kanṣoṣo fúnni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”
Nínú ìwákiri wa lati ní òye ohun tí a kò mọ̀, a lè fi ìgbàmíràn gbáralé àwọn ìrírí ti ẹran ara wa tó wọ́pọ̀, tàbí àwọn ohun tí a mọ̀. Fún àpẹrẹ, a le kọ́ ẹ̀kọ́ díẹ̀ nípa Ọlọ́run Baba nípasẹ̀ pé a jẹ́ òbí àti àwọn ìbáṣepọ̀ ẹbí ti ayé ikú. Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, a níláti ṣọ́ra ni lílo àwọn àfiwé wọ̀nyí jìnnà jù nínú ìgbìyànjú wa láti ní òye Baba Ọ̀run. Àwọn ìhùwàsí ti Ọlọ́run Baba tayọ èyíkéyìí àìjẹ́ pípé àwọn ìhùwàsí ẹni ìṣubú kan. Ọlọ́run Baba ni Baba pípé náà. Ó jẹ́ olùfẹ́ni ní pípé, àláànú, onísùúrù, àti olóye ó sì jẹ́ ológo ní pípé. A lè gbẹ́kẹ̀lé E ní pípé. Ìfẹ́ ti Krístì nṣe àfihàn ìfẹ́ ti Ọlọ́run Baba ó sì jẹ́ ìdúrófún kan ti ìfẹ́ náà.
Jésù Krístì jẹ́ méjèèjì àpẹrẹ àti ọ̀nà náà. Nínú Krístì, a lè ní òye síi nípa áwọn ìhùwàsí pípé ti Baba àti ètò Rẹ̀. Nípasẹ̀ Krístì, a fún wa ní agbára ìleṣe láti borí àwọn títẹ̀sí ti ọkùnrin àti obìnrin ẹlẹ́ran ara kí a lè dàbí Baba síi.
Gẹ́gẹ́ bíi Baba wa Ọ̀run Jésù Krístì jẹ́ aláànú àti olóòtọ́ ní pípé. Àwọn ìhùwàsí àtọ̀runwá ti àìṣègbè àti àánú wọ̀nyí kò sí ní àtakò. Wọ́n jẹ́ amúgbá-lẹ́gbẹ̀ẹ́. Méjèèjì àìṣègbè àti àánú nṣe àpéjúwe Ìfẹ́ pípé Ọlọ́run fún àwọn Ọmọ Rẹ̀. A le gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run Baba àti Jésù Kríst nítorípé Wọ́n jẹ́ olóotọ́ àti dídára pẹ̀lú gbogbo wa.
Ọlọ́run Baba àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, báramu ní pípé nínú èrò áti ìfẹ́. Nítorípé Ọlọ́run àti Jésù Krístì fẹ́ràn wa, a fún wa ní ànfààní àti àyè bíi ọmọ-ẹ̀hìn tòótọ́ láti dá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Wọn. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ wa, ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Krístì jẹ́ títóbi síi: “Àti nísisìyí, nítorí májẹ̀mú èyítí ẹ̀yin ti dá a ó máa pè yín ní ọmọ Krístì, ọmọkùnrin rẹ̀, àti ọmọbìnrin rẹ̀; nítorí ẹ kíyèsíi, ní òní yí ni ó ti bíi yín ní ti ẹ̀mí; nítorítí ẹ̀yin wípé ọkàn yín ti yípadà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀; nítorínáà, a bíi yín nínú rẹ ẹ̀yin sì ti di ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ̀.”
Bíi ọmọ-ẹ̀hìn, nígbàtí a bá dá tí a sì pa àwọn májẹ̀mú mímọ́ mọ́, a njẹ́ bíbùkún pẹ̀lú agbára ti ẹ̀mí. A jẹ́ sísopọ̀ mọ́ Krístì àti Ọlọ́run Baba nínú ìbáṣepọ̀ pàtàkì kan a sì le ní ìrírí ìfẹ́ àti ayọ̀ Wọn ní ìwọ̀n tí a pamọ́ fún àwọn tí wọ́n ti dá tí wọ́n sì pa àwọn májẹ̀mú mọ́. Agbára wa láti ní ìmọ́lára ìwọ̀n kíkún ti ìfẹ́ Ọlọ́run, tàbí láti tẹ̀síwájú nínú ìfẹ́ Rẹ̀, dá lórí àwọn ìfẹ́-inú àti àwọn ìgbésẹ̀ òdodo wa.
Nínú Jòhánnù orí kẹẹ̀dógún, ẹsẹ kẹsan, a kà pe, “Bí Baba ti fẹ́ mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi ti fẹ́ yín.” Àti nígbànáà a fúnwa ní ìfipè kan, “ẹ Tẹ̀síwájú nínú ìfẹ́ mi.”
Nínu ẹsẹ tó tẹ̀lé, a fún wa ni ọ̀nà láti tẹ̀síwájú nínú ìfẹ́ Rẹ̀: “Bí ẹ̀yin bá pa àwọn òfin mi mọ̀, ẹ ó gbé nínú ìfẹ́ mi; àní bí emi ti pà àwọn òfin Bàbá mi mọ́, tí mò sì ngbé nínú ìfẹ́ rẹ̀.”
Lẹ́hìnnáà a rí èrèdí ti pípa àwọn òfin náà mọ́ ní ẹsẹ 11: “Àwọn ohun wọ̀nyí ni mo ti wí fún yín, pé kí ayọ̀ mi lè dúró nínú yín, àti kí ayọ̀ yín lè kún.”
Nípasẹ̀ jíjẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn májẹ̀mú tòótọ́, a le bẹ̀rẹ̀sí ni òye dáradára síi nípa ìwà àdánidá ti Ọlọ́run àti ayọ̀ tí Ó fẹ́ kí gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ ó ní ìrírí. Bákannáà a le bẹ̀rẹ̀sí ní òye àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ díẹ̀ tí ó lè dàbí pé o dojúrú ní àkọ́kọ́. Fún àpẹrẹ, báwo ni Ọlọ́run ṣe le ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀ nígbàtí àwọn ọmọ rẹ̀ kan njìyà púpọ̀ tóbẹ́ẹ̀? Ìdáhùn nàà wà nínú ìwòye pípé ti Ọlọ́run àti nínú ètò pípé Rẹ̀. Ó nrí wa láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé ọjọ́ iwájú ológo ti a lé ní. Ó ti pèsè ọ́ná kan, nípasẹ̀ Ọmọ Rẹ̀ Jésù Krístì, fún gbogbo wa, àwa ọmọ Rẹ̀, láti borí àwọn ìrora, ìjìyà, àwọn ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀bi, àti àdánìkanwà ti ayé kíkú wa. Ọlọ́run ti pèsè ọ̀nà àti yíyàn fún wa.
Àwọn àpẹrẹ ti àwọn tí wọ́n ti ni ìrírí ayọ̀ nípasẹ̀ jíjẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn le rànwá lọ́wọ́ láti mú kí ìlànà yí yé wa síi. Bóyá ẹ ti gbọ́ gbólóhùn ọ̀rọ̀ pé inú wa kàn máa ndùn bíi ọmọ wa tí inú rẹ̀ kò dùn jùlọ. Mo ti ríi pé èyí kò nílò láti jẹ́ bẹ́ẹ̀. Ìyá mi ẹni ọdún mẹrinlélaadọwa ní àwọn àtẹ̀lé tó ju igba tí wọ́n wà láàyè. Ní ọ̀gangan èyíkéyìí àkókò, ó kéré jù ọ̀kan nínú àwọn igba náà yíó ní àìdùn-inú. Bí ọ̀rọ̀ yí bá jẹ́ òtítọ́, ìyá mi yíò máa fi ọ̀pọ̀ ìgbà wà nínú ipò àìní-inú-dídùn, eyítí kò rí bẹ́ẹ̀. Àwọn tí wọ́n mọ̀ ọ́ mọ̀ bí ó ti jẹ́ aláyọ̀ tó.
Nísisìnyi yíó wùmí láti ṣe àbápín ìrírí míràn. Ní Oṣù Kínní 2019, ìyàwó mi, Debbie, àti èmi ni a pe sí ọ́fíìsì Ààrẹ Nelson. Ó ti gbé àga kan sún mọ́ wa, a sì jókòó ní ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ orúnkún sí orúnkún. Lẹ́hìn tí ó nawọ́ ìpè wa lọ́wọ́lọ́wọ́ sí wa, Ààrẹ Nelson yíra sí Debbie ó sì dojúkọ ọ́. Ó jẹ́ aláanú, olùfẹ́ni, ẹni jẹ́jẹ́, ó sì kún fún ayọ̀, bíi baba tàbi baba-àgbà pípé. Ó mú ọwọ́ Debbie ó sì gbá a pẹ́pẹ́, ní fífi tún dá a lójú pé nkan yíó dára àti pé ẹbí wa yíó di alábùkún fún. Lójú wa ní àkókò náà, ó dàbí ẹnipé àwa ni ènìyàn pàtàkì jùlọ sí i àti pé ó ní gbogbo àkókò inú ayé fún wa. A kúrò ní ọ́fíìsì rẹ̀ ní ọ̀sán Ọjọ́ Ẹtì náà pẹlú ìmọ̀lára ìdánilójú, fífẹ́ràn, àti kíkún fún ayọ̀.
Ní Ọjọ́ Ajé a rí ìròhìn náà. Nínú ọjọ́ kannáà tí Ààrẹ Nelson ti lò pẹ̀lu wa, ìkan lára àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ti kọjá lọ pẹ̀lú àrùn jẹjẹrẹ. O yà wá lẹ́nu. Ọkàn wa kún bí a ti nṣọ̀fọ̀ fún òun àti ẹbí rẹ̀. Ọkàn wa kún bákannáà fún ìmoore fún ìfiyèsí sí wa bíi-ti-Krístì nígbàtí ó nṣọ̀fọ̀ fún ọmọbìnrin rẹ̀ tó njìyà.
Bí a ti ronújinlẹ̀ lórí ìrírí yí, a bi ara wa léèrè, “Báwo ni ó ṣe lè jẹ́ aláanú, olùfẹ́ni, tí ó sì kún fún ayọ̀ tóbẹ́ẹ̀ ní irú ákókò ìṣòro bẹ́ẹ̀?” Ìdáhùn náà ni nítorípé ó mọ̀. Ó mọ̀ pé Krístì ti ṣẹ́gun. Ó mọ̀ pé òun yíó tún wà pẹ̀lú ọmọbìnrin òun lẹ́ẹ̀kansíi tí òun ó sì lo ayérayé pẹ̀lú rẹ̀. Ayọ̀ àti ìwòye ayérayé nwá nípasẹ̀ sísopọ̀ mọ́ Olùgbàlà nípa dídá àti pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ àti nípasẹ̀ jíjẹ́ ọmọ̀ẹ̀hìn bíi-ti-Krístì.
Ààrẹ Nelson ti kọ́ni pe: “Gẹ́gẹ́bí Olùgbàlà ti npèsè àláfíà tí ó ‘ré gbogbo òye kọjá’ [Àwọn Fílípì 4:7], Ó tún nfúnni ní ìtóbi, ìjìnlẹ̀, àti ìbú ayọ̀ tí ó tako ọgbọ́n èrò orí tàbí òye ènìyàn. Fún àpẹrẹ, kò dàbí pé ó ṣeéṣe láti ní ìmọ̀lára ayọ̀ nígbàtí ọmọ rẹ bá njìyà pẹ̀lú àìsàn kan tí kò ṣeé wòsàn tàbí nígbàtí ó bá pàdánù iṣẹ́ rẹ tàbí nígbàtí ọkọ tàbí ìyàwó rẹ bá dà ọ́. Síbẹ̀ èyí gan an ni ayọ̀ tí Olùgbàlà nfún ni.”
Bí a ti ndá tí a sì npa àwọn májẹ̀mú mọ́, bíi ìwà ẹ̀dá a ó yí síta a ó sì ní ìfẹ́-inú láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ní imọ̀lára ìwọ̀n ayọ̀ àti ìfẹ́ tí a nmọ̀lára nínú àwọn ìbáṣepọ̀ onímájẹ̀mú wa. A lè jẹ́ ara iṣẹ́ títóbijùlọ lórí ilẹ̀ ayé lónìí—kíkó Ísráẹ́lì jọ. A lè ṣèrànwọ́ láti mú àwọn ọmọ Ọlọ́run wá sí ọ̀dọ̀ Krístì. Bí wòlíì Jákọ́bù ti kọ́ni pé, “Alábùkún-fún sì ni ẹ̀yin; fún nítorítí ẹ̀yin ti jẹ́ aláápọn ní ṣiṣe iṣẹ́ pẹ̀lú mi nínú ọgbà-àjàrà mi, tí ẹ sì ti pa àwọn òfin mi mọ́, tí ẹ̀yin sì ti mú èso àdánidá wá fún mi lẹ́ẹ̀kansíi, … ẹ̀yin yíò ní ayọ̀ pẹ̀lú mi nítorí èso ti ọgbà-àjàrà mi.”
Bí a ti nso ara wa pọ̀ láti ṣiṣẹ́ bíi ọmọ-ẹ̀hìn májẹ̀mú, ní èyíkéyìí ìpele agbára, ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Baba àti Ọmọ njẹ́ mímúdára síi, ayọ́ wa ndi títúnṣe, ìwòye ayérayé wa sì ndi gbígbòòrò. Àwa nígbànáà yíó di fífún ni ẹ̀bùn pẹ̀lú agbára a ó sì lè ní ìmọ̀lára ayọ̀ ní ìwọ̀n ti a pamọ́ fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn májẹ̀mú tòótọ́ ti Ọlọ́run. Ní orúkọ mímọ́ Jésù Krístì, àmín.