Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Foríbalẹ̀
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2025


14:14

Foríbalẹ̀

Kíni fíforíbalẹ̀ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí fún ẹ̀yin àti èmi?

“Nígbàtí a sì bí Jésù ní Bẹ́thlẹ́hẹ́mù ti Judea nígbà ayé Hẹ́rọ́dù ọba, kíyèsì, àwọn amòye kan ti ìhà ìlà-oòrùn wá sí Jérúsálẹ́mù,

“Wọ́n nbèèrè wípé, Níbo ni ẹnití a bí tí íṣe ọba àwọn júù wà? Nítorí àwa ti rí ìràwọ̀ rẹ̀ ní ìlà-oòrùn, àwà si wá láti foríbalẹ̀ fún un.”

Àwọn Maji, bí a ti npè wọ́n nígbàmíràn, ní ọgbọ́n ní wíwá láti rí àti láti foríbalẹ̀ fún Mèssíàh. Fún wọn, fíforíbalẹ̀ túmọ̀ sí títẹríba níwájú ọmọ náà Jésù àti fífun Un ní àwọn ẹ̀bùn ti wúrà àti iyebíye, àwọn èròjà dídún.

Kíni fíforíbalẹ̀ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí fún ẹ̀yin àti èmi?

Nígbàtí a ba ronú nípa ìforíbalẹ̀, àwọn èrò wa máa nyí sí àwọn ọ̀nà tí a fi nfi ìfọkànsìn ẹ̀sìn hàn ní ìkọ̀kọ̀ àti nínú àwọn ìsìn ìjọsìn pẹ̀lú. Bí mo ti nyẹ ọ̀ràn ti fíforíbalẹ̀ fún Baba wa Ọ̀run àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, Olùgbàlà wa wo, àwọn èrò mẹrin tí ó wá sí mi lọ́kan: àkọ́kọ́, àwọn ìṣe tí ó jẹ́ ìjọ́sìn wa; èkejì, àwọn ìhùwàsí àti ìmọ̀lára tí ó wọ inú ìjọ́sìn wa; ẹ̀kẹ́ta, ìyàsọ́tọ̀ ìjọ́sìn wa; àti ìkẹ́rin, ìnílò láti farawé àwọn Ẹni Mímọ́ tí à nsìn.

Àwọn Ìṣe Tí Ó Jẹ́ Ìjọsìn Wa

Irú ìjọsìn kan tí ó wọ́pọ̀ tí ó sì ṣe pàtàkì jùlọ ni láti kórajọ nínú ibi tí a yàsímímọ́ láti ṣe àwọn ìṣe ìfọkànsìn. Olúwa wípé, “Àti kí ìwọ ó lè pa ara rẹ mọ́ ní kíkún síi láìsí àbàwọ́n kúrò nínú ayé, ìwọ yíò lọ sí ilé àdúrà kí o sì rúbọ oúnjẹ Olúwa ní ọjọ́ mímọ́ mi.” Bẹ́ẹ̀ni, èyí, ni kókó ìwúnilórí nínú àwọn ilé ìjọsìn. Ṣùgbọ́n gbogbo wa mọ̀ pé, bí ó bá ṣeéṣe, ibi tí a kò yàsímímọ́ yíò ṣeé bí a bá ṣé lọṣọ pẹ̀lú ìwọ̀n ìsọdimímọ́.

Ìpàdé Oúnjẹ Olúwa

Pàtàkì jùlọ ni ohun tí a bá ṣe nígbàtí a báa kórajọ ní ọjọ́ Olúwa. Bẹ́ẹ̀ni, a nwọ aṣọ dídára wa tí a lè wọ̀ ní ìbámu sí ìnísí wa—kìí ṣe àṣejù, ṣùgbọ́n ìwọ̀ntún-wọ̀nsìn ní ọ̀nà láti fi ọ̀wọ̀ àti ìbọlá fún Ọba kan hàn. Ìwà wa bákannáà jẹ́ ọlọ́wọ̀ àti ìbọlá fún. À njọ́sìn nípa dídarapọ̀ nínú àdúrà; à njọ́sìn nípa kíkọ àwọn orin (kìí kàn ṣe fífetísílẹ̀ síi ṣùgbọ́n kíkọ àwọn orin náà); à njọ́sìn nípa kíkọ́ni àti ìkẹ́kọ̀ọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Jésù wípé, “rántí pé lórí èyí, ọjọ́ Olúwa, ìwọ yíò rú ẹbọ-ọrẹ rẹ [tí ó túmọ̀ sí, ‘àwọn ẹbọ-ọrẹ … ti àkokò, ẹ̀bùn, tàbí ọ̀nà, nínú ìsìn sí Ọlọ́run àti ọmọnìkejì’] àti oúnjẹ Olúwa rẹ sí Ọ̀gá Ògo, ní jíjẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ fún àwọn arákùnrin rẹ, àti níwájú Olúwa.” À nwá papọ̀ kìí ṣe láti ṣe àlejo tàbí gba ìṣàlejò—bíi ti ẹgbẹ́ kan, fún àpẹrẹ—ṣùgbọ́n láti rántí Rẹ̀ kí a sì gba “ìkọ́ni síi ní pípé” nínú ìhìnrere Rẹ̀.

Ní ìpàdé àpapọ̀ àìpẹ́ jùlọ, Alàgbà Patrick Kearon rán wa létí pé “a kìí kórajọ ní Ọjọ́ Ìsinmi kí a lè wà nínú ìpàdé oúnjẹ Olúwa lásán kí a lè tẹ̀ẹ́ kúrò nínú àkójọ náà. A máa nwá papọ̀ láti jọ́sìn. Ìyàtọ̀ pàtàkì kan wà láàrin méjéèjì. Láti wà níbẹ̀ túmọ̀ sí láti jẹ́ àfojúrí ní ibìkan. Ṣùgbọ́n láti jọ́sìn jẹ́ láti fi tinútinú yìn ín kí a sì bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run wa ní ọ̀nà tí ó nyíwa padà!”

Fífi ìfọkànsìn sí àwọn Ọjọ́-ìsinmi wa sí Olúwa àti èrèdí Rẹ̀ niti ara rẹ̀ jẹ́ ìṣe ìjọsìn. Àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, Alàgbà Russell M. Nelson nígbànáà ṣàkíyèsí: “Báwo ni a ó ṣe ya Ọjọ́ Ìsinmi sí mímọ́? Ní àwọn ọdún ti mo ṣì kéré ju báyi lọ, mo ṣe àṣàrò iṣẹ́ àwọn ẹlòmiràn tí wọ́n ti ṣe àkójọ àwọn àtòsílẹ̀ àwọn ohun tí ó le jẹ́ ṣíṣe àti àwọn ohun tí le jẹ́ ṣíṣe ní Ọjọ́ Ìsinmi. Ní ìgbẹ̀hìn gbẹ́hín ni mo kọ́ láti inú àwọn ìwé mímọ́ pé ìṣe àti ìwà mi ní Ọjọ́ Ìsinmi jẹ́ àmì kan láàrin èmi àti Baba mi Ọrun [wo Exodus 31:13; Ezekiel 20:12, 20]. Pẹ̀lú òye náà, èmi kò nílò àwọn àtòsílẹ̀ mọ́ nípa àwọn ṣíṣe àti àwọn máṣe. Nígbàtí mo bá níláti ṣe ìpinnu kan bóyá ìṣe kan dára tó fún Ọjọ́ Ìsinmi tàbí bẹ́ẹ̀kọ́, mo kàn máa nbi ara mi léèrè pé, ‘Irú àmì wo ni mo fẹ́ láti fifún Ọlọ́run?’”

Ìjọsìn ní ọjọ́ Olúwa ni ó fi àmì rẹ̀ hàn nípa ìdojúkọ lórí irúbọ ètùtù nlá ti Jésù Krístì. À nṣe ayẹyẹ Àjínde Rẹ̀ ní ọdún Àjínde déédé àti ní ọ̀nà pàtàkì, ṣùgbọ́n bákannáà ní gbogbo ọ̀sẹ̀ bí a ti nṣe àbápín àwọn àmì ti oúnjẹ Olúwa nípa ètùtù Rẹ̀, pẹ̀lú Àjínde Rẹ̀. Fún àwọn onírẹ̀lẹ̀, ṣíṣe àbápín oúnjẹ Olúwa ni ìsàmì ti ìjọsìn Ọjọ́-ìsinmi.

Jíjọ́sìn papọ̀ bí “ara Krístì” ní agbára àti èrè àìláfiwé bí a ti nkọ́ni, sìn, tí a sì nṣe ìmúdúró ara wa. Pẹ̀lú ìwuni, ẹ̀kọ́ àìpẹ́ kan ri pé àwọn tí wọ́n wò ìgbésí ayé ti ẹ̀mí wọn bí ìkọ̀kọ̀ pátápátá lè má ní ààyò sí ìdàgbà ti ẹ̀mí, tàbí láti wípé ìgbàgbọ́ wọn ṣe pàtàkì gan an, tàbí kí wọ́n ní àkokò ìfọkànsìn déédé pẹ̀lú Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́bí ìletò àwọn Ènìyàn Mímọ́, à nfún ara wa lókun nínú ìjọsìn àti nínú ìgbàgbọ́.

Àní nítorínáà, a kò lè gbàgbé àwọn ìṣe ojojúmọ́ ti ìjọsìn tí à nṣe ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àti ní ilé. Olùgbàlà rán wá létí, “Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀ ìwọ yíò rú ẹbọ àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ̀ nínú òdodo ní gbogbo ọjọ́ àti gbogbo àkokò.” Arábìnrin kan fi ọgbọ́n ṣàkíyèsí, “Èmì kò lè ronú ọ̀nà tó jinlẹ̀ síi láti jọ́sìn Ọlọ́run ju láti jẹ́kí àwọn ọmọ kékèké Rẹ káàbọ̀ sínú ayé wa kí a sì ṣètọ́jú fún wọn kí a sì kọ́ wọn ní ètò Rẹ̀ fún wọn.”

Álmà àti Ámúlẹ́kì kọ́ àwọn ará Sórámù tí a gbẹ́sẹ̀lé kúrò ní àwọn sínágọ́gù láti jọ́sìn Ọlọ́run kìí ṣe ní ẹ̀ẹ̀kan lọ́sẹ̀ lásán, ṣùgbọ́n nígbàgbogbo, àti “ní ibikíbi tí ẹ lè wà.” Wọ́n sọ̀rọ̀ nípa àdúrà bí ìjọsìn:

“Ẹ̀yin gbọ́dọ̀ kó àníyàn ọkàn nyín jáde nínú iyàrá nyín làti ibi ìkọ̀kọ̀ nyín, àti nínú aginjù nyín.

Bẹ́ẹ̀ni, nígbàtí ẹ̀yin kò bá sì kígbe pe Olúwa, ẹ jẹ́ kí ọkàn yín kún, kí ó sì fà síi nínú àdúrà láìsimi.”

Bákannáà wọ́n sọ̀rọ̀ ti ṣíṣe àwárí àwọn ìwé-mímọ́, jíjẹ́ ẹ̀rí nípa Krístì, ṣíṣe àwọn ìṣe ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ àti iṣẹ́-ìsìn, gbígba Ẹ̀mí Mímọ́, àti gbígbé nínú ìdúpẹ́ lójojúmọ́. Ẹ yẹ èrò náà wo: “gbígbé nínú ìdúpẹ́ lójojúmọ́.” Ó sọ̀rọ̀ sí ìlàsílẹ̀ mi èkejì:

Àwọn Ìhùwàsí àti Ìmọ̀lára Àtọ̀runwá nínú Ìjọsìn

Níní ìmọ̀lára àti fífi ìmoore hàn sí Ọlọ́run ni, nítòótọ́, ohun tí ó nmú ìjọsìn wa ní àtúnṣe ọgbọ́n aláyọ̀ ní àtàkò sí kí a kàn wò ó bí ojúṣe kan síi.

Ìjọsìn òtítọ́ túmọ̀ sí níní ìfẹ́ Ọlọ́run àti yíyọ̀ọ̀da ìfẹ́ wa sí I—ẹ̀bùn iyebíye jùlọ tí a lè fúnni. Nígbàtí a bií èyítí ó jẹ́ òfin kínní nínú gbogbo àṣẹ, Jésù fèsì,“Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ̀, àti gbogbo ọkàn rẹ̀, àti gbogbo inú rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ.” Bákannáà Ó pe èyí ní òfin àkọ́kọ́.

Èyí ni àwòṣe ti ìjọsìn ti Jésù nípa Baba. Ayé Rẹ̀ àti ìrúbọ ètùtù Rẹ̀ ni a yàsímímọ́ sí ògo ti Baba. Pẹ̀lú ìfọwọ́tọ́ a rántí ẹ̀bẹ̀ ìbanilọ́kanjẹ́ ti Jésù ní àárín ìjìyà àti ìrora àìlèrò: “Baba mi, bí ó bá ṣeéṣe, jẹ kí ago yi kọjá kúrò lọ́dọ̀ mi,” ṣùgbọ́n lẹ́hìn ìtẹríbà Rẹ̀ “bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀ kìí ṣe ìfẹ́ tèmi, ṣùgbọ́n tìrẹ ní ká ṣe.”

Krísti ní Gẹ́tsémánì

Ìjọ́sìn ni títiraka láti tẹ̀lé àpẹrẹ pípé yí. A kò ní di pípé nínú èrò yí lójúkannáà, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tí a bá “fi ìrúbọ ọkàn ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ fún [Un],” Òun yíò rì wá bọmi lẹ́ẹ̀kansi pẹ̀lú Ẹ̀mí Rẹ̀ yíò sì kún inú wa pẹ̀lú oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀.

Ẹ̀kẹ́ta, Yíyàtọ̀ ti Ìjọsìn Wa

Ní ìpín kínní ti Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú, Olúwa kéde ìfẹ̀sùnkànni yí nípa ayé:

“Wọ́n ti yapa kùrò nínú àwọn ìlànà mi, wọ́n sì ti sẹ́ májẹ̀mú ayérayé mi;

“Wọn kò wá Olúwa láti fi ẹsẹ̀ òdodo rẹ̀ múlẹ̀, ṣùgbọ́n olúkúlùkù ènìyàn nrìn ní ọ̀nà tirẹ̀, àti ní títẹ̀lé àwòrán ọlọ́run tirẹ̀, èyítí àwòrán rẹ̀ wà ní ìrí ti ayé.”

Ó dára fún wa láti rántí àpẹrẹ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Júù mẹ́ta, Hananiah, Mishael, àti Azariah, tí a gbé ní ìgbèkùn lọ sí Bábílónì láìpẹ́ lẹ́hìn tí Léhì àti ẹbí rẹ̀ fi Jérúsálẹ́mù sílẹ̀. Ọba Nebuchadnezzar tún orúkọ wọn sọ sí Shadrach, Meshach, àti Abed-nego. Lẹ́hìnnáà, nígbàtí àwọn mẹ́ta wọ̀nyí kọ̀ láti jọ́sìn èré tí wọ́n gbé kalẹ̀ nípa Ọba Nebuchadnezzar, ó pàṣẹ pé kí a jù wọ́n sínú iná ìlérù tó njó, ó wí fún wọn pé, “tani Ọlọ́run náà tí yíò sì gbà yín kúrò ní ọwọ́ mi?”

Ẹ ó rántí ìdáhùn ìgboyà wọn:

“Ọlọ́run wa ẹnití àwa nsìn lè gbà wá lọ́wọ́ iná ìlérù tí njó, òun ó sì gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀, ọba.

“Ṣùgbọ́n bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó yé ọ, … pé àwà kì yíò sin àwọn òrìṣà rẹ, bẹ́ẹ̀ni àwà kì yíò tẹríba fún ère wúrà èyí tí ìwọ ti gbékalẹ̀.”

Shadrach, Meshach, àti Abed-nego ni a gbàlà nínú iná ìléru.

Iná náà gbóná gan an tí ó fi pa àwọn tí wọ́n jù wọ́n sínú rẹ̀, ṣùgbọ́n Shadrach, Meshach, àti Abed-nego kò ní ìpalára. “Nígbànáà ni Nebuchadnezzar sọ̀rọ̀, ó sì wípé, Olùbùkún ni Ọlọ́run Shadrach, Meshach, àti Abed-nego, ẹnití ó … gba ìránṣẹ́ rẹ̀ là tí ó gbẹ́kẹ̀lé e, … wọ́n sì fi ara wọn jìn, kí wọn kí ó máṣe sìn tàbí kí wọn kí ó tẹríba fún òrìṣàkórìṣà bíkòṣe Ọlọ́run àwọn tíkalara wọn.” Wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Jèhófàh fún ìdándè, “ṣùgbọ́n bí bẹ́ẹ̀kọ́,” ni pé, àní bí Ọlọ́run Rẹ̀ kò bá dá ikú wọn dúró, síbẹ̀ wọn yíò dúró ní òtítọ́ sí I.

Ohunkóhùn tí ó bá ṣíwájú lórí ìjọsìn Baba àti Ọmọ náà di òrìṣà kan. Awọn tí wọ́n kọ Ọlọ́run bí orísun òtítọ́, tàbí kọ ẹ̀jẹ́ eyikeyi ìjiyìn sí I, ní àyọrísí rọ́pò arawọn bí ọlọ́run wọn. Ẹnikan tí ó bá fi ìṣoótọ́ sí ẹgbẹ́ tàbí èrò ṣíwájú ìdarí tọ̀run njọ́sìn ọlọ́run èké. Àní àwọn wọnnì tí wọ́n ní wọ́n njọ́sìn Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọn kò pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́ nrìn ní ọ̀nà ti ara wọn: “Wọ́n nsúnmọ́ mi pẹ̀lú ètè wọn, ṣùgbọ́n ọkàn wọn jinnà sí mi.” Ohun yíyàsọ́tọ̀ ìjọsìn wa ni “Ọlọ́run òtítọ́ kanṣoṣo, àti Jésù Krístì, ẹnití [Ó] ti rán.”

Ní òpin, ìnilò láti Farawé Baba àti Ọmọ náà

Nígbẹ̀hìn, bí a ṣe ngbé lè jẹ́ dídárajùlọ, irú àtilẹ̀bá jùlọ ti ìjọsìn. Fífi ìfọkànsìn wa hàn túmọ̀ sí fífarawé Baba àti Ọmọ náà—ìmúdàgbà àwọn ìhùwàsí àti ìwà Wọn nínú arawa. Bí, ọ̀rọ̀ náà ti lọ, ìfarawé ni irú òdodo jùlọ ti ìpọ́nni, nígbànáà a lè wípé pẹ̀lú ọ̀wọ̀ sí Ọba kan, àfarawé ni irú òdodo jùlọ ti ìbọ̀wọ̀ fún. Èyí dá àbá aápọn kan, ìlàkàkà ìmúdúró ní ọ̀dọ̀ wa láti wá ìwàmímọ́. Ṣùgbọ́n dídà bíiti Krístì síi bákannáà ni àbájáde àdánidá ti àwọn ìṣe ìjọsìn. Gbólóhùn ọ̀rọ̀ Alàgbà Kearon’s tí a kọ ṣíwájú nípa jíjọ́sìn, “ní ọ̀nà kan tí ó nyí wa padà,” ṣe pàtàkì. Ìjọsìn òtítọ́ jẹ́ ìyípadà.

Èyí ni ẹwà ipa ọ̀nà májẹ̀mú—ìpa ọ̀nà ìjọsìn, ìfẹ́, àti ìṣòótọ́ sí Ọlọ́run. À nwọnu ipa ọ̀nà nípa ìrìbọmi, jíjẹ́ ẹ̀jẹ́ láti gbé orúkọ Krístì lé orí ara wa kí a sì pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́. À ngba ẹ̀bùn ti Ẹ̀mí Mímọ́, ìránṣẹ́ oore-ọ̀fẹ́ Olùgbàlà tí ó nràpadà tí ó sì nwẹ̀ wá nù kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ bí a ti nronúpìwàdà. Àní a lè wípé à njọ́sìn Rẹ̀ nínú ríronúpìwàdà.

Níbẹ ni àtẹ̀lé àfikún àwọn ìlànà oye-àlùfáà àti májẹ̀mú tí à nṣe nínú ilé Olúwa tí ó nsọ wá dimímọ́ síi. Àwọn ayẹyẹ àti ìlànà ti tẹ́mpìlì jẹ́ irú ìjọsìn ìgbéga kan.

Ààrẹ Russell M. Nelson ti tẹnumọ pé “gbogbo ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n nkópa nínú àwọn ìlànà oyè-àlùfáà àti tí wọ́n ndá tí wọ́n sì npa àwọn májẹ̀mú mọ pẹ̀lú Ọlọ́run ní ààyè tààrà sí agbára Ọlọ́run.” Èyí kìí ṣe agbára tí à nfa lé orí láti sìn àti láti bùkún nìkan. Ó jẹ́ agbára tọ̀run tí ó nṣiṣẹ́ nínú wa láti túnṣe àti láti yà wá sí mímọ́ bákannáà. Bí a ti nrìn ní ipa ọ̀nà màjẹ̀mú, agbára ”ìyàsímímọ́ ti-ọlọ́run ni ó farahàn” nínú wa.

Bóyá àwà, bí àwọn ará Néfì àti Lámánì àtijọ́, “ṣubú lulẹ̀ ní ẹsẹ̀ Jésù, wọ́n sì … jọ́sìn rẹ̀.” Njẹ́ àwà, bí a ti pàṣẹ́ nípasẹ̀ Jésù, “ṣubú lulẹ̀ kí a sì jọ́sìn Baba [ní] orúkọ [Ọmọ náà].” Njẹ́ kí a gba Ẹ̀mí Mímọ́ kí a sì yí ọkàn wa sí Ọlọ́run, kí a máṣe ní ọlọ́run míràn níwájú Rẹ̀, àti bí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Jésù Krístì, farawé ìwà Rẹ̀ nínú ìgbésí ayé ti ara wa. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé bí a ti nṣe é, a ó ní ìrírí ayọ̀ ìjọsìn. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.