Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
“Nípa Èyí Gbogbo Ènìyàn Yíó Mọ̀ Pé Ẹ̀yin Jẹ́ Ọmọ-ẹ̀hìn Mi”
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2025


15:4

“Nípa Èyí Gbogbo Ènìyàn Yíó Mọ̀ Pé Ẹ̀yin Jẹ́ Ọmọ-ẹ̀hìn Mi”

Ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run àti àwọn ọmọ Rẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí alágbára kan sí aráyé pé ní tòótọ́ èyí ni Ìjọ Kristì náà.

Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn Arábinrin Uchtdorf àti èmi nrin ìrìnàjò kọjá ní ìhà gúsù Germany. Ó jẹ́ kété ṣaájú Ọdún Àjínde, a sì pe ọ̀rẹ́ dáradára kan, tí kìí ṣe ọmọ Ìjọ, láti darapọ̀ mọ́ wa nínú iṣẹ́-ìsìn ìjọ́sìn wa Ọjọ́ Ìsinmi. A fẹ́ràn ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n yí, nítorínáà ó ṣe déédé àti bíi ìwà ẹ̀dá láti pín ìmọ̀lára wa pẹ̀lú rẹ̀ nípa Olùgbàlà àti Ìjọ Rẹ̀ àti láti pè é láti wá wòó! Ó tẹ́wọ́gba ìpè náà ó sì darapọ̀ mọ́ wa níbi àwọn ìpàdé ti ẹ̀ka kan nítòsí.

Bí o bá ti mú ọ̀rẹ́ kan wá sí ilé ìjọsìn fún ìgbà àkọ́kọ́ rí, bóyá o lè fi òye gbé irú ìmọ̀lára tí mo ní ní òwúọ̀ Ọjọ́ Ìsinmi náà. Mo fẹ́ kí ohun gbogbo lọ ní pípé. Ọ̀rẹ́ wa jẹ́ ọ̀mọ̀wé, ẹni ẹ̀mí dáradára kan. Mo nírètí pẹ̀lú ìtara pé àwọn ìpàdé ẹ̀ka yí yíó fún un ní ìwúrí àti pé kí ó ṣojú Ìjọ dáradára.

Ẹ̀ka náà npàdé nínú àwọn yàrá àyágbé kan ní àjà kejì ilé ìtajà nlá kan. Láti dé ibẹ̀, a níláti lo àwọn àkàsọ̀ ní ẹ̀hìn ilé náà, ní kíkọjá àwọn òórùn dídùn líle láti inú àwọn ọjà tí wọ́n kó pamọ́ síbẹ̀.

Bí ìpàdé oúnjẹ Olúwa ti bẹ̀rẹ̀, mo ronú nípa ọ̀rẹ́ mi tí ó nní ìrírí yí fún ìgbà àkọ́kọ́, èmi kò sì lè ṣe àìkíyèsí àwọn ohun kan tí ó mú mi tijú díẹ̀. Orin kíkọ, fún àpẹrẹ, kò dún bíi ti Ẹgbẹ́ Akọrin Àgọ́. Àwọn ọmọdé tí wọ́n nsáré kiri pẹ̀lú ariwo ni a le gbọ́ ní ìgbà oúnjẹ Olúwa. Àwọn tó sọ̀rọ̀ ṣe dídárajùlọ wọ́n, ṣùgbọ́n wọn kò ní ìmọ̀ ọ̀rọ̀ sísọ ní gbangba. Mo jókòó pẹ̀lú àìbalẹ̀ ara ní gbogbo ìpàdé náà, ní ìrètí pé bóyá Ilé Ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi yíó dárajù.

Kò rí bẹ́ẹ̀.

Ní gbogbo òwúrọ̀ mo ṣàníyàn nipa ohun tí ọ̀rẹ́ wa yíó rò nípa ilé ìjọsìn tí a ti mú un wá yìí.

Lẹ́hìnnáà, bí a ti nwakọ̀ lọ sílé, mo yíra láti bá ọ̀rẹ́ wa sọ̀rọ̀. Mo fẹ́ ṣàlàyé pé eléyìí kàn jẹ́ ẹ̀ka kékeré kan àti pé kò dúró fún Ìjọ náà ní odidi. Ṣùgbọ́n kí ntó sọ ọ̀rọ̀ kan, òun sọ̀rọ̀ sókè.

“Èyíinì rẹwà o,” ni ó sọ.

Èmi kò le sọ̀rọ̀ mọ́.

Ó tẹ̀síwájú, ˇMo ní ìtẹ̀mọ́ra tóbẹ́ẹ̀ pẹ̀lú bí àwọn ènìyàn ṣe ntọ́jú ara wọn nínú ìjọ yín. Gbogbo wọ́n dàbí ẹnipé wọ́n wá láti àwọn àgbétẹ́lẹ̀ tó yàtọ̀, àti pé síbẹ̀ ó hàn kedere pé wọ́n nì ojúlówó ìfẹ́ sí ara wọn, Èyí ni ohun tí mo rò pé Krístì fẹ́ kí Ìjọ Rẹ̀ ó dàbí.”

Ó dára, mo yára ronúpìwàdà ìwà ẹjọ́ dídá mi. Èmi fẹ́ àwọn ìpàdé tó wàní-pípé láti mú kí ó wu ọ̀rẹ́ mi. Ṣùgbọ́n ohun tí àwọn ọmọ ìjọ ẹ̀ka yi ṣe yọrí ni ọkàn pípé ti ẹ̀mí ìfẹ́, inúrere, sùúrù, àti àánú.

“Pé Kí Ìgbàgbọ́ Le Pọ̀ síi ni Ilẹ̀ Ayé”

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, mo fẹ́ràn Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Ó jẹ́ Ìjọ tòótọ́ àti alààyè ti Olùgbàlà, ó sì nkọ́ni ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere Jésù Krístì tí a múpadábọ̀sípò. Agbára ati àṣẹ oyè-àlùfáà Rẹ̀ ngbé níhin. Jésù Krístì ndarí Ìjọ yìí fúnrarẹ̀, nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ ti Òun ti pè tí Ó sì ti fún láṣẹ, àti nípa wòlíì alààyè kan, àní Ààrẹ Russell M. Nelson. Olùgbàlà ti fún àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ikẹhìn ní iṣẹ́ àrà ọ̀tọ̀ láti kó àwọn ọmọ Ọlọ́run jọ kí wọn ó sì pèsè ayé sílẹ̀ fún Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Olùgbàlà. Mo jẹ́ ẹ̀rí mi pé gbogbo èyí jẹ́ òtítọ́.

Ṣùgbọ́n ó ṣe pàtàkì láti rántí pé nígbàtí púpọ̀ jùlọ àwọn ènìyàn bá ní ìrírí Ìjọ Jésù Krístì fún ìgbà àkọ́kọ́, wọn kò ronú nípa àṣẹ oyè-àlùfáà tàbí àwọn ìlànà tàbí kíkó Isráẹ́lì jọ. Ohun tí ó ṣeéṣe kí wọn ó fura sí, ju gbogbo ohun miràn lọ, ni ìmọ̀lára tí wọ́n ní nígbàtí wọ́n wà pẹ̀lú wa àti bí a ti ntọ́jú ara wa.

“Ẹ Fẹ́ràn ara yín,” ni Jésù wí. “Nípa èyí ẹni gbogbo yíó mọ̀ pé ẹ̀yin jẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn mi.” Nígbà púpọ̀, ẹ̀rí àkọ́kọ́ ènìyàn nípa Jésù Krístì máa nwá nígbàtí ọkùnrin tàbí obìnrin náà bá ní ìmọ̀lára ìfẹ́ láàrin àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Jésù Krístì.

Olùgbàlà wí pé Òun mú Ìjọ Òun padàbọ̀sípò “kí ìgbàgbọ́ … le pọ̀ síi ní ilẹ̀ ayé.” Nítorínáà, nígbàtí àwọn ènìyàn bá wá sí àwọn ìpàdé Ìjọ wa, Olùgbàlà fẹ́ kí wọn ó lọ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ líle sìi nínú Rẹ̀! Ìfẹ́ tí àwọn ọ̀rẹ́ wa bá mọ̀lára ní ààrin wa yíó gbé wọn súnmọ́ Jésù Krístì síi! Èyí ni ibi-afẹ́dé ìrọ̀rùn wa ní gbogbo ìgbà tí a bá péjọ.

Ẹnikẹ́ni tí ó bá nlépa ìgbàgbọ́ nlá sìi nínú Krístì tàbí ìsopọ̀ sísúnmọ́ síi sí Baba Ọ̀run níláti ní ìmọ̀lára wíwà nílé nínú Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Pípè wọ́n sí àwọn ìpàdé wa le jẹ́ déédé àti ìwà ẹ̀dá bíi pípè wọ́n sínú ilé wa.

Bí Ó ti Yẹ àti Bí Ó ti Rí

Nísisìnyí, mo mọ̀ pé mo nṣe àpejúwe bi ó ti yẹ kí ó rí. Àti pé ninú ayé kíkú yí, a kìí sáàbà ní ìrírí bi ó ti yẹ kí ó rí. Àti pé “títí di ọjọ́ pípé náà” àlàfo yíó máa fi gbogbo ìgbà wà láàrin bí ó ti yẹ kí ó rí àti bí ó ti rí. Nítorínáà, kínni a níláti ṣe nígbàtí Ìjọ kò bá nímọ̀lára bíi ọjọ́ pípé kan? Nígbàtí, fún èyíkéyí ìdí, wọ́ọ̀dù wa kò bá tíì mú ìgbàgbọ́ tàbí ìfẹ́ pípé dàgbà? Tàbí nígbàtí ìmọ̀lára nwá bíi pé a kò yẹ níbẹ̀?

Ohun kan tí a níláti ṣe ni ki a dáwọ́ dúró lórí bí ó ti yẹ kí ó rí!

Ojú ewé àkọlé Ìwé ti Mọ́rmọ́nì ní ìkìlọ̀ pàtàkì yí nínú pé: “Bí àwọn àlébù bá wà,” ni ó wí, “wọ́n jẹ́ àlébù ti àwọn ènìyàn, nítorínáà, máṣe dá àwọn ohun ti Ọlọ́run lẹ́bi.”

Njẹ́ ìwé kan—tàbí ìjọ kan tàbí ènìyàn kan—le ní “àwọn àlébù” àti “àwọn àṣìṣe” kí ó sì jẹ́ iṣẹ́ Ọlọ́run síbẹ̀?

Ìdáhùn mi ni àsọtúnsọ bẹ́ẹ̀ni!

Nítorínàà, nígbàtí a bá mú ara wa sí àwọn òsùnwọ̀n gíga ti Olúwa, ẹ jẹ́kí a ní sùúrù bákannáà pẹ̀lú ara wa. Olukúlùkù wa jẹ́ iṣẹ́ kan ti ó ntẹ̀síwájú, gbogbo wa sì gbára lé Olùgbàlà fún èyíkéyìí ìlọsíwájú ti a bá ní. Èyí jẹ́ òtítọ́ fún wa bí ẹnìkọ̀ọ̀kan, ó sì jẹ́ òtítọ́ fún ìjọba Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé.

Olúwa npè wa kìí ṣe láti kàn darapọ̀ mọ́ ìjọba Rẹ̀ ṣùgbọ́n bákannáà láti fi ìtara kópa nínú kíkọ́ rẹ̀. Ọlọ́run nwòye àwọn ènìyàn kan tí wọ́n jẹ́ “ọkàn kan àti àyà kan.” Àti láti jẹ́ ti ọkàn kan, a gbọ́dọ̀ wá ọkàn àìléèrí , èyí sì nílò ìyípadà ọkàn nlá.

Ṣùgbọ́n ìyẹn kò túmọ̀ sí pé èmi ó yí ọkàn mi padà láti wà ní ìbámu pẹlú tìrẹ. Tàbí kí ó túmọ̀ sí yíyí ọkàn tirẹ padà láti wà ní ìbámu pẹ̀lú tèmi. Ó túmọ̀ sí pé kí gbogbo wa yí ọkàn wa padà láti wà ni ìbámu pẹ̀lú Olùgbàlà.

Bí a kò bá tíì sí níbẹ̀, ẹ rántí, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olúwa, kò sí ohun tí kò ṣeéṣe.

Ìbámu àti Jíjẹ́ ti Ara-kan

Àti pé bí ẹ bá ní ìmọ̀lára rí pé ẹ kò wà ní ìbámu tóbí ẹnipé ẹ ko yẹ tó, ẹ jọ̀wọ́ ẹ mọ̀ pé ẹ kò dá nìkan wà. Njẹ́ gbogbo wa kò ha ti wà ní àwọn ipò ìgbé ayé nígbàtí a nmọ̀lára bíi àjèjì nínú yàrá náà? Mo ti ní ìrírí yìí ju ìgbà kan lọ. Nígbàtí mo wà ní ọmọ ọdún mọ́kànlá, a fi ipá mú ẹbí mi láti fi ibùgbé wa sílẹ̀ tí a sì kó lọ sí agbègbè kan tí a kò mọ̀. Ohun gbogbo yàtọ̀ sí ohun tí mo ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Ìsọ̀rọ̀ mi si fi hàn kedere sí àwọn ọmọdé míràn pé èmi yàtọ̀ sí ohun tí àwọn ti dámọ̀ tẹ́lẹ̀. Ní àkókò kan nígbàtí mo nílò ìbádọ́rẹ̀ẹ́ àti jíjẹ́ ti ara-kan gidi, mo ni ìmọ̀lára dídánìkanwà àti àìnílé.

Níhin lórí ilẹ̀ ayé, púpọ̀jù àwọn ìyàtọ̀ tí a nfura sí—àwọn ìyàtọ̀ tí àwọn kan lára wa nlò láti pín ara wọn sí ìsọ̀rí—ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ohun ti ayé: ìfarahàn àfojúrí, orílẹ̀-èdè ìbí, èdè, ìwọṣọ, àwọn àṣà, ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n, “Ọlọ́run kìí wo àwọn nkan bí àwọn ènìyàn ti í ṣe. Àwọn ènìyàn máa nwo ìrínisí òde-ara, ṣùgbọ́n Olúwa máa nwo ọkàn.”

Látinú ìwòye Rẹ̀, ìsọ̀rí kan wà tí ó nwá ṣaáju gbogbo àwọn míràn: ọmọ Ọlọ́run. Gbogbo wa ní ìbámu pípé nínú ọ̀kan yí.

Ó jẹ́ ìwà ẹ̀dá láti fẹ́ áti wà ní àyíká àwọn ènìyàn ti wọ́n rí, nsọ̀rọ̀, nṣe ìṣe, àti nronú bí àwa ti nṣe. Ìbikan wà fún èyí.

Ṣùgbọ́n nínú Ìjọ ti Olùgbàlà, a nkó gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run jọ tí wọ́n ṣetán láti jẹ́ kíkójọ àti tí wọ́n nwá òtítọ́. Kì í ṣe ìrísí àfojúrí, ìwòye òṣèlú, àṣà, tàbí ẹ̀yà wa ni ó nmú wa papọ̀. Kìí ṣe àgbétẹ́lẹ̀ wa to wọ́pọ̀ ló nṣe wá lọ́kan. Ó jẹ́ àfojúsùn wa tó wọ́pọ̀, ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run àti ìfẹ́ fún aládùúgbò, ìfarajì wa sí Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀ tí a múpadàbọ̀sípò. Àwa Jẹ́ “ọ̀kan ninu Krístì.”

Ìrẹ́pọ̀ tí a nwá kìí ṣe láti jẹ́ kí gbogbo ènìyàn dúró ní ibi kannáà; ó jẹ́ láti mú kí gbogbo ènìyàn kọjú sí ọnà kannáà—sí ìhà Jésù Krístì. A jẹ́ ọ̀kan, kìí ṣe nítorí ibi tí a ti dé, ṣùgbọ́n ibi tí a ntiraka láti lọ, kìí ṣe nítorí ẹni tí a jẹ́ ṣùgbọ́n ẹni tí a nlépa láti jẹ́.

Èyí ni ohun tí Ìjọ òtítọ́ Krístì wà fún.

Ara Kan

Bí ẹ bá fẹ̀ràn Ọlọ́run, bí ẹ bá fẹ́ mọ̀ Ọ́ dàra síi nipa títẹ̀lé Ọmọ Rẹ, nígbànáà ẹ jẹ́ ti ìhìn. Bí o bá nfi ìtara lépa láti pa àwọn òfin Olùgbàlà mọ́—àní bí o kò tilẹ̀ tíì jẹ́ pípé nípa rẹ̀ síbẹ̀—nígbànáà ìwọ yẹ ní pípé fún Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.

Àti pé báwo ni bi ẹ bá yàtọ̀ sí àwọn ènìyàn ní àyíká yín? Èyí kò sọ ọyím di àìyẹ—ó mú yín jẹ́ apákan ara Krístì tí a nílò. Gbogbo ènìyàn ni a nílò nínú ara Krístì. Àwọn etí ngbọ́ ohun tí ojú kò lè rí láé. Ẹsẹ̀ nṣe àwọn ohun ti àwọn ọwọ́ kò ní le ṣe dáradára.

Èyí kò túmọ̀ sí pé iṣẹ́ rẹ jẹ́ láti yí gbogbo èniyàn padà láti dàbí rẹ. Ṣùgbọ́n ó túmọ̀ sí pé ẹ ní ohun pàtàkì kan láti fi sílẹ̀—àti pé ẹ ní ohun pàtàkì kan láti kọ́!

Ohùn Kan

Ní gbogbo abala ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò, a ndi alábùkúnfún pẹ̀lú orin onímìísí láti ọ̀dọ̀ àwọn akọrin tó ní ẹ̀bùn. Bí ẹ ti nfetísílẹ̀, ẹ lè fura pé gbogbo àwọn akọrin náà kìí kọ irú ohùn kannáà. Nígbàmíràn àwọn apákan a gbé adùn orin, nígbàmíràn àwọn míràn. Ṣùgbọ́n gbogbo wọn nlọ́wọ́ sí ìró rírẹwà náà, wọ́n sì nní ìrẹ́pọ̀ pátápátá. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ọmọ ẹgbẹ́ akọrin ní àfojúsùn kannáà: láti yin Ọlọ́run àti láti gbé ọkàn wa sókè sí I. Ọ̀kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ fi iyè àti ọkàn rẹ̀ sórí èrèdí àtọ̀runwá kannáà. Nígbàtí èyí bá sì ṣẹlẹ̀, wọ́n máa ndi ohùn kan nítòótọ́.

Bí ẹ kò bá tíì di ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, a pè yín láti darapọ̀ mọ́ wa bí a ti nyọ ayọ̀ nínú “orin ìràpadà ti ìfẹ́” Olùgbàlà.” A nílò yín. A fẹ́ràn yín. Ìjọ yíó dára síi pẹ̀lú àwọn aápọn yín láti sin Olúwa àti awọn ọmọ Rẹ̀.

Bí ẹ bá ti fihàn tẹ́lẹ̀, nípasẹ̀ ìrìbọmi, nípasẹ̀ dídá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, ìfẹ́ inú yín láti “wá sínú agbo Ọlọ́run, àti lati jẹ́ pípè ni àwọn ènìyàn rẹ̀,” ẹ ṣeun fún jíjẹ́ ara iṣẹ́ nlá àti àtọ̀runwa yí àti fún ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ láti mú Ìjọ Jésù Krístì jẹ́ ohun tí Olùgbàlá fẹ́ kí ó jẹ́.

Bí mo ti kọ́ láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ mi ní Germany, ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run àti àwọn ọmọ Rẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí alágbara kan sí aráye pé nítòótọ́ èyí ni Ìjọ Olùgbàlà.

Njẹ́ kí Ọlọ́run bùkún wa kí a le fi sùúrù ṣùgbọ́n pẹ̀lú aápọn lépa láti gbé nínú òṣùnwọ̀n bí ó ti yẹ kí ó rí tí Olùgbàla, Olùràpadà, àti Olúwa wa ti gbékalẹ̀ fún wa—kí gbogbo ènìyàn le mọ̀ pé a jẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀. Ní orúkọ mímọ́ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Jòhánnù 13:34–35, New King James Version.

  2. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 1:21.

  3. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 46:5–6.

  4. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 50:24.

  5. Mósè 7:18.

  6. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 97:21.

  7. Wo Álmà 5:14.

  8. Wo Lúkù 1:37.

  9. 1Sámúẹ́lì 16:7, New English Translation.

  10. Wo Russell M. Nelson, “Àwọn Yíyàn Fún Ayérayé” (ìsìn àkanṣe káríayé fún àwọn ọ̀dọ́ àgbà, 15 Oṣú Karun, 2022), Ibi-ìkàwe Ìhìnrere.

  11. Gàlátíà 3:28.

  12. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 6:36.

  13. Wo 1Kọ́ríntì 12:12–27. Nínú ara Krístì, a kìí fi ojú fo àwọn ìyàtọ̀, àti pé a kìí kàn fi ara dà wọ́n. A dúpẹ́ fún ìkópa àrà ọ̀tọ̀ tí ọmọ ìjọ kọ̀ọ̀kan ṣe, fún rere ti gbogbo ara náà.

  14. Gẹ́gẹ́ bí yíó ti jẹ́ àìtọ́ fún etí láti wo ara náà kí ó sì wí pé, “Èmi kò dàbí ojú, kò gbọdọ̀ sí àyè fún mi ni ìhín,” yíó jẹ́ àìtọ́ bákannáà fún ojú láti wí fún etí pé, “Ìwọ kò dàbí èmi, a kò nílò rẹ ní ìhín” (wo 1Kọ́ríntì 12:16, 21).

  15. Álmà 5:26.

  16. Mòsíàh 18:8. Nígbàti a rì wá bọmi, a jẹ́ ẹ̀rí pé, láàrin àwọn nkan míràn, a fẹ́ láti jẹ́ ara àwọn ènìyàn kan tí wọ́n “nbá ara wọn gbé àwọn ìṣoro” àti “nṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú àwọn [ẹnití] nṣọ̀fọ̀” àti tí wọ́n “ntu àwọn tí wọ́n nílò ìtùnú nínú” (ẹsẹ 8–9). Ní àwọn ọ̀rọ̀ míràn, nígbàtí a bá darapọ̀ mọ́ Ìjọ Jésù Krístì, a nwí—pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ṣùgbọ́n ní kedere—pé a fẹ́ láti dàbí Olùgbàlà wa ọ̀wọ́n síi, a sì fẹ́ láti ṣe é papọ̀.