Ṣọ́ra Ìdánwò Kejì
Ẹ máṣe fi ara pamọ́ fún àwọn tí yíò fẹ́ràn, tí wọn yíó sì ṣe àtìlẹhìn yín; dípò bẹ́ẹ̀, ẹ sáré sí wọn.
Ní ọdún bíi mélòó kan sẹ́hìn, nígbàtí mo pé ọmọ ọdún méjìlá, wọ́n pè mí láti wà níbi ìpàgọ́ òru mọ́jú ti iyejú Oyè Àlùfáà Árónì fún ìgbà àkọ́kọ́ mi. Èyí jẹ́ ìfipè tí a ti nretí tipẹ́ nítorí baba mi jẹ́ olórí iyejú kan òun sì máa nfi ìgbàgbogbo lọ sí ìpàgọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin wọ́ọ̀dù, nígbàtí a máa nfi èmí sílẹ̀ nílé.
Nígbàtí ọjọ́ náà dé, inú mi dùn. Àti pé mo gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́ pé mo fẹ́ gidigidi láti ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin àgbàlagbà. Mo pinnu láti fi ara mi hàn. Nínú ìtiraka náà, kò pẹ́ tí wọ́n fi dán mi wò láti mọ̀ bóyá mo máa ṣeré pẹ̀lú wọn kí nsì jẹ́ ara ẹgbẹ́ náà.
Iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún mi ni láti gba kọ́kọ́rọ́ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ baba mi kí wọ́n lè ṣe eré kan lé àwọn olóri. Èmi kò rántí gangan ohun tí mo sọ láti pàrọwà fún baba mi, ṣùgbọ́n láìpẹ́ mo sáré lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ ọmọkùnrin pẹ̀lú àwọn kọ́kọ́rọ́ ní ọwọ́, mo ní ìyangàn fún àṣeyọrí mi.
Nígbànáà ni ìyànsíṣẹ́ tí ó kàn. Mo ní láti ṣí ìlẹ̀kùn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kí a sì fi igi kan sí ààrín ìfẹ̀hìntì awakọ̀ àti fèrè ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́. Àti pé mo ní láti ti ìlẹ̀kùn kí fèrè náà lè fọn títí ìrọ̀lẹ́ láìsí èyíkèyí ọ̀nà láti wọlé sí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà láti yọ ohun èlò àtọwọ́dá náà kúrò.
Èyí, ni ibi tí ìtàn náà ti di dídàmú onírora fún mi. Ní kété tí mo di ọ̀pá náà mú níbi tó yẹ, mo ti lẹ̀kùn mo sì sáré bí mo ti lè ṣe láti farapamọ́ sínú àwọn igbó tí ó wà nítòsí. Bí mo ṣe kúnlẹ̀, mo nímọ̀lára ìrora gbígbóná janjan. Nínú òkùnkùn àti nínú ìyára mi, mo ti jókòó lórí igi ọ̀rọ̀ èso píà onírìíra.
Ìró igbe ìrora mi ni a bòmọ́lẹ̀ nípa fèrè aláriwo náà, mi ò sì ní ohun tó lè gbà mí ju pé kí npadà sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, ní jíjẹ́wọ́ “àwọn ẹ̀ṣẹ̀” mi, kí nsì máa wá ìtọ́jú ìṣègùn tó ntini lójú.
Ní ìyọ́kù alẹ́ náà, mo dùbúlẹ̀ lórí ikùn mi nínú àgọ́ kan nígbà tí baba mi, ní lílò àwọn píláyà, yọ àwọn ẹ̀hìn igi ọ̀rọ̀ kúró nínú … mi ó dara, jẹ́ kí nkan wípé mi ò jókòó pẹ̀lú ìtùra fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ lẹ́hìnnáà.
Mo ti ronú lórí ìrírí náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà. Mo ti lè rẹ́rìn-ín nísisìyí sí ìwà òmùgọ̀ ìgbà èwe mi àní gẹ́gẹ́bí àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ti ṣe kedere sí mi.
Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ìhùwàsí ẹ̀dá ènìyàn dà bí èyí tí ó wọ́pọ̀ nínú ènìyàn àdánidá—ìfẹ́ inú láti báa mu, ìfẹ́ inú láti fi araẹni hàn, ìbẹ̀rù pípàdánù, àti ìdí tí ó múni nípá ìnílò láti sápamọ́ kí a lè yẹra fún àwọn àbájáde rẹ̀. Ìhùwàsí ìkẹhìn yi ni èmi yíò fojúsí lónìí—sísá pamọ́ lẹ́hìn tí a ṣe nkan tí kò yẹ̀.
Báyìí, èmi kò fi eré ọmọdé mi dọ́gba pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ búburú, ṣùgbọ́n a lè fa àwọn àfiwéra díẹ̀ tó lè wúlò bí a ṣe dán wa wò nínú àtìpó ayé ikú wa.
Nínú Ọgbà Édẹ́nì, Ádámù àti Éfà ní ìṣẹ̀lẹ̀ aláìlẹ́gbẹ́ kan—ọ̀pọ̀ oúnjẹ, ẹwà àìlákàwé ọgbà náà—kì í ṣe ọgbà rírẹwà nìkan ṣùgbọ́n ọgbà tí kò ní èpò tàbí píà onírìíra .
Síbẹ̀síbẹ̀, a tún mọ̀ pé ìgbé ayé ọgbá dín ìlọsíwájú tí wọ́n nílò kù. Ọgbà náà kì í ṣe ibi tí ó gbẹ̀hìn bí kò ṣe àdánwò, àkọ́kọ́ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí yíò fi ẹ̀rí hàn, múra sílẹ̀, tí yíò sì jẹ́ kí wọ́n tẹ̀ síwájú sí ibi tí wọ́n nlọ ní ìkẹhìn pìpadàbọ̀ síwájú Baba àti Ọmọ.
Ìwọ yíò rántí pé àtakò wà nínú ọgbà náà. Lúsíférì ni a gbà láàyè láti dán Ádámù àti Éfà wò. Ó kọ́kọ́ dán Ádámù wò láti jẹ nínú èso igi ìmọ̀ rere àti búburú. Ní rírántí májẹ̀mú náà láti máṣe jẹ nínú rẹ̀, Ádámù kọ̀. Nígbànáà ni alábùkúnfùn Éfà wá, ẹni tí ó yàn láti jẹ nínú èso náà, ní yíyí Ádámù lọ́kàn padà láti ṣe bàkannáà.
Lẹ́hìnnáà, Ádámù àti Éfà kéde pé ìpinnu yìí ṣe pàtàkì láti mú ètò Baba Ọ̀run ṣẹ. Ṣùgbọ́n nípa jíjẹ nínú èso náà, wọ́n ti rú òfin—òfin kan tí a fi fún wọn ní tààràtà láti ọ̀dọ̀ Baba. Àbájáde àti fífúnpa òye rere àti búburú gbọ́dọ̀ fi wọ́n sílẹ̀ nínú ìrora nígbàtí wọ́n gbọ́ ohùn Baba ní kíkéde ìpadàbọ̀ Rẹ̀ sí ọgbà. Wọ́n mọ̀ pé àwọn wà ní ìhòòhò, nítorí pé nítòótọ́ ni wọ́n wa láìní aṣọ, wọ́n sì ngbé ní ipò àìmọ́kan. Ṣùgbọ́n bóyá dídunni jù gan-an ni wíwà láìsí aṣọ wọn ní àkókò náà, tí a ti fi wọ́n hàn nísisìyí fún ìrékọjá wọn. Wọn jẹ́ aláìláàbò àti aláìlágbára. Wọn wà ní ìhòhò ní gbogbo ọgbọn orí àwọn ọ̀rọ̀ náà.
Láé Lúsíférì, olùwá-ààyè náà, ní mímọ̀ ipò ìfihàn àti àìlera wọn, tún dán wọn wò lẹ́ẹ̀kansi—ní àkókò yí láti farapamọ fún Ọlọ́run.
Ìdánwò yí—èmi yíò pè é ní “ìdánwò kejì”—ni ìdánwò tí ó lè mú àbájáde títóbi jùlọ wá tí a bá juwọ́sílẹ̀. Dájúdájú, láti yẹra fún gbogbo àwọn ìdánwò àkọ́kọ́ láti rú òfin Ọlọ́run jẹ́ dídára, ṣùgbọ́n a mọ̀ pé gbogbo ènìyàn yíò juwọ́lẹ̀ fún onírúurú ìdánwò àkọ́kọ́ níhì-ín lórí ilẹ̀-ayé. Bí a ṣe ntẹ̀ síwájú nínú dídàgbà àti òye wa, a nírètí pé okun wa láti yẹra fún àwọn ìdánwò àkọ́kọ́ yíò túbọ̀ gbèrú sí i bí a ṣe ntiraka láti túbọ̀ dà bí Olùgbàlà wa, Jésù Krístì síi.
Àwọn kan lè gbìyànjú láti sápamọ́ fún Ọlọ́run nítorí pé wọn ò fẹ́ kí wọ́n ṣàwárí wọn tàbí kí wọ́n firawọn hàn, wọ́n sì nní ìmọ̀lára ìtìjú tàbí ẹ̀bi. Bíótiwùkíórí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹsẹ ìwé mímọ́ kọ́ wa pé sísápamọ́ fún Ọlọ́run kò ṣeéṣe. Èmi yìó ṣe àbápín díẹ̀ níkan:
Olúwa kọ́ Jeremíàh nípasẹ̀ àwọn ìbéèrè wọ̀nyí: “Ẹnikẹ́ni ha le fi ara rẹ̀ pamọ nì ibi ìkọkọ tí èmi kì yíò fi rí i? ni Olúwa wí. Èmi kò ha kún ọ̀run òhun ayé?”
Àti pé a kọ́ Jóbù:
“Nítorí ojú rẹ̀ nbẹ ní ọ̀nà ènìyàn, ó sì rí gbogbo ìrìn rẹ̀.
“Kò sí òkùnkùn, tàbí òjìji ikú, níbi tí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ yíò ti fi ara wọn pamọ́.”
Onísáàmù Dáfídì nínú ọ̀pọ̀ ewì kígbe pé:
“Olúwa, ìwọ ti wádìí mi, ìwọ sì ti mọ̀ mí.
“Ìwọ mọ ìjòkó mi àti ìdìde mi, ìwọ mọ̀ èrò mi ní ọ̀nà jíjìn réré. …
“Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi, kíyèsí i, Olúwa, ìwọ mọ̀ ọ́ pátápátá. …
“Níbo ni èmi o gbé lọ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀mí rẹ? tàbí níbo ni èmi o sáré kúrò níwájú rẹ?
“Bí èmi bá gòkè lọ sí ọ̀run, ìwọ wà níbẹ̀: bí èmi bá sì tẹ́ ẹní mi ní ipò òkú, kíyèsí i, ìwọ wà níbẹ̀.”
Àwọn Olùyípadà Titun
Fún àwọn wọnnì tí wọ́n ti darapọ̀ mọ́ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn láìpẹ́, ìdánwò kejì lè dàbí ìpèníjà ní pàtàkì. Nípasẹ̀ ìrìbọmi yín ẹ ti ṣe àdéhùn láti gbé orúkọ Jésù Krístì sórí ara yín, èyítí ó jẹ́ pé ó pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbé ayé ti o nílò ìyípadà. Yíyí ìgbé ayé ènìyàn padà kò rọrùn. Nígbàgbogbo ó nílò kí ẹ yí àwọn àṣà àti àwọn ìṣe padà àti pàápàá àwọn ẹgbẹ́ láti tẹ̀síwájú sí ọ̀dọ́ olùfẹ́ni Baba yín Ọ̀run.
Ọ̀tá náà mọ́ pè o lè jẹ́ aláìlera sí àwọn ìkọlù àrekérekè rẹ. Òun yíò jẹ́ kí ìgbé ayé yín tí ó kọjá, èyítí kò jẹ́ kí ẹ ní ìtẹ́lọ́rùn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà, báyìí dàbí wíwuni láìṣe òtítọ́. Olùfisùn náà, gẹ́gẹ́bí a ti pè é nínú ìwé Ìfihàn, yíò dán yín wò pẹ̀lú àwọn ìrònú tí ó dún bí èyí: “Ìwọ kò lágbára tó láti yí ìgbé ayé rẹ padà; ìwọ kò lè ṣe èyí; ìwọ kò wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn wọ̀nyí; wọn kì yíò gbà ọ́ láé; ìwọ jẹ́ aláìlera jù.”
Bí ó bá dà bíi pé àwọn èrò wọ̀nyí ndún ní òtítọ́ sí ẹ̀yin tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbìn sí ipa ọ̀nà májẹ̀mú, a bẹ̀ yín láti má ṣe fetí sí ohùn olùfisùn náà. A fẹ́ràn yín; ẹ lè ṣe é; a tẹ́wọ́gba yín; àti pé, pẹ̀lú Rẹ̀, ẹ̀yin yíò ní agbára láti ṣe ohun gbogbo. Ní àkókò tí ẹ nílò ìfẹ́ àti àtìlẹ́hìn wa púpọ̀ jùlọ, ẹ máṣe jẹ́ kí a tàn yín sínú èrò pé a yíò kọ̀ yín tí ẹ ba gbé ìgbésẹ̀ kan padà sí ìgbé ayé ìṣaájú yín. Nípasẹ̀ agbára àìlẹ́gbẹ́ Ètùtù ti Jésù Krístì, ẹ lè tún padà di mímúláradá lẹ́ẹ̀kànsi. Ṣùgbọ́n tí ẹ bá fi ara pàmọ kúrò lọ́dọ̀ Rẹ̀ ti ẹ sì mú ara yín jìnnà kúrò sí agbègbè ìgbàgbọ́ titun tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ rí, ẹ mú ara yín jìnnà sí gbogbo orísun tí ó lè àti tí yíò fún yín ní agbára láti borí.
Ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n kan, ẹni tí ó yí padà láìpẹ́, ṣàjọpín bí ó ti ṣòro tó láti gbé ìgbàgbọ́ dúró ní àdádúró. Agbára nlá nbẹ́ ní dídà àti jíjẹ́ apákan àpéjọpọ̀ alátìlẹ́hìn—tí gbogbo wọn nkọ́sẹ́ síbẹ̀síbẹ̀ tí wọ́n nlọsíwájú bí a ti nbùkúnfún wọn nípasẹ̀ ìfẹ́ Olùgbàlà Jésù Krístì.
Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni pé “Bíborí ayé kìí ṣe ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kan tàbí méjì. Ó nṣẹlẹ̀ ní gbogbo ìgbé ayé bí a ti nrọ̀mọ́ ẹ̀kọ́ Krístì léraléra. À nkọ́ ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì nípa ìrònúpìwàdà ojojúmọ́ àti pípá àwọn májẹ̀mú tí ó nfún wa ní ẹ̀bùn agbára mọ́. À ndúró lórí ipá ọ̀nà májẹ̀mú a sì ndi alábùkúnfún pẹ̀lú okun ti ẹ̀mí, ìfihàn araẹni, àníkún ìgbàgbọ́, àti ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ángẹ́lì.”
Bí ẹ bá ní ìpalára ti ara, ipò yín yíò burú si àti pé ó lè di dídẹ́rùbà ìgbé ayé tí ẹ kò bá wá ìtọ́jú ìlera tó dára. Èyíinì jẹ́ òtítọ́ fún àwọn ọgbẹ́ ti ẹ̀mí pẹ̀lú. Àwọn ọgbẹ́ àìtọ́jú ti ẹ̀mí, nìkan lè halẹ̀ mọ́ ìgbàlà ayérayé yín. Ẹ máṣe fi ara pamọ́ fún àwọn tí yíò fẹ́ràn tí wọn yíó sì ṣe àtìlẹhìn yín; dípò bẹ́ẹ̀, ẹ sáré sí wọn. Àwọn bíṣọ́ọ̀pù rere, ààrẹ ẹ̀ka, àti àwọn olórí lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún yín láti ní ààyè sí agbára ìwòsàn Ètùtù Jésù Krístì.
Sí àwọn tí ó lè wà ní sísápamọ́, a rọ̀ yín láti padà wá. Ẹ nílò ohun tí ìhìnrere àti Ètùtù Jésù Krístì nfúnni, a sì nílò ohun tí ẹ nfúnni. Ọlọ́run mọ ẹ̀ṣẹ̀ yín; ẹ kò lè fi ara pamọ́ fún Un. Ẹ bá ara yín làjà níwájú Rẹ̀.
Gẹ́gẹ́bí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Rẹ̀, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ gbé àṣà wíwà pẹ̀lú nínú Ìjọ dàgbà tí ó jẹ́ ìfẹ́ni, i`tẹ́wọ́gbà, àti ìgbani-níyànjú fún gbogbo àwọn ẹni tí ó fẹ́ láti ní ìlọsíwájú ní ẹ̀gbẹ́ ipa ọ̀nà Rẹ̀.
Ṣọ́ra Fún Ìdánwò Kejì yìí! Tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn wòlíì àtijọ́ àti ti òde òní kí ẹ mọ̀ pé ẹ kò lè sápamọ́ fún Baba olùfẹ́ni.
Dípò bẹ́ẹ̀, ẹ yọ̀ọ̀da ara yín fún agbára ìwòsàn oníyanu Ètùtù Jésù Krístì. Èyí gan-an ni èrèdí wíwàláàyè wa—láti gba ara aláìlera àti ara tí ó “wà lábẹ́ gbogbo onírurú àìlera” tí yíò sì juwọ́ sílẹ̀ sí, pẹ̀lú ìbànújẹ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìdánwò àkọ́kọ́; láti ní ìlọsíwájú àní nígbàtí a bá ṣubú sínú àwọn ìdánwò wọ̀nyí; àti láti wá ìrànlọ́wọ́ àtọ̀runwá lẹ́hìn ṣíṣe bẹ́ẹ̀, kí a lè dàbí Olùgbàlà wa àti Baba wa ní Ọ̀run. Ọ̀nà Rẹ̀ ni í ṣe. Òun ni ọ̀nà kanṣoṣo! Nípa àwọn òtítọ́ wọ̀nyí ni mo jẹ́ ẹ̀rí ni orúkọ Jésù Krístì, àmín.