Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìfẹ́ Mi fún Olùgbàlà Ni “Èrèdí” Mi
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2025


10:29

Ìfẹ́ Mi fún Olùgbàlà Ni “Èrèdí” Mi

Mo fẹ́ràn Olùgbàlà wa. Èyí ni ìdí tòótọ́ àti tí ó lágbára jùlọ tí mo fi nṣe ohun tí mo nṣe.

Njẹ́ ẹ ti ṣàkíyèsí rí pé wòlíì wa ọ̀wọ́n, Ààrẹ Russell M. Nelson, máa nnawọ́ ìpè sí wa ní gbogbo ìgbà? Láì-yani-lẹ́nu, ó ti pé wa láti ṣàṣàrò kí a sì ronú lórí àwọn ọ̀rọ̀ tí a pín ní àwọn ìpàdé àpapọ̀ méjì tí ó kọjá. Ní Oṣù Kẹ́rin ọdún 2024, ó wípé, “Mo ní ìrètí pé ẹ ó ṣe àṣàrò àwọn ọ̀rọ̀ ìpàdé apapọ̀ yí léraléra ní àwọn oṣù tó nbọ̀.” Lẹ́hìnnáà, ní Oṣù Kẹwa ọdún 2024, ó wípé, “Mo rọ̀ yín láti ṣe àṣàrò àwọn ọ̀rọ̀ wọn. Ẹ lò wọ́n bí ìdánwò lítímọ́sì ti ohun tó jẹ́ òtítọ́ àti ohun tí kìí ṣe bẹ́ẹ̀ nínú oṣù mẹ́fà tó nbọ̀.”

Àwọn ìfipè wọ̀nyí ni a lè fi kún àwọn ìpè alásọtẹ́lẹ̀ tí a ti gbà jálẹ̀ ìgbésí ayé wa, títí kan àwọn tí a ti gbà ní àwọn ọdún àìpẹ́ yí. A lè nímọ̀lára tàbí rò pé àwọn ìfipè wọ̀nyí jẹ́ ohun míràn tí a nílò láti ṣàfikún sí àwọn àtòkọ ohun ṣíṣe wa lásán nítorípé a pè tàbí sọ fún wa láti ṣe é. Ṣùgbọ́n njẹ́ díẹ̀ lè wà sí i bí?

Ní ríronú lórí èyí àti gbogbo ìfipè tí a gbà, mo rántí ohun kan tí mo kọ́ tí mo sì pinnu ní ìgbà pípẹ́ sẹ́hìn. Mo ngbìyànjú láti ṣe àwọn nkan wọ̀nyí, èyítí ó ṣe pàtàkì fún mi nítorí mo nifẹ Rẹ̀; mo fẹ́ràn Olùgbàlà wa. Èyí ni ìdí tòótọ́ àti tí ó lágbára jùlọ tí mo fi nṣe ohun tí mo nṣe, àti lẹ́hìnnáà ní sísopọ̀ pẹ̀lú èyí ni ìfẹ́ mi fún yín, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ẹlẹgbẹ́ mi.

Bí arákùnrin yín, mo nírètí pé ẹ̀yin yíò gbèrò àwọn ọ̀rọ́ mi bí ìfipè òdodo kan láti wá láti ní òye ànfààní láti so ohun gbogbo tí a nṣe pọ pẹ̀lú ìfẹ́ wa fún Olùgbàlà.

Ṣíṣe èyí yìó rànwá lọ́wọ́ láti ní òye tòótọ́ “èrèdí” tí ó wà lẹ́hìn ohun gbogbo tí a nṣe bí ọmọ-ẹ̀hìn Olùgbàlà. Èyí yíò rànwá lọ́wọ́ láti fún ìsopọ̀ onímájẹ̀mú wa pẹ̀lú Ọlọ́run lókun, ní níní òye àwọn òtítọ́ àtọ̀runwá àti ayérayé Rẹ̀—àwọn òtítọ́ ayérayé àti òtítọ́ Rẹ̀ tí kò lè yí padà láé. Àwọn òtítọ́ ayérayé bíi “Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gba a gbọ́ má bàa ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”

Ó nwúni nígbà míràn nítorípé a máa nṣe àwọn nkan léraléra débi pé wọ́n ti yí padà di àṣà, a máa njẹ́ kí àwọn àṣà tàbí ìṣe wọ̀nyí darí ìgbìyànjú wa láti gbé ìgbàgbọ́ ró nínú Jésù Krístì. Ó dàbí ẹnipé a ṣe àwọn nkan wọ̀nyí nítorípé a ti ṣe wọ́n fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún láì ronú nípa ipa wọn lórí ìsopọ̀ májẹ̀mú wa pẹ̀lú Olùgbàlà.

Nínú ayé wa, a máa nfìgbàgbogbo fojúsùn sórí ohun tí a nṣe àti sórí ṣíṣe àṣeyọrí léraléra nínú àwọn iṣẹ́ ṣíṣe àti àwọn ibi-afẹ́dé. Ní àyíká ẹ̀mí kan, a ní ànfààní láti lọ ré kọjá ṣíṣe àwọn nkan tàbí ṣíṣe àṣeyọrí àwọn ibi-afẹ́dé nípa níní òye ìdí tí a fi nṣe wọ́n. Bí a bá lè ní òye tí a sì sopọ̀ pé ìdí tí ó wà lẹ́hìn àwọn ìṣe wa ní í ṣe sí ìfẹ́ wa fún Olùgbàlà àti Baba wa Ọ̀run, nípa lílo àwọn ànfààní wọ̀nyí, a yíò lóye pé bíótilẹ̀jẹ́pé ṣíṣe àwọn ohun òdodo bíi níní àwọn ìṣe ìjọ tàbí àwọn àṣà àti ṣíṣe wọ́n ní déédé jẹ́ ohun tí ó dára, nígbàtí a bá so wọ́n pọ̀ pẹ̀lú “ìdí,” náà a o´ di alábùkúnfún láti lóye èrèdí náà. Kò ní jẹ́ ṣíṣe ohun rere lásán tàbí ṣíṣe é ní títọ́; a yíò tún gbà á ni títọ́.

Fún àpẹẹrẹ, nígbàtí ẹ bá ṣètò ibi-afẹ́dé kan láti ka àwọn ìwé-mímọ́, gbàdúrà òtítọ́, tàbí múra ìṣe kan sílẹ̀ fún ẹbí tàbí wọ́ọ̀dù yín, njẹ́ ibi-afẹ́dé tòótọ́ ni láti kàn ṣe àwọn iṣẹ́-ṣíṣe wọ̀nyí bí? Tàbí njẹ́ àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ ọ̀nà, àwọn ohun èlò ní àrọ́wọ́tó yín, láti ṣe àṣeyọrí ibi-afẹ́dé tòótọ́? Njẹ́ èrèdí rẹ̀ jẹ́ láti ṣe ìṣe kan lásán nítorí pé a ti ṣe é fún ọ̀pọ̀ ọdún àti lẹ́hìn náà kí a fàmì sí ààyè pé a ti parí rẹ̀? Tàbí, lẹ́ẹ̀kan síi, njẹ́ àwọn ọ̀nà wọ̀nyí tí a nlò láti kẹ́kọ̀ọ́, ní ìmọ̀lára, àti láti sopọ̀ pẹ̀lú Olùgbàlà?

Jọ̀wọ́ máṣe ṣi kókó ọ̀rọ̀ mí gbọ́ nípa níní àwọn ìṣe àti àṣà tàbí ìṣètò àwọn ibi-afẹ́dé àti ṣíṣe iṣẹ́ takuntakun láti ṣe àṣeyọrí wọn; kò sí ohun tí kò tọ́ pẹ̀lú èyí. Ṣùgbọ́n, mo pè yín láti ṣí ọkàn àti àyà yín sí ànfààní àti ìbùkún ti níní òye èrèdí tí a fi nṣe àwọn nkan wọ̀nyí àti bí a ti nṣe ẹ̀sìn wa.

Àpẹrẹ pàtàkì ti àwọn àṣà tí Krístì wà ní ààrin gbùngbùn rẹ̀ ni ìpèníjà tí Ààrẹ Dallin H. Oaks nà sí gbogbo wa ní orúkọ Àjọ Ààrẹ Ìkínní. Ààrẹ Oaks wípé, “Bí a ṣe nwọ ọdún titun yìí, ẹ jẹ́ ká múra sílẹ̀ fún ayẹyẹ Ọdún Àjínde ti ẹbọ ètùtù Jésù Krístì. … Ohun yòówù kí àwọn ẹlòmíràn gbàgbọ́ tàbí kí wọ́n máa ṣe, a gbọ́dọ̀ ṣayẹyẹ Ajinde Olùgbàlà wa alààyè nípa ṣíṣe àṣàrò àwọn ìkọ́ni Rẹ̀ àti ṣíṣe ìrànwọ́ láti fìdí àwọn àṣà Àjínde múlẹ̀ ní àwùjọ wa lápapọ̀, ní pàtàkì nínú àwọn ẹbí tiwa.” Bí ẹ ti lè rí, kìí ṣe ìfipè níkan láti ní àwọn àṣà. Dípò bẹ́ẹ̀, a nlo àwọn àṣà wọ̀nyí bíi ọ̀nà láti kẹ́kọ̀ọ́ díẹ̀ síì nípa Olùgbàlà àti láti rántí Àjínde Rẹ̀.

Bí a ṣe lè so ìdí pọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ wa fún Olùgbàlà púpọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni a ó ní ànfààní tó láti gba ohun tí a nílò tàbí tí a nwá. Ààrẹ Nelson wí pé, “Èyíkéyìí àwọn ìbéèrè tàbí wàhálà tí ẹ ní, ìdáhùn ni à nrí nígbàgbogbo nínú ìgbé ayé àti àwọn ìkọ́ni Jésù Krístì.” Àti lẹ́hìnnáà ó nawọ́ ìfipè yí: “Ẹ kẹ́kọ̀ọ́ si nípa Ètùtù Rẹ̀, ìfẹ́ Rẹ̀, àánú Rẹ̀, ẹ̀kọ́ Rẹ̀, àti ìhìnrere ìwòsàn àti ìlọsíwájú Rẹ̀ tí a múpadábọ̀sípò. Ẹ Yípadà sí I! Ẹ Tẹ̀lé E!”

Ẹ ronú èyí nínú ọkàn àti àyà yín: Njẹ́ ẹ gbàgbọ́ pé ìfipè Ààrẹ Nelson ní èròngbà láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa làti múra àtòkọ yíyẹ̀wò kan níbití a ó ti kó ìmọ̀ díẹ̀ jọ síi tí a ó sì parí àwọn iṣẹ́ ṣíṣe pípé kí á lè ṣàyẹ̀wò ìfipè rẹ̀ láti àwọn àtòkọ iṣẹ́-ṣíṣe wa? Tàbí njẹ́ o npè wá láti ṣe àkíyèsí apákan àwọn òtítọ́ àti àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ ayérayé wọ̀nyí bí ànfààní láti ní òye “èrèdí” náà àti láti so ìfẹ́ ti májẹ̀mú Olùgbàlà fún wa pẹ̀lú ìrìn-àjò jíjẹ́ ọmọ ẹ̀hìn ní gbogbo ìgbésí-ayé wa pọ̀ bí?

Ẹ jẹ́ kí nṣàkàwé ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ tí mo ngbíyànjú láti fi hàn. Ọ̀nà kan, èyí tí ó kọjá ìwọ̀n, lè jẹ́ láti ka gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ láti ìpàdé àpàpọ̀, àti pé bí mo bá ṣe tán, èmi ó fàmì sí ìfipè yìí látinú àtòkọ ohun ṣíṣe mi láìṣe ohunkóhun míràn pẹ̀lú ohun tí mo kà. Ó yé mi pé èyí jẹ́ ọ̀ràn tó kọjá ìwọ̀n, ṣùgbọ́n kìí ṣe òtítọ́. Bóyá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wà ní ààyè laarin èyí àti èrò tó dára.

Ìfipè náà ni láti ṣe àṣàrò àti kí á ronú lórí àwọn ọ̀rọ̀ láti ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò kí a sì lò wọ́n láti pinnu àti láti lóye ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe láti dára sí i.

Nígbàtí a bá tẹ́wọ́gba ìfipe náà, níní òye “ìdí” náà tí ó wà lẹ́hìn rẹ̀, a ó ní àwọn ànfààní díẹ̀ síi láti súnmọ́ Olùgbàlà síi. A yíò bẹ̀rẹ láti ní òye pé nítorí mo fẹ́ràn Olùgbàlà, mo fẹ́ kẹkọọ síi nípa Rẹ̀ nípa ṣíṣàṣàrò àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì alààyè. Àti nítorí pé mo fẹ́ràn ọmọnìkejì mi, èmi yíò ṣàjọpín àwọn ẹ̀kọ́ àwọn wòlíì, aríran, àti àwọn olùfihàn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, ní bíbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn olólùfẹ́ mi.

Nínú àwọn àpẹrẹ méjèèjì, ẹ nṣe ohun òdodo. Ní ọ̀kan, ibiafẹ́dé náà dàbí ẹnipé ó nlo àwọn ọ̀nà tí Baba Ọ̀run àti Olùgbàlà ti fún wa, èyítí ó jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí a pín lákokò ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò. Ẹ̀dà kejì gba ìbùkún ìjinlẹ̀ ti jíjèrè oyè sínú àwọn èrèdí tí ó wà ní abẹ́lẹ̀, ní fífúnní ní ipa ọ̀nà láti ní òye àwọn òtítọ́ ayérayé àti àwọn ìbùkún tí a ṣèlérí fún gbogbo àwọn tí wọ́n fi àwọn ìkọ́ni àti ìgbé-ayé Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, ṣe ọ̀gangan pàtàkì ti ìgbé-ayé wọn.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, mo ní ìrètí pé ẹ lè ní ìmọ̀lára kí ẹ sì rí pàtàkì síso àwọn ìṣe wa pọ̀ mọ́ ìfẹ́ wa fún Olùgbàlà. Ní gbogbo àgbáyé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohùn yìó gbìyànjú láti nípa lórí yín àti, bí ó ba ṣeéṣe, darí yín láti gbàgbọ́ pé díẹ̀ nínú àwọn òtítọ́ ìpìlẹ̀ ìhìnrere ti Jésù Krístì tí a múpadàsípò kò ṣe pàtàkì. Àwọn ohùn wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú òtítọ́ ṣíṣe kókó ti ìnílò fún ìmúpadàbọ̀sípò ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí, pẹ̀lú jíjẹ́ pàtàkì níní ìjọba Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé, tí a nṣojú nípasẹ̀ ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn dúró fún.

Ẹ lè gbọ́ àwọn ohùn ti ó ntẹnumọ` pé ìbáṣepọ̀ araẹni tàbí níní òye pẹ̀lú Olùgbàlà nìkan ti tó àti pé ẹ̀sìn tàbí Ìjọ tí a múpadàbọ̀sípò kò wúlò tàbí kò ṣe pàtàkì. Mo pè yín pé kí ẹ lọ́ra láti gbèrò tàbí kí ẹ tilẹ̀ lera sí jíjẹ́ dídarí nípasẹ̀ àwọn èrò òdì wọ̀nyí kí ẹ sì yára síi láti rántí ohun tí Olùgbàlà ti nsọ tí ó sì nkọ́ wa láti ìgbà àtijọ́—bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ ti Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì fún wa àti síso ìfẹ́ wa fún Wọn pọ̀ bíi ìdí láti tẹ̀lé Wọn.

Ọlọ́run Baba àti Ọmọ Rẹ̀ wá wọ́n sì bá Joseph Smith sọ̀rọ̀ láti mú Ìjọ Jésù Krístì padàbọ̀sípò àti láti bẹ̀rẹ̀ ìgba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àkókò, Ìjọba Rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Nítorínáà, Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn ni ọ̀nà tí Baba Ọ̀run gbé kalẹ̀ láti ní ààyè sí àwọn májẹ̀mú tí yíò jẹ́ kí á lè padà sílé. Nípa bẹ́ẹ̀, a nílò ju ìbáṣepọ̀ araẹni nìkan lọ pẹ̀lú Baba Ọ̀run àti Ọmọ Rẹ̀; a nílò àwọn ìlànà oyè-àlùfáà pàtàkì nípasẹ̀ èyítí a fi le dá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Wọn. Èyí npèsè ìsopọ̀ ti májẹ̀mú pẹ̀lú Wọn ó sì nfún wa ní ààyè sí ìfẹ́ ti májẹ̀mú Wọn, ní mímú kí ó ṣeéṣe láti lè dé ìjọba ògo gíga jùlọ tí a pèsè sílẹ̀ fún àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ olootọ àti olódodo sí àwọn májẹ̀mú wọn.

Pẹ̀lú gbogbo agbára ẹmí mi, mo jẹ́ ẹ̀rí sí òtítọ́ àti ìwà-ọ́run Olùgbàlà wa, Jésù Krístì. Ó fẹ́ràn yín. Ó mọ ohun tí ó nṣẹlẹ̀ nínú ayé yín. Apá Rẹ̀ ṣí sílẹ̀ gbaara, ní nínawọ́ ìfipè náà, “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, … èmi ó sì fún yín ní ìsinmi.”

Mo fẹ́ràn Olùgbàlà, àti pé ìfẹ́ mi fún Un ni “ìdí” mi. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.