Máṣe Sé Ọkàn Rẹ Le
Bí a bá ronúpìwàdà tọkàntọkàn, tí a rẹ ara wa sílẹ̀, tí a sì gbẹ́kẹ̀lé tí a sì gbáralé Olúwa, ọkàn wa yíò di rírọ̀.
Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì bẹ̀rẹ̀ nígbàtí Ọlọ́run Baba àti Olùfẹ́ Ọmọ Rẹ̀ farahàn sí Joseph Smith kékeré, ní gbígbọ́ àdúrà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀. Bí ara Ìmúpadàbọ̀sípò Joseph Smith ṣe ìyírọ̀pada àkọsílẹ̀ àtijọ̀ nípasẹ̀ ẹ̀bùn àti agbára Ọlọ́run. Àkọsílẹ̀ yìí ní “ìbáṣepọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn ará America àtijọ́, ó sì ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere àìnípẹ̀kun.”
Nígbàtí mo jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin, bí mo ṣe nka Ìwé ti Mọ́mọ́nì, ó máa nyàmílẹ́nu ìdí tí Lámánì àti Lémúẹ́lì kò fi gba àwọn òtítọ́ tí a fi fún wọn gbọ́, àní nígbàtí ángẹ́lì Olúwa kan farahàn tí ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ ní tààràtà. Kínìdí tí Lámánì àti Lémúẹ́lì kò fi lè jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti olùgbọràn sí àwọn ẹ̀kọ́ baba wọn, Léhì, àti arákùnrin àbúrò wọn Néfì?
Mo rí ọ̀kan lára àwọn ìdáhùn sí ìbéèrè yìí nínú 1 Néfì, tí ó sọ pé Néfì “bànújẹ́ nítorí líle ọkàn wọn.” Néfì béèrè lọ́wọ́ àwọn arákùnrin rẹ̀ àgbà pé, “Báwo ni ó ṣe jẹ́ tí ẹ̀yin ṣe le tó bẹ́ẹ̀ nínú ọkàn yín, tí ẹ̀yin sì fọ́jú nínú ọkàn yín?”
Kínni ó túmọ́sí láti ní ọkàn líle?
Ìyírọ̀padà ti Korean nípa “líle” nínú Ìwé Ti Mọ́mọ́nì jẹ́ 완악 (Wan-Aak: 頑惡). Gbólóhùn yìí máa nlo ọ̀rọ̀ Ṣáínà náà “Wan” (頑), túmọ̀ sí “alágídí,” àti “Aak” (惡), tó túmọ̀ sí “ẹni burúkú.” Nígbàtí a bá sé ọkàn wa le, a ti fọ́jú, àwọn ohun rere kò sì lè wọ inú ọkàn wa tàbí iyè-inú wa. A di alágídí a sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ìfojúsọ́nà púpọ̀ síi sórí àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ayé, ní pípa ọkàn wa dé sí àwọn ohun ti Ọlọ́run. A yàn láti fojúsùn sórí àwọn èrò tiwa nìkan lákokò tí a kò gba àwọn ìmọ̀ràn àti ìtọ́sọ́nà ti àwọn míràn. A yàn láti má ṣí àwọn ọkàn wa sí àwọn ohun Ọlọ́run ṣùgbọ́n dípò sí ipa ti àwọn ohun ti ayé àti àwọn ọ̀tá. Nígbàtí ọkàn wa bá di líle, a ntako ipa ti Ẹ̀mí Mímọ́. A “nlọ́ra láti rántí Olúwa,” àti pé bí àkókò ṣe nlọ a ndi “onírẹ̀wẹ̀sì” sí àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀.
Álmà kọ́ àwọn ènìyàn ní Ammoníhà pé diẹ̀ nínú wọn “yíò kọ Ẹ̀mí Ọlọ́run nítorí líle ọkàn wọn.” Ó tún kọ́ni pé “àwọn tí yíò sé ọkàn wọn le, àwọn ni a fún ní ìpín tí ó kéré jù nínú ọ̀rọ̀ náà títí wọn kò fi mọ ohunkóhun nípa àwọn ohun ìjìnlẹ̀ rẹ̀.” Nígbẹ̀hìn-gbẹ́hín, Ẹ̀mí fà sẹ́hìn, Olúwa “yíò sì mú ọ̀rọ̀ [Rẹ̀] kúrò” lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n ti sé ọkàn wọn le, gẹ́gẹ́bí Lámánì àti Lémúẹ́lì. Nítorípé Lámánì àti Lémúẹ́lì máa nsé ọkàn wọn le nígbàgbogbo, wọ́n tako àwọn ìmọ̀lára Ẹ̀mí Mímọ́, tí wọ́n sì yàn láti máṣe gba àwọn ọ̀rọ̀ àti ìkọ́ni baba wọn àti Néfì, nígbẹ̀hìn wọn kọ àwọn òtítọ́ ayérayé láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
Ní ìyàtọ̀ sí Lámánì àti Lémúẹ́lì, Néfì nrẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ nígbàgbogbo, ní wíwá ìtọ́sọ́nà láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Olúwa. Ní ìpadàbọ̀, Olúwa sọ ọkàn Néfì di rírọ̀. Néfì ṣe àbápín pé òun “kígbe sí Olúwa; sì kíyèsíi ó bẹ̀ mí wò, ó sì sọ ọkàn mi di rírọ̀ tí mo gba gbogbo ọ̀rọ̀ tí baba mi ti sọ gbọ́.” Olúwa ran Néfì lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́gbà, òye, àti láti gba gbogbo ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run àti àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ gbọ́. Néfì ní agbára láti ní ojúgbà ti Ẹ́mí Mímọ́ nígbàgbogbo.
Kíni a lè ṣe láti má sé àwọn ọkàn wa le?
Àkọ́kọ́, a lè máa ṣe ìṣe ìronúpìwàdà lójojúmọ́.
Olùgbàlà wa kọ́ni pé, “Nítorínáà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ronúpíwàdà tí ó sì tọ̀ mí wá bí ọmọdé, òun ni èmi ó gbà.” Mo fẹ́ràn wólíì wa, Ààrẹ Russell M. Nelson, ó kọ́ni pé:
“Ríronúpìwàdà ni kọ́kọ́rọ́ sí ìlọsíwájú. Ìgbàgbọ́ mímọ́ npa wá mọ́ ní rírìn síwájú lórí ipa ọ̀nà májẹ̀mú.
“Ẹ jọ̀wọ́ ẹ máṣe bẹ̀rù tàbí dẹ́kun ríronúpìwàdà. Inú Sátánì ndùn sí ìrora yín. … Bẹ̀rẹ̀ ní òní láti ní ìrírí ayọ̀ ti mímú ènìyàn ẹlẹ́ran ara kúrò. Olùgbàlà fẹ́ràn wa nígbàgbogbo ṣùgbọ́n nípàtàkì nígbàtí a bá ronúpìwàdà.”
Bí a ṣe nní ìrírí ayọ̀ rírọ̀ ọkàn wa tí a sì nwa sọ́dọ̀ Olúwa, a ndà “bí ọmọdé, onítẹríba, oníwatútù, onírẹ̀lẹ̀, onísùúrù, tí ó kún fún ìfẹ́, tí ó ṣetán láti tẹríba fún ohun gbogbo tí Olúwa rí pé ó yẹ láti fi lé òun lọ́wọ́, àní gẹ́gẹ́bí ọmọ ti ntẹríba fún baba rẹ̀.”
Ìkejì, a lè ṣè ìṣe ìrẹ̀lẹ̀.
Ìrònúpìwàdà ojojúmọ́ yíò mú ìrẹ̀lẹ̀ wá sí ọkàn wa. A fẹ́ láti di onírẹ̀lẹ̀ níwájú Olúwa, bí ọmọ kékeré tí ó ngbọ́ràn sí baba wọn. Nígbànáà a yíò ni Ẹ̀mí Mímọ́ pẹ̀lú wa nígbàgbogbo, àti pé ọkàn wa yíò di rírọ̀.
Èmi àti ìyàwó mi, Sue, ti mọ tọkọtaya oníyanu kan fún ọdún mẹ́rin sẹ́hìn. Nígbàtí a pàdé wọn lákọ̀ọ́kọ́, ọkọ náà jẹ́ ọmọ ìjọ titun, ìyàwó rẹ̀ sì npàdé àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere láti ṣe àṣàrò ìhìnrere. Ọ̀pọ̀ àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere ló pàdé rẹ̀ láti ràn án lọ́wọ́ láti wá sọ́dọ̀ Krístì. A nímọ̀lára pé ó ní ẹ̀rí alárinrin nípa ìhìnrere ó sì mọ̀ pé òtítọ́ ni Ìjọ. Ó máa nní ìmọ̀lára Ẹ̀mí lọ́pọ̀ ìgbà nígbà ìbẹ̀wò wa ó sì máa nkópa nínú gbogbo ìpàdé. Ó nífẹ̀ẹ́ láti ṣe àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ìjọ oníyanu ti wọ́ọ̀dù náà. Ṣùgbọ́n, ó ṣòro fún un láti fi ara rẹ̀ lélẹ̀ láti wọnú omi ìrìbọmi. Ní ọjọ́ kan ó nka Mórónì 7:43–44, èyí tí ó kà pé:
“Àti pẹ̀lú, ẹ̀ kíyèsĩ mo wí fún yín pé òun kì yíò ní ìgbàgbọ́ àti ìrètí, àfi bí ó bá jẹ́ oníwàtútù ènìyàn, àti onírẹ̀lẹ̀-ọkàn ènìyàn.
“Bíóbáríbẹ̃, asán ni ìgbàgbọ́ àti ìrètí [yín], nítorítí ẹnikẹ́ni kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọ́run, àfi oníwàtútù àti onírẹ̀lẹ́ ọkàn ènìyàn.”
Lẹ́hìn kíka àwọn ẹsẹ wọ̀nyí, ó ri ohun tí ó nílò láti ṣe. Ó rò pé òun ti lóye ìtumọ̀ jíjẹ́ oníwàtútù àti onírẹ̀lẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, òye rẹ̀ kò tó láti ní ìgbàgbọ́ àti ìrètí láti gbọ́ràn sí àwọn òfin Ọlọ́run. Ó ní láti jáwọ́ nínú agídí àti ọgbọ́n ara rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ nípasẹ̀ ìrònúpìwàdà tòótọ́. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í lóye ìrẹ̀lẹ̀ ní ojú ìwòye Ọlọ́run. Ó gbáralé Baba Ọ̀run ó sì gbàdúrà kí a sọ ọkàn ti ara rẹ̀ di rírọ̀. Nípasẹ̀ àwọn àdúrà wọ̀nyí, ó ní ìmọ̀lára ijẹri Ẹ̀mí sí i pé Baba Ọ̀run fẹ́ kí òun ṣe ìrìbọmi.
Àwọn méjèèjì ọkọ àti ìyàwó ṣe àbápín pé bí wọ́n ṣe túbọ̀ nní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n túbọ̀ nlóye àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ọkàn wọn sì di rírọ̀ láti tẹ̀lé àwọn ìkọ́ni Olúwa wa Jésù Kristi.
Ìkẹ́ta, a lè gbẹ́kẹ̀lé kí a sì gbáralé Olùgbàlà wa.
Néfì jẹ́ àpẹrẹ nlá ti fífàyè gba ọkàn rẹ̀ láti jẹ́ rírọ̀ nípa gbígbẹ́kẹ̀lé Olúwa. Ó kọ́ni pé, “Èmi ti gbẹ́kẹ̀lé ọ, èmi yíò sì gbẹ́kẹ̀lé ọ títí láé. Èmi kì yíò fi ìgbẹ́kẹ̀lé mi sí apá ẹran ara.” Bákannáà, nínú ìfihàn kan tí a fi fún Wòlíì Joseph Smith, Olúwa wípé, “Fi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ sínú Ẹ̀mí náà tí ndarí láti ṣe rere—bẹ́ẹ̀ni, láti ṣe òdodo, láti rìn ní ìrẹ̀lẹ̀.” Nígbàtí a bá gbẹ́kẹ̀ wa lé Olúwa, tí a sì gbáralé E, Òun yìó sọ ọkàn wa di rírọ̀, a ó sì tìwá lẹ́hìn nínú ìdánwò, wàhálà, àti ìpọ́njú.
Bí a bá ronúpìwàdà tọkàntọkàn, tí a rẹ ara wa sílẹ̀, tí a sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé tí a sì gbáralé Olúwa, ọkàn wa yíò di rírọ̀. Òun yíò sì tú Ẹ̀mí Rẹ̀ jáde yíò sì fi àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ọ̀run hàn wa. A yíò gba gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí Ó ti kọ gbọ́, àti pé òye wa yíò di jíjinlẹ̀.
Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, ni àpẹrẹ ìgbẹ̀hìn ti ìwàtútù. Ní 2 Néfì 31:7, a kà pé, “Ṣùgbọ́n bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jẹ́ mímọ́, ó fihàn sí àwọn ọmọ ènìyàn pé, nípa ti ara òun rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Baba, ó sì jẹ́rĩ sí Baba pé òun yíò ní ígbọ́ran sí i ní pípa àwọn òfin rẹ̀ mọ́.” Àní bíótilẹ̀jẹ́ pé Òun jẹ́ mímọ́ àti pípé, Ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Baba ó sì ṣe ìgbọràn sí I nípa ṣíṣe ìrìbọmi.
Ní ìparí ayé ikú Rẹ̀, Jésù Krístì fi ìfẹ́ tirẹ̀ fún Baba Rẹ̀ nípa mímú nínú ago kíkorò náà. Ìjìyà yìí mú kí Ó “wárìrì nítorí ìrora, ó sì ṣẹ̀jẹ̀ ní gbogbo ihò ara, ó sì jìyà méjèèjì ara àti ẹ̀mí.” Olùgbàlà béèrè pé kí Ó “máa mu ago kíkorò náà, kí ó sì dínkù.” “Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀,” Ó wípé, “ògo ni fún Baba, àti pé [Ó] kópa ó sì pari àwọn ìmúrasílẹ̀ [Rẹ̀] fún àwọn ọmọ ènìyàn.”
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, a ti fún wa ní ìwà rere. A lè yàn láti mú ọkàn wa le, tàbí a lè yàn láti mú ọkàn wa rọ̀. Nínú ìgbé ayé ojojúmọ́ wa, a lè yàn láti ṣe àwọn ohun tí ó npe Ẹ̀mí Olúwa láti wọlé àti láti gbé inú ọkàn wa. Mo mọ̀ pé nínú àwọn yíyàn wọ̀nyí, ni àláfíà àti ayọ̀ wà.
Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀lé àpẹrẹ Olùgbàlà wa, Jésù Krístì ẹni tí ó tẹ̀lé ìfẹ́ Baba. Bí a ṣe nṣe bẹ́ẹ̀, Olúwa ti ṣèlérí fún wa pé, “Nítorí, kíyèsí i, èmi yíò kó wọn jọ bí àgbébọ̀ ti nkó àwọn ọmọ rẹ̀ jọ lábẹ́ ìyẹ́ apá rẹ̀, bí wọn kò bá sé ọkàn wọn le.” Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.