Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìrònúpìwàdà Rẹ Kò Di Ẹrù Fún Jésù Krístì; Ó Tànmọ́lẹ̀ Fún Ayọ̀ Rẹ̀
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2025


11:44

Ìrònúpìwàdà Rẹ Kò Di Ẹrù Fún Jésù Krístì; Ó Tànmọ́lẹ̀ Fún Ayọ̀ Rẹ̀

Ìfipè láti ronúpìwàdà jẹ́ àfihàn ìfẹ́ Ọlọ́run. Sísọ bẹ́ẹ̀ni sí ìfipè náà jẹ́ àfihàn tiwa.

Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdùn sẹhin lọ́nà ìrìnàjò lọ sí Florida, mo jókòó ní ìta ní kíka ìwé kan. Àkọ́lé rẹ̀ dábàá pé a ṣì lè lọ sí ọ̀run, bíótilẹ̀jẹ́pé a kò jẹ́ pípé bayi. Obìnrin kan tó nrìn kọjá bèèrè, “Njẹ́ o rò pé ó ṣeéṣe?”

Mo gbójú sókè, nínú ìdàmú, nígbànáà mo sì damọ̀ pé ó nsọ̀rọ̀ nípa ìwé tí mò nkà. Mo sọ nkan ẹlẹgàn bíi, “Ó dára, èmi kò tíì lọ jìnnà nínú rẹ, ṣùgbọ́n èmi yíò jẹ́ kí ó mọ bí o ṣe parí.”

Ah, bí ó ti wùmí tó láti rin ìrìn-àjò padà ní àkókò! Màá sọ fun un pé, “Bẹ́ẹ̀ni, o ṣeéṣe! Nítorípé ọ̀run kìí ṣe fún àwọn ènìyàn tó ti jẹ́ pípé; ó wà fún àwọn ènìyàn tí a ti dáríjì, tí ó yan Krístì léraléra.”

Lónìí mo fẹ́ láti ba àwa tí a máa nnímọ̀lára nígbà míràn pé, “Ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì dàbí ẹnipé ó nṣiṣẹ́ fún gbogbo ènìyàn ṣùgbọ́n èmi.” Àwọn tí ó yanilẹ́nu níkọ̀kọ̀ pé, “Níwọ̀n bí mo ti nṣe àṣìṣe kan náà, bóyá bí mo ṣe rí nìyí.” Àwọn tí wọ́n,dàbí èmi, ní àwọn ọjọ́ nígbàtí ipa-ọ̀nà májẹ̀mú ní ìmọ̀lára dídàgẹ̀rẹ̀ púpọ̀, ó fẹ́rẹ̀ jẹ majẹmu gígùn kan!

Òjíṣẹ́ ìhìnrere àgbàyanu kan ní Australia, Alàgbà QaQa láti Fiji, ní irú ìmọ̀lára kan náà nínú ẹ̀rí lílọ rẹ̀: “Mo mọ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ mi, ṣùgbọ́n nígbà míràn ó máa nyàmílẹ́nu pé, , ‘Njẹ́ Ọlọ́run mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀?’ Nítorí pé mi ò pé, mo sì tún nṣe àṣìṣe.”

Nínú ìbéèrè onírẹ̀lẹ̀ kan náà, Alàgbà QaQa ṣàkópọ̀ ohun tí mo sábà máa nṣàníyàn nípa rẹ̀. Bóyá ìwọ náà nní ìyàlẹ́nu pé, “Mo ngbìyànjú gidigidi, ṣùgbọ́n njẹ́ Ọlọ́run mọ̀ pé mo ngbìyànjú nítòótọ́? Nígbàtí mo bá kùnà, njẹ́ Ọlọ́run mọ̀ pé mo ṣì nifẹ Òun bí?”

Ó dùn mí láti gba èyí, ṣùgbọ́n èmi náà máa ndíwọ̀n ìbáṣepọ̀ mi pẹ̀lú Olùgbàlà kù nípa bí mo ṣe ngbé ìgbé ayé pípé. Mo rò pé ìgbé ayé ìgbọràn túmọ̀ sí pé èmi kì yíò nílò láti ronúpìwàdà láé. Nígbàtí mo bá sì ṣe àṣìṣe, èyí tí ó jẹ́ ojojúmọ́, mo ya ara mi kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ní ríronú pé, “Ó gbọ́dọ̀ ti ní ìjákulẹ̀ nínú mi.”

Èyíinì kìí ṣe òtítọ́.

Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé bí ẹ bá dúró títí tí ẹ ó fi di mímọ́ tó tàbí pípé tó láti lọ sọ́dọ̀ Olùgbàlà, ẹ ti pàdánù gbogbo ààyè náà.

Bí a bá nronú nípa àwọn òfin àti ìgbọràn lọ́nà míràn ńkọ́?

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé nígbàtí Ọlọ́run bìkítà nípa àwọn àṣìṣe wa, Ó bìkítà díẹ̀ síi nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lẹ́hìn tí a ṣe àṣìṣe. Njẹ́ a yíò yípadà sí I léraléra bí? Njẹ́ a yíò dúró ní ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú yí?

Bóyá ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa “Bí [ìwọ] bá nífẹ̀ẹ́ mi, pa àwọn òfin mi mọ́” kí ẹ sì nímọ̀lára ìrẹ̀wẹ̀sì nítorí pé ẹ kò pa gbogbo òfin mọ́. Ẹ jẹ́ kí nrán yín létí pé ó tún jẹ́ òfin láti ronúpìwàdà! Ní tòótọ́, ó lè jẹ́ òfin tí a tún sọ jùlọ nínú àwọn ìwé mímọ́.

Nínú ìdánìkansọ̀rọ̀ Álmà, “Áà ìbá ṣe pé èmi jẹ́ ángẹ́lì, tí èmi ìbá sì ní ìfẹ́ ọkàn [mi]… kí nsì kígbe ìrònúpìwàdà,” kò gbìyànjú láti dójú ti wa nípa títọ́ka sí àwọn àṣìṣe wa. Ó fẹ́ kígbe ìrònúpìwàdà kí èmi àti ìwọ lè yẹra fún ìjìyà nínú ayé. Ìdí kan tí Álmà fi korira ẹ̀ṣẹ̀ ni nítorípé ó nfa ìrora fún wa.

Nígbà míràn mo ní láti rántí, bíi àkọsílẹ̀ Lẹ̀ẹ́mọ́-ọ kan ní iwájú orí mi, pé àwọn òfin jẹ́ ipa ọ̀nà kúrò nínú ìrora. Ìrònúpìwàdà sì jẹ́ bákanáà. Wòlíì wa wípé, “Olùgbàlà fẹ́ràn wa nígbàgbogbo ṣùgbọ́n nípàtàkì nígbàtí a bá ronúpìwàdà.”

Nítorínáà nígbàtí Olúwa wípé, “Ẹ ronúpìwàdà, ẹ ronúpìwàdà,” kí ni bí ẹ bá fojúinú wò Ó pé ó nwípé, “Mo nífẹ̀ẹ́ yín. Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ.” Wo àwòrán Rẹ ní bíbẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú yín láti fi ìhùwàsí tí ó nfa ìrora sílẹ̀ lẹ́hìn, tó npè yín láti jáde nínú òkùnkùn kí ẹ yípadà sí ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀.

Nínú wọ́ọ̀dù ọmọbìnrin mi Carly, àlùfáà titun kúnlẹ̀ láti bùkún oúnjẹ Olúwa, dípò wíwípé, “Kí wọ́n kí ó lè ṣe é ní ìrántí ti ẹ̀jẹ̀ Ọmọ rẹ,” o kàn wípé, “Kí wọn kí ó lè ṣe é ní ìrántí ìfẹ́ ti Ọmọ rẹ.” Omijé kún ojú Carly bí òtítọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọnnì ṣe wọ inú rẹ̀.

Olùgbàlà wa ṣe tán láti jìyà ìrora Ètùtù Rẹ̀ nítorí Ó fẹ́ràn yín. Ní tòótọ́, ẹ̀yin ni “ayọ tí a gbé ka iwájú rẹ̀” nígbà tí Ó njìyà.

Ìfipè láti ronúpìwàdà jẹ́ àfihàn ìfẹ́ Ọlọ́run.

Sísọ bẹ́ẹ̀ni sí ìfipè náà jẹ́ àfihàn tiwa.

Wo àwòrán ààyò rẹ nípa Krístì. Nísisìyí fojú inú wò Ó pé ó nrẹ́rìn-ín músẹ́ pẹ̀lú ayọ̀ ní gbogbo ìgbà tí ẹ bá nlo ẹ̀bùn Rẹ̀, nítorí òun ni “ìmọ́lẹ̀ pípé ti ìrètí.”

Bẹ́ẹ̀ni, ìrònúpìwàdà rẹ kò di ẹrù fún Jésù Krístì; ó tànmọ́lẹ̀ ayọ̀ Rẹ̀!

Ẹ jẹ́ kí á kọ́ ìyẹn!

Nítorí ìrònúpìwàdà jẹ́ ìrohìn tí ó dára jùlọ!

A kò dúró ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú nípa àìní ṣe àṣìṣe rárá. A dúró ní ipa ọ̀nà náà nípa ríronúpìwàdà lójoójúmọ́.

Àti pé nígbàtí a bá nronúpìwàdà, Ọlọ́run ndáríjì láìní tìwá lójú, ṣe àfiwé wa sí ẹlòmíràn, tàbí bá wa wí nítorí èyí jẹ́ ohun kannáà tí a nronúpìwàdà nípa rẹ̀ ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá.

Ó sì nyọ̀ ní gbogbo ìgbà tí Ó bá rí wa lórí ìkúnlẹ̀ wa. Inú rẹ̀ ndùn láti dáríjì wá nítorí pé sí Òun àwa jẹ́ ẹni onínú dídùn!

Njẹ́ ẹ kò nímọ̀lára pé òtítọ́ ni èyí?

Njẹ́ kínìdí tí ó ṣòro fún wa láti gbàgbọ́?!

Sátánì, olùfisùn nlá àti ẹlẹ́tàn, nlo ìtìjú láti pa wá mọ́ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Ìtìjú jẹ́ òkùnkùn gidi tí ó wúwo tóbẹ́ẹ̀ pé bí ẹ bá mú un jáde kúrò nínú ara yín, yíò ní ojúlówó ìwọ̀n tàbí gíga sí i.

Ìtìjú ni ohùn tí o nlù yín gan, tí ó wípé, “Kíni ẹ̀ nro?” “Njẹ́ ẹ ti ṣe ohunkóhun ní títọ́ rí?”

Ìtìjú kìí sọ fún wa pé a ṣe àṣìṣe; ó máa nsọ fún wa pé àwa ni àwọn àṣìṣe wa. Àní ẹ tilẹ̀ lè gbọ́, “Farapamọ́.” Ọ̀tá náà nṣe ohun gbogbo ní agbára rẹ̀ láti tọ́jú ìwúwo náà sinú, ní sísọ fún wa pé iye náà ti ga jú, pé yíò rọrún tí èyí bá dúró nínú òkùnkùn, ní yíyọ gbogbo ìrètí kúrò.

Sátánì ni olè ìrètí náà.

Àti pé ẹ nílò láti gbọ́ èyí, nítorínáà èmi yíò sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí síta: Ẹ̀yín kìí ṣe ohùn ní orí yín tàbí àwọn àṣìṣe tí ẹ ti ṣe. Ẹ lè nílò láti sọ èyí síta bákannáà. Sọ fún Sátánì, “Kìí ṣe òní.” Fi í sí ẹ̀hìn rẹ.

Ẹ nímọ̀lára ìfàmọ́ra náà, ìbànújẹ́ ìwà-bí-Ọlọ́run tí ó nyí yín padà sí Olùgbàlà yín, kí ẹ sì wòó kí oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ wọ inú ayé yín àti ayé àwọn tí ẹ nifẹ. Mo ṣèlérí pé ní ìṣẹ́jú tí a bá fi ìgboyà mú ọkàn ìròbìnújẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni Òun ó wà níbẹ̀.

Bí ẹ bá rí ẹnì kan tó nrì, njẹ́ ẹ kò ní na ọwọ́ yín jáde kí ẹ sì gbà wọ́n? Njẹ́ ẹ lè fojú inú wo Olùgbàlà yín tí ó kọ ọwọ́ ninàjáde yín bí? Lóòtọ́, mo fojú inú wò Ó ó nwẹ̀ nínú omi, tí ó nsọ̀ kalẹ̀ kọjá ohun gbogbo láti gbé wa ga kí a lè gba èémí! Kò sẹ́ni tó lè rì ju ìmọ́lẹ̀ Krístì tó ntàn lọ.

Olùgbàlà ntàn títí ayérayé ju òkùnkùn ìtìjú lọ. Òun kì yíò kọlú yíyẹ yín láé. Wòó pẹ́kípẹ́kí.

  • Fojú inú wòó pé ọwọ́ yí dúró fún iye.

  • Ọwọ́ yí dúró fún ìgbọràn. Bóyá ẹ jí ní òwúrọ̀ yìí, ẹ gbàdúrà tó nítumọ̀, tí ẹ sì wá àwọn ẹsẹ Ìwé mímọ́ wò láti gbọ́ ohùn Ọlọ́run. Ẹ ti ṣe àwọn ìpinnu tí ó dára àti pé ẹ nṣe ìtọ́jú àwọn ènìyàn tí ó wà ní àyíká yín pẹ̀lú ìwà-bíi-Krístì. Ẹ̀ nfetí sílẹ̀ sí ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò! Ìgbọràn yín wà nihin!

  • Tàbí bóyá àwọn nkan kò tíì lọ dáradára. Ẹ ti tiraka láìpẹ́ yìí láti ṣe àwọn nkan kékeré, ti ó rọrùn láti sopọ̀ mọ́ ọ̀run. Ẹ ti ṣe àwọn ìpinnu kan tí ẹ kò ní inú dídùn sí.

  • Níbo ni iye yín wá? Njẹ́ ọwọ́ yí ti gbéra rárá?

A kò so iye yín pọ̀ mọ́ ìgbọràn. Iye yín jẹ́ àìyẹsẹ̀; kò yípadà láé. A fi fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, àti pé kò sí ohun tí èmi tàbí ẹni míràn lè ṣe láti yí padà. Ìgbọràn nmú ìbùkún wá; èyíinì jẹ́ òtítọ́. Ṣùgbọ́n iye kìí ṣe ọ̀kan nínú wọn. Iye yín “nga ní ojú Ọlọ́run nígbàgbogbo,” láìka ibi yìówù kí ìpinnu yín ti gbé yín lọ.

Nígbàtí mo ṣe àwọn àṣiṣe, mo fẹ́ láti dúró nínú ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú pẹ̀lú Krístì, èmi yíò sọ ìdí rẹ̀ fún yín.

Mo dàgbà ní gbígba àwọn ẹ̀kọ́ omi wíwẹ̀ a sì kẹ́kọ̀ọ́ pé nígbàtí àwọn onidajọ bá gba bíbẹ́somi kan wọlé, wọ́n nwo bí ó ti jẹ́ ṣíṣe. Njẹ́ wíwọlé jẹ́ ní ìnàró ní pípé, pẹ̀lú àwọn ìka ẹsẹ̀ ní ṣónṣó àti omi kékeré kan ní dídànu? Lẹ́hìnnáà wọ́n nṣe nkan àràọ̀tọ̀. Wọ́n nṣe àgbéyẹ̀wò ìwọ̀n ìṣòro.

Gbogbo ènìyàn nwẹ omi pẹ̀lú ìwọ̀n ìṣòro tiwọn. Olùgbàlà yín nìkan ni ó mọ bí ìwọ̀n ìṣòro tí ẹ wẹ̀ pẹ̀lú ṣe tó. Mo fẹ́ ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ẹnìkan tí ó gbà mí, tí ó mọ ọkàn mi àti bí mo ṣe ngbìyànjú tó!

Ó mọ̀ pé ìkùukù òkùnkùn nbọ̀ sórí gbogbo àwa arìnrìn-àjò, tí ìrìnàjò wa nkọjá lọ sí ẹ̀bá odò ẹlẹ́gbin—nítorínáà nígbàtí a bá di ọ̀pá irin mú, yíò ta sí wa lára.

Wíwá sọ́dọ̀ Krístì jẹ́ wíwí pé, “Njẹ́ ìwọ yíò rànmílọ́wọ́?” pẹ̀lú ìrètí, ìdánilójú tí a fi hàn pé apá Rẹ̀ ni a nàsí yín nígbàgbogbo. Mo gbàgbọ́ pé ìwò titun ti ìrònúpìwàdà túmọ̀ sí pé bíótilẹ̀jẹ́pé a kò ní ìgbọràn pípé síbẹ̀, a ngbìyànjú ìgbọràn ìfẹ́ni báyìí, ní yíyàn láti dúró, lẹ́ẹ̀kansi àti lẹ́ẹ̀kansi, nítorí a fẹ́ràn Rẹ̀.

Rántí àwọn ènìyàn Ọba Bẹ́njámínì, tí wọn kò ní ìtẹ̀sí láti ṣe ibi mọ́ bí kò ṣe kìkì láti máa ṣe rere nígbàgbogbo? Njẹ́ ẹ rò pé wọ́n kó àgọ́ wọn jọ, wọ́n lọ sílé, wọn ò sì tún ṣe àṣìṣe míràn? Dájúdájú bẹ́ẹ̀kọ́! Ìyàtọ̀ náà ni pé wọn kò fẹ́ láti ṣẹ̀. Wọ́n ní ìgbọràn ìfẹ́ni! Ọkàn wọn yípadà ó sì yí sí Ọlọ́run nígbàtí wọ́n tiraka!

Lẹ́ẹ̀kanrí, ní etí òkun, mo rí ẹyẹ kan tó nfò sínú afẹ́fẹ́, ní fífẹ́ àwọn ìyẹ́ rẹ̀ ní kíkan-kíkan, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ ìṣe àníyàn, ṣùgbọ́n dídúró ní ààyè kannáà. Nígbànáà ní ṣe àkíyèsí ẹyẹ míràn, tí ó ga jùlọ. Ó ti nrìn ìrìn afẹ́fẹ́ ó sì nlefo nírọ̀rùn, láìsí ìyọnu nínú ìjì. Èyíinì ni ìyàtọ̀ laarin ìgbìyànjú láti ṣe èyí fún ara wa àti yíyí sí Olùgbàlà wa, jíjẹ́ kí Ó gbé wa sókè, pẹ̀lú “ìwòsàn ní ìyẹ́ rẹ̀.”

Bí olùdarí míṣọ̀n ní Australia, nígbà ìbẹ̀wò ìkẹhìn wa pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan òjíṣẹ́ ìhìnrere, a sọ̀rọ̀ nípa 3 Néfì 17, níbití àwọn ènìyàn náà ti sún mọ́ Olùgbàlà tí wọ́n sì gbọ́ tí Ó ngbàdúrà fún wọn. A béèrè pé, “Bí ẹ bá lè gbọ́ tí Olùgbàlà ngbàdúrà fún yín, kí ni ẹ rò pé Òun yíò sọ?”

Láti gbọ́ ìdáhùn wọn jẹ́ ọ̀kan lára ​​àwọn ìrírí ti Ẹ̀mí jùlọ ní ìgbésí ayé mi. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere wọ̀nyí yíò dánu dúró, omijé yíò sì kún ojú wọn bí a ṣe nrán wọn létí pé, “Olùgbàlà yín mọ ìwọ̀n ìṣòro tí ẹ̀ nní ìrírí rẹ̀. Ó ti nímọ̀lára rẹ̀!”

Èyí ni ohun tí àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere náà sọ ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ àti pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́: Arábìnrin kan wípé, “Jésù yíò sọ fún Baba pé, ‘Ó nṣe gbogbo ohun gbìyànjú. Mo mọ bí èmi ó ti jẹ́ ẹ̀rí mi.’” Alàgbà kan wípé, “Pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀ nínú ìgbé ayé rẹ̀, mo ní inú dídùn fún un.”

Jẹ́kí a gbìyànjú èyí. Ní alẹ́ òní, ṣaájú kí ẹ tó gbàdúrà, ẹ fojú inú wo Jésù Krístì nítòsí. Òun ni Alágbàwí yín lọ́dọ̀ Baba. Bèèrè lọ́wọ́ ararẹ, “Kíni Olùgbàlà mi yíò wí fún Baba nípa mi?”

Àti lẹ́hìnnáà dákẹ́jẹ́.

Fetísílẹ̀ fún ohùn náà ti o nsọ àwọn ohun rere nípa yín—ohùn Olùgbàlà, ọ̀rẹ́ yín tí ó dára jùlọ, àti Baba yín Ọ̀run, ẹni tí ó wà níbẹ gan-an. Rántí, ìfẹ́ Wọn àti yíyẹ yín jẹ́ nla nígbàgbogbo, láìbìkítà kíni!

Mo dúró nihin láti jẹ́ ẹ̀ri pé Jésù Krístì nfi ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí wọ́n jókòó sínú òkùnkùn. Nítorínáà, ní àwọn ọjọ́ wọnni nígbàtí ẹ bá nímọ̀lára ohùn tó nsọ fún yín láti farapamọ́ fúnra yín sínú yàrá tó ṣókùnkùn, mo pè yín láti ní ìgboyà àti láti gbàgbọ́ nínú Krístì! Ẹ rìn síwájú kí ẹ sì tan ìmọ́lẹ̀—Ìmọ́lẹ̀ Pípé ti Ìrètí wa.

Wíwẹ̀ nínú ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀, ẹ yíò rí àwọn ènìyàn ní àyíká yín tí wọ́n nímọ̀lára àdánìkanwà bákannáà, ṣùgbọ́n nísisìyí, pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ lọ́wọ́, ẹ̀yin àti àwọn yíò ní ìyàlẹ́nu, “Ìdí tí a fi nbẹ̀rù gidi nínú òkùnkùn? Àti pé kínìdí tí a fi dúró níbẹ̀ fún ìgbà pípẹ́?”

“Njẹ́ ki Olúwa Ìmọ́lẹ̀ di yín mú nínú apá Rẹ̀ kí O sì tù yín nínú kí ó sì fẹ́ràn yín nígbàgbogbo.” Njẹ́ kí a nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀ kí a sì yàn Án nígbàgbogbo, lẹ́ẹ̀kànsi àti lẹ́ẹ̀kànsi. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.