Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Kópa láti Múrasílẹ̀ fún Ìpadàbọ̀ Krístì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2025


11:23

Kópa láti Gbáradì fún Ìpadàbọ̀ Krístì

Àwọn ìpè àti àwọn ọ̀nà míràn tí a ngbà lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ Ọlọ́run ní àìláfiwé ìmúrasílẹ̀ wa láti pàdé Olùgbàlà.

Ní oṣù díẹ̀ sẹ́hìn, mo dúró nínú gbọ̀ngàn kan nígbàtí Alàgbà Neil L. Andersen rìn lẹ́gbẹ̀ẹ́. A ṣẹ̀ṣẹ̀ pè mí bí Aláṣẹ Gbogbogbo titun kan. Ó dàbí ó rí ìmọ̀lára àìkúnjú-ìwọ̀n mi, ó rẹ́rìn-ín ó sì wípé, “Ó dáa, ó dà bí ẹni pé ọkùnrin kan wà tí kò mọ ohun tí ó nṣe.”

Mo sì rò pé, “Wòlíì tòótọ́ àti aríran kan wà.”

Alàgbà Andersen nígbànáà sọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, “Máṣe ìyọnu, Alàgbà Shumway. Ó máa dára síi—ní ọdún marun tàbí mẹ́fà.”

Njẹ́ ẹ ti ní ìyàlẹ́nu rí nípa ìdí tí wọ́n fi nsọ pé kí a ṣe àwọn nkan nínú ìjọba Ọlọ́run tí ó dàbí ẹnipé ó kọjá agbára wa? Pẹ̀lú àwọn ìbèèrè ìgbé ayé, njẹ́ ẹ ti bèèrè ìdí tí a tilẹ̀ fi nílò àwọn ìpè nínú Ìjọ? Ó dára, mo ní.

Mo gba ìdáhùn ní ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò tí ó kọjá nígbàtí Ààrẹ Russell M. Nelson wípé, ”Nìsisìyí ni àkokò náà fún yín àti fún èmi láti múrasílẹ̀ fún Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Olúwa àti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì náà.” Nígbàtí Ààrẹ Nelson sọ èyí, Ẹ̀mí kọ́ mi pé bí a ṣe nkópa nínú iṣẹ́ Ọlọ́run, a npèsè ara wa àti àwọn ẹlòmíràn sílẹ̀ fún ìpadàbọ̀ Krístì. Ìlérí Olúwa jẹ́ ọ̀rọ̀-iyàn pé àwọn ìpè, iṣẹ́-ìránṣẹ́, ìjọ́sìn tẹ́mpìlì, títẹ̀lé àwọn ìṣítí, àti àwọn ọ̀nà míràn tí a gbà nlọ́wọ́ nínú iṣẹ́ Ọlọ́run nmúra wa sílẹ̀ láìláfiwé láti pàdé Olùgbàlà.

Inù Ọlọ́run dùn Nígbàtí A Kópa Nínú Iṣẹ́ Rẹ̀

Nínú “ọlánlá àkókò yìí,” nígbàtí ìjọba Ọlọ́run ngbòòrò sí i tí àwọn tẹ́mpìlì sì káàkiri ilẹ̀ ayé, àìní npọ̀ sí i fún àwọn ọkàn tó nfẹ́ láti kópa nínú iṣẹ́ Ọlọ́run. Iṣẹ́ ìsìn àìmọtara-ẹni-nìkan gan-an ni jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn ìwà bíi Krístì. Ṣùgbọ́n sísìn kìí sábà rọrùn. Èrèdí nìyí tí mo fi ní ìfẹ́sí ẹ̀yin ọmọ-ẹ̀hìn olùpamọ-májẹ̀mú, pẹ̀lú àwọn olùfẹ́ òjíṣẹ́ ìhìnrere wa, ẹ̀yin tí ẹ fi àwọn ìfẹ́-inú àti ìpèníjà yín sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan láti sin Ọlọ́run nípa sísìn àwọn ọmọ Rẹ̀. Ọlọ́run “ní ìdùnnú láti bu ọlá fún [yín fún sísìn Ín] nínú òdodo.” Ó ṣe ìlérí pé, “Títóbi ni èrè [rẹ] yíó jẹ́ àti ayérayé ni ògo [rẹ] yíó jẹ́.” Nígbàtí a bá sọ bẹ́ẹ̀ni sí sísìn, a nsọ bẹ́ẹ̀ni sí Jésù Krístì. Àti nígbàtí a bá sọ bẹ́ẹ̀ni sí Krístì, a nsọ bẹ́ẹ̀ni sí ìgbé ayé tí ó pọ̀ jùlọ tí ó ṣeéṣe.

Mo kẹ́kọ̀ọ́ yí lákokò tí mo nṣiṣẹ́ tí mo sì nka ìmọ̀-ẹ̀rọ kẹ́míkálì ní kọ́lẹ́jì. A pè mí láti jẹ́ olùṣètò ìṣe fún wọ́ọ̀dù ọ̀dọ́ àdánìkanwà kan. Èyí ni àlá-burúkú ìpè mi. Síbẹ̀, mo tẹ́wọ́ gbàá, àti ní àkọ́kọ́ ó jẹ́ ìdààmú. Lẹ́hìnáà níbi ìṣe ṣíṣe kan ọmọbìnrin arẹwà kan ní ìkọlù nípa ọ̀nà tí mo fi pín wàrà dídì. Ó padà nígbà mẹ́ta, ní ìrètí láti gba àkíyèsí mi. A wọnú ìfẹ́, àti pé ó dábàá àti fẹ́ mi ní ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́hìnnáà. Ó dára, bóyá kò yára tó bẹ́ẹ̀ rárá, áti pé èmi ní ẹni tí ó dábàá àti fẹ, ṣùgbọ́n òtítọ́ ni pé: mo bẹ̀rù láti ronú pípàdánù Heidi kánípé mo sọ pé rárá sí ìpè náà.

Ìkópa wa Ni Ìgbáradì fún Ìpadàbọ̀ Krístì

A nkópa nínú iṣẹ́ Ọlọ́run kìí ṣe nítorí pé Ọlọ́run nílò wa ṣùgbọ́n nítorí a nílò Ọlọ́run àti àwọn ìbùkún nlá Rẹ̀. Ó ṣèlérí, “Nítorí, kíyèsí i, èmi yíò bùkún gbogbo àwọn tí nṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà mi pẹ̀lú ìbùkún nlá.” Ẹ jẹ́ kí nṣe abápín àwọn ìlànà mẹ́ta tí ó nkọ́ni bí ìkópa wa nínú iṣẹ́ Ọlọ́run ṣe nbùkún tí ó sì nrànwá lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ láti pàdé Olùgbàlà.

Àkọ́kọ́, bí a ṣe nkópa, a ntẹ̀síwájú sí ìhà “ìwọ̀n ìṣẹ̀dá [wa]”

A kọ́ àpẹrẹ yìí nínú àkọsílẹ̀ ti Ìṣẹ̀dá. Lẹ́hìn iṣẹ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, Ọlọ́run jẹ́wọ́ ìlọsíwájú tí a ṣe nípa wíwípé “ó dára.” Kó wípé iṣẹ́ náà ti parí tàbí ó pé. Ṣùgbọ́n ìlọsíwájú wà lójoójúmọ́, àti pé ní ojú Ọlọ́run, èyíinì jẹ́ dídára!

Àwọn ìpè kìí ṣe ìpinnu tàbí ìfọwọ́sí iye tàbí yíyẹ ènìyàn. Dípò bẹ́ẹ̀, bí a ṣe nṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ní ọ̀nàkọnà tí Ó bá bèèrè, a ndàgbà sínú òdiwọ̀n ìṣẹ̀dá tiwa.

Ọlọ́run máa nyọ̀ nínú ìlọsíwájú wa, bẹ́ẹ̀ ló sì yẹ kí àwa náà, àní nígbàtí a ṣì ní iṣẹ́ láti ṣe. Nígbà míràn a lè ma ní okun tàbí ọ̀nà láti sìn nínú ìpè kan. Síbẹ̀, a lè kópa nínú iṣẹ́ náà kí a sì dáàbò bo ẹ̀rí wa nípasẹ̀ àwọn ọ̀nà tó nítumọ̀ bíi àdúrà àti ṣíṣe àṣàrò ìwé mímọ́. Olùfẹ́ni Baba wa Ọ̀run kìí dá wa lẹ́bi nígbàtí a bá fẹ́ ṣùgbọ́n tí a kò lè sìn.

Èkejì, iṣẹ́ ìsìn ngbé àwọn ilé àti àwọn ìjọ wa ga sí àwọn ibi mímọ́ níbití a ti lè ṣe ìgbé ayé májẹ̀mú.

Fún àpẹrẹ, májẹ̀mú wa láti rántí Krístì nígbàgbogbo ni a ṣe bí ẹnìkọ̀ọ̀kan, ṣùgbọ́n májẹ̀mú yí ni à ngbé bí a ṣe nsin àwọn ẹlòmíràn. Àwọn ìpè yí wa ká pẹ̀lú àwọn ànfààní láti “gbé … ẹrù ọmọnìkéjì wa, àti nípa bẹ́ẹ̀ a mú òfin Krístì ṣẹ.” Nígbàtí a bá sìn nítorí pé a fẹ́ràn Ọlọ́run tí a sì fẹ́ gbé ìgbé ayé àwọn májẹ̀mú wa, iṣẹ́ ìsìn tí ó dàbí ojúṣe àti tí ó gba agbára ndi aláyọ̀ àti ayínipadà.

Àwọn ìlànà ìgbàlà àti ìgbéga kò gbàwálà nítorí wọn mú àtòkọ àyẹ̀wo ọ̀run ṣẹ. Dípo bẹ́ẹ̀, nígbàtí a bá ngbé ìgbé ayé àwọn májẹ̀mú tó so mọ́ àwọn ìlànà wọ̀nyí, a ndi irú ènìyàn tí ó fẹ́ láti wà níwájú Ọlọ́run. Òye yìí borí àwọn iyèméjì láti sìn tàbí àwọn fífẹ́ láti má ṣe ìránṣẹ́. Ìmúrasílẹ̀ wa láti pàdé Krístì máa nyára kánkán nígbàtí a bá jáwọ́ bíbéèrè ohun tí Ọlọ́run yíò fàyè gbà tí a sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè ohun tí Ọlọ́run yíò fẹ́.

Ìkẹta, kíkópa nínú iṣẹ́ Ọlọ́run nrànwá lọ́wọ́ láti gba ẹ̀bùn oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run kí a sì nímọ̀lára ìfẹ́ nlá Rẹ̀.

A kìí gba owó ìsànpadà fún sísìn. Dípò bẹ́ẹ̀, Ìwé Mímọ́ kọ́ni pé fún “iṣẹ́ [wa a] ní láti gba oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, kí [a] lè lágbára nínú Ẹ̀mí, [ní] ìmọ̀ Ọlọ́run, [àti] láti kọ́ni pẹ̀lú agbára àti àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Eyíinì jẹ́ ìṣòwò tí ó dára púpọ̀!

Nítorí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, àwọn agbára tàbí àìlágbára wa kìí ṣe ìpìlẹ̀ àkọ́kọ́ fún nínawọ́ tàbí gbígba ìpè kan. Ọlọ́run kò retí ìṣe pípé tàbí tálẹ́ntì àràọ̀tọ̀ láti kópa nínú iṣẹ́ Rẹ̀. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, Ẹ́stérì Ayaba kì bá ti gba orílẹ̀-èdè rẹ̀ là, Pétérù kì bá ti ṣe aṣáájú-ọ̀nà Ìjọ àkọ́kọ́, Joseph Smith kì yíò sì jẹ́ wòlíì Ìmúpadàbọ̀sípò.

Bí a ṣe nṣe ìṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́ láti ṣe ohun kan tí ó kọjá agbára wa, àìlera wa farahàn. Èyí kò tunilára rara, ṣùgbọ́n ó pọn dandan láti “mọ pé nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́ [Ọlọ́run] … pé a ní agbára láti ṣe àwọn nkan wọ̀nyí.”

A yíò ṣubú ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà bí a ṣe nkópa ní iṣẹ́ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n nínú ìyànjú wa, Jésù Krístì mú wa. Ó sì gbé wa sókè díẹ̀díẹ̀ láti ní ìrírí ìgbàlà kúrò nínú ìjákulẹ̀ àti ìbẹ̀rù àti láti inú ìmọ̀lára bí ẹnipé a kì yíò tó láé. Nígbàtí a bá ya aápọn wa kékeré ṣùgbọ́n dídára jùlọ sí mímọ́, Ọlọ́run nsọ ọ́ di títóbi. Nígbàtí a bá ṣèrúbọ fún Krístì, Òun nsọ wá di mímọ́. Èyí ni agbára ìyínipadà ti oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. Bí a ṣe nsìn, a ndàgbà nínú oore-ọ̀fẹ́ títí tí a ó fi múra sílẹ̀ láti “di gbígbé sókè nípasẹ̀ Baba, láti dúró níwájú [Jésù Kristi].”

Ran Àwọn Ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti Gbà àti láti Yọ̀ nínú Ẹ̀bùn Àwọn Ìpè

Èmi kò mọ gbogbo ohun tí Olùgbàlà yíò bèèrè lọ́wọ́ mi nígbàtí mo bá dúró níwájú Rẹ̀, ṣùgbọ́n bóyá ìbèèrè kan yìó jẹ́, “Ta ni o mú wá pẹ̀lú rẹ?” Àwọn ìpè jẹ́ àwọn ẹ̀bùn mímọ́ láti ọ̀dọ̀ olùfẹ̀ni Baba Ọ̀run láti ṣe ìrànlọ́wọ́ láti mú àwọn míràn wá pẹ̀lú wa sọ́dọ̀ Krístì. Nítorínáà mo pe àwọn olórí àti oúkúlùkù wa láti mọ̀ọ́mọ̀ wá àwọn tí kò ní àwọn ìpè. Ẹ gba wọ́n níyànjú kí ẹ sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kópa nínú iṣẹ́ Ọlọ́run láti múrasílẹ̀ fún ìpadàbọ̀ Krístì.

Jòhánnù kò wá déédé sí Ilé ìjọsìn nígbàtí bíṣọ́pù rẹ̀ ṣàbẹ̀wò tí ó sì sọ fún un pé Olúwa ní iṣẹ́ kan fún un láti ṣe. Ó pe Jòhánnù láti jáwọ́ nínú sìgá mímu. Bíótilẹ̀jẹ́pé Jòhánnù ti gbìyànjú lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà láti dáwọ́ dúró, ní àkókò yìí ó nímọ̀lára agbára àìrí kan tí ó nràn án lọ́wọ́.

Lẹ́hìn ọ̀sẹ̀ mẹ́ta péré, ààrẹ èèkàn náà bẹ Jòhánnù wò. Ó pè é láti sìn ní bìṣọ́príkì. Ó ya Jòhánnù lẹ́nu. Ó wí fún ààrẹ èèkàn náà pé òun ṣẹ̀ṣẹ̀ jáwọ́ sìgá mímu. Bí èyí bá túmọ̀ sí pé yìó ní láti kọ àṣà wíwà nínú àwọn eré bọ́ọ̀lù alámọ̀dájú ní ọjọ́ Ìsinmi, ní dídára, èyíinì jẹ́ púpọ̀ jù láti bèèrè. Ìdáhùn onímìísí ààrẹ èèkàn náà rọrùn: “Jòhánnù, èmi kò béèrè lọ́wọ́ rẹ; Olúwa ni.”

Sí èyí tí Jòhánnù dáhùn pé, “Ó dára bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, èmi yíò sìn.”

Jòhánnù wí fún mi pé àwọn ìrúbọ wọ̀nyí láti sìn ní àwọn ọ̀gangan ìyípadà ti ẹ̀mí fún òun àti ẹbí rẹ̀.

Ó yàmílẹ́nu bóyá a ní ààyè ìfọ́jú kan, ní kíkùnà láti nawọ́ àwọn ìpè sí àwọn ènìyàn tí wọ́n, dàbí ẹnipé wọn kò lè ṣeé tàbí kò yẹ, sí ìwò àye ikú wa. Tàbí a lè ní àníyàn díẹ̀ síi pẹ̀lú àṣà ìmúṣe ju pẹ̀lú ẹ̀kọ́ ìlọsíwájú lọ, ní àìbìkítà láti ri bí Olùgbàlà ṣe nmú agbára pọ̀ si nínú àìríbẹ́ẹ̀ àti àìdánwò nípa fífún wọn ní àwọn ànfààní láti sìn.

Alàgbà David A. Bednar kọ́ni ní pàtàkì àṣẹ Ìwé Mímọ́ láti “jẹ́ kí gbogbo [obìnrin àti] ọkùnrin kọ́ ojúṣe [wọn], àti láti gbé ìgbésẹ̀.” Njẹ́ a nṣe èyí? Nígbàtí àwọn olórí àti àwọn òbí bá jẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn kọ́ ẹ̀kọ́ kí wọ́n sì ṣe ìṣe fúnra wọn, wọ́n ntan wọ́n sì ngbilẹ̀. Nígbàtí ipa ọ̀nà tó rọrùn jù le jẹ́ láti fún àwọn olóotọ́ ọmọ ìjọ ní ìpè kejì, ọ̀nà tí ó dára jùlọ ni láti pe àwọn tí kò ríbẹ́ẹ̀ láti sìn kí wọ́n sì jẹ́kí wọn ó kẹ́kọ̀ọ́ kí wọn ó sì dàgbà.

Bí Krístì bá wà níhìn nípa ti ara, Òun yíò ṣàbẹ̀wò sí àwọn aláìsàn, yíò kọ́ kíláàsì Ilé Ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi, yíò jókòó pẹ̀lú ọ̀dọ́mọbìnrin onírora ọkàn náà, yíò sì bùkún àwọn ọmọdé. Òun lè ṣe iṣẹ́ ti ara Rẹ̀. Ṣùgbọ́n o ngbé ayé ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ yí láti jẹ́ kí á gbé ìgbésẹ̀ kí a sì kẹ́kọ̀ọ́, nítorínáà Ó rán wa ní ipò Rẹ̀.

Pẹ̀lú kíkópa nínú iṣẹ́ Ọlọ́run ni “ẹ̀tọ́, ànfààní àti ojúṣe láti ṣe aṣojú fún Olúwa [Jésù Kristi] nwá.” Nígbàtí a bá sìn láti gbé Krístì ga kìí ṣe ara wa, iṣẹ́ ìsìn wa ndi aláyọ̀. Nígbàtí àwọn ẹlòmíràn bá kúrò ní kíláàsì, ìpàdé, ìbẹ̀wò iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa, tàbí ìṣe ṣíṣe ní rírántí Krístì ju bí wọ́n ṣe nrántí wa lọ, iṣẹ́ náà nfúnni ní agbára.

Ní wíwá pẹ̀lú ìtara láti ṣe aṣojú Krístì, a ndàbí Rẹ̀ síi.” Èyíinì ni ìmúrasílẹ̀ tó dára jùlọ fún àkókò mímọ́ náà nígbàtí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yíò kúnlẹ̀ tí a ó sì jẹ́wọ́ pé Jésù ni Krístì náà, èyítí mo jẹ́ ẹ̀rí pé Ó jẹ́, àti pé Ààrẹ Russell M. Nelson ni “ohùn Rẹ̀ … títí dé òpin ilẹ̀ ayé” láti ràn wá lọ́wọ́ láti “múrasílẹ̀ … fún èyí tó nbọ̀.” Ní orúkọ mímọ́ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Russell M. Nelson, “Jésù Krístì Olúwa Yíò Padàwá,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá 2024, 121.

  2. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 4:2–4.

  3. Russell M. Nelson, “Jésù Krístì Olúwa Yíò Padàwá,” 121.

  4. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 76:50–70.

  5. Wo Jòhánnù 10:10.

  6. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 21:9.

  7. Ẹkọ àti Àwọn Májẹmú 88:19.

  8. Wo Gẹ́nẹ́sísì 1.

  9. Nínú òwe Olùgbàlà ti àwọn tálẹ́ntì, Ọ̀gá náà si fúnni ní ojúṣe “àwọn ohun díẹ̀” fún ìránṣẹ́ kọ̀ọ̀kan. Ọ̀gá náà túbọ̀ pọkàn pọ̀ sórí ìtẹ̀síwájú ìránṣẹ́ kọ̀ọ̀kan síhà dídi ọ̀gá “lórí ohun púpọ̀” kò sì bìkítà nípa ipadabọ̀ àwọn ẹrù Rẹ̀. Ìránṣẹ́ kan tí ó bẹ̀rù tí kò fẹ́ láti ṣiṣẹ́ ni a ti dá lẹ́bi àti láìní ìlọsíwájú. (Wo Máttéù 25:14–30.)

  10. Wo Lúkù 21:19. Alàgbà David A. Bednar kọ́ni pé “iṣẹ́ òdodo jẹ́ ohun kòṣeémánìí fún ìlọsíwájú ẹ̀mí” (“Àwọn Ohun Bí Wọ́n Ṣe Jẹ́ 2.0” [ìfọkànsìn jákèjádò ayé fún àwọn ọ̀dọ́ àgbà, 3 Oṣù kọkànlá, 2024], Ibi ìkàwé ìhìnrere).

  11. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 10:4.

  12. Wo Mòsíàh 4:24.

  13. Wo Russell M. Nelson, “Ohun ti A Nkọ́ tí A Kò Sì Ní Gbàgbé LaéLàìhónà, Oṣù karun 2021, 79: “Ọlọ́run fẹ́ kí á ṣiṣẹ́ papọ̀ kí a sì ran ara wa lọ́wọ́. Ìdí nìyí tí Ó fi rán wa wá sí ilẹ̀ ayé nínú àwọn ẹbí tí Ó sì ṣètò wa sínú àwọn wọ́ọ̀dù àti àwọn èèkàn. Ìdí nìyí tí Ó fi sọ fúnwa láti sìn kí a sì ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ara wa. … A le ṣe àṣeyọrísí ohun púpọ̀ síi lápapọ̀ ju bí a ti le dá nìkan ṣe lọ. Ètò ìdùnnú ti Ọlọ́run yío di mímú rẹ̀wẹ̀sì bí àwọn ọmọ Rẹ̀ bá dúró nínú ìyàsọ́tọ̀, ọ̀kàn kúrò lọ́dọ̀ òmíràn.”

  14. Romans 1:12; bákannáà wo Mosiah 18:8–9.

  15. Ààrẹ Henry B. Eyring kọ́ni pé, “Láti pè láti sìn jẹ́ ìpè láti wá láti nífẹ̀ẹ́ Ọ̀gá tí a nsìn. Ó jẹ́ ìpè láti jẹ́ kí àwọn ìṣẹ̀dá wa yípadà” (“Gẹ́gẹ́bí Ọmọdé,” Làìhónà, Oṣù karun 2006, 17).

  16. Wo Henry B. Eyring, “Njẹ́ ó yẹ kí Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn ta ọjà kan nígbà tí ìlò rẹ̀ tako Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n?,” Ẹ́nsáìn, Oṣù Kẹ́rin 1977, 30.

  17. Mòsíàh 18:26; bákannáà wo Mòsíàh 27:5.

  18. Wo 2 Néfì 3:13, 24.

  19. Jákọ́bù 4:7.

  20. Wo Isáíàh 40:29–31; 2 Kọ́ríntì 12:9.

  21. Wo Máttéù 14:15–21. Bíótilẹ̀ jẹ́ pé a fi ìṣù búrẹ́dì márùn-ún kan àti ẹja méjì bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, Olùgbàlà fi ìmoore gba ẹ̀bùn náà ó sì gbé e ga sí àní ju ohun tí a nílò lọ. Ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀kọ́ nla ti iṣẹ́ ìyanu yi ni pe ohun ti Olùgbàlà nfún wa ni nígbàgbogbo tó ju díẹ̀ sìi!

  22. Gbòngbò Latin ti ọ̀rọ̀ náà ẹbọ ni sacer, ìtumọ̀ mímọ́ tàbí mimọ, àti facere, túmọ̀ sí láti ṣe. Bí a ṣe nrúbọ fún Ọlọ́run, Ó sọ wá di mímọ́ (wo Hélámánì 3:35; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 132:50).

  23. 3 Néfì 27:14.

  24. Wo Ẹ̀kọ́ ati àwọn Májẹ̀mú 15:6; 16:6; 18:10–16.

  25. Wo Mórónì 7:2; Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò: Sísìn nínú Ìjọ Jésù Krístì ti awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, 4.1, Ibi Ìkàwé Ìhìnrere

  26. Wo “Ẹ Jẹ́ Kí A Tẹ̀síwájú,” Àwọn Orin, no. 243.

  27. Ìrírí ti araẹni àti ìfọ̀rọ̀ránṣẹ́, 4 Oṣù Kínní, Ọdún 2025; orúkọ ti yí padà.

  28. Wo Máttéù 10:5–8; Lúkù 10:1–9; Ìwé ìléwọ́ Gbogbogbò, 4.2.6.

  29. Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 107:99; àtẹnumọ́ àfikún; láti inú ìbáraẹnisọ̀rọ̀ pẹ̀lú Alàgbà David A. Bednar, Oṣù kejìlá. 2024.

  30. Wo Ìtàn—Josefu Smith 1:20. Àwọn ọ̀dọ́ wa kìí ṣe àwọn olórí ọjọ́ iwájú nìkan nínú Ìjọ. Wọ́n lè darí ní àwọn ọ̀nà pàtàkì ní báyìí. Mo rí òtítọ́ yi ní sísìn pẹ̀lú 744 ti àwọn ọmọ-ẹ̀hìn oníyanujùlọ jùlọ ti Jésù Krístì nínú Iṣẹ́ Míṣọ̀n Illinois Chicago láti 2019–2022. Lákokò Covid, àwọn ọ̀dọ́ ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀hìn alágbára ti Krístì ṣe ìtọ́sọ́nà iṣẹ́ Ọlọ́run síwájú sí àwọn àìrí gíga rí ní àwọn ọ̀nà ìyàlẹ́nu àti ìmọ̀titun.

  31. Wo 2 Néfì 27:20–21.

  32. Wàásù Ìhìnrere Mi: Atọ́nà Kan Sí Pípín Ìhìnrere Jésù Krístì (2023), 3.

  33. Jákọ́bù 1:17, 19, iṣẹ́ Jákọ́bù jẹ́ iṣẹ́ Olúwa Kò gbé ipò rẹ̀ ga fún ara rẹ̀ bíkòṣe sí Olúwa kí ó baà lè kọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí ó sì baà lè jẹ́ aláìlábàwọ́n ní ọjọ́ ìkẹhìn.

  34. Wo 3 Néfì 27:27.

  35. Ẹ̀kọ́ ati àwọn Májẹ̀mú 1:11–12.