Ìgbàgbọ́: Àsopọ̀ Mímọ́ ti Ìgbẹ́kẹ̀lé àti Ìṣòótọ́
Ìgbàgbọ́ ndàgbà bí a ṣe ngbẹ́kẹ̀lé Jésù Krístì ó sì ntàn bí a ṣe njẹ́ olóòtọ́ àti adúróṣinṣin sí I.
Nígbàtí mo pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, mo bá ọ̀rẹ́ mi José Luis ṣe àdéhùn pé kí nkọ́ ọ bí o ṣe lè lúwẹ̀ẹ́. Nítorínàà lówurọ̀ ọjọ́ kan a ya àkókò láti ṣe ìgbáradì. Nígbàtí ẹ̀kọ́ wa ti parí àti tí mò nlọ kúrò nínú adágún omi, mo gbọ́ tí ọ̀rẹ́ mi npariwo fún ìrànlọ́wọ́. Ò sì ti nrì ní òpin adágún omi tí ó jìn.
Mo ju ara mi sínú omi mo sì wẹ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ nígbàtí mo ngbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́. Bí mo ṣe di ọwọ́ rẹ̀ mú láti fà á wá sí orí ilẹ̀, ọ̀rẹ́ mi tí kò ní ìrètí gún òkè lọ sí ẹ̀hìn mi ó sì fi mí sínú ìdìmú kan. Báyi àwa méjèèjì nrì. Ní ìgbìyànjú mi láti dé òkè, mo gbàdúrà pẹ̀lú gbogbo agbára mi fún ìyanu láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Lẹ́hìnáà, láìyára ṣùgbọ́n ní dídúro gbọin, agbára Ọlọ́run farahàn bí mo ṣe ní ìmọ̀lára ọwọ́ kan tí ó ngbe mi lọ sí òpin adágún omi àìjìn, tí ó gbé wa lọ sí ibi ààbò.
Ìrírí yìí jẹ́rìí sí ẹ̀kọ́ jíjinlẹ̀ kan tí Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni nígbà kan pé: “Nígbàtí o bá nawọ́ fún agbára Olúwa nínú ìgbésí-ayé yín pẹ̀lú irú kíkankíkan kannáà tí ẹnití o´nrì sínú omi ní nígbàtí ó bá ṣe ntiraka láti mí tí ó sì ntiraka fún afẹ́fẹ́ láti mí, agbára láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi yíò jẹ́ tìyin.”
Ẹ̀yin ọmọdé àti ọ̀dọ́, lónìí mo fẹ́ bá yín sọ̀rọ̀ nípa ìlànà pàtàkì ti ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì.
Níní ìgbàgbọ́ nínú Krístì túmọ̀ sí níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Rẹ̀
Kíni ó túmọ̀ si láti ní ìgbàgbọ́ nínú Krístì? Ṣé ó túmọ̀ sí pé a gbàgbọ́ nínú Rẹ̀ tàbí ni ẹ̀rí pé ó jẹ́ gidi? Ìyẹn lè jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n ó ju ìyẹn lọ. Njẹ́ ẹ ti ronú ìgbàgbọ́ nígbàgbogbo bí ìgbẹkẹ̀lé? Ẹ ronú nípa ẹni tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé jù lọ—bóyá ọmọ ẹbí tàbí ọ̀rẹ́ kan. Kíni ìdí tí ẹ fi gbẹ́kẹ̀lé wọn? Ó ṣeé ṣe nítorí pé ẹ ti rí ìfẹ́ àti ìrànlọ́wọ́ wọn nígbàgbogbo.
Nígbàtí a bá ní ìgbàgbọ́ nínú Krístì, a ndá àwọn ìbùkún Rẹ̀ mọ̀ a sì nṣe ìdàgbàsokè ìbáṣepọ́ ti ìgbẹ́kẹlé pẹ̀lú Rẹ̀.
Báwo Ni Ẹ Ṣe Lè Mú Ìgbẹ́kẹ̀lé Yín Nínú Krístì Pọ̀ Síi?
Nínú ìfọkànsìn àwọn ọ̀dọ́ kan láìpẹ́ yìí, wọ́n pè yín láti “ṣe àṣàrò lórí àkókò kan nínú ìgbésí ayé yín nígbàtí ẹ ti rí ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ ti ọ̀run.” Gbìyànjú ìdárayá yi!
Bẹ̀rẹ̀ nípa ṣíṣe àṣàrò nípa Krístì àti ayọ̀ tí Ètùtù àti ìhìnrere Rẹ̀ nmú wá sí ayé yín. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹ ṣe àkọsílẹ̀ ti “àwọn ìrántí onítumọ̀ ti ẹ̀mí” ibi tí Ọlọ́run ti wà níbẹ̀ fún yín, fún àwọn olólùfẹ́ yín, àti fún àwọn ènìyàn nínú àwọn ìwé mímọ́. Nísisìyí, àwọn ẹ̀rí wọ̀nyí kò ní mú agbára wá sí ìgbé ayé rẹ títí tí Ẹ̀mí yíò fi gbé wọn jáde nínú “àwọn tábìlì ẹran ara” ti ọkàn yín. Nítorínáà ẹ ronú jinlẹ̀ kí ẹ sì ṣe àkọsílẹ̀ gbogbo ohun tí Ọlọ́run gbékalẹ̀ kí àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí le dé ní àkókò tí ó tọ́ gan-an.
Lẹ́hìnnáà, ẹ lo ìdárayá yìí gẹ́gẹ́bí ànfààní láti sún mọ́ Ọlọ́run. Ẹ gbàdúrà sí Bàbá yín Ọ̀run bí ẹni pé ó jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́. Fi ìfẹ́ àti ìmoore hàn fún àwọn ìbùkún Rẹ̀. Àní bèèrè lọ́wọ́ Rẹ̀ bí Ó ṣe ní ìmọ̀lára nípa nípa ìtọ́nisọ́nà tí ayé yín nlọ.
Tí ẹ bá jẹ́ olódodo àti onírẹ̀lẹ̀, ẹ̀yin yíò gbọ́ ìdáhùn Rẹ̀ ẹ̀yin yíò sì bẹ̀rẹ̀ ìbáṣepọ̀ ti araẹni àti ti ó pẹ́ títí pẹ̀lú Bàbá Ọ̀run àti Jésù Krístì. Kìí ṣe ìyẹn nìkan, ṣùgbọ́n àwọn ìhùwàsí ẹ̀sìn rẹ yíò ní ìtumọ̀! Fún àpẹrẹ, ìwọ yíò máa fojú sọ́nà fún àdúrà yín, ṣíṣe àṣàrò araẹni, àti ìjọsìn tẹ́mpìlì bí àwọn ànfààní láti mọ̀ Wọ́n kí ẹ sì wà pẹ̀lú Wọn.
Ìgbàgbọ́ Ngbilẹ̀ síi pẹ̀lú Ìṣòótọ́
Ẹ ṣe àkíyèsí pé ìgbàgbọ́ ndàgbà bí a ṣe ngbẹ́kẹ̀lé Jésù Krístì ó sì ntàn bí a ṣe njẹ́ olóòtọ́ àti adúróṣinṣin sí I. Tí ẹ bá fẹ́ ìbáṣepọ̀ tòótọ́ pẹ̀lú Kristi, ẹ fi hàn án nípa dídá àwọn májẹ̀mú àti bíbọlá fún wọn pẹ̀lú òtítọ́ àti ìdúróṣinṣin. Bíbá Jésù Kristi dá májẹ̀mú ngbé ìrètí ró. Bíbọlá fún wọn ngbé ìgbàgbọ́ ró.
Ẹ jẹ́ kí nlo àpẹrẹ ti araẹni kan: Nígbàtí mo wà lọ́mọdé, mo rí màmá mi tó ndá nìkan sọkún lọ́jọ́ kan. Nígbàtí mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ kílódé, ó rọra sọ pé, “Mo nílò rẹ láti jẹ́ ọmọkùnrin rere.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo mọ̀ pé kì í ṣe èmi ló fa ìdààmú ọkàn rẹ̀, mo fẹ́ràn mo sì fọkàn tán ìyá mi bíi pé kò sí ẹlòmíràn mo sì fẹ́ mú kí ìgbésí ayé rẹ̀ dínkù ní ìṣòro. Nítorínáà, pẹ̀lú omijé lójú mi àti pẹ̀lú gbogbo ọ̀wọ̀ tí ọmọ-ọdún-mẹ́san lè ní, mo ṣèlérí fún un lọ́jọ́ náà pé èmi yíò máa làkàkà nígbà gbogbo láti jẹ́ ọmọ tó dára jù lọ kí nsì múu gbéra ga.
Ǹjẹ́ ẹ lè fojú inú wo agbára tí ìlérí náà ní—tí ó sì tún nní—lórí mi?
Ìlérí náà pẹ̀lú rẹ̀ yíò ṣe ìtọ́sọ́nà ìgbésí-ayé mi. Ṣááju ṣíṣe àwọn ìpinnu, Èmi yíò ronú bóyá àwọn ìgbésẹ̀ mi yíò dùn mọ́ ọ nínú. Ìdè ìlérí yìí àti ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ìyá mi ni àwọn ìdákọ̀ró fún ìwà mi jálẹ̀ ìgbésí ayé mi.
Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́hìnnáà, bí mo ṣe wá túbọ̀ mọ Jésù Kristi sí i, mo ti mọ bí mo ṣe lè gbé ìgbàgbọ́ mi kalẹ̀ nínú Rẹ̀. Mo dá májẹ̀mú pẹ̀lú Olúwa, bí mo sì ti nwá láti bọ̀wọ̀ fún wọn, Ó ti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi jì, ó tọ́ ìgbésí ayé mi, ó sì “kún mi pẹ̀lú ìfẹ́ Rẹ̀” dé pàtàkì ìwàláàyè mi. Kristi ti gbin ìfẹ́ jíjinlẹ̀, ọ̀wọ̀, àti ìdúróṣinṣin sínú mi fún Un.
Ǹjẹ́ ẹ lóye ìdí “tí ìgbàgbọ́ fi jẹ́ ìlànà ìṣe” àti pé “láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti mú inú [Ọlọ́run] dùn”?
Bí o ṣe ngbìyànjú láti ṣe ohun tó wù Ú, ìwọ yíò sọ, bíi Jósẹ́fù ní Égíptì nígbàtí aya Pọ́tífárì dán an wò, “Báwo ni mo ṣe lè ṣe ohun búburú ńlá yìí, kí nsì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run?” Nígbàtí ẹ̀yin bá sì dojú kọ àtakò, ẹ̀yin yíò sọ bíi ti ọ̀dọ́ wòlíì Jósẹ́fù pé: “Mo mọ̀, mo sì mọ̀ pé Ọlọ́run mọ̀ bẹ́ẹ̀, mi ò sì lè sẹ́ ọ̀rọ̀ náà … Mo mọ̀ pé nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ màá ṣẹ Ọlọ́run.”
Nítorínáà ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi jẹ́ ìdè ìgbẹ́kẹ̀lé tí a gbé kalẹ̀ nínú ìdúróṣinṣin àti ìfẹ́. Ní ọ̀rọ̀ míràn, nínú ìmoore fún ìfẹ́ aláàánú Ọlọ́run (hẹ́sẹ̀d), a nfi ìfẹ́ òtítọ́ wa (émúnàh) hàn nípa pípa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́.
Kristi ṣèlérí pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní àwọn òfin mi, tí ó sì npa wọ́n mọ́ … ni Baba mi yíó fẹ́ràn, èmi yíò sì fẹ́ràn rẹ̀, èmi yíò sì fi ara mi hàn fún un.” Tí ẹ bá farajìn sí jíjẹ́ olóotọ́ sí I, Òun yíò fi ìfẹ́ Rẹ̀ hàn fún yín.
Ìgbàgbọ́ Nínú Ojú Ìpọ́njú
Ṣùgbọ́n báwo ni ó ṣe yẹ kí ẹ dáhùn sí irú àwọn ipò ìkọlù tí ó nílò àwọn iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀? Lákoko tí àwọn ìpèníjà bá jẹ èyítí kò ṣeé ṣe àti ní ìgbà míràn tí ó ba ni lẹ́rù, rọra rìn láìsí ìjayà sọ́dọ̀ Rẹ̀, gẹ́gẹ́bí àkòrí FSY 2025 ti npèni: “Wò mí ní gbogbo èrò; maṣe ṣiyèméjì, máṣe bẹ̀rù.”
Báwo Ni Ẹ Ṣe Lè Rìn Láìsí Ìjayà Sí Ìhà Ọ̀dọ̀ Rẹ̀?
Ẹ ronú pé o jẹ́ olùwákiri kan ní agbègbè tí a kò ṣe àfihàn rẹ̀. Láti borí àwọn ìdíwọ́ tí ó wà níwájú, a nílò orísun ìmọ́lẹ̀ kan. Òtítọ́ yín sí Ọlọ́run àti àwọn ìbáṣepọ̀ ìgbàgbogbo pẹ̀lú Rẹ̀ jẹ́ òróró fún fìtílà yín. Nítorínáà nígbàtí ẹ bá pàdé àwọn ipò òkùnkùn àti ewu, dípò lílọ sí ìhà ọ̀dọ̀ wọn bíi afọ́jú, ẹ̀yin yíò ti tan fìtílà yín tí ó kún fún òróró ìgbàgbọ́ nínú Krístì láti tan àwọ̀n dídán ìrètí sílẹ̀ ní ipa ọ̀nà àìdánilójú. Àwọn ìrírí rẹ tí ó ti kọjá yíò mú ìrètí rẹ pọ̀ si pé Olúwa yíò gbé yín dúró nínú ìrìn-àjò yín.
Báwo ni Ẹ̀yin Ṣe Le Rìn Jìnà Tó Pẹ̀lú Ìrètí àti Ìgbàgbọ́ Yín nínú Krístì?
Ṣé ẹ rántí ìtàn mi ní ibi adágún omi? Ní àkókò àìnírètí náà, iṣẹ́ ìyanu dé lọ́nà tí mo ti ní ìretí, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò mu dá wa lójú pé yíò máa wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ wa nígbà gbogbo. Ìgbàgbọ́ wa gbọ́dọ̀ wà ní ààrin oókan Krístì kí ìrètí wa sì wà nínú àwọn ìbùkún Rẹ̀, bí Ó ti yàn láti fi wọ́n ránṣẹ́. “Ẹ retí àwọn iṣẹ́ ìyanu,” ṣùgbọ́n “ẹ jẹ́kí Ọlọ́run borí nínú ayé wa.”
Àwọn Ìlérí Ọlọ́run fún Àwọn Ènìyàn Rẹ̀ Olóotọ́
Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀dọ́, báwo ni a ti nífẹ́ẹ̀ yín tí a sì gbà yín gbọ́ tó! Ẹ̀yin jẹ́ ti ìdílé Ọlọ́run ẹ sì jẹ́ ọmọ májẹ̀mú. Ẹ gbàgbọ́ kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Jésù Krístì. Òun yíò jẹ́kí ẹ di ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀ nítòótọ́.
Mo pè yín láti bẹ̀rẹ̀ lónìí láti tọ́jú ìbáṣepọ̀ yín pẹ̀lú Jésù Krístì. Ṣe àdéhùn láti máṣe kọ̀ Ọ́ sílẹ̀ láéláé.
Ìdúróṣinṣin yín, ìfẹ́, àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Krístì yíò ṣe ìhùwàsí àti ìdánimọ̀ yín tẹ̀lé Tirẹ̀. Ẹ̀yin yíò ní ìgboyà àti agbára láti borí àwọn ìkọlù Sàtánì. Àti nígbàtí ẹ̀yin bá ṣe àwọn àṣìṣe, ẹ̀yin yíò ṣàfẹ́rí fún ìdáríjì Rẹ̀. Níkẹhìn, ìrètí yín fún ọjọ́ iwájú yíò jẹ́ ìmọ́lẹ̀. Òun yíò gbẹ́kẹ̀lé yín pẹ̀lú agbára Rẹ̀ láti ṣe àṣeyọrí ohunkohun tí Ó nretí láti ọ̀dọ̀ yín, àní agbára láti pada sí iwájú rẹ̀.
Mo jẹ́rìí sí yín nípa ayọ̀ tí ó nwá láti inú kíkọ “orin ti ìfẹ́ ìràpadà” àti pé “a yí wa ká títí láé nínú apá ìfẹ́ rẹ̀.” Ní orúkọ mímọ́ Jésù Krístì, àmín.